Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

‘Ìfẹ́ Wa Ti Jinlẹ̀ Sí I’

‘Ìfẹ́ Wa Ti Jinlẹ̀ Sí I’

‘Ìfẹ́ Wa Ti Jinlẹ̀ Sí I’

NÍ ỌJỌ́ Friday, ní March 31, lọ́dún 2000 ni Òkè Usu ní erékùṣù Hokkaido ní Japan bú gbàù lẹ́yìn ọdún mẹ́tàlélógún tí kò fi tú nǹkan kan jáde. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ló di dandan fún láti sá kúrò ní àgbègbè eléwu nígbà tó pàpà bú gbàù. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló pàdánù ilé àti iṣẹ́ wọn. Ṣùgbọ́n a dúpẹ́ pé kò sẹ́ni tó ṣòfò ẹ̀mí. Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́rìndínláàádọ́ta wà lára àwọn tó sá àsálà, àmọ́ wọ́n rẹni fẹ̀yìn tì.

Lọ́jọ́ tí òkè náà bú gbàù ni a ṣètò pé kí Kristẹni òjíṣẹ́ arìnrìn àjò kan tó ń sìn ní àgbègbè yẹn bẹ̀rẹ̀ sí bójú tó ètò ìrànlọ́wọ́. Láìpẹ́ ni àwọn ohun àfiṣèrànwọ́ bẹ̀rẹ̀ sí dé láti àwọn ìjọ itòsí. Lẹ́yẹ-ò-sọkà ni wọ́n ṣètò ìgbìmọ̀ olùpèsè ìrànwọ́ lábẹ́ àbójútó ẹ̀ka iléeṣẹ́ wa ní Japan. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin Japan sì bẹ̀rẹ̀ sí fi nǹkan ránṣẹ́. Láti lè máa bá ìgbòkègbodò tẹ̀mí nìṣó, a rán àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó jẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún sí ìjọ tí jàǹbá náà bá jù lọ. Alábòójútó àyíká sì bẹ àgbègbè náà wò léraléra láti bá wọn kẹ́dùn, kí ó sì tì wọ́n lẹ́yìn nípa tẹ̀mí.

Àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà lágbègbè tí jàǹbá náà dé kò ṣíwọ́ ṣíṣe àwọn ìpàdé Kristẹni ní àkókò lílé koko yẹn. Inú àwọn ilé àdáni tó wà lágbègbè tí jàǹbá náà ò dé ni wọ́n ti ń ṣèpàdé. Nígbà tí wọ́n sọ pé àwọn èèyàn lè padà ságbègbè tí Gbọ̀ngàn Ìjọba wà, àwọn ará padà, wọ́n sì rí i pé ilé náà ti gbun, ògiri rẹ̀ ti lanu, àní ó ti di ẹgẹrẹmìtì. Nítòsí Gbọ̀ngàn Ìjọba náà, èéfín ṣì ń rú túú jáde látinú ihò tuntun tó wà lórí òkè náà. Àwọn Ẹlẹ́rìí wá ronú pé, ‘Ǹjẹ́ ó bọ́gbọ́n mu láti máa bá a lọ ní ṣíṣe ìpàdé níbẹ̀? Ǹjẹ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba náà ṣeé tún ṣe?’

Wọ́n pinnu pé ńṣe làwọn máa kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun ságbègbè tí jàǹbá náà ò dé. Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn ràn wọ́n lọ́wọ́ bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ. Owó táwọn Ẹlẹ́rìí tó wà nígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin orílẹ̀-èdè náà dá ni wọ́n fi kọ́ ilé yìí. Kíá ni wọ́n rí ilẹ̀ rà. Kò sì pẹ́ rárá tí wọ́n fi parí kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun náà, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn. Ní ọjọ́ Sunday, July 23, 2000, èèyàn márùndínlọ́gọ́rin ló pésẹ̀ sípàdé tí wọ́n kọ́kọ́ ṣe nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun yìí. Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó wá ló da omijé ayọ̀ lójú. Nígbà tí wọ́n ya Gbọ̀ngàn Ìjọba náà sí mímọ́ ní October ọdún yẹn, ọ̀kan lára àwọn alàgbà tó wà nínú ìjọ ibẹ̀ sọ látọkànwá pé: “Ìbúgbàù náà fa ìnira àti ìjìyà. Ṣùgbọ́n, ilé yìí ti sọ ìbẹ̀rù wa di ayọ̀. Ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà àti fún àwọn Kristẹni arákùnrin wa ọ̀wọ́n ti jinlẹ̀ sí i!”

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 19]

Ìbúgbàù Òkè Usu: AP Photo/Koji Sasahara