Gbin Òdodo, Kí O sì Ká Inú-Rere-Onífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run
Gbin Òdodo, Kí O sì Ká Inú-Rere-Onífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run
“O DÁJÚ pé ènìyàn yóò rí láburú nítorí pé ó lọ ṣe onídùúró fún àjèjì, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá kórìíra bíbọ ọwọ́ yóò wà láìní àníyàn.” (Òwe 11:15) Òwe tó ṣe ṣókí yìí mà kúkú jẹ́ kó ṣe kedere pé kò dáa kéèyàn tọwọ́ bọ ohun tápá ẹni ò ní ká o! Ẹni tó bá lọ ṣe onídùúró fẹ́ni tí ń yáwó ní ìyákúyàá, á rógun àfọwọ́fà. Yẹra fún bíbọ ọwọ́—tó dà bíi fífọwọ́ síwèé àdéhùn ní Ísírẹ́lì ìgbàanì—o ò sì ní dá gbèsè síra ẹ lọ́rùn.
Ní kedere, ìlànà tí ọ̀rọ̀ yìí dá lé lórí ni pé: “Ohun yòówù tí ènìyàn bá ń fúnrúgbìn, èyí ni yóò ká pẹ̀lú.” (Gálátíà 6:7) Hóséà wòlíì sọ pé: “Ẹ fún irúgbìn fún ara yín ní òdodo; ẹ kárúgbìn ní ìbámu pẹ̀lú inú-rere-onífẹ̀ẹ́.” (Hóséà 10:12) Àní sẹ́, gbin òdodo nípa ṣíṣe àwọn nǹkan lọ́nà Ọlọ́run, kí o sì ká inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́. Léraléra ni Sólómọ́nì Ọba Ísírẹ́lì lo ìlànà yìí láti fún wa níṣìírí tó fakíki pé ká máa gbé ìgbésẹ̀ tó tọ́, ká máa sọ ọ̀rọ̀ tí ń gbéni ró, ká sì máa ní èrò rere. Fífarabalẹ̀ ronú lórí ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tó sọ yóò fún wa níṣìírí ní tòótọ́ láti gbin irúgbìn òdodo fún ara wa.—Òwe 11:15-31.
Gbin ‘Òòfà Ẹwà,’ Kí O sì Ká “Ògo”
Ọlọgbọ́n ọba náà sọ pé: “Obìnrin olóòfà ẹwà ni ó di ògo mú; ṣùgbọ́n àwọn afìkà-gboni-mọ́lẹ̀, ní tiwọn, di ọrọ̀ mú.” (Òwe 11:16) Ẹsẹ yìí fi ìyàtọ̀ hàn láàárín ògo tí kì í ṣá, tí obìnrin olóòfà ẹwà, ìyẹn “obirin oloore-ọfẹ,” lè ní àti ọrọ̀ tí kì í tọ́jọ́, tí afìkà-gboni-mọ́lẹ̀ lè kó jọ.—Bibeli Mimọ.
Báwo lèèyàn ṣe lè ní òòfà ẹwà tí ń yọrí sí ògo? Sólómọ́nì gbà wá nímọ̀ràn pé: “Fi ìṣọ́ ṣọ́ ọgbọ́n tí ó gbéṣẹ́ àti agbára láti ronú, wọn yóò sì jẹ́ . . . òòfà ẹwà fún ọrùn rẹ.” (Òwe 3:21, 22) Onísáàmù sì sọ pé ‘a da òòfà ẹwà sí ètè ọba kan.’ (Sáàmù 45:1, 2) Bẹ́ẹ̀ ni o, ọgbọ́n tó gbéṣẹ́, agbára láti ronú àti sísọ ọ̀rọ̀ ọmọlúwàbí jáde lẹ́nu lè fi kún iyì àti òòfà ẹwà ẹni. Dájúdájú èyí ṣe pàtàkì gan-an fún obìnrin tó jẹ́ olóye. Àpẹẹrẹ irú obìnrin bẹ́ẹ̀ ni Ábígẹ́lì, aya Nábálì akúrí. Obìnrin náà “ní ọgbọ́n inú dáadáa, ó sì lẹ́wà ní ìrísí,” Dáfídì Ọba sì yìn ín nítorí “ìlóyenínú” rẹ̀.—1 Sámúẹ́lì 25:3, 33.
Ó dájú pé obìnrin olùfọkànsìn tó ní òòfà ẹwà tòótọ́ yóò gba ògo. Àwọn èèyàn á máa sọ̀rọ̀ rẹ̀ ní rere. Bó bá ti lọ́kọ, yóò níyì lójú ọkọ rẹ̀. Kódà, yóò mú ògo bá ìdílé rẹ̀ lódindi. Ògo rẹ̀ kò sì ní wọmi. “Orúkọ ni ó yẹ ní yíyàn dípò ọ̀pọ̀ yanturu ọrọ̀; ojú rere sàn ju fàdákà àti wúrà pàápàá.” (Òwe 22:1) Orúkọ rere tó ní lọ́dọ̀ Ọlọ́run kò ní bà jẹ́ láé.
Òwe 11:16, New International Version) Ìsọ̀wọ́ kan náà ni afìkà-gboni-mọ́lẹ̀ àtàwọn olubi àti ọ̀tá àwọn olùjọsìn Jèhófà wà. (Jóòbù 6:23; 27:13) Irú ẹni bẹ́ẹ̀ ‘kì í gbé Ọlọ́run ka iwájú rẹ̀.’ (Sáàmù 54:3) Irú ẹni bẹ́ẹ̀ lè “to fàdákà jọ pelemọ bí ekuru,” nípa kíkó àwọn aláìmọwọ́mẹsẹ̀ nífà àti fífojú wọn gbolẹ̀. (Jóòbù 27:16) Àmọ́, níjọ́ ọjọ́ kan, ó lè dùbúlẹ̀ kí ó má sì dìde, ọjọ́ tó bá sì jàjà lajú rẹ̀, ó lè jẹ́ àlàgbẹ̀yìn nìyẹn. (Jóòbù 27:19) Gbogbo ọrọ̀ àti àṣeyọrí rẹ̀ á sì wá já sí ìmúlẹ̀mófo.—Lúùkù 12:16-21.
Òdìkejì èyí ló máa ṣẹlẹ̀ sí afìkà-gboni-mọ́lẹ̀, ìyẹn ‘aláìlójú àánú.’ (Ẹ̀kọ́ pàtàkì mà ni Òwe 11:16 ń kọ́ wa yìí o! Láìfọ̀rọ̀ bọpo bọyọ̀, ọba Ísírẹ́lì jẹ́ ká rí ìyọrísí jíjẹ́ olóòfà ẹwà àti jíjẹ́ afìkà-gboni-mọ́lẹ̀, ó sì tipa báyìí rọ̀ wá pé ká gbin òdodo.
“Inú-Rere-Onífẹ̀ẹ́” Ń Mú Èrè Wá
Sólómọ́nì tún kọ́ wa ní ẹ̀kọ́ mìíràn nínú àjọṣepọ̀ ẹ̀dá, nígbà tó sọ pé: “Ènìyàn tí ó ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́ ń bá ọkàn ara rẹ̀ lò lọ́nà tí ń mú èrè wá, ṣùgbọ́n ìkà ènìyàn ń mú ìtanùlẹ́gbẹ́ wá bá ẹ̀yà ara òun fúnra rẹ̀.” (Òwe 11:17) Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan sọ pé: “Kókó pàtàkì inú òwe yìí ni pé ìṣesí wa sáwọn èèyàn, ì báà jẹ́ rere tàbí búburú, máa ń ní ìyọrísí tí a kò ní lọ́kàn tàbí tí a kò retí lórí wa.” Ẹ jẹ́ ká gbé ọ̀ràn ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ obìnrin kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Lisa yẹ̀ wò. a Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èèyàn dáadáa ni, kì í sábàá dé níye aago tó bá dá fáwọn èèyàn. Àìmọye ìgbà ló máa ń fi ọgbọ̀n ìṣẹ́jú tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ pẹ́ lẹ́yìn nígbà tó bá ṣètò láti bá àwọn mìíràn tí wọ́n jẹ́ akéde Ìjọba náà lọ sí òde ìwàásù. Lisa ń ṣe ara rẹ̀ ni. Ǹjẹ́ ó lè dẹ́bi fáwọn ẹlòmíràn bó bá sú wọn láti máa fàkókò gidi ṣòfò, tí wọn ò sì fẹ́ bá a ládèéhùn mọ́?
Ẹnì kan tó jẹ́ aṣefínnífínní-dóríi-bíńtín—tó fẹ́ ṣe ju agbára rẹ̀ lọ—kàn ń fìyà jẹ ara rẹ̀ ni. Nígbà tó jẹ́ pé ohun tí apá rẹ̀ ò ká láá máa nàgà sí nígbà gbogbo, kò sígbà tí kò ní tán ara rẹ̀ lókun, kò sì sígbà tí kò ní já ara rẹ̀ kulẹ̀. Ṣùgbọ́n, a ó ṣe ara wa láǹfààní bí a bá mọ̀wọ̀n ara wa, tá a sì ń lépa àwọn góńgó tí ọwọ́ wa lè tẹ̀. Bóyá nǹkan kì í tètè yé wa, bó ṣe ń tètè yé àwọn ẹlòmíràn. Tàbí kẹ̀, kí ó jẹ́ pé àìsàn tàbí ọjọ́ ogbó kò jẹ́ ká lè ṣe tó bá a ṣe fẹ́. Ẹ má ṣe jẹ́ kí agara dá wa bá a ṣe ń sapá láti tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí, àmọ́ ẹ jẹ́ ká máa fọgbọ́n ṣe ìwọ̀n tá a lè ṣe. Aláyọ̀ ni wá, bá a bá ‘ń sa gbogbo ipá wa,’ dé ibi tí agbára wa mọ.—2 Tímótì 2:15; Fílípì 4:5.
Ọlọgbọ́n ọba náà tún ṣàlàyé síwájú sí i nípa bí olódodo ṣe ń ṣe ara rẹ̀ láǹfààní, ṣùgbọ́n tí ìkà ènìyàn ń ṣe ara rẹ̀ léṣe. Ó sọ pé: “Ẹni burúkú ń pa owó ọ̀yà èké, ṣùgbọ́n ẹni tí ń fúnrúgbìn òdodo, ń jẹ èrè òótọ́. Ẹni tí ó dúró gbọn-in gbọn-in fún òdodo wà ní ìlà fún ìyè, ṣùgbọ́n ẹni tí ń lépa ohun búburú wà ní ìlà fún ikú ara rẹ̀. Àwọn oníwà wíwọ́ ní ọkàn-àyà jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú Jèhófà, ṣùgbọ́n àwọn aláìlẹ́bi ní ọ̀nà wọn jẹ́ ìdùnnú rẹ̀. Bí ọwọ́ tilẹ̀ wọ ọwọ́, ènìyàn búburú kì yóò lọ láìjìyà; ṣùgbọ́n ọmọ àwọn olódodo yóò yèbọ́ dájúdájú.”—Òwe 11:18-21.
Onírúurú ọ̀nà ni ẹsẹ wọ̀nyí fi tẹnu mọ́ kókó pàtàkì náà, pé: Gbin òdodo, kí o sì jẹ èrè rẹ̀. Ẹni ibi lè máa ṣe màkàrúrù tàbí kí ó máa ta tẹ́tẹ́ nítorí pé ó ń wá ìfà. Nígbà tó sì jẹ́ pé ẹní ń wá ìfà ń wá òfò ni, kò sígbà tí kò ní pàdánù. Ẹni tó ń fi tọkàntara ṣiṣẹ́ láìṣàbòsí ló ń gba owó tó ní àlùbáríkà nítorí pé ó ní ìfọ̀kànbalẹ̀. Aláìlẹ́bi yóò ní ìyè àìnípẹ̀kun nítorí pé ó rí ojú rere Ọlọ́run. Àmọ́ kí ni ìpín ẹni búburú? “Bí ọwọ́ tilẹ̀ wọ ọwọ́” nínú ṣíṣe àdàkàdekè, ẹni ibi kò ní lọ láìjìyà. (Òwe 2:21, 22) Ẹ ò rí i pé ọ̀rọ̀ ìyànjú àtàtà ni pé ká gbin òdodo!
Onílàákàyè Ló Ní Ẹwà Tòótọ́
Sólómọ́nì ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Gẹ́gẹ́ bí òrùka imú oníwúrà ní imú ẹlẹ́dẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni obìnrin tí ó Òwe 11:22) Òrùka imú jẹ́ ohun ọ̀ṣọ́ ìgbàlódé lákòókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì. Òrùka imú tá a fi wúrà ṣe, tí obìnrin kan tì bọ ẹ̀bá imú tàbí tó wà lórí igi imú rẹ̀, jẹ́ ohun ọ̀ṣọ́ táwọn èèyàn máa tètè rí. Ẹ ò rí i pé kò bójú mu rárá láti fi irú ohun ọ̀ṣọ́ iyebíye bẹ́ẹ̀ símú ẹlẹ́dẹ̀! Bẹ́ẹ̀ gan-an lọ̀ràn rí fẹ́ni tó lẹ́wà ní ìrísí, àmọ́ tí kò ní ‘òye.’ Onítọ̀hún ì báà jẹ́ ọkùnrin tàbí obìnrin, irú rẹ̀ kọ́ là ń ṣọ̀ṣọ́ sí lára. Ohun ọ̀ṣọ́ ò tiẹ̀ yẹ ẹ́ ni.
jẹ́ arẹwà, ṣùgbọ́n tí ó yí padà kúrò nínú ìlóyenínú.” (Òótọ́ ni pé a máa ń ṣàníyàn nípa èrò táwọn èèyàn ní nípa ìrísí wa. Àmọ́ kí nìdí tí a ó fi jẹ́ kí ìrísí wa ká wa lára ju bó ṣe yẹ lọ tàbí ká máa dààmú jù nípa rẹ̀? A ò lè rí nǹkan ṣe sí bí àwọn ẹ̀yà ara wa kan ṣe rí. Ìrísí kọ́ ló jà jù. Ǹjẹ́ òótọ́ kọ́ ni pé ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn tá a fẹ́ràn, tí wọ́n sì níyì lójú wa kì í kúkú ṣe àwọn tí ìrísí wọn ta yọ? Ẹwà ojú kọ́ ló ń fúnni láyọ̀. Ohun tó jà jù ni ẹwà ti inú, tó ń jẹ yọ látinú àwọn ànímọ́ tí kì í ṣá, tí í ṣe irú àwọn ànímọ́ tí Ọlọ́run ní. Fún ìdí yìí, ǹjẹ́ kí a jẹ́ onílàákàyè, ká sì máa sapá láti ní irú àwọn ànímọ́ bẹ́ẹ̀.
“A Óò Mú Ọkàn Tí Ó Lawọ́ Sanra”
Sólómọ́nì Ọba sọ pé: “Ìfẹ́-ọkàn àwọn olódodo dára dájúdájú; ìrètí àwọn ẹni burúkú jẹ́ ìbínú kíkan.” Láti fi hàn pé bẹ́ẹ̀ gan-an lọ̀ràn rí, ó fi kún un pé: “Ẹnì kan wà tí ń fọ́n ká, síbẹ̀síbẹ̀ ó ń pọ̀ sí i; àti ẹni tí ń fawọ́ sẹ́yìn kúrò nínú ohun tí ó tọ́, ṣùgbọ́n àìní nìkan ni ó ń yọrí sí.”—Òwe 11:23, 24.
Bá a ṣe ń sapá kárakára láti fọ́n ìmọ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ká, lédè mìíràn, tá à ń pín ìmọ̀ yẹn fáwọn ẹlòmíràn, ó dájú pé ńṣe la óò túbọ̀ máa lóye “ìbú àti gígùn àti gíga àti jíjìn” rẹ̀. (Éfésù 3:18) Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ẹni tí kò lo ìmọ̀ rẹ̀ lè pàdánù ìmọ̀ tó ní. Dájúdájú, “ẹni tí ó bá ń fúnrúgbìn kín-ún yóò ká kín-ún pẹ̀lú; ẹni tí ó bá sì ń fúnrúgbìn yanturu yóò ká yanturu pẹ̀lú.”—2 Kọ́ríńtì 9:6.
Ọba náà ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “A óò mú ọkàn tí ó lawọ́ sanra [láásìkí], ẹni tí ó sì ń bomi rin àwọn ẹlòmíràn ní fàlàlà, a ó bomi rin òun náà ní fàlàlà.” (Òwe 11:25) Inú Jèhófà á dùn sí wa gan-an bá a bá fi ìwà ọ̀làwọ́ lo àkókò àti ohun ìní wa láti fi ṣètìlẹyìn fún ìjọsìn tòótọ́. (Hébérù 13:15, 16) Jèhófà ‘yóò ṣí ibodè ibú omi ọ̀run fún wa, yóò sì tú ìbùkún dà sórí wa ní ti tòótọ́ títí kì yóò fi sí àìní mọ́.’ (Málákì 3:10) Ẹ sáà wo aásìkí tẹ̀mí táwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ní lónìí!
Sólómọ́nì tún mú àpẹẹrẹ míì wá nípa bí ìgbésẹ̀ àwọn olódodo ṣe yàtọ̀ sí tàwọn olubi, ó sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń fawọ́ ọkà sẹ́yìn—àwọn ènìyàn ìlú yóò fi í bú, ṣùgbọ́n ìbùkún ń bẹ fún orí ẹni tí ó jẹ́ kí a máa rà á.” (Òwe 11:26) Èèyàn lè jèrè àjẹpajúdé bó bá kọ́kọ́ ra gbogbo ọjà tó wà nílẹ̀ lówó pọ́ọ́kú, tó wá kó o pa mọ́ dìgbà tí kò ní sí mọ́, kó tó bẹ̀rẹ̀ sí tà á lówó gegere. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó dáa láti máa ṣún nǹkan lò, kéèyàn sì mọ bá a ṣe ń tọ́jú nǹkan pa mọ́, síbẹ̀ àwọn èèyàn kì í fojú rere wo onímọtara-ẹni-nìkan tó kó ọjà pa mọ́ torí àtijèrè àjẹpajúdé. Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, àwọn èèyàn á súre fún ẹni tí kì í tìtorí pé àwọn èèyàn ti há, kó wá sọjà dọ̀wọ́n.
Nígbà tí ọba Ísírẹ́lì ń rọ̀ wá pé ká máa lépa ohun rere, ìyẹn ohun tó tọ́, ó sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń wá ohun rere yóò máa bá a nìṣó ní wíwá ìfẹ́ rere; ṣùgbọ́n ní ti ẹni tí ń wá ohun búburú káàkiri, yóò wá sórí rẹ̀. Ẹni tí ó bá gbẹ́kẹ̀ lé ọrọ̀ rẹ̀—òun fúnra rẹ̀ yóò ṣubú; ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹ̀ka eléwé ni olódodo yóò máa gbilẹ̀.”—Òwe 11:27, 28.
Olódodo Ń Jèrè Ọkàn
Láti fi hàn pé ìwà òmùgọ̀ kì í bímọ re, Sólómọ́nì sọ pé: “Ní ti ẹnikẹ́ni tí ó bá mú ìtanùlẹ́gbẹ́ wá bá ilé ara rẹ̀, ẹ̀fúùfù ni yóò ní.” (Òwe 11:29a) Ẹ̀ṣẹ̀ Ákáánì ‘mú ìtanùlẹ́gbẹ́ wá sórí rẹ̀,’ wọ́n sì sọ òun àtàwọn aráalé rẹ̀ lókùúta pa. (Jóṣúà, orí 7) Lóde òní, olórí agboolé Kristẹni kan àtàwọn mìíràn nínú ìdílé rẹ̀ lè dá ẹ̀ṣẹ̀ tó mú ká yọ wọ́n kúrò nínú ìjọ Kristẹni. Èèyàn lè mú ìtanùlẹ́gbẹ́ wá sórí ilé ara rẹ̀ bí òun alára bá kùnà láti pa àwọn àṣẹ Ọlọ́run mọ́, tó sì fàyè gba ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo nínú ìdílé rẹ̀. Ìjọ Kristẹni lè ṣíwọ́ bíbá òun, àti bóyá àwọn mìíràn nínú ìdílé rẹ̀ pẹ̀lú kẹ́gbẹ́, nítorí pé wọ́n jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ tí kò ronú pìwà dà. (1 Kọ́ríńtì 5:11-13) Kí wá ni èrè rẹ̀? Ẹ̀fúùfù lásán ni—kò lè rí nǹkan gidi tó níye lórí jèrè.
Ìyókù ẹsẹ náà kà pé: “Òmùgọ̀ ènìyàn sì ni yóò jẹ́ ìránṣẹ́ ẹni tí ó gbọ́n ní ọkàn-àyà.” (Òwe 11:29b) Níwọ̀n bí òmùgọ̀ èèyàn kò ti lọ́gbọ́n lórí, a kò lè gbé ẹrù iṣẹ́ lé e lọ́wọ́. Ìyẹn nìkan kọ́ o, àìmète-mèrò nínú ọ̀ràn ara rẹ̀ lè jẹ́ kí ó wọ wàhálà lọ́dọ̀ àwọn ẹlòmíràn, lọ́nà kan tàbí òmíràn. Irú aláìlọ́gbọ́n bẹ́ẹ̀ lè di “ìránṣẹ́ ẹni tí ó gbọ́n ní ọkàn-àyà.” Nítorí náà, ó ṣe pàtàkì pé ká máa lo ọgbọ́n àti làákàyè nínú gbogbo ohun tí a bá ń ṣe.
Ọlọgbọ́n ọba náà mú un dá wa lójú pé: “Èso olódodo jẹ́ igi ìyè, ẹni tí ó bá sì ń jèrè àwọn ọkàn jẹ́ ọlọ́gbọ́n.” (Òwe 11:30) Báwo lèyí ṣe ń ṣẹlẹ̀? A mọ̀ pé olódodo máa ń tu àwọn èèyàn lára nípa tẹ̀mí nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe rẹ̀. Ó máa ń fún wọn níṣìírí láti sin Jèhófà, wọ́n sì lè jèrè ìyè tí Ọlọ́run ṣèlérí ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀.
‘Ẹlẹ́ṣẹ̀ Yóò Jèrè Iṣẹ́ Ọwọ́ Rẹ̀ Jù Bẹ́ẹ̀ Lọ’
Àwọn òwe tá a mẹ́nu kàn lókè yìí mà kúkú gbà wá níyànjú láti gbin òdodo o! Sólómọ́nì sọ ọ̀rọ̀ mìíràn tó fi hàn pé ìlànà náà, “ohun yòówù tí ènìyàn bá ń fúnrúgbìn, èyí ni yóò ká,” tún wúlò lọ́nà mìíràn, ó sọ pé: “Wò ó! Olódodo—ilẹ̀ ayé ni a ó ti san án lẹ́san. Mélòómélòó ni ó yẹ kí ẹni burúkú àti ẹlẹ́ṣẹ̀ rí bẹ́ẹ̀!”—Òwe 11:31.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé olódodo máa ń sapá láti ṣe ohun tó tọ́, ó máa ń ṣàṣìṣe nígbà míì. (Oníwàásù 7:20) A ó sì “san án lẹ́san” nítorí àṣìṣe rẹ̀, ìyẹn ni pé a óò fún un ní ìbáwí. Ẹni burúkú wá ńkọ́, tó jẹ́ pé ńṣe ló mọ̀ọ́mọ̀ yàn láti tọ ipa ọ̀nà búburú, tí kò sì fẹ́ tọ ọ̀nà títọ́? Ǹjẹ́ kò yẹ kí ‘ẹ̀san’ tirẹ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ—àní kí ó jẹ àjẹkún ìyà? Àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé pé: “Bí ó bá . . . jẹ́ pé agbára káká ni a fi ń gba olódodo là, níbo ni aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run àti ẹlẹ́ṣẹ̀ yóò gbé yọjú?” (1 Pétérù 4:18) Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká pinnu pé a óò máa ṣe ara wa láǹfààní nígbà gbogbo nípa gbígbin irúgbìn òdodo.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí orúkọ onítọ̀hún padà.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
‘Òòfà ẹwà’ jẹ́ kí Ábígẹ́lì gba “ògo”
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]
‘Ẹni burúkú ń pa owó ọ̀yà èké, ṣùgbọ́n olódodo ń jẹ èrè òótọ́’
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
‘Fúnrúgbìn yanturu, kí o sì kárúgbìn yanturu’