Fífi Ẹ̀mí Ìfara-ẹni-rúbọ Sìn
Ìtàn Ìgbésí Ayé
Fífi Ẹ̀mí Ìfara-ẹni-rúbọ Sìn
GẸ́GẸ́ BÍ DON RENDELL ṢE SỌ Ọ́
Ọmọ ọdún márùn-ún péré ni mí nígbà tí màmá mi kú lọ́dún 1927. Síbẹ̀, ìgbàgbọ́ rẹ̀ nípa lórí ìgbésí ayé mi gan-an. Báwo ló ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀?
ÒGBÓǸKANGÍ ọmọ Ìjọ Áńgílíkà ni màmá mi nígbà tó fẹ́ bàbá mi, tí í ṣe jagunjagun. Kí Ogun Àgbáyé Kìíní tó jà nìyẹn o. Nígbà tí Ogun Àgbáyé Kìíní bẹ́ sílẹ̀ ní ọdún 1914, màmá mi tako àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì rẹ̀, ó ní kò yẹ kó máa ti orí àga ìwàásù kéde pé káwọn èèyàn lọ wọṣẹ́ ológun. Kí lèsì àlùfáà? “Sáà máa lọ sílé, máà jẹ́ kíyẹn dà ọ́ láàmú!” Èsì yẹn ò tẹ́ màmá mi lọ́rùn rárá.
Nígbà tí eruku ogun ṣì ń sọ lálá lọ́dún 1917, Màmá lọ wo “Photo-Drama of Creation” [Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Onífọ́tò Nípa Ìṣẹ̀dá]. Bó ṣe rí i pé òtítọ́ lòun rí yìí ló fi ṣọ́ọ̀ṣì sílẹ̀ lójú ẹsẹ̀, tó di ara àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìyẹn orúkọ tá a mọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sí nígbà yẹn. Ó ń ṣèpàdé pẹ̀lú ìjọ kan ní Yeovil, ìlú kan nítòsí West Coker, ìyẹn abúlé wa tó wà ní ẹkùn Somerset nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.
Láìpẹ́ ni màmá mi sọ nípa ẹ̀sìn tuntun yìí fáwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ méjì àti àbúrò rẹ̀ kan. Àwọn àgbàlagbà inú ìjọ Yeovil sọ fún mi nípa bí màmá mi àti Millie àbúrò rẹ̀ ṣe máa ń fi tìtara-tìtara gun kẹ̀kẹ́ jákèjádò ìgbèríko wa gbígbòòrò, tí wọ́n ń pín ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà, Studies in the Scriptures kiri. Àmọ́, ó ṣeni láàánú pé ikọ́ ẹ̀gbẹ, tó jẹ́ àrùn tí kò gbóògùn nígbà yẹn, dá màmá mi wó sórí bẹ́ẹ̀dì fún ọdún kan ààbọ̀ tó lò kẹ́yìn láyé.
Ẹ̀mí Ìfara-Ẹni-Rúbọ Gidi
Àǹtí mi Millie, tó ń gbé lọ́dọ̀ wa nígbà yẹn ló tọ́jú màmá wa nígbà tí àìsàn ọ̀hún gbé e dè. Òun náà ló tún tọ́jú èmi àti Joan ẹ̀gbọ́n mi ọmọ ọdún méje. Gbàrà tí Màmá kú ni Àǹtí Millie sọ pé òun ṣe tán láti máa tọ́jú àwa ọmọ nìṣó. Inú bàbá mi dùn pé òun rẹ́ni ran òun lẹ́rù yìí. Ó gbà pé kí Àǹtí Millie kúkú máa gbé lọ́dọ̀ wa.
A nífẹ̀ẹ́ àǹtí wa gan-an bá a ṣe ń dàgbà. Inú wa sì dùn pé ó gbà láti jókòó tì wá. Ṣùgbọ́n kí ló jẹ́ kó ṣe ìpinnu yẹn? Àǹtí Millie sọ fún wa ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà pé òun mọ̀ pé ojúṣe òun ni láti máa bá iṣẹ́ tí màmá wa bẹ̀rẹ̀ nìṣó—ìyẹn ni láti fi òtítọ́ Bíbélì kọ́ èmi àti Joan—nítorí òun mọ̀ pé bàbá wa kò ní jẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí pé kò nífẹ̀ẹ́ sí ìsìn.
Lẹ́yìn ìyẹn la tún wá mọ̀ pé Àǹtí Millie ti ṣe ìpinnu mìíràn tó tẹ̀wọ̀n gan-an. Kí ó lè ráyè tọ́jú wa dáadáa, ó pinnu pé òun ò ní lọ́kọ rárá. Ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ yìí mà ga o! Ẹnu èmi àti Joan kò gbọpẹ́ fún ohun tó ṣe yìí. A ò jẹ́ gbàgbé gbogbo ohun tí Àǹtí Millie kọ́ wa àti àpẹẹrẹ àtàtà tó fi lélẹ̀.
Àkókò Ìpinnu
Iléèwé Ìjọ Áńgílíkà tí ń bẹ lábúlé wa lèmi àti Joan ń lọ. Àǹtí Millie sì jẹ́ kó yé obìnrin tó jẹ́ ọ̀gá iléèwé náà pé ẹ̀kọ́ ìsìn tiwa yàtọ̀. Ńṣe la máa ń gbọ̀nà ilé lọ nígbà táwọn ọmọ yòókù bá ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì. Nígbà tí àlùfáà bá sì wá kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ ìsìn, ńṣe la máa ń kúrò láàárín wọn, wọ́n á sì fún wa ní àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a óò há sórí. Ìpìlẹ̀ rere lèyí jẹ́ fún mi, nítorí pé ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wọ̀nyẹn ṣì wà lọ́kàn mi digbí.
Mo fi iléèwé sílẹ̀ lọ́mọ ọdún mẹ́rìnlá láti lọ fi ọdún mẹ́rin kọ́ṣẹ́ nílé iṣẹ́ kan tó ń ṣe wàràkàṣì ládùúgbò wa. Mo tún kọ́ dùrù títẹ̀. Mo sì fẹ́ràn orin kíkọ àti ijó jíjó nígbà tí ọwọ́ bá dilẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé òtítọ́ Bíbélì wà lọ́kàn mi, síbẹ̀ kò sún mi gbégbèésẹ̀. Nígbà tó wá dọjọ́ kan ní March 1940, àgbàlagbà Ẹlẹ́rìí kan sọ pé kí n ká lọ sí àpéjọ kan nílùú Swindon, tó jẹ́ ìrìn nǹkan bí àádọ́fà [110] kìlómítà. Albert D. Schroeder, tí ń bójú tó iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ló sọ àsọyé fún gbogbo ènìyàn níbẹ̀. Àpéjọ yìí ló yí ìgbésí ayé mi padà.
Ogun Àgbáyé Kejì ṣì ń jà lọ́wọ́. Kí ni mò ń fi ìgbésí ayé mi ṣe ná? Mo pinnu pé màá padà sí Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà nílùú Yeovil. Ọ̀rọ̀ nípa ìjẹ́rìí ojú pópó ni wọ́n ń sọ ní ìpàdé àkọ́kọ́ tí mo lọ. Pẹ̀lú ìwọ̀nba ìmọ̀ tí mo ní, mo yọ̀ǹda ara mi fún iṣẹ́ yìí. Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ fáwọn tó pera wọn lọ́rẹ̀ẹ́ mi. Ńṣe ni wọ́n ń fi mí ṣẹ̀sín bí wọ́n ṣe ń gba ẹ̀gbẹ́ mi kọjá!
A batisí mi ní June 1940, nílùú Bristol. Láàárín oṣù kan, mo fọwọ́ síwèé aṣáájú ọ̀nà déédéé, ìyẹn ajíhìnrere alákòókò kíkún. Ẹ wo bí inú mi ti dùn tó, nígbà tí Joan ẹ̀gbọ́n mi náà fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ rẹ̀ hàn nípa ṣíṣe batisí láìpẹ́ lẹ́yìn náà!
Ṣíṣe Aṣáájú Ọ̀nà Nígbà Ogun
Ọdún kan lẹ́yìn tí ogun náà bẹ̀rẹ̀ ni wọ́n fìwé pè mí pé kí n wá wọṣẹ́ ológun. Níwọ̀n bí mo ti forúkọ sílẹ̀ tẹ́lẹ̀ nílùú Yeovil pé ẹ̀rí ọkàn mi kò ní jẹ́ kí n lọ sógun, ó di dandan kí n lọ jẹ́jọ́ níwájú ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́ kan nílùú Bristol. Èmi àti John Wynn ti jọ ń ṣe aṣáájú ọ̀nà nílùú Cinderford, Gloucestershire àti lẹ́yìn a Lẹ́yìn náà, nígbà ìgbẹ́jọ́ nílé ẹjọ́ kan nílùú Carmarthen, wọ́n ní kí n lọ ṣẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́ta lọ́gbà ẹ̀wọ̀n Swansea, kí n tún san pọ́n-ùn mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n owó ìtanràn—owó ńlá sì nìyẹn láyé ọjọ́un. Lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n dá ẹjọ́ ẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́ta mìíràn fún mi torí pé mi ò san owó ìtanràn ọ̀hún.
náà ní Haverfordwest àti Carmarthen, lágbègbè Wales.Nígbà ìgbẹ́jọ́ ẹlẹ́ẹ̀kẹta, wọ́n bi mí pé: “Ṣé o ò mọ ohun tí Bíbélì sọ ni, pé, ‘Fi ohun ti iṣe ti Kesari fun Kesari’?” Èmi náà fèsì pé: “Mo kúkú mọ̀ bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n èmi náà á fẹ́ parí ẹsẹ yẹn, pé: ‘ati ohun ti iṣe ti Ọlọrun fun Ọlọrun.’ Ìyẹn sì ni mò ń ṣe.” (Mátíù 22:21, Bibeli Mimọ) Ọ̀sẹ̀ mélòó kan lẹ́yìn náà ni mo gba lẹ́tà pé iṣẹ́ ológun kì í ṣe túláàsì fún mi mọ́.
Ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1945 ni wọ́n ní kí n wá di ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì ní London. Ní ìgbà òtútù tó tẹ̀ lé e, Nathan H. Knorr, tó ń bójú tó iṣẹ́ ìwàásù kárí ayé nígbà yẹn, àti Milton G. Henschel, akọ̀wé rẹ̀, wá sí London. Mo wà lára àwọn ọ̀dọ́ arákùnrin mẹ́jọ tí wọ́n pè láti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì wá sí kíláàsì kẹjọ ti ilé ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead, láti wá gba ẹ̀kọ́ nípa iṣẹ́ míṣọ́nnárì.
Àwọn Iṣẹ́ Tá A Yàn fún Mi Gẹ́gẹ́ bí Míṣọ́nnárì
Ní May 23, 1946, a wọ ọkọ̀ òkun tí wọ́n lò nígbà ogun, tí wọ́n ń pè ní Liberty, ní èbúté kékeré àwọn ará Cornish lágbègbè Fowey. Ọ̀gá Àgbà Collins, tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni alábòójútó èbúté náà. Bí a ṣe ṣíkọ̀ ló tẹ aago gan-un. Láìṣẹ̀ṣẹ̀ máa sọ ọ́, tibi-tire lọkàn wa ń rò bí ọkọ̀ wa ṣe ṣí kúrò ní èbúté ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Ẹ̀fúùfù líle hàn wá léèmọ̀ nínú ìrìn àjò tá a fi la Òkun Àtìláńtíìkì kọjá. Àmọ́ a gúnlẹ̀ láyọ̀ sí Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́tàlá gbáko.
Ohun mánigbàgbé ni lílọ sí àpéjọ àgbáyé ọlọ́jọ́ mẹ́jọ náà, Àpéjọ Ìṣàkóso Ọlọ́run ti Àwọn Orílẹ̀-Èdè Aláyọ̀, tá a ṣe nílùú Cleveland, ní Ìpínlẹ̀ Ohio, láti August 4 sí 11, 1946. Ọ̀kẹ́ mẹ́rin [80,000] ló wá, títí kan èèyàn méjì lé lọ́ọ̀ọ́dúnrún [302] tó wá láti orílẹ̀-èdè méjìlélọ́gbọ̀n. Àpéjọpọ̀ yẹn ni wọ́n ti mú ìwé ìròyìn Jí!, b àti ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà “Jẹki Ọlọrun Jẹ Olõtọ” jáde níwájú ogunlọ́gọ̀ tí inú wọn ń dùn ṣìnkìn.
A kẹ́kọ̀ọ́ yege ní ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì ní 1947. Wọ́n rán èmi àti Bill Copson lọ sí ilẹ̀ Íjíbítì. Àmọ́ ká tó lọ, mo ní àǹfààní láti gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ nípa iṣẹ́ ọ́fíìsì lọ́dọ̀ Richard Abrahamson ní Bẹ́tẹ́lì ti Brooklyn. Ìlú Alẹkisáńdíríà la gúnlẹ̀ sí. Kò sì pẹ́ tí ìgbésí ayé Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn ayé fi bá mi lára mu. Àmọ́ ká sòótọ́, èdè Lárúbáwá ṣòroó gbọ́, ìyẹn ló fi jẹ́ pé káàdì ìjẹ́rìí tá a kọ lédè mẹ́rin ni mò ń lò.
Bill Copson wà níbẹ̀ fún ọdún méje. Ṣùgbọ́n àwọn aláṣẹ kò gbà kí n dúró mọ́ lẹ́yìn ọdún àkọ́kọ́, nítorí náà mo ní láti fi orílẹ̀-èdè náà sílẹ̀. Mo ka ọdún tí mo fi ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì yẹn sí ọdún tó lárinrin jù lọ nínú ìgbésí ayé mi. Mo
láǹfààní dídarí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé tó ju ogún lọ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Àwọn kan tó sì kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nígbà yẹn ṣì ń fi ìtara yin Jèhófà títí di báyìí. Nígbà tí mo kúrò ní Íjíbítì, wọ́n ní kí n kọjá sí Kípírọ́sì.Láti Kípírọ́sì, Mo Kọjá Lọ sí Ísírẹ́lì
Mo bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ èdè tuntun, ìyẹn èdè Gíríìkì, mo sì tún ń kọ́ èdè àdúgbò ibẹ̀ láàárín àkókò kan náà. Láìpẹ́ lẹ́yìn tí wọ́n ní kí Anthony Sideris kọjá sí Gíríìsì ni wọ́n fi mí ṣe alábòójútó iṣẹ́ náà ní Kípírọ́sì. Nígbà yẹn, ẹ̀ka iléeṣẹ́ wa ní Kípírọ́sì ló tún ń bójú tó Ísírẹ́lì. Fún ìdí yìí, èmi àtàwọn arákùnrin mìíràn láǹfààní láti bẹ àwọn Ẹlẹ́rìí mélòó kan wò ní Ísírẹ́lì lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan.
Nígbà tí mo kọ́kọ́ lọ sí Ísírẹ́lì, a ṣe àpéjọ kékeré nílé àrójẹ kan nílùú Haifa. Nǹkan bí àádọ́ta tàbí ọgọ́ta èèyàn ló pésẹ̀ síbẹ̀. Nígbà tá a pín kálukú sí ìsọ̀rí èdè tirẹ̀, èdè mẹ́fà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ la fi ṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ náà! Ní àkókò mìíràn, mo pe àwọn ará Jerúsálẹ́mù wá wo sinimá kan táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe, mo sì sọ àsọyé níbẹ̀. Àwọn ìwé ìròyìn èdè Gẹ̀ẹ́sì ròyìn rẹ̀ lọ́nà rere.
Nǹkan bí ọgọ́rùn-ún Ẹlẹ́rìí ló wà ní Kípírọ́sì nígbà tí à ń wí yìí. Wọ́n sì gbọ́dọ̀ jà raburabu láti lè dúró nínú ìgbàgbọ́. Àwọn jàǹdùkú tí àwọn àlùfáà Ìjọ Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Gíríìsì ń kó kiri da àpéjọ wa rú. Ibẹ̀ sì ni wọ́n ti kọ́kọ́ sọ mí lókùúta nígbà tí mò ń jẹ́rìí ní ìgbèríko. Èmi náà wá kọ́ béèyàn ṣe ń di mọ̀jà-mọ̀sá! Lójú àtakò gbígbóná janjan yẹn, ó fún ìgbàgbọ́ wa lókun láti ní míṣọ́nnárì púpọ̀ sí i ní erékùṣù náà. Dennis àti Mavis Matthews, àti Joan Hulley àti Beryl Heywood dé bá mi nílùú Famagusta. Tom àti Mary Goulden àti Nina Constanti, tó jẹ́ ọmọ Kípírọ́sì tí wọ́n bí sí London, sì lọ sílùú Limassol. Àkókò yẹn náà ni wọ́n gbé Bill Copson wá sí Kípírọ́sì. Bert àti Beryl Vaisey sì wá bá a níbẹ̀ lẹ́yìn náà.
Mo Gba Kámú Nígbà Tí Ipò Tuntun Yọjú
Nígbà tí ọdún 1957 ń parí lọ, àìsàn kan kọlù mí tó dá iṣẹ́ míṣọ́nnárì mi dúró. Tẹ̀dùntẹ̀dùn ni mo fi pinnu láti padà sí ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì láti lọ tọ́jú ara mi. Mo bẹ̀rẹ̀ sí ṣe aṣáájú ọ̀nà níbẹ̀ títí di ọdún 1960. Joan ẹ̀gbọ́n mi àti ọkọ rẹ̀ fi inú rere gbà mí sílé. Àmọ́ ìgbà ti yí padà. Ńṣe ni nǹkan túbọ̀ ń le sí i fún Joan. Yàtọ̀ sí títọ́jú ọkọ rẹ̀ àti ọmọbìnrin wọn, ọdún mẹ́tàdínlógún tí mi ò fi sí nílé ló ti fi tìfẹ́tìfẹ́ tọ́jú bàbá wa àti Àǹtí Millie, tí wọ́n ti darúgbó, tí ara wọn ò sì le mọ́. Mo wá rí i kedere pé àkókò tó fún èmi náà láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ àǹtí mi. Ìyẹn ni mo fi dúró ti ẹ̀gbọ́n mi títí àǹtí mi àti bàbá mi fi kú.
Kò sóhun tí ì bá dùn tó kí n fìdí kalẹ̀ sí ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Àmọ́ lẹ́yìn ìsinmi ráńpẹ́, ọkàn mi ní kí n padà sẹ́nu iṣẹ́ tá a yàn fún mi. Àbí owó rẹpẹtẹ kọ́ ni ètò Jèhófà ná sórí ẹ̀kọ́ tí wọ́n kọ́ mi? Nítorí náà, lọ́dún 1972, mo fi owó ara mi wọkọ̀ padà sí Kípírọ́sì láti lọ ṣe aṣáájú ọ̀nà níbẹ̀.
Nathan H. Knorr dé láti wá ṣètò àpéjọpọ̀ kan tá a fẹ́ ṣe lọ́dún tó tẹ̀ lé e. Nígbà tó rí i pé mo padà wá, ó dámọ̀ràn pé kí n di alábòójútó àyíká gbogbo erékùṣù náà. Mo gbádùn àǹfààní yìí fún ọdún mẹ́rin gbáko. Àmọ́ iṣẹ́ tó fakíki ni,
torí ó túmọ̀ sí pé èdè Gíríìkì ni mo gbọ́dọ̀ máa sọ lọ́pọ̀ ìgbà.Àkókò Wàhálà
Èmi àti Paul Andreou, tí í ṣe Ẹlẹ́rìí ará Kípírọ́sì tó ń sọ èdè Gíríìkì, la jọ ń gbélé kan náà ní abúlé Karakoumi, tó wà nítòsí ìlà oòrùn ìlú Kyrenia ní etíkun ìhà àríwá Kípírọ́sì. Ẹ̀ka iléeṣẹ́ Kípírọ́sì wà nílùú Nicosia, tí ń bẹ ní gúúsù àwọn Òkè Kyrenia. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1974, ìlú Nicosia ni mo wà nígbà tí wọ́n dìtẹ̀ gbàjọba lọ́wọ́ Ààrẹ Makarios. Ojú mi ló sì ṣe nígbà tí ààfin rẹ̀ jó kanlẹ̀. Nígbà tí wàhálà náà rọlẹ̀, mo sá wá sílùú Kyrenia, níbi tá a ti ń múra sílẹ̀ de àpéjọ àyíká. Ọjọ́ méjì lẹ́yìn náà ni mo gbọ́ tí bọ́ǹbù àkọ́kọ́ bú gbàù ní èbúté náà, mo sì rí i tójú ọ̀run kún fún ọkọ̀ hẹlikópítà tó ń kó ọmọ ogun bọ̀ láti ilẹ̀ Turkey.
Níwọ̀n bí mo ti jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, àwọn ọmọ ogun Turkey gbé mi wá sí ẹ̀yìn òde ìlú Nicosia, níbi tí òṣìṣẹ́ àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ti fọ̀rọ̀ wá mi lẹ́nu wò, tó sì wá kàn sí ẹ̀ka iléeṣẹ́ wa. Ó wá ku bí mo ṣe máa gba àárín àwọn wáyà tẹlifóònù àti wáyà iná mànàmáná tó kúnlẹ̀ jánganjàngan kọjá, tí màá lè dé àdúgbò tó ti dahoro lódìkejì lọ́hùn-ún láàárín àwọn ọmọ ogun ìhà méjèèjì. Ẹ wo bí inú mi ti dùn tó pé wáyà ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ àárín èmi àti Jèhófà Ọlọ́run kò ṣeé já! Àdúrà ló mẹ́sẹ̀ mi dúró lákòókò yìí tí mo fojú winá ìrírí tó burú jáì nínú ìgbésí ayé mi.
Mi ò ní nǹkan kan mọ́. Ṣùgbọ́n inú mi dùn pé mo rí ààbò ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ wa. Kò pẹ́ tí wàhálà yẹn fi rọlẹ̀ ṣá. Kò gba àwọn ọmọ ogun náà ní ọjọ́ púpọ̀ láti gba ìdámẹ́ta ìhà àríwá erékùṣù náà. A ní láti sá fi Bẹ́tẹ́lì sílẹ̀. A ṣí lọ sílùú Limassol. Inú mi dùn láti ṣiṣẹ́ níbẹ̀ pẹ̀lú ìgbìmọ̀ kan tá a dá sílẹ̀ láti bójú tó ọ̀ọ́dúnrún àwọn ará tí rògbòdìyàn náà sọ di ẹdun arinlẹ̀, tí ọ̀pọ̀ nínú wọ́n ti pàdánù ilé wọn.
Wọ́n Tún Yan Àwọn Iṣẹ́ Mìíràn fún Mi
Ní January 1981, Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso sọ pé kí n lọ sí Gíríìsì láti lọ di ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì nílùú Áténì. Àmọ́ nígbà tí ọdún yẹn fi máa parí, mo tún ti padà sí Kípírọ́sì níbi tí wọ́n ti fi mí ṣe akóṣẹ́jọ Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka. Andreas Kontoyiorgis àti Maro ìyàwó rẹ̀, tí wọ́n jẹ́ ará Kípírọ́sì tí wọ́n rán wá láti ìlú London, jẹ́ “àrànṣe afúnnilókun” fún mi.—Kólósè 4:11.
Nígbà tí Theodore Jaracz parí ìbẹ̀wò ìpínlẹ̀ ńlá tó wá ṣe ní 1984, mo rí lẹ́tà kan gbà látọ̀dọ̀ Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso tó kàn sọ pé: “Nígbà tí Arákùnrin Jaracz bá parí ìbẹ̀wò rẹ̀, a óò fẹ́ kí o tẹ̀ lé e lọ sí Gíríìsì.” Wọn ò sọ ìdí. Ṣùgbọ́n nígbà tá a dé Gíríìsì, wọ́n ka lẹ́tà míì látọ̀dọ̀ Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso sétí Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka níbẹ̀, pé a ti fi mí ṣe akóṣẹ́jọ Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka lórílẹ̀-èdè yẹn.
Ní àkókò tí à ń sọ yìí, ńṣe ni ìpẹ̀yìndà ń rú bí egbìnrìn ọ̀tẹ̀ ní Gíríìsì. Wọ́n tún ń fẹ̀sùn kàn wá lóríṣiríṣi pé à ń mú kí àwọn èèyàn pa ẹ̀sìn wọn dà lọ́nà tí kò bófin mu. Ojoojúmọ́ ni wọ́n ń mú àwọn èèyàn Jèhófà, tí wọ́n ń wọ́ wọn lọ c
sílé ẹjọ́. Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá ló jẹ́ láti mọ àwọn ará tó di ìwà títọ́ wọn mú ní àkókò hílàhílo yẹn! Ẹjọ́ àwọn kan lára wọn tilẹ̀ déwájú Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù, pẹ̀lú ìyọrísí kíkàmàmà tó tún jẹ́ kí iṣẹ́ ìwàásù tẹ̀ síwájú ní Gíríìsì.Nígbà tí mò ń sìn ní Gíríìsì, mo lọ sí àwọn àpéjọpọ̀ mánigbàgbé kan nílùú Áténì, Tẹsalóníkà àti ní àwọn erékùṣù Ródésì àti Kírétè. Ọdún mẹ́rin yẹn jẹ́ ọdún aláyọ̀, ọdún tó mérè wá ni. Ṣùgbọ́n ìyípadà mìíràn tún ń bọ̀ lọ́nà—màá tún padà sí Kípírọ́sì ní 1988.
Mo Tún Bára Mi Ní Kípírọ́sì, Kí N Tó Wá Padà sí Gíríìsì
Lẹ́yìn tí mo kúrò ní Kípírọ́sì, àwọn ará ra ilé tuntun fún ẹ̀ka iléeṣẹ́ nílùú Nissou, tí kò jìnnà sílùú Nicosia. Arákùnrin Carey Barber, láti orílé iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Brooklyn ló wá sọ àsọyé tá a fi yà á sí mímọ́. Kò fi bẹ́ẹ̀ sí wàhálà ní erékùṣù náà mọ́ báyìí. Inú mi sì dùn láti padà wá. Ṣùgbọ́n mi ò ní dúró pẹ́ níbẹ̀.
Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti fọwọ́ sí i pé kí wọ́n kọ́ Bẹ́tẹ́lì tuntun sí Gíríìsì, síbì kan tí kò jìnnà síhà àríwá ìlú Áténì. Níwọ̀n bí mo ti gbọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì àti èdè Gíríìkì, wọ́n ní kí n padà síbi ìkọ́lé tuntun náà ní 1990, kí n máa ṣe ògbufọ̀ fún àwọn tó ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀, ìyẹn ìdílé kọ́lékọ́lé láti ilẹ̀ òkèèrè. Mo ṣì rántí bí mo ṣe máa ń fi tayọ̀tayọ̀ dé ibi iṣẹ́ ìkọ́lé náà láago mẹ́fà àárọ̀ nígbà ẹ̀ẹ̀rùn, tí màá máa kí ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ará káàbọ̀, ìyẹn àwọn ará tó jẹ́ Gíríìkì tí wọ́n yọ̀ǹda ara wọn láti wá ran ìdílé tó ń ṣiṣẹ́ ìkọ́lé náà lọ́wọ́! Mi ò lè gbàgbé ayọ̀ àti ìtara wọn láé.
Àwọn àlùfáà Ìjọ Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ilẹ̀ Gíríìkì àtàwọn ìsọ̀ǹgbè wọn gbìyànjú láti já wọ ibi ìkọ́lé náà, kí wọ́n sì dáṣẹ́ wa dúró. Ṣùgbọ́n Jèhófà gbọ́ àdúrà wa, ó sì dáàbò bò wá. Mo wà níbi ìkọ́lé náà títí wọ́n fi ya ibùgbé Bẹ́tẹ́lì tuntun náà sí mímọ́ ní April 13, 1991.
Mo Dúró Ti Ẹ̀gbọ́n Mi Ọ̀wọ́n
Lọ́dún tó tẹ̀ lé e, mo padà wá lo àkókò ìsinmi nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Ọ̀dọ̀ ẹ̀gbọ́n mi àti ọkọ rẹ̀ ni mo dé sí. Ó bani nínú jẹ́ pé nígbà tí mo wà níbẹ̀, àrùn ọkàn kọlu ọkọ ẹ̀gbọ́n mi lẹ́ẹ̀mejì, ó sì kú. Igi-lẹ́yìn-ọgbà ni Joan jẹ́ fún mi lẹ́nu iṣẹ́ míṣọ́nnárì mi. Bóyá ló lè jẹ́ kí ọ̀sẹ̀ kan kọjá láìkọ lẹ́tà ìṣírí sí mi. Ìbùkún ńlá mà ni irú lẹ́tà bẹ́ẹ̀ máa ń jẹ́ fún míṣọ́nnárì o! Ó ti wá di opó báyìí. Ara rẹ̀ ò le mọ́. Ó sì ń fẹ́ alábàárò. Kí ni kí n ṣe o?
Ọmọ Joan, ìyẹn Thelma àti ọkọ rẹ̀ ń tọ́jú opó mìíràn tó jẹ́ olóòótọ́ nínú ìjọ wọn. Àìsàn kò-gbóògùn ló ń ṣe opó yìí. Ẹbí wa sì tún ni. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé lẹ́yìn ọ̀pọ̀ àdúrà, mo pinnu pé màá dúró kí n lè ṣèrànwọ́ láti tọ́jú Joan. Kò rọrùn láti mọ́kàn kúrò lórí iṣẹ́ tí mo fi sílẹ̀. Ṣùgbọ́n mo ṣì ní àǹfààní láti sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà nínú ìjọ Pen Mill, ìyẹn ọ̀kan lára ìjọ méjì tó wà nílùú Yeovil.
Mò ń gbúròó àwọn ará tá a jọ sìn nígbà tí mo wà nílẹ̀ òkèèrè déédéé, wọ́n ń fóònù, wọ́n ń kọ lẹ́tà, mo sì mọrírì èyí gan-an. Bí mo bá sọ pé mo fẹ́ padà sí Gíríìsì tàbí Kípírọ́sì pẹ́nrẹ́n, mo mọ̀ pé kíá làwọn ará á fowó ọkọ̀ ránṣẹ́. Ṣùgbọ́n mo ti di ẹni ọgọ́rin ọdún báyìí, ojú ti di bàìbàì, ara sì ti di hẹ́gẹhẹ̀gẹ. Àìlèsá-sókè-sódò bíi ti tẹ́lẹ̀ ń múni rẹ̀wẹ̀sì. Ṣùgbọ́n àwọn ọdún tí mo fi sìn ní Bẹ́tẹ́lì ti jẹ́ kí àwọn àṣà kan tó wúlò fún mi gan-an báyìí mọ́ mi lára. Bí àpẹẹrẹ, mo máa ń ka ẹ̀kọ́ ojoojúmọ́ déédéé kí n tó jẹun àárọ̀. Mo tún kọ́ láti máa gbé nírẹ̀ẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, kí n sì nífẹ̀ẹ́ wọn—ìwọ̀nyí ṣe pàtàkì fún àṣeyọrí nínú iṣẹ́ ìsìn míṣọ́nnárì.
Bí mo ṣe ń wẹ̀yìn wo ohun tó lé ní ọgọ́ta ọdún alárinrin tí mo fi yin Jèhófà, mo mọ̀ pé iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún ni ààbò gíga jù lọ àti ilé ẹ̀kọ́ tó dára jù lọ. Mo gbà tọkàntọkàn pé òótọ́ lọ̀rọ̀ tí Dáfídì sọ fún Jèhófà, pé: “Ìwọ ti jẹ́ ibi gíga ààbò fún mi àti ibi ìsásí ní ọjọ́ wàhálà mi.”—Sáàmù 59:16.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ìtàn ìgbésí ayé John Wynn, tó pè ní “Mo Dúpẹ́ Mo Tọ́pẹ́ Dá,” wà nínú Ilé Ìṣọ́ September 1, 1997, ojú ìwé 25 sí 28.
b Ìwé ìròyìn yìí là ń pè ní Consolation tẹ́lẹ̀.
c Wo Ilé Ìṣọ́, December 1, 1998, ojú ìwé 20 sí 21, àti September 1, 1993, ojú ìwé 27 sí 31; Jí!, January 8, 1998, ojú ìwé 21 sí 22, àti March 22, 1997, ojú ìwé 14 sí 15.
[Àwọn àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 24]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
GÍRÍÌSÌ
Áténì
KÍPÍRỌ́SÌ
Nicosia
Kyrenia
Famagusta
Limassol
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Màmá mi rèé lọ́dún 1915
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
Àwọn tá a jọ wà ní kíláàsì kẹjọ ti ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì rèé lórí òrùlé Bẹ́tẹ́lì ní Brooklyn, lọ́dún 1946 (èmi lẹni kẹrin láti apá òsì)
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Èmi àti Àǹtí Millie nígbà tí mo kọ́kọ́ padà wá sílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì