Ọwọ́ Wo Làwọn Èèyàn Fi Ń Mú Ìlànà Ẹ̀sìn Lóde Òní?
Ọwọ́ Wo Làwọn Èèyàn Fi Ń Mú Ìlànà Ẹ̀sìn Lóde Òní?
Àwọn ọkùnrin mẹ́ẹ̀ẹ́dógún àtàwọn àfẹ́sọ́nà wọn lọ síbi ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ìrọ̀lẹ́ tí [ìjọ Kátólíìkì] ṣètò rẹ̀ fáwọn tó ń múra àtiṣe ìgbéyàwó. Nínú ọgbọ̀n èèyàn wọ̀nyí, ẹni mẹ́ta péré ló sọ pé àwọn ní ìgbàgbọ́.”—La Croix, ìwé ìròyìn ojoojúmọ́ lédè Faransé tí àwọn Kátólíìkì ń tẹ̀ jáde.
IPÒ tí ọ̀ràn ẹ̀sìn wà ò fara rọ mọ́ báyìí o. Àkọlé ẹ̀yìn ìwé ìròyìn àgbáyé náà Newsweek ti July 12, 1999, béèrè pé: “Ǹjẹ́ Ọlọ́run Ti Kú?” Ìwé ìròyìn náà dáhùn pé ńṣe ló dà bí ẹni pé Ọlọ́run ti kú lójú àwọn èèyàn apá ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ Yúróòpù. Nígbà tí ìwé ìròyìn ilẹ̀ Faransé náà Le Monde, ń sọ̀rọ̀ nípa ìpàdé tí ẹgbẹ́ alákòóso Ìjọ Kátólíìkì ṣe nílùú Róòmù ní oṣù October, 1999, ó sọ pé: “Ó ti wá ṣòro báyìí ju ti ìgbàkigbà rí lọ fún Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì láti fi ẹ̀kọ́ rẹ̀ kọ́ àwọn èèyàn tí ara wọ́n ti ‘kọ̀ ọ́.‘ . . . Ní Ítálì, ẹnu ẹ̀sìn Kátólíìkì ò kò mọ́ lórí ẹ̀kọ́ ìsìn àti àṣà. . . . Ní Jámánì, awuyewuye tó ń lọ lórí ọ̀ràn fífàyè gba àwọn ibùdó tó ń rí sí ọ̀ràn ìṣẹ́yún ti túbọ̀ ń mú kí àwùjọ kan tó nífẹ̀ẹ́ sí òmìnira máa ta ko ọlá àṣẹ póòpù, wọn ò fẹ́ máa tẹ̀ lé àwọn àṣẹ gbà-bí-mo-ṣe-wí mọ́. Àwọn aláàkíyèsí kan tiẹ̀ ti sọ pé ìwà ta-ní-máa-mú-mi nípa ìlànà ìwà rere àti ètò fífi ikú bàṣírí olókùnrùn tí wọ́n dáwọ́ lé ní [ilẹ̀ Netherlands], kò ṣẹ̀yìn jíjá tí wọ́n ń jáwọ́ nínú ẹ̀sìn Kristẹni lọ́sàn-án gangan.”
Bákan náà lọ̀ràn ṣe rí láwọn ibòmíràn. Lọ́dún 1999, Bíṣọ́ọ̀bù Àgbà Canterbury, ìyẹn George Carey, sọ pé Ìjọ Áńgílíkà ò ní pẹ́ kógbá sílé.” Nínú àpilẹ̀kọ kan tí ìwé ìròyìn ilẹ̀ Faransé náà Le Figaro pé àkọlé rẹ̀ ní, “Òpin Ẹ̀sìn Kristẹni Nílẹ̀ Yúróòpù,” ó sọ pé: “Bákan náà lọ̀ràn ṣe rí níbi gbogbo. . . . Àwọn èèyàn ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣiyèméjì nípa àwọn ohun tó bá ìwà rere àti ẹ̀kọ́ ìsìn mu.”
Àwọn Èèyàn Ò Fi Bẹ́ẹ̀ Lọ́wọ́ Nínú Ọ̀ràn Ẹ̀sìn Mọ́
Ojoojúmọ́ ni iye èèyàn tó ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì nílẹ̀ Yúróòpù ń dín kù. Iye àwọn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì ilẹ̀ Faransé tó ń lọ sí Máàsì ní gbogbo ọjọ́ Sunday ò tó ìdá mẹ́wàá nínú ọgọ́rùn-ún, kódà kìkì ìdá mẹ́ta sí mẹ́rin péré nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì nílùú Paris ló ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì déédéé.
Bákan náà ni iye àwọn tó ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì ṣe ń dín kù nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Jámánì àtàwọn orílẹ̀-èdè Scandinavia, tàbí kó tiẹ̀ tún burú jù bẹ́ẹ̀ lọ pàápàá.Ọ̀ràn mìíràn tó tún ń kó àwọn aṣáájú ẹ̀sìn lọ́kàn sókè ni ti bí kò ṣe sí àwọn àlùfáà tó pọ̀ tó. Láàárín ọ̀rúndún kan péré, iye àwọn àlùfáà tó wà nílẹ̀ Faransé ti lọọlẹ̀ gan-an. Ìpíndọ́gba àlùfáà mẹ́rìnlá sí èèyàn ẹgbàárùn-ún ni tẹ́lẹ̀ àmọ́ ní báyìí kò tó àlùfáà kan tó ń bójú tó ẹgbàárùn-ún èèyàn. Ní gbogbo ilẹ̀ Yúróòpù, ńṣe ni ìpíndọ́gba ọjọ́ orí àwọn àlùfáà ń lọ sókè, iye wọn sì ti dín kù gan-an láwọn orílẹ̀-èdè bíi Ireland àti Belgium. Lákòókò kan náà, ńṣe ni iye àwọn ògo wẹẹrẹ tí wọ́n ń lọ sílé ẹ̀kọ́ katikísìmù ń lọọlẹ̀ sí i, èyí tó ń mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí ṣiyèméjì pé bóyá ni apá Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì á ká ọ̀ràn ọ̀hún.
Tó bá kan ọ̀ràn ẹ̀sìn, àwọn èèyàn ò ní ìgbọ́kànlé nínú rẹ̀ mọ́ páàpáà. Ìdá mẹ́fà péré nínú ọgọ́rùn-ún àwọn èèyàn ilẹ̀ Faransé ló gbà pé “inú ẹ̀sìn kan ṣoṣo la ti lè rí òtítọ́.” Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ìdá mẹ́ẹ̀ẹ́dógún nínú ọgọ́rùn-ún ni iye yẹn lọ́dún 1981, kódà ìpín àádọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún ni lọ́dún 1952. Ńṣe ni iye àwọn tó ń dágunlá sí ọ̀ràn ìsìn túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Iye àwọn èèyàn tí wọ́n sọ pé kò sóhun tó kan àwọn kan ìsìn ti ròkè láti ìdá mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún lọ́dún 1980 sí ìdá méjìlélógójì nínú ọgọ́rùn-ún lọ́dún 2000.—Les valeurs des Français—Évolutions de 1980 à 2000 (Ìṣirò ti Ilẹ̀ Faransé—Àwọn Ìṣẹ̀lẹ̀ Àtọdún 1980 sí 2000).
Ìyípadà Ńlá Nínú Ọ̀ràn Ìwà Rere
Ìṣòro báwọn ohun tó ṣe pàtàkì ṣe ń di nǹkan àtijọ́ tún kan ọ̀ràn ìwà rere pẹ̀lú. Gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ ṣáájú, ọ̀pọ̀ àwọn tó ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì ni ò ka àwọn òfin ìwà rere ti ṣọ́ọ̀ṣì wọn sí. Wọn ò gbà rárá pé àwọn aṣáájú ẹ̀sìn wọn lẹ́tọ̀ọ́ láti fi àwọn ìlànà ìwà híhù lélẹ̀. Àwọn èèyàn kan náà tí wọ́n pàtẹ́wọ́ wàá-wòó nítorí ohun tí póòpù ṣe lórí ọ̀ràn ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn, ni wọ́n tún sọ pé àwọn ò gba tiẹ̀ mọ́ nígbà tó sọ àwọn ọ̀rọ̀ tó kan bí wọ́n ṣe ń gbé ìgbésí ayé wọn. Bí àpẹẹrẹ, ibi púpọ̀ làwọn èèyàn ò ti fara mọ́ ohun tó sọ nípa lílo oògùn máàlóyún, kódà ọ̀pọ̀ tọkọtaya tó jẹ́ Kátólíìkì ló kọ etí dídi sí i.
Bí ọ̀ràn yìí ṣe kan àwọn ẹlẹ́sìn náà ló kan àwọn tí kì í ṣe ẹlẹ́sìn, tó wà nípò èyíkéyìí láwùjọ. Àwọn ìwà tí Ìwé Mímọ́ kọ̀ làwọn èèyàn ń hù. Ní ogún ọdún sẹ́yìn, ìdá márùndínláàádọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún àwọn èèyàn ilẹ̀ Faransé ló sọ pé ohun burúkú gbáà ni ìwà ìbẹ́yà-kannáà-lòpọ̀. Àmọ́ lónìí, ìdá ọgọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún ló sọ pé kò sóhun tó burú níbẹ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn ló sọ pé ohun tó dára ni ìṣòtítọ́ nínú ìgbéyàwó, àmọ́ kìkì ìdá mẹ́rìndínlógójì nínú ọgọ́rùn-ún ló sọ pé kò dáa rárá kéèyàn ti gbéyàwó kó tún máa lójú sóde.—Róòmù 1:26, 27; 1 Kọ́ríńtì 6:9, 10; Hébérù 13:4.
Àmúlùmálà Ẹ̀sìn
Èyí tó tún dé báyìí ní apá Ìwọ̀ Oòrùn ayé ni ẹ̀sìn ṣe-é-bó-ṣe-wù-ọ́, èyí tí olúkúlùkù lẹ́tọ̀ọ́ láti yan ohun tó bá wù ú láti gbà gbọ́. Wọ́n fara mọ́ àwọn ẹ̀kọ́ kan, wọn ò sì fara mọ́ àwọn mìíràn. Àwọn kan sọ pé Kristẹni làwọn bẹ́ẹ̀ sì rèé wọ́n nígbàgbọ́ nínú àtúnwáyé, tinútinú làwọn mìíràn sì fi ń tẹ̀ lé ìgbàgbọ́ àwọn ẹ̀sìn bíi mélòó kan lákòókò kan náà. (Oníwàásù 9:5, 10; Ìsíkíẹ́lì 18:4, 20; Mátíù 7:21; Éfésù 4:5, 6) Ìwé náà Les valeurs des Français fi hàn gbangba pé ọ̀pọ̀ onígbàgbọ́ lóde òní ló ti ń kúrò lójú ọ̀nà tí ẹ̀sìn là kalẹ̀, wọn ò sì ní lè padà mọ́.
Bó ti wù kó rí, ewu ń bẹ nínú àṣà kí olúkúlùkù máa ṣẹ̀sìn rẹ̀ lọ́nà tó bá wù ú. Jean Delumeau, tó jẹ́ òpìtàn nípa ẹ̀sìn àti ọmọ ẹgbẹ́ Institut de France, fi gbogbo ara gbà pé kò ṣeé ṣe kí ẹnì kan sọ pé òun fẹ́ lọ dá ẹ̀sìn tara òun sílẹ̀, pé òun ò sì ní lo èyíkéyìí lára àwọn ọ̀nà ẹ̀sìn tá a ti là sílẹ̀. “Ìgbàgbọ́ ò lè rọ́wọ́ mú láìjẹ́ pé ó fi ti ẹ̀sìn kan pàtó ṣe.” Àwọn ojúlówó nǹkan tẹ̀mí àti ọ̀nà tá a gbà ń ṣe ẹ̀sìn kò gbọ́dọ̀ yara wọn lẹ́sẹ̀ kan. Àmọ́ ibo la ti lè rí irú ìsopọ̀ bẹ́ẹ̀ nílé ayé tí ò dúró sójú kan yìí?
Láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin Bíbélì la ti lè rí i pé Ọlọ́run ló ń fi ìwà àti ìlànà rere lélẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó fún ẹ̀dá èèyàn lómìnira yálà kó yàn láti tẹ̀ lé ìlànà yìí tàbí kó yàn láti má ṣe bẹ́ẹ̀. Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn kárí ayé ló mọ̀ pé ìwé ṣíṣeyebíye yìí wúlò gan-an lóde òní àti pé òun tún ni ‘fìtílà fún ẹsẹ̀ wọn, àti ìmọ́lẹ̀ sí òpópónà wọn.’ (Sáàmù 119:105) Kí nìdí tí wọ́n fi sọ bẹ́ẹ̀? Èyí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.