Báwo La Ṣe Lè Lo Ìgbésí Ayé Wa Lọ́nà Tí Inú Jèhófà Dùn Sí?
Báwo La Ṣe Lè Lo Ìgbésí Ayé Wa Lọ́nà Tí Inú Jèhófà Dùn Sí?
“Lánàá òde yìí, odindi wákàtí méjì, tó ṣeyebíye ló ṣòfò láàárín ìgbà tí oòrùn là sí ìgbà tí oòrùn wọ̀. Kò sì sérè ńbẹ̀, nítorí a ò lè rí àkókò tó ṣòfò náà gbà mọ́ títí ayé!”—Lydia H. Sigourney, òǹkọ̀wé ọmọ ilẹ̀ Amẹ́ríkà (ọdún 1791 sí 1865).
Ó DÀ bíi pé ọjọ́ ayé wa kò tó nǹkan, ká sì tó pajú pẹ́ ó ti kọjá lọ. Onísáàmù náà Dáfídì ronú nípa bí ìgbésí ayé èèyàn ṣe kúrú tó, ó sì gbàdúrà pé: “Jèhófà, jẹ́ kí n mọ òpin mi, àti ìwọ̀n ọjọ́ mi—ohun tí ó jẹ́, kí n lè mọ bí mo ti jẹ́ aláìwàpẹ́ tó. Wò ó! Ìwọ ti ṣe ọjọ́ mi ní kìkì ìwọ̀nba díẹ̀; gbogbo ọjọ́ ayé mi sì dà bí èyí tí kò tó nǹkan ní iwájú rẹ.” Ohun tó wà lórí ẹ̀mí Dáfídì ni pé kó gbé ìgbésí ayé rẹ̀ lọ́nà tá á múnú Ọlọ́run dùn, yálà nípa ọ̀rọ̀ sísọ tàbí ìṣe rẹ̀. Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa bó ṣe gbára lé Ọlọ́run, ó ní: “Ìfojúsọ́nà mi ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ.” (Sáàmù 39:4, 5, 7) Jèhófà gbọ́ àdúrà rẹ̀. Ó yẹ gbogbo ìgbòkègbodò Dáfídì wò lóòótọ́, ó sì pín in lérè níbàámu pẹ̀lú iṣẹ́ rẹ̀.
Ó rọrùn kí ọwọ́ èèyàn dí láti àárọ̀ ṣúlẹ̀ kí ìgbésí ayé olúwarẹ̀ sì di ti kòókòó jàn-ánjàn-án pẹ̀lú ìgbòkègbodò tó pọ̀ rẹpẹtẹ. Èyí lè mú ká bẹ̀rẹ̀ sí ṣàníyàn, àgàgà bí ohun tá a fẹ́ ṣe bá pọ̀ tí àkókò wa ò sì tó nǹkan. Ṣé ohun tó jẹ Dáfídì lógún náà jẹ wá lógún, ìyẹn láti gbé ìgbésí ayé wa lọ́nà tó ṣètẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run? Ó dájú pé Jèhófà ń kíyè sí kálukú wa ó sì ń yẹ̀ wá wò. Jóòbù tó bẹ̀rù Ọlọ́run sọ ní nǹkan bí egbèjìdínlógún [3,600] ọdún sẹ́yìn pé Jèhófà rí gbogbo ọ̀nà òun ó sì ń ka gbogbo ìṣísẹ̀ òun. Jóòbù béèrè lọ́wọ́ ara rẹ̀ pé: “Nígbà tí ó bá sì béèrè fún ìjíhìn, kí ni mo lè fi dá a lóhùn?” (Jóòbù 31:4-6, 14) A lè lo ìgbésí ayé wa lọ́nà táá múnú Ọlọ́run dùn tá a bá ṣètò bá ó ṣe máa fi àwọn ohun tẹ̀mí ṣáájú, ká máa pa àṣẹ Ọlọ́run mọ́ ká sì máa lo àkókò wa lọ́nà tó bọ́gbọ́n mu. Ẹ jẹ́ ká túbọ̀ túṣu ọ̀ràn yìí désàlẹ̀ ìkòkò.
Ká Máa Jẹ́ Kí Àwọn Ohun Tẹ̀mí Jẹ Wá Lógún Jù Lọ
Ìwé Mímọ́ rọ̀ wá láti ṣètò bá ó ṣe máa fi nǹkan tẹ̀mí ṣáájú nígbà tó sọ pé: “Máa wádìí dájú àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù.” Kí làwọn ohun tó ṣe pàtàkì yìí? Ó wé mọ́ “ìmọ̀ pípéye àti ìfòyemọ̀ kíkún.” (Fílípì 1:9, 10) Láti ní ìmọ̀ nípa ète Jèhófà ń béèrè pé ká lo àkókò wa lọ́nà tó mọ́gbọ́n dání. Àmọ́ fífi ohun tẹ̀mí ṣe olórí àníyàn wa á jẹ́ ká gbé ìgbésí ayé tó lérè tó sì ń tẹ́ni lọ́rùn.
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rán wa létí pé ká “máa bá a nìṣó ní wíwádìí ohun tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún Olúwa dájú.” Wíwádìí dájú yìí gbọ́dọ̀ wé mọ́ ṣíṣàyẹ̀wò èrò ọkàn wa àtàwọn ohun tá a nífẹ̀ẹ́ sí. Àpọ́sítélì náà ń bá ọ̀rọ̀ lọ pé: “Ẹ máa bá a lọ ní ríróye ohun tí ìfẹ́ Jèhófà jẹ́.” (Éfésù 5:10, 17) Nígbà náà, kí làwọn ohun tó ṣètẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Jèhófà? Òwe Bíbélì kan dáhùn rẹ̀ pé: “Ọgbọ́n ni ohun ṣíṣe pàtàkì jù lọ. Ní ọgbọ́n; pẹ̀lú gbogbo ohun tí o sì ní, ní òye. Gbé e níyì gidigidi, yóò sì gbé ọ ga.” (Òwe 4:7, 8) Inú Jèhófà máa ń dùn sí ẹni tó bá ní ọgbọ́n Ọlọ́run tó sì ń lò ó. (Òwe 23:15) Ibi tí ọgbọ́n yìí dára sí ni pé kò sẹ́ni tó lè gbà á mọ́ni lọ́wọ́ kò sì ṣeé bà jẹ́. Kódà, ńṣe lá máa fìṣọ́ ṣọ́ni tá sì máa pani mọ́ ‘kúrò ní ọ̀nà búburú àti kúrò lọ́wọ́ àwọn tí ń sọ ohun àyídáyidà.’—Òwe 2:10-15.
Ẹ ò rí i nígbà náà pé ó bọ́gbọ́n mu láti yàgò fún ohunkóhun tó lè mú ká bẹ̀rẹ̀ sí fọwọ́ dẹngbẹrẹ mú àwọn nǹkan tẹ̀mí! A ní láti máa fi ìmọrírì hàn fún àwọn ọ̀rọ̀ Jèhófà ká sì máa bẹ̀rù rẹ̀ bó ṣe yẹ. (Òwe 23:17, 18) Òótọ́ ni pé ìgbàkigbà ní ìgbésí ayé wa la lè bẹ̀rẹ̀ sí ní irú ẹ̀mí yìí, àmọ́ ohun tó dára jù lọ ni pé ká ti kékeré fi kọ́ra kí fífi àwọn ìlànà Bíbélì sílò ti mọ́ wa lára. Sólómọ́nì ọlọ́gbọ́n ọba sọ pé: “Rántí Ẹlẹ́dàá rẹ Atóbilọ́lá nísinsìnyí, ní àwọn ọjọ́ tí o wà ní ọ̀dọ́kùnrin.”—Oníwàásù 12:1.
Ọ̀nà pàtàkì kan tá a lè gbà máa ní ìmọrírì fún Jèhófà ni nípa gbígbàdúrà sí i lójoojúmọ́. Dáfídì mọ bó ti ṣe pàtàkì tó láti máa sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn wa fún Jèhófà. Ìyẹn ló fi bẹ Ọlọ́run pé: “Gbọ́ àdúrà mi, Jèhófà, sì fi etí sí igbe mi fún ìrànlọ́wọ́. Má ṣe dákẹ́ sí omijé mi.” (Sáàmù 39:12) Ǹjẹ́ àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà máa ń wọ̀ wá lákínyẹmí ara nígbà míì débi pé omijé á jáde lójú wa? Ní tòótọ́, bá a bá ṣe sọ àwọn ọ̀rọ̀ àṣírí tó wà lọ́kàn wa fún Jèhófà tó tá a sì ṣàṣàrò lórí Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe máa sún mọ́ wa tó.—Jákọ́bù 4:8.
Kọ́ Bá A Ṣe Ń Jẹ́ Onígbọràn
Ẹlòmíràn tó tún jẹ́ ẹni ìgbàgbọ́ tó sì gbára lé Ọlọ́run ni Mósè. Bíi ti Dáfídì náà ni ti Mósè ṣe rí. Ó rí i pé wàhálà kúnnú ìgbésí ayé. Èyí ló mú kó rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Jèhófà pé kó kọ́ òun ní ‘bí òun yóò ṣe máa ka àwọn ọjọ́ òun ní ọ̀nà tí òun á fi lè jèrè ọkàn-àyà ọgbọ́n.’ (Sáàmù 90:10-12) Mímọ àwọn òfin àti ìlànà Jèhófà àti pípa wọ́n mọ́ nìkan ló lè mú kéèyàn ní ọkàn-àyà ọgbọ́n. Mósè mọ èyí ó sì sapá láti jẹ́ kí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì mọ òtítọ́ pàtàkì yìí. Ìyẹn ló ṣe tẹ òfin àtàwọn ìlànà Ọlọ́run mọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì létí gbọnmọgbọnmọ kí wọ́n tó gba Ilẹ̀ Ìlérí. Nígbà tó bá sì yá, ẹnikẹ́ni tí Jèhófà bá máa fi jẹ ọba lórí Ísírẹ́lì gbọ́dọ̀ kọ ẹ̀dà kan Òfin náà fún ara rẹ̀ kó sì máa kà á ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀. Kí nìdí rẹ̀? Òun ni pé kó lè kọ́ láti bẹ̀rù Ọlọ́run. Èyí jẹ́ ọ̀nà kan láti dán ìgbọràn ọba kan wò. Kò ní jẹ́ kó máa fẹlá lórí àwọn arákùnrin rẹ̀, á sì jẹ́ kó jọba pẹ́. (Diutarónómì 17:18-20) Jèhófà tún ìlérí yìí ṣe nígbà tó sọ fún Sólómọ́nì ọmọ Dáfídì pé: “Bí ìwọ yóò bá sì rìn ní àwọn ọ̀nà mi, nípa pípa àwọn ìlànà àti àṣẹ mi mọ́, gan-an gẹ́gẹ́ bí Dáfídì baba rẹ ti rìn, èmi yóò mú àwọn ọjọ́ rẹ gùn sí i pẹ̀lú.”—1 Ọba 3:10-14.
Ọ̀rọ̀ ìgbọràn kì í ṣe ọ̀rọ̀ kékeré lójú Ọlọ́run o. Tá a bá fojú tín-ínrín àwọn kan lára ohun tí Jèhófà ń béèrè pé ká ṣe àtàwọn ìlànà rẹ̀ bíi pé wọn ò ṣe pàtàkì, ó dájú pé kò ní ṣàì mọ èyí. (Òwe 15:3) Ó yẹ kí mímọ̀ tá a mọ èyí sún wa láti ní ọ̀wọ̀ tó ga fún gbogbo ìtọ́sọ́nà Jèhófà bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè má rọrùn láti ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà mìíràn. Sátánì ń sa gbogbo ipá rẹ̀ láti “dábùú ọ̀nà wa” bá a ṣe ń sapá láti pa àwọn òfin àti àṣẹ Ọlọ́run mọ́.—1 Tẹsalóníkà 2:18.
Ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká ṣègbọràn sí ìmọ̀ràn Ìwé Mímọ́ tó sọ pé ká máa pàdé pọ̀ fún ìjọsìn àti ìbákẹ́gbẹ́pọ̀. (Diutarónómì 31:12, 13; Hébérù 10:24, 25) Nítorí náà, ó dára ká bi ara wa léèrè pé: ‘Ǹjẹ́ mo ní ìpinnu àti ẹ̀mí àìyẹhùn tó lè mú kí n máa ṣe ohun tó yẹ ní ṣíṣe?’ Tá a bá ń ṣàìka ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ àti ìtọ́ni tá à ń rí gbà ní àwọn ìpàdé Kristẹni sí nítorí ká lè rí towó ṣe, ńṣe ni àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà á bà jẹ́. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Kí ọ̀nà ìgbésí ayé yín wà láìsí ìfẹ́ owó, bí ẹ ti ń ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú àwọn nǹkan ìsinsìnyí. Nítorí [Jèhófà] ti wí pé: ‘Dájúdájú, èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà tàbí kọ̀ ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà.’” (Hébérù 13:5) Ṣíṣègbọràn sí àṣẹ Jèhófà látọkànwá fi hàn pé a ní ìdánilójú pé o máa tọ́jú wa.
Jésù kọ́ bá a ṣe ń jẹ́ onígbọràn ó sì rí èrè níbẹ̀. Àwa náà lè ṣe bẹ́ẹ̀. (Hébérù 5:8) Bá a bá ṣe fi jíjẹ́ onígbọràn kọ́ra sí ló ṣe máa túbọ̀ rọrùn fún wa láti ṣègbọràn kódà nínú àwọn ohun tí ò tó nǹkan. Lóòótọ́, àwọn ẹlòmíràn lè máa kanra mọ́ wa tàbí kí wọ́n tiẹ̀ ṣe wá níkà nítorí ìdúróṣinṣin wa. Pàápàá níbi iṣẹ́, nílé ẹ̀kọ́ tàbí nínú agboolé táwọn òbí ti ń ṣe ẹ̀sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Síbẹ̀, à ń rí ìtùnú nínú ohun tí Jèhófà sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé tí wọ́n bá ‘nífẹ̀ẹ́ Jèhófà nípa fífetí sí ohùn rẹ̀ tí wọ́n sì fà mọ́ ọn, òun yóò fún wọn ní ìyè àti ọjọ́ gígùn.’ (Diutarónómì 30:20) Ìlérí kan náà yìí la ṣe fún àwa náà.
Máa Lo Àkókò Lọ́nà Tó Mọ́gbọ́n Dání
Lílo àkókò wa lọ́nà tó mọ́gbọ́n dání á tún jẹ́ ká lè lo ìgbésí ayé wa lọ́nà tó ṣètẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Jèhófà. Àkókò ò dà bí owó, nítorí owó ṣe é fi pa mọ́ àmọ́ téèyàn ò bá lo àkókò, ó lọ láú nìyẹn. Bí wákàtí kọ̀ọ̀kan ṣe ń kọjá báyìí, ó lọ gbére nìyẹn. Nígbà tó sì jẹ́ pé àwọn ohun tá a fẹ́ ṣe pọ̀ jù èyí tágbára wa ká lọ, ṣé à ń lo àkókò wa lọ́nà tí àá fi lè bá àwọn ohun tà á ń lépa nínú ìgbésí ayé wa? Góńgó pàtàkì tí gbogbo Kristẹni gbọ́dọ̀ máa lé ni kíkópa déédéé nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn.—Mátíù 24:14; 28:19, 20.
Kìkì ìgbà tá a bá mọ bí àkókò ṣe ṣeyebíye tó la tó máa ń mọ bá a ṣe lè lò ó lọ́nà tó mọ́gbọ́n dání. Ohun tí Éfésù 5:16 sọ bá a mu, ó rọ̀ wá láti ‘ra àkókò tí ó rọgbọ padà fún ara wa,’ èyí túmọ̀ sí yíyááfì àwọn ohun tí ò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì. Ó túmọ̀ sí dídín àwọn ohun tó ń fi àkókò ṣòfò kù. Wíwo tẹlifíṣọ̀n láwòjù, jíjókòó ti Íńtánẹ́ẹ̀tì láti máa yẹ ìsọfúnni wò kiri ṣáá, kíka àwọn ìwé tí ò lè ṣeni láǹfààní, tàbí ṣíṣe eré ìtura àti eré ìnàjú láṣejù lè mú kó rẹ̀ wá tẹnutẹnu. Kò tán síbẹ̀ o, kíkó dúkìá jọ pelemọ lè gba àkókò tó yẹ ká fi jèrè ọkàn-àyà ọgbọ́n.
Àwọn èèyàn tó fara mọ́ ọ̀rọ̀ ṣíṣètò àkókò ẹni sọ pé: “Kò ṣeé ṣe láti lo àkókò rẹ lọ́nà tó yẹ láìjẹ́ pé o ní àwọn ohun tó ṣe sàn-án tó ò ń lépa.” Wọn dábàá ọ̀nà márùn-ún téèyàn lè gbà gbé ohun táá máa lépa kalẹ̀, wọ́n ní: kó ṣe sàn-án, kó ṣeé díwọ̀n, kó jẹ́ èyí tó ṣeé bá, kó jẹ́ tòótọ́, kó sì jẹ́ èyí tá a fàkókò sí.
Mímú kí Bíbélì kíkà wa túbọ̀ dára sí i jẹ́ góńgó kan tó yẹ kéèyàn lépa. Ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ ni pé ká jẹ́ kí ohun tá à ń lépa ṣe sàn-án, ìyẹn ni pé láti ka Bíbélì látòkèdélẹ̀. Lẹ́yìn náà, kí ohun tá à ń lépa ṣeé díwọ̀n. Èyí á jẹ́ ká lè mọ bá a ṣe ń tẹ̀ síwájú sí. Ńṣe ló yẹ kí ohun tá à ń lépa mú ká túbọ̀ máa làkàkà sí i ká sì máa tẹ̀ síwájú. Ó tún yẹ kí ohun tá à ń lépa jẹ́ ohun tòótọ́ tó sì ṣeé bá. A gbọ́dọ̀ ronú nípa ibi tágbára wá mọ, bá a ṣe jáfáfá sí àti bá a ṣe lákòókò sí. Àwọn kan lè nílò àkókò púpọ̀ sí i láti lè lé ohun náà bá. Èyí tó gbẹ̀yìn ni pé a gbọ́dọ̀ fàkókò sí ìgbà tá a fẹ́ lé góńgó wa bá. Téèyàn bá sọ pé àkókò báyìí lòun fẹ́ parí ohun kan, ìyẹn lè jẹ́ kó túbọ̀ sapá láti rí i pé òun ṣe é.
Gbogbo ará ìdílé Bẹ́tẹ́lì tí wọ́n ń sìn ní orílé iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lágbàáyé tàbí ní àwọn ẹ̀ka iléeṣẹ́ wa kárí ayé, ní ohun kan sàn-án tí wọ́n ń lépa, ìyẹn kíka Bíbélì látìbẹ̀rẹ̀ dópin lọ́dún àkọ́kọ́ tí wọ́n dé Bẹ́tẹ́lì. Wọ́n mọ̀ pé Bíbélì kíkà lọ́nà tó ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ máa ń mú kí wọ́n dàgbà nípa tẹ̀mí ó sì túbọ̀ ń mú kí àjọṣe wọn pẹ̀lú Jèhófà, tó ń kọ́ wọn láti ṣe ara wọn láǹfààní, túbọ̀ ṣe tímọ́tímọ́ sí i. (Aísáyà 48:17) Ǹjẹ́ àwa náà lè fi Bíbélì kíkà déédéé ṣe góńgó tá a fẹ́ lé bá?
Àǹfààní Tó Wà Nínú Lílo Ìgbésí Ayé Wa Lọ́nà Tó Ṣètẹ́wọ́gbà
Ìbùkún yàbùgà yabuga ló wà nínú fífi àwọn ohun tẹ̀mí sí ipò kìíní. Lákọ̀ọ́kọ́, ó ń jẹ́ ká láyọ̀ pé a ṣe ohun kan láṣeyọrí ó sì ń jẹ́ kí ìgbésí ayé ní ìtumọ̀. Fífi àdúrà bá Jèhófà sọ̀rọ̀ látọkànwá ní gbogbo ìgbà ń mú ká túbọ̀ sún mọ́ ọn. Gbígbà tá à ń gbàdúrà yìí ń fi hàn pé a gbẹ́kẹ̀ lé e. Kíka Bíbélì lójoojúmọ́ àtàwọn ìtẹ̀jáde mìíràn tá a gbé karí Bíbélì tó ń wá látọ̀dọ̀ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ń fi hàn pé a fẹ́ láti tẹ́tí sí Ọlọ́run bó ṣe ń bá wa sọ̀rọ̀. (Mátíù 24:45-47) Èyí ń ràn wá lọ́wọ́ láti jèrè ọkàn-àyà ọgbọ́n láti lè ṣe ìpinnu àti yíyàn tó yẹ nínú ìgbésí ayé wa.—Sáàmù 1:1-3.
Ó ń dùn mọ́ wa láti máa pa àwọn àṣẹ Jèhófà mọ́, nítorí pé pípa a mọ́ kì í ṣe ẹrù ìnira fún wa. (1 Jòhánù 5:3) Ńṣe là ń mú kí àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà túbọ̀ lágbára sí i tá a bá ń lo ọjọ́ kọ̀ọ̀kan lọ́nà tó ṣètẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ rẹ̀. Èyí tún ń mú ká di alátìlẹyìn tòótọ́ nípa tẹ̀mí fún àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa. Àwọn ìwà yìí tún ń mú inú Jèhófà Ọlọ́run dùn. (Òwe 27:11) Bẹ́ẹ̀ sì rèé, kò sí èrè tó pọ̀ tó rírí ojú rere Jèhófà nísinsìnyí àti títí láé!
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Àwọn Kristẹni kì í fi ojú kékeré wo àwọn ohun tẹ̀mí
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
Ṣé ò ń lo àkókò rẹ lọ́nà tó bọ́gbọ́n mu?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
À ń mú kí àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà túbọ̀ lágbára sí i bá a ṣe ń lo ọjọ́ kọ̀ọ̀kan lọ́nà tó ṣètẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ rẹ̀