Báwo Ni Òtítọ́ Ti Ṣeyebíye Tó Lójú Rẹ?
Báwo Ni Òtítọ́ Ti Ṣeyebíye Tó Lójú Rẹ?
“Ẹ ó sì mọ òtítọ́, òtítọ́ yóò sì dá yín sílẹ̀ lómìnira.”—JÒHÁNÙ 8:32.
1. Báwo ni lílò tí Pílátù lo ọ̀rọ̀ náà “òtítọ́” ṣe yàtọ̀ sí bí Jésù ṣe lò ó?
“KÍ NI òtítọ́?” Nígbà tí Pílátù béèrè ìbéèrè yìí, ó dà bí ẹni pé ohun tí òtítọ́ túmọ̀ sí lóréfèé ló fẹ́ mọ̀. Ọ̀rọ̀ tí Jésù, ní tirẹ̀, ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ kí ìbéèrè yẹn tó wáyé, ni pé: “Nítorí èyí ni a ṣe bí mi, nítorí èyí sì ni mo ṣe wá sí ayé, kí n lè jẹ́rìí sí òtítọ́.” (Jòhánù 18:37, 38) Láìdàbí Pílátù, Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì fi hàn pé Jésù lo ọ̀rọ̀ atọ́ka tó ṣe pàtó nígbà tó ń tọ́ka sí “òtítọ́.” Ó ń tọ́ka sí òtítọ́ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run.
Ìṣarasíhùwà Ayé Yìí sí Òtítọ́
2. Gbólóhùn wo ni Jésù sọ tó fi bí òtítọ́ ti níye lórí tó hàn?
2 Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ìgbàgbọ́ kì í ṣe ohun ìní gbogbo ènìyàn.” (2 Tẹsalóníkà 3:2) A lè sọ ohun kan náà nípa òtítọ́. Kódà nígbà táwọn èèyàn bá láǹfààní láti mọ òtítọ́ tá a gbé ka Bíbélì, ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń dìídì fọwọ́ rọ́ òtítọ́ sẹ́yìn. Bẹ́ẹ̀, ó ṣeyebíye púpọ̀! Jésù sọ pé: “Ẹ ó sì mọ òtítọ́, òtítọ́ yóò sì dá yín sílẹ̀ lómìnira.”—Jòhánù 8:32.
3. Ìkìlọ̀ wo la gbọ́dọ̀ kọbi ara sí nípa àwọn ẹ̀kọ́ tí ń tanni jẹ?
3 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé òtítọ́ kì í ṣe ohun tá a lè rí nínú ìmọ̀ ọgbọ́n orí àti àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ ènìyàn. (Kólósè 2:8) Ohun tó tiẹ̀ ṣẹlẹ̀ ni pé, ẹ̀kọ́ èké ni irú àwọn ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀. Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ fún àwọn Kristẹni tó wà ní Éfésù pé bí wọ́n bá gbà wọ́n gbọ́, wọ́n á dà bí ọmọ ọwọ́ nípa tẹ̀mí, “tí a ń bì kiri gẹ́gẹ́ bí nípasẹ̀ àwọn ìgbì òkun . . . nípasẹ̀ gbogbo ẹ̀fúùfù ẹ̀kọ́ nípasẹ̀ ìwà àgálámàṣà àwọn ènìyàn, nípasẹ̀ àlùmọ̀kọ́rọ́yí nínú dídọ́gbọ́n hùmọ̀ ìṣìnà.” (Éfésù 4:14) Lóde òní, “ìwà àgálámàṣà àwọn ènìyàn” ni ìpolongo àwọn tó lòdì sí òtítọ́ Ọlọ́run ń gbé lárugẹ. Irú ìpolongo bẹ́ẹ̀ máa ń fi àlùmọ̀kọ́rọ́yí yí òtítọ́ padà sí èké, ó sì máa ń pe irọ́ ní òtítọ́. Tá a bá fẹ́ rí òtítọ́ lójú gbogbo irú àpadé-àludé bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ máa fi taápọntaápọn yẹ Ìwé Mímọ́ wò.
Àwọn Kristẹni àti Ayé
4. Àwọn wo ni òtítọ́ wà lárọ̀ọ́wọ́tó wọn, kí sì ni ojúṣe àwọn tó bá gbà á?
4 Nígbà tí Jésù Kristi ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó ti di ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó gbàdúrà sí Jèhófà pé: “Sọ wọ́n di mímọ́ nípasẹ̀ òtítọ́; òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ.” (Jòhánù 17:17) A ó sọ irú àwọn bẹ́ẹ̀ di mímọ́, tàbí kí a yà wọn sọ́tọ̀ fún sísin Jèhófà àti sísọ orúkọ rẹ̀ àti Ìjọba rẹ̀ di mímọ̀. (Mátíù 6:9, 10; 24:14) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé òtítọ́ kì í ṣe ohun ìní gbogbo ènìyàn, síbẹ̀ òtítọ́ Jèhófà wà lárọ̀ọ́wọ́tó, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ fún gbogbo àwọn tó ń wá a, láìfi orílẹ̀-èdè, ẹ̀yà, tàbí irú èèyàn tẹ́nì kan jẹ́ látilẹ̀wá pè. Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé: “Mo róye pé Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.”—Ìṣe 10:34, 35.
5. Èé ṣe táwọn èèyàn fi máa ń ṣe inúnibíni sáwọn Kristẹni?
5 Àwọn Kristẹni ń sọ òtítọ́ Bíbélì fún àwọn ẹlòmíràn, àmọ́ ibi gbogbo kọ́ la ti ń tẹ́wọ́ gbà wọ́n. Jésù kìlọ̀ pé: “Àwọn ènìyàn yóò fà yín lé ìpọ́njú lọ́wọ́, wọn yóò sì pa yín, ẹ ó sì jẹ́ ẹni ìkórìíra lọ́dọ̀ gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ní tìtorí orúkọ mi.” (Mátíù 24:9) Nígbà tí àlùfáà ará Ireland nì, John R. Cotter, ń sọ̀rọ̀ lórí ẹsẹ yìí, ó kọ̀wé ní ọdún 1817 pé: “Dípò káwọn èèyàn mọrírì ìsapá wọn [ìyẹn àwọn Kristẹni] láti tún ìgbésí ayé àwọn èèyàn ṣe nípasẹ̀ ìwàásù wọn, ńṣe ló ń mú kí wọn kórìíra àwọn ọmọ ẹ̀yìn, tí wọ́n sì ń ṣe inúnibíni sí wọn, nítorí títú tí wọ́n ń tú àwọn ìwà ibi wọn fó.” Irú àwọn tó ń ṣe inúnibíni bẹ́ẹ̀ kò “tẹ́wọ́ gba ìfẹ́ òtítọ́ náà, kí a bàa lè gbà wọ́n là.” Tìtorí èyí ni “Ọlọ́run fi jẹ́ kí ìṣiṣẹ́ ìṣìnà tọ̀ wọ́n lọ, kí wọ́n bàa lè gba irọ́ gbọ́, kí a bàa lè dá gbogbo wọn lẹ́jọ́ nítorí tí wọn kò gba òtítọ́ gbọ́ ṣùgbọ́n wọ́n ní ìdùnnú nínú àìṣòdodo.”—2 Tẹsalóníkà 2:10-12.
6. Irú ìfẹ́ wo ni kò yẹ kí Kristẹni ní?
6 Àpọ́sítélì Jòhánù gba àwọn Kristẹni tó ń gbé nínú ayé búburú yìí níyànjú pé: “Ẹ má ṣe máa nífẹ̀ẹ́ yálà ayé tàbí àwọn ohun tí ń bẹ nínú ayé. . . . Ohun gbogbo tí ń bẹ nínú ayé—ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú àti fífi àlùmọ́ọ́nì ìgbésí ayé ẹni hàn sóde lọ́nà ṣekárími—kò pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Baba, ṣùgbọ́n ó pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ ayé.” (1 Jòhánù 2:15, 16) Nípa sísọ pé “ohun gbogbo,” Jòhánù kò yọ ohunkóhun sílẹ̀. Ìdí nìyẹn tí a kò fi gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ sí ohunkóhun tó wà nínú ayé yìí tó lè mú ká kúrò nínú òtítọ́. Kíkọbi ara sí ìmọ̀ràn Jòhánù yóò ní ipa tó lágbára lórí ìgbésí ayé wa. Lọ́nà wo?
7. Ipa wo ni ìmọ̀ òtítọ́ ń ní lórí àwọn olóòótọ́ ọkàn?
7 Ní ọdún 2001, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́rin ààbọ̀ lóṣooṣù, tí a sì ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan àti ní àwùjọ-àwùjọ ní ohun tí Ọlọ́run béèrè fún ìyè. Àbájáde rẹ̀ ni pé, 263,431 èèyàn la batisí. Ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ di èyí tó níye lórí gan-an lójú àwọn ọmọ ẹ̀yìn tuntun náà, wọ́n sì yàgò fún ẹgbẹ́ búburú àti àwọn ìwàkíwà tí ń tàbùkù sí Ọlọ́run, èyí tó wọ́pọ̀ nínú ayé yìí. Àtìgbà tí wọ́n ti ṣe batisí ni wọ́n ti ń bá a lọ láti máa gbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà tí Jèhófà là sílẹ̀ fún gbogbo Kristẹni. (Éfésù 5:5) Ṣé bẹ́ẹ̀ ni òtítọ́ ṣeyebíye tó lójú rẹ?
Jèhófà Bìkítà Nípa Wa
8. Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo ìyàsímímọ́ wa, èé sì ti ṣe tó fi bọ́gbọ́n mu láti ‘máa wá ìjọba náà lákọ̀ọ́kọ́’?
8 Láìka àìpé wa sí, Jèhófà fi àánú tẹ́wọ́ gba ìyàsímímọ́ wa. Ńṣe ló dà bíi pé ó rẹ ara rẹ̀ wálẹ̀ láti fà wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀. Ó tipa bẹ́ẹ̀ kọ́ wa láti máa lépa àwọn góńgó àti ìfẹ́ ọkàn tó mọ́yán lórí. (Sáàmù 113:6-8) Bákan náà, Jèhófà fún wa láyè láti ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú òun, ó sì ṣèlérí láti bójú tó wa bí a bá ń “bá a nìṣó . . . ní wíwá ìjọba náà àti òdodo Rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́.” Bí a bá ń ṣe èyí, tí a sì ń pa ara wa mọ́ nípa tẹ̀mí, ó ṣèlérí pé: “Gbogbo nǹkan mìíràn wọ̀nyí ni a ó sì fi kún un fún yín.”—Mátíù 6:33.
9. Ta ni “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” náà, báwo ni Jèhófà sì ṣe ń bìkítà fún wa nípa lílo “ẹrú” yìí?
9 Jésù Kristi yan àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ méjìlá, ó sì fi ìpìlẹ̀ ìjọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró lélẹ̀, èyí tí a wá ń pè ní “Ísírẹ́lì Ọlọ́run.” (Gálátíà 6:16; Ìṣípayá 21:9, 14) Nígbà tó yá, òun náà la tún pè ní “ìjọ Ọlọ́run alààyè, ọwọ̀n àti ìtìlẹyìn òtítọ́.” (1 Tímótì 3:15) Jésù pe àwọn mẹ́ńbà ìjọ yẹn ní “ẹrú olóòótọ́ àti olóye,” ó tún pè wọ́n ní “olóòótọ́ ìríjú náà, ẹni tí í ṣe olóye.” Ẹrú olóòótọ́ yẹn ni Jésù sọ pé yóò máa fún àwọn Kristẹni ní “ìwọ̀n ìpèsè oúnjẹ wọn ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu.” (Mátíù 24:3, 45-47; Lúùkù 12:42) Bí a kò bá jẹun, ebi máa pa wá kú ni. Bákan náà, bí a kò bá jẹ oúnjẹ tẹ̀mí, a ó di aláìlera, a ó sì kú nípa tẹ̀mí. Nítorí náà, wíwà tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” wà tún jẹ́ ẹ̀rí mìíràn tá a fi mọ̀ pé Jèhófà bìkítà nípa wa. Ǹjẹ́ kí a máa mọrírì àwọn ìpèsè tẹ̀mí tá à ń rí gbà nípasẹ̀ “ẹrú” náà.—Mátíù 5:3.
10. Èé ṣe tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa pésẹ̀ sáwọn ìpàdé déédéé?
10 Jíjẹ oúnjẹ tẹ̀mí kan ìdákẹ́kọ̀ọ́. Ó tún kan bíbá àwọn Kristẹni mìíràn kẹ́gbẹ́, àti lílọ sí àwọn ìpàdé ìjọ. Ǹjẹ́ o lè rántí ohun tó o jẹ ní oṣù mẹ́fà, tàbí ọ̀sẹ̀ mẹ́fà pàápàá sẹ́yìn? Ó ṣeé ṣe kó o ti gbàgbé. Síbẹ̀, ohunkóhun tó o bá jẹ ló ń fún ara rẹ lókun tó o nílò láti máa wà láàyè. Ó sì ṣeé ṣe kó o ti jẹ irú oúnjẹ kan náà lẹ́yìn ìyẹn. Bákan náà làwọn oúnjẹ tẹ̀mí tá à ń jẹ láwọn ìpàdé Kristẹni wa ṣe rí. Ó ṣeé ṣe ká máà rántí gbogbo ohun tá a gbọ́ láwọn ìpàdé wa. Ó sì ṣeé ṣe ká ti gbọ́ ìsọfúnni kan náà láìmọye ìgbà. Síbẹ̀, oúnjẹ tẹ̀mí ni, ó ṣe pàtàkì fún ìlera wa. Àwọn ìpàdé wa máa ń fún wa ní àwọn ohun agbẹ́mìíró nípa tẹ̀mí, èyí tí ó máa ń dé lákòókò yíyẹ.
11. Kí ni ojúṣe wa nígbà tá a bá lọ sáwọn ìpàdé Kristẹni?
11 Lílọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni tún gbé ẹrù iṣẹ́ mìíràn kà wá lórí. A gba àwọn Kristẹni níyànjú pé kí wọ́n máa ‘fún ara wọn níṣìírí,’ kí wọ́n sì máa ru àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn nínú ìjọ sókè sí “ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà.” Mímúra àwọn ìpàdé Kristẹni sílẹ̀, lílọ síbẹ̀, àti kíkópa nínú rẹ̀ ń fún ìgbàgbọ́ wa lẹ́nìkọ̀ọ̀kan lókun, ó sì ń fún àwọn ẹlòmíràn níṣìírí. (Hébérù 10:23-25) Bíi tàwọn ọmọ ọwọ́ tí wọ́n lè máa ṣa oúnjẹ jẹ, àwọn kan lè fẹ́ ká máa fún wọn níṣìírí ní gbogbo ìgbà kí wọ́n tó lè máa jẹ oúnjẹ amáralókun nípa tẹ̀mí. (Éfésù 4:13) Yóò jẹ́ ẹ̀rí pé a nífẹ̀ẹ́ bí a bá ń fúnni ní irú ìṣírí bẹ́ẹ̀ nígbà tó bá pọn dandan, kí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lè di Kristẹni tó dàgbà dénú, tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé nípa wọn pé: “Oúnjẹ líle jẹ́ ti àwọn ènìyàn tí ó dàgbà dénú, ti àwọn tí wọ́n tipasẹ̀ lílò kọ́ agbára ìwòye wọn láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.”—Hébérù 5:14.
Bíbójútó Ara Wa Nípa Tẹ̀mí
12. Ta ló ní ẹrù iṣẹ́ tó pọ̀ jù lọ bí a óò bá dúró nínú òtítọ́? Ṣàlàyé.
12 Ọkọ, aya, tàbí àwọn òbí wa lè fún wa níṣìírí ní ọ̀nà òtítọ́. Bákan náà ni àwọn alàgbà ìjọ lè ṣe olùṣọ́ àgùntàn wa gẹ́gẹ́ bí ara agbo tó wà lábẹ́ àbójútó wọn. (Ìṣe 20:28) Àmọ́, ta ló ní ẹrù iṣẹ́ tó pọ̀ jù lọ bí a óò bá máa rin ọ̀nà òtítọ́ nìṣó? Ká sọ tòótọ́, ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ni ẹrù iṣẹ́ náà já lé léjìká. Bọ́rọ̀ sì ṣe rí gan-an nìyẹn, ì báà jẹ́ nígbà tí nǹkan ń lọ déédéé tàbí ní àkókò ìṣòro. Gbé ìṣẹ̀lẹ̀ tó tẹ̀ lé e yìí yẹ̀ wò.
13, 14. Gẹ́gẹ́ bí ìrírí ọ̀dọ́ àgùntàn kan ṣe fi hàn, báwo la ṣe lè rí ìrànlọ́wọ́ tẹ̀mí tá a nílò gbà?
13 Ní ilẹ̀ Scotland, àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn bíi mélòó kan ń jẹko ní pápá kan nígbà tí ọ̀kan nínú wọn jẹ̀ lọ sí ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè kékeré kan, tó sì tibẹ̀ já sínú kòtò kan tó wà nísàlẹ̀. Kò fara pa o, àmọ́ ẹ̀rù bà á, kò sì lè gòkè padà. Bó ṣe bẹ̀rẹ̀ sí ké mẹ̀ẹ́ẹ̀-mẹ̀ẹ́ẹ̀ nìyẹn. Ìyá rẹ̀ gbọ́ igbe náà, òun náà sì bẹ̀rẹ̀ sí ké títí táwọn olùṣọ́ àgùntàn fi wá yọ ọ̀dọ́ àgùntàn náà jáde.
14 Kíyè sí bó ṣe ṣẹlẹ̀ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé. Ọ̀dọ́ àgùntàn náà kígbe fún ìrànlọ́wọ́, ìyá rẹ̀ gbọ́, òun náà bẹ̀rẹ̀ sí ké, bí àwọn olùṣọ́ àgùntàn ṣe gbọ́ ni wọ́n gbé ìgbésẹ̀ ojú ẹsẹ̀ láti yọ ọ́ nínú ọ̀fìn. Bí ọmọ àgùntàn kékeré àti ìyá rẹ̀ bá lè rí i pé ewu ń bọ̀, tí wọ́n sì kígbe fún ìrànlọ́wọ́ lójú ẹsẹ̀, ǹjẹ́ kò yẹ kí àwa náà ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tá a bá kọsẹ̀ nípa tẹ̀mí tàbí nígbà tá a bá dojú kọ àwọn ewu tí a ò retí nínú ayé Sátánì? (Jákọ́bù 5:14, 15; 1 Pétérù 5:8) A gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ o, àgàgà tí a ò bá tíì nírìírí, yálà nítorí pé a jẹ́ ọmọdé tàbí nítorí pé a ṣì jẹ́ ẹni tuntun nínú òtítọ́.
Títẹ̀lé Ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run Ń Mú Ayọ̀ Wá
15. Kí ni ìmọ̀lára obìnrin kan nígbà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí dara pọ̀ mọ́ ìjọ Kristẹni?
15 Ronú nípa bí ìmọ̀ Bíbélì ṣe níye lórí tó, àti ìfọ̀kànbalẹ̀ tó máa ń mú wá fún àwọn tó ń sin Ọlọ́run tòótọ́. Ìyá kan tó jẹ́ ẹni àádọ́rin ọdún, tó ti ń lọ sí Ìjọ Áńgílíkà látìgbà tí wọ́n ti bí i gbà pé kí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan wá máa bá òun ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kò pẹ́ tó fi mọ̀ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run, ó sì ń bá àwọn ará ṣe “Àmín” sí àdúrà àtọkànwá tí wọ́n ń gbà níwájú àwùjọ ní Gbọ̀ngàn Ìjọba àdúgbò. Ó fi ìmọ̀lára tó ga sọ pé: “Dípò jíjẹ́ kí Ọlọ́run dà bí ẹnì kan tó ga gan-an ju ẹni téèyàn lè bá sọ̀rọ̀, ó dà bíi pé ńṣe lẹ pè é wá sí àárín wa bí ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ kan. Ó jẹ́ ohun kan tí n kò nírìírí rẹ̀ rí.” Ó ṣeé ṣe kí olùfìfẹ́hàn ọ̀wọ́n yẹn má gbàgbé ìmọ̀lára yìí tó kọ́kọ́ ní nípa òtítọ́ láé. Ǹjẹ́ kí àwa náà má ṣe gbàgbé bí òtítọ́ ti ṣeyebíye tó lójú wa nígbà tá a kọ́kọ́ tẹ́wọ́ gbà á.
16. (a) Kí ló lè ṣẹlẹ̀ bí a bá fi kíkówójọ ṣe olórí góńgó wa? (b) Báwo la ṣe lè rí ayọ̀ tòótọ́?
16 Ọ̀pọ̀ gbà pé ayọ̀ àwọn yóò pọ̀ sí i bí àwọn bá ní owó púpọ̀ sí i. Àmọ́, bí a bá fi kíkó owó jọ ṣe olórí góńgó wa nínú ìgbésí ayé, a lè di ẹni tó ní “ìrora ọkàn tí kò ṣeé fẹnu sọ.” (1 Tímótì 6:10, Phillips) Ronú lórí ọ̀pọ̀ èèyàn tó ń ta tẹ́tẹ́, àtàwọn tó ń ta kàlòkàlò, tàbí àwọn tí wọ́n kàn ń méfò láìronú jinlẹ̀ láwọn ọjà ìdókòwò, tí wọ́n ń ronú pé àwọn ó tibẹ̀ dolówó rẹpẹtẹ. Ìwọ̀nba èèyàn kéréje ló ń rí ọrọ̀ tí wọ́n ń retí. Àwọn tó rí i pàápàá sábà máa ń rí i pé ọrọ̀ òjijì wọn kì í mú ayọ̀ wá. Dípò ìyẹn, ayọ̀ pípẹ́ títí máa ń wá látinú ṣíṣe ìfẹ́ Jèhófà, bíbá ìjọ Kristẹni ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú ìtọ́sọ́nà ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà àti ìrànlọ́wọ́ àwọn áńgẹ́lì rẹ̀. (Sáàmù 1:1-3; 84:4, 5; 89:15) Nígbà tá a bá ṣe èyí, àwọn ìbùkún tí a kò retí lè tẹ̀ wá lọ́wọ́. Ǹjẹ́ òtítọ́ ṣeyebíye lójú rẹ débi pé ó lè mú irú ìbùkún bẹ́ẹ̀ wá sínú ìgbésí ayé rẹ?
17. Kí ni wíwọ̀ tí Pétérù wọ̀ sí ọ̀dọ̀ Símónì oníṣẹ́ awọ fi hàn nípa irú ẹ̀mí tí àpọ́sítélì náà ní?
17 Gbé ìrírí kan tí àpọ́sítélì Pétérù ní yẹ̀ wò. Ní ọdún 36 Sànmánì Tiwa, ó rin ìrìn àjò míṣọ́nnárì lọ sí Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ṣárónì. Ó tẹsẹ̀ dúró ní Lídà, níbi tó ti wo Áínéásì tó ní àrùn ẹ̀gbà sàn, ó wá forí lé èbúté Jópà. Ibẹ̀ ló ti jí Dọ́káàsì dìde. Ìṣe 9:43 sọ fún wa pé: “Ó dúró ní Jópà fún ọjọ́ púpọ̀ díẹ̀ pẹ̀lú Símónì kan, tí ó jẹ́ oníṣẹ́ awọ.” Ibi tá a tọ́ka sí wẹ́rẹ́ yìí fi hàn pé Pétérù kò ní ẹ̀mí ẹ̀tanú bó ṣe ń wàásù fún àwọn èèyàn tó wà ní ìlú ńlá yẹn. Lọ́nà wo? Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Frederic W. Farrar kọ̀wé pé: “Kò sẹ́ni tó jẹ́ arinkinkin mọ́ Òfin [Mósè] Àtẹnudẹ́nu tó lè gbà láti wọ̀ sí ilé ẹni tó jẹ́ oníṣẹ́ awọ. Fífi ojoojúmọ́ rí awọ ẹran àti òkú onírúurú ẹran tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ yìí, àti àwọn nǹkan mìíràn tí wọ́n ń lò, mú kó jẹ́ iṣẹ́ àìmọ́, tó jẹ́ ìríra lójú gbogbo ẹni tó bá jẹ́ arinkinkin mọ́ òfin.” Kódà bí “ilé” Símónì tó wà “lẹ́bàá òkun” kò tilẹ̀ sún mọ́ ibi iṣẹ́ awọ rẹ̀, síbẹ̀ Farrar sọ pé Símónì ń ṣe ‘iṣẹ́ kan tó ń rí àwọn èèyàn lára, tí kì í jẹ́ káwọn èèyàn fojú gidi wo gbogbo àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ náà.’—Ìṣe 10:6.
18, 19. (a) Kí nìdí tí ìran tí Pétérù rí fi dà á láàmú? (b) Ìbùkún àìròtẹ́lẹ̀ wo ni Pétérù rí?
18 Pétérù tí kò ní ẹ̀mí ẹ̀tanú tẹ́wọ́ gba aájò àlejò tí Símónì ṣe, ibẹ̀ sì ni Pétérù ti rí ìran kan tí kò retí látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Ó rí ìran kan tí wọ́n ti pa á láṣẹ fún un pé kó jẹ àwọn ẹran tí òfin àwọn Júù kà sí aláìmọ́. Pétérù sọ pé òun kò tíì “jẹ ohunkóhun tí ó jẹ́ ẹlẹ́gbin àti aláìmọ́ rí.” Àmọ́ ìgbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n sọ fún un pé: “Dẹ́kun pípe ohun tí Ọlọ́run ti wẹ̀ mọ́ ní ẹlẹ́gbin.” Kò yani lẹ́nu pé, “Pétérù . . . wà nínú ìdàrú-ọkàn ńláǹlà ní inú lọ́hùn-ún ní ti ohun tí ìran tí òun rí lè túmọ̀ sí.”—Ìṣe 10:5-17; 11:7-10.
19 Pétérù kò mọ̀ pé Kèfèrí kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Kọ̀nílíù náà ti rí ìran kan ní ọjọ́ tó ṣáájú ìyẹn ní Kesaréà, tó jẹ́ àádọ́ta kìlómítà síbẹ̀. Áńgẹ́lì Jèhófà ti sọ pé kí Kọ̀nílíù rán àwọn ìránṣẹ́ láti wá Pétérù lọ sí ilé Símónì tó jẹ́ oníṣẹ́ awọ. Kọ̀nílíù rán àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ sílé Símónì, Pétérù sì tẹ̀ lé wọn padà sí Kesaréà. Ibẹ̀ ló ti wàásù fún Kọ̀nílíù àtàwọn ẹbí àtọ̀rẹ́ rẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn ni Kèfèrí aláìdádọ̀dọ́ tó kọ́kọ́ di onígbàgbọ́, tó sì gba ẹ̀bùn ẹ̀mí mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ajogún Ìjọba náà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé aláìdádọ̀dọ́ làwọn ọkùnrin wọ̀nyí, síbẹ̀ gbogbo àwọn tó gbọ́ ọ̀rọ̀ Pétérù la batisí. Èyí ló ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè, táwọn Júù kà sí aláìmọ́, láti di mẹ́ńbà ìjọ Kristẹni. (Ìṣe 10:1-48; 11:18) Ẹ ò rí i pé àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ lèyí jẹ́ fún Pétérù—bẹ́ẹ̀ nítorí pé òtítọ́ ṣeyebíye sí i ni, ó sì sún un láti tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Jèhófà, ó sì fi ìgbàgbọ́ gbégbèésẹ̀!
20. Ìtìlẹ́yìn àtọ̀runwá wo la máa ń rí nígbà tá a bá fi òtítọ́ sípò kìíní nínú ìgbésí ayé wa?
20 Pọ́ọ̀lù gbà wá níyànjú pé: “Ní sísọ òtítọ́, ẹ jẹ́ kí a fi ìfẹ́ dàgbà sókè nínú ohun gbogbo sínú ẹni tí í ṣe orí, Kristi.” (Éfésù 4:15) Bẹ́ẹ̀ ni o, òtítọ́ yóò mú ayọ̀ tí kò lẹ́gbẹ́ wá fún wa nísinsìnyí tí a bá fi sí ipò kìíní nínú ìgbésí ayé wa, tí a sì gbà pé kí Jèhófà máa fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ darí wa. A kò tún ní gbàgbé pé àwọn áńgẹ́lì mímọ́ ń tì wá lẹ́yìn nínú iṣẹ́ ìwàásù wa. (Ìṣípayá 14:6, 7; 22:6) Àǹfààní ńlá la mà ní yìí o, láti ní irú ìtìlẹ́yìn bẹ́ẹ̀ nínú iṣẹ́ tí Jèhófà yàn fún wa láti ṣe! Pípa ìwà títọ́ mọ́ yóò sún wa láti máa yin Jèhófà, Ọlọ́run òtítọ́, títí ayérayé. Ǹjẹ́ a tún rí ohun mìíràn tó lè ṣeyebíye jùyẹn lọ?—Jòhánù 17:3.
Kí Ni A Ti Kọ́?
• Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ èèyàn kì í fi í tẹ́wọ́ gba òtítọ́?
• Ojú wo ló yẹ káwọn Kristẹni fi wo àwọn nǹkan tí ń bẹ nínú ayé Sátánì?
• Kí ló yẹ kó jẹ́ ìṣarasíhùwà wa sí àwọn ìpàdé, èé sì ti ṣe?
• Kí ni ẹrù iṣẹ́ tá a ní láti bójú tó ara wa nípa tẹ̀mí?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán ilẹ̀/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
ÒKUN ŃLÁ
Kesaréà
PẸ̀TẸ́LẸ̀ ṢÁRÓNÌ
Jópà
Lídà
Jerúsálẹ́mù
[Àwòrán]
Pétérù tẹ̀ lé ìdarí látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ó sì rí àwọn ìbùkún tí kò retí
[Credit Line]
Àwòrán ilẹ̀: Mountain High Maps® Copyright © 1997 Digital Wisdom, Inc.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Jésù jẹ́rìí sí òtítọ́
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Bí oúnjẹ ti ara, oúnjẹ tẹ̀mí ṣe pàtàkì fún ìlera wa