Ẹ Máa Fi Ọkàn-àyà Tó Fẹsẹ̀ Múlẹ̀ Ṣinṣin Sin Jèhófà
Ẹ Máa Fi Ọkàn-àyà Tó Fẹsẹ̀ Múlẹ̀ Ṣinṣin Sin Jèhófà
“Ọkàn-àyà mi fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin, Ọlọ́run, Ọkàn-àyà mi fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin.”—SÁÀMÙ 57:7.
1. Èé ṣe tá a fi lè ní ìdánilójú bíi ti Dáfídì?
JÈHÓFÀ lè jẹ́ ká fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin nínú ìgbàgbọ́ Kristẹni, kí a lè rọ̀ mọ́ ẹ̀sìn Kristẹni tòótọ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó ti ṣe ìyàsímímọ́. (Róòmù 14:4) Nítorí náà, a lè ní ìdánilójú bíi ti Dáfídì onísáàmù, ẹni tó kọrin pé: “Ọkàn-àyà mi fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin, Ọlọ́run.” (Sáàmù 108:1) Bí ọkàn-àyà wa bá fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin, ìyẹn yóò sún wa láti gbé níbàámu pẹ̀lú ìyàsímímọ́ wa sí Ọlọ́run. Tá a bá sì ń wojú rẹ̀ fún ìtọ́sọ́nà àti okun, a lè di ẹni tí kò ṣeé ṣí nípò, tó ń dúró ti ìpinnu àti ìgbàgbọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùpa ìwà títọ́ mọ́, tó sì ń “ní púpọ̀ rẹpẹtẹ láti ṣe nígbà gbogbo nínú iṣẹ́ Olúwa.”—1 Kọ́ríńtì 15:58.
2, 3. Kí ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù tó wà nínú 1 Kọ́ríńtì 16:13?
2 Nínú ọ̀rọ̀ ìyànjú tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ní Kọ́ríńtì ìgbàanì, tó sì dájú pé ó tún kan àwa Kristẹni òde òní, ó sọ pé: “Ẹ wà lójúfò, ẹ dúró gbọn-in gbọn-in nínú ìgbàgbọ́, ẹ máa bá a nìṣó bí ọkùnrin, ẹ di alágbára ńlá.” (1 Kọ́ríńtì 16:13) Ní èdè Gíríìkì, ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn àṣẹ wọ̀nyí la sọ bí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́, tó sì tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ ìgbésẹ̀ tí kò yẹ kó dáwọ́ dúró. Kí ni ìjẹ́pàtàkì ọ̀rọ̀ ìṣílétí yìí?
3 A lè “wà lójúfò” nípa tẹ̀mí tá a bá ń kọ ojú ìjà sí Èṣù, tá a sì sún mọ́ Ọlọ́run. (Jákọ́bù 4:7, 8) Gbígbára lé Jèhófà ń mú kó ṣeé ṣe fún wa láti wà níṣọ̀kan, ká sì ‘dúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́ Kristẹni.’ Gbogbo wa—títí kan ọ̀pọ̀ obìnrin tó wà láàárín wa—ní láti “máa bá a nìṣó bí ọkùnrin” nípa fífi ìgboyà sin Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùpòkìkí Ìjọba náà. (Sáàmù 68:11) A ó “di alágbára ńlá” bí a bá ń wo ojú Baba wa ọ̀run fún okun láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀.—Fílípì 4:13.
4. Kí ló mú wa ṣe batisí gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni?
4 A fi hàn pé a tẹ́wọ́ gba òtítọ́ nígbà tá a ya ara wa sí mímọ́ pátápátá fún Jèhófà, tá a sì fi ẹ̀rí èyí hàn nípa ṣíṣe ìrìbọmi. Àmọ́, kí ló ṣamọ̀nà sí ṣíṣe batisí? Lákọ̀ọ́kọ́, a gba ìmọ̀ pípéye nípa Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sínú. (Jòhánù 17:3) Èyí ló jẹ́ ká nígbàgbọ́, tó tún sún wa láti ronú pìwà dà, tó sì mú ká fi tọkàntọkàn kẹ́dùn ìwà àìtọ́ tá a ti hù sẹ́yìn. (Ìṣe 3:19; Hébérù 11:6) Ẹ̀yìn ìyẹn la yí padà, nítorí pé ká lè máa gbé ìgbésí ayé tó wà níbàámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run la ṣe sá fún àwọn ìwà búburú. (Róòmù 12:2; Éfésù 4:23, 24) Ohun tó wá tẹ̀ lé èyí ni pé a fi tọkàntọkàn ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà nínú àdúrà. (Mátíù 16:24; 1 Pétérù 2:21) A bẹ Ọlọ́run pé kó fún wa ní ẹ̀rí ọkàn rere, a sì ṣe batisí gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí ìyàsímímọ́ wa fún un. (1 Pétérù 3:21) Ríronú lórí àwọn ìgbésẹ̀ wọ̀nyí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti wà lójúfò, ká máa sapá nìṣó láti gbé níbàámu pẹ̀lú ìyàsímímọ́ wa, ká sì máa bá a lọ láti fi ọkàn-àyà tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin sin Jèhófà.
Má Ṣe Jáwọ́ Nínú Wíwá Ìmọ̀ Pípéye
5. Èé ṣe tó fi yẹ ká máa bá a lọ láti gba ìmọ̀ kún ìmọ̀ nínú Ìwé Mímọ́?
5 Ká tó lè gbé níbàámu pẹ̀lú ìyàsímímọ́ wa fún Ọlọ́run, a gbọ́dọ̀ máa bá a lọ láti jèrè ìmọ̀ Ìwé Mímọ́ tó ń gbé ìgbàgbọ́ ró. Ẹ wo bí oúnjẹ tẹ̀mí ti jẹ́ ohun ìdùnnú fún wa tó nígbà tá a kọ́kọ́ mọ̀ nípa òtítọ́ Ọlọ́run! (Mátíù 24:45-47) “Oúnjẹ” wọ̀nyẹn dùn gan-an—wọ́n sì ṣe ara wa lóore nípa tẹ̀mí. Ó ṣe pàtàkì fún wa nísinsìnyí láti máa jẹ oúnjẹ tí ń fúnni lókun nípa tẹ̀mí kí a lè ní ọkàn-àyà tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Jèhófà tó ti ṣe ìyàsímímọ́.
6. Ọ̀nà wo ló ṣeé ṣe ká gbà ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ní ìmọrírì àtọkànwá fún òtítọ́ Bíbélì?
6 A nílò ìsapá láti fi kún ìmọ̀ wa nípa Ìwé Mímọ́. Ó dà bíi wíwá ìṣúra tó fara sin kiri—ìyẹn sì gba ìsapá. Àmọ́ èrè ńlá ni o, láti rí “ìmọ̀ Ọlọ́run gan-an”! (Òwe 2:1-6) Nígbà tí ẹnì kan tó jẹ́ olùpòkìkí Ìjọba Ọlọ́run kọ́kọ́ bá ọ ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó ṣeé ṣe kó lo ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. Ó ti lè gbà yín ní àkókò tí kò kéré kẹ́ ẹ tó parí òrí kọ̀ọ̀kan, bóyá ẹ ò tiẹ̀ lè parí orí kan nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ kan pàápàá. O jàǹfààní nígbà tẹ́ ẹ̀ ń ka àwọn Ìwé Mímọ́ tá a tọ́ka sí, tẹ́ ẹ sì jíròrò wọn. Bí kókó kan bá ṣòro fún ọ láti lóye, onítọ̀hún á ṣàlàyé rẹ̀. Ẹni tó ń bá ọ ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà yẹn máa ń múra sílẹ̀ dáadáa, ó máa ń gbàdúrà fún ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run, ó sì ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ní ìmọrírì àtọkànwá fún òtítọ́.
7. Kí ló ń mú kéèyàn tóótun láti kọ́ àwọn ẹlòmíràn ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?
7 Ìsapá yìí tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ, nítorí pé Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Kí ẹnikẹ́ni tí a ń fi ọ̀rọ̀ ẹnu kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ ọ̀rọ̀ náà máa ṣàjọpín àwọn ohun rere gbogbo pẹ̀lú ẹni tí ń fúnni ní irúfẹ́ ẹ̀kọ́ ọlọ́rọ̀ ẹnu bẹ́ẹ̀.” (Gálátíà 6:6) Níhìn-ín, ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Gíríìkì yìí fi hàn pé ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run la gbìn sínú èrò inú àti ọkàn ẹni tí a “fi ọ̀rọ̀ ẹnu kọ́ lẹ́kọ̀ọ́.” Ọ̀nà tí a gbà kọ́ ẹ yẹn ló mú kó o tóótun láti jẹ́ olùkọ́ fún àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú. (Ìṣe 18:25) Tó o bá fẹ́ gbé níbàámu pẹ̀lú ìyàsímímọ́ rẹ, o gbọ́dọ̀ dúró dáadáa nípa tẹ̀mí, kí o si fẹsẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nìṣó.—1 Tímótì 4:13; Títù 1:13; 2:2.
Rántí Ìrònúpìwàdà àti Ìyílọ́kànpadà Rẹ
8. Báwo ló ṣe lè ṣeé ṣe láti ní ìwà bí Ọlọ́run?
8 Ǹjẹ́ o rántí bí ara ṣe tù ọ́ pẹ̀sẹ̀ nígbà tó o kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, tó o ronú pìwà dà, tó o sì rí i pé Ọlọ́run ti dárí jì ọ́ nítorí ìgbàgbọ́ tó o ní nínú ẹbọ ìràpadà Jésù? (Sáàmù 32:1-5; Róòmù 5:8; 1 Pétérù 3:18) Ó dájú pé o ò ní fẹ́ padà sínú ìgbésí ayé ẹ̀ṣẹ̀. (2 Pétérù 2:20-22) Yàtọ̀ sáwọn nǹkan mìíràn tó o tún lè ṣe, gbígbàdúrà sí Jèhófà nígbà gbogbo lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ní ìwà bí Ọlọ́run, láti gbé níbàámu pẹ̀lú ìyàsímímọ́ rẹ, kó o sì máa fi ìṣòtítọ́ sin Jèhófà nìṣó.—2 Pétérù 3:11, 12.
9. Lẹ́yìn jíjáwọ́ nínú àwọn iṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀, ipa ọ̀nà wo ló yẹ ká máa tọ̀?
9 Lẹ́yìn tá a ti yí ọ lọ́kàn padà, tó o sì ti jáwọ́ nínú àwọn iṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀, máa wá ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run nìṣó nípa mímú kí ọkàn rẹ fẹsẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in. Lẹ́nu kan, ńṣe lo dà bí ẹni tó ṣìnà tẹ́lẹ̀, tó wá rẹ́ni júwe ọ̀nà fún un, tó sì wá bẹ̀rẹ̀ sí tọ ọ̀nà tó tọ́. Kò yẹ kó o tún ṣìnà mọ́ o. Máa gbára lé ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run, kí o sì pinnu pé ọ̀nà ìyè ni wàá máa tọ̀.—Aísáyà 30:20, 21; Mátíù 7:13, 14.
Má Gbàgbé Ìyàsímímọ́ àti Ìrìbọmi Rẹ
10. Àwọn kókó wo ló yẹ ká fi sọ́kàn nípa ìyàsímímọ́ wa fún Ọlọ́run?
10 Rántí pé o ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà nínú àdúrà, pẹ̀lú ìrètí fífi ìṣòtítọ́ sìn ín títí ayérayé. (Júúdà 20, 21) Ìyàsímímọ́ túmọ̀ sí yíya ara ẹni sọ́tọ̀ fún ète mímọ́ kan. (Léfítíkù 15:31; 22:2) Ìyàsímímọ́ rẹ kì í ṣe àdéhùn onígbà kúkúrú, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ẹ̀jẹ́ kan tí o jẹ́ fún ènìyàn. Ó jẹ́ ìyàsímímọ́ tí kì í yẹ̀ fún Ọba Aláṣẹ Ayé òun Ọ̀run. Gbígbé níbàámu pẹ̀lú rẹ̀ sì ń béèrè ìdúróṣinṣin sí Ọlọ́run títí ayé. Bẹ́ẹ̀ ni o, ‘yálà a wà láàyè ni o tàbí a kú ni o, ti Jèhófà la jẹ́.’ (Róòmù 14:7, 8) Ayọ̀ wa sinmi lórí ṣíṣe ìfẹ́ rẹ̀ àti bíbá a lọ láti fi ọkàn-àyà tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin sìn ín.
11. Èé ṣe tó fi yẹ kó o rántí ìbatisí rẹ àti ìjẹ́pàtàkì rẹ̀?
11 Máa rántí ìrìbọmi tó o ṣe gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí ìyàsímímọ́ àtọkànwá rẹ fún Ọlọ́run. Kì í ṣe ìrìbọmi tipátipá, nítorí ìwọ fúnra rẹ̀ lo ṣe ìpinnu náà. Ṣé o ti wá pinnu báyìí láti máa ṣe ohun tó wà níbàámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run ní gbogbo ìyókù ìgbésí ayé rẹ? O bẹ Ọlọ́run pé kó fún ọ ní ẹ̀rí ọkàn rere, o sì fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ rẹ hàn nípa ṣíṣe batisí. Pa ẹ̀rí ọkàn rere yẹn mọ́ nípa mímú ẹ̀jẹ́ ìyàsímímọ́ rẹ̀ ṣẹ. Ìbùkún Jèhófà yóò sì wà pẹ̀lú rẹ.—Òwe 10:22.
Ìfẹ́ Ọkàn Rẹ Kó Ipa Pàtàkì
12, 13. Báwo ni ìfẹ́ wa àtọkànwá ṣe tan mọ́ ìyàsímímọ́ àti ìbatisí?
12 Láìṣe àní-àní, ìyàsímímọ́ àti ìbatisí ti mú ìbùkún ńlá bá àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn jákèjádò ayé. Nígbà tá a fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ wa fún Ọlọ́run hàn nípa ṣíṣe ìrìbọmi, a kú sí ipa ọ̀nà ìgbésí ayé wa àtijọ́, àmọ́ ìyẹn ò mú ìfẹ́ ọkàn tiwa kúrò. Gẹ́gẹ́ bí onígbàgbọ́ tí a ti kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ dáadáa, ìfẹ́ tó wà lọ́kàn wa gan-an la tẹ̀ lé nígbà tá a ya ara wa sí mímọ́ fún Ọlọ́run nínú àdúrà, tí a sì ṣe batisí. Yíya ara wa sí mímọ́ fún Ọlọ́run àti ṣíṣe batisí béèrè pé ká mọ ohun tí ìfẹ́ Ọlọ́run jẹ́, ká sì yàn láti ṣe é látọkànwá. (Éfésù 5:17) Nípa bẹ́ẹ̀, a fara wé Jésù, ẹni tó ṣe ohun tí ọkàn rẹ̀ fẹ́ kó ṣe nígbà tó pa iṣẹ́ káfíńtà tì, tó ṣe batisí, tó sì yọ̀ǹda ara rẹ̀ pátápátá fún ṣíṣe ìfẹ́ Baba rẹ̀ ọ̀run.—Sáàmù 40:7, 8; Jòhánù 6:38-40.
13 Jèhófà Ọlọ́run pète pé Ọmọ òun yóò di “pípé nípasẹ̀ àwọn ìjìyà.” Nítorí náà Jésù ní láti ṣe ìpinnu àtọkànwá, kí ó bàa lè fi ìṣòtítọ́ fara da irú àwọn ìjìyà bẹ́ẹ̀. Láti ṣe èyí, ó ṣe “ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ àti ìtọrọ . . . pẹ̀lú igbe ẹkún kíkankíkan àti omijé, a sì gbọ́ ọ pẹ̀lú ojú rere nítorí ìbẹ̀rù rẹ̀ fún Ọlọ́run.” (Hébérù 2:10, 18; 5:7, 8) Bí a bá ní irú ìbẹ̀rù tó jinlẹ̀ bẹ́ẹ̀ fún Ọlọ́run, kí ó dá àwa náà lójú pé a óò ‘gbọ́ wa pẹ̀lú ojú rere,’ kò sì sí àní-àní pé Jèhófà yóò fẹsẹ̀ wa múlẹ̀ ṣinṣin gẹ́gẹ́ bí àwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ tó ti ya ara wọn sí mímọ́.—Aísáyà 43:10.
O Lè Ní Ọkàn-Àyà Tó Fẹsẹ̀ Múlẹ̀ Ṣinṣin
14. Èé ṣe tó fi yẹ ká máa ka Bíbélì lójoojúmọ́?
14 Kí ni yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ní ọkàn-àyà tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin, kí o sì tipa bẹ́ẹ̀ máa gbé níbàámu pẹ̀lú ìyàsímímọ́ rẹ fún Ọlọ́run? Máa ka Bíbélì lójoojúmọ́, kí o lè túbọ̀ máa gba ìmọ̀ kún ìmọ̀ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Èyí ni ohun tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ti ń rọ̀ wá ṣáá láti máa ṣe. Wọ́n ń fún wa nírú ìmọ̀ràn yẹn nítorí pé gbígbé níbàámu pẹ̀lú ìyàsímímọ́ wa ń béèrè pé ká máa rìn nínú òtítọ́ Ọlọ́run. Tó bá jẹ́ pé ètò àjọ Jèhófà mọ̀ọ́mọ̀ ń fi ẹ̀kọ́ èké kọ́ni ni, kò ní máa fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àtàwọn tí wọ́n ń wàásù fún nímọ̀ràn pé kí wọ́n máa ka Bíbélì.
15. (a) Kí ló yẹ ká gbé yẹ̀ wò nígbà tá a bá ń ṣe ìpinnu? (b) Kí nìdí tá a fi lè sọ pé iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ kọ́ niṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ fún àwọn Kristẹni?
15 Nígbà tó o bá ń ṣe ìpinnu, máa ronú lórí bí wọ́n ṣe lè nípa lórí mímú ẹ̀jẹ́ ìyàsímímọ́ rẹ sí Jèhófà ṣẹ. Èyí lè kan iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ rẹ. Ǹjẹ́ ò ń sapá láti jẹ́ kí ó ràn ọ́ lọ́wọ́ nínú mímú ìjọsìn tòótọ́ tẹ̀ síwájú? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn agbanisíṣẹ́ máa ń rí i pé àwọn Kristẹni tó ti ya ara wọn sí mímọ́ ṣeé fọkàn tán, wọ́n kì í sì í fiṣẹ́ ṣeré, wọ́n tún ti rí i pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í kánjú láti dé ipò ọlá nínú ayé, wọn kì í sì í bá àwọn ẹlòmíràn du ipò tó ń mówó wọlé jù lọ níbi iṣẹ́. Ìdí ni pé ohun tí àwọn Ẹlẹ́rìí ń lépa kì í ṣe kíkó ọrọ̀ jọ, lílókìkí, wíwà nípò iyì tàbí ipò agbára. Ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run lohun tó ṣe pàtàkì jù lọ lójú àwọn tó ń gbé níbàámu pẹ̀lú ìyàsímímọ́ wọn fún Ọlọ́run. Iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ tó ń mú kó ṣeé ṣe fún wọn láti ní àwọn ohun kòṣeémánìí inú ìgbésí ayé kọ́ niṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ, ipò kejì ni irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ wà. Bíi ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, olórí iṣẹ́ wọn ni iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni. (Ìṣe 18:3, 4; 2 Tẹsalóníkà 3:7, 8; 1 Tímótì 5:8) Ǹjẹ́ ò ń fi ire Ìjọba náà sípò kìíní nínú ìgbésí ayé rẹ?—Mátíù 6:25-33.
16. Kí la lè ṣe bí àwọn àníyàn tí kò ní láárí bá ń mú kó ṣòro fún wa láti máa gbé níbàámu pẹ̀lú ìyàsímímọ́ wa fún Ọlọ́run?
16 Ó ṣeé ṣe kí onírúurú àníyàn ti kó ìdààmú bá àwọn kan kí wọ́n tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Àmọ́, ẹ wo bí ọkàn wọn ṣe kún fún ayọ̀, ìmọrírì, àti ìfẹ́ fún Ọlọ́run tó nígbà tí wọ́n tẹ́wọ́ gba ìrètí Ìjọba náà! Ríronú lórí àwọn ìbùkún tí wọ́n ti rí gbà látìgbà yẹn lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti gbé níbàámu pẹ̀lú ìyàsímímọ́ wọn fún Jèhófà. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, bí àníyàn tí kò ní láárí lórí àwọn ìṣòro tó wọ́pọ̀ nínú ètò nǹkan ìsinsìnyí bá wá fẹ́ fún “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” pa, bí ẹ̀gún ṣe máa ń dí irúgbìn lọ́wọ́ kí ó má lè dàgbà débi tí yóò ti sèso ńkọ́? (Lúùkù 8:7, 11, 14; Mátíù 13:22; Máàkù 4:18, 19) Bí o bá kíyè sí i pé èyí ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹlẹ̀ sí ọ tàbí sí ìdílé rẹ, kó gbogbo àníyàn rẹ lé Jèhófà, kí o sì gbàdúrà pé kí ó ràn ọ́ lọ́wọ́ láti túbọ̀ ní ìfẹ́ àti ìmọrírì. Bí o bá ju ẹrù ìnira rẹ sọ́dọ̀ rẹ̀, yóò mẹ́sẹ̀ rẹ dúró, yóò sì fún ọ ní okun tí wàá fi máa sìn ín tayọ̀tayọ̀ pẹ̀lú ọkàn tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin.—Sáàmù 55:22; Fílípì 4:6, 7; Ìṣípayá 2:4.
17. Báwo ló ṣe lè ṣeé ṣe láti kojú àdánwò líle koko?
17 Máa gbàdúrà sí Jèhófà Ọlọ́run déédéé. O tiẹ̀ lè máa gbàdúrà bó o ṣe gbà á nígbà tó ò ń ya ara rẹ sí mímọ́ fún un. (Sáàmù 65:2) Nígbà tí ohun kan bá fẹ́ mú ọ ṣe ohun tí kò tọ́ tàbí bí o bá dojú kọ àdánwò líle koko, wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run, kí o sì gbàdúrà pé kí ó ràn ọ́ lọ́wọ́ láti tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà ọ̀hún. Máa rántí pé ìgbàgbọ́ ṣe pàtàkì, nítorí pé Jákọ́bù, ọmọ ẹ̀yìn kọ̀wé pé: “Bí ẹnikẹ́ni nínú yín bá ṣaláìní ọgbọ́n [láti fi kojú àdánwò kan], kí ó máa bá a nìṣó ní bíbéèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, nítorí òun a máa fi fún gbogbo ènìyàn pẹ̀lú ìwà ọ̀làwọ́ àti láìsí gíganni; a ó sì fi í fún un. Ṣùgbọ́n kí ó máa bá a nìṣó ní bíbéèrè nínú ìgbàgbọ́, láìṣiyèméjì rárá, nítorí ẹni tí ó bá ń ṣiyèméjì dà bí ìgbì òkun tí ẹ̀fúùfù ń bì, tí a sì ń fẹ́ káàkiri. Ní ti tòótọ́, kí ẹni yẹn má rò pé òun yóò rí ohunkóhun gbà lọ́dọ̀ Jèhófà; ó jẹ́ aláìnípinnu, aláìdúrósójúkan ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀.” (Jákọ́bù 1:5-8) Bí àdánwò kan bá fẹ́ dà bí èyí tó kọjá agbára wa, a lè ní ìdánilójú pé: “Kò sí ìdẹwò kankan tí ó ti bá yín bí kò ṣe ohun tí ó wọ́pọ̀ fún àwọn ènìyàn. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run jẹ́ olùṣòtítọ́, kì yóò sì jẹ́ kí a dẹ yín wò ré kọjá ohun tí ẹ lè mú mọ́ra, ṣùgbọ́n pa pọ̀ pẹ̀lú ìdẹwò náà, òun yóò tún ṣe ọ̀nà àbájáde kí ẹ lè fara dà á.”—1 Kọ́ríńtì 10:13.
18. Kí la lè ṣe bí ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo tó fara sin bá ń dí wa lọ́wọ́ àtigbé níbàámu pẹ̀lú ìyàsímímọ́ wa fún Jèhófà?
18 Bí ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo tó o fi pa mọ́ bá ń da ọkàn rẹ láàmú ńkọ́, tó sì ń dí ọ lọ́wọ́ àtigbé níbàámu pẹ̀lú ìyàsímímọ́ rẹ fún Ọlọ́run? Bí o bá ti ronú pìwà dà, mímọ̀ pé Jèhófà ‘kò ní tẹ́ńbẹ́lú ọkàn-àyà tí ó ní ìròbìnújẹ́ tí ó sì wó palẹ̀’ lè fi ọ́ lọ́kàn balẹ̀. (Sáàmù 51:17) Wá ìrànlọ́wọ́ àwọn Kristẹni alàgbà tí wọ́n jẹ́ onífẹ̀ẹ́, pẹ̀lú ìdánilójú pé àwọn náà—tí wọ́n ń fara wé Jèhófà—kò ní fọwọ́ yẹpẹrẹ mú ìfẹ́ ọkàn rẹ láti padà ní àjọṣe tí ó dára pẹ̀lú Baba rẹ ọ̀run. (Sáàmù 103:10-14; Jákọ́bù 5:13-15) Lẹ́yìn náà, pẹ̀lú okun tẹ̀mí tá a ti sọ dọ̀tun àti ọkàn-àyà fífẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin, wàá lè ṣe ipa ọ̀nà títọ́ fún ẹsẹ̀ rẹ, wàá sì lè gbé níbàámu pẹ̀lú ìyàsímímọ́ rẹ fún Ọlọ́run.—Hébérù 12:12, 13.
Máa Fi Ọkàn-Àyà Tó Fẹsẹ̀ Múlẹ̀ Ṣinṣin Sìn Nìṣó
19, 20. Èé ṣe tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa bá a lọ láti gbé níbàámu pẹ̀lú ìyàsímímọ́ wa?
19 Ní àwọn àkókò líle koko wọ̀nyí, a gbọ́dọ̀ tiraka láti gbé níbàámu pẹ̀lú ìyàsímímọ́ wa, ká sì máa bá a lọ láti fi ọkàn-àyà tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin sin Ọlọ́run. Jésù sọ pé: “Ẹni tí ó bá fara dà á dé òpin ni ẹni tí a ó gbà là.” (Mátíù 24:13) Níwọ̀n bí a tí ń gbé ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,” ìgbàkigbà ni òpin lè dé. (2 Tímótì 3:1) Yàtọ̀ síyẹn, kò sí ẹnikẹ́ni nínú wa tó lè fọwọ́ sọ̀yà pé a máa wà láàyè lọ́la. (Jákọ́bù 4:13, 14) Nítorí náà, ó ṣe pàtàkì pé ká máa bá a lọ láti gbé níbàámu pẹ̀lú ìyàsímímọ́ wa lónìí!
20 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tẹnu mọ́ èyí nínú lẹ́tà rẹ̀ kejì. Ó fi hàn pé bí àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run ṣe ṣègbé nínú Ìkún Omi, bẹ́ẹ̀ náà ni ayé ìṣàpẹẹrẹ, tàbí àwùjọ àwọn ènìyàn búburú, yóò pa run ní “ọjọ́ Jèhófà.” Pétérù wá là á mọ́lẹ̀ pé: “Irú ènìyàn wo ni ó yẹ kí ẹ jẹ́ nínú ìṣe ìwà mímọ́ àti àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run”! Ó tún rọ̀ wọ́n pé: ‘Ẹyin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, bí ẹ ti ní ìmọ̀ èyí tẹ́lẹ̀, ẹ ṣọ́ ara yín kí [àwọn olùkọ́ èké àti àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run] má bàa mú yín lọ, kí ẹ sì ṣubú kúrò nínú ìfẹsẹ̀múlẹ̀ ṣinṣin tiyín.’ (2 Pétérù 3:5-17) Á mà burú jáì o, bí ẹnì kan tó ti ṣe batisí bá di ẹni tó ṣáko lọ, tó sì parí ìgbésí ayé rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹni tó kùnà láti ní ọkàn-àyà tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin!
21, 22. Báwo ni ọ̀rọ̀ inú Sáàmù 57:7 ṣe já sí òtítọ́ nínú ọ̀ràn Dáfídì àti ti àwọn Kristẹni tòótọ́?
21 Ìpinnu rẹ láti gbé níbàámu pẹ̀lú ìyàsímímọ́ rẹ fún Ọlọ́run lè túbọ̀ lágbára sí i bí o bá ń rántí ọjọ́ ayọ̀ tí o ṣe batisí, tó o sì ń wá ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run kí ọ̀rọ̀ àti ìṣe rẹ lè máa mú ọkàn-àyà rẹ̀ yọ̀. (Òwe 27:11) Jèhófà kì í já àwọn ènìyàn rẹ̀ kulẹ̀, ó sì dájú pé ó yẹ ká jẹ́ olóòótọ́ sí i. (Sáàmù 94:14) Ó fi ìyọ́nú àti àánú hàn nípa sísọ ìmọ̀ àwọn ọ̀tá dòfo, ó sì dá Dáfídì nídè. Dáfídì mọrírì èyí gan-an, ó sì polongo bí ìfẹ́ tí òun ní sí Olùdáǹdè òun ti lágbára tó, tí ó sì dúró sán-ún. Pẹ̀lú ìmọ̀lára tó jinlẹ̀, ó kọ ọ́ lórin pé: “Ọkàn-àyà mi fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin, Ọlọ́run, ọkàn-àyà mi fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin. Ṣe ni èmi yóò máa kọrin, tí èmi yóò sì máa kọ orin atunilára.”—Sáàmù 57:7.
22 Bíi ti Dáfídì, àwọn Kristẹni tòótọ́ kò yẹsẹ̀ kúrò nínú ìfọkànsìn wọn fún Ọlọ́run. Pẹ̀lú ọkàn-àyà tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin, wọ́n gbà pé Jèhófà ni olùdáǹdè tó dá àwọn sí, wọ́n sì ń fi ayọ̀ kọrin ìyìn sí i. Bí ọkàn-àyà rẹ bá fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin, yóò gbára lé Ọlọ́run, ìrànlọ́wọ́ Rẹ̀ yóò sì jẹ́ kí o lè mú ẹ̀jẹ́ ìyàsímímọ́ rẹ ṣẹ. Dájúdájú, o lè dà bí “olódodo” tí onísáàmù kọrin nípa rẹ̀ pé: “Kì yóò fòyà ìhìn búburú pàápàá. Ọkàn-àyà rẹ̀ fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin, a gbé e lé Jèhófà.” (Sáàmù 112:6, 7) Pẹ̀lú ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run àti gbígbára lé e pátápátá, o lè gbé níbàámu pẹ̀lú ìyàsímímọ́ rẹ, kí o sì máa fi ọkàn-àyà tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin sin Jèhófà.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Èé ṣe tó fi yẹ ká máa bá a lọ láti gba ìmọ̀ pípéye látinú Bíbélì?
• Èé ṣe tó fi yẹ ká máa rántí ìrònúpìwàdà àti ìyílọ́kànpadà wa?
• Báwo la ṣe ń jàǹfààní látinú rírántí ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi wa?
• Kí ni yóò ràn wá lọ́wọ́ láti máa fi ọkàn-àyà tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin sin Jèhófà?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Ǹjẹ́ o dúró dáadáa nípa tẹ̀mí nípa kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Sísọ iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni di olórí iṣẹ́ wa ń ràn wá lọ́wọ́ láti máa fi ọkàn-àyà tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin sin Jèhófà