Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa Ṣe Pàtàkì Gan-an fún Ọ
Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa Ṣe Pàtàkì Gan-an fún Ọ
ǸJẸ́ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa ní ìjẹ́pàtàkì tí ò ṣeé gbàgbé fún ọ? Láti mọ èyí, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ wo ìjẹ́pàtàkì tí Jésù Kristi fúnra rẹ̀ gbà pé ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì yìí ní.
Ní ìrọ̀lẹ́ Nísàn 14, ọdún 33 Sànmánì Tiwa, Jésù kó àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ méjìlá jọ sínú yàrá òkè kan ní Jerúsálẹ́mù láti ṣayẹyẹ Ìrékọjá tí wọ́n máa ń ṣe lọ́dọọdún. Lẹ́yìn tí wọ́n jẹ oúnjẹ Ìrékọjá náà tán, Júdásì ọ̀dàlẹ̀ nì jáde kúrò nínú yàrá náà láti lọ da Jésù. (Jòhánù 13:21, 26-30) Jésù wá fi “Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa” náà lọ́lẹ̀ fún àwọn àpọ́sítélì mọ́kànlá yòókù. (1 Kọ́ríńtì 11:20) A tún máa ń pè é ní Ìṣe Ìrántí, níwọ̀n bí Jésù ti pàṣẹ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ máa ṣe èyí gẹ́gẹ́ bí ìrántí mi.” Ìṣẹ̀lẹ̀ kan ṣoṣo yìí la pàṣẹ pé káwọn Kristẹni máa ṣe ìrántí rẹ̀.—1 Kọ́ríńtì 11:24, The Jerusalem Bible.
Níbi púpọ̀, ńṣe làwọn èèyàn máa ń gbé ère kalẹ̀ tàbí kí wọ́n ya ọjọ́ kan pàtó sọ́tọ̀ láti ṣèrántí ẹnì kan tàbí ohun pàtàkì kan. Ní ti èyí tá à ń sọ lọ́wọ́ yìí, oúnjẹ ìrántí kan ni Jésù dá sílẹ̀—oúnjẹ kan tí yóò wà fún ìránnilétí, tí yóò ran àwọn ọmọ ẹ̀yìn lọ́wọ́ láti máa rántí ohun pàtàkì tó ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ mánigbàgbé yẹn. Fún àwọn ìran tó ń bọ̀, oúnjẹ ìrántí yìí yóò máa rán àwọn tó bá ń ṣayẹyẹ náà létí ìtumọ̀ ohun tí Jésù ṣe lálẹ́ ọjọ́ yẹn, àgàgà àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ tó lò. Àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ wo ni Jésù lò, kí ni wọ́n sì túmọ̀ sí? Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ìtàn tí Bíbélì sọ nípa ohun tó wáyé lálẹ́ yẹn lọ́dún 33 Sànmánì Tiwa.
Àwọn Ohun Ìṣàpẹẹrẹ Ọlọ́wọ̀
“Ó mú ìṣù búrẹ́dì kan, ó dúpẹ́, ó bù ú, ó sì fi í fún wọn, ó wí pé: ‘Èyí túmọ̀ sí ara mi tí a ó fi fúnni nítorí yín. Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.’”—Lúùkù 22:19.
Nígbà tí Jésù mú ìṣù búrẹ́dì náà tó sọ pé, “èyí túmọ̀ sí ara mi,” ohun tó ń sọ ni pé búrẹ́dì aláìwú náà dúró fún ẹran ara rẹ̀ tí kò ní ẹ̀ṣẹ̀ kankan, èyí tó fúnni “nítorí ìyè ayé.” (Jòhánù 6:51) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìtumọ̀ Bíbélì kan sọ pé “èyí ni ara mi,” ìwé atúmọ̀ èdè náà, Greek-English Lexicon of the New Testament láti ọwọ́ Thayer, sọ pé ọ̀rọ̀ ìṣe yìí sábà máa ń ní ìtumọ̀ “tọ́ka sí, dúró fún, túmọ̀ sí.” Ó ń gbé èrò dídúró fún tàbí ṣíṣàpẹẹrẹ yọ síni lọ́kàn.—Mátíù 26:26.
Ohun kan náà ló ṣe sí ife wáìnì. Jésù sọ pé: “Ife yìí túmọ̀ sí májẹ̀mú tuntun nípa agbára ìtóye ẹ̀jẹ̀ mi, tí a óò tú jáde nítorí yín.”—Nínú ohun tí Mátíù kọ, ohun tí Jésù sọ nípa ife náà ni pé: “Èyí túmọ̀ sí ‘ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú’ mi, tí a óò tú jáde nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn fún ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀.” (Mátíù 26:28) Jésù lo wáìnì tó wà nínú ife náà gẹ́gẹ́ bí ohun ìṣàpẹẹrẹ, tàbí àmì, ẹ̀jẹ̀ òun fúnra rẹ̀. Ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ tá a ta sílẹ̀ ló máa jẹ́ ìpìlẹ̀ “májẹ̀mú tuntun” fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tó fi ẹ̀mí yàn, tí wọ́n máa ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba àti àlùfáà pẹ̀lú rẹ̀ ní ọ̀run.—Jeremáyà 31:31-33; Jòhánù 14:2, 3; 2 Kọ́ríńtì 5:5; Ìṣípayá 1:5, 6; 5:9, 10; 20:4, 6.
Wáìnì tó wà nínú ife náà tún ń ránni létí pé ẹ̀jẹ̀ Jésù tí a ta sílẹ̀ ló máa jẹ́ ìpìlẹ̀ fún pípèsè “ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀,” ó sì tipa bẹ́ẹ̀ ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fáwọn tó ń mu nínú rẹ̀ láti di ẹni tá a pè sí ìwàláàyè ti ọ̀run gẹ́gẹ́ bí ajùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi. Abájọ tó fi jẹ́ pé kìkì àwọn tó ní ìpè ti ọ̀run—tí wọ́n jẹ́ ìwọ̀nba kéréje—nìkan làwọn tó máa ń jẹ búrẹ́dì náà, tí wọ́n sì máa ń mu wáìnì tí a fi ń ṣe Ìṣe Ìrántí.—Lúùkù 12:32; Éfésù 1:13, 14; Hébérù 9:22; 1 Pétérù 1:3, 4.
Gbogbo àwọn tó jẹ́ ọmọlẹ́yìn Jésù, àmọ́ tí wọn ò sí nínú májẹ̀mú tuntun náà wá ńkọ́? “Àwọn àgùntàn mìíràn” ti Olúwa làwọn wọ̀nyí, kò sóhun tó kàn wọ́n kan ṣíṣàkóso pẹ̀lú Kristi ní ọ̀run, kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe ni wọ́n ń wọ̀nà fún gbígbádùn ìyè ayérayé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé. (Jòhánù 10:16; Lúùkù 23:43; Ìṣípayá 21:3, 4) Gẹ́gẹ́ bí “ogunlọ́gọ̀ ńlá” àwọn Kristẹni tòótọ́ tí wọ́n “ń ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún [Ọlọ́run] tọ̀sán-tòru,” inú wọn dùn láti jẹ́ òǹwòran tó ń fi ìmọrírì hàn níbi Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa náà. Ọ̀rọ̀ àti ìṣe wọn tipa bẹ́ẹ̀ polongo pé: “Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wa, ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́, àti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà ni ìgbàlà wa ti wá.”— Ìṣípayá 7:9, 10, 14, 15.
Báwo Ló Ṣe Yẹ Ká Máa Ṣe É Léraléra Tó?
“Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.”—Lúùkù 22:19.
Báwo ló ṣe yẹ ká máa ṣe Ìṣe Ìrántí náà léraléra tó ká má bàa gbàgbé ikú Kristi? Jésù ò sọ ní pàtó. Àmọ́, nígbà tó jẹ́ pé Nísàn 14 ló dá Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa sílẹ̀, tíyẹn sì jẹ́ alẹ́ ọjọ́ Ìrékọjá táwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń ṣayẹyẹ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan lọ́dún, ó hàn gbangba pé Jésù fẹ́ ká máa ṣayẹyẹ Ìṣe Ìrántí lọ́nà kan náà. Nígbà tó jẹ́ pé ọdọọdún làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń ṣayẹyẹ ìdáǹdè wọn kúrò nínú ìgbèkùn ní Íjíbítì, ọdọọdún làwọn Kristẹni náà ń ṣayẹyẹ ìdáǹdè wọn kúrò nínú ìgbèkùn ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú.—Ẹ́kísódù 12:11, 17; Róòmù 5:20, 21.
Ṣíṣe táwọn èèyàn ń ṣayẹyẹ ìrántí ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì kan lọ́dọọdún kì í ṣe ohun àjèjì rárá. Bí àpẹẹrẹ, ronú nípa ìgbà tí tọkọtaya kan bá ń ṣayẹyẹ ìrántí ọjọ́ tí wọ́n ṣègbéyàwó tàbí nígbà tí orílẹ̀-èdè kan bá ń ṣayẹyẹ ìrántí ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì kan nínú ìtàn rẹ̀. Ẹ̀ẹ̀kan lọ́dún ni wọ́n sábà máa ń ṣayẹyẹ yìí ní àyájọ́ ọjọ́ tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé. Ó dùn mọ́ni pé, ní ọ̀rúndún bíi mélòó kan lẹ́yìn ikú Kristi, wọ́n ṣì ń pe ọ̀pọ̀ àwọn tó pera wọn ní Kristẹni ní Quartodeciman tó túmọ̀ sí “Àwọn Ọlọ́jọ́ Kẹrìnlá,” nítorí pé wọ́n ń ṣayẹyẹ ikú Jésù lẹ́ẹ̀kan lọ́dún, ní Nísàn 14.
Ayẹyẹ Ráńpẹ́ Ni àmọ́ Ó Ṣe Pàtàkì Gan-an
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé ṣíṣe ayẹyẹ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa yóò mú kó ṣeé ṣe fáwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù láti máa “pòkìkí ikú Olúwa.” (1 Kọ́ríńtì 11:26) Nítorí náà, ìrántí yìí yóò dá lórí ipa pàtàkì tí Jésù tipasẹ̀ ikú rẹ̀ kó nínú mímú ète Ọlọ́run ṣẹ.
Nípasẹ̀ jíjẹ́ olóòótọ́ títí dójú ikú, Jésù Kristi dá Jèhófà Ọlọ́run láre gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́dàá àti Ọba Aláṣẹ òdodo tó jẹ́ ọlọ́gbọ́n tó sì nífẹ̀ẹ́. Ní ìyàtọ̀ pátápátá sí ohun tí Sátánì sọ, Jésù ò dà bí Ádámù, òun ní tirẹ̀ fi hàn kedere pé ó ṣeé ṣe fún ẹ̀dá ènìyàn láti jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run, kódà lábẹ́ pákáǹleke tó burú jáì.—Jóòbù 2:4, 5.
Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa náà tún ń jẹ́ ká máa fi ìmọrírì rántí ìfẹ́ ìfara-ẹni-rúbọ tí Jésù ní. Láìfi àwọn àdánwò líle koko pè, Jésù ṣègbọràn sí Baba rẹ̀ láìkù síbì kan. Ìyẹn ló jẹ́ kó ṣeé ṣe fún un láti fi ìwàláàyè ẹ̀dá ènìyàn pípé rẹ̀ lélẹ̀ kó lè dá ohun bàǹtàbanta tí ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù gbé sọ nù padà. Gẹ́gẹ́ bí Jésù fúnra rẹ̀ ṣe ṣàlàyé, ó wá láti “fi ọkàn rẹ̀ fúnni gẹ́gẹ́ bí pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.” (Mátíù 20:28) Nítorí ìdí èyí, gbogbo ẹni tó bá lo ìgbàgbọ́ nínú Jésù lè rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ wọn gbà kí wọ́n sì ní ìyè àìnípẹ̀kun níbàámu pẹ̀lú ète tí Jèhófà ní fún ìràn ènìyàn ní ìpilẹ̀ṣẹ̀.—Róòmù 5:6, 8, 12, 18, 19; 6:23; 1 Tímótì 2:5, 6. a
Gbogbo èyí tún jẹ́ ká rí ọ̀pọ̀-yanturu oore àti inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí Jèhófà fi hàn nínú ṣíṣètò fún ìgbàlà ọmọ aráyé. Bíbélì sọ pé: “Nípa èyí ni a fi ìfẹ́ Ọlọ́run hàn kedere nínú ọ̀ràn tiwa, nítorí Ọlọ́run rán Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo jáde sínú ayé kí a lè jèrè ìyè nípasẹ̀ rẹ̀. Ìfẹ́ náà jẹ́ lọ́nà yìí, kì í ṣe pé àwa ti nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, bí kò ṣe pé òun nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì rán Ọmọ rẹ̀ jáde gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìpẹ̀tù fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.”—1 Jòhánù 4:9, 10.
Dájúdájú, ayẹyẹ kíkàmàmà ni Ìṣe Ìrántí jẹ́! Kò ju ráńpẹ́ o, àmọ́ ó ṣe pàtàkì tó ohun tá a ní láti ṣayẹyẹ rẹ̀ jákèjádò ayé nínú onírúurú ipò téèyàn lè wà, bẹ́ẹ̀ ló tún jẹ́ ohun ìṣàpẹẹrẹ gidi táwọn èèyàn ṣì ń rántí lẹ́yìn àkókò gígùn gan-an.
Ó Ṣe Pàtàkì fún Ọ
Ohun tí ikú ìrúbọ Olúwa wa Jésù Kristi ná òun fúnra rẹ̀ àti Jèhófà, Baba rẹ̀ kúrò ní kékeré. Róòmù 5:12; Hébérù 7:26) Kò sóhun tó ní kó má máa wà láàyè lọ títí láé. Wọn ì bá lè fagbára gba ẹ̀mí rẹ̀ pàápàá, àyàfi tó bá fúnra rẹ̀ yọ̀ǹda rẹ̀. Ó sọ pé: “Kò sí ènìyàn kankan tí ó [gba ẹ̀mí mi] kúrò lọ́wọ́ mi, ṣùgbọ́n mo fi í lélẹ̀ ní ìdánúṣe ti ara mi.”—Jòhánù 10:18.
Gẹ́gẹ́ bí ẹni pípé, Jésù ò jogún ikú bíi tiwa. (Síbẹ̀, Jésù fínnúfíndọ̀ fi ìwàláàyè ẹ̀dá ènìyàn pípé rẹ̀ lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ kó lè jẹ́ pé “nípasẹ̀ ikú rẹ̀ kí ó lè sọ ẹni tí ó ní ọ̀nà àtimú ikú wá di asán, èyíinì ni, Èṣù; àti pé kí ó lè dá gbogbo àwọn tí a ti fi sábẹ́ ìsìnrú ní gbogbo ìgbésí ayé wọn nítorí ìbẹ̀rù ikú nídè kúrò lóko ẹrú.” (Hébérù 2:14, 15) Ìfẹ́ ìfara-ẹni-rúbọ tí Kristi ní tún hàn kedere nínú irú ikú tó yọ̀ǹda ara rẹ̀ láti kú. Ó mọ bóun ṣe máa jìyà àti irú ikú tóun máa kú ní àmọ̀dunjú.—Mátíù 17:22; 20:17-19.
Ìṣe Ìrántí náà tún ń rán wa létí ìfẹ́ gíga jù lọ tí Jèhófà, Baba wa ọ̀run, fi hàn fún aráyé. Ohun ìbànújẹ́ gidi ni fún un, bí òun tó ‘jẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ gidigidi nínú ìfẹ́ni, tó sì jẹ́ aláàánú,’ ṣe ń gbọ́ “igbe ẹkún kíkankíkan” tó sì ń wo “omijé” Jésù nínú ọgbà Gẹtisémánì, tí wọ́n nà án bíi pé kó kú, tí wọ́n kàn án mọ́gi lọ́nà rírorò, tó sì kú ikú tí ń roni lára gógó. (Jákọ́bù 5:11, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé; Hébérù 5:7; Jòhánù 3:16; 1 Jòhánù 4:7, 8) Ríronú nípa rẹ̀ nísinsìnyí pàápàá, tó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbàá ọdún lẹ́yìn náà, ṣì ń fa ẹ̀dùn ọkàn fún ọ̀pọ̀ èèyàn.
Ẹ jẹ́ ká tiẹ̀ rò ó wò ná pé Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi san iye tó ga tó báyẹn fún àwa ẹlẹ́ṣẹ̀! (Róòmù 3:23) Ojoojúmọ́ ni jíjẹ́ tá a jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ àti aláìpé ń bá wa fínra. Àmọ́ lórí ìpìlẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù, a lè bẹ Ọlọ́run pé kó dárí jì wá. (1 Jòhánù 2:1, 2) Èyí mú kó ṣeé ṣe fún wa láti gbádùn òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ pẹ̀lú Ọlọ́run ká sì ní ẹ̀rí ọkàn mímọ́ tónítóní. (Hébérù 4:14-16; 9:13, 14) Ìyẹn nìkan kọ́ o, a tún lè nírètí gbígbé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé títí láé. (Jòhánù 17:3; Ìṣípayá 21:3, 4) Ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ gíga jù lọ tí Jésù ní ló mú kí èyí àti ọ̀pọ̀ ìbùkún mìíràn ṣeé ṣe.
Fífi Ìmọrírì Hàn fún Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa
Kò sí àní-àní pé Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa jẹ́ àgbàyanu ẹ̀rí tó fi “inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run títayọ ré kọjá” hàn. Pípèsè tí Jèhófà Ọlọ́run sì pèsè ẹbọ ìràpadà náà—èyí tí ìfẹ́ ìfara-ẹni-rúbọ Jésù mú kó ṣeé ṣe—jẹ́ ìfihàn “ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ rẹ̀ aláìṣeé-ṣàpèjúwe” ní ti tòótọ́. (2 Kọ́ríńtì 9:14, 15) Ǹjẹ́ àwọn ìfihàn oore tí Ọlọ́run ṣe nípasẹ̀ Jésù Kristi yìí ò yẹ kó sún ọ láti ní ìmọrírì jíjinlẹ̀ tó sì wà pẹ́ títí fún un?
Ó dá wa lójú pé wọ́n sún wa ṣe bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, a ké sí ọ tìfẹ́tìfẹ́ pé kó o dara pọ̀ mọ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti ṣayẹyẹ Ìṣe Ìrántí ikú Jésù. Lọ́dún yìí, a ó ṣe Ìṣe Ìrántí náà lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀ ní ọjọ́ Wednesday, April 16. Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ yóò dùn láti jẹ́ kó o mọ àkókò pàtó tí a ó ṣe ayẹyẹ pàtàkì yìí àti ibi tí a óò ti ṣe é.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìjíròrò lórí ìràpadà, jọ̀wọ́ wo ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun, tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
“ÈYÍ NI ARA MI” TÀBÍ “ÈYÍ TÚMỌ̀ SÍ ARA MI” ÈWO NI?
Nígbà tí Jésù sọ pé, “Èmi ni ẹnu ọ̀nà” àti “Èmi ni àjàrà tòótọ́,” kò sẹ́ni tó ronú pé ó jẹ́ ẹnu ọ̀nà tàbí àjàrà ní ti gidi. (Jòhánù 10:7; 15:1) Bákan náà, nígbà tí Bíbélì The New Jerusalem Bible ṣàyọlò ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé: “Ife yìí ni májẹ̀mú tuntun,” a ò parí èrò sí pé ife náà fúnra rẹ̀ ni májẹ̀mú tuntun ọ̀hún. Nítorí náà, nígbà tó sọ pé búrẹ́dì náà ‘jẹ́’ ara òun, ó hàn gbangba pé ńṣe ni búrẹ́dì náà túmọ̀ sí ara rẹ̀, tàbí pé ó ń ṣàpẹẹrẹ ara rẹ̀. Abájọ tí ìtumọ̀ Charles B. Williams fi sọ pé: “Èyí dúró fún ara mi.”—Lúùkù 22:19, 20.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Búrẹ́dì aláìwú àti wáìnì náà jẹ́ ohun tó bá a mu wẹ́kú láti fi ṣàpẹẹrẹ ara aláìlẹ́ṣẹ̀ Jésù àti ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ tí a ta sílẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Ìṣe Ìrántí náà jẹ́ ìránnilétí ìfẹ́ gíga jù lọ tí Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi fi hàn