Èé Ṣe Tó Fi Yẹ Kó o Ṣe Batisí?
Èé Ṣe Tó Fi Yẹ Kó o Ṣe Batisí?
“Ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn.”—Mátíù 28:19.
1, 2. (a) Báwo ni ìbatisí ṣe wáyé nínú àwọn ọ̀ràn kan? (b) Àwọn ìbéèrè wo la gbé dìde nípa ìbatisí?
LẸ́YÌN tí Charlemagne, Ọba àwọn ẹ̀yà Frank ṣẹ́gun àwọn Saxon, ó fagbára mú kí gbogbo wọn lápapọ̀ ṣe batisí lọ́dún 775 sí 777 Sànmánì Tiwa. Òpìtàn John Lord kọ̀wé pé: “Ó fipá sọ wọ́n di Kristẹni aláfẹnujẹ́.” Bẹ́ẹ̀ náà ni Vladimir Kìíní, tó jẹ́ alákòóso ilẹ̀ Rọ́ṣíà ṣe pinnu pé gbogbo àwọn ọmọ abẹ́ òun gbọ́dọ̀ di “Kristẹni,” lẹ́yìn tó gbé ọmọbabìnrin kan tó jẹ́ ẹlẹ́sìn Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ilẹ̀ Gíríìkì níyàwó lọ́dún 987 Sànmánì Tiwa. Ó pàṣẹ pé káwọn èèyàn òun lápapọ̀ ṣe batisí—pé kí wọ́n fi idà pa ẹnikẹ́ni tó bá kọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀!
2 Ǹjẹ́ irú ìbatisí bẹ́ẹ̀ tọ̀nà? Ǹjẹ́ ó nítumọ̀ gidi? Ṣé ẹnikẹ́ni ló kàn lè ṣe batisí?
Ìbatisí—Lọ́nà Wo?
3, 4. Èé ṣe tí wíwọ́n omi síni lára tàbí dída omi léni lórí kì í ṣe ọ̀nà tí ó tọ́ fún Kristẹni láti ṣe batisí?
3 Nígbà tí Charlemagne àti Vladimir Kìíní fagbára mú àwọn èèyàn ṣe batisí, àwọn alákòóso wọ̀nyẹn ṣe ohun tó lòdì pátápátá sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ká sọ tòótọ́, kò sí àǹfààní kankan nínú ìbatisí tá a ti wọ́n omi sáwọn èèyàn lára, tàbí èyí tá a ti da omi léni lórí, tàbí èyí tá a ti ri àwọn tí a kò fi òtítọ́ Ìwé Mímọ́ kọ́ bọmi pàápàá.
4 Ṣàgbéyẹ̀wò ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jésù ará Násárétì lọ sọ́dọ̀ Jòhánù Olùbatisí ní ọdún 29 Sànmánì Tiwa. Jòhánù ń batisí àwọn èèyàn nínú Odò Jọ́dánì. Ńṣe ni wọ́n fínnúfíndọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀ kí ó lè batisí wọn. Ṣé ó wulẹ̀ sọ pé kí wọ́n dúró sí Jọ́dánì ni, tó sì da omi díẹ̀ tó bù nínú odò náà lé wọn lórí tàbí ńṣe ló wọ́n omi náà sí wọn lára? Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jòhánù batisí Jésù? Mátíù ròyìn pé lẹ́yìn tí a batisí rẹ̀, “Jésù jáde lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ láti inú omi.” (Mátíù 3:16) Ó lọ sí ìsàlẹ̀ omi náà, nígbà tó rì í bọnú Odò Jọ́dánì. Bákan náà la ṣe batisí ìwẹ̀fà ará Etiópíà tó jẹ́ olùfọkànsìn nínú “ìwọ́jọpọ̀ omi.” Wọ́n nílò irú ìwọ́jọpọ̀ omi bẹ́ẹ̀ nítorí pé ìbatisí Jésù àti ti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ jẹ́ rírì wọ́n bọnú omi pátápátá.—Ìṣe 8:36.
5. Báwo làwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ṣe batisí àwọn èèyàn?
5 Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a túmọ̀ sí “ṣe batisí,” “ìbatisí,” àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, tọ́ka sí rírì bọmi tàbí títẹ̀ bọnú omi. Ìwé atúmọ̀ èdè náà, Smith’s Bible Dictionary sọ pé: “Ìbatisí ní gidi àti ní ṣáńgílítí túmọ̀ sí ìrìbọmi.” Abájọ tí àwọn ìtumọ̀ Bíbélì kan fi tọ́ka sí “Jòhánù Arinibọmi” àti “Jòhánù Atẹnibọmi.” (Mátíù 3:1, Rotherham; Diaglott interlinear) Ìwé History of the Christian Religion and Church, During the Three First Centuries tí Augustus Neander ṣe, sọ pé: “Ríri èèyàn bọmi ni ọ̀nà tá a gbà ń ṣe batisí ní ìpilẹ̀ṣẹ̀.” Ìwé Faransé náà, Larousse du XXe Siècle (Paris, 1928) sọ pé: “Àwọn Kristẹni àkọ́kọ́ pàá ṣe batisí wọn nípasẹ̀ ìrìbọmi níbikíbi tí wọ́n bá ti rí omi.” Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ New Catholic Encyclopedia sì sọ pé: “Ó hàn gbangba pé ọ̀nà tí Ṣọ́ọ̀ṣì àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ gbà ń ṣe Ìbatisí jẹ́ nípasẹ̀ ìrìbọmi.” (1967, Apá Kejì, ojú ìwé 56) Nítorí náà, lóde òní, ìbatisí gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ ìgbésẹ̀ tí a fínnúfíndọ̀ ṣe, tó sì jẹ́ ríri èèyàn bọnú omi pátápátá.
Ìdí Tuntun Tó Fí Yẹ Ká Ṣe Batisí
6, 7. (a) Kí ni ìdí tí Jòhánù fi batisí àwọn èèyàn? (b) Kí ló jẹ́ tuntun nípa ìbatisí táwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ṣe?
6 Ìdí tí Jòhánù fi ṣe ìbatisí tirẹ̀ yàtọ̀ sí ìdí táwọn ọmọlẹ́yìn Jésù fi ṣe ìrìbọmi tiwọn. (Jòhánù 4:1, 2) Jòhánù batisí àwọn èèyàn gẹ́gẹ́ bí àmì tí gbogbo èèyàn fi mọ̀ pé wọ́n ti ronú pìwà dà ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ṣẹ̀ sí Òfin. a (Lúùkù 3:3) Àmọ́, ohun kan jẹ́ tuntun nínú ìbatisí tí àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ṣe. Ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa, àpọ́sítélì Pétérù rọ àwọn olùgbọ́ rẹ̀ pé: “Ẹ ronú pìwà dà, kí a sì batisí olúkúlùkù yín ní orúkọ Jésù Kristi fún ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín.” (Ìṣe 2:37-41) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Júù àtàwọn aláwọ̀ṣe ni Pétérù ń bá sọ̀rọ̀, síbẹ̀ kò sọ̀rọ̀ nípa ìbatisí tó jẹ́ àmì ìrònúpìwàdà lórí ẹ̀ṣẹ̀ tó lòdì sí Òfin; bẹ́ẹ̀ ni kò sọ pé ìbatisí ní orúkọ Jésù túmọ̀ sí wíwẹ ẹ̀ṣẹ̀ nù.—Ìṣe 2:10.
7 Nígbà yẹn ni Pétérù lo èkíní nínú “àwọn kọ́kọ́rọ́ ìjọba náà.” Fún ète wo? Kí ó lè ṣí ìmọ̀ nípa àǹfààní tí àwọn olùgbọ́ rẹ̀ ní láti wọnú Ìjọba ọ̀run payá fún wọn ni. (Mátíù 16:19) Nítorí pé àwọn Júù ti kọ Jésù gẹ́gẹ́ bí Mèsáyà, ríronú pìwà dà àti lílo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ jẹ́ kókó tuntun, tó sì ṣe pàtàkì nínú títọrọ ìdáríjì lọ́dọ̀ Ọlọ́run àti rírí ìdáríjì náà gbà. Wọ́n lè fi hàn ní gbangba pé àwọn ní irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ nípa ṣíṣe ìrìbọmi ní orúkọ Jésù Kristi. Ní ọ̀nà yẹn, wọ́n á fi hàn pé àwọn ti ya ara àwọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run nípasẹ̀ Kristi. Gbogbo àwọn tó bá fẹ́ kí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà wọ́n lóde òní gbọ́dọ̀ ní irú ìgbàgbọ́ kan náà, kí wọ́n ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà Ọlọ́run, kí wọ́n sì ṣe batisí Kristẹni tó jẹ́ ẹ̀rí ìyàsímímọ́ wọn fún Ọlọ́run Gíga Jù Lọ náà.
Ìmọ̀ Pípéye Ṣe Pàtàkì
8. Kí nìdí tí ìrìbọmi Kristẹni kò fi tọ́ sí gbogbo èèyàn?
8 Kì í ṣe gbogbo èèyàn ni ìrìbọmi Kristẹni tọ́ sí. Jésù pàṣẹ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́, ẹ máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún yín mọ́.” (Mátíù 28:19, 20) Káwọn èèyàn tó ṣe ìrìbọmi, a gbọ́dọ̀ ‘kọ́ wọn láti pa gbogbo ohun tí Jésù pa láṣẹ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ mọ́.’ Nítorí náà, ìbatisí tá a ṣe tipátipá fáwọn tí kò nígbàgbọ́ tá a gbé ka ìmọ̀ pípéye nípa Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ èyí tí kò wúlò rárá, tó sì lòdì sí àṣẹ tí Jésù pa fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tòótọ́.—Hébérù 11:6.
9. Kí ló túmọ̀ sí láti ṣe batisí “ní orúkọ Baba”?
9 Kí ló túmọ̀ sí láti ṣe batisí “ní orúkọ Baba”? Ó túmọ̀ sí pé ẹni tó fẹ́ ṣe ìrìbọmi náà bọ̀wọ̀ fún ipò àti ọlá àṣẹ Baba wa ọ̀run. Ó sì tipa bẹ́ẹ̀ gbà pé Jèhófà Ọlọ́run ni Ẹlẹ́dàá wa, “Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ilẹ̀ ayé,” àti Ọba Aláṣẹ Ayé òun Ọ̀run.—Sáàmù 83:18; Aísáyà 40:28; Ìṣe 4:24.
10. Kí ló túmọ̀ sí láti ṣe batisí ‘lórúkọ Ọmọ’?
10 Láti ṣe batisí ‘lórúkọ Ọmọ’ túmọ̀ sí láti bọ̀wọ̀ fún ipò àti ọlá àṣẹ Jésù gẹ́gẹ́ bí Ọmọ bíbí kan ṣoṣo Ọlọ́run. (1 Jòhánù 4:9) Àwọn tó tóótun fún ìrìbọmi tẹ́wọ́ gba Jésù gẹ́gẹ́ bí ẹni tí Ọlọ́run tipasẹ̀ rẹ̀ pèsè “ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.” (Mátíù 20:28; 1 Tímótì 2:5, 6) Àwọn tó fẹ́ ṣe ìrìbọmi tún gbọ́dọ̀ bọ̀wọ̀ fún “ipò gíga” tí Ọlọ́run gbé Ọmọ rẹ̀ sí.—Fílípì 2:8-11; Ìṣípayá 19:16.
11. Kí ló túmọ̀ sí láti ṣe batisí ‘ní orúkọ ẹ̀mí mímọ́’?
11 Kí ni ìjẹ́pàtàkì ṣíṣe batisí ‘ní orúkọ ẹ̀mí mímọ́’? Èyí túmọ̀ sí pé àwọn tó fẹ́ ṣe batisí gbà pé ẹ̀mí mímọ́ jẹ́ ipá ìṣiṣẹ́ Jèhófà, èyí tó ń lò ní onírúurú ọ̀nà tó bá ète rẹ̀ mu. (Jẹ́nẹ́sísì 1:2; 2 Sámúẹ́lì 23:1, 2; 2 Pétérù 1:21) Àwọn tó tóótun láti ṣe batisí gbà pé ẹ̀mí mímọ́ ló ran àwọn lọ́wọ́ láti lóye “àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run,” láti máa ṣe iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà, àti láti ní àwọn èso ti ẹ̀mí, ìyẹn “ìfẹ́, ìdùnnú, àlàáfíà, ìpamọ́ra, inú rere, ìwà rere, ìgbàgbọ́, ìwà tútù, ìkóra-ẹni-níjàánu.”—1 Kọ́ríńtì 2:10; Gálátíà 5:22, 23; Jóẹ́lì 2:28, 29.
Ìjẹ́pàtàkì Ìrònúpìwàdà àti Ìyílọ́kànpadà
12. Báwo ni ìrìbọmi Kristẹni ṣe tan mọ́ ìrònúpìwàdà?
12 Yàtọ̀ sí ìbatisí Jésù tó jẹ́ aláìlẹ́ṣẹ̀, ìbatisí jẹ́ àmì tí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà, ìyẹn àmì tó fi ìrònúpìwàdà hàn. Nígbà tá a bá ronú pìwà dà, èyí túmọ̀ sí pé a kẹ́dùn tàbí pé a kábàámọ̀ nǹkan kan tá a ṣe tàbí tá a kùnà láti ṣe. Àwọn Júù ọ̀rúndún kìíní, tí wọ́n fẹ́ múnú Ọlọ́run dùn ní láti ronú pìwà dà ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ṣẹ Kristi. (Ìṣe 3:11-19) Àwọn Kèfèrí kan tó jẹ́ onígbàgbọ́ ní Kọ́ríńtì ronú pìwà dà kúrò nínú àgbèrè, ìbọ̀rìṣà, olè jíjà, àti àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo mìíràn. Nítorí ìrònúpìwàdà wọn, a ‘wẹ̀ wọ́n mọ́’ nínú ẹ̀jẹ̀ Jésù; a ‘sọ wọ́n di mímọ́,’ tàbí a yà wọ́n sọ́tọ̀, fún iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run; a sì fi orúkọ Kristi àti ẹ̀mí Ọlọ́run ‘polongo wọn ní olódodo.’ (1 Kọ́ríńtì 6:9-11) Ìrònúpìwàdà jẹ́ ìgbésẹ̀ pàtàkì nínú jíjèrè ẹ̀rí ọkàn rere àti ìdáǹdè tí Ọlọ́run máa ń fúnni kúrò nínú ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀.—1 Pétérù 3:21.
13. Nínú ọ̀ràn ìbatisí, kí ni ìyílọ́kànpadà wé mọ́?
13 Ìyílọ́kànpadà gbọ́dọ̀ wáyé kí a tó ṣe batisí gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ìyílọ́kànpadà jẹ́ ìgbésẹ̀ tí ẹni tó ti fi tọkàntọkàn pinnu láti tẹ̀ lé Kristi Jésù ń fínnúfíndọ̀ gbé. Irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ máa ń ṣíwọ́ híhu ìwà búburú tí wọ́n ń hù tẹ́lẹ̀, wọ́n á sì pinnu láti ṣe ohun tí ó tọ́ lójú Ọlọ́run. Nínú Ìwé Mímọ́, àwọn ọ̀rọ̀ ìṣe Hébérù àti ti Gíríìkì tó ní í ṣe pẹ̀lú ìrònúpìwàdà ní èrò yíyí padà nínú. Ìgbésẹ̀ yìí túmọ̀ sí kíkúrò ní ọ̀nà búburú kí a sì yí padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run. (1 Àwọn Ọba 8:33, 34) Ìyílọ́kànpadà ń béèrè “àwọn iṣẹ́ tí ó yẹ fún ìrònúpìwàdà.” (Ìṣe 26:20) Ó ń béèrè pé ká pa ìjọsìn èké tì, ká gbé ìgbésẹ̀ tó bá àwọn àṣẹ Ọlọ́run mu, ká sì máa fún Jèhófà ní ìfọkànsìn tí a yà sọ́tọ̀ gedegbe. (Diutarónómì 30:2, 8-10; 1 Sámúẹ́lì 7:3) Ìyílọ́kànpadà ń yọrí sí yíyí ìrònú wa, ète wa, àti ìtẹ̀sí ọkàn wa padà. (Ìsíkíẹ́lì 18:31) À ń “yí padà” bí a ṣe ń fi àkópọ̀ ìwà tuntun rọ́pò àwọn ìwà tínú Ọlọ́run kò dùn sí.— Ìṣe 3:19; Éfésù 4:20-24; Kólósè 3:5-14.
Ìyàsímímọ́ Àtọkànwá Ṣe Pàtàkì
14. Kí ni ìyàsímímọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù túmọ̀ sí?
14 Ìyàsímímọ́ àtọkànwá fún Ọlọ́run tún gbọ́dọ̀ wáyé kí àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù tó ṣe batisí. Ìyàsímímọ́ túmọ̀ sí yíyanisọ́tọ̀ fún ète mímọ́ kan. Ìgbésẹ̀ yìí ṣe pàtàkì gan-an débi pé a gbọ́dọ̀ sọ fún Jèhófà nínú àdúrà pé a ti pinnu láti fún un ní ìfọkànsìn tí a yà sọ́tọ̀ gedegbe títí ayérayé. (Diutarónómì 5:9) Àmọ́ ṣá o, a kò ya ara wa sí mímọ́ fún iṣẹ́ pàtó kan tàbí fún ènìyàn kan bí kò ṣe fún Ọlọ́run fúnra rẹ̀.
15. Èé ṣe táwọn tó múra tán fún ìbatisí fi ní láti ṣèrìbọmi?
15 Nígbà tá a bá ya ara wa sí mímọ́ fún Ọlọ́run nípasẹ̀ Kristi, a fi hàn pé a ti pinnu láti lo ìgbésí ayé wa nínú ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run bí a ti lànà rẹ̀ sílẹ̀ nínú Ìwé Mímọ́. Láti fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ yẹn hàn, àwọn tó múra tán fún ìbatisí gbọ́dọ̀ ṣe ìrìbọmi, àní bí Jésù ṣe ṣe batisí ní Odò Jọ́dánì láti fi hàn pé òun ti fi ara òun fún Ọlọ́run pátápátá. (Mátíù 3:13) Ó yẹ fún àfiyèsí pé Jésù ń gbàdúrà ní àkókò pàtàkì yẹn.—Lúùkù 3:21, 22.
16. Báwo la ṣe lè fi ayọ̀ wa hàn lọ́nà tó bójú mu nígbà tá a bá rí àwọn tó ń ṣe batisí?
16 Ìbatisí Jésù kì í ṣe ọ̀ràn eré, àmọ́ ó jẹ́ ohun tó kún fún ìdùnnú. Bẹ́ẹ̀ náà ni ìrìbọmi Kristẹni ṣe rí lóde òní. Nígbà tá a bá rí àwọn èèyàn tí wọ́n ń fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ wọn fún Ọlọ́run hàn, a lè fi ìdùnnú wa hàn nípa fífi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ pàtẹ́wọ́, ká sì gbóríyìn fún wọn. Àmọ́, a gbọ́dọ̀ yẹra fún sísà wọ́n, sísúfèé, àti irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀, ká lè fi hàn pé a mọyì ìjẹ́mímọ́ ìgbésẹ̀ ìgbàgbọ́ tí wọ́n gbé yìí. A ó fi ìdùnnú wa hàn ní ọ̀nà tó gbayì.
17, 18. Kí ló ń jẹ́ ká mọ̀ bóyá àwọn kan tóótun láti ṣe ìbatisí?
17 Láìdàbí àwọn tó ń wọ́n omi sáwọn ọmọ ọwọ́ lára tàbí àwọn tó ń fi agbára mú kí àwọn tí kò mọ̀ nípa Ìwé Mímọ́ ṣe batisí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò fagbára mú ẹnikẹ́ni ṣe batisí rí. Àní, wọn kì í tiẹ̀ batisí àwọn tí kò bá tóótun nípa tẹ̀mí. Kódà, kí ẹnì kan tó di oníwàásù ìhìn rere tí kò tíì ṣe batisí pàápàá, àwọn Kristẹni alàgbà máa ń rí i dájú pé irú ẹni bẹ́ẹ̀ lóye àwọn lájorí ẹ̀kọ́ Bíbélì, pé ó ń gbé níbàámu pẹ̀lú wọn, pé ó sì dáhùn bẹ́ẹ̀ ni sí ìbéèrè bíi, “Ṣé lóòótọ́ lo fẹ́ di Ẹlẹ́rìí Jèhófà?”
18 Lọ́pọ̀ ìgbà, táwọn èèyàn bá ń kópa tó ṣe gúnmọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà, tí wọ́n sì sọ pé ó wu àwọn láti ṣe batisí ni àwọn Kristẹni alàgbà máa ń bá wọn jíròrò láti rí i dájú pé wọ́n jẹ́ onígbàgbọ́ tó ti ya ara wọ́n sí mímọ́ fún Jèhófà, tó sì ti dé ojú ìwọ̀n ohun tí Ọlọ́run ń béèrè fún ìbatisí. (Ìṣe 4:4; 18:8) Bí wọ́n bá ṣe fúnra wọn dáhùn àwọn ìbéèrè tó lé ní ọgọ́rùn-ún tó dá lórí àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì ló ń ran àwọn alàgbà lọ́wọ́ láti mọ̀ bóyá àwọn tó ń dáhùn ìbéèrè yìí dé ojú ìwọ̀n ohun tí Ìwé Mímọ́ là sílẹ̀ fún ìrìbọmi. Àwọn kan kò ní tóótun, nípa bẹ́ẹ̀ a ò ní gbà wọ́n láyè láti ṣe batisí gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni.
Ṣé Nǹkan Kan Ń Dí Ẹ Lọ́wọ́ Ni?
19. Lójú ohun tó wà nínú Jòhánù 6:44, àwọn wo ló máa jẹ́ àjùmọ̀jogún pẹ̀lú Jésù?
19 Bóyá ohun tí wọ́n sọ fún ọ̀pọ̀ lára àwọn irú-wá-ògìrì-wá tí wọ́n batisí tipátipá ni pé wọ́n á lọ sí ọ̀run nígbà tí wọ́n bá kú. Àmọ́, ohun tí Jésù sọ nípa àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ni pé: “Kò sí ènìyàn kankan tí ó lè wá sọ́dọ̀ mi láìjẹ́ pé Baba, tí ó rán mi, fà á.” (Jòhánù 6:44) Jèhófà ti fa àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì tí wọ́n máa jẹ́ àjùmọ̀jogún pẹ̀lú Jésù nínú Ìjọba ọ̀run sọ́dọ̀ Kristi. Ìbatisí tá a fagbára múni ṣe kò sì tíì mú kí ẹnikẹ́ni tóótun fún ipò ológo yẹn nínú ìṣètò Ọlọ́run.—Róòmù 8:14-17; 2 Tẹsalóníkà 2:13; Ìṣípayá 14:1.
20. Kí ló lè ran àwọn kan tí kò tíì ṣe ìrìbọmi lọ́wọ́?
20 Láti àárín àwọn ọdún 1930 ní pàtàkì ni ògìdìgbó tó ń retí àtila “ìpọ́njú ńlá” já, kí wọ́n sì máa gbé orí ilẹ̀ ayé títí láé, ti ń dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ “àwọn àgùntàn mìíràn” Jésù. (Ìṣípayá 7:9, 14; Jòhánù 10:16) Wọ́n tóótun fún ìbatisí nítorí pé wọ́n mú ìgbésí ayé wọn bá Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mu, wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú ‘gbogbo ọkàn-àyà wọn, ọkàn wọn, okun wọn, àti èrò inú wọn.’ (Lúùkù 10:25-28) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan wà tí wọ́n gbà pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ‘ń jọ́sìn Ọlọ́run ní ẹ̀mí àti òtítọ́,’ síbẹ̀ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ kò tíì tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, kí wọ́n sì fi hàn pé àwọn ní ìfẹ́ jíjinlẹ̀ àti ìfọkànsìn tí a yà sọ́tọ̀ gedegbe fún Jèhófà nípa ṣíṣe batisí. (Jòhánù 4:23, 24; Diutarónómì 4:24; Máàkù 1:9-11) Àdúrà àtọkànwá tó sì ṣe pàtó lórí ìgbésẹ̀ pàtàkì yìí lè jẹ́ ohun tó máa mórí wọn yá, tó sì máa fún wọn níṣìírí láti mú ìgbésí ayé wọn wà níbàámu pẹ̀lú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí yóò mú kí wọ́n ya ara wọn sí mímọ́ pátápátá fún Jèhófà Ọlọ́run, kí wọ́n sì ṣe batisí.
21, 22. Kí nìdí táwọn kan fi ń lọ́ tìkọ̀ láti ya ara wọn sí mímọ́, kí wọ́n sì ṣe ìrìbọmi?
21 Àwọn kàn ò fẹ́ ya ara wọn sí mímọ́, kí wọ́n sì ṣe batisí nítorí pé àwọn nǹkan ti ayé tàbí ìlépa ọrọ̀ ti gba gbogbo àkókò wọn débi pé ìwọ̀nba àkókò díẹ̀ ni wọ́n ní fún àwọn nǹkan tẹ̀mí. (Mátíù 13:22; 1 Jòhánù 2:15-17) Ẹ wo bí ayọ̀ wọn ì bá ti pọ̀ tó, ká ní wọ́n lè yí ojú ìwòye wọn àti ohun tí wọ́n ń lépa padà! Sísún mọ́ Jèhófà yóò mú kí ipò tẹ̀mí wọn túbọ̀ dára sí i, yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ láti bọ́ lọ́wọ́ ṣíṣàníyàn, yóò sì fún wọn ní àlàáfíà àti ìtẹ́lọ́rùn tó máa ń tinú ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run wá.—Sáàmù 16:11; 40:8; Òwe 10:22; Fílípì 4:6, 7.
22 Àwọn mìíràn sọ pé àwọn nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, àmọ́ wọn ò fẹ́ ya ara wọn sí mímọ́ kí wọ́n sì ṣe ìrìbọmi nítorí pé wọ́n rò pé àwọn á tipa bẹ́ẹ̀ bọ́ lọ́wọ́ ìjíhìn. Àmọ́ olúkúlùkù wa ni yóò jíhìn fún Ọlọ́run. Ìgbà tá a ti gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà ni ẹrù iṣẹ́ náà ti já lé wa léjìká. (Ìsíkíẹ́lì 33:7-9; Róòmù 14:12) Gẹ́gẹ́ bí ‘àwọn àyànfẹ́,’ inú orílẹ̀-èdè kan tí a ti yà sí mímọ́ fún Jèhófà la bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì sí. Ó sì tipa bẹ́ẹ̀ di dandan fún wọn láti fi ìṣòtítọ́ sìn ín ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà rẹ̀. (Diutarónómì 7:6, 11) Kò sí ẹni tá a bí sínú irú orílẹ̀-èdè bẹ́ẹ̀ lóde òní, àmọ́ tá a bá ti rí ìtọ́ni pípéye gbà látinú Ìwé Mímọ́, ó yẹ ká fi ìgbàgbọ́ ṣiṣẹ́ lé e lórí.
23, 24. Àwọn ìbẹ̀rù wo ni kò yẹ kó máa mú kéèyàn lọ́ tìkọ̀ láti ṣe batisí?
23 Ìbẹ̀rù pé àwọn ò tíì ní ìmọ̀ tó lè mú káwọn kan máa sá fún ṣíṣe batisí. Àmọ́, gbogbo wa la ní ọ̀pọ̀ nǹkan láti kọ́, nítorí pé ‘aráyé kò lè rídìí iṣẹ́ tí Ọlọ́run tòótọ́ ti ṣe láé láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin.’ (Oníwàásù 3:11) Gbé ọ̀ràn ìwẹ̀fà ará Etiópíà yẹ̀ wò. Gẹ́gẹ́ bí aláwọ̀ṣe, ó mọ Ìwé Mímọ́ títí dé àyè kan, ṣùgbọ́n kò lè dáhùn gbogbo ìbéèrè tó ní í ṣe pẹ̀lú àwọn ète Ọlọ́run. Àmọ́, nígbà tí ìwẹ̀fà náà gbọ́ nípa ètò tí Jèhófà ṣe fún ìgbàlà nípasẹ̀ ẹbọ ìràpadà Jésù, ojú ẹsẹ̀ ló ṣe ìrìbọmi.—Ìṣe 8:26-38.
24 Àwọn kan ń lọ́ tìkọ̀ láti ya ara wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run nítorí wọ́n ń bẹ̀rù pé àwọn lè kùnà. Monique, ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún sọ pé: “Mò ń sá fún ṣíṣe batisí nítorí mò ń bẹ̀rù pé mi ò ní lè gbé níbàámu pẹ̀lú ìyàsímímọ́ mi.” Àmọ́, bí a bá fi gbogbo ọkàn wa gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ‘yóò mú àwọn ipa ọ̀nà wa tọ́.’ Yóò ràn wá lọ́wọ́ láti máa “bá a lọ ní rírìn nínú òtítọ́” gẹ́gẹ́ bí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ tó ti ṣe ìyàsímímọ́.—Òwe 3:5, 6; 3 Jòhánù 4.
25. Ìbéèrè wo ló yẹ ká gbé yẹ̀ wò báyìí?
25 Nítorí ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún nínú Jèhófà àti ìfẹ́ àtọkànwá tá a ní fún un, ọdọọdún ni ẹgbẹẹgbẹ̀rún ń ya ara wọn sí mímọ́, tí wọ́n sì ń ṣe ìrìbọmi. Dájúdájú, gbogbo ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó ti ya ara wọn sí mímọ́ ló fẹ́ jẹ́ olóòótọ́ sí i. Àmọ́, àwọn àkókò líle koko là ń gbé, a sì ń dojú kọ onírúurú àdánwò ìgbàgbọ́. (2 Tímótì 3:1-5) Kí la lè ṣe láti máa gbé níbàámu pẹ̀lú ìyàsímímọ́ wa sí Jèhófà? Èyí ni a óò gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Níwọ̀n bí Jésù ti jẹ́ aláìlẹ́ṣẹ̀, ìrìbọmi tó ṣe kì í ṣe àmì ìrònúpìwàdà. Ìrìbọmi rẹ̀ jẹ́ àmì pé ó fi ara rẹ̀ fún Ọlọ́run láti ṣe ìfẹ́ Baba rẹ̀.—Hébérù 7:26; 10:5-10.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Báwo la ṣe ń ṣe batisí Kristẹni?
• Ìmọ̀ wo lèèyàn gbọ́dọ̀ ní kó tó lè ṣe batisí?
• Àwọn ìgbésẹ̀ wo ló ń ṣamọ̀nà sí ṣíṣe batisí gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni tòótọ́?
• Èé ṣe táwọn kan fi ń lọ́ tìkọ̀ láti ṣe batisí, àmọ́ báwo la ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]
Ǹjẹ́ o mọ ohun tó túmọ̀ sí láti ṣe batisí ‘ní orúkọ Baba, orúkọ Ọmọ, àti ti ẹ̀mí mímọ́’?