Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ǹjẹ́ ó tọ̀nà láti sọ pé àánú Jèhófà ń pẹ̀rọ̀ sí ìdájọ́ òdodo rẹ̀?
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti lo gbólóhùn yìí, ó dára ká yẹra fún un, nítorí ohun tó dà bíi pé ó túmọ̀ sí ni pé àánú Jèhófà ń rọ ìdájọ́ òdodo rẹ̀ lójú tàbí pé ó ń fawọ́ ìdájọ́ òdodo rẹ̀ sẹ́yìn, bí ẹni pé àánú ṣe pàtàkì ju ìdájọ́ òdodo tó jẹ́ ànímọ́ lílekoko. Èyí kò tọ̀nà rárá.
Ọ̀rọ̀ èdè Hébérù tí a tú sí “ìdájọ́ òdodo” nínú Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tún lè túmọ̀ sí “ìdájọ́.” Ìtumọ̀ ìdájọ́ òdodo àti òdodo kò fi bẹ́ẹ̀ jìnnà síra. Àmọ́, ìdájọ́ òdodo sábà máa ń ní ọ̀ràn òfin nínú. Òdodo kì í sábà rí bẹ́ẹ̀. Òótọ́ ni pé ìdájọ́ òdodo Jèhófà lè wé mọ́ fífi ìyà tí ó tọ́ jẹni, ṣùgbọ́n ó tún lè wé mọ́ pípèsè ìgbàlà fún àwọn ẹni yíyẹ. (Jẹ́nẹ́sísì 18:20-32; Aísáyà 56:1; Málákì 4:2) Nítorí náà, kò yẹ ká máa wo ìdájọ́ òdodo Jèhófà bí èyí tó le koko jù tàbí èyí tó yẹ ká pẹ̀rọ̀ sí.
Ọ̀rọ̀ tí èdè Hébérù lò fún “àánú” lè túmọ̀ sí lílo ìkóra-ẹni-níjàánu nínú ṣíṣe ìdájọ́. Ó tún lè tọ́ka sí fífi ìyọ́nú hàn lọ́nà tó gbéṣẹ́, tó ń mú ìtura bá àwọn tójú ń pọ́n.—Diutarónómì 10:18; Lúùkù 10:29-37.
Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run ìdájọ́ òdodo àti àánú. (Ẹ́kísódù 34:6, 7; Diutarónómì 32:4; Sáàmù 145:9) Ìdájọ́ òdodo àti àánú rẹ̀ pé, wọ́n sì máa ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀ ni. (Sáàmù 116:5; Hóséà 2:19) Àwọn ànímọ́ méjèèjì ló ṣe déédéé ara wọn tàbí tí wọ́n jẹ́ àṣekún ara wọn. Nítorí náà, tá a bá sọ pé àánú Jèhófà pẹ̀rọ̀ sí ìdájọ́ òdodo rẹ̀, a tún ní láti sọ pé ìdájọ́ òdodo rẹ̀ pẹ̀rọ̀ sí àánú rẹ̀.
Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Jèhófà yóò máa bá a nìṣó ní fífojúsọ́nà fún fífi ojú rere hàn sí yín, nítorí náà, yóò dìde láti fi àánú hàn sí yín. Nítorí pé Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run ìdájọ́ [“ìdájọ́ òdodo,” The New English Bible].” (Aísáyà 30:18) Aísáyà fi hàn níhìn-ín pé ìdájọ́ òdodo Jèhófà ń jẹ́ kó fi àánú hàn, kì í ṣe pé àánú rẹ̀ ń pẹ̀rọ̀ sí ìdájọ́ òdodo rẹ̀ tàbí ó ń ká a lọ́wọ́ kò. Jèhófà ń fi àánú hàn nítorí pé ó jẹ́ onídàájọ́ òdodo àti nítorí pé ó nífẹ̀ẹ́.
Lóòótọ́, òǹkọ̀wé Bíbélì nì, Jákọ́bù kọ̀wé pé: “Àánú a máa yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun lórí ìdájọ́.” (Jákọ́bù 2:13b) Àmọ́, nínú àyíká ọ̀rọ̀ yẹn, kì í ṣe Jèhófà ni Jákọ́bù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ bí kò ṣe àwọn Kristẹni tó ń ṣàánú—fún àpẹẹrẹ, àwọn tó ń ṣàánú àwọn ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ àti àwọn òtòṣì. (Jákọ́bù 1:27; 2:1-9) Nígbà tí Jèhófà bá fẹ́ dá irú àwọn aláàánú bẹ́ẹ̀ lẹ́jọ́, ó máa ń ro ti ìwà wọn, ó sì máa ń fi tàánútàánú dárí jì wọ́n nítorí ẹbọ Ọmọ rẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, àánú tí wọ́n ti ṣe ń yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun lórí ìdájọ́ líle koko tí ì bá tọ́ sí wọn.—Òwe 14:21; Mátíù 5:7; 6:12; 7:2.
Nítorí náà, kò tọ̀nà láti sọ pé àánú Jèhófà ń pẹ̀rọ̀ sí ìdájọ́ òdodo rẹ̀, bí ẹni pé ìdájọ́ òdodo rẹ̀ le débi pé ó di dandan láti fi àánú pẹ̀rọ̀ sí i. Lọ́dọ̀ Jèhófà, ọgbọọgba ni àwọn ànímọ́ méjèèjì jẹ́. Wọ́n ṣe déédéé ara wọn bí wọ́n ti ṣe déédéé pẹ̀lú àwọn ànímọ́ mìíràn tí Jèhófà ní, bí ìfẹ́ àti ọgbọ́n.