Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Ìpàdé Tí Ń Runi Sókè sí Ìfẹ́ àti sí Iṣẹ́ Àtàtà

Àwọn Ìpàdé Tí Ń Runi Sókè sí Ìfẹ́ àti sí Iṣẹ́ Àtàtà

“Ẹ Wá Sọ́dọ̀ Mi . . . Èmi Yóò Sì Tù Yín Lára”

Àwọn Ìpàdé Tí Ń Runi Sókè sí Ìfẹ́ àti sí Iṣẹ́ Àtàtà

LÁTI Toronto sí Tokyo, láti Moscow sí Montevideo—ó máa ń tó ìgbà bíi mélòó kan láàárín ọ̀sẹ̀ tí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àtàwọn ọ̀rẹ́ wọn máa ń wọ́ lọ síbi ìjọsìn wọn. Àwọn olórí ìdílé tó ti rẹ̀ lẹ́yìn iṣẹ́ àṣekára tí wọ́n ń ṣe látòwúrọ̀ ṣúlẹ̀ wà lára wọn; bẹ́ẹ̀ náà làwọn aya àti ìyá tí wọ́n jẹ́ òṣìṣẹ́ aláápọn, tí wọ́n ń gbé àwọn ọmọ kéékèèké dání wá; àwọn ọ̀dọ́ tó ń ta kébé, tí wọ́n ti wà níléèwé látàárọ̀; àwọn arúgbó tí kò lè rìn púpọ̀ mọ́ nítorí ìrora; àwọn opó àtàwọn ọmọ òrukàn tó nígboyà; títí kan àwọn tó sorí kọ́, tí wọ́n ń wá ìtùnú.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wọ̀nyí ń lo ọ̀pọ̀ ohun ìrìnnà láti débẹ̀—bẹ̀rẹ̀ látorí ọkọ̀ ojú irin dorí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, látorí ọkọ̀ ojú irin abẹ́lẹ̀ dórí àwọn ọkọ̀ akẹ́rù. Àwọn kan ní láti sọdá àwọn odò tó kún fún ọ̀nì, àwọn mìíràn sì ní láti fara da sún kẹẹrẹ fà kẹẹrẹ ọkọ̀ nínú àwọn ìlú ńlá. Kí nìdí táwọn èèyàn wọ̀nyí fi ń ṣe gbogbo akitiyan tó pọ̀ tó báyìí?

Ìdí pàtàkì náà ni pé lílọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni àti sísọ̀rọ̀ níbẹ̀ jẹ́ ọ̀nà pàtàkì kan láti jọ́sìn Jèhófà Ọlọ́run. (Hébérù 13:15) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tún mẹ́nu kan ìdí mìíràn nígbà tó kọ̀wé pé: “Ẹ sì jẹ́ kí a gba ti ara wa rò lẹ́nì kìíní-kejì láti ru ara wa sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà, kí a má máa kọ ìpéjọpọ̀ ara wa sílẹ̀, . . . ṣùgbọ́n kí a máa fún ara wa ní ìṣírí lẹ́nì kìíní-kejì, pàápàá jù lọ bí ẹ ti rí i pé ọjọ́ náà ń sún mọ́lé.” (Hébérù 10:24, 25) Ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù yìí fi hàn pé ó fara mọ́ ohun tí Dáfídì onísáàmù náà wí, ẹni tó kọrin pé: “Mo yọ̀ nígbà tí wọ́n ń wí fún mi pé: ‘Jẹ́ kí a lọ sí ilé Jèhófà.’”—Sáàmù 122:1.

Èé ṣe táwọn Kristẹni fi máa ń yọ̀ pé ó ṣeé ṣe fún àwọn láti lọ sí àwọn ìpàdé? Nítorí pé àwọn tó wà níbẹ̀ kì í ṣe òǹwòran lásán. Dípò ìyẹn, ìpàdé náà máa ń fún wọn láǹfààní láti mọ ara wọn lẹ́nì kìíní kejì. Ní pàtàkì jù lọ, àwọn àpéjọ wọ̀nyí máa ń jẹ́ kéèyàn láǹfààní láti fúnni, kì í ṣe láti gbà nìkan, ó tún máa ń jẹ́ ká ru ara wa sókè láti fi ìfẹ́ hàn, ká sì kópa nínú àwọn iṣẹ́ àtàtà. Èyí ló máa ń jẹ́ káwọn ìpàdé dáni lára yá gágá. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, àwọn ìpàdé Kristẹni tún jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tí Jésù gbà ń mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ pé: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, . . . èmi yóò sì tù yín lára.”—Mátíù 11:28.

Ibi Tá A Ti Lè Rí Ìtùnú àti Aájò

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ìdí pàtàkì láti wo àwọn ìpàdé wọn gẹ́gẹ́ bí ibi tí wọ́n ti ń rí ìtura. Lọ́nà kan, àwọn ìpàdé ni “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ti ń fúnni ní oúnjẹ tẹ̀mí ní àkókò tó bẹ́tọ̀ọ́ mu. (Mátíù 24:45) Àwọn ìpàdé tún ń kó ipa pàtàkì nínú sísọ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà di ọ̀jáfáfá àti onítara nínú iṣẹ́ kíkọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Yàtọ̀ síyẹn, Gbọ̀ngàn Ìjọba lèèyàn ti lè rí àwọn ọ̀rẹ́ tó nífẹ̀ẹ́, tí wọ́n ń ṣaájò ẹni, tí wọ́n bìkítà, àní tí wọ́n múra tán láti ṣèrànwọ́ àti láti tu àwọn ẹlòmíràn nínú láwọn àkókò ìṣòro.—2 Kọ́ríńtì 7:5-7.

Ohun tí Phillis nírìírí rẹ̀ gan-an nìyí, ìyẹn opó kan tí ọkọ rẹ̀ kú nígbà tọ́mọ rẹ̀ kan wà lọ́mọ ọdún márùn-ún tí ìkejì sì wà lọ́mọ ọdún mẹ́jọ. Nígbà tó ń ṣàpèjúwe ipa tí ń tuni lára tí àwọn ìpàdé Kristẹni ní lórí òun àtàwọn ọmọ òun, ó sọ pé: “Ìtùnú ló jẹ́ láti lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba, nítorí pé àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ ẹni sábà máa ń fi ìfẹ́ wọn àti aájò wọn hàn nípa dídìmọ́ni, bíbáni fèròwérò nínú Ìwé Mímọ́, tàbí dídinilọ́wọ́ mú gírígírí. Ó jẹ́ ibi tó máa ń wù mí lọ ní gbogbo ìgbà.”—1 Tẹsalóníkà 5:14.

Lẹ́yìn tí wọ́n ṣe iṣẹ́ abẹ tí ó le fún Marie tán, dókítà rẹ̀ sọ pé á tó ọ̀sẹ̀ mẹ́fà ó kéré tán kí ara rẹ̀ tó le. Marie kò lè lọ sípàdé láwọn ọ̀sẹ̀ tí ara rẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí kọ́fẹ. Dókítà rẹ̀ ṣàkíyèsí pé kò ṣàwàdà bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́. Nígbà tí dókítà náà rí i pé Marie kì í lọ sípàdé, ó ní kó gbìyànjú láti máa lọ. Marie fèsì pé ọkọ òun, táwọn ò jọ sí nínú ẹ̀sìn kan náà kò ní jẹ́ kí òun máa lọ sípàdé nítorí àìlera òun. Bí dókítà náà ṣe kọ̀wé nìyẹn, tó “pa á láṣẹ” pé kí Marie rí i dájú pé òun ń lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba kí ó lè rí ìṣírí àti àwọn èèyàn tá a máa gbé e ró. Marie parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Lẹ́yìn tí mo lọ sí ìpàdé kan, ara tù mí gan-an. Mo bẹ̀rẹ̀ sí jẹun, mo sùn dáadáa lóru ọjọ́ yẹn, mi ò fi bẹ́ẹ̀ lo egbòogi apàrora mọ́, mo sì tún dẹni tó ń rẹ́rìn-ín músẹ́!”—Òwe 16:24.

Àwọn ará ìta pàápàá ń kíyè sí ẹ̀mí ìfẹ́ tó gbilẹ̀ láwọn ìpàdé Kristẹni. Akẹ́kọ̀ọ́ kan yàn láti fara balẹ̀ wo ìṣe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kó lè rí nǹkan kọ sínú ìwé tó fẹ́ kọ nípa àjọṣe ẹ̀dá. Nípa bí ipò nǹkan ṣe rí láwọn ìpàdé, ó kọ ọ́ sínú ìwé rẹ̀ pé: “Bí wọ́n ṣe kí mi tọ̀yàyàtọ̀yàyà . . . wú mi lórí gan-an ni. . . . Ìwà bí ọ̀rẹ́ àárín àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ ànímọ́ kan tí kò fara sin rárá, òun ni mo sì rí i pé ó jẹ́ ànímọ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ láàárín àwùjọ náà.”—1 Kọ́ríńtì 14:25.

Nínú ayé tó kún fún wàhálà yìí, ìjọ Kristẹni jẹ́ ibi ààbò nípa tẹ̀mí. Ó jẹ́ ibi tí àlàáfíà àti ìfẹ́ ti gbilẹ̀. Bí o bá ń wá sí àwọn ìpàdé, ìwọ fúnra rẹ yóò rí i bí ọ̀rọ̀ onísáàmù náà ṣe jẹ́ òótọ́ tó, èyí tó sọ pé: “Wò ó! Ó mà dára o, ó mà dùn o, pé kí àwọn ará máa gbé pa pọ̀ ní ìṣọ̀kan!”—Sáàmù 133:1.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

KÍKÚNJÚ ÀÌNÍ PÀTÀKÌ KAN

Báwo làwọn tí kò gbọ́rọ̀ ṣe lè jàǹfààní nínú àwọn ìpàdé Kristẹni? Káàkiri àgbáyé làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń dá àwọn ìjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè àwọn adití sílẹ̀. Láàárín ọdún mẹ́tàlá sí àkókò tá a wà yìí, wọ́n ti dá ìjọ mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n àti àwọn àwùjọ mẹ́tàlélógójì tí wọ́n ti ń sọ èdè adití sílẹ̀ ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Wọ́n sì ti ní àwọn ìjọ bí ogóje [140] tí wọ́n ti ń sọ èdè adití báyìí láwọn orílẹ̀-èdè tó lé ní ogójì. Wọ́n ti ṣe àwọn ìtẹ̀jáde Kristẹni sínú fídíò ní àwọn èdè mẹ́tàlá tó jẹ́ ti àwọn adití.

Ìjọ Kristẹni fáwọn adití láǹfààní láti yin Jèhófà. Odile, tó ti fìgbà kan jẹ́ ẹlẹ́sìn Kátólíìkì nílẹ̀ Faransé, tó máa ń ní ìdààmú ọkàn lọ́pọ̀ ìgbà, tó sì ti ń ronú àtipa ara rẹ̀, dúpẹ́ gidigidi fún ẹ̀kọ́ Bíbélì tó rí gbà láwọn ìpàdé Kristẹni. Obìnrin yìí sọ pé: “Ara mi wá le, mo sì tún padà ní ayọ̀ nínú ìgbésí ayé mi. Àmọ́ lékè gbogbo rẹ̀, mo rí òtítọ́. Ìgbésí ayé mi ti wá ní ète nínú báyìí.”