Ǹjẹ́ O Ṣírò Ohun Tó Máa Ná Ọ?
Ǹjẹ́ O Ṣírò Ohun Tó Máa Ná Ọ?
JÉSÙ KRISTI nawọ́ ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun sí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. Àmọ́ ó tún rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n ṣírò ohun tí jíjẹ́ Kristẹni máa ná wọn. Ó ṣàlàyé kókó náà nípa bíbéèrè pé: “Ta ni nínú yín tí ó fẹ́ kọ́ ilé gogoro kan tí kò ní kọ́kọ́ jókòó, kí ó sì gbéṣirò lé ìnáwó náà [tàbí, ṣírò ohun tó máa ná òun], láti rí i bí òun bá ní tó láti parí rẹ̀?” (Lúùkù 14:28) Irú àwọn nǹkan wo ni Jésù ní lọ́kàn pé ó lè náni?
Gbogbo Kristẹni ló ń dojú kọ àdánwò—àwọn àdánwò mìíràn sì máa ń le bí ojú ẹja. (Sáàmù 34:19; Mátíù 10:36) Ìyẹn la fi gbọ́dọ̀ múra sílẹ̀ ní ti èrò orí àti nípa tẹ̀mí, kí àtakò tàbí ìṣòro mìíràn má bàa bá wa lábo. A ti ní láti ṣírò irú àwọn ìṣòro bẹ́ẹ̀ mọ́ ohun tó gbà láti jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Kristi. Nítorí a mọ̀ pé èrè wa—ìyẹn bíbọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú—níye lórí ju ohunkóhun tá a lè rí nínú ètò ìsinsìnyí. Dájúdájú, kò sí ohun tí Ọlọ́run gbà láyè—bó jẹ́ ikú pàápàá—tó lè ba tiwa jẹ́ títí ayé, bá a bá ń sin Ọlọ́run láìyẹsẹ̀.—2 Kọ́ríńtì 4:16-18; Fílípì 3:8.
Báwo ni ìgbàgbọ́ wa ṣe lè lágbára gan-an? Ìgbàgbọ́ wa máa ń lágbára sí i ní gbogbo ìgbà tá a bá ṣe ìpinnu tó tọ́, tá a dúró gbọn-in ti ìlànà Kristẹni, tàbí tá a gbé ìgbésẹ̀ kan tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu—àgàgà nígbà tí nǹkan kan bá fẹ́ tì wá ṣe ohun tí kò tọ́. Ìgbàgbọ́ wa tún máa ń lágbára sí i, ó sì máa ń jinlẹ̀ sí i nígbà tí àwa fúnra wa bá rí ìbùkún Jèhófà nítorí títọ ipa ọ̀nà ìṣòtítọ́. À ń tipa báyìí tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù àti àpẹẹrẹ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ àkọ́kọ́ àti àpẹẹrẹ gbogbo àwọn ọkùnrin àtobìnrin ìgbàgbọ́ tí wọ́n ti “gbéṣirò” tí ó tọ́ “lé” ohun tí sísin Ọlọ́run máa ná wọn láti ọdún wọ̀nyí wá.—Máàkù 1:16-20; Hébérù 11:4, 7, 17, 24, 25, 32-38.