Ojú Tí Jèhófà Fi Ń wo Àwọn Ẹlòmíràn Ni Kó O Máa Fi Wò Wọ́n
Ojú Tí Jèhófà Fi Ń wo Àwọn Ẹlòmíràn Ni Kó O Máa Fi Wò Wọ́n
“Kì í ṣe ọ̀nà tí ènìyàn gbà ń wo nǹkan ni Ọlọ́run gbà ń wo nǹkan.”—1 SÁMÚẸ́LÌ 16:7.
1, 2. Báwo ni ojú tí Jèhófà fi wo Élíábù ṣe yàtọ̀ pátápátá sí ojú tí Sámúẹ́lì fi wò ó, ẹ̀kọ́ wo la sì lè rí kọ́ nínú èyí?
NÍ Ọ̀RÚNDÚN kọkànlá ṣááju Sànmánì Tiwa, Jèhófà rán wòlíì Sámúẹ́lì ní iṣẹ́ bòókẹ́lẹ́ kan. Ó pàṣẹ fún wòlíì náà pé kó lọ sí ilé ọkùnrin kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jésè kó sì fòróró yan ọ̀kan lára àwọn ọmọ Jésè láti di ọba lọ́la ní Ísírẹ́lì. Nígbà tí Sámúẹ́lì rí Élíábù àkọ́bí Jésè, ó dá a lójú pé òun ti rí ẹni náà gan-an tí Ọlọ́run yàn. Àmọ́ Jèhófà sọ pé: “Má wo ìrísí rẹ̀ àti gíga rẹ̀ ní ìdúró, nítorí pé èmi ti kọ̀ ọ́. Nítorí kì í ṣe ọ̀nà tí ènìyàn gbà ń wo nǹkan ni Ọlọ́run gbà ń wo nǹkan, nítorí pé ènìyàn lásán-làsàn ń wo ohun tí ó fara hàn sí ojú; ṣùgbọ́n ní ti Jèhófà, ó ń wo ohun tí ọkàn-àyà jẹ́.” (1 Sámúẹ́lì 16:6, 7) Sámúẹ́lì ti kùnà láti fi ojú tí Jèhófà fi wo Élíábù wò ó. a
2 Ẹ ò rí i pé ó rọrùn gan-an kéèyàn ṣàṣìṣe nípa irú ojú tó fi ń wo àwọn ẹlòmíràn! Lọ́nà kan, a lè fi àṣìṣe gba tàwọn kan tí ìrísí wọn fani mọ́ra gan-an àmọ́ tó jẹ́ pé apanilẹ́kún-jayé ni wọ́n. Lọ́nà mìíràn, a lè máà fẹ́ rí àwọn kan tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ èèyàn sójú rárá, ká kórìíra wọn bí nǹkan míì nítorí pé ìwà àbímọ́ni wọn máa ń bí wa nínú.
3, 4. (a) Bí aáwọ̀ bá wà láàárín àwọn Kristẹni méjì, kí ló yẹ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn pinnu láti ṣe? (b) Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ ká bi ara wa nígbà tí aáwọ̀ bá wà láàárín àwa àti ẹnì kan tó jẹ́ onígbàgbọ́ bíi tiwa?
3 Àwọn ìṣòro lè dìde tá a bá tètè ń dá àwọn ẹlòmíràn lẹ́jọ́—kódà àwọn tá a ti mọ̀ tipẹ́ pàápàá. Ó ṣeé ṣe kí aáwọ̀ wà láàárín ìwọ àti Kristẹni kan tó ti fìgbà kan jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ tímọ́tímọ́. Ṣé wàá fẹ́ kí ìjà náà parí kẹ́ ẹ sì tún padà di ọ̀rẹ́ bíi ti àtẹ̀yìnwá? Kí ló máa ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣe èyí?
4 O ò ṣe fara balẹ̀ wo Kristẹni arákùnrin tàbí arábìnrin rẹ yìí dáadáa? Kó o sì ṣe èyí lójú ìwòye ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé: “Kò sí ènìyàn kankan tí ó lè wá sọ́dọ̀ mi láìjẹ́ pé Baba, tí ó rán mi, fà á.” (Jòhánù 6:44) Kó o wá bi ara rẹ pé: ‘Kí nìdí tí Jèhófà fi fa ẹni yìí sọ́dọ̀ Ọmọ rẹ̀? Àwọn ànímọ́ fífanimọ́ra wo ni ẹni yìí ní? Ṣé mò ń gbójú fo àwọn ànímọ́ wọ̀nyí tẹ́lẹ̀ ni, àbí ńṣe ni mi ò tiẹ̀ kà wọ́n kún? Kí nìdí tá a tiẹ̀ fi ń bára wa ṣọ̀rẹ́ tẹ́lẹ̀? Kí ló fà á ti mo fi fi ẹni yìí ṣọ̀rẹ́ tẹ́lẹ̀?’ Lákọ̀ọ́kọ́, ó lè má rọrùn fún ọ láti rí ànímọ́ kankan tó dára lára onítọ̀hún, àgàgà tó bá ti pẹ́ díẹ̀ tẹ́ ẹ ti jọ ń bínú síra yín. Àmọ́, ìgbésẹ̀ pàtàkì tẹ́ ẹ lè gbé láti tún padà dọ̀rẹ́ nìyí. Láti ṣàkàwé ọ̀nà tá a lè gbà ṣe èyí, ẹ jẹ́ ká wo àwọn ànímọ́ rere tá a lè rí lára àwọn ọkùnrin méjì tó jẹ́ pé ojú àṣìṣe tí wọ́n ṣe la fi ń wò wọ́n nígbà míì. Wòlíì Jónà àti àpọ́sítélì Pétérù ni.
Fífi Ojú Tó Tọ́ Wo Irú Ẹni Tí Jónà Jẹ́
5. Iṣẹ́ wo la gbé lé Jónà lọ́wọ́, kí ló sì ṣe?
5 Jónà sìn gẹ́gẹ́ bíi wòlíì fún ìjọba àríwá Ísírẹ́lì nígbà ayé Jèróbóámù Ọba Kejì tó jẹ́ ọmọkùnrin Jèhóáṣì. (2 Àwọn Ọba 14:23-25) Lọ́jọ́ kan, Jèhófà pàṣẹ fún Jónà láti fi Ísírẹ́lì sílẹ̀ kó sì rìnrìn àjò lọ sí Nínéfè, olú ìlú Ilẹ̀ Ọba Ásíríà alágbára. Iṣẹ́ wo la yàn fún un? Iṣẹ́ náà ni pé kó lọ kìlọ̀ fáwọn olùgbé ibẹ̀ pé a ó pa ìlú ńlá wọn alágbára run. (Jónà 1:1, 2) Dípò kí Jónà ṣe ohun tí Ọlọ́run rán an yìí, ńṣe ló fẹsẹ̀ fẹ! Ó lọ wọ ọkọ̀ òkun tó ń lọ sí Táṣíṣì, ìyẹn ìlú kan tó jìnnà gan-an sí Nínéfè.—Jónà 1:3.
6. Kí nìdí tí Jèhófà fi yan Jónà láti lọ sí Nínéfè?
6 Kí ló máa ń wá sọ́kàn rẹ nígbà tó o bá ronú nípa Jónà? Ṣé o máa ń ronú pé wòlíì tó ya aláìgbọràn ni? Tá a bá wò ó láìronú lórí ọ̀ràn náà dáadáa, a lè sọ pé bó ṣe jẹ́ nìyẹn. Àmọ́ ṣe tìtorí pé Jónà jẹ́ aláìgbọràn ni Jèhófà ṣe yàn án gẹ́gẹ́ bíi wòlíì? Kò gbọ́dọ̀ jẹ́ bẹ́ẹ̀! Jónà ti ní láti ní àwọn ànímọ́ kan tó dára. Ṣàgbéyẹ̀wò àkọsílẹ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi wòlíì.
7. Lábẹ́ àwọn ipò wo ni Jónà ti sin Jèhófà ní Ísírẹ́lì, ipa wo sì ni mímọ̀ tó o mọ èyí ní lórí èrò rẹ̀ nípa rẹ̀?
7 Jónà ti fi ìṣòtítọ́ ṣiṣẹ́ àṣekára ní Ísírẹ́lì, ìyẹn ìpínlẹ̀ kan tó jẹ́ pé kì í gbọ́ kì í gbà làwọn ará ibẹ̀. Wòlíì Ámósì, tí òun àti Jónà jọ gbé ayé lákòókò kan náà, ṣàpèjúwe àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ayé ìgbà yẹn gẹ́gẹ́ bí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ fàájì bi nǹkan míì. b Àwọn ohun búburú ń ṣẹlẹ̀ lórílẹ̀-èdè náà o, àmọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò wo apá ibẹ̀ rárá. (Ámósì 3:13-15; 4:4; 6:4-6) Síbẹ̀, Jónà fi ìṣòtítọ́ ṣe iṣẹ́ tá a yàn fún un pé kó wàásù fún wọn. Tó o bá jẹ́ olùpòkìkí ìhìn rere náà, wàá mọ bó ṣe nira tó láti máa bá àwọn èèyàn tó rò pé àwọn ti ní gbogbo nǹkan tán, tí wọn ò sì ka èèyàn sí sọ̀rọ̀. Nítorí náà, bá a ṣe ń wo àwọn ìkùdíẹ̀ káàtó tí Jónà ní, ẹ má ṣe jẹ́ ká gbàgbé àwọn ànímọ́ ìṣòtítọ́ àti ìfaradà rẹ̀ bó ṣe ń wàásù fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì aláìnígbàgbọ́.
8. Ìṣòro líle koko wo ni ọmọ Ísírẹ́lì kan tó jẹ́ wòlíì máa dojú kọ ní Nínéfè?
8 Iṣẹ́ lílọ sí Nínéfè wá nira gan-an ju gbogbo ti àtẹ̀yìnwá. Kí Jónà tó lè dé ìlú ńlá yẹn, ó máa fi ẹsẹ̀ rin ìrìn àjò nǹkan bí ẹgbẹ̀rin kìlómítà—ìrìn àjò tí kì í ṣe kékeré, tó máa gbà tó nǹkan bí oṣù kan gbáko ni. Gbàrà tí wòlíì yìí bá débẹ̀ ló máa bẹ̀rẹ̀ sí wàásù fáwọn ará Ásíríà, tí gbogbo èèyàn mọ mọ́ ìwà òǹrorò wọn. Dídáni lóró lọ́nà tó burú jáì jẹ́ ara ọ̀nà tí wọ́n gbà ń ja ogun tiwọn. Wọ́n tiẹ̀ máa ń fi ìwà òǹrorò wọn yangan. Abájọ tí wọ́n fi pe Nínéfè ní “ìlú ńlá ìtàjẹ̀sílẹ̀”!—Náhúmù 3:1, 7.
9. Nígbà tí ìjì líle fẹ́ gbẹ̀mí àwọn afòkunṣọ̀nà, àwọn ànímọ́ wo ni Jónà fi hàn?
9 Kí Jónà má bàá ṣègbọràn sí àṣẹ Jèhófà, ó wọ ọkọ̀ òkun tó gbé e lọ síbi tó jìnnà réré sí ibi iṣẹ́ tá a yàn fún un. Síbẹ̀síbẹ̀, Jèhófà ò kọ ìránṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀ tàbí kó fi ẹlòmíràn rọ́pò rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni Jèhófà pe orí Jónà wálé. Ọlọ́run mú kí ìjì líle kan bẹ̀rẹ̀ sí jà lórí òkun. Ìgbì omi náà ń gbé ọkọ̀ tí Jónà wà nínú rẹ̀ káàkiri. Ó kù díẹ̀ káwọn aláìmọwọ́mẹsẹ̀ pàdánù ẹ̀mí wọn, Jónà ló sì ṣokùnfà gbogbo rẹ̀! (Jónà 1:4) Kí ni kí Jónà wá ṣe? Nítorí pé Jónà ò fẹ́ káwọn atukọ̀ ojú omi tí wọ́n wà lókè ọkọ náà pàdánù ẹ̀mí wọn, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ gbé mi, kí ẹ sì jù mí sínú òkun, òkun yóò sì pa rọ́rọ́ fún yín.” (Jónà 1:12) Kò sóhun tó lè mú kí Jónà ronú pé nígbà táwọn afòkunṣọ̀nà bá ju òun sómi, Jèhófà yóò ṣe ọ̀nà àbájáde fún òun. (Jónà 1:15) Bó ti wù kó rí, Jónà múra tán láti fi ẹ̀mí ara rẹ̀ jinkú káwọn atukọ̀ ojú omi náà má bàa ṣègbé. Ǹjẹ́ a rí ànímọ́ ìgboyà, ìrẹ̀lẹ̀ àti ìfẹ́ tó fi hàn níhìn-ín?
10. Kí ló ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí Jèhófà mú kí Jónà padà sẹ́nu iṣẹ́ tó yàn fún un?
10 Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, Jèhófà gba Jónà là. Ǹjẹ́ ohun tí Jónà ṣe yìí sọ ọ́ di ẹni tí kò tóótun láti ṣojú fún Ọlọ́run mọ́? Ó tì o, tàánútàánú àti tìfẹ́tìfẹ́ ni Jèhófà fi mú kí wòlíì náà padà sẹ́nu iṣẹ́ tó yàn fún un pé kó wàásù fáwọn ará Nínéfè. Nígbà tí Jónà gúnlẹ̀ sí Nínéfè, ó fi ìgboyà sọ fún àwọn olùgbé ibẹ̀ pé ìwà búburú wọn ti dé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run àti pé a ó pa ìlú ńlá wọn run ní ogójì ọjọ́ sí i. (Jónà 1:2; 3:4) Lẹ́yìn tí wọ́n gbọ́ ìkéde tí Jónà ṣe láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ yìí, àwọn ará Nínéfè ronú pìwà dà, ìlú wọn ò sì pa run mọ́.
11. Kí ló fi hàn pé Jónà kọ́ ẹ̀kọ́ pàtàkì?
11 Síbẹ̀, ojú tí Jónà fi ń wo nǹkan kò tíì dára. Àmọ́ nípasẹ̀ ẹ̀kọ́ gbígbéṣẹ́ kan, Jèhófà ran Jónà lọ́wọ́ láti mọ̀ pé Òun ń rí kọjá kìkì ìrísí òde. Òun máa ń ṣàyẹ̀wò ọkàn èèyàn. (Jónà 4:5-11) Pé Jónà kọ́ ẹ̀kọ́ pàtàkì kan la rí ẹ̀rí rẹ̀ kedere nínú àkọsílẹ̀ tí òun fúnra rẹ̀ kọ láìfi ohunkóhun pa mọ́. Bó ṣe múra tán láti ròyìn àwọn àṣìṣe tiẹ̀ fúnra rẹ̀ láìfi ibi tó lè tini lójú níbẹ̀ pàápàá pa mọ́ túbọ̀ fi ẹ̀rí hàn pé ó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. Ìgboyà ló lè mú kéèyàn gbà pé òun ṣe àṣìṣe!
12. (a) Báwo la ṣe mọ̀ pé ojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn èèyàn ni Jésù náà fi ń wò wọ́n? (b) Irú èrò wo la gbà wá níyànjú láti ní nípa àwọn tá à ń wàásù ìhìn rere náà fún? (Wo àpótí tó wà lójú ìwé 18.)
12 Ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́yìn ìyẹn, Jésù Kristi sọ ọ̀rọ̀ ìwúrí nípa ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó wáyé nínú ìgbésí ayé Jónà. Ó ní: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí Jónà ti wà ní ikùn ẹja mùmùrara náà fún ọ̀sán mẹ́ta àti òru mẹ́ta, bẹ́ẹ̀ náà ni Ọmọ ènìyàn yóò wà ní àárín ilẹ̀ ayé fún ọ̀sán mẹ́ta àti òru mẹ́ta.” (Mátíù 12:40) Nígbà tí Jónà bá jíǹde, yóò gbọ́ pé Jésù fi àkókò tí Òun fúnra rẹ̀ lò nínú ibojì wé àkókò ṣíṣókùnkùn biribiri yìí nínú ìgbésí ayé wòlíì náà. Ǹjẹ́ inú wa ò dùn láti sin Ọlọ́run tí kì í kọ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ṣe àṣìṣe? Onísáàmù náà kọ̀wé pé: “Bí baba ti ń fi àánú hàn sí àwọn ọmọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà ń fi àánú hàn sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀. Nítorí tí òun fúnra rẹ̀ mọ ẹ̀dá wa, ó rántí pé ekuru ni wá.” (Sáàmù 103:13, 14) Láìṣe àní-àní, “eruku” yìí—títí kan àwọn aláìpé ènìyàn lónìí—lè ṣe ohun púpọ̀ láṣeyanjú pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run!
Èrò Tó Yẹ Ká Ní Nípa Pétérù
13. Àwọn ànímọ́ tí Pétérù ní wo ló lè wá síni lọ́kàn, àmọ́ kí nìdí tí Jésù fi yàn án gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì?
13 Wàyí o, ẹ jẹ́ ká sáré gbé àpẹẹrẹ kejì yẹ̀ wò, ìyẹn ni ti àpọ́sítélì Pétérù. Tí wọ́n bá ní kó o ṣàpèjúwe Pétérù, ṣé ohun tó máa wá sí ọ lọ́kàn lójú ẹsẹ̀ ni pé oníwàdùwàdù ẹ̀dá ni, kódà ọ̀yájú èèyàn ni pàápàá? Lóòótọ́ ni Pétérù ń ṣe bẹ́ẹ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Àmọ́, ká ní Pétérù jẹ́ oníwàdùwàdù, tàbí ọ̀yájú ní ti tòótọ́, ǹjẹ́ Jésù ì bá yàn án gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ méjìlá? (Lúùkù 6:12-14) Rárá o! Jésù gbójú fo àwọn àléébù wọ̀nyí, ó sì rí i pé Pétérù láwọn ànímọ́ tó dáa.
14. (a) Kí ló ṣeé ṣe kó fà á tí Pétérù fi jẹ́ ẹni tí kì í fi ọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ? (b) Kí nìdí tó fi yẹ kínú wa dùn pé Pétérù máa ń béèrè ìbéèrè lóòrèkóòrè?
14 Pétérù máa ń ṣe bí agbẹnusọ fáwọn àpọ́sítélì yòókù nígbà mìíràn. Àwọn kan lè wo èyí gẹ́gẹ́ bí ohun tó fi hàn pé kì í ṣe ẹni tó mẹ̀tọ́mọ̀wà. Àmọ́ ṣe bọ́rọ̀ ṣe rí nìyẹn? Àwọn kan sọ pé ó ṣeé ṣe kí Pétérù dàgbà ju àwọn àpọ́sítélì yòókù lọ—pé bóyá ni ò dàgbà ju Jésù alára pàápàá. Tó bá jẹ́ pé bọ́rọ̀ ṣe rí nìyẹn, ìyẹn lè ràn wá lọ́wọ́ láti mọ ìdí tí Pétérù fi sábà máa ń kọ́kọ́ sọ̀rọ̀. (Mátíù 16:22) Àmọ́ ṣá o, àwọn nǹkan mìíràn wà tá a ní láti gbé yẹ̀ wò. Pétérù jẹ́ ẹni tẹ̀mí. Òùngbẹ ìmọ̀ tó ń gbẹ ẹ́ ló jẹ́ kó máa béèrè àwọn ìbéèrè. Èyí sì ti ṣe wá láǹfààní gan-an. Jésù sọ àwọn ọ̀rọ̀ ṣíṣeyebíye mélòó kan tó fi dáhùn àwọn ìbéèrè Pétérù, àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sì wà nínú Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀rọ̀ kan tí Pétérù sọ ni Jésù ń fèsì rẹ̀ nígbà tó sọ̀rọ̀ nípa “olóòótọ́ ìríjú náà.” (Lúùkù 12:41-44) Ìwọ náà ronú nípa ìbéèrè tí Pétérù béèrè pé: “Àwa ti fi ohun gbogbo sílẹ̀, a sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn; kí ni yóò wà fún wa ní ti gidi?” Èyí ló wá mú kí Jésù ṣe ìlérí afúnnilókun náà pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ó bá ti fi àwọn ilé tàbí àwọn arákùnrin tàbí àwọn arábìnrin tàbí baba tàbí ìyá tàbí àwọn ọmọ tàbí àwọn ilẹ̀ sílẹ̀ nítorí orúkọ mi yóò rí gbà ní ìlọ́po-ìlọ́po sí i, yóò sì jogún ìyè àìnípẹ̀kun.”—Mátíù 15:15; 18:21, 22; 19:27-29.
15. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé Pétérù jẹ́ adúróṣinṣin ní ti tòótọ́?
15 Pétérù tún ní ànímọ́ rere mìíràn—adúróṣinṣin ni. Nígbà tí ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn sá kúrò lẹ́yìn Jésù nítorí pé wọn ò lóye ọ̀kan lára àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀, Pétérù ló gbẹnu sọ fáwọn àpọ́sítélì méjìlá yòókù, ó sọ pé: “Olúwa, ọ̀dọ̀ ta ni àwa yóò lọ? Ìwọ ni ó ní àwọn àsọjáde ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòhánù 6:66-68) Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn á mà mú ọkàn Jésù yọ̀ o! Nígbà tó yá, tí àwọn jàǹdùkú wá mú Ọ̀gá wọn, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ló fẹsẹ̀ fẹ. Àmọ́ Pétérù tẹ̀ lé ọ̀pọ̀lọpọ̀ èrò náà lọ jìnnà títí tó fi wọ àgbàlá àlùfáà àgbà. Ìgboyà ló jẹ́ kó lọ síbẹ̀, kì í ṣe ojo rárá. Nígbà tí wọ́n ń fọ̀rọ̀ wá Jésù lẹ́nu wò lọ́wọ́, Pétérù dara pọ̀ mọ́ àwùjọ àwọn Júù kan níbi tí wọ́n ti ń yáná. Ọ̀kan nínú àwọn ẹrú àlùfáà àgbà dá a mọ̀, ó sì fẹ̀sùn kàn án pé ó máa ń bá Jésù rìn. Lóòótọ́, Pétérù sẹ́ Ọ̀gá rẹ̀, àmọ́ ẹ máà jẹ́ ká gbàgbé pé ìdúróṣinṣin rẹ̀ àti àníyàn tó ní fún Jésù ló sún un sínú ipò líléwu yẹn, ipò tí èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn àpọ́sítélì kò nígboyà tó láti dojú kọ.—Jòhánù 18:15-27.
16. Kí nìdí pàtàkì tá a fi gbé àwọn ànímọ́ rere tí Jónà àti Pétérù ní yẹ̀ wò?
16 Àwọn ànímọ́ rere tí Pétérù ní pọ̀ gan-an ju àwọn àbùkù rẹ̀ lọ. Bákan náà lọ̀rọ̀ Jónà rí. Bá a ṣe wá ní èrò tó sunwọ̀n sí i nípa Jónà àti Pétérù ju ti tẹ́lẹ̀ lọ yìí, bákan náà la ṣe gbọ́dọ̀ kọ́ ara wa láti túbọ̀ ní èrò tó dáa nípa irú ojú tá a fi ń wo àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa nípa tẹ̀mí lóde òní. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yóò jẹ́ kí a ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú wọn. Kí nìdí tó fi pọn dandan fún wa láti ṣe èyí?
Fífi Ẹ̀kọ́ Náà Sílò Lónìí
17, 18. (a) Kí ló lè mú kí èdè àìyedè wáyé láàárín àwọn Kristẹni? (b) Ìmọ̀ràn Bíbélì wo ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti yanjú aáwọ̀ àárín àwa àtàwọn onígbàgbọ́ bíi tiwa?
17 Àtọkùnrin àtobìnrin àtàwọn ọmọdé tí wọ́n wá látinú ìdílé olówò tàbí tálákà, tí ìmọ̀ ẹ̀kọ́ wọn àti ẹ̀yà tí wọ́n ti wá yàtọ̀ síra, gbogbo wọn pátá ló ń fi ìṣọ̀kan sin Jèhófà lóde òní. (Ìṣípayá 7:9, 10) Ẹ ò rí i pé onírúurú ànímọ́ ló kúnnú ìjọ Kristẹni! Níwọ̀n bí a ti ń sin Ọlọ́run ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́, kò sọ́gbọ́n tá a lè rí dá sí i tí àìpé ò ní máa fara hàn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan.—Róòmù 12:10; Fílípì 2:3.
18 Bá a tilẹ̀ mọ ibi tí àwọn arákùnrin wa kù díẹ̀ káàtó sí, síbẹ̀ a ò ní máa wo ìwọ̀nyí nìkan. A ó sapá láti fara wé Jèhófà, ẹni tí onísáàmù náà kọrin nípa rẹ̀ pé: “Bí ó bá jẹ́ pé àwọn ìṣìnà ni ìwọ ń ṣọ́, Jáà, Jèhófà, ta ni ì bá dúró?” (Sáàmù 130:3) Dípò tá a ó fi máa wo àwọn ìwà àbímọ́ni tó lè pín wa níyà, a ó máa “lépa àwọn ohun tí ń yọrí sí àlàáfíà àti àwọn ohun tí ń gbéni ró fún ara wa lẹ́nì kìíní-kejì.” (Róòmù 14:19) A ó gbìyànjú láti máa fi ojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn ẹlòmíràn wò wọ́n, a ó máa gbójú fo àwọn àléébù wọn, a ó sì máa tẹjú mọ́ àwọn ànímọ́ rere tí wọ́n ní. Nígbà tá a bá ṣe èyí, ó máa ń ràn wá lọ́wọ́ láti ‘máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara wa lẹ́nì kìíní-kejì.’—Kólósè 3:13.
19. To àwọn ìgbésẹ̀ bíbójúmu tí Kristẹni kan lè gbé láti yanjú aáwọ̀ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé.
19 Bí èdè àìyedè bá wáyé tí ọ̀rọ̀ náà sì ń bà wá lọ́kàn jẹ́ ní gbogbo ìgbà ńkọ́? (Sáàmù 4:4) Ṣé irú èyí ti wáyé rí láàárín ìwọ àti ẹnì kan tẹ́ ẹ jọ jẹ́ onígbàgbọ́? O ò ṣe gbìyànjú àtiyanjú ọ̀ràn náà? (Jẹ́nẹ́sísì 32:13-15) Lákọ̀ọ́kọ́ ná, gbàdúrà sí Jèhófà, kó o bẹ̀ ẹ́ pé kó tọ́ ẹ sọ́nà. Lẹ́yìn náà, ronú nípa àwọn ànímọ́ rere tí onítọ̀hún ní, kó o sì tọ̀ ọ́ lọ pẹ̀lú “ìwà tútù tí ó jẹ́ ti ọgbọ́n.” (Jákọ́bù 3:13) Sọ fún un pé o fẹ́ ki ìjà tó wà láàárín yín parí. Rántí ìmọ̀ràn onímìísí yẹn, tó sọ pé: “Kí olúkúlùkù ènìyàn yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́, lọ́ra nípa ọ̀rọ̀ sísọ, lọ́ra nípa ìrunú.” (Jákọ́bù 1:19) Ìmọ̀ràn tó sọ pé “lọ́ra nípa ìrunú” fi hàn pé ẹnì kejì lè ṣe tàbí kó sọ ohun kan tó lè mú ọ bínú. Bí irú ìyẹn bá wáyé, bẹ Jèhófà pé kó ràn ọ́ lọ́wọ́ kó o lè lo ìkóra ẹni níjàánu. (Gálátíà 5:22, 23) Jẹ́ kí arákùnrin rẹ sọ gbogbo ohun tó ń bí i nínú, kó o sì fara balẹ̀ gbọ́ ohun tó ń sọ. Má ṣe dá ọ̀rọ̀ mọ́ ọn lẹ́nu, kódà bó ò tiẹ̀ fara mọ́ gbogbo nǹkan tó ń sọ. Ojú ìwòye rẹ̀ lè má tọ̀nà, àmọ́ bí ọ̀ràn náà ṣe rí lójú rẹ̀ lákòókò yẹn nìyẹn. Gbìyànjú láti wo ọ̀ràn náà bó ṣe ń wò ó. Ìyẹn lè túmọ̀ sí pé kó o fi ojú tí arákùnrin rẹ fi wò ọ́ yẹn tún ara rẹ wò.—Òwe 18:17.
20. Nígbà tẹ́ ẹ bá ń yanjú aáwọ̀, kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì láti tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́ gbọ́ ohun tí ẹnì kejì ń sọ kó o tó fèsì?
20 Nígbà tó bá kan ìwọ náà láti sọ̀rọ̀, sọ ọ́ lọ́nà tó kún fún oore ọ̀fẹ́. (Kólósè 4:6) Sọ ohun tó o mọrírì nípa arákùnrin rẹ fún un. Tọrọ àforíjì fún ohunkóhun tó o ṣe tí aáwọ̀ náà fi wáyé. Bí ìsapá onírẹ̀lẹ̀ tó o ṣe yìí bá mú kí ìjà náà parí, dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà. Bí ìjà náà ò bá sì parí, túbọ̀ máa bẹ Jèhófà pé kó tọ́ ẹ sọ́nà bó o ṣe ń wá àǹfààní mìíràn láti yanjú ọ̀ràn náà.—Róòmù 12:18.
21. Báwo ni ìjíròrò yìí ṣe ràn ọ́ lọ́wọ́ láti máa fi ojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn ẹlòmíràn wò wọ́n?
21 Jèhófà nífẹ̀ẹ́ gbogbo ìránṣẹ́ rẹ̀. Ó tẹ́ ẹ lọ́rùn láti lò gbogbo wa nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ láìka jíjẹ́ tá a jẹ́ aláìpé sí. Bá a ṣe túbọ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa ojú tó fi ń wo àwọn ẹlòmíràn ni ìfẹ́ tá a ní sí àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa á túbọ̀ máa pọ̀ sí i. Bí ìfẹ́ tó o ní sí Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ bá ti kú, o lè ta á jí. Ẹ ò rí i pé ìbùkún ńlá la óò rí gbà tá a bá sapá láti máa fojú tó dáa wo àwọn ẹlòmíràn—àní, ká máa fi ojú tí Jèhófà fi ń wò wọ́n wò wọ́n!
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ó wá hàn kedere nígbẹ̀yìn gbẹ́yín pé Élíábù arẹwà náà kò láwọn ànímọ́ tó yẹ kí ẹni tó tóótun láti jẹ́ ọba Ísírẹ́lì ní. Nígbà tí Gòláyátì, òmìrán ará Filísínì nì sọ pé òun fẹ́ bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì figẹ̀ wọngẹ̀, ńṣe ni ìbẹ̀rùbojo mú Élíábù, àtàwọn ọkùnrin mìíràn ní Ísírẹ́lì.—1 Sámúẹ́lì 17:11, 28-30.
b Ó hàn gbangba pé Jèróbóámù Kejì ti jẹ́ kí ọrọ̀ apá àríwá Ìjọba náà pọ̀ gan-an nítorí àwọn ìṣẹ́gun pàtàkì bíi mélòó kan, gbígbà tí wọ́n gba àwọn ìpínlẹ̀ kan padà, àti ìṣákọ́lẹ̀ tó ṣeé ṣe kó máa wọlé látibẹ̀.—2 Sámúẹ́lì 8:6; 2 Àwọn Ọba 14:23-28; 2 Kíróníkà 8:3, 4; Ámósì 6:2.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo ìkùdíẹ̀ káàtó àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ rẹ̀?
• Àwọn ànímọ́ rere wo ni Jónà àti Pétérù ní tó o lè mẹ́nu kàn?
• Irú èrò wo lo pinnu láti ní nípa àwọn Kristẹni arákùnrin rẹ?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 18]
Ronú Nípa Ojú Tí Ọlọ́run Fi Ń Wo Àwọn Ẹlòmíràn
Bó o ṣe ń ṣàṣàrò lórí ìtàn tó wà nínú Bíbélì nípa Jónà, ǹjẹ́ o rídìí tó fi yẹ kó o wá fojú tuntun wo àwọn tó o máa ń wàásù ìhìn rere náà fún déédéé? Wọ́n lè dà bí ẹni tó ní gbogbo nǹkan tí wọ́n fẹ́ tàbí tí kò ka ẹnikẹ́ni sí bíi tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì, tàbí kẹ̀ kí wọ́n máa ṣàtakò sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Síbẹ̀síbẹ̀, ojú wo ni Jèhófà Ọlọ́run fi ń wò wọ́n? Kódà àwọn tí wọ́n lókìkí nínú ètò àwọn nǹkan yìí lè yí padà sọ́dọ̀ Jèhófà lọ́jọ́ kan, gẹ́gẹ́ bí ọba Nínéfè ṣe yí padà nítorí ìwàásù Jónà.—Jónà 3:6, 7.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Ǹjẹ́ ojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn ẹlòmíràn ni o fi ń wò wọ́n?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]
Jésù rí ohun kan tó dára sọ nípa ìrírí Jónà