Kí Ni Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa?
Kí Ni Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa?
KÍ LÓ máa ń wá sí ọ lọ́kàn nígbà tó o bá gbọ́ ọ̀rọ̀ náà “oúnjẹ alẹ́ Olúwa”? Ọ̀pọ̀ ni ìrònú wọn máa ń lọ sára àwòrán tí wọ́n yà sára amọ̀ tútù táwọn èèyàn gbà pó dára gan-an, èyí tí ayàwòrán Leonardo da Vinci (tó gbé ayé ní 1452-1519) yà ní ìlú Mílan, Ítálì. Òkodoro òtítọ́ ibẹ̀ ni pé Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa jẹ́ àwòrán táwọn ayàwòrán máa ń fẹ́ yà, táwọn òǹkọ̀wé máa ń fẹ́ kọ̀wé nípa rẹ̀, tí àwọn olórin náà sì máa ń fẹ́ kọrin nípa rẹ̀ láti ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún wá.
Kí wá ni Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa gan-an, kí ló sì túmọ̀ sí fáwọn èèyàn tó wà láyé lónìí? Àwọn ìwé gbédègbẹ́yọ̀ àti ìwé atúmọ̀ èdè á sọ fún ọ pé Oúnjẹ Alẹ́ Ìkẹyìn, tá a tún ń pè ní Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa ni oúnjẹ tí Jésù Kristi àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ jọ jẹ ní alẹ́ tó ṣáájú ikú ìrúbọ rẹ̀. Torí pé òun ni oúnjẹ alẹ́ tí Jésù àtàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ jọ jẹ kẹ́yìn làwọn kan ṣe ń pè é ní Oúnjẹ Alẹ́ Ìkẹyìn. Níwọ̀n bó sì ti jẹ́ pé Jésù Kristi Olúwa fúnra rẹ̀ ló dá a sílẹ̀, ó bá a mu wẹ́kú láti pè é ní Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa.
Jálẹ̀ àwọn ọ̀rúndún ni ọ̀pọ̀ èèyàn ti fi ẹ̀mí ara wọn rúbọ nítorí ohun tí wọ́n rò pé ó tó nǹkan téèyàn ń tìtorí ẹ̀ kú. Àwọn bíi mélòó kan lára àwọn ikú wọ̀nyí ṣàǹfààní fáwọn èèyàn kan fún sáà kan. Àmọ́ ní ìfiwéra, kò sí èyíkéyìí lára àwọn ikú ìfara-ẹni-rúbọ wọ̀nyẹn, bó ti wù kó lókìkí tó, tó ṣe pàtàkì tó ikú Jésù Kristi. Bẹ́ẹ̀ ni, kò sí ikú ẹnikẹ́ni nínú ìtàn ẹ̀dá ènìyàn tó kún fún wàhálà yìí tó lè ní irú ipa tó lágbára tó sì gbòòrò bi ìyẹn láé lórí wa. Kí nìdí?
Láti dáhùn ìbéèrè yẹn àti láti ràn ọ́ lọ́wọ́ kó o lè mọ ìjẹ́pàtàkì Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa, a rọ̀ ọ́ láti ka àpilẹ̀kọ tó kàn.