Ẹ̀yin Ọ̀dọ́—Jèhófà Ò Mà Ní Gbàgbé Iṣẹ́ Yín!
Ẹ̀yin Ọ̀dọ́—Jèhófà Ò Mà Ní Gbàgbé Iṣẹ́ Yín!
“Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ yín àti ìfẹ́ tí ẹ fi hàn fún orúkọ rẹ̀, ní ti pé ẹ ti ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn ẹni mímọ́, ẹ sì ń bá a lọ ní ṣíṣe ìránṣẹ́.”—HÉBÉRÙ 6:10.
1. Báwo ni ìwé Hébérù àti Málákì nínú Bíbélì ṣe fi hàn pé Jèhófà mọyì iṣẹ́ ìsìn rẹ?
ǸJẸ́ o ti ṣe ọ̀rẹ́ rẹ kan lóore rí tónítọ̀hún ò sì dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ? Ó lè dunni gan-an nígbà táwọn èèyàn bá fojú kéré ìwà ọ̀làwọ́ tá a fi hàn tàbí tí wọn ò tiẹ̀ rántí pé a ṣe àwọn lóore rárá. Àmọ́, ẹ ò rí i bí ìyẹn ṣe yàtọ̀ pátápátá sígbà tá a bá sin Jèhófà tọkàntọkàn! Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ yín àti ìfẹ́ tí ẹ fi hàn fún orúkọ rẹ̀, ní ti pé ẹ ti ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn ẹni mímọ́, ẹ sì ń bá a lọ ní ṣíṣe ìránṣẹ́.” (Hébérù 6:10) Ronú nípa ohun tíyẹn túmọ̀ sí ná. Jèhófà yóò dìídì ka ara rẹ̀ sí aláìṣòdodo—ìyẹn ni pé yóò gbà pé òun ti ṣẹ̀—tó bá gbàgbé ohun tá a ti ṣe àti ohun tá à ń ṣe lọ nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Ọlọ́run tó mọrírì gan-an ni lóòótọ́!—Málákì 3:10.
2. Kí ló mú kí sísin Jèhófà jẹ́ àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ ní ti tòótọ́?
2 Àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ lo ní láti jọ́sìn Ọlọ́run tó moore yìí àti láti máa ṣiṣẹ́ sìn ín. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé iye àwọn tẹ́ ẹ jọ jẹ́ onígbàgbọ́ ò ju mílíọ̀nù mẹ́fà lọ ní ìfiwéra pẹ̀lú àwọn bíi bílíọ̀nù mẹ́fà èèyàn tó wà láyé, àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ gan-an ni lóòótọ́. Yàtọ̀ síyẹn, òtítọ́ náà pé ò ń fetí sí ìhìn rere náà, o sì ń mú un lò fi hàn pé Jèhófà ní ire rẹ lọ́kàn gan-an. Ó ṣe tán, Jésù sọ pé: “Kò sí ènìyàn kankan tí ó lè wá sọ́dọ̀ mi láìjẹ́ pé Baba, tí ó rán mi, fà á.” (Jòhánù 6:44) Bẹ́ẹ̀ ni o, Jèhófà ń ran àwọn èèyàn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan lọ́wọ́ láti ṣe ara wọn láǹfààní lórí ìpìlẹ̀ ẹbọ Kristi.
Mímọrírì Àǹfààní Àrà Ọ̀tọ̀ Tó O Ní
3. Báwo làwọn ọmọ Kórà ṣe fi ìmọrírì hàn fún àǹfààní tí wọ́n ní láti sin Jèhófà?
3 Gẹ́gẹ́ bá a ṣe jíròrò rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ lo ní láti mú ọkàn Jèhófà yọ̀. (Òwe 27:11) Èyí jẹ́ ohun tó ò gbọ́dọ̀ fọwọ́ yẹpẹrẹ mú láé. Àwọn ọmọ Kórà fi báwọn ṣe mọrírì àǹfààní tí wọ́n ní láti sin Jèhófà hàn nínú ọ̀kan lára àwọn sáàmù onímìísí tí wọ́n kọ. A kà á pé: “Ọjọ́ kan nínú àwọn àgbàlá rẹ sàn ju ẹgbẹ̀rún ọjọ́ níbòmíràn. Mo ti yàn láti máa dúró ní ibi àbáwọ ilé Ọlọ́run mi kàkà kí n máa rìn kiri nínú àwọn àgọ́ ìwà burúkú.”—Sáàmù 84:10.
4. (a) Kí ló lè mú káwọn kan ka jíjọ́sìn Jèhófà sí ohun tó ń káni lọ́wọ́ kò? (b) Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà ń fi hàn pé òun ń fẹ́ láti kíyè sí àwọn ìránṣẹ́ òun kí òun sì san èrè fún wọn?
4 Ṣé ojú tíwọ náà fi ń wo àǹfààní tó o ní láti sin Baba rẹ ọ̀run nìyẹn? Ká sọ tòótọ́, ìgbà mìíràn wà tó lè dà bíi pé jíjọ́sìn Jèhófà ń ká ọ lọ́wọ́ kò. Lóòótọ́, gbígbé níbàámu pẹ̀lú àwọn ìlànà Bíbélì gba kéèyàn ní ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ dé àyè kan. Àmọ́, ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, kò sóhun tí Jèhófà béèrè lọ́wọ́ rẹ tí kì í ṣe fún àǹfààní ara rẹ. (Sáàmù 1:1-3) Àti pé, Jèhófà rí àwọn ìsapá rẹ, ó sì ń fi ìmọrírì hàn fún ìdúróṣinṣin rẹ. Kódà, Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé Jèhófà “ni olùsẹ̀san fún àwọn tí ń fi taratara wá a.” (Hébérù 11:6) Jèhófà sì ń wá àǹfààní tóun máa fi ṣe èyí. Wòlíì kan tó jẹ́ olódodo ní Ísírẹ́lì ìgbàanì sọ pé: “Ní ti Jèhófà, ojú rẹ̀ ń lọ káàkiri ní gbogbo ilẹ̀ ayé láti fi okun rẹ̀ hàn nítorí àwọn tí ọkàn-àyà wọn pé pérépéré síhà ọ̀dọ̀ rẹ̀.”—2 Kíróníkà 16:9.
5. (a) Kí ni ọ̀nà dídára jù lọ tó o lè gbà fi hàn pé ọkàn rẹ pé pérépéré síhà ọ̀dọ̀ Jèhófà? (b) Kí nìdí tí bíbá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ rẹ fi lè dà bí ohun tó ṣòro?
5 Ọ̀nà dídára jù lọ tó o lè gbà fi hàn pé ọkàn rẹ pé pérépéré síhà ọ̀dọ̀ Jèhófà ni pé kó o bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Ǹjẹ́ o ti làǹfààní àtibá àwọn tẹ́ ẹ jọ ń lọ sílé ìwé kan náà sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ rẹ rí? Lákọ̀ọ́kọ́, ó lè dà bí ohun tó ṣòro, èrò pé o tiẹ̀ fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀ lásán lè kó jìnnìjìnnì bá ọ. O lè máa ronú pé, ‘Bí wọ́n bá fi mi ṣe yẹ̀yẹ́ ńkọ́? Tí wọ́n bá rò pé ẹ̀sìn tó ṣàjèjì ni mò ń ṣe ńkọ́?’ Jésù sọ pé kì í ṣe gbogbo èèyàn ló máa fetí sí ìhìn Ìjọba náà. (Jòhánù 15:20) Àmọ́, ìyẹn ò wá túmọ̀ sí pé gbogbo ìgbà ni wọ́n á máa fi ọ́ ṣẹlẹ́yà tí wọ́n á sì máa pa ọ́ tì. Ní ìyàtọ̀ pátápátá síyẹn, ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí ló ti rí àwọn tó fetí sílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ wọn, kódà táwọn ẹlẹgbẹ́ wọ́n túbọ̀ bọ̀wọ̀ fún wọn nítorí pé wọ́n dúró gbọn-in lórí ìgbàgbọ́ wọn.
“Jèhófà Yóò Ràn Ọ́ Lọ́wọ́”
6, 7. (a) Báwo ló ṣe ṣeé ṣe fún ọmọbìnrin ọdún mẹ́tàdínlógún kan láti jẹ́rìí fáwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀? (b) Ẹ̀kọ́ wo lo ti rí kọ́ nínú ìrírí Jennifer?
6 Àmọ́ báwo lo ṣe lè fi ìgboyà sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ rẹ? O ò ṣe pinnu pé o ò ní fi ohunkóhun pa mọ́ nígbà táwọn èèyàn bá béèrè ẹ̀sìn tó ò ń ṣe? Gbé ìrírí Jennifer ọmọbìnrin ọlọ́dún mẹ́tàdínlógún yẹ̀ wò. Ó ní: “Nígbà tí mò ń jẹ oúnjẹ ọ̀sán lọ́wọ́ nílé ìwé. Àwọn ọmọbìnrin tá a jọ ń jẹun lórí tábìlì kan náà bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ nípa ìsìn, ọ̀kan lára wọn sì béèrè ẹ̀sìn tí mò ń ṣe.” Ǹjẹ́ ẹ̀rù ba Jennifer láti fèsì? “Bẹ́ẹ̀ ni o,” ó là á mọ́lẹ̀ pé, “nítorí pé mi ò mọ irú ojú tí wọ́n máa fi wò mí.” Kí ni Jennifer wá ṣe? Ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó ní: “Mo sọ fáwọn ọmọbìnrin náà pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mí. Ẹnu kọ́kọ́ yà wọ́n. Ó hàn gbangba pé ohun tí wọ́n rò tẹ́lẹ̀ ni pé abàmì ẹ̀dá làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Èyí mú kí wọ́n bi mí láwọn ìbéèrè, ó sì mú kí n là wọ́n lóye nípa díẹ̀ lára àwọn èrò òdì tí wọ́n ní. Kódà lẹ́yìn ọjọ́ yẹn, àwọn kan lára àwọn ọmọbìnrin náà ṣì máa ń wá bá mi lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan tí wọ́n á sì máa bi mí láwọn ìbéèrè.”
7 Ǹjẹ́ Jennifer kábàámọ̀ pé òun lo àǹfààní yẹn láti sọ̀rọ̀ nípa ohun tó gbà gbọ́? Rárá o! Ó ní: “Ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn múnú mi dùn gan-an lẹ́yìn tí àkókò oúnjẹ ọ̀sán parí. Àwọn ọmọbìnrin wọ̀nyẹn ti wá mọ irú ẹni táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ báyìí.” Ìmọ̀ràn tí Jennifer fúnni báyìí rọrùn gan-an, ó ní: “Tó bá ṣòro fún ọ láti jẹ́rìí fáwọn ọmọ kíláàsì rẹ tàbí àwọn olùkọ́ rẹ, gbàdúrà lójú ẹsẹ̀. Jèhófà yóò ràn ọ́ lọ́wọ́. Inú rẹ yóò dùn pé o lo àǹfààní tó o ní dáadáa láti jẹ́rìí.”—1 Pétérù 3:15.
8. (a) Báwo ni àdúrà ṣe ran Nehemáyà lọ́wọ́ nígbà tó dojú kọ ipò tí kò retí? (b) Àwọn ipò wo ló lè dìde nílé ìwé tó máa gba pé kó o gbàdúrà kúkúrú sí Jèhófà ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́?
8 Ṣàkíyèsí pé Jennifer sọ pé kó o ‘gbàdúrà lójú ẹsẹ̀’ sí Jèhófà nígbà tí àǹfààní láti jẹ́rìí nípa ìgbàgbọ́ rẹ bá yọjú. Ohun tí Nehemáyà, tó jẹ́ agbọ́tí fún Atasásítà Ọba Páṣíà ṣe gẹ́lẹ́ nìyẹn nígbà tó bá ara rẹ̀ nínú ipò kan tí kò retí rárá. Ojú Nehemáyà fà ro nígbà tí wọ́n sọ nípa ìyà tó ń jẹ àwọn Júù fún un tó sì ti gbọ́ pé ògiri àti àwọn ẹnubodè Jerúsálẹ́mù ti rún wómúwómú. Ọba náà ṣàkíyèsí pé Nehemáyà ń ṣàníyàn nípa ohun kan, ó wá béèrè ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́ Nehemáyà. Kí Nehemáyà tó fèsì, ó kọ́kọ́ gbàdúrà fún ìtọ́sọ́nà. Ẹ̀yìn ìyẹn ló wá fi ìgboyà tọrọ àyè láti padà lọ sí Jerúsálẹ́mù kó sì ṣèrànwọ́ láti tún ìlú tó wó palẹ̀ náà kọ́. Atasásítà gbà pé kí Nehemáyà lọ. (Nehemáyà 2:1-8) Ẹ̀kọ́ wo lo rí kọ́ níbẹ̀? Bí ẹ̀rù bá ń bà ọ́ nígbà tí àǹfààní láti jẹ́rìí nípa ìgbàgbọ́ rẹ bá yọ, má ṣe gbàgbé àǹfààní tó o ní láti gbàdúrà ìdákẹ́jẹ́ẹ́. Pétérù kọ̀wé pé: ‘Ẹ kó gbogbo àníyàn yín lé e, nítorí ó bìkítà fún yín.’—1 Pétérù 5:7; Sáàmù 55:22.
‘Múra Tán Láti Ṣe Ìgbèjà’
9. Báwo ló ṣe ṣeé ṣe fún Leah ọmọ ọdún mẹ́tàlá láti fi ẹ̀dà mẹ́tàlélógún ìwé Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè fáwọn èèyàn?
9 Gbé ìrírí mìíràn yẹ̀ wò. Leah, ọmọ ọdún mẹ́tàlá ń ka ìwé Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́ a lákòókò oúnjẹ ọ̀sán nílé ìwé. Ó ní: “Àwọn tó kù ń wò mí, láìpẹ́ ọ̀pọ̀ èrò ti sọgbà yí mi ká. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí béèrè ohun tí ìwé náà wà fún.” Nígbà tí wọ́n jáde ilé ìwé lọ́jọ́ yẹn, àwọn ọmọbìnrin mẹ́rin ló ní kí Leah báwọn mú ẹ̀dà kọ̀ọ̀kan ìwé Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè náà wá. Láìpẹ́ àwọn ọmọbìnrin wọ̀nyí àtàwọn mìíràn ti jọ ń ka ìwé náà, àwọn tí wọ́n jọ ń kà á wọ̀nyí náà tún fẹ́ gba ẹ̀dà tiwọn. Láàárín ọ̀sẹ̀ bíi mélòó kan tó tẹ̀ lé e, Leah ti fún àwọn ọmọ tí wọ́n jọ ń lọ sílé ìwé kan náà àtàwọn ọ̀rẹ́ wọn ní ẹ̀dà mẹ́tàlélógún ìwé Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè ọ̀hún. Ǹjẹ́ ó rọrùn fún Leah láti fìgboyà sọ̀rọ̀ nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ ń bi í ní ìbéèrè nípa ìwé tó ń kà? Kò rọrùn rárá! Ó sọ pé: “Àyà mi kọ́kọ́ ń já. Àmọ́, mo wá gbàdúrà mo sì mọ̀ pé Jèhófà wà pẹ̀lú mi.”
10, 11. Báwo ló ṣe ṣeé ṣe fún ọmọdébìnrin Ísírẹ́lì kan láti ran olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Síríà kan lọ́wọ́ láti mọ̀ nípa Jèhófà, ìyípadà wo ni ọ̀gágun náà sì ṣe lẹ́yìn ìyẹn?
10 Ìrírí Leah lè rán wa létí irú ipò kan náà tó dojú kọ ọmọdébìnrin Ísírẹ́lì kan tí wọ́n mú nígbèkùn lọ sí Síríà. Adẹ́tẹ̀ ni Náámánì, tó jẹ́ olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Síríà. Ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pe ìyàwó rẹ̀ ló bẹ̀rẹ̀ ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tó mú kí ọmọbìnrin kékeré náà sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ rẹ̀. Ó ní: “Ká ní olúwa mi wà níwájú wòlíì tí ó wà ní Samáríà ni! Bí ọ̀ràn bá rí bẹ́ẹ̀, ì bá wò ó sàn nínú ẹ̀tẹ̀ rẹ̀.”—2 Àwọn Ọba 5:1-3.
11 Ìgboyà ọmọbìnrin kékeré yìí mú kí Náámánì wá mọ̀ pé “kò sí Ọlọ́run níbikíbi lórí ilẹ̀ ayé, bí kò ṣe ní Ísírẹ́lì.” Ó tiẹ̀ tún pinnu pé òun “kì yóò rú ọrẹ ẹbọ sísun tàbí ẹbọ sí ọlọ́run mìíràn mọ́, bí kò ṣe sí Jèhófà.” (2 Àwọn Ọba 5:15, 17) Ó dájú pé Jèhófà bù kún ìgboyà ọmọdébìnrin náà. Ó lè ṣe bákan náà fáwọn ọ̀dọ́ lóde òní. Leah rí i pé òótọ́ pọ́ńbélé lọ̀rọ̀ yìí. Láìpẹ́, àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀ wá bá a, wọ́n sì sọ fún un pé ìwé Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè náà ti ran àwọn lọ́wọ́ láti tún ìwà àwọn ṣe. Leah ní: “Inú mi dùn gan-an, nítorí mo mọ̀ pé mò ń ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti túbọ̀ mọ̀ nípa Jèhófà àti láti yí ìgbésí ayé wọn padà.”
12. Báwo lo ṣe lè nígboyà láti gbèjà ìgbàgbọ́ rẹ?
12 Ìwọ náà lè láwọn ìrírí tó jọ ti Jennifer àti Leah. Tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Pétérù, tó kọ̀wé pé gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, o gbọ́dọ̀ máa ‘wà ní ìmúratán nígbà gbogbo láti ṣe ìgbèjà níwájú olúkúlùkù ẹni tí ó bá fi dandan béèrè lọ́wọ́ rẹ ìdí fún ìrètí tí ń bẹ nínú rẹ, ṣùgbọ́n kí o máa ṣe bẹ́ẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú inú tútù àti ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀.’ (1 Pétérù 3:15) Báwo lo ṣe lè ṣe ìyẹn? Fara wé ìṣe àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní tí wọ́n gbàdúrà pé kí Jèhófà ran àwọn lọ́wọ́ láti wàásù ní “àìṣojo rárá.” (Ìṣe 4:29) Lẹ́yìn náà, máa fi ìgboyà bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ rẹ. Ohun tó máa tibẹ̀ jáde lè yà ọ́ lẹ́nu gan-an. Àti pé, wàá tún mú ọkàn Jèhófà yọ̀.
Àwọn Fídíò Àtàwọn Àkànṣe Iṣẹ́
13. Àwọn àǹfààní wo làwọn ọ̀dọ́ kan lò láti jẹ́rìí? (Wo àwọn àpótí tó wà lójú ìwé 20 àti 21.)
13 Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ló ti ṣàlàyé ìgbàgbọ́ wọn fáwọn ọmọ tí wọ́n jọ ń lọ sílé ìwé tàbí àwọn olùkọ́ wọn nípa lílo àwọn fídíò. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àkànṣe iṣẹ́ tá a yàn fúnni láti ṣe nílé ìwé ti ṣí ọ̀nà sílẹ̀ láti mú ìyìn bá Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n fún àwọn ọmọkùnrin méjì tí wọ́n jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, táwọn méjèèjì sì jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní iṣẹ́ àṣetiléwá kan pé kí wọ́n kọ ọ̀rọ̀ lórí ọ̀kan lára àwọn ìsìn tó wà láyé gẹ́gẹ́ bí apá kan ẹ̀kọ́ kíláàsì wọn tó dá lórí ìtàn nípa ayé. Àwọn méjèèjì pèrò pọ̀ láti kọ ọ̀rọ̀ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n sì mú gbogbo ìsọfúnni tí wọ́n fi ṣiṣẹ́ yìí jáde látinú ìwé Jehovah’s Witnesses—Proclaimers of God’s Kingdom. b Wọ́n tún ní láti fi ìṣẹ́jú márùn-ún sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Lẹ́yìn èyí, olùkọ́ náà àtàwọn akẹ́kọ̀ọ́ béèrè ọ̀pọ̀ ìbéèrè lọ́wọ́ wọn tó mú káwọn ọmọkùnrin yìí wà níwájú kíláàsì náà fún ogún ìṣẹ́jú sí i. Fún odidi ọ̀sẹ̀ bíi mélòó kan lẹ́yìn ìyẹn làwọn ọmọ kíláàsì fi ń bi wọ́n láwọn ìbéèrè nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà!
14, 15. (a) Kí nìdí tí ìbẹ̀rù ènìyàn fi jẹ́ ìdẹkùn? (b) Kí nìdí tó fi yẹ kí ọkàn rẹ balẹ̀ láti bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ rẹ?
14 Gẹ́gẹ́ bí àwọn ìrírí wọ̀nyí ti fi hàn, o lè rí ìbùkún ńláǹlà gbà tó o bá ń bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Má ṣe jẹ́ kí ìbẹ̀rù ènìyàn fi àǹfààní àti ayọ̀ tó wà nínú ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti mọ Jèhófà dù ọ́. Bíbélì sọ pé: “Wíwárìrì nítorí ènìyàn ni ohun tí ń dẹ ìdẹkùn, ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà ni a óò dáàbò bò.”—Òwe 29:25.
15 Rántí pé, gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni ọ̀dọ́, o ní ohun kan táwọn ojúgbà rẹ ń wá kiri lójú méjèèjì—ìyẹn ni ọ̀nà ìgbésí ayé tó dára jù lọ nísinsìnyí àti ìlérí ìyè àìnípẹ̀kun lọ́jọ́ iwájú. (1 Tímótì 4:8) Ó dùn mọ́ni pé, ohun tí ìwádìí kan sọ nípa orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà—ìyẹn orílẹ̀-èdè tó o lè máa ronú pé àwọn èèyàn ibẹ̀ lápapọ̀ ò ka ohunkóhun sí tàbí pé iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wọn nìkan ni wọ́n gbájú mọ́—ni pé àwọn tó pọ̀ ju ìdajì nínú àwọn ọ̀dọ́ ibẹ̀ ni kò fọwọ́ yẹpẹrẹ mú ọ̀ràn ẹ̀sìn rárá. Ìdámẹ́ta lára wọn ló sì sọ pé ọ̀rọ̀ ìsìn ló ní “ipa tó ṣe pàtàkì jù lọ” nínú ìgbésí ayé àwọn. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé bọ́rọ̀ ṣe rí láwọn ibi púpọ̀ káàkiri àgbáyé nìyẹn. Nítorí náà, ó lè jẹ́ pé ńṣe ni inú àwọn ojúgbà rẹ nílé ìwé máa dùn láti gbọ́ ohun tó o fẹ́ bá wọn sọ nípa Bíbélì.
Gẹ́gẹ́ Bí Ọ̀dọ́, Sún Mọ́ Jèhófà
16. Kí ni mímú inú Jèhófà dùn ní nínú yàtọ̀ sí bíbá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀?
16 Ká sòótọ́, mímú ọkàn Jèhófà yọ̀ kì í wulẹ̀ ṣe sísọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ lásán. O tún ní láti jẹ́ kí ìwà rẹ bá àwọn ìlànà rẹ̀ mu. Àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé: “Èyí ni ohun tí ìfẹ́ fún Ọlọ́run túmọ̀ sí, pé kí a pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́; síbẹ̀ àwọn àṣẹ rẹ̀ kì í ṣe ẹrù ìnira.” (1 Jòhánù 5:3) Wàá rí i pé òótọ́ pọ́ńbélé lọ̀rọ̀ yìí tó o bá sún mọ́ Jèhófà. Báwo lo ṣe lè ṣe ìyẹn?
17. Báwo lo ṣe lè sún mọ́ Jèhófà?
17 Wá àkókò láti ka Bíbélì àtàwọn ìtẹ̀jáde tá a gbé karí Bíbélì. Bó o bá ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà tó, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe máa rọrùn fún ọ tó láti ṣègbọràn sí i àti láti bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Jésù sọ pé: “Ẹni rere a máa mú ohun rere jáde wá láti inú ìṣúra rere ọkàn-àyà rẹ̀, . . . nítorí lára ọ̀pọ̀ yanturu tí ń bẹ nínú ọkàn-àyà ni ẹnu rẹ̀ ń sọ.” (Lúùkù 6:45) Nítorí náà, jẹ́ kí ohun rere kún inú ọkàn rẹ. O ò ṣe gbé góńgó kan ka iwájú ara rẹ lórí ọ̀ràn yìí? Bóyá o lè ṣe ju ti tẹ́lẹ̀ lọ nípa bó o ṣe máa múra sílẹ̀ fún àwọn ìpàdé ìjọ ní ọ̀sẹ̀ tó ń bọ̀ yìí. Góńgó rẹ kejì lè jẹ́ láti kópa nípasẹ̀ ìdáhùn kúkúrú àmọ́ tó jẹ́ èyí tó tọkàn wá. Àmọ́ ṣá o, ó ṣe pàtàkì pé kí ìwọ alára máa fi àwọn ohun tó ò ń kọ́ ṣèwà hù.—Fílípì 4:9.
18. Kódà bó o tiẹ̀ kojú àwọn àtakò kan, kí ló yẹ kó fi ọ́ lọ́kàn balẹ̀?
18 Àwọn ìbùkún tó máa ń wá látinú sísin Jèhófà jẹ́ èyí tó máa ń wà pẹ́ títí—àní, títí ayérayé. Lóòótọ́ o, o lè máa bá àtakò pàdé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, tàbí kí wọ́n tiẹ̀ fi ọ́ ṣẹ̀sín nítorí pé o jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àmọ́ ronú nípa Mósè. Bíbélì sọ pé “ó tẹjú mọ́ sísan ẹ̀san náà.” (Hébérù 11:24-26) Ọkàn ìwọ náà lè balẹ̀ pé Jèhófà yóò san ọ́ lérè fún ìsapá tó o ṣe láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀ tó o sì ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Láìsí àní-àní, kò ní ‘gbàgbé iṣẹ́ rẹ àti ìfẹ́ tí o fi hàn fún orúkọ rẹ̀’ láé.—Hébérù 6:10.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde.
b Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Kí nìdí tó fi lè dá ọ lójú pé Jèhófà mọrírì iṣẹ́ ìsìn rẹ?
• Àwọn ọ̀nà tó gbéṣẹ́ wo làwọn kan ti rí i pé a lè gbà jẹ́rìí nílé ìwé?
• Báwo lo ṣe lè nígboyà láti jẹ́rìí fáwọn ọmọ kíláàsì rẹ?
• Báwo lo ṣe lè sún mọ́ Jèhófà?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Kódà Àwọn Ògo Wẹẹrẹ Ń Yin Jèhófà!
Àní àwọn ògo wẹẹrẹ tí ò tíì pé ọmọ ọdún mẹ́tàlá pàápàá ti jẹ́rìí tó gbéṣẹ́ nílé ìwé. Gbé àwọn ìrírí kúkúrú wọ̀nyí yẹ̀ wò.
Kíláàsì kárùn-ún tí Amber ọmọ ọdún mẹ́wàá wà nílé ìwé ń ka ìwé kan tó sọ̀rọ̀ nípa bí ìjọba Násì ṣe fìyà jẹ àwọn Júù nígbà Ogun Àgbáyé Kejì. Amber pinnu láti mú fídíò Purple Triangles wá fún olùkọ́ rẹ̀. Ó ya olùkọ́ náà lẹ́nu láti rí i pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà náà fojú winá inúnibíni lábẹ́ ìjọba Násì. Olùkọ́ yìí wá fi fídíò náà han gbogbo ọmọ kíláàsì lápapọ̀.
Nígbà ti Alexa wà lọ́mọ ọdún mẹ́jọ, ó kọ lẹ́tà kan sí kíláàsì rẹ̀, tó fi ṣàlàyé ìdí tóun ò fi lè bá wọn kópa nínú ayẹyẹ Kérésìmesì. Lẹ́tà náà wú olùkọ́ rẹ̀ lórí gan-an tó fi sọ pé kí Alexa kà á sókè ketekete fún kíláàsì rẹ̀ àti fún kíláàsì méjì mìíràn pẹ̀lú! Ohun tó sọ nígbà tó fẹ́ parí lẹ́tà náà ni pé: “Wọ́n ti kọ́ mi pé kí n máa bọ̀wọ̀ fún àwọn ẹlòmíràn tí ohun tí wọ́n gbà gbọ́ yàtọ̀ sí tèmi, mo sì dúpẹ́ lọ́wọ́ yín pé ẹ̀yìn náà bọ̀wọ̀ fún ìpinnu tí mo ṣe pé n ò ní ṣayẹyẹ Kérésìmesì.”
Kété lẹ́yìn tí Eric bẹ̀rẹ̀ ipele kìíní ní kọ́lẹ́ẹ̀jì ló mú Iwe Itan Bibeli Mi lọ sílé ìwé, ó sì tọrọ àyè láti fi ìwé náà han àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀. Olùkọ́ rẹ̀ wá sọ pé: “Mo ní èrò kan tó sàn ju ìyẹn lọ. O ò ṣe ka ìtàn kan níbẹ̀ sí kíláàsì létí?” Eric ṣe bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó ní kí gbogbo àwọn tó bá fẹ́ ní ẹ̀dà kan ìwé náà nawọ́ sókè. Àwọn méjìdínlógún—títí kan olùkọ́ náà—ló nawọ́ sókè! Eric wá rí i nísinsìnyí pé òun ní àkànṣe ìpínlẹ̀ tó jẹ́ tòun láti jẹ́rìí.
Whitney ọmọ ọdún mẹ́sàn-án dúpẹ́ gidigidi fún ìwé pẹlẹbẹ náà, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti Ìmọ̀ Ẹ̀kọ́. c Ó ní: “Ọdọọdún ni màmá mi máa ń fún àwọn olùkọ́ mi ní ìwé pẹlẹbẹ yìí, àmọ́ èmi fúnra mi ló ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́dún yìí. Nítorí ìwé pẹlẹbẹ ọ̀hún, èmi ni olùkọ́ mi yàn gẹ́gẹ́ bí ‘akẹ́kọ̀ọ́ tó gbayì jù lọ́sẹ̀ náà.’”
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
c Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló tẹ gbogbo ìtẹ̀jáde tá a mẹ́nu kàn níhìn-ín jáde.
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Àwọn Ọ̀nà Táwọn Kan Ti Gbà Láti Sọ̀rọ̀ Nípa Ìgbàgbọ́ Wọn
Àwọn kan ti yan àkòrí tó fún wọn láǹfààní láti jẹ́rìí nínú ọ̀rọ̀ tí wọ́n ní kí wọ́n kọ tàbí iṣẹ́ tí wọ́n ní kí wọ́n ṣe nílé ìwé
Àwọn ọ̀dọ́ bíi mélòó kan ti fún olùkọ́ wọn ní fídíò tàbí ìtẹ̀jáde kan tó sọ̀rọ̀ nípa kókó ẹ̀kọ́ kan tí wọ́n ti jíròrò nínú kíláàsì
Àwọn ọ̀dọ́ mìíràn ti béèrè ìbéèrè lọ́wọ́ àwọn ọ̀dọ́ kan tó ń ka Bíbélì tàbí ìtẹ̀jáde kan tá a gbé karí Bíbélì lákòókò ìsinmi
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Àwọn tó nírìírí lè ṣèrànwọ́ láti kọ́ àwọn ọ̀dọ́ láti sin Jèhófà