Ǹjẹ́ O Rántí?
Ǹjẹ́ O Rántí?
Ǹjẹ́ o gbádùn kíka àwọn Ilé Ìṣọ́ tó jáde lẹ́nu àìpẹ́ yìí? Tóò, wò ó bí o bá lè dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e wọ̀nyí:
• Ètò wo la gbé ka Ìwàásù Lórí Òkè tó o lè máa tẹ̀ lé kí másùnmáwo bàa dín kù?
Lójoojúmọ́, o lè máa ka ọ̀kọ̀ọ̀kan lára lájorí ẹ̀kọ́ tí Jésù fi kọ́ni nínú ìwàásù yẹn tàbí àwọn ẹ̀kọ́ tó wà níbòmíràn nínú Ìwé Ìhìn Rere. Bó o bá ń ṣàṣàrò lórí ẹ̀kọ́ yẹn, tó o sì ń gbìyànjú láti fi sílò, ayọ̀ rẹ á pọ̀ sí i, másùnmáwo á sì dín kù.—12/15, ojú ìwé 12-14.
• Kí nìdí mẹ́ta pàtàkì tó fi yẹ káwọn alàgbà nínú ìjọ kọ́ àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ láti bójú tó àfikún ẹrù iṣẹ́?
Nítorí pé iye àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń pọ̀ sí i, à ń fẹ́ àwọn ọkùnrin púpọ̀ sí i tó ṣeé fẹrù iṣẹ́ lé lọ́wọ́, kí wọ́n lè ran àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe batisí lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú. Ọjọ́ orí àti àìlera ti ń dín ohun táwọn alàgbà ọlọ́jọ́ pípẹ́ lè ṣe kù báyìí. Àwọn alàgbà kan tó dáńgájíá tún ń gbé àwọn ẹrù iṣẹ́ kan yàtọ̀ sí ti ìjọ wọn. Fún ìdí yìí, ó lè má ṣeé ṣe fún wọn láti ráyè ṣe gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe tẹ́lẹ̀ nínú ìjọ tiwọn.—1/1, ojú ìwé 29.
• Báwo làwọn èèyàn ṣe ń gbẹ́kẹ̀ lé àwọn ọlọ́run tí kì í ṣe ẹni gidi?
Ọ̀pọ̀ ló ń sin àwọn ọlọ́run tí ẹ̀sìn wọ́n gbé kalẹ̀, àmọ́ tó wulẹ̀ jẹ́ àwọn ọlọ́run aláìlẹ́mìí tí kò lè gbani là, gẹ́gẹ́ bí Báálì kò ti lè gbani là nígbà ayé Èlíjà. (1 Àwọn Ọba 18:26, 29; Sáàmù 135:15-17) Àwọn mìíràn ti sọ àwọn gbajúgbajà òṣèré àtàwọn eléré ìdárayá dòrìṣà, àwọn tí kò lè fúnni ní ìrètí gúnmọ́ fún ọjọ́ ọ̀la. Ní ìyàtọ̀ pátápátá sí èyí, Jèhófà wà ní ti gidi, ó sì ń mú àwọn ète rẹ̀ ṣẹ.—1/15, ojú ìwé 3-5.
• Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ látinú irú ojú tí Kéènì fi wo ìkìlọ̀ tí Ọlọ́run fún un?
Ọlọ́run fún wa ní òmìnira láti ṣe ohun tó wù wá, a sì lè yàn láti ṣe ohun tó tọ́ dípò ṣíṣíwọ́ ṣíṣe rere, gẹ́gẹ́ bí Kéènì ti ṣe. Bíbélì tún fi hàn pé Jèhófà máa ń dá àwọn aláìronúpìwàdà lẹ́jọ́.—1/15, ojú ìwé 22-23.
• Kí nìdí tí ìmọ́tótó fi ṣe pàtàkì gan-an lóde òní?
Nítorí ìyípadà nínú ọ̀nà ìgbésí ayé àwọn èèyàn, ọ̀pọ̀ ni kò ráyè tọ́jú ilé bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́. Dídágunlá sí ìmọ́tótó lórí oúnjẹ àti omi lè ṣàkóbá fún ìlera wa. Láfikún sí ìmọ́tótó nípa tara, Bíbélì tún tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì ìmọ́tótó nípa tẹ̀mí, ní ti ìwà rere àti ní ti èrò orí.—2/1, ojú ìwé 3-6.
• Pọ́ọ̀lù sọ nípa àwọn ẹlẹ́rìí tó wà kí ẹ̀sìn Kristẹni tó dé, pé a kò ní “sọ wọ́n di pípé láìsí àwa.” Kí lọ̀rọ̀ yìí túmọ̀ sí? (Hébérù 11:40)
Nínú Ẹgbẹ̀rúndún tí ń bọ̀, Kristi àtàwọn arákùnrin rẹ̀ ẹni àmì òróró lọ́run, tí ń sìn bí ọba àti àlùfáà, yóò jẹ́ káwọn tí a óò jí dìde jàǹfààní nínú ìràpadà náà. Irú àwọn olóòótọ́ bẹ́ẹ̀ tá a mẹ́nu kàn nínú Hébérù orí kọkànlá la ó tipa bẹ́ẹ̀ ‘sọ di pípé.’—2/1, ojú ìwé 23.
• Kí ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó sọ fáwọn Hébérù pé: “Ẹ kò tíì dúró tiiri títí dé orí ẹ̀jẹ̀”? (Hébérù 12:4)
Ohun tó ń sọ ni fífaradà á dójú ikú. Ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ wà nínú ìtàn nípa àwọn tó ti ṣe olóòótọ́ dójú ikú. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Hébérù tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí kò tíì rí àdánwò tó le tó yẹn, ó yẹ kí wọ́n máa tẹ̀ síwájú títí wọ́n á fi dàgbà dénú, kí wọ́n gbé ìgbàgbọ́ wọn ró láti lè fara da ohun yòówù tó bá dé.—2/15, ojú ìwé 29.
• Kí nìdí tó fi yẹ ká yẹra fún sísọ pé àánú Jèhófà pẹ̀rọ̀ sí ìdájọ́ òdodo rẹ̀?
Láwọn èdè kan, “pẹ̀rọ̀” lè túmọ̀ sí rọ̀ lójú tàbí ká lọ́wọ́ kò. Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run ìdájọ́ òdodo àti àánú, nínú bó sì ṣe ń lo ànímọ́ méjèèjì yẹn, ńṣe ni wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ pọ̀. (Ẹ́kísódù 34:6, 7; Diutarónómì 32:4; Sáàmù 116:5; 145:9) Ìdájọ́ òdodo Jèhófà kò béèrè fífi àánú rọ̀ ọ́ lójú tàbí fífi pẹ̀rọ̀ sí i.—3/1, ojú ìwé 30.
• Ǹjẹ́ ó bójú mu kí Kristẹni jẹ́ kí wọ́n kun ẹbí rẹ̀ tó kú lọ́ṣẹ?
Kíkun òkú lọ́ṣẹ jẹ́ ọ̀nà tí wọ́n fi ń tọ́jú òkú kí ó má tètè jẹrà. Àwọn kan láyé àtijọ́ ń ṣe é nítorí ẹ̀sìn. Àwọn olùjọsìn tòótọ́ kò jẹ́ ṣe é nítorí ẹ̀sìn. (Oníwàásù 9:5; Ìṣe 24:15) Kíkun òkú lọ́ṣẹ kàn ń fawọ́ aago ohun tí kò lè ṣàì ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn ni, ìyẹn pípadà tí òkú yóò padà di ekuru. (Jẹ́nẹ́sísì 3:19) Àmọ́ kò sídìí fún dída ara wa láàmú bí òfin bá béèrè pé kí a kun òkú lọ́ṣẹ tàbí bí àwọn aráalé wa kan bá fẹ́ bẹ́ẹ̀ tàbí bó bá pọn dandan nítorí pé àwọn kan máa rin ọ̀nà jíjìn láti débi ìsìnkú náà.—3/15, ojú ìwé 19-31.
• Àwọn àpẹẹrẹ wo ló wà nínú Bíbélì tá a fi mọ̀ pé Ọlọ́run tẹ́wọ́ gba àwọn èèyàn látinú gbogbo orílẹ̀-èdè?
Jèhófà rán Jónà pé kó lọ kìlọ̀ fáwọn ará Nínéfè, Ọlọ́run sì rọ Jónà pé kó tẹ́wọ́ gba ìrònúpìwàdà wọn. Ní ọ̀rọ̀ àti ìṣe, Jésù fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ nínú fífi ìfẹ́ hàn sáwọn ará Samáríà. Àpọ́sítélì Pétérù àti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kópa nínú mímú ìhìn rere lọ fún àwọn tí kì í ṣe Júù. Àwọn àpẹẹrẹ bẹ́ẹ̀ fi hàn pé ó dáa ká máa gbìyànjú láti ran àwọn èèyàn láti onírúurú ipò lọ́wọ́.—4/1, ojú ìwé 21-24.