Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Sátánì Ló Ń Ṣàkóso Sànmánì Tá A Wà Yìí?

Ṣé Sátánì Ló Ń Ṣàkóso Sànmánì Tá A Wà Yìí?

Ṣé Sátánì Ló Ń Ṣàkóso Sànmánì Tá A Wà Yìí?

“TÁ A bá wo gbogbo láabi tó ti ṣẹlẹ̀ ní ọ̀rúndún tó kọjá, a ò ṣì sọ tá a bá pè é ní ọ̀rúndún Sátánì. Kò tíì sírú ọ̀rúndún bẹ́ẹ̀ táwọn èèyàn ti ní i lọ́kàn tó sì ń wù wọ́n láti pa ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn nítorí ọ̀ràn ẹ̀yà, ẹ̀sìn tàbí ipò tí wọ́n wà láwùjọ.”

Ibi tí wọ́n ti ṣe àyájọ́ àádọ́ta ọdún tí wọ́n dá àwọn aláìmọwọ́mẹsẹ̀ tí wọ́n jù sẹ́wọ̀n láwọn ọgbà panipani nígbà ìjọba Násì sílẹ̀ lọ̀rọ̀ yìí, tí wọ́n kọ sínú ọ̀rọ̀ olóòtú nínú ìwé ìròyìn The New York Times ti January 26, 1995, ti wáyé. Ìpakúpa Rẹpẹtẹ náà—tó jẹ́ ọ̀kan lára ìpẹ̀yàrun tó tàn kálẹ̀ jù lọ nínú ìtàn—gbẹ̀mí nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́fà àwọn Júù. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù mẹ́ta àwọn ará Poland tí kì í ṣe Júù tí ẹ̀mí wọn lọ sí ohun tí wọ́n pè ní “Ìpakúpa Rẹpẹtẹ Tá Ò Kà Sí.”

Jonathan Glover sọ nínú ìwé rẹ̀ Humanity—A Moral History of the Twentieth Century, pé: “Wọ́n fojú bù ú pé mílíọ̀nù mẹ́rìndínláàádọ́rùn-ún èèyàn ni ogun ti gbẹ̀mí rẹ̀ láti ọdún 1900 títí di ọdún 1989.” Ó tún sọ pé: “Iye èèyàn tó kú nínú ogun ní ọ̀rúndún ogún pọ̀ kọjá ohun tí ẹ̀dá èèyàn lè lóye rẹ̀. Kò ṣeé ṣe láti mọ̀ iye èèyàn tó kú ní pàtó, nítorí pé nǹkan bíi mílíọ̀nù méjìdínlọ́gọ́ta èèyàn lẹ̀mí wọn lọ sí ogun àgbáyé méjèèjì. Tá a bá pín iye àwọn tó kú yìí sí iye ọdún tó wà nínú ọ̀rúndún ogún, a jẹ́ pé ogun ń pa nǹkan bí ẹgbẹ̀tàlá ó dín ọgọ́rùn-ún [2,500] èèyàn lójoojúmọ́, èyí lé ní ọgọ́rùn-ún èèyàn láàárín wákàtí kan láìdáwọ́dúró fún odidi àádọ́rùn-ún ọdún.”

Èyí ló fà á tí wọ́n fi sọ pé ọ̀rúndún ogún jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀rúndún tí wọ́n ta ẹ̀jẹ̀ èèyàn sílẹ̀ jù lọ nínú ìtàn ẹ̀dá. Nínú ìwé Hope Against Hope, Nadezhda Mandelstam, kọ ọ́ pé: “Ohun tó jẹ́ kí èṣù borí bá a ṣe ń rí i yìí ni pé àwọn ìlànà tó yẹ kí ẹ̀dá èèyàn tẹ̀ lé ti dìdàkudà.” Àmọ́ ṣé lóòótọ́ ni èṣù ti borí nínú bíbá tó bá Ọlọ́run fẹsẹ̀ wọnsẹ̀?

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 2]

ÀWÒRÁN Ẹ̀YÌN ÌWÉ: Ìyà àti ọmọ: J.R. Ripper/SocialPhotos

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]

U.S. Department of Energy photograph