Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ibo Ni Gbogbo Àwọn Aládùúgbò Wa Lọ?

Ibo Ni Gbogbo Àwọn Aládùúgbò Wa Lọ?

Ibo Ni Gbogbo Àwọn Aládùúgbò Wa Lọ?

“Àwùjọ òde òní ò ka jíjẹ́ aládùúgbò sí ohunkóhun.”—Benjamin Disraeli, òṣèlú ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tó gbé ayé ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún.

ÀWỌN tó jẹ́ arúgbó lára àwọn ará Cuba ní ọ̀nà àrà ọ̀tọ̀ tí wọ́n gbà ń mú kí ìlera wọn sunwọ̀n sí i: nípa àjọṣepọ̀ láàárín àwọn aládùúgbò tàbí ẹgbẹ́ àwọn òbí àgbà, bí wọ́n ṣe máa ń pè wọ́n. Gẹ́gẹ́ bí ohun tó wà nínú ìròyìn ọdún 1997, nǹkan bí ọ̀kan nínú àwọn arúgbó márùn-ún ló wà nínú irú ẹgbẹ́ yẹn, níbi tí wọ́n ti ń rí alábàákẹ́gbẹ́, alátìlẹyìn, àti ojúlówó ìrànlọ́wọ́ kí wọ́n lè máa gbé ìgbésí ayé lọ́nà tó lè mú kí ìlera wọn sunwọ̀n sí i. Ìwé ìròyìn World-Health sọ pé: “Ìgbàkigbà táwọn oníṣègùn tó ń tọ́jú ìdílé ládùúgbò bá nílò ìrànlọ́wọ́ láti jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ nípa abẹ́rẹ́ àjẹsára kan, inú ẹgbẹ́ àwọn òbí àgbà ni wọ́n ti ń rí àwọn tó múra tán tí wọ́n sì dáńgájíà láti ṣèrànwọ́.”

Àmọ́ ṣá o, ó ṣeni láàánú pé ní apá ibi púpọ̀ lórí ilẹ̀ ayé, àwọn àgbègbè kan ò ní irú àwùjọ tó bìkítà bẹ́ẹ̀ mọ́. Bí àpẹẹrẹ, wo ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń bani nínú jẹ́ tó ṣẹlẹ̀ sí Wolfgang Dircks, tó ń gbé inú ilé kan ní ìwọ̀ oòrùn Yúróòpù. Ní ọdún bíi mélòó kan sẹ́yìn, ìwé ìròyìn The Canberra Times ròyìn pé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìdílé mẹ́tàdínlógún tó ń gbénú ilé kan náà pẹ̀lú Wolfgang ti ṣàkíyèsí pé àwọn ò rí i mọ́, síbẹ̀ “kò sẹ́ni tó ronú pé kóun tiẹ̀ tẹ aago ẹnu ọ̀nà rẹ̀ wò.” Ìgbà tí onílé wá ṣílẹ̀kùn ibẹ̀ nígbẹ̀yìngbẹ́yín, “ló bá eegun èèyàn tó wà lórí ìjókòó níwájú tẹlifíṣọ̀n.” Àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ ohun tí wọ́n máa ṣe lórí tẹlifíṣọ̀n ní December 5, 1993 ló wà nínú àwọn ìwé tó bá lórí itan eegun èèyàn náà. Wolfgang ti kú láti ọdún márùn-ún sẹ́yìn. Ẹ ò rí i pé ọ̀rọ̀ burúkú gbáà lèyí, tó fi hàn pé kò sóhun tó ń jẹ́ ìfẹ́ àti ìbìkítà láàárín àwọn aládùúgbò mọ́! Abájọ tí aláròkọ kan fi kọ ọ́ sínú ìwé ìròyìn The New York Times Magazine pé àdúgbò òun, bíi tí ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn ti di “àwùjọ àwọn àjèjì.” Ṣé bí àdúgbò tìrẹ náà ṣe rí nìyẹn?

Òótọ́ ni pé àwọn abúlé kan ṣì ń gbádùn ìfẹ́ aládùúgbò àti pé àwọn àdúgbò kan láàárín ìlú ń tiraka láti túbọ̀ máa ṣàníyàn nípa àwọn aládùúgbò wọn. Síbẹ̀síbẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn tó ń gbé ìlú ńlá ló ń nímọ̀lára pé àwọn dá nìkan wà àti pé ewú lè wu wọ́n ládùúgbò tiwọn fúnra wọn. Wọn ò wá ní í jẹ́ káwọn ará àdúgbò mọ̀ wọ́n. Lọ́nà wo?

Ṣíṣàì Jẹ́ Kí Ará Àdúgbò Mọni

Dájúdájú, ọ̀pọ̀ jù lọ wa ló láwọn aládùúgbò tá a jọ ń gbé nítòsí ara wa. Iná tẹlifíṣọ̀n tó ń ṣe wìrìwìrì, òjìji èèyàn tá à ń rí lójú fèrèsé, iná mànàmáná tí wọ́n ń tàn tí wọ́n ń pa, dídún àwọn ọkọ̀ tó ń wọlé àtàwọn tó ń jáde, ìró ẹsẹ̀ àwọn èèyàn ní gbàgede, gbígbọ́ ìró kọ́kọ́rọ́ báwọn èèyàn ṣe ń ṣílẹ̀kùn tí wọ́n sì ń tì í jẹ́ àmì pé àwọn aládùúgbò wa ṣì “wà níbẹ̀.” Àmọ́, ojúlówó ìfẹ́ aládùúgbò gan-an máa ń pòórá nígbà táwọn tó ń gbé nítòsí ara ò bá mọ ara wọn dunjú tàbí tí wọn kì í rójú ara wọn nílẹ̀ nítorí kòókòó jàn-ánjàn-án ojoojúmọ́. Àwọn kan lè ronú pé kò pọn dandan káwọn sọ ara àwọn di ojúlùmọ̀ àwọn aládùúgbò àwọn tàbí káwọn tiẹ̀ ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú wọn pàápàá. Ìwé ìròyìn Herald Sun ti ilẹ̀ Ọsirélíà sọ pé: “Àwọn èèyàn ò tiẹ̀ fẹ́ sọ ara wọn di ojúlùmọ̀ àwọn tí wọ́n jọ ń gbé inú ilé kan náà mọ́, èyí sì ń jẹ́ kí àjọṣe ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà jó àjórẹ̀yìn. Ó ti wá rọrùn láti pa àwọn tí ò gbọ́ fáàrí tì báyìí.”

Ìṣẹ̀lẹ̀ tuntun yìí kò yani lẹ́nu rárá. Nínú ayé kan tí àwọn èèyàn ti jẹ́ “olùfẹ́ ara wọn,” àdúgbò kọ̀ọ̀kan ti ń kórè àbájáde ọ̀nà ìgbésí ayé anìkànjọpọ́n tí ọ̀pọ̀ ń gbé. (2 Tímótì 3:2) Àbájáde rẹ̀ ni ìnìkanwà àti ìyara-ẹni-nípa tó gbòde kan. Ìyara-ẹni-nípa kì í jẹ́ káwọn èèyàn lè fọkàn tán ara wọn, àgàgà nígbà tí ìwà ipá àti ìwà ọ̀daràn bá ń ṣẹlẹ̀ léraléra ládùúgbò. Tó bá yá, àìfọkàn-tán-ara-wọn kò ní jẹ́ kí wọ́n lè ṣàánú ara wọn mọ́.

Bó ti wù kí ọ̀ràn náà rí ládùúgbò tìrẹ, kò sí bó ò ṣe ní gbà pé ohun iyebíye làwọn aládùúgbò rere jẹ́ láwùjọ. Ohun púpọ̀ la lè ṣe láṣeyọrí nígbà táwọn èèyàn bá jọ ń lépa ohun kan náà. Àwọn aládùúgbò rere tún lè jẹ́ ìbùkún pàápàá. Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e yóò fi bó ṣe rí bẹ́ẹ̀ hàn.