Ǹjẹ́ Ó Yẹ Kágbé Ìgbàgbọ́ Wa Ka Ọgbọ́n Orí?
Ǹjẹ́ Ó Yẹ Kágbé Ìgbàgbọ́ Wa Ka Ọgbọ́n Orí?
Olórí ilé ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn kan ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà kọ̀wé pé: “Àwọn tó ń sọ pé àwọn ‘lẹ́mìí ìsìn’ ti pọ̀ jù lóde òní. Ìdí náà gan-an tí wọ́n sì ń tìtorí rẹ̀ gba ọ̀ràn ẹ̀sìn kanrí kò ju pé wọn kì í fẹ́ ro orí wọn.” Ó wá fi kún un pé: “Wọ́n kàn fẹ́ gbé gbogbo nǹkan karí ‘ìgbàgbọ́ ni.’”
ÌṢÒRO tí èyí ti fà ni pé ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tó sọ pé àwọn gba ẹ̀kọ́ kan gbọ́ ni kì í ronú lórí ìdí tí wọ́n fi gbà á gbọ́, wọn kì í sì í ronú lórí bóyá ìgbàgbọ́ àwọn bọ́gbọ́n mu. Abájọ tí àwọn èèyàn kì í fẹ́ jíròrò ọ̀ràn ẹ̀sìn mọ́.
Ó bani nínú jẹ́ pé àwọn àṣà bíi lílo ère nínú ìjọsìn àti gbígba àdúrà àhásórí kì í jẹ́ kéèyàn lo làákàyè rẹ̀. Ó sì jọ pé àṣà wọ̀nyí àtàwọn ilé ìsìn gàgàrà-gàgàrà, àwọn fèrèsé aláwọ̀ mèremère, àtàwọn orin àgbọ́máleèlọ, nìkan ni àìmọye èèyàn ń tìtorí rẹ̀ ṣẹ̀sìn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ṣọ́ọ̀ṣì kan sọ pé Bíbélì làwọn gbé ìgbàgbọ́ àwọn kà, síbẹ̀ ìwàásù ‘gba Jésù gbọ́, a ó sì gbà ọ́ là’ tí wọ́n ń ṣe, kò jẹ́ káwọn èèyàn rí ìjẹ́pàtàkì kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní àkọ́jinlẹ̀. Ọ̀ràn àtifi ìlànà Kristẹni yanjú ìṣòro ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà tàbí ọ̀ràn ìṣèlú làwọn mìíràn ń wàásù ní tiwọn. Kí ni gbogbo èyí ti yọrí sí?
Ẹnì kan tó máa ń kọ̀wé nípa ọ̀ràn ẹ̀sìn sọ nípa ìṣòro tí èyí ti dá sílẹ̀ ní Àríwá Amẹ́ríkà, ó ní: “Ẹ̀sìn Kristẹni . . . ti wá di ẹ̀sìn àwọn aláfẹnujẹ́ lásán. Àwọn tó ń ṣe ẹ̀sìn ọ̀hún kò [sì] mọ nǹkan kan nípa ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn wọn.” Olùwádìí kan tiẹ̀ là á mọ́lẹ̀ pé Amẹ́ríkà ti di “orílẹ̀-èdè àwọn aláìmọ̀kan nípa Bíbélì.” Ká sòótọ́, ohun kan náà ló ń ṣẹlẹ̀ láwọn orílẹ̀-èdè yòókù tó ń pera wọn ní ẹlẹ́sìn Kristi. Ọ̀pọ̀ ẹ̀sìn mìíràn tí kì í ṣe Kristẹni wà, táwọn náà kì í jẹ́ káwọn èèyàn lo ọpọlọ wọn, tó jẹ́ pé orin wuuru, àdúrà tó ń dún bí ọfọ̀ àti onírúurú àṣàrò tó la ọ̀ràn awo lọ ni wọ́n máa ń rọ́ sáwọn èèyàn lágbárí, dípò tí wọn ì bá fi jẹ́ kí wọ́n ronú lọ́nà tó bọ́gbọ́n mu, tó sì yè kooro.
Àmọ́ o, àwọn èèyàn yìí kan náà, tí kì í bìkítà nípa bóyá òótọ́ ni ẹ̀kọ́ tí ẹ̀sìn wọn fi ń kọ́ wọn, máa ń ronú jinlẹ̀jinlẹ̀ lórí àwọn nǹkan mìíràn lójoojúmọ́. Ǹjẹ́ kò ṣe ọ́ ní kàyéfì pé ẹni tó ń yẹ aṣọ wò fínnífínní kó tó rà á lọ́jà, ìyẹn aṣọ tó máa gbó lọ́jọ́ kan o, tó bá dọ̀ràn ìsìn, òun kan náà ló tún máa fi àìbìkítà sọ pé, ‘Bó bá jẹ́ ẹ̀sìn tó dára lójú àwọn òbí mi nìyẹn, á jẹ́ pé ìyẹn náà ló dára lójú tèmi’?
Bó bá jẹ́ pé lóòótọ́ la fẹ́ ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́, ǹjẹ́ kò yẹ ká fara balẹ̀ ronú lórí bí ohun tá a gbà gbọ́ nípa Ọlọ́run ti jóòótọ́ tó? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nípa àwọn ẹlẹ́sìn kan nígbà ayé rẹ̀ pé wọ́n ní “ìtara fún Ọlọ́run; ṣùgbọ́n kì í ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ pípéye.” (Róòmù 10:2) A lè fi irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ wé ọmọ tí ìyá rẹ̀ sọ fún pé kó lọ ra òróró wá, àmọ́ tó lọ ra epo pupa nítorí pé kò fetí sí ohun tí ìyá rẹ̀ ní kó rà. Inú ọmọ náà lè dùn sí ohun tó rà, àmọ́ ǹjẹ́ ohun tó rà máa tẹ́ ìyá ọmọ náà lọ́rùn?
Kí ni Ọlọ́run ń fẹ́ nínú ìjọsìn tòótọ́? Bíbélì dáhùn, pé: “Èyí dára lọ́pọ̀lọpọ̀, ó sì ṣe ìtẹ́wọ́gbà lójú Olùgbàlà wa, Ọlọ́run, ẹni tí ó jẹ́ ìfẹ́ rẹ̀ pé kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.” (1 Tímótì 2:3, 4) Àwọn kan lè máa rò pé kò ṣeé ṣe láti ní irú ìmọ̀ yẹn pẹ̀lú bí ẹ̀sìn ṣe pọ̀ jáǹrẹrẹ lóde òní. Ṣùgbọ́n gbà á rò ná—bó bá jẹ́ pé ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé káwọn èèyàn ní ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́, ǹjẹ́ Ọlọ́run á tún fi ìmọ̀ ọ̀hún dù wọ́n? Bíbélì sọ pé kò ní ṣe bẹ́ẹ̀. Ó ní: “Bí ìwọ bá wá [Ọlọ́run], yóò jẹ́ kí o rí òun.”—1 Kíróníkà 28:9.
Báwo ni Ọlọ́run ṣe ń sọ ara rẹ̀ di mímọ̀ fún àwọn tó bá ń fi tọkàntọkàn wá a? Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e yóò dáhùn èyí.