Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ Ó Yẹ—Káwọn Kristẹni Máa Kun Òkú Lọ́ṣẹ?

Ǹjẹ́ Ó Yẹ—Káwọn Kristẹni Máa Kun Òkú Lọ́ṣẹ?

Ǹjẹ́ Ó Yẹ—Káwọn Kristẹni Máa Kun Òkú Lọ́ṣẹ?

Nígbà tó kù díẹ̀ kí Jékọ́bù, baba ńlá olóòótọ́ nì kú, ó bẹ ẹ̀bẹ̀ ìkẹyìn yìí pé: “Ẹ sin mí pẹ̀lú àwọn baba mi sínú hòrò tí ó wà nínú pápá Éfúrónì ọmọ Hétì, sínú hòrò tí ó wà nínú pápá Mákípẹ́là tí ó wà ní iwájú Mámúrè ní ilẹ̀ Kénáánì.”—Jẹ́nẹ́sísì 49:29-31.

JÓSẸ́FÙ pa ọ̀rọ̀ baba rẹ̀ mọ́ nípa lílo àṣà tó gbilẹ̀ nílẹ̀ Íjíbítì lákòókò yẹn. Ó pàṣẹ fún “àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àwọn oníṣègùn, pé kí wọ́n kun baba òun lọ́ṣẹ.” Gẹ́gẹ́ bí ìtàn tó wà nínú Jẹ́nẹ́sísì orí àádọ́ta ti sọ, ogójì ọjọ́ gbáko làwọn oníṣègùn náà fi kun òkú náà lọ́ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí àṣà wọn. Kíkùn tí wọ́n kun Jékọ́bù lọ́ṣẹ mú kí ó ṣeé ṣe fún àwọn ará agboolé ńlá àtàwọn èèyàn jàǹkànjàǹkàn ará Íjíbítì tó rọra rin ìrìn àjò nǹkan bí irínwó [400] kìlómítà láti gbé òkú Jékọ́bù lọ sí Hébúrónì fún sísin.—Jẹ́nẹ́sísì 50:1-14.

Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe ká rí òkú Jékọ́bù tí wọ́n kùn lọ́ṣẹ yìí lọ́jọ́ kan? Kò dà bíi pé ó lè ṣeé ṣe. Ilẹ̀ Ísírẹ́lì jẹ́ àgbègbè tó lómi dáadáa, èyí tí kò jẹ́ kí àwọn ohun tí wọ́n lè walẹ̀ rí níbẹ̀ fi bẹ́ẹ̀ pọ̀. (Ẹ́kísódù 3:8) Àwọn irin ìgbàanì àtàwọn ohun tí wọ́n fi òkúta ṣe pọ̀ rẹpẹtẹ, àmọ́ èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn ohun tó jẹ́ ẹlẹgẹ́, bí aṣọ, awọ, àtàwọn òkú tí wọ́n kùn lọ́ṣẹ ló ti jẹrà nítorí ọ̀rinrin àti ojú ọjọ́.

Kí ni kíkun òkú lọ́ṣẹ túmọ̀ sí? Kí nìdí tí wọ́n fi ń ṣe é? Ǹjẹ́ ó yẹ káwọn Kristẹni máa ṣe é?

Ibo Ni Àṣà Náà Ti Bẹ̀rẹ̀?

Láìfọ̀rọ̀gùn, kíkun òkú lọ́ṣẹ jẹ́ títọ́jú òkú ènìyàn tàbí ti ẹranko lọ́nà tí kò fi ní tètè bà jẹ́. Ó dà bíi pé àwọn òpìtàn gbà pé ilẹ̀ Íjíbítì ni kíkun òkú lọ́ṣẹ ti bẹ̀rẹ̀. Àmọ́ àwọn ará Ásíríà, àwọn ará Páṣíà, àtàwọn Síkítíánì ìgbàanì pẹ̀lú máa ń ṣe bẹ́ẹ̀. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé rírí tí wọ́n máa ń rí àwọn òkú tí wọ́n ti sin sínú yanrìn aṣálẹ̀, láìjẹ́ pé wọ́n jẹrà ló fà á tí wọ́n fi nífẹ̀ẹ́ sí kíkun òkú lọ́ṣẹ, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gbìyànjú ẹ̀ wò. Ó ní láti jẹ́ pé irú ìsìnkú bẹ́ẹ̀ kì í jẹ́ kí ọ̀rinrin àti afẹ́fẹ́ dé ibi tí òkú ọ̀hún wà, òkú náà kò sì ní tipa bẹ́ẹ̀ tètè jẹrà. Àbá àwọn kan ni pé kíkun òkú lọ́ṣẹ bẹ̀rẹ̀ nígbà tí wọ́n rí i pé àwọn òkú kan kò jẹrà nígbà tí wọ́n gbé wọn sínú èròjà natron (sodium carbonate), ìyẹn àlubà kan tó wọ́pọ̀ nílẹ̀ Íjíbítì àti láwọn àgbègbè rẹ̀.

Ète ẹni tó ń kun òkú lọ́ṣẹ ni láti dá iṣẹ́ táwọn kòkòrò tíntìntín ń ṣe dúró, èyí tó máa ń bẹ̀rẹ̀ láàárín wákàtí díẹ̀ lẹ́yìn téèyàn bá ti kú, tó sì máa ń jẹ́ kí òkú bẹ̀rẹ̀ sí jẹrà. Bí ó bá ṣeé ṣe láti dá ohun táwọn kòkòrò wọ̀nyí ń ṣe dúró, jíjẹrà á dáwọ́ dúró tàbí ó kéré tán, òkú náà kò ní tètè jẹrà. Ohun mẹ́ta ló wà fún: pípa òkú náà mọ́ bí ẹni tó ṣì wà láàyè, dídí jíjẹrà lọ́wọ́, àti títọ́jú òkú náà lọ́nà táwọn kòkòrò kò fi ní lè bà á jẹ́.

Ọ̀ràn ẹ̀sìn ni olórí ìdí táwọn ará Íjíbítì fi ń kun òkú lọ́ṣẹ. Èrò wọn ni pé lẹ́yìn téèyàn bá kú, á ṣì fẹ́ máa ní àjọṣe pẹ̀lú àwọn ará ayé. Wọ́n gbà gbọ́ pé wọ́n á máa lo ẹran ara wọn títí ayérayé ni, yóò sì padà wà láàyè tó bá yá. Bí kíkun òkú lọ́ṣẹ ṣe wọ́pọ̀ tó nígbà yẹn, a ò tíì rí àkọsílẹ̀ kankan títí di bá a ṣe ń wí yìí nípa bí àwọn ará Íjíbítì ṣe máa ń ṣe é. Àkọsílẹ̀ tó ṣì dára jù lọ ni èyí tí Herodotus, òpìtàn Gíríìkì nì, kọ ní ọ̀rúndún kárùn-ún ṣááju Sànmánì Tiwa. Àmọ́, ìròyìn tá a gbọ́ ni pé ìgbìyànjú láti ṣe é lọ́nà tí Herodotus gbà kọ ọ́ sílẹ̀ kò fi bẹ́ẹ̀ kẹ́sẹ járí.

Ǹjẹ́ Ó Yẹ Káwọn Kristẹni Máa Ṣe É?

Àwọn tí ìsìn wọn yàtọ̀ sí ti Jékọ́bù ló kùn ún lọ́ṣẹ. Síbẹ̀, kò sóhun tó lè mú ká ronú pé nígbà tí Jósẹ́fù gbé òkú baba rẹ̀ fún àwọn oníṣègùn, á sọ fún wọn pé kí wọ́n ṣe àdúrà àti ààtò tí wọ́n sábà máa ń ṣe nígbà tí wọ́n bá ń kun òkú lọ́ṣẹ ní Íjíbítì láyé ìgbà yẹn. Àwọn ọkùnrin ìgbàgbọ́ ni Jékọ́bù àti Jósẹ́fù. (Hébérù 11:21, 22) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe Jèhófà ló ní kí wọ́n kun òkú Jékọ́bù lọ́ṣẹ, síbẹ̀ Ìwé Mímọ́ kò bẹnu àtẹ́ lu àṣà yìí. Kíkùn tí wọ́n kun òkú Jékọ́bù lọ́ṣẹ kò wá túmọ̀ sí pé ohun tí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tàbí ìjọ Kristẹni gbọ́dọ̀ máa ṣe nìyẹn. Ká sọ tòótọ́, kò sí ìtọ́ni pàtó kankan lórí kókó yìí nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Lẹ́yìn tí wọ́n kun Jósẹ́fù alára lọ́ṣẹ ní Íjíbítì, kò tún síbòmíràn tí Ìwé Mímọ́ ti mẹ́nu kan àṣà yẹn mọ́.—Jẹ́nẹ́sísì 50:26.

Àwọn òkú tó ti jẹrà tí wọ́n rí láwọn ibojì ní Palẹ́sìnì fi hàn pé kì í ṣe àṣà àwọn Hébérù láti máa kun òkú lọ́ṣẹ, ó kéré tán wọn kò ṣe é lọ́nà tó fi máa wà bẹ́ẹ̀ fún àkókò gígùn. Fún àpẹẹrẹ, wọn ò kun òkú Lásárù lọ́ṣẹ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n fi aṣọ yí i lára, síbẹ̀ ó ṣe àwọn tó wà níbẹ̀ bákan nígbà tí wọ́n fẹ́ yí òkúta tí wọ́n fi bo ibojì rẹ̀ kúrò. Nítorí pé Lásárù ti kú ní ọjọ́ mẹ́rin ṣáájú àkókò yẹn, arábìnrin rẹ̀ mọ̀ pé àwọn máa gbọ́ òórùn nígbà tí wọ́n bá ṣí ibojì náà.—Jòhánù 11:38-44.

Ǹjẹ́ wọ́n kun Jésù Kristi lọ́ṣẹ? Àwọn ìwé Ìhìn Rere kò sọ bẹ́ẹ̀. Ní àkókò yẹn, àṣà àwọn Júù ni pé kí wọ́n fi àwọn èròjà atasánsán àti òróró lọ́fínńdà múra òkú sílẹ̀ kí wọ́n tó sin ín. Bí àpẹẹrẹ, kí wọ́n lè múra òkú Jésù sílẹ̀, Nikodémù mú èròjà atasánsán tó pọ̀ gan-an wá fún ète yìí. (Jòhánù 19:38-42) Kí ló dé tí èròjà atasánsán náà fi pọ̀ tó bẹ́ẹ̀? Ó ní láti jẹ́ ìfẹ́ àti ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ tó ní fún Jésù ló sún un hu irú ìwà ọ̀làwọ́ bẹ́ẹ̀. Kò yẹ ká parí èrò sí pé kí òkú náà má bàa jẹrà ló jẹ́ kí wọ́n lo àwọn èròjà atasánsán tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀.

Ṣé ó yẹ kí Kristẹni lòdì sí àṣà kíkun òkú lọ́ṣẹ? Ká sọ tòótọ́, kíkun òkú lọ́ṣẹ wulẹ̀ ń fawọ́ aago ohun tó gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn ni. Inú ekuru la ti wá, inú ekuru la ó sì padà sí nígbà tá a bá kú. (Jẹ́nẹ́sísì 3:19) Àmọ́ báwo ló ṣe yẹ kí àkókò tí ẹni náà kú jìnnà tó sí àkókò ìsìnkú rẹ̀? Bó bá jẹ́ pé àwọn mẹ́ńbà ìdílé àtàwọn ọ̀rẹ́ ń bọ̀ láti ọ̀nà jíjìn, tí wọ́n á sì fẹ́ rí òkú náà, kò sí ṣíṣe, kò sí àìṣe, a gbọ́dọ̀ kun òkú náà lọ́ṣẹ dé ìwọ̀n kan.

Nítorí náà, lójú ohun tí Ìwé Mímọ́ wí, kó sídìí fún dída ara wa láàmú tí àṣà àdúgbò bá béèrè pé kí a kun òkú lọ́ṣẹ tàbí tí àwọn mẹ́ńbà ìdílé bá fẹ́ bẹ́ẹ̀. Àwọn òkú “kò mọ nǹkan kan rárá.” (Oníwàásù 9:5) Bí wọ́n bá wà nínú ìrántí Ọlọ́run, a óò jí wọn dìde sínú ìyè nínú ayé tuntun tó ṣèlérí.—Jóòbù 14:13-15; Ìṣe 24:15; 2 Pétérù 3:13.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

KÍKUN ÒKÚ LỌ́ṢẸ—LÁYÉ ÀTIJỌ́ ÀTI LÁYÉ ÌSINSÌNYÍ

Ní Íjíbítì ìgbàanì, ọ̀nà tí wọ́n máa gbà kun òkú lọ́ṣẹ sinmi lórí bí ìdílé kan bá ṣe rí já jẹ tó. Ó ṣeé ṣe kí àwọn ìdílé tó jẹ́ olówó yan kíkun òkú lọ́ṣẹ lọ́nà tó wà nísàlẹ̀ yìí:

Wọn ó fi ohun èlò onírin kan fa ọpọlọ òkú náà jáde gba ti ihò imú rẹ̀. Lẹ́yìn náà, wọ́n á da àwọn oògùn kan sí i lágbárí. Ìgbésẹ̀ tó tẹ̀ lé e ni pé, wọ́n a kó gbogbo tìfun-tẹ̀dọ̀ rẹ̀ jáde, á wá ku ọkàn àti kíndìnrín rẹ̀ nìkan. Kí wọ́n lè dé inú ikùn rẹ̀, wọ́n ní láti gé ibì kan lára rẹ̀, àmọ́ wọ́n ka èyí sí ẹ̀ṣẹ̀. Kí wọ́n lè yanjú ìṣòro títakókó yìí, àwọn tó ń kun òkú lọ́ṣẹ ní Íjíbítì máa ń wá ẹnì kan tí ń gé nǹkan láti wá gé ibi tí wọ́n fẹ́ gé náà. Bó bá sì ti ń parí iṣẹ́ yìí ló máa fẹsẹ̀ fẹ, nítorí pé èpè àti sísọni lókùúta ni ìyà tí wọ́n fi ń jẹ ẹni tó ń ṣe iṣẹ́ tí wọ́n kà sí ìwà ọ̀daràn yìí.

Lẹ́yìn tí wọ́n bá ti kó gbogbo ohun tó wà níkùn òkú náà jáde tán, wọ́n á wá fọ̀ ọ́ mọ́ tónítóní. Herodotus, òpìtàn nì kọ̀wé pé: “Wọ́n á kó ògidì tùràrí, àti èèpo igi kaṣíà tí wọ́n ti lọ̀, pẹ̀lú onírúurú èròjà atasánsán, yàtọ̀ sí òjíá, kún inú ikùn tó ti ṣófo náà, wọ́n á sì rán an pa.”

Wọ́n á wá fa omi ara òkú náà gbẹ nípa rírẹ ẹ́ sínú èròjà natron fún àádọ́rin ọjọ́. Lẹ́yìn náà, wọ́n á wá wẹ òkú náà, wọ́n á sì rọra fi aṣọ ọ̀gbọ̀ wé e. Wọ́n á wá da oje igi tàbí ohun kan tó dà bíi gọ́ọ̀mù tó máa ṣe iṣẹ́ àtè sára aṣọ ọ̀gbọ̀ náà, wọ́n á wá gbé òkú tí wọ́n kùn lọ́ṣẹ náà [mummy] sínú àpótí onígi tí wọ́n ṣe lọ́ṣọ̀ọ́, èyí tí wọ́n ṣe lọ́nà tó fi lè gba ènìyàn.

Lóde òní, wọ́n lè parí kíkun òkú lọ́ṣẹ láàárín wákàtí bíi mélòó kan. Bí wọ́n ṣe ń ṣe é ni pé wọ́n á rọ èròjà olómi tí wọ́n fi ń kun òkú lọ́ṣẹ sínú àwọn iṣan, àti òpó tí ń gbẹ́jẹ̀ jáde láti inú ọkàn, wọ́n á tún dà á sínú àwọn ihò tó wà nínú ikùn àti àyà. Onírúurú nǹkan olómi tí wọ́n fi ń kun òkú lọ́ṣẹ ni wọ́n ti ṣe, tí wọ́n sì ti lò bí ọdún ti ń gorí ọdún. Àmọ́, èròjà formaldehyde ni ọ̀pọ̀ jù lọ máa ń lò fún kíkun òkú lọ́ṣẹ, nítorí pé kò wọ́nwó àti pé kì í sì í ṣeni léṣe.

[Àwòrán]

Pósí oníwúrà ti Ọba Tutankhamen