Iṣẹ́ Ìwàásù Tí A Kò Lè Gbàgbé
Iṣẹ́ Ìwàásù Tí A Kò Lè Gbàgbé
“Oòrùn náà mú gan-an. Ńṣe ló dà bí ẹni pé ọ̀nà olókè tá a gbà náà kò lópin. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ìrìn àti làálàá, a dé ibi tá à ń lọ: abúlé kan tó jìnnà gan-an ni. Ó ti rẹ̀ wá tẹnutẹnu, àmọ́ àárẹ̀ yìí di ayọ̀ nígbà tá a dé ilé àkọ́kọ́ tí wọ́n sì gbà wá tọwọ́tẹsẹ̀. Nígbà tó fi máa di ìrọ̀lẹ́, gbogbo ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá a kó dání lá ti fi síta, a sì ti bẹ̀rẹ̀ ọ̀pọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó wu àwọn èèyàn náà gan-an láti kẹ́kọ̀ọ́. Àmọ́ ṣá àjò ò lè dùn kónílé má relé, ó di dandan pé ká lọ, ṣùgbọ́n a sọ fún wọn pé a máa padà wá.”
ÀWỌN ìrírí bí èyí wọ́pọ̀ gan-an láàárín àwùjọ àwọn òjíṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà kan ní Mẹ́síkò. Ohun tó wà lórí ẹ̀mí wọn ni pé kí wọ́n fi gbogbo ara lọ́wọ́ nínú ṣíṣe iṣẹ́ tí Jésù Kristi gbé lé àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ́wọ́ pé: “Ẹ ó sì jẹ́ ẹlẹ́rìí mi . . . títí dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.” (Ìṣe 1:8) Nílùú Mẹ́síkò, wọ́n ṣètò àkànṣe kan fún wíwàásù—èyí tí wọ́n pè ní ìpínlẹ̀ tá a yàn fáwọn aṣáájú ọ̀nà. Èrèdí ètò yìí jẹ́ láti lè wàásù láwọn ìpínlẹ̀ tá ò yàn fún ìjọ èyíkéyìí, tí a kì í sì í wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run níbẹ̀ déédéé. Àwọn ìpínlẹ̀ yìí sábà máa ń jẹ́ ibi àdádó tàbí àwọn àgbègbè tó nira láti dé. Wọ́n tún máa ń ṣèrànwọ́ fáwọn ìjọ àdádó tí wọ́n ní ìpínlẹ̀ tó pọ̀ gan-an láti wàásù.
Ká bàa lè mọ àwọn ibi tó máa wà lára àwọn ìpínlẹ̀ tá a yàn fáwọn aṣáájú ọ̀nà ní orílẹ̀-èdè náà, ńṣe ni ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń kọ́kọ́ wo ohun tó jẹ́ àìní ìpínlẹ̀ náà. a Lẹ́yìn náà, wọ́n á wá yan àwọn aṣáájú ọ̀nà àkànṣe láti lọ síbẹ̀. Wọ́n á fún wọn ní ọkọ̀ tó lè rin àwọn ọ̀nà tó rí gbágungbàgun tí wọn ò dọ̀dà sí. Inú àwọn ọkọ̀ yìí ni wọ́n máa ń kó àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ sí, wọ́n sì máa ń sùn sínú rẹ̀ nígbà mìíràn.
Wọ́n Gba Ìhìn Rere Náà
Láti October 1996 la ti ń ké sáwọn oníwàásù ìhìn rere náà káàkiri pé kí wọ́n wá ran àwọn aṣáájú ọ̀nà àkànṣe lọ́wọ́ nínú ìgbòkègbodò yìí. Àwọn akéde Ìjọba náà àtàwọn aṣáájú ọ̀nà déédéé tí wọ́n fẹ́ láti sìn níbi tí àìní gbé pọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí lọ́wọ́ nínú ìgbòkègbodò náà. A yan àwọn kan sáwọn ìjọ tó wà ní àgbègbè ibi tá a ti ń lọ wàásù náà kí wọ́n lè bójú tó ìpínlẹ̀ náà kí wọ́n sì padà lọ bẹ àwọn tó fìfẹ́ hàn wò. Ọ̀pọ̀ àwọn akéde àtàwọn aṣáájú ọ̀nà ló tẹ́wọ́ gba ìkésíni náà, ìrírí tí wọ́n sì ti rí níbẹ̀ ń wúni lórí gan-an.
Bí àpẹẹrẹ, Kristẹni ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Abimael, tó ń ṣiṣẹ́ tó ń mówó gọbọi wọlé nílé iṣẹ́ tẹlifóònù alágbèéká, pinnu pé òun á lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù náà láwọn àgbègbè àdádó wọ̀nyẹn. Nígbà táwọn ọ̀gá rẹ̀ rí i pé ó fẹ́ fiṣẹ́ sílẹ̀, kíá ni wọ́n fún un ní ìgbéga lẹ́nu iṣẹ́ tí wọ́n sì fi kún owó oṣù rẹ̀. Àwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ náà ò jẹ́ kó rímú mí, wọ́n sọ fún un pé àǹfààní ńlá ló ní yìí o pé ìwà òpònú ló máa jẹ́ tó bá kọ̀ ọ́. Àmọ́ ṣá, ohun tó wà lórí ẹ̀mí Abimael ni pé kóun fi oṣù mẹ́ta gbáko lọ́wọ́ nínú ètò ìwàásù àkànṣe náà. Lẹ́yìn tí Abimael gbádùn iṣẹ́ ìsìn yìí, ló bá pinnu pé òun á ṣí lọ sí ìjọ àdádó kan tá a ti nílò àwọn akéde Ìjọba náà gan-an. Ó ti níṣẹ́ kékeré kan tó fi ń pawọ́ báyìí, ìgbésí ayé ṣe-bóo-ti-mọ ló sì ń gbé.
Ìrírí mìíràn ni ti Julissa, odidi wákàtí méjìlélógún ló máa fi rìnrìn àjò nínú bọ́ọ̀sì kó tó dé ibi tá a yàn fún un. Ó ti ń ṣe àjáwọ̀ ọkọ̀ bọ̀ o, nígbà tó débi tá á ti wọ ẹyọ kan tó kù tá a gbé e
débi tó ń lọ, kò bọ́kọ̀ nílẹ̀ mọ́. Àmọ́ ó rí ọkọ̀ akẹ́rù kan tó ń kó àwọn òṣìṣẹ́. Julissa lo ìgboyà, ó bẹ̀ wọ́n pé kí wọ́n gbé òun. Ṣùgbọ́n ṣá ọkàn rẹ̀ ò balẹ̀ nítorí pé òun nìkan lobìnrin tó wà láàárín àwọn ọkùnrin tó pọ̀ gan-an. Nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí wàásù fún ọ̀dọ́kùnrin kan ló wá rí i pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹni yẹn! Julissa sọ pé: “Yàtọ̀ síyẹn, àṣé ọ̀kan lára àwọn alàgbà ìjọ tí wọ́n yàn mí sí ni ẹni tó ń wa ọkọ̀ náà!”Àwọn Àgbàlagbà Ò Gbẹ́yìn
Kì í kúkú ṣe àwọn ọ̀dọ́ nìkan ló lọ́wọ́ nínú ìgbòkègbodò yìí. Arábìnrin àgbàlagbà kan tó ń jẹ́ Adela, ti ní in lọ́kàn tipẹ́tipẹ́ láti túbọ̀ fi àkókò púpọ̀ sí i ṣiṣẹ́ ìwàásù. Ó wá rí àǹfààní yìí nígbà tí wọ́n ké sí i pé kó wá nípìn-ín nínú ìgbòkègbodò ìwàásù àkànṣe yìí. Ó sọ pé: “Mo gbádùn ìpínlẹ̀ tá a yàn fún mi gidi gan-an débi pé mo sọ fáwọn alàgbà ìjọ náà pé kí wọ́n jẹ́ kí n kúkú máa gbébẹ̀. Inú mi dùn pé mo ṣì wúlò fún Jèhófà bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti ń darúgbó.”
Bákan náà, ìmọrírì tí Martha, ẹni ọgọ́ta ọdún fi hàn sí Jèhófà àti ìfẹ́ tó ní sáwọn èèyàn bíi tiẹ̀ ló mú kó yọ̀ǹda ara rẹ̀ láti lọ́wọ́ nínú ìgbòkègbodò náà. Nígbà tó rí i pé jíjìn tí ìpínlẹ̀ tí wọ́n pín fóun àtàwọn tó kù rẹ̀ jìnnà, àti pé ọ̀nà ibẹ̀ tí ò dára kì í jẹ́ káwọn lè dé ọ̀dọ̀ gbogbo èèyàn níbẹ̀, ó ra ọkọ̀ kan ó sì gbé e fáwọn aṣáájú ọ̀nà náà kí wọ́n máa lò ó. Ọkọ̀ tí arábìnrin yìí gbé kalẹ̀ mú kí wọ́n lè dé àwọn ìpínlẹ̀ tó pọ̀ sí i kí wọ́n sì wàásù òtítọ́ inú Bíbélì fáwọn èèyàn púpọ̀ sí i.
Báwọn Èèyàn Ṣe Dáhùn Padà Ń Wúni Lórí
Ohun tó wà lórí ẹ̀mí àwọn tó lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù àkànṣe yìí ni pé kí wọ́n ‘sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn.’ Bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ lọ̀ràn sì ṣe rí. Àwọn èèyàn tí wọ́n wà ní àdádó ti rí òtítọ́ Bíbélì tó ń fúnni ní ìyè. (Mátíù 28:19, 20) Ọ̀pọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì la ti bẹ̀rẹ̀. Àwọn akéde tó wà ládùúgbò náà tàbí àwọn ajíhìnrere tí wọ́n dúró sí ìpínlẹ̀ náà ló ń darí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ wọ̀nyí. Ìgbà mìíràn sì wà tá a ṣètò àwọn akéde sí àwùjọ àwùjọ, a tiẹ̀ ti dá àwọn ìjọ kéékèèké sílẹ̀ láwọn ibòmíràn pàápàá.
Ọkọ̀ èrò ni Magdaleno àtàwọn yòókù ẹ̀ máa ń wọ̀ lọ sí ìpínlẹ̀ àdádó tá a yàn wọ́n sí. Tí wọ́n bá wà lójú ọ̀nà, wọ́n máa ń lo àǹfààní yìí láti wàásù fún awakọ̀ wọn. “Ọkùnrin náà sọ fún wa pé àwọn Ẹlẹ́rìí wá sílé òun lọ́sẹ̀ tó kọjá àmọ́ òun ò sí nílé. Nígbà tó dé, àwọn tó wà nínú
ìdílé rẹ̀ sọ nǹkan tí wọ́n ti gbọ́ fún un. A sọ fún un pé kì í ṣe ìtòsí níbẹ̀ làwa ti wá, pé ńṣe la wá láti onirúurú ìpínlẹ̀ lórílẹ̀-èdè náà láti gbárùkù ti iṣẹ́ ìwàásù àkànṣe yìí, pé olúkúlùkù ló sì sanwó ọkọ̀ tó wọ̀ wá. Èyí wú awakọ̀ náà lórí gan-an, ó sì sọ pé òun àti ìdílé òun á bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní ọ̀sẹ̀ náà. Ó tiẹ̀ ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ náà, nítorí pé kò gbowó ọkọ̀ lọ́wọ́ wa.”Ohun mìíràn tó tún wú Magdaleno lórí ni báwọn èèyàn agbègbè olókè Chiapas ṣe gba ìhìn náà. “Èmi àti ìyàwó mi sọ ìhìn Ìjọba náà fún àwùjọ àwọn ọ̀dọ́ mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n tí wọ́n ń lọ sí Ṣọ́ọ̀ṣì Presbyterian. Gbogbo wọn ló tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́ fún odidi ọgbọ̀n ìṣẹ́jú. Wọ́n gbé Bíbélì wọn jáde, a sì jẹ́rìí fún wọn dáadáa nípa àwọn ète Jèhófà. Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn èèyàn náà ló ní Bíbélì tí wọ́n fi èdè Tzeltal kọ. A bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bíi mélòó kan tó sì ń tẹ̀ síwájú.
Inúnibíni Rọlẹ̀
Ó ti lé lọ́dún méjì tí ìhìn Bíbélì ti dé abúlé kan tó wà ní Chiapas gbẹ̀yìn, inúnibíni táwọn èèyàn ibẹ̀ ń ṣe ló sì fà á. Teresa, tó jẹ́ ajíhìnrere alákòókò kíkún, kíyè sí i pé ọkàn àwọn akéde kan ò fi bẹ́ẹ̀ balẹ̀ láti wàásù ní abúlé náà. “Àmọ́, ó ya gbogbo wa lẹ́nu pé àwọn èèyàn náà tẹ́tí sí wa. Nígbà tá a wàásù tán, ni ọ̀wààrà òjò bá bẹ̀rẹ̀ sí rọ̀. Ibi tá a ti ń wá ibi tá a lè forí pa mọ́ sí la ti dé ilé ọ̀gbẹ́ni kan tó ń jẹ́ Sebastián, ọ̀gbẹ́ni yìí ṣèèyàn ó sì jẹ́ ká wọlé kí òjò má bà a pa wá. Nígbà tá a wọlé, mo béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ bóyá wọ́n ti wàásù dé ọ̀dọ̀ rẹ̀. Nígbà tó sọ pé rárá, mo wàásù fún un mo sì fi ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú rẹ̀. b Lẹ́yìn ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, pẹ̀lú omijé lójú ni Sebastián fi ń bẹ̀ wá pé ká padà wá bá òun ṣèkẹ́kọ̀ọ́.”
Àwùjọ àwọn aṣáájú ọ̀nà mìíràn tí wọ́n lọ sí Chiapas ròyìn pé: “Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, ìròyìn ayọ̀ la mú tọ̀hún bọ̀. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n la bẹ̀rẹ̀ ní ọ̀sẹ̀ àkọ́kọ́ pàá; lọ́sẹ̀ kejì, a ké sáwọn èèyàn pé kí wọ́n wá wo fídíò The Bible—Its Power in Your Life. Ọgọ́ta èèyàn ló wá. Gbogbo wọn pátá ló gbádùn rẹ̀. Lópin gbogbo rẹ̀, a sọ pé a máa dá ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé ìjọ kan sílẹ̀ níbẹ̀. Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ fún wa pé ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé ìjọ méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ la dá sílẹ̀ ní abúlé yìí.
“Lẹ́yìn tá a parí iṣẹ́ láwọn ìpínlẹ̀ tí wọ́n yàn fún wa, a padà lọ ṣèbẹ̀wò sáwọn abúlé náà láti fún àwọn tó fìfẹ́ hàn lókun ká sì lè mọ bí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé ìjọ tá a dá sílẹ̀ ṣe ń lọ sí. A ní kí wọ́n wá sí ìpàdé fún gbogbo ènìyàn àti Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́. Àmọ́ ṣá, kò síbi tó tóbi tó tá a ti lè ṣe ìpàdé náà. Ẹni tó ní ká máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé ìjọ nílé òun
nawọ́ sí gbàgede ilé rẹ̀ ó sì sọ pé: ‘A lè ṣe ìpàdé náà ní ẹ̀yìnkùlé mi.’”Ní òpin ọ̀sẹ̀ náà, gbogbo àwọn aṣáájú ọ̀nà tó wá ṣèbẹ̀wò àtàwọn tó fìfẹ́ hàn ló fi tìtaratìtara tún gbàgede náà ṣe ká lè ṣe ìpàdé náà níbẹ̀. Èèyàn mẹ́tàlélọ́gọ́rùn-ún ló wá sí ìpàdé àkọ́kọ́. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ogójì là ń darí ní abúlé náà báyìí.
“Ìrírí Àgbàyanu”
Yàtọ̀ sí pé àbájáde iṣẹ́ ìwàásù náà ń wúni lórí púpọ̀, àwọn tó lọ́wọ́ nínú ìgbòkègbodò yìí fúnra wọn ti jàǹfààní tó ga lọ́lá. Ọ̀dọ́ aṣáájú ọ̀nà kan tó ń jẹ́ María, tóun náà kópa nínú ìwàásù yìí sọ bó ṣe rí lára rẹ̀, ó ní: “Ìdí méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni mo fi gbádùn ètò náà. Ayọ̀ mi nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pọ̀ sí i, àjọṣe àárín èmi àti Jèhófà sì wá ṣe tímọ́tímọ́ sí i. Lákòókò kan tá à ń gun orí òkè ńlá kan báyìí, ó rẹ̀ wá tẹnutẹnu. Àmọ́ lẹ́yìn tá a bẹ Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́, ńṣe ni ọ̀rọ̀ Aísáyà 40:29-31 ṣẹ sí wá lára, pé: ‘Àwọn tí ó ní ìrètí nínú Jèhófà yóò jèrè agbára padà.’ Èyí ló jẹ́ ká débi tá à ń lọ à sì bá àwọn èèyàn tó gbà wá tọwọ́tẹsẹ̀ ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.”
Ọ̀dọ́ aṣáájú ọ̀nà mìíràn tó ń jẹ́ Claudia, ẹni ọdún mẹ́tàdínlógún sọ fún wa pé: “Mo ti jàǹfààní níbẹ̀ gan-an. Mo ti kọ́ láti túbọ̀ di ògbóṣáṣá sí i nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, èyí sì ti fún mi láyọ̀ púpọ̀, bẹ́ẹ̀ ló ti tún jẹ́ kí n gbé àwọn góńgó tẹ̀mí tí mo fẹ́ lé bá kalẹ̀. Mo tún ti dàgbà dénú nípa tẹ̀mí. Màmá mi ló máa ń bá mi ṣe gbogbo nǹkan nígbà tí mo wà nílé. Àmọ́ ní báyìí tí mo ti túbọ̀ nírìírí sí i, mo ti dẹni tó lè dá nǹkan ṣe fúnra rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, tẹ́lẹ̀ ńṣe ni mo máa ń ṣa oúnjẹ jẹ. Àmọ́ ní báyìí, ó ti di pé kí n jẹ́ kí onírúurú ipò mọ́ mi lára, n kì í ṣa oúnjẹ jẹ mọ́. Irú iṣẹ́ ìsìn yìí ti mú kí n láwọn ọ̀rẹ́ àtàtà. Ńṣe la jọ máa ń pín nǹkan tá a bá ní a sì máa ń ran ara wa lọ́wọ́.”
Ìkórè Aláyọ̀
Kí làwọn ohun tó ti tìdí ìsapá àkànṣe wọ̀nyí jáde? Nígbà tó fi máa di ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 2002, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjìdínlọ́gbọ̀n ó lé ọ̀ọ́dúnrún [28,300] àwọn aṣáájú ọ̀nà ló ti lọ sí ìpínlẹ̀ tá a yàn fáwọn aṣáájú ọ̀nà yìí. Wọ́n ti darí ọ̀kẹ́ méje [140,000] ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, iye wákàtí tí wọ́n sì ti lò nínú iṣẹ́ ìwàásù ti lé ní mílíọ̀nù méjì. Wọ́n ti fi nǹkan bí ọ̀kẹ́ mẹ́fà ó lé ẹgbẹ̀rún [121,000] ìwé ńlá àti ìwé ìròyìn tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọ̀kẹ́ mẹ́rìndínlógójì ó lé ẹgbàárùn-ún [730,000] sóde, kí wọ́n lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Bíbélì. A sì sábà máa ń rí àwọn aṣáájú ọ̀nà kan tí wọ́n ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ogún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ.
Inú àwọn èèyàn tá a ṣe inú rere sí yìí dùn gan-an fún ìsapá ńláǹlà táwọn èèyàn ṣe láti mú ìhìn Bíbélì dé ọ̀dọ̀ wọn. Pẹ̀lú bí wọn ò ṣe fi bẹ́ẹ̀ rí já jẹ yẹn, ọ̀pọ̀ wọn ló máa ń ta kú pé káwọn akéde náà gba ọrẹ. Gbogbo ìgbà táwọn aṣáájú ọ̀nà bá dé ọ̀dọ̀ ìyá arúgbó kan tó jẹ́ ẹni àádọ́rin ọdún, tó sì jẹ́ aláìní, ló máa ń ta wọ́n lọ́rẹ. Táwọn yẹn bá ní kó fi ọrẹ náà sílẹ̀, ńṣe ló máa bú sẹ́kún. Ìdílé kan tó jẹ́ aláìní máa ń sọ fáwọn ajíhìnrere alákòókò kíkún náà pé adìyẹ àwọn ti yé ẹyin o, pé àwọn gan-an ni adìyẹ ọ̀hún sì yé ẹyìn náà fún, nítorí náà kí wọ́n wá kó o.
Èyí tó ṣe pàtàkì jù lọ níbẹ̀ ni pé àwọn èèyàn olóòótọ́ ọkàn yìí ní ìmọrírì tòótọ́ fáwọn nǹkan tẹ̀mí. Bí àpẹẹrẹ, ìrìn wákàtí mẹ́ta àtààbọ̀ ni ọ̀dọ́mọbìnrin kan máa ń nìkan rin wá sí ìpàdé Kristẹni, kì í sì í pa ìpàdé kankan jẹ. Orúnkún máa ń yọ obìnrin àgbàlagbà kan tó fìfẹ́ hàn lẹ́nu, síbẹ̀ ó máa ń rìnrìn àjò wákàtí méjì láti gba ìtọ́ni Bíbélì lákòókò ìbẹ̀wò alábòójútó arìnrìn-àjò. Àwọn tí ò kàwé tẹ́lẹ̀ fẹ́ láti mọ̀ ọ́n kọ mọ̀ ọ́n kà kí wọ́n lè túbọ̀ jàǹfààní nínú ẹ̀kọ́ Bíbélì. Ìbùkún ńláǹlà ni wọ́n ti ri gbà fún ìsapá wọn yìí.
Nínú ìwé Ìṣe, Lúùkù ṣàpèjúwe ìran kan tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rí, pé: “Ọkùnrin kan ará Makedóníà dúró, ó ń pàrọwà fún un, ó sì wí pé: ‘Rékọjá wá sí Makedóníà, kí o sì ràn wá lọ́wọ́.’” Tinútinú ni Pọ́ọ̀lù fi ṣe bẹ́ẹ̀. Lónìí, ọ̀pọ̀ ló ti lo irú ẹ̀mí kan náà láwọn ibi àdádó tó wà ní Mẹ́síkò, tí wọ́n yọ̀ǹda ara wọn láti polongo ìhìn rere náà “títí dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.”—Ìṣe 1:8; 16:9, 10.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ní ọdún àìpẹ́ yìí, ó lé ní ìdá mẹ́jọ nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ìpínlẹ̀ táwọn ìjọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í ti í wàásù déédéé ní Mẹ́síkò. Èyí túmọ̀ sí pé iye tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́jọ ó lé ọ̀kẹ́ mẹ́wàá [8,200,000] ló ń gbé láwọn àgbègbè àdádó yìí níbi tí a kì í ti í ṣe iṣẹ́ ìwàásù náà déédéé.
b Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí ará Mẹ́síkò ló ti lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù àkànṣe náà