Wọ́n Borí Inúnibíni
Wọ́n Borí Inúnibíni
ỌDÚN 1911 ni wọ́n bí Frieda Jess ní Denmark. Obìnrin yìí àtàwọn òbí rẹ̀ sì ti ibẹ̀ kó lọ sí Husum ní àríwá ilẹ̀ Jámánì. Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà ló bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ ní Magdeburg, nígbà tó sì di ọdún 1930, ó ṣe ìrìbọmi gẹ́gẹ́ bí Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, bí wọ́n ti ń pe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà yẹn. Ọdún 1933 ni Hitler gorí àlééfà, ìyẹn sì jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ ọdún mẹ́tàlélógún gbáko tí Frieda fi jìyà lábẹ́ ìjọba oníkùmọ̀ méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.
March ọdún 1933 ni ìjọba Jámánì sọ pé kí gbogbo èèyàn dìbò. Ọ̀mọ̀wé Detlef Garbe, tó jẹ́ olórí Ibi Ìrántí Àgọ́ Ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ Neuengamme tó wà nítòsí Hamburg, ṣàlàyé pé: “Àwọn tó wà nínú Ìjọba Násì fẹ́ fagbára mú ọ̀pọ̀ èèyàn láti dìbò fún Adolf Hitler tó jẹ́ olórí ìjọba àti aṣáájú wọn.” Àmọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ Jésù pé kí wọ́n jẹ́ aláìdásí-tọ̀túntòsì nínú ọ̀ràn ìṣèlú, kí wọ́n sì jẹ́ ẹni tí “kì í ṣe apá kan ayé,” nítorí náà wọn ò dìbò. Kí ni àbájáde rẹ̀? Wọ́n fòfin de àwọn Ẹlẹ́rìí náà.—Jòhánù 17:16.
Frieda ń bá ìgbòkègbodò Kristẹni rẹ̀ lọ ní bòókẹ́lẹ́, kódà ó ń ṣèrànwọ́ láti tẹ àwọn ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ jáde. Ó tiẹ̀ sọ pé: “A yọ́ kó lára àwọn ìwé ìròyìn náà wọnú àwọn àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ nítorí àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa tó wà níbẹ̀.” Wọ́n mú un ní 1940, àwọn Àjọ Ọlọ́pàá Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ Gestapo sì fọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò, ẹ̀yìn ìyẹn ló wá lo ọ̀pọ̀ oṣù ní àhámọ́ àdáwà. Báwo ló ṣe fara dà á? Ó ní: “Àdúrà ni ààbò mi. Mo máa ń bẹ̀rẹ̀ àdúrà gbígbà láàárọ̀ kùtù hàì, màá sì gbàdúrà lọ́pọ̀ ìgbà lójúmọ́. Àdúrà fún mi lókun, ó sì ràn mí lọ́wọ́ láti má ṣe ṣàníyàn jù.”—Fílípì 4:6, 7.
Wọ́n dá Frieda sílẹ̀, àmọ́ àwọn Àjọ Ọlọ́pàá Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ Gestapo tún mú un ní 1944. Lọ́tẹ̀ yìí, ọdún méje gbáko ni wọ́n ní kó lọ lò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n Waldheim. Frieda ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó ní: “Àwọn ẹ̀ṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n náà ní kí èmi àtàwọn obìnrin bíi mélòó kan mìíràn máa ṣiṣẹ́ láwọn balùwẹ̀ àti ilé ìgbọ̀nsẹ̀. Èmi àti ẹlẹ́wọ̀n kan tó wá láti Czechoslovakia la sábà máa ń ṣiṣẹ́ pọ̀, ìyẹn ni mo fi ráyè bá a sọ̀rọ̀ tó pọ̀ gan-an nípa Jèhófà àti nípa ìgbàgbọ́ mi. Àwọn ìfọ̀rọ̀wérọ̀ wọ̀nyẹn fún mi lágbára gan-an.”
Wọ́n Dá Mi Sílẹ̀, àmọ́ Fúngbà Díẹ̀ Ni
Àwọn ọmọ ogun Soviet dá àwọn tó wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n Waldheim nídè ní May 1945, Frieda sì lómìnira àtipadà sí Magdeburg àti sẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, àmọ́ fúngbà díẹ̀ ni. Wọ́n tún bẹ̀rẹ̀ sí ṣe kèéta àwọn Ẹlẹ́rìí, àmọ́ àwọn aláṣẹ Ẹ̀ka Iṣẹ́ ti Soviet ló wà nídìí ọ̀ràn náà lọ́tẹ̀ yìí. Gerald Hacke tó wà ní Ibùdó Ìṣèwádìí Ọ̀ràn Ìjọba Oníkùmọ̀ ti Hannah-Arendt kọ̀wé pé: “Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹgbẹ́ àwùjọ bíi mélòó kan tí àwọn aláṣẹ bóofẹ́bóokọ̀ méjèèjì tó wà nílẹ̀ Jámánì máa ń ṣenúnibíni sí ṣáá.”
Kí ló fa kèéta tí wọ́n tún bẹ̀rẹ̀ lákọ̀tun yìí? Lẹ́ẹ̀kan sí i, olórí ohun tó fà á ni àìdásí-tọ̀túntòsì Kristẹni. Ní 1948, Ìlà Oòrùn Jámánì ṣètò ìdìbò kan tí gbogbo àwọn tó wà nílùú kópa nínú rẹ̀,
torí náà gẹ́gẹ́ bí àlàyé tí Hacke ṣe, “olórí ohun tó fa [inúnibíni tí wọ́n ṣe sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà] ni pé wọn ò kópa nínú ìdìbò yẹn.” August 1950 ni wọ́n wá fòfin de àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Ìlà Oòrùn Jámánì. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún Ẹlẹ́rìí ni wọ́n fọlọ́pàá mú, títí kan Frieda.Bí Frieda tún ṣe bára rẹ̀ nílé ẹjọ́ nìyẹn, wọ́n sì rán an lọ sẹ́wọ̀n ọdún mẹ́fà gbáko. Ó ní: “Èmi àtàwọn onígbàgbọ́ bíi tèmi la jọ wà pa pọ̀ lọ́tẹ̀ yìí, ìbákẹ́gbẹ́ yẹn sì ṣèrànwọ́ gan-an ni.” Nígbà tí wọn dá a sílẹ̀ lọ́dún 1956, Ìwọ̀ Oòrùn Jámánì ló forí lé. Frieda ti di ẹni àádọ́rùn-ún ọdún, ó ń gbé ní Husum báyìí, ó ṣì ń sin Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́ náà di bá a ti ń sọ̀rọ̀ yìí.
Ọdún mẹ́tàlélógún gbáko ni Frieda fi fojú winá inúnibíni lábẹ́ ìjọba àwọn aláṣẹ bóofẹ́bóokọ̀ méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ohun tó sọ ni pé: “Ìjọba Násì fẹ́ pa mi; àwọn Kọ́múníìsì fẹ́ ba ìwà títọ́ mi jẹ́. Ibo ni mo ti rí okun tí mo fi kojú wọn? Kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì dáadáa nígbà tí mo bá wà lómìnira, àdúrà ìgbà gbogbo nígbà tí mo bá dá nìkan wà, ìbákẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ ní ìgbàkigbà tó bá ṣeé ṣe, àti sísọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ mi fáwọn ẹlòmíràn ní gbogbo ìgbà tí àyè ẹ̀ bá yọ.”
Ìjọba Aláṣẹ Oníkùmọ̀ ní Hungary
Orílẹ̀-èdè mìíràn táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tún ti fara da ọ̀pọ̀ ọdún táwọn èèyàn fi ṣe kèéta wọn ni Hungary. Kì í tiẹ̀ ṣe ìjọba aláṣẹ oníkùmọ̀ méjì péré ló ṣe inúnibíni sáwọn kan bí kò ṣe mẹ́ta tọ̀ọ̀tọ̀. Àpẹẹrẹ kan ni ti Ádám Szinger. Wọ́n bí Ádám ní Paks, Hungary, ní 1922, inú ẹ̀sìn Pùròtẹ́sítáǹtì ni wọ́n sì ti tọ́ ọ dàgbà. Ní 1937, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan wá sílé Ádám, ojú ẹsẹ̀ ló sì fìfẹ́ hàn sí ìwàásù wọn. Ohun tó kọ́ nínú Bíbélì mú kó dá a lójú pé àwọn ẹ̀kọ́ tí ṣọ́ọ̀ṣì rẹ̀ fi ń kọ́ni kò bá Bíbélì mu rárá. Bó ṣe fi Ṣọ́ọ̀ṣì Pùròtẹ́sítáǹtì sílẹ̀ nìyẹn tó dara pọ̀ mọ́ àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn.
Agbára ìjọba aláṣẹ oníkùmọ̀ wá ń pọ sí i ní Hungary. Ó tó ìgbà bíi mélòó kan táwọn ọlọ́pàá rí Ádám níbi tó ti ń wàásù láti ilé dé ilé, tí wọ́n sì mú un kí wọ́n lè fọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò. Ogun tí wọ́n ń fún mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí túbọ̀ ń pọ̀ sí i, nígbà tó sì di ọdún 1939, wọ́n wá fòfin de iṣẹ́ wọn. Ní 1942, wọ́n mú Ádám lọ sọ́gbà ẹ̀wọ̀n, wọ́n sì lù ú bíi pé kó kú. Kí ló ràn án lọ́wọ́ lọ́mọ ọdún mọ́kàndínlógún, tó fi lè fara da ìjìyà àti ọ̀pọ̀ oṣù tó lò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n? Ó ní: “Nígbà tí mo wa nílé, mo fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì dáadáa, mo sì rí i pé mo lóye àwọn ète Jèhófà dáadáa.” Ẹ̀yìn ìgbà tí wọ́n tú Ádám sílẹ̀ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n ló wá ṣèrìbọmi gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí fún Jèhófà nígbẹ̀yìngbẹ́yín. Alẹ́ nínú òkùnkùn ló ṣe ìrìbọmi yẹn ní August 1942, nínú odò kan tó wa nítòsí ilé rẹ̀.
Ẹ̀wọ̀n ní Hungary, Àgọ́ Ìfìyàjẹni Oníṣẹ́ Àṣekára ní Serbia
Láàárín àkókò tí ogun àgbáyé kejì ń lọ lọ́wọ́, Hungary dara pọ̀ mọ́ Jámánì láti bá Soviet Union jagun. Bí wọ́n ṣe pe Ádám nìyẹn pé kó wá wọṣẹ́ ológun nígbà ìwọ́wé ọdún 1942. Ó ròyìn pé: “Mo sọ fún wọn pé mi ò lè ṣiṣẹ́ ológun nítorí ẹ̀kọ́ tí mo ti kọ́ nínú Bíbélì. Mo ṣàlàyé fún wọn bí mo ṣe wà láìdásí tọ̀túntòsì.” Wọ́n rán an lọ sí ẹ̀wọ̀n ọdún mọ́kànlá. Àmọ́ Ádám ò pẹ́ púpọ̀ ní Hungary.
Nǹkan bí ọgọ́jọ [160] àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n kó láti onírúurú ibi ní ọdún 1943, wọ́n kó wọn sínú ọkọ̀ ojú omi akẹ́rù, wọ́n sì kó wọn gba Odò Danube lọ sí Serbia. Ádám wà lára wọn. Serbia làwọn ẹlẹ́wọ̀n wọ̀nyí ti wá wà lábẹ́ Ìjọba Násì tí Hitler ń ṣàkóso. Wọ́n há wọn mọ́ inú àgọ́ ìfìyàjẹni oníṣẹ́ àṣekára ní Bor, wọ́n sì ń fagbára kó wọn ṣiṣẹ́ níbi tí wọ́n ti ń wa bàbà. Nǹkan bí ọdún kan lẹ́yìn ìyẹn ni wọ́n tún kó wọn padà sí Hungary, níbi táwọn ọmọ ogun Soviet ti tú Ádám sílẹ̀ nígbà ìrúwé ọdún 1945.
Ó Wà ní Hungary Lábẹ́ Ìṣàkóso Kọ́múníìsì
Àmọ́ òmìnira yìí ò pẹ́ rárá. Nígbà tó fi máa di òpin àwọn ọdún 1940, ìjọba Kọ́múníìsì tún gbẹ́sẹ̀ lé iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, báwọn Ìjọba Aláṣẹ Oníkùmọ̀ ti ṣe gẹ́lẹ́ kí ogun tó bẹ̀rẹ̀. Ọdún 1952 ni wọ́n tún mú Ádám, ó ti di ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n, ó ti gbéyàwó, ó sì ti bímọ méjì lákòókò tá à ń wí yìí. Wọ́n mú un, wọ́n sì fẹ̀sùn
ìwà ipá kàn án nígbà tó tún kọ láti wọṣẹ́ ológun. Ádám ṣàlàyé fún ilé ẹjọ́ náà pé: “Èyí kì í ṣe ìgbà àkọ́kọ́ tí mo kọ̀ láti wọṣẹ́ ológun. Nígbà tí ogun ń jà lọ́wọ́, mo lọ sẹ́wọ̀n, wọ́n sì gbé mi lọ sí Serbia nítorí ọ̀ràn kan náà yìí. Tìtorí ẹ̀rí ọkàn mi ni mo ṣe kọ̀ láti wọṣẹ́ ológun. Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mi, mi ò sì ń lọ́wọ́ nínú ọ̀ràn ìṣèlú.” Ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́jọ ni wọ́n kọ́kọ́ dá fún Ádám, àmọ́ wọ́n wá dín in kù sí mẹ́rin nígbà tó yá.Ádám ṣáà ń bá bí wọ́n ṣe ń gbógun tì í yìí lọ títí di agbedeméjì àwọn ọdún 1970, ìyẹn ọdún márùndínlógójì lẹ́yìn táwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kọ́kọ́ wá sílé àwọn òbí rẹ̀. Látìbẹ̀rẹ̀ dópin àkókò tá a wí yìí, ọdún mẹ́tàlélógún gbáko ni ilé ẹjọ́ mẹ́fà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ fi rán an lọ sáwọn ọgbà ẹ̀wọ̀n àtàwọn àgọ́ bíi mẹ́wàá tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ tó ti ṣẹ̀wọ̀n. Ó fara da inúnibíni lábẹ́ ìjọba mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀—Ìjọba Aláṣẹ Oníkùmọ̀ ní Hungary ṣáájú ogun, Ìjọba Násì ti Jámánì ní Serbia, àti Kọ́múníìsì ní Hungary nígbà ọ̀tẹ̀ abẹ́lẹ̀.
Ádám ṣì ń gbé ní Paks ìlú rẹ̀ di bá a ti ń sọ̀rọ̀ yìí, ó ń fi ìṣòtítọ́ sin Ọlọ́run níbẹ̀. Ṣé ó láwọn ànímọ́ àrà ọ̀tọ̀ tó mú kó lè fara da àwọn ìṣòro náà tayọ̀tayọ̀ ni? Rárá o. Ó ṣàlàyé pé:
“Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àdúrà, àti bíbá àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ ẹni kẹ́gbẹ́ ṣe pàtàkì gan-an. Àmọ́ mà á tún fẹ́ mẹ́nu kan kókó méjì mìíràn. Lákọ̀ọ́kọ́, Jèhófà ni Orísun okun. Àjọṣe tímọ́tímọ́ tí mo ní pẹ̀lú rẹ̀ ló gba ẹ̀mí mi là. Èkejì ni pé, mo máa ń rántí ohun tó wà nínú Róòmù orí Kejìlá ṣáá ni, èyí tó sọ pé: ‘Ẹ má ṣe gbẹ̀san fúnra yín.’ Nítorí náà, mi ò di kùnrùngbùn sí ẹnikẹ́ni rí. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo láǹfààní àtigbẹ̀san lára àwọn tó ń ṣenúnibíni sí mi, àmọ́ mi ò jẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀. A ò gbọ́dọ̀ lo okun tí Jèhófà fún wa láti fi búburú san búburú.”
Fífòpin sí Gbogbo Inúnibíni
Frieda àti Ádám ti láǹfààní láti jọ́sìn Jèhófà láìsí ìdíwọ́ kankan mọ́ báyìí. Àmọ́ kí làwọn ìrírí bíi tiwọn yìí fi hàn nípa inúnibíni táwọn èèyàn máa ń ṣe nítorí ẹ̀sìn? Ó jẹ́ ká mọ̀ pé irú inúnibíni bẹ́ẹ̀ kì í kẹ́sẹ járí, àgàgà nígbà tí wọ́n bá ṣe é sáwọn ojúlówó Kristẹni. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé inúnibíni tí wọ́n ṣe sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ọ̀pọ̀ ohun ìní ṣòfò, ó sì fa ìjìyà tó burú jáì, síbẹ̀ ó kùnà láti ṣe ohun tí wọ́n fẹ́ kó ṣe. Lónìí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń gbá yìn ìn nílẹ̀ Yúróòpù, níbi táwọn ìjọba bóofẹ́bóokọ̀ méjì tó lágbára gan-an ti jẹ gàba nígbà kan rí.
Irú ojú wo làwọn ẹlẹ́rìí fi wo inúnibíni? Gẹ́gẹ́ bí ohun tá a rí nínú ìrírí Frieda àti Ádám, wọ́n fi àwọn ìmọ̀ràn Bíbélì sílò, èyí tó sọ pé: “Má ṣe jẹ́ kí ibi ṣẹ́gun rẹ, ṣùgbọ́n máa fi ire ṣẹ́gun ibi.” (Róòmù 12:21) Ǹjẹ́ rere lè ṣẹ́gun ibi lóòótọ́? Bẹ́ẹ̀ ni o, ìyẹn tó bá ní í ṣe pẹ̀lú ìgbàgbọ́ lílágbára nínú Ọlọ́run. Bíborí táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà borí inúnibíni nílẹ̀ Yúróòpù jẹ́ ìṣẹ́gun ẹ̀mí Ọlọ́run, ó jẹ́ ìfihàn agbára rere tó ń wá látinú ìgbàgbọ́ tí ẹ̀mí mímọ́ ń mú jáde nínú àwọn Kristẹni onírẹ̀lẹ̀. (Gálátíà 5:22, 23) Ẹ̀kọ́ tó yẹ kí gbogbo wa fi sọ́kàn nínú ayé oníwà ipá tá a wà yìí nìyẹn.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Frieda Jess, (tó ti di Thiele báyìí) ní àkókò tí wọ́n mú un àti nísinsìnyí
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Ádám Szinger, ní àkókò tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n àti nísinsìnyí