Ìtumọ̀ “Septuagint”—Wúlò Láyé Ọjọ́un àti Lóde Òní
Ìtumọ̀ “Septuagint”—Wúlò Láyé Ọjọ́un àti Lóde Òní
ỌLỌ́LÁ kan tó jẹ́ ọmọ Etiópíà ń darí bọ̀ wálé láti Jerúsálẹ́mù. Ó ń ka àkájọ ìwé ìsìn kan sókè ketekete bó ṣe wà nínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀ lójú ọ̀nà aṣálẹ̀ tó ń gbà lọ sílé. Àlàyé ohun tó kà wọ̀ ọ́ lọ́kàn gan-an débi pé ìgbésí ayé rẹ̀ yí padà látìgbà yẹn lọ. (Ìṣe 8:26-38) Aísáyà 53:7, 8, lọkùnrin yìí ń kà ní èdè àkọ́kọ́ tá a tú Bíbélì sí—ìyẹn ìtumọ̀ Septuagint lédè Gíríìkì. Ìtumọ̀ yìí kópa tó ga nínú títan ìsọfúnni inú Bíbélì kálẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún, ìdí rèé tí wọ́n fi ń pè é ní ìtumọ̀ Bíbélì tó yí ayé padà.
Ìgbà wo ni wọ́n ṣe ìtumọ̀ Septuagint, báwo sì ni ipò nǹkan ṣe rí nígbà náà? Èé ṣe tí irú ìtumọ̀ yìí fi ṣe pàtàkì? Báwo ló ti ṣe wúlò tó láti ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún wá? Tí ohun kan bá wà tí ìtumọ̀ Septuagint lè kọ́ wa lóde òní, kí lohun náà?
Àwọn Júù Tó Ń Sọ Èdè Gíríìkì La Kọ Ọ́ Fún
Nígbà tí Alẹkisáńdà Ńlá yan wọ Íjíbítì lẹ́yìn tó pa ìlú àwọn ará Fòníṣíà tí à ń pè ní Tírè run lọ́dún 332 ṣáájú Sànmánì Tiwa, ńṣe làwọn èèyàn ń fayọ̀ pàdé rẹ̀ láti dúpẹ́ pé ó dá wọn nídè. Ibẹ̀ ló ti tẹ ìlú Alẹkisáńdíríà dó, tí í ṣe ojúkò ẹ̀kọ́ kíkọ́ láyé ọjọ́un. Alẹkisáńdà fẹ́ kọ́ àwọn èèyàn tó wà ní ilẹ̀ tí ó ṣẹ́gun náà ní àṣà ìbílẹ̀ Gíríìkì, èyí ló fi ní káwọn èèyàn máa sọ èdè Gíríìkì ní gbogbo ibi tó ń ṣàkóso lé lórí.
Nígbà tó fi máa di ọ̀rúndún kẹta ṣááju Sànmánì Tiwa, àwọn Júù tó wà nílùú Alẹkisáńdíríà ti pọ̀ gan-an. Ọ̀pọ̀ àwọn Júù tó tẹ̀ dó káàkiri àgbègbè Palẹ́sìnì lẹ́yìn táwọn ará Bábílónì kó wọn nígbèkùn ló ṣí wá sílùú Alẹkisáńdíríà. Báwo làwọn Júù yìí ṣe gbọ́ èdè Hébérù tó? Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Cyclopedia tí McClintock àti Strong ṣe, sọ pé: “Ọ̀pọ̀ èèyàn ló mọ̀ pé lẹ́yìn táwọn Júù padà dé láti oko ẹrú Bábílónì, wọn ò fi bẹ́ẹ̀ gbọ́ ìjìnlẹ̀ èdè Hébérù mọ́. Èdè àwọn ará Kálídíà ni wọ́n fi ń ṣàlàyé ohun tí wọ́n bá kà fún wọn nínú ìwé Mósè nínú sínágọ́gù tó wà ní Palẹ́sìnì . . . Ó tiẹ̀ jọ pé tá-tà-tá lásán làwọn Júù tó wà ní Alẹkisáńdíríà gbọ́ nínú èdè Hébérù; èdè Gíríìkì tìlú Alẹkisáńdíríà ni wọ́n gbọ́ dáadáa.” Ó hàn gbangba pé ó rọ̀ wọ́n lọ́rùn dáadáa láti túmọ̀ Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù sí èdè Gíríìkì ní Alẹkisáńdíríà.
Júù kan tó gbáyé ní ọ̀rúndún kejì ṣáájú Sànmánì Tiwa, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Àrísítóbúlù, kọ̀wé pé wọ́n túmọ̀ lára Òfin Hébérù sí èdè Gíríìkì. Ó ní wọ́n parí ìtumọ̀ yìí lákòókò tí Pẹ́tólẹ́mì Philadelphus wà lórí oyè (285 sí 246 ṣáájú Sànmánì Tiwa). Ohùn àwọn èèyàn kò ṣọ̀kan nípa ohun tí òfin tí Àrísítóbúlù sọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ́. Àwọn kan sọ pé kìkì ìwé márùn-ún àkọ́kọ́ nínú Bíbélì ló ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, àwọn mìíràn sì sọ pé gbogbo Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù ló ní lọ́kàn.
Èyí ó wù ó jẹ́, ohun tí ìtàn àtẹnudẹ́nu sọ ni pé àwọn Júù bíi méjìléláàádọ́rin tí wọ́n jẹ́ ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ló kọ́kọ́ túmọ̀ Ìwé Mímọ́ láti èdè Hébérù sí Gíríìkì. Nígbà tó yá, wọ́n já nọ́ńbà méjì orí iye yẹn kúrò, ó wá di àádọ́rin. Ìdí rèé tí wọ́n fi ń pe ìtumọ̀ Bíbélì yìí ní Septuagint, tó túmọ̀ sí “àádọ́rin.” Lẹ́tà àwọn ará Róòmù ni wọ́n fi ń kọ ọ́, ìyẹn LXX, tó dúró fún àádọ́rin. Nígbà tó máa di ìparí ọ̀rúndún kejì ṣáájú Sànmánì Tiwa, gbogbo Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù ti wà lédè Gíríìkì. Bí wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ sí pe gbogbo Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù tí wọ́n tú sí èdè Gíríìkì ní ìtumọ̀ Septuagint nìyẹn.
Ó Wúlò ní Ọ̀rúndún Kìíní
Àwọn Júù tó ń sọ èdè Gíríìkì ṣáájú ìgbà ayé Jésù Kristi àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ àti àwọn tó sọ ọ́ nígbà ayé wọn pàápàá lo ìtumọ̀ Septuagint dáadáa. Ọ̀pọ̀ lára àwọn Júù àtàwọn aláwọ̀ṣe tó kóra jọ sí Jerúsálẹ́mù ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa, ló wá láti àgbègbè Éṣíà, Íjíbítì, Líbíà, Róòmù àti Kírétè—èdè Gíríìkì sì ni wọ́n ń sọ lágbègbè wọ̀nyí. Ó dájú pé ìtumọ̀ Septuagint làwọn èèyàn yìí ń kà. (Ìṣe 2:9-11) Èyí mú kí ìtumọ̀ náà ṣe bẹbẹ nínú títan ìhìn rere náà kálẹ̀ ní ọ̀rúndún kìíní.
Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ọmọ ẹ̀yìn náà Sítéfánù ń bá àwọn tó wá láti Kírénè, Alẹkisáńdíríà, Sìlíṣíà àti Éṣíà sọ̀rọ̀, ó sọ pé: “Jósẹ́fù ránṣẹ́ pe Jékọ́bù baba rẹ̀ àti gbogbo ìbátan rẹ̀ láti ibẹ̀ [Kénáánì], iye àwọn tí ó jẹ́ ọkàn márùndínlọ́gọ́rin.” (Ìṣe 6:8-10; 7:12-14) Nínú Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù, Jẹ́nẹ́sísì orí 46 sọ pé iye ìbátan Jósẹ́fù jẹ́ àádọ́rin. Àmọ́ ìtumọ̀ Septuagint pe iye yẹn ní márùndínlọ́gọ́rin. Ó hàn gbangba pé inú ìtumọ̀ Septuagint ni Sítéfánù ti fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ.—Jẹ́nẹ́sísì 46:20, 26, 27.
Ọ̀pọ̀ àwọn Kèfèrí tó bẹ̀rù Ọlọ́run àti “àwọn Gíríìkì tí ń jọ́sìn Ọlọ́run” ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù Ìṣe 13:16, 26; 17:4) Ìmọ̀ táwọn èèyàn yìí ti ní látinú ìtumọ̀ Septuagint ló mú kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bẹ̀rù Ọlọ́run tàbí kí wọ́n máa sìn ín. Bí Pọ́ọ̀lù ṣe ń wàásù fáwọn tó ń sọ èdè Gíríìkì, ó sábà máa ń ka ìtumọ̀ Bíbélì yìí tàbí kó ṣàyọlò ọ̀rọ̀ inú rẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 22:18; Gálátíà 3:8.
wàásù fún bó ṣe ń káàkiri Éṣíà Kékeré àti Gíríìsì nínú ìrìn àjò míṣọ́nnárì rẹ̀ ẹlẹ́ẹ̀kejì àti ẹlẹ́ẹ̀kẹta. (Iye ìgbà tí Ìwé Mímọ́ Kristẹni lédè Gíríìkì fa ọ̀rọ̀ yọ ní tààràtà látinú Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù tó ọ̀ọ́dúnrún ó lé ogún [320]. Àpapọ̀ àyọlò àti ìtọ́kasí tó ṣe sì tó nǹkan bí àádọ́rùn-ún lé lẹ́gbẹ̀rin [890]. Ìtumọ̀ Septuagint ni èyí tó pọ̀ jù lọ lára àyọlò yìí ti wá. Àbájáde èyí ni pé àwọn ọ̀rọ̀ tá a fà yọ látinú ìtumọ̀ Septuagint àmọ́ tí kò sí nínú àwọn ìwé àfọwọ́kọ lédè Hébérù di apá kan Ìwé Mímọ́ Kristẹni lédè Gíríìkì tí Ọlọ́run mí sí. Kókó pàtàkì mà nìyẹn o! Jésù ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé la ti máa wàásù ìhìn rere Ìjọba náà. (Mátíù 24:14) Kí ọ̀rọ̀ yìí lè nímùúṣẹ, Jèhófà á jẹ́ kí a túmọ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó ní ìmísí sí onírúurú èdè táwọn èèyàn ń kà kárí ayé.
Ó Wúlò Lóde Òní
Ìtumọ̀ Septuagint ṣì wúlò títí dòní olónìí. Ó ń jẹ́ ká rí àṣìṣe tó ṣeé ṣe káwọn adàwékọ ṣe nígbà tí wọ́n ń ṣe àdàkọ ìwé àfọwọ́kọ tí wọ́n dà kọ sí èdè Hébérù lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Bí àpẹẹrẹ, Jẹ́nẹ́sísì 4:8, kà pé: “Lẹ́yìn ìyẹn, Kéènì sọ fún Ébẹ́lì arákùnrin rẹ̀ pé: [‘Jẹ́ kí a kọjá lọ sínú pápá.’] Ó wá ṣẹlẹ̀ pé, nígbà tí wọ́n wà nínú pápá, Kéènì bẹ̀rẹ̀ sí fipá kọlu Ébẹ́lì arákùnrin rẹ̀, ó sì pa á.”
Ọ̀rọ̀ náà “jẹ́ kí á kọjá lọ sínú pápá” tó wà nínú àkámọ́ kò sí nínú àwọn ìwé tí wọ́n fọwọ́ kọ lédè Hébérù tó wà láti nǹkan bí ọ̀rúndún kẹwàá Sànmánì Tiwa síwájú. Àmọ́, ọ̀rọ̀ yìí wà nínú àwọn ìwé àfọwọ́kọ ti ìtumọ̀ Septuagint ògbólógbòó àtàwọn ìwé díẹ̀ tí wọ́n kọ láyé ìgbà náà lọ́hùn-ún. Àmì tó fi hàn pé a fẹ́ fa ọ̀rọ̀ tẹ́nì kan sọ yọ, wà nínú ìwé àfọwọ́kọ wọ̀nyẹn lédè Hébérù, àmọ́ kò sí ọ̀rọ̀ tí Kéènì sọ níwájú àmì yìí. Kí ló lè fa èyí? Jẹ́nẹ́sísì 4:8 ní gbólóhùn méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó tẹ̀ léra nínú, ọ̀rọ̀ náà “sínú (tàbí nínú) pápá” ló sì parí wọn, ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà Cyclopedia, tí McClintock àti Strong ṣe, sọ pé: “Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé oríṣi ọ̀rọ̀ [kan náà] . . . tó gbẹ̀yìn gbólóhùn méjèèjì ló mú kí ojú adàwékọ tó dà á kọ lédè Hébérù fo ọ̀kan lára wọn. Nítorí náà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe lojú adàwékọ fo awẹ́ gbólóhùn tó parí pẹ̀lú ọ̀rọ̀ náà “sínú pápá,” tó ṣáájú. Ó wá hàn gbangba pé ìtumọ̀ Septuagint àtàwọn ìwé àfọwọ́kọ mìíràn tọ́jọ́ wọn ti pẹ́, lè jẹ́ kéèyàn rí àṣìṣe tó wà nínú Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù tí wọ́n ṣàdàkọ rẹ̀ níkẹyìn.
Àmọ́ o, ìtumọ̀ Septuagint náà kò ṣàì láwọn àṣìṣe nínú. Nígbà míì, àwọn ìwé àfọwọ́kọ lédè Hébérù ni wọ́n máa ń fi ṣàtúnṣe ti ìtumọ̀ èdè Gíríìkì yìí. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé tá a bá fi ìwé àfọwọ́kọ lédè Hébérù wé ìtumọ̀ ti èdè Gíríìkì, tá a tún fi wéra pẹ̀lú èyí tí wọ́n tú sí èdè mìíràn, àá rí àṣìṣe táwọn tó túmọ̀ rẹ̀ àtàwọn tó ṣàdàkọ rẹ̀ ṣe. Èyí á sì jẹ́ ká lè túmọ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lọ́nà tó pegedé.
Láti ọ̀rúndún kẹrin Sànmánì Tiwa ni wọ́n ti ṣe àdàkọ odindi ẹ̀dà Septuagint tá a ní lónìí. Kò sí lẹ́tà Hébérù mẹ́rin (YHWH) tó dúró fún Jèhófà, orúkọ Ọlọ́run, nínú àwọn ìwé àfọwọ́kọ bẹ́ẹ̀ àtàwọn ẹ̀dà tá a kọ lẹ́yìn náà. “Ọlọ́run” àti “Olúwa” lédè Gíríìkì ni wọ́n fi dípò lẹ́tà mẹ́rin tó dúró fórúkọ Ọlọ́run ní gbogbo ibi tó ti fara hàn nínú Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù. Àmọ́ o, àwárí kan tí wọ́n ṣe ní Palẹ́sìnì ní nǹkan bí àádọ́ta ọdún sẹ́yìn tànmọ́lẹ̀ sí ọ̀rọ̀ yìí. Àwọn kan tó ń wá inú hòrò tó wà ní bèbè apá ìwọ̀ oòrùn Òkun Òkú, ṣàwárí ògbólógbòó àkájọ ìwé aláwọ ti ìwé àwọn wòlíì méjìlá (láti Hóséà dé Málákì), tí wọ́n fi èdè Gíríìkì kọ. Àárín ọdún 50 ṣáájú Sànmánì Tiwa sí ọdún 50 Sànmánì Tiwa ni wọ́n kọ wọ́n. Nínú àjákù ìwé àfọwọ́kọ tí wọ́n kọ tipẹ́tipẹ́ sẹ́yìn yìí, wọn ò fi ọ̀rọ̀ náà “Ọlọ́run” àti “Olúwa” rọ́pò lẹ́tà mẹ́rin tó dúró fórúkọ Ọlọ́run. Èyí ló fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé orúkọ Ọlọ́run wà nínú ẹ̀dà Ìwé Mímọ́ ní ìtumọ̀ Septuagint tí wọ́n kọ́kọ́ ṣe.
Lọ́dún 1971, wọ́n tẹ àjákù àkájọ ìwé tí wọ́n fi òrépèté ṣe (Fouad Papyri 266) jáde. Kí ni wọ́n rí nínú apá kan ìtumọ̀ Septuagint yìí, tí wọ́n ti kọ
láti nǹkan bí ọ̀rúndún kìíní tàbí ọ̀rúndún kejì ṣáájú Sànmánì Tiwa? Orúkọ Ọlọ́run wà nínú wọn pẹ̀lú. Àwọn àjákù ẹ̀dà Septuagint ìgbà láéláé yìí pèsè ẹ̀rí tó múná dóko pé Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ọ̀rúndún kìíní mọ orúkọ Ọlọ́run, wọ́n sì lò ó.Lónìí, Bíbélì ni ìwé tá a ti túmọ̀ sí èdè tó pọ̀ jù lọ láyé yìí . Ṣàṣà làwọn èèyàn tí kò ní odindi Bíbélì tàbí apá kan rẹ̀ lédè wọn ní gbogbo ayé. Ní pàtàkì, a mọyì Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tá a tú sí èdè òde òní tó sì péye. Ó ti wà lódindi tàbí lápá kan ní èdè tó lé ní ogójì báyìí. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé tó ń tọ́ka sí ìtumọ̀ Septuagint àtàwọn ìwé àfọwọ́kọ ìgbà láéláé mìíràn ló wà nínú New World Translation of the Holy Scriptures—With References. Ká sòótọ́, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lóde òní mọrírì ìtumọ̀ Septuagint, wọ́n sì mọ ìjẹ́pàtàkì rẹ̀.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Ọmọ ẹ̀yìn náà Fílípì ṣàlàyé apá ibi tó kà látinú ìtumọ̀ “Septuagint”
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Ọ̀pọ̀ ìgbà ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fa ọ̀rọ̀ yọ látinú ìtumọ̀ “Septuagint”