Ìtùnú ní Àkókò Ìṣòro
Ìtùnú ní Àkókò Ìṣòro
ÀWỌN ìròyìn tá à ń gbọ́ lóde òní kì í tu èèyàn nínú rárá. Ọkùnrin kan kọ̀wé pé: “Àwọn ìròyìn lọ́ọ́lọ́ọ́ ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì báni gan-an débi pé ńṣe lẹ̀rù àtigbọ́ ìròyìn aago mẹ́fà máa ń bà wá.” Ilé ayé kún fún ogun, ìpayà, ìjìyà, ìwà ọ̀daràn àti àrùn—tó jẹ́ àwọn nǹkan búburú tó lè kàn wá láìpẹ́, ìyẹn tí wọn ò bá tíì ṣe bẹ́ẹ̀.
Bíbélì sọ ọ́ tẹ́lẹ̀ pé báyìí gẹ́lẹ́ ni ipò nǹkan ṣe máa rí lónìí. Nígbà tí Jésù ń ṣàpèjúwe àkókò wa yìí, ó ní ogun, àjàkálẹ̀ àrùn, àìtó oúnjẹ àti ìsẹ̀lẹ̀ ńláńlá yóò wà. (Lúùkù 21:10, 11) Bákan náà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé nípa “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò,” nígbà táwọn èèyàn yóò jẹ́ òǹrorò, olùfẹ́ owó, àti aláìní ìfẹ́ ohun rere. Ó pe àkókò yẹn ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.”—2 Tímótì 3:1-5.
Ìdí nìyẹn táwọn ìròyìn tó ń sọ nípa bípò nǹkan ṣe rí nínú ayé fi bá ohun tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ mu láwọn ọ̀nà kan. Àmọ́ ìyẹn nìkan náà ni wọ́n fi bára mu. Bíbélì lani lóye nípa àwọn nǹkan tí a kò lè rí nínú àwọn ìròyìn. Kì í ṣe kìkì ìdí tí ìwà ibi fi gbilẹ̀ ni ohun tá a lè mọ̀ látinú Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí, a tún lè mọ bí ọjọ́ iwájú yóò ṣe rí pẹ̀lú.
Ojú Tí Ọlọ́run Fi Ń Wo Ìwà Ibi
Bíbélì ṣàlàyé irú ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ipò ìdààmú tá a wà lónìí. Bó tilẹ̀ jẹ pé ó ti rí àwọn 1 Jòhánù 4:8) Jèhófà bìkítà nípa àwọn èèyàn gan-an ni, ó sì kórìíra gbogbo ìwà búburú. Ìyẹn ló fi bá a mu pé a lè yíjú sí Ọlọ́run fún ìtùnú, nítorí ó jẹ́ ẹni rere àti oníyọ̀ọ́nú, tó lágbára láti mú ibi kúrò lórí ilẹ̀ ayé, tó sì fẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Onísáàmù kọ̀wé pé: “[Ọba ọ̀run tí Ọlọ́run yàn] yóò dá òtòṣì tí ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ nídè, ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ pẹ̀lú, àti ẹnì yòówù tí kò ní olùrànlọ́wọ́. Òun yóò káàánú ẹni rírẹlẹ̀ àti òtòṣì, yóò sì gba ọkàn àwọn òtòṣì là. Yóò tún ọkàn wọn rà padà lọ́wọ́ ìnilára àti lọ́wọ́ ìwà ipá, ẹ̀jẹ̀ wọn yóò sì ṣe iyebíye ní ojú rẹ̀.”—Sáàmù 72:12-14.
wàhálà ìsinsìnyí tẹ́lẹ̀, kò fọwọ́ sí wọn bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe pé ó fẹ́ fàyè gbà wọ́n títí ayé. Àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé: “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” (Ǹjẹ́ o máa ń káàánú àwọn tí ìyà ń jẹ? Ó ṣeé ṣe kó o máa ṣe bẹ́ẹ̀. Ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò jẹ́ ànímọ́ kan tí Jèhófà dá mọ́ wa, nítorí pé ó dá wa ní àwòrán ara rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 1:26, 27) Ọkàn wa lè balẹ̀ nígbà náà pé kì í ṣe pé Jèhófà ò bìkítà nípa ìyà tó ń jẹ aráyé. Jésù, tó mọ Jèhófà dáadáa ju ẹnikẹ́ni mìíràn lọ, kọ́ wa pé Jèhófà ní ìfẹ́ tó ga sí wa, ó sì kún fún ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́.—Mátíù 10:29, 31.
Ìṣẹ̀dá pàápàá jẹ́rìí sí i pé Ọlọ́run bìkítà nípa ìran ènìyàn. Jésù sọ pé Ọlọ́run “ń mú kí oòrùn rẹ̀ ràn sórí àwọn ènìyàn burúkú àti rere, . . . ó sì ń mú kí òjò rọ̀ sórí àwọn olódodo àti aláìṣòdodo.” (Mátíù 5:45) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn èèyàn ìlú Lísírà pé: “[Ọlọ́run] kò fi ara rẹ̀ sílẹ̀ láìsí ẹ̀rí ní ti pé ó ṣe rere, ó ń fún yín ní òjò láti ọ̀run àti àwọn àsìkò eléso, ó ń fi oúnjẹ àti ìmóríyágágá kún ọkàn-àyà yín dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.”—Ìṣe 14:17.
Ta Ló Fa Ìwà Ibi?
Ó yẹ ká kíyè sí i pé Pọ́ọ̀lù tún sọ fún àwọn èèyàn ìlú Lísírà pé: “Ní àwọn ìran tí ó ti kọjá, [Ọlọ́run] gba gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè láyè láti máa bá a lọ ní ọ̀nà wọn.” Nítorí náà, àwọn orílẹ̀-èdè—tàbí àwọn èèyàn fúnra wọn—ló ń fọwọ́ ara wọn fa èyí tó pọ̀ jù lọ nínú ìṣòro tó ń bá wọn fínra. Ọlọ́run ò jẹ̀bi rárá.—Ìṣe 14:16.
Èé ṣe tí Jèhófà fi wá fàyè gba ohun búburú láti ṣẹlẹ̀? Ǹjẹ́ ó máa ṣe ohunkóhun nípa rẹ̀? Inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nìkan ṣoṣo la ti lè rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí. Ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀ ni pé ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyẹn kan ẹlòmíràn tó jẹ́ ẹni ẹ̀mí, ó sì tún ní í ṣe pẹ̀lú kókó kan tí onítọ̀hún gbé dìde ní ibùgbé àwọn ẹni ẹ̀mí.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
Àwọn èèyàn lẹ́mìí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò. Ṣé Ọlọ́run pàápàá ò wá ní bìkítà nípa ìyà tó ń jẹ ẹ̀dá ènìyàn ni?
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 2]
Ẹ̀YÌN ÌWÉ: Ọkọ̀ ológun: FỌ́TÒ ÀJỌ ÌPARAPỌ̀ ORÍLẸ̀-ÈDÈ 158181/J. Isaac; ìsẹ̀lẹ̀: San Hong R-C Picture Company
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]
Apá òsì lókè, Croatia: FỌ́TÒ ÀJỌ UN 159208/S. Whitehouse; ọmọ tí ebi ń pa: FỌ́TÒ ÀJỌ UN 146150 LÁTI ỌWỌ́ O. MONSEN