Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Ẹ Jẹ́ Kí A Máa Ṣe Ohun Rere sí Gbogbo Ènìyàn”

“Ẹ Jẹ́ Kí A Máa Ṣe Ohun Rere sí Gbogbo Ènìyàn”

“Ẹ Wá Sọ́dọ̀ Mi, . . . Èmi Yóò Sì Tù Yín Lára”

“Ẹ Jẹ́ Kí A Máa Ṣe Ohun Rere sí Gbogbo Ènìyàn”

IṢẸ́ wíwàásù àti kíkọ́ni ní ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ni olórí iṣẹ́ Jésù. (Máàkù 1:14; Lúùkù 8:1) Níwọ̀n bí àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi ti ń sapá láti fara wé e, wọ́n ka iṣẹ́ kíkọ́ni ní ìhìn Bíbélì nípa Ìjọba Ọlọ́run sí iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé wọn. (Lúùkù 6:40) Láìsí àní-àní, ó ń mú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́kàn yọ̀ bí a ti ń rí ìtura pípẹ́ títí tí ìhìn Ìjọba náà ń mú wá fáwọn tó tẹ́wọ́ gbà á—gẹ́gẹ́ bó ti rí nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé.—Mátíù 11:28-30.

Yàtọ̀ sí pé Jésù kọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó tún ṣe àwọn iṣẹ́ rere mìíràn, bíi mímú àwọn aláìsàn lára dá àti bíbọ́ àwọn tí ebi ń pa. (Mátíù 14:14-21) Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń fi iṣẹ́ ríran àwọn aláìní lọ́wọ́ kún iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n ń ṣe. Ó ṣe tán, “iṣẹ́ rere gbogbo” ni Ìwé Mímọ́ ń mú àwọn Kristẹni gbára dì fún, ó sì tún rọ̀ wọ́n láti “máa ṣe ohun rere sí gbogbo ènìyàn.”2 Tímótì 3:16, 17; Gálátíà 6:10.

“Àwọn Ará Wa Dúró Tì Wá Gbágbáágbá”

Ní September 1999, ìsẹ̀lẹ̀ ńlá kan wáyé lórílẹ̀-èdè Taiwan. Oṣù díẹ̀ lẹ́yìn náà ni wábi-wọ́sí òjò bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀, tí omíyalé sì fa ọ̀kan lára jàǹbá tó burú jáì nínú ìtàn orílẹ̀-èdè Venezuela. Lẹ́yìn ìyẹn tún ni ìkún omi ńlá kún bo orílẹ̀-èdè Mòsáńbíìkì. Nígbà ìṣẹ̀lẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí, kíá làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kó oúnjẹ, omi, oògùn, aṣọ, àgọ́ àtàwọn ohun ìdáná lọ síbi tí ìjábá wọ̀nyẹn ti ṣẹlẹ̀. Àwọn oníṣẹ́ ìṣègùn tó yọ̀ǹda ara wọn wá wọ̀rọ̀kọ̀ fi ṣàdá, wọ́n ṣètò àwọn ibùdó fún títọ́jú àwọn tó fara pa. Àwọn kọ́lékọ́lé tó yọ̀ǹda ara wọn sì kọ́ àwọn ilé tuntun fáwọn tí ìjábá wọ̀nyí sọ di aláìnílé.

Ìrànlọ́wọ́ àsìkò táwọn tó wà nínú ìṣòro wọ̀nyí rí gbà, wú wọn lórí gan-an. Malyori, tí omíyalé tó ṣẹlẹ̀ ní Venezuela, wó ilé rẹ̀, sọ pé: “Àwọn ará wa dúró tì wá gbágbáágbá, nígbà tá a wà nínú hílàhílo.” Lẹ́yìn tí àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni kọ́ ilé tuntun fún ìdílé Malyori, ohun tí obìnrin yìí sọ ni pé: “A dúpẹ́, a tún tọ́pẹ́ dá nítorí gbogbo ohun tí Jèhófà ṣe fún wa!” Nígbà tá a sì fún àwọn tí ìkún omi gbé ilé wọn lọ ní Mòsáńbíìkì ní kọ́kọ́rọ́ ilé wọn tuntun, ńṣe ni gbogbo wọn kàn bú sórin Ìjọba Ọlọ́run tó ní àkọlé náà “Jehofah Ni Ibi-Ìsádi Wa.” a

Ríran àwọn tó wà nínú ìṣòro lọ́wọ́ tún ń múnú àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn pàápàá dùn. Marcelo, tó ṣe iṣẹ́ nọ́ọ̀sì nínú ibùdó olùwá-ibi-ìsádi ní Mòsáńbíìkì sọ pé: “Inú mi dùn gan-an pé mo láǹfààní láti ṣèrànwọ́ fáwọn ará tó ti rí ìpọ́njú tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀.” Huang, tó yọ̀ǹda ara rẹ̀ nígbà tí ilẹ̀ sẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Taiwan sọ pé: “Ó jẹ́ ayọ̀ ńláǹlà láti nípìn-ín nínú kíkó oúnjẹ àti àwọn àgọ́ lọ fáwọn ará tó wà nínú ìṣòro. Ó fún ìgbàgbọ́ wa lókun.”

Ètò Ìyọ̀ǹda Ara Ẹni Tó Múná Dóko

Iṣẹ́ ìyọ̀ǹda ara ẹni tún ti mú ìtura tẹ̀mí wá fún ẹgbẹẹgbàárùn-ún àwọn ẹlẹ́wọ̀n kárí ayé. Lọ́nà wo? Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti pèsè àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fáwọn tó lé ní ọ̀kẹ́ kan àtààbọ̀ [30,000] tó ń ṣẹ̀wọ̀n ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ọgbà ẹ̀wọ̀n ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà nìkan. Kò tán síbẹ̀ o, níbi tó bá ti ṣeé ṣe, àwọn Ẹlẹ́rìí máa ń fúnra wọn lọ sáwọn ọgbà ẹ̀wọ̀n láti kọ́ àwọn ẹlẹ́wọ̀n lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọ́n á sì ṣe àwọn ìpàdé Kristẹni níbẹ̀. Ǹjẹ́ ó ń ṣàǹfààní fáwọn ẹlẹ́wọ̀n?

Àwọn ẹlẹ́wọ̀n kan tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti bẹ̀rẹ̀ sí sọ ohun tí wọ́n ń rí kọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí ń tuni lára fáwọn tí wọ́n jọ jẹ́ ẹlẹ́wọ̀n. Ìyọrísí èyí ni pé, nínú àwọn ọgbà ẹ̀wọ̀n mélòó kan kárí ayé, a ti rí àwọn àwùjọ ẹlẹ́wọ̀n tí wọ́n ń jọ́sìn Jèhófà pa pọ̀ báyìí. Ẹlẹ́wọ̀n kan ní Ìpínlẹ̀ Oregon, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ròyìn ní 2001, pé: “Àwùjọ wa ń pọ̀ sí i. A ti ní àwọn méje tó ń kéde Ìjọba Ọlọ́run. A sì ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì méjìdínlógójì. Àwọn tó ń wá sípàdé láti gbọ́ àsọyé fún gbogbo ènìyàn àti Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ lé ní mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n. Èèyàn mọ́kàndínlógójì ló sì pésẹ̀ síbi Ìṣe Ìrántí [ikú Kristi]. Èèyàn mẹ́ta ló máa ṣe ìrìbọmi láìpẹ́!”

Àwọn Àǹfààní àti Ayọ̀

Àwọn aláṣẹ ọgbà ẹ̀wọ̀n ti rí i pé ètò ìyọ̀ǹda ara ẹni yìí gbéṣẹ́. Àmọ́ o, ohun tó ń wú àwọn aláṣẹ lórí jù lọ ni àǹfààní pípẹ́ títí tí ètò ìyọ̀ǹda ara ẹni yìí ń ṣe. Ìròyìn kan sọ pé: “Láàárín ọdún mẹ́wàá tí ètò yìí ti ń bá a bọ̀, kò sí ẹnì kankan tó jáde lẹ́wọ̀n lẹ́yìn tó ṣèrìbọmi gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó tún padà sọ́gbà ẹ̀wọ̀n mọ́—ní ìfiwéra pẹ̀lú ìdá márùn-ún sí mẹ́fà tó ń padà wá lára àwọn àwùjọ yòókù.” Àlùfáà kan tó ń wàásù lọ́gbà ẹ̀wọ̀n ní Ìpínlẹ̀ Idaho, tí àṣeyọrí àwọn Ẹlẹ́rìí tó ń yọ̀ǹda ara wọn wú lórí gan-an, sọ nínú lẹ́tà kan tó kọ sí orílé iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan kò fara mọ́ ẹ̀kọ́ yín, síbẹ̀ ètò yín wú mi lórí gan-an ni.”

Ṣíṣèrànwọ́ fáwọn tó wà lẹ́wọ̀n tún ń mérè wá fáwọn tó yọ̀ǹda ara wọn. Lẹ́yìn tí ẹnì kan tó yọ̀ǹda ara rẹ̀ darí ìpàdé pẹ̀lú àwùjọ àwọn ẹlẹ́wọ̀n kan, tí wọ́n sì kọ orin Ìjọba Ọlọ́run fúngbà àkọ́kọ́, ó kọ̀wé pé: “Orí mi wú bí mo ti ń gbọ́ tí èèyàn méjìdínlọ́gbọ̀n jùmọ̀ ń kọrin ìyìn sí Jèhófà. Ohùn wọ́n sì ròkè lálá! Ẹ wo àǹfààní ńlá tó jẹ́ láti wà níbẹ̀!” Ẹnì kan tó yọ̀ǹda ara rẹ̀ láti máa bẹ àwọn ọgbà ẹ̀wọ̀n wò ní Ìpínlẹ̀ Arizona sọ pé: “Ìbùkún ńlá mà ni kíkópa nínú iṣẹ́ pàtàkì yìí jẹ́ o!”

Àwọn Ẹlẹ́rìí tó ń yọ̀ǹda ara wọn kárí ayé gbà tọkàntọkàn pé òótọ́ lọ̀rọ̀ Jésù, pé: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.” (Ìṣe 20:35) Wọ́n tún fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé títẹ̀lé ìmọ̀ràn Bíbélì láti máa ṣe ohun rere sí gbogbo èèyàn ń mú ìtura wa lóòótọ́.—Òwe 11:25.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo orin 85 nínú ìwé orin Kọrin Ìyìn si Jehofah, tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Venezuela

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Taiwan

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Mòsáńbíìkì