Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Rántí?

Ǹjẹ́ O Rántí?

Ǹjẹ́ O Rántí?

Ǹjẹ́ o gbádùn kíka àwọn Ilé Ìṣọ́ tó jáde lẹ́nu àìpẹ́ yìí? Ó dára, wò ó bí o bá lè dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e wọ̀nyí:

Báwo la ṣe lè jàǹfààní látinú kíkẹ́kọ̀ọ́ nípa ìdílé Ṣáfánì?

Adàwékọ àti akọ̀wé Jòsáyà Ọba Júdà ni Ṣáfánì. Torí pé Ṣáfánì jẹ́ ọkùnrin olókìkí kan láàfin, èyí mú kó dúró ti Ọba bó ṣe ń ṣakitiyan láti mú ìjọsìn tòótọ́ padà bọ̀ sípò. Àwọn ọmọkùnrin Ṣáfánì méjì ló ti Jeremáyà wòlíì lẹ́yìn gbágbáágbá. Ọmọ rẹ̀ ọkùnrin mìíràn àti méjì lára àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀ ọkùnrin tún fi ipò ńlá tí wọ́n wà ṣètìlẹ́yìn fún ìjọsìn tòótọ́. Bákan náà, ó yẹ kí àwa pẹ̀lú fi ohun ìní wa àti ipò wa ṣètìlẹ́yìn fún ìjọsìn tòótọ́.—12/15, ojú ìwé 19-22.

Báwo ni Irene Hochstenbach ṣe borí àìlera ara rẹ̀ tó fi ṣeé ṣe fun láti sin Jèhófà?

Ó ya adití látìgbà tó ti wà lọ́mọ ọdún méje. Láìfi jíjẹ́ tó jẹ́ adití pè, ó kọ́ láti bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ àti pé nísinsìnyí ó ń bá ọkọ rẹ̀ (tó jẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjò) lọ káàkiri bó ṣe ń bẹ àwọn ìjọ wò lórílẹ̀ èdè Netherlands.—1/1, ojú ìwé 23-6.

Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tuntun méjì wo la mú jáde ní Àpéjọ Àgbègbè ti “Àwọn Olùfi Ìtara Pòkìkí Ìjọba Ọlọ́run?”

Káàkiri àgbáyé ni inú àwọn Kristẹni ti dùn láti gba ìwé tá a mú jáde náà, Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà, a ṣe ìwé yìí fún bíbá àwọn ẹni tuntun tó ti kẹ́kọ̀ọ́ ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun parí ṣèkẹ́kọ̀ọ́; ìwé kejì ni, Sún Mọ́ Jèhófà, tó jíròrò àwọn ànímọ́ Jèhófà àti ìbálò rẹ̀. Ìwé náà tún sọ bá a ṣe lè fara wé bó ṣe ń lo àwọn ànímọ́ rẹ̀.—1/15, ojú ìwé 23-24.

Kí ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ tó wà nínú Òwe 12:5, tó sọ pé: “Ìrònú àwọn olódodo jẹ́ ìdájọ́”?

Àwọn èèyàn rere kí ì ro èròkerò, àìṣègbè àti òdodo ló máa ń wà lọ́kàn wọn. Ìfẹ́ Ọlọ́run àti tàwọn ẹ̀dá èèyàn ẹlẹgbẹ́ wọn ló ń sún àwọn adúróṣinṣin ṣe ohun tí wọ́n ń ṣe, ìdí rèé tí wọn kì í fi í ronú ibi.—1/15, ojú ìwé 30.

Kí ló máa mú kéèyàn ní èrò tó yẹ nípa iṣẹ́ ṣíṣe?

Ohun tó ti dáa ni kéèyàn ti gba ẹ̀kọ́ bó ṣe yẹ kó tẹpá mọ́ṣẹ́ láti kékeré. Bíbélì rọ̀ wá láti fọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́, ká má ṣe ya ọ̀lẹ. (Òwe 20:4) Ó sì tún rọ àwọn Kristẹni pé kí wọ́n má ṣe iṣẹ́ àṣekúdórógbó. Ó yẹ ká mọ̀ pé iṣẹ́ ìsìn wa sí Ọlọ́run ló yẹ kó gba ipò iwájú nínú ìgbésí ayé wa. (1 Kọ́ríńtì 7:29-31) Láfikún sí i, àwọn Kristẹni tòótọ́ mọ̀ dájú ṣáká pé Ọlọ́run kì yóò kọ̀ wọ́n sílẹ̀.—2/1, ojú ìwé 4-6.

Ibo la ti kọ́kọ́ mẹ́nu kan pẹpẹ nínú Bíbélì?

Inú Jẹ́nẹ́sísì 8:20 ni, ibẹ̀ la ti tọ́ka sí pẹpẹ tí Nóà kọ́ nígbà tó jáde kúrò nínú ọkọ̀ áàkì lẹ́yìn Àkúnya Omi. Àmọ́ ṣá o, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé orí pẹ́pẹ́ ni Kéènì àti Ébẹ́lì ti rú ẹbọ táwọn náà rú. (Jẹ́nẹ́sísì 4:3, 4)—2/15, ojú ìwé 28.

Báwo ni àwọn Kristẹni kan ṣe lè lo ipò nǹkan tó yí padà lọ́nà tó dára?

Àwọn kan fara mọ́ ìyípadà tó dé ba iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wọn tó mú kí wọn túbọ̀ lo àkókò púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ tàbí kí wọ́n tiẹ̀ fiṣẹ́ sílẹ̀ fúnra wọn. Ẹrù ìdílé táwọn míì ń gbé tó ti fúyẹ́, bíi kí àwọn ọmọ wọn ti dàgbà kí wọ́n sì ti ṣègbéyàwó, ti mú kí wọ́n fi kún ẹrù iṣẹ́ wọn nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run àti àkókò tí wọn ń lò nínú rẹ̀.—3/1, ojú ìwé 19-22.

Báwo ni àpẹẹrẹ Jónà àti ti àpọ́sítélì Pétérù ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti máa fi irú ojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn ẹlòmíràn wò wọ́n?

Gbogbo wa la mọ̀ pé Jónà àti Pétérù ní kùdìẹ̀ kudiẹ nínú ọ̀nà ìgbàronú, a sì mọ bí wọ́n ti ṣe nígbà tá a dán ìgbàgbọ́ wọn àti bí wọ́n ṣe ń ṣègbọràn sí wò. Síbẹ̀síbẹ̀, Jèhófà rí i pé wọ́n ní ànímọ́ tó dára, o sì ń lò wọ́n nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Nígbà tí ẹnì kan bá ṣe ohun tó bí wa nínú tàbí tó ṣe ohun tí a ò fẹ́, a lè wo àwọn ànímọ́ rere tá a mọ̀ mọ́ ẹni yẹn látilẹ̀wá ká sì tún wo àwọn ànímọ́ rere tí Ọlọ́run rí lára rẹ̀.—3/15, ojú ìwé 16-19.

Kí ló fa ìyàtọ̀ nínú bí àwọn ìtumọ̀ Bíbélì ṣe to orí ìwé nínú Sáàmù?

Ìyàtọ̀ wà láàárín bá a ṣe to àwọn orí ìwé nínú èyí tá a fi èdè Hébérù ìjímìjí kọ àti èyí tá a túmọ̀ sí èdè Gíríìkì nínú Septuagint. Àwọn ìtumọ̀ tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe tún lè yàtọ̀ síra, àmọ́ ó sinmi lórí bóyá ìwé mímọ́ ní èdè Hébérù la gbé e kà ni tàbí ti Septuagint.—4/1, ojú ìwé 31.