Ibo Lo Ti Lè Rí Ìlànà Ẹ̀sìn Tòótọ́?
Ibo Lo Ti Lè Rí Ìlànà Ẹ̀sìn Tòótọ́?
BÍ ẸNÍ ń ṣẹ̀fẹ̀ ni Rodolphe fi béèrè pé: “Tó bá jẹ́ tìtorí pé ìdílé rẹ ń ṣe ẹ̀sìn kan pàtó ni ìwọ náà ṣe fẹ́ ṣe é, o ò ṣe kúkú ṣe ẹ̀sìn Celtic táwọn baba ńlá wa ayé ọjọ́hun ṣe ní ẹgbàá [2,000] ọdún sẹ́yìn?” Ńṣe làwọn ọmọdé tó gbọ́ ohun tó sọ yìí bú sẹ́rìn-ín.
Rodolphe sọ pé: “Àjọṣe àárín èmi àti Ọlọ́run ṣe pàtàkì gan-an lójú mi. Mi ò fi ibì kankan fara mọ́ àṣà pé kí wọ́n máa mú mi ní ọ̀ranyàn láti tẹ̀ lé àṣà ẹ̀sìn kan kìkì nítorí pé àwọn èèyàn mi tó ti gbé ayé ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún sẹ́yìn ṣe irú ẹ̀sìn bẹ́ẹ̀.” Tìṣọ́ratìṣọ́ra ni Rodolphe fi gbé ọ̀ràn náà yẹ̀ wò; kò fojú kéré ọ̀ràn náà rárá, kó máa sọ pé ohun àjogúnbá ni.
Òótọ́ ni pé fífi ẹ̀sìn ẹni lé ìran tó ń bọ̀ lẹ́yìn lọ́wọ́ kò fi bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀ mọ́ lóde òní, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ èèyàn ni ò tíì lè fi ẹ̀sìn tí ìdílé wọn ń ṣe sílẹ̀. Àmọ́ ṣé gbogbo ìgbà ló tọ̀nà pé kéèyàn fara mọ́ àwọn ẹ̀kọ́ ìsìn òbí ẹni? Kí ni Bíbélì sọ?
Lẹ́yìn táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti rìnrìn ogójì ọdún nínú aginjù, Jóṣúà tó rọ́pò Mósè sọ àwọn ohun kan fún wọn pé kí wọ́n yan èyí tí wọ́n bá fẹ́, ó ní: “Wàyí o, bí ó bá burú ní ojú yín láti máa sin Jèhófà, lónìí yìí, ẹ yan ẹni tí ẹ̀yin yóò máa sìn fún ara yín, yálà àwọn ọlọ́run tí àwọn baba ńlá yín tí wọ́n wà ní ìhà kejì Odò tẹ́lẹ̀ sìn ni tàbí àwọn ọlọ́run àwọn Ámórì ní ilẹ̀ àwọn ẹni tí ẹ ń gbé. Ṣùgbọ́n ní tèmi àti agbo ilé mi, Jèhófà ni àwa yóò máa sìn.”—Jóṣúà 24:15.
Ọ̀kan lára àwọn baba ńlá tí Jóṣúà sọ̀rọ̀ rẹ̀ ni Térà, ìyẹn baba Ábúráhámù, tó gbé ní ìlú Úrì tó wà lápá ìlà oòrùn Odò Yúfírétì nígbà náà lọ́hùn-ún. Bíbélì ò ṣàlàyé kúlẹ̀kúlẹ̀ àwọn ohun mìíràn fún wa nípa Térà, kìkì pé ó sin òrìṣà ló jẹ́ ká mọ̀. (Jóṣúà 24:2) Ábúráhámù tó jẹ́ ọmọ rẹ̀ ò mọ ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́, síbẹ̀ kò lọ́ tìkọ̀ rárá láti kúrò ní ìlú rẹ̀ nígbà tí Jèhófà sọ pé kó ṣe bẹ́ẹ̀. Dájúdájú, ẹ̀sìn tí Ábúráhámù yàn yàtọ̀ pátápátá sí ti bàbá rẹ̀. Ohun tí Ábúráhámù ṣe yìí ló mú kó rí ìbùkún tí Ọlọ́run ṣèlérí rẹ̀, tó sì fi di ẹni tí ọ̀pọ̀ ẹ̀sìn kà sí “baba gbogbo àwọn tí ó gba Ọlọ́run gbọ́.”—Róòmù 4:11, Today’s English Version.
Bíbélì tún sọ̀rọ̀ Rúùtù ní rere, ìyẹn ìyá ńlá Jésù Kristi. Ará Móábù ni Rúùtù, ọmọ Ísírẹ́lì sì lọkọ rẹ̀. Nígbà tó di opó, ó di pé kó yàn láti dúró sí orílẹ̀-èdè tirẹ̀ tàbí kó bá ìyá ọkọ rẹ̀ padà sí Ísírẹ́lì. Nítorí pé Rúùtù mọ̀ pé ìjọsìn Jèhófà ṣe pàtàkì ju òrìṣà táwọn òbí òun ń bọ lọ, ó là á mọ́lẹ̀ kedere fún ìyá ọkọ rẹ̀ pé: “Àwọn ènìyàn rẹ ni yóò jẹ́ ènìyàn mi, Ọlọ́run rẹ ni yóò sì jẹ́ Ọlọ́run mi.”—Rúùtù 1:16, 17.
Nígbà tí ìwé atúmọ̀ èdè Dictionnaire de la Bible, ń sọ̀rọ̀ lórí bí àkọsílẹ̀ yìí ti ṣe pàtàkì tó nínú àwọn ìwé Bíbélì, ó ṣàlàyé pé àkọsílẹ̀ náà fi hàn “bí obìnrin kan tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ òkèèrè, tá a bí láàárín àwọn kèfèrí tó
kórìíra àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, táwọn ọmọ Ísírẹ́lì náà kì í sì í fẹ́ rí sójú, . . . ṣe tìtorí ìfẹ́ tó ní sí orílẹ̀-èdè Jèhófà àti ìjọsìn rẹ̀, di ìyá ńlá Dáfídì Ọba mímọ́ nípasẹ̀ ìdarí àtọ̀runwá.” Rúùtù ò lọ́ tìkọ̀ rárá láti yan ìsìn tó yàtọ̀ sí tàwọn òbí rẹ̀, ìpinnu rẹ̀ yìí ló sì jẹ́ kí Ọlọ́run bù kún un.Àkọsílẹ̀ tó sọ̀rọ̀ nípa bí ẹ̀sìn Kristẹni ṣe bẹ̀rẹ̀ ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa ìdí táwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù fi jáwọ́ nínú ẹ̀sìn àwọn baba ńlá wọn. Àpọ́sítélì Pétérù sọ̀rọ̀ lọ́nà tó ń yíni lérò padà nígbà tó ń bá àwùjọ kan sọ̀rọ̀, ó sì rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n “gba ara [wọn] là kúrò lọ́wọ́ ìran oníwà wíwọ́ yìí,” nípa ríronú pìwà dà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn kí wọ́n sì ṣe batisí ní orúkọ Jésù Kristi. (Ìṣe 2:37-41) Ọ̀kan lára àwọn àpẹẹrẹ tó gbàfiyèsí jù lọ ni ti Sọ́ọ̀lù, tó jẹ́ Júù tó máa ń ṣenúnibíni sáwọn Kristẹni. Nígbà tó ń lọ sí Damásíkù, ó rí ìran Kristi, ẹ̀yìn èyí ló di Kristẹni tá a sì wá mọ̀ ọ́n sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù.—Ìṣe 9:1-9.
Èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ni wọn ò ní irú ìrírí kíkàmàmà bí èyí. Síbẹ̀, gbogbo wọn ló jáwọ́ nínú ẹ̀sìn àwọn Júù tàbí ti òrìṣà àwọn kèfèrí. Àwọn tó gba ẹ̀sìn Kristẹni ṣe bẹ́ẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n ti lóye àwọn ohun tó jẹ́ òtítọ́ yékéyéké, lọ́pọ̀ ìgbà lèyí máa ń jẹ́ lẹ́yìn tí wọ́n ti bá wọn fọ̀rọ̀ jomitoro ọ̀rọ̀ dáadáa lórí ipa tí Jésù ń kó gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà náà. (Ìṣe 8:26-40; 13:16-43; 17:22-34) Àwọn Kristẹni ìjímìjí yìí ní àwọn ìsọfúnni tó ṣe gbòógì nípa ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí wọ́n ṣe àwọn àtúnṣe kan nínú ìgbésí ayé wọn. Gbogbo èèyàn nílé lóko ló gba ìkésíni náà, àtàwọn tó jẹ́ Júù àtàwọn tí kì í ṣe Júù, ìsọfúnni náà kò sì yàtọ̀ síra. Tí wọ́n bá fẹ́ múnú Ọlọ́run dùn, wọ́n ní láti tẹ̀ lé ọ̀nà ìjọsìn tuntun kan, ìyẹn ti ẹ̀sìn Kristẹni.
Yíyàn Tó Kàn Wá
Dájúdájú, ó gba ìgboyà ní ọ̀rúndún kìíní láti jáwọ́ nínú ẹ̀sìn téèyàn bá lọ́wọ́ àwọn òbí rẹ̀—ìyẹn ẹ̀sìn àwọn Júù, jíjọ́sìn olú ọba tàbí jíjọ́sìn àwọn òrìṣà—kéèyàn wá dara pọ̀ mọ́ ẹ̀sìn táwọn Júù àtàwọn ará Róòmù máa ń yọ ṣùtì sí. Inúnibíni rírorò ni yíyan irú ẹ̀sìn yìí ń yọrí sí. Lónìí, ó gba irú ìgboyà kan náà téèyàn ò bá fẹ́ “jẹ́ kí wọ́n sọ òun dà bíi tàwọn mìíràn nínú ayé tó jẹ́ pé àṣà ṣohun-tí-gbogbo-èèyàn-ń-ṣe tó gbòde ni wọ́n ń tẹ̀ lé,” gẹ́gẹ́ bí àlàyé tí Hippolyte Simon, tó jẹ́ àlùfáà ìjọ Kátólíìkì ti Clermont-Ferrand, ṣe nínú ìwé rẹ̀ Vers une France païenne? Ó gba ìgboyà láti di ara ẹ̀sìn táwọn èèyàn ibẹ̀ ò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ tí wọ́n sì máa ń ṣàtakò sí nígbà mìíràn, ìyẹn ẹ̀sìn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
Inú ẹ̀sìn Kátólíìkì ni wọ́n ti tọ́ ọ̀dọ́mọkùnrin kan tó ń jẹ́ Paul, ọmọ ìlú Bastia ní Corsica, dàgbà. Ó máa ń kópa nínú àwọn ìgbòkègbodò inú ṣọ́ọ̀ṣì lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, irú bíi títa àkàrà òyìnbó láti rí owó fún ẹgbẹ́ aláàánú kan tí ìjọ Kátólíìkì dá sílẹ̀. Ó wù ú láti túbọ̀ lóye Bíbélì sí i, èyí ló mú kó gbà láti máa jíròrò pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà déédéé. Bí àkókò ti ń lọ, ó wá rí i pé nǹkan tóun ń kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ á fún òun ní àǹfààní tó wà títí láé. Nítorí èyí, Paul tẹ́wọ́ gba àwọn ẹ̀kọ́ ṣíṣeyebíye tó wà nínú Bíbélì ó sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àwọn òbí rẹ̀ kò bá a fa wàhálà kankan o, èyí ò sì ṣe ìpalára kankan fún àjọṣe tímọ́tímọ́ tó wà láàárín ìdílé náà.
Apá gúúsù ilẹ̀ Faransé ni Amélie ń gbé ní tiẹ̀. Àtọ̀dọ̀ ìran mẹ́rin tó ṣáájú làwọn tó jẹ́ ara ìdílé rẹ̀ ti ń ṣe ẹ̀sìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bọ̀. Kí ló mú ọ̀dọ́bìnrin yìí fara mọ́ àwọn ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn àwọn òbí rẹ̀? Ó sọ pé: “Èèyàn ò lè di Ẹlẹ́rìí Jèhófà kìkì nítorí pé àwọn òbí rẹ̀ tàbí àwọn òbí rẹ̀ àgbà jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Bópẹ́ bóyá, ohun tí wàá sọ fún ara rẹ ni pé, ‘Ẹ̀sìn mi ni, nítorí pé àwọn ohun tí
mo gbà gbọ́ tó sì dá mi lójú nípa ẹ̀sìn ló jẹ́ kí n ṣe é.’” Amélie mọ̀ pé ìgbàgbọ́ tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in nípa ẹ̀sìn rẹ̀ jẹ́ kí ìgbésí ayé rẹ̀ ní ète ó sì ń fún un ní ayọ̀ tí ò lópin gẹ́gẹ́ bíi ti ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà.Ìdí Tó Fi Yẹ Kó O Gba Ẹ̀kọ́ Ọlọ́run
Ìwé Òwe orí 6, ẹsẹ 20, fún àwọn tó fẹ́ mú inú Ọlọ́run dùn nímọ̀ràn pé: “Ìwọ ọmọ mi, pa àṣẹ baba rẹ mọ́, má sì ṣe ṣá òfin ìyá rẹ tì.” Kì í ṣe ohun tí kò yé èèyàn ni ìmọ̀ràn yìí ní ká tẹ̀ lé, kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló ń fún àwọn èwe níṣìírí pé kí wọ́n tẹ́wọ́ gba àwọn ìlànà tí Ọlọ́run fi lélẹ̀ nípa mímú kí ìgbàgbọ́ wọn túbọ̀ jinlẹ̀ sí i kí wọ́n sì dúró gbágbáágbá sọ́dọ̀ Ọlọ́run. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọ àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pé kí wọ́n “máa wádìí ohun gbogbo dájú,” kí wọ́n ṣàyẹ̀wò bóyá ẹ̀kọ́ tí wọ́n ń kọ́ wà níbàámu pẹ̀lú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ìfẹ́ Rẹ̀, kí wọ́n sì gbé ìgbésẹ̀ tó bá yẹ.—1 Tẹsalóníkà 5:21.
Tèwe tàgbà àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí iye wọn lé ní mílíọ̀nù mẹ́fà, ti ṣe irú ìpinnu yẹn yálà agboolé Kristẹni la ti bí wọn tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Nípasẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àfẹ̀sọ̀ṣe, wọ́n ti rí àwọn ìdáhùn tó ṣe é gbíyè lé sáwọn ìbéèrè wọn nípa ìdí téèyàn fi wà láyé wọ́n sì ti rí òye tó ṣe kedere nípa ohun tí Ọlọ́run fẹ́ fún ẹ̀dá èèyàn. Bí wọ́n ṣe gba ìmọ̀ yìí, wọ́n tún tẹ́wọ́ gba àwọn ẹ̀kọ́ tí Ọlọ́run ń kọ́ni wọ́n sì ń sa gbogbo ipá wọn láti ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́.
Yálà o máa ń ka ìwé ìròyìn yìí déédéé tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, o ò ṣe kúkú jẹ́ káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣàyẹ̀wò Bíbélì kó o lè rí ìlànà ẹ̀sìn tòótọ́ tó wà níbẹ̀. Lọ́nà yìí, wàá lè “tọ́ ọ wò, kí [o] sì rí i pé Jèhófà jẹ́ ẹni rere,” wàá sì tún lè gba ìmọ̀ tó ń sinni lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun nígbà téèyàn bá fi sílò.—Sáàmù 34:8; Jòhánù 17:3.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Ìdílé kan tí ìrandíran rẹ̀ mẹ́rin jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ilẹ̀ Faransé
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Rúùtù yàn láti sin Jèhófà dípò àwọn òrìṣà táwọn baba ńlá rẹ̀ sìn