Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ibo La Ti Lè Rí Ojúlówó Ìtùnú?

Ibo La Ti Lè Rí Ojúlówó Ìtùnú?

Ibo La Ti Lè Rí Ojúlówó Ìtùnú?

“Ọlọ́run àti Baba Olúwa wa Jésù Kristi . . . ń tù wá nínú nínú gbogbo ìpọ́njú wa.”—2 KỌ́RÍŃTÌ 1:3, 4.

1. Àwọn ipò wo ló lè mú káwọn èèyàn nílò ìtùnú lójú méjèèjì?

 ÀÌSÀN tí ń sọni di aláàbọ̀ ara lè mú kí ẹnì kan máa ronú pé ayé òun ti bà jẹ́. Ilẹ̀ ríri, ìjì àti ìyàn ń sọ àwọn èèyàn dẹni tí ò ní gá tí ò ní go. Ogun lè gbẹ̀mí àwọn kan nínú ìdílé, ó lè ba ilé jẹ́ tàbí kó di pé káwọn onílé ọlọ́nà fi gbogbo dúkìá wọn sílẹ̀ kí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sá kìjokìjo káàkiri fún ààbò. Ìwà ìrẹ́jẹ lè mú káwọn èèyàn máa ronú pé kò síbi táwọn ti lè rí ìrànlọ́wọ́. Àwọn èèyàn tí irú ìṣẹ̀lẹ̀ láabi báyìí bá ṣẹlẹ̀ sí nílò ìtùnú lójú méjèèjì. Àmọ́ ibo ni wọ́n ti lè rí i?

2. Èé ṣe tí kò fi sí irú ìtùnú mìíràn tá a lè fi wé èyí tí Jèhófà ń pèsè?

2 Àwọn kan tó lójú àánú àtàwọn ètò àjọ kan máa ń gbìyànjú láti tu àwọn èèyàn nínú. Àwọn èèyàn sì máa ń mọrírì àwọn ọ̀rọ̀ atunilára lọ́pọ̀lọpọ̀. Pípèsè àwọn ohun àfiṣèrànwọ́ bí oúnjẹ, ilé àti aṣọ lè mú kéèyàn ní àwọn ohun tó nílò fúngbà díẹ̀. Àmọ́ kìkì Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́, ló lè ṣàtúnṣe ọ̀ràn náà kó sì pèsè ìrànlọ́wọ́ tá a nílò tí irú àwọn àjálù ibi bẹ́ẹ̀ ò fi ní ṣẹlẹ̀ mọ́ láé. Bíbélì sọ nípa rẹ̀ pé: “Ìbùkún ni fún Ọlọ́run àti Baba Olúwa wa Jésù Kristi, Baba àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ àti Ọlọ́run ìtùnú gbogbo, ẹni tí ń tù wá nínú nínú gbogbo ìpọ́njú wa, kí àwa lè tu àwọn tí ó wà nínú ìpọ́njú èyíkéyìí nínú nípasẹ̀ ìtùnú tí Ọlọ́run fi ń tu àwa tìkára wa nínú.” (2 Kọ́ríńtì 1:3, 4) Báwo ni Jèhófà ṣe ń tù wá nínú?

Mímú Ohun Tó Ń Fa Àwọn Ìṣòro Náà Kúrò

3. Báwo ni ìtùnú tí Ọlọ́run ń fúnni ṣe máa mú ohun tó ń fa àwọn ìṣòro ẹ̀dá èèyàn kúrò?

3 Gbogbo ẹ̀dá èèyàn pátá ló ti jogún àìpé tó jẹ́ àbájáde ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù, tó mú kí onírúurú ìṣòro máa gbilẹ̀, tó sì ń yọrí sí ikú ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀. (Róòmù 5:12) Ohun tó tún mú kí ọ̀rọ̀ náà túbọ̀ burú sí i ni bó ṣe jẹ́ pé Sátánì Èṣù ni “olùṣàkóso ayé yìí.” (Jòhánù 12:31; 1 Jòhánù 5:19) Jèhófà ò kàn sọ pé inú òun ò dùn sí ipò àìláyọ̀ tó ń kojú ẹ̀dá èèyàn, ńṣe ló dìídì rán Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo náà wá sáyé láti rà wá padà, Ó sì tún sọ fún wa pé a lè bọ́ lọ́wọ́ àtúbọ̀tán ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù tá a bá lo ìgbàgbọ́ nínú Ọmọ Òun. (Jòhánù 3:16; 1 Jòhánù 4:10) Ọlọ́run tún sọ tẹ́lẹ̀ pé Jésù Kristi, tá a ti gbé gbogbo àṣẹ láyé lọ́run lé lọ́wọ́, máa pa Sátánì àti gbogbo ètò àwọn nǹkan búburú rẹ̀ run ráúráú.—Mátíù 28:18; 1 Jòhánù 3:8; Ìṣípayá 6:2; 20:10.

4. (a) Ìpèsè wo ni Jèhófà ti ṣe láti mú ká túbọ̀ ní ìgbọ́kànlé nínú ìlérí tó ṣe pé òun á fún wa ní ìtùnú? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe ń jẹ́ ká fòye mọ ìgbà tí ìtùnú náà máa dé?

4 Kí ìgbẹ́kẹ̀lé tá a ní nínú àwọn ìlérí Ọlọ́run bàa túbọ̀ lágbára sí i, ó ti ṣàkọsílẹ̀ àwọn ẹ̀rí tó pọ̀ jaburata tó fi hàn pé kò sí ni, ohunkóhun tó bá sàsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ máa nímùúṣẹ. (Jóṣúà 23:14) Lára ohun tó kọ sínú Bíbélì ni àkọsílẹ̀ nípa ohun tó ti ṣe láti gba àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀ lákòókò ìṣòro tó kọjá agbára ẹ̀dá èèyàn. (Ẹ́kísódù 14:4-31; 2 Àwọn Ọba 18:13–19:37) Bákan náà, nípasẹ̀ Jésù Kristi, Jèhófà ti fi hàn pé lára ohun tó wà lọ́kàn òun ni ṣíṣe ìwòsàn “gbogbo onírúurú àìlera ara” tó ń bá àwọn èèyàn jà, títí kan jíjí àwọn òkú dìde pàápàá. (Mátíù 9:35; 11:3-6) Ìgbà wo wá ni gbogbo èyí á ṣẹlẹ̀? Nínú ìdáhùn tí Bíbélì fúnni, ó ṣàkọsílẹ̀ nípa àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ètò ògbólógbòó yìí, èyí tó máa ṣáájú ọ̀run tuntun àti ayé tuntun ti Ọlọ́run. Bí Jésù ṣe ṣàpèjúwe àkókò náà bá àkókò tá a wà yìí mu rẹ́gí.—Mátíù 24:3-14; 2 Tímótì 3:1-5.

Ìtùnú Fáwọn Tó Wà Nínú Ìṣòro

5. Nígbà tí Jèhófà ń fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì ní ìtùnú, kí lohun tó rán wọn létí rẹ̀?

5 Ọ̀nà tí Jèhófà gbà bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́ lò jẹ́ ká mọ bó ṣe fún wọn ní ìtùnú nígbà tí wọ́n wà nínú wàhálà. Ó rán wọn létí irú Ọlọ́run tóun jẹ́. Èyí túbọ̀ fún ìgbọ́kànlé wọn nínú àwọn ìlérí rẹ̀ lókun sí i. Jèhófà mú káwọn wòlíì rẹ̀ ṣe ìfiwéra tó jinlẹ̀ láàárín òun tóun jẹ́ Ọlọ́run tòótọ́ tóun sì wà láàyè àtàwọn òrìṣà tí wọn ò lè ran ara wọn lọ́wọ́ áńbọ̀sìbọ́sí àwọn tó ń jọ́sìn wọn. (Aísáyà 41:10; 46:1; Jeremáyà 10:2-15) Nígbà tí Jèhófà sọ fún Aísáyà pé, “Ẹ tu àwọn ènìyàn mi nínú, ẹ tù wọ́n nínú,” ó mú kí wòlíì rẹ̀ lo àwọn àkàwé àtàwọn àpèjúwe iṣẹ́ ìṣẹ̀dá Rẹ̀ kó bàa lè fi bí Jèhófà ṣe tóbi tó gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà hàn.—Aísáyà 40:1-31.

6. Kí làwọn nǹkan tí Jèhófà máa ń sọ nígbà mìíràn nípa àkókò pàtó tí ìdáǹdè máa wáyé?

6 Láwọn àkókò mìíràn, ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń fún àwọn èèyàn rẹ̀ ní ìtùnú jẹ́ nípa sísọ àkókò kan pàtó tóun á gbà wọ́n sílẹ̀, ì báà jẹ́ pé àkókò náà ti sún mọ́lé tàbí pé ó ṣì jìnnà. Nígbà tí ìdáǹdè kúrò ní Íjíbítì kù fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́, ó sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì tá a ni lára pé: “Ìyọnu àjàkálẹ̀ kan sí i ni èmi yóò mú wá sórí Fáráò àti Íjíbítì. Lẹ́yìn ìyẹn, òun yóò rán yín lọ kúrò níhìn-ín.” (Ẹ́kísódù 11:1) Nígbà táwọn orílẹ̀-èdè mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ gbìmọ̀ pọ̀ tí wọ́n kógun ja Júdà nígbà ayé Jèhóṣáfátì Ọba, Jèhófà sọ fáwọn èèyàn rẹ̀ pé òun á gba ìjà wọn jà “lọ́la.” (2 Kíróníkà 20:1-4, 14-17) Àmọ́ ní ti ìdáǹdè wọn kúrò ní Bábílónì, Aísáyà ti ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ ní nǹkan tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó igba ọdún ṣáájú, ó sì tún tipasẹ̀ Jeremáyà ṣe àwọn àlàyé síwájú sí i ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún kí ìdáǹdè náà tó wáyé. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyẹn fún àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run níṣìírí gan-an nígbà tí àkókò ìdáǹdè wọn sún mọ́ tòsí!—Aísáyà 44:26–45:3; Jeremáyà 25:11-14.

7. Kí lohun náà tó sábàá máa ń wà nínú ìlérí ìdáǹdè, báwo sì lèyí ṣe nípa lórí àwọn olódodo èèyàn ní Ísírẹ́lì?

7 Ó yẹ fún àfiyèsí pé àwọn ìlérí tó ń fún àwọn èèyàn Ọlọ́run ní ìtùnú sábàá máa ń ní àwọn ìsọfúnni nípa Mèsáyà náà nínú. (Aísáyà 53:1-12) Láti ìran kan sí òmíràn làwọn ìsọfúnni yìí ti máa ń fún àwọn olóòótọ́ ní ìrètí lójú àdánwò rẹpẹtẹ tí wọ́n ń kojú. A kà á nínú Lúùkù 2:25, pé: “Sì wò ó! ọkùnrin kan wà ní Jerúsálẹ́mù tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Síméónì, ọkùnrin yìí sì jẹ́ olódodo àti onífọkànsìn, tí ń dúró de ìtùnú Ísírẹ́lì [ìyẹn dídé Mèsáyà náà], ẹ̀mí mímọ́ sì wà lára rẹ̀.” Síméónì mọ̀ nípa ìrètí Mèsáyà náà tó wà nínú Ìwé Mímọ́, ríretí tó sì ń retí ìmúṣẹ náà nípa lórí ìgbésí ayé rẹ̀. Kò kúkú mọ bí gbogbo rẹ̀ a ṣe nímùúṣẹ látòkèdélẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni kò sí láyé mọ́ nígbà tí ìgbàlà tá a sàsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ wá nímùúṣẹ, àmọ́ inú rẹ̀ dùn nígbà tó rí Ẹni náà tó máa jẹ́ “ohun àmúlò [Ọlọ́run] fún gbígbanilà.”—Lúùkù 2:30.

Ìtùnú Nípasẹ̀ Kristi

8. Báwo ni ìrànlọ́wọ́ tí Jésù ṣe fáwọn èèyàn ṣe rí tá a bá fi wéra pẹ̀lú ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn rò pé àwọn nílò?

8 Kì í ṣe gbogbo ìgbà ni Jésù Kristi máa ń pèsè ìrànlọ́wọ́ táwọn èèyàn rò pé àwọn nílò nígbà tó ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. Àwọn kan ń wọ̀nà fún Mèsáyà tó máa fún wọn lómìnira kúrò lábẹ́ àjàgà Róòmù tó jẹ gàba lé wọn lórí. Àmọ́ Jésù kò sọ pé òun fẹ́ yí ètò tó wà nílẹ̀ padà; ohun tó sọ fáwọn èèyàn náà ni pé kí wọ́n “san àwọn ohun ti Késárì padà fún Késárì.” (Mátíù 22:21) Ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn láti ṣe ju pé kó kàn wulẹ̀ fún àwọn èèyàn lómìnira kúrò lábẹ́ àwọn ìjọba olóṣèlú kan lọ. Àwọn èèyàn náà fẹ́ fi Jésù jọba, àmọ́ ó sọ fún wọn pé òun á “fi ọkàn [òun] fúnni gẹ́gẹ́ bí ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.” (Mátíù 20:28; Jòhánù 6:15) Kò tíì tó àsìkò fún un láti gorí ìtẹ́ bí ọba, àti pé Jèhófà ló máa gbé àṣẹ tó fi máa ṣàkóso lé e lọ́wọ́ kì í ṣe àwọn èèyàn tí nǹkan kì í tẹ́ lọ́rùn.

9. (a) Ìhìn ìtùnú wo ni Jésù polongo rẹ̀? (b) Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé ìhìn náà bá àwọn ipò táwọn èèyàn ń dojú kọ mu? (d) Ìpìlẹ̀ wo ni iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù fi lélẹ̀?

9 Ìtùnú tí Jésù ń fúnni wà nínú “ìhìn rere ìjọba Ọlọ́run.” Gbogbo ibi tí Jésù dé ló ti polongo ìhìn yìí. (Lúùkù 4:43) Ó tẹnu mọ́ bí ìhìn náà ṣe ṣe pàtàkì tó fún yíyanjú ìṣòro táwọn èèyàn ń dojú kọ lójoojúmọ́ nípa ṣíṣe àṣefihàn nǹkan tóun á ṣe fún ẹ̀dá èèyàn gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà Tó Ń Ṣàkóso. Káwọn èèyàn tójú ń pọ́n bàa lè rí i pé ó dára láti wà láàyè, ó la ojú afọ́jú ó sì mú káwọn odi bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ (Mátíù 12:22; Máàkù 10:51, 52), ó wo arọ sàn (Máàkù 2:3-12), ó wo àwọn àìsàn tí ń ríni lára sàn lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bíi tirẹ̀ (Lúùkù 5:12, 13), ó sì tún wo àwọn àrùn búburú mìíràn tó ń ṣe wọ́n sàn. (Máàkù 5:25-29) Ó fún àwọn ìdílé tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ ní ìtura ńlá nípa jíjí àwọn ọmọ wọn tó kú dìde. (Lúùkù 7:11-15; 8:49-56) Ó jẹ́ ká mọ̀ pé òun lágbára láti dá ìjì líle dúró àti pé kò ṣòro fóun láti bọ́ ogunlọ́gọ̀ èèyàn ní àbọ́yó. (Máàkù 4:37-41; 8:2-9) Kò tán síbẹ̀ o, Jésù tún kọ́ wọn láwọn ìlànà tí wọ́n lè lò nínú ìgbésí ayé láti yanjú àwọn ìṣòro tó bá jẹ yọ tó sì tún máa jẹ́ kí wọ́n nírètí tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ nípa ìṣàkóso òdodo lábẹ́ Mèsáyà náà. Ìdí rèé tó fi jẹ́ pé nígbà tí Jésù ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, bó ṣe ń fún àwọn tó gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí wọ́n sì nígbàgbọ́ níṣìírí náà ló tún ń fi ọ̀nà tá a máa gbà fún àwọn èèyàn níṣìírí ní nǹkan bí ẹgbàá ọdún sí àkókò náà lélẹ̀.

10. Kí ni ẹbọ Jésù mú kó ṣeé ṣe?

10 Ẹ̀yìn ìgbà tó ti lé ní ọgọ́ta ọdún tí Jésù ti fi ìgbésí ayé rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá èèyàn rúbọ tá a sì ti jí i dìde sí òkè ọ̀run ni àpọ́sítélì Jòhánù wá kọ̀wé lábẹ́ ìmísí pé: “Ẹ̀yin ọmọ mi kéékèèké, mo ń kọ̀wé nǹkan wọ̀nyí sí yín kí ẹ má bàa dá ẹ̀ṣẹ̀. Síbẹ̀síbẹ̀, bí ẹnikẹ́ni bá dá ẹ̀ṣẹ̀, àwa ní olùrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ Baba, Jésù Kristi, ẹni tí í ṣe olódodo. Òun sì ni ẹbọ ìpẹ̀tù fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, síbẹ̀ kì í ṣe fún tiwa nìkan ṣùgbọ́n fún ti gbogbo ayé pẹ̀lú.” (1 Jòhánù 2:1, 2) Ìtùnú ńláǹlà làwọn àǹfààní ẹbọ ẹ̀dá ènìyàn pípé Jésù jẹ́ fún wa. A mọ̀ pé a lè rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà, a lè ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́, àjọṣe tó gbámúṣé pẹ̀lú Ọlọ́run àti ìrètí wíwà láàyè títí láé.—Jòhánù 14:6; Róòmù 6:23; Hébérù 9:24-28; 1 Pétérù 3:21.

Olùtùnú Ni Ẹ̀mí Mímọ́

11. Kí ni ìpèsè mìíràn fún ìtùnú tí Jésù tún ṣèlérí kó tó kú?

11 Nígbà tí Jésù wà pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní alẹ́ ọjọ́ tó lò gbẹ̀yìn kó tó kú ikú ìrúbọ tó kú, ó tún sọ̀rọ̀ nípa ètò mìíràn tí Baba rẹ̀ ọ̀run ti ṣe láti fún wọn ní ìtùnú. Jésù sọ pé: “Èmi yóò sì béèrè lọ́wọ́ Baba, yóò sì fún yín ní olùrànlọ́wọ́ [olùtùnú; pa·raʹkle·tos, lédè Gíríìkì] mìíràn láti wà pẹ̀lú yín títí láé, ẹ̀mí òtítọ́ náà.” Jésù mú un dá wọn lójú pé: “Olùrànlọ́wọ́ náà, ẹ̀mí mímọ́, . . . yóò kọ́ yín ní ohun gbogbo, tí yóò sì mú gbogbo ohun tí mo ti sọ fún yín padà wá sí ìrántí yín.” (Jòhánù 14:16, 17, 26) Báwo wá ni ẹ̀mí mímọ́ ṣe fún wọn ní ìtùnú ní ti gidi?

12. Báwo ni ipa tí ẹ̀mí mímọ́ ń kó láti rán àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù létí ohun tí wọ́n ti kọ́, ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́ láti fún ọ̀pọ̀ èèyàn ní ìtùnú?

12 Àwọn àpọ́sítélì ti kẹ́kọ̀ọ́ ní mẹ́sàn-án mẹ́wàá lọ́dọ̀ Jésù. Ó dájú pé wọn ò lè gbàgbé ìrírí náà, àmọ́ ǹjẹ́ wọ́n á rántí gbogbo ọ̀rọ̀ tó sọ? Ǹjẹ́ ipò àìpé wọn ò ní jẹ́ kí wọ́n gbàgbé àwọn ìtọ́ni ṣíṣeyebíye tó fún wọn? Jésù mú un dá wọn lójú pé ẹ̀mí mímọ́ á ‘rán wọn létí gbogbo nǹkan tóun ti sọ fún wọn.’ Ìdí rèé tí Mátíù fi lè kọ Ìhìn Rere àkọ́kọ́ ní nǹkan bí ọdún mẹ́jọ lẹ́yìn tí Jésù kú, nínú èyí tó ti ṣàkọsílẹ̀ Ìwàásù amọ́kànyọ̀ tí Jésù ṣe Lórí Òkè, ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àpèjúwe tó ṣe nípa Ìjọba náà, àti kúlẹ̀kúlẹ̀ ìjíròrò tó ṣe nípa àmì wíwàníhìn-ín rẹ̀. Ní nǹkan bí àádọ́ta ọdún lẹ́yìn àkókò yẹn, àpọ́sítélì Jòhánù náà kọ àkọsílẹ̀ kan tó ṣe é gbára lé nínú èyí tó ti sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa àwọn ọjọ́ mélòó kan tí Jésù lò gbẹ̀yìn lórí ilẹ̀ ayé. Ẹ wo bí àwọn àkọsílẹ̀ tí Ọlọ́run mí sí wọ̀nyí ṣe jẹ́ afúnniníṣìírí títí di àkókò tá a wà yìí!

13. Báwo ni ẹ̀mí mímọ́ ṣe jẹ́ olùkọ́ fún àwọn Kristẹni ìjímìjí?

13 Yàtọ̀ sí pé ẹ̀mí mímọ́ jẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù rántí àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó tún kọ́ wọn ó sì tún jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ òye ète Ọlọ́run. Nígbà tí Jésù ṣì wà pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó sọ àwọn nǹkan kan fún wọn àmọ́ tí ò yé wọn dáadáa nígbà náà. Àmọ́ nígbà tó ṣe, ẹ̀mí mímọ́ mú kí Jòhánù, Pétérù, Jákọ́bù, Júúdà àti Pọ́ọ̀lù kọ àwọn àlàyé tó jinlẹ̀ nípa àwọn ète Ọlọ́run tí òye rẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ ń yé wọn. Ìdí rèé tí ẹ̀mí mímọ́ fi jẹ́ olùkọ́ nípa fífún wọn ní ìdánilójú pé Ọlọ́run ló ń darí wọn.

14. Àwọn ọ̀nà wo ni ẹ̀mí mímọ́ gbà ran àwọn èèyàn Jèhófà lọ́wọ́?

14 Ẹ̀bùn ìyanu ti ẹ̀mí mímọ́ tún fẹ̀rí hàn gbangba pé ìjọ Kristẹni ni Ọlọ́run ń fi inú rere hàn sí báyìí, pé kò fi hàn sí Ísírẹ́lì àbínibí mọ́. (Hébérù 2:4) Iṣẹ́ táwọn èso ẹ̀mí náà sì ń ṣe nínú ìgbésí ayé kálukú tún jẹ́ kókó pàtàkì tó ń jẹ́ ká mọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tòótọ́. (Jòhánù 13:35; Gálátíà 5:22-24) Ẹ̀mí yìí tún ń fún àwọn ọmọ ìjọ náà lókun láti jẹ́ ẹlẹ́rìí onígboyà tí kì í bẹ̀rù.—Ìṣe 4:31.

Ìrànlọ́wọ́ Lákòókò Ìṣòro Líle Koko

15. (a) Àwọn ìṣòro wo làwọn Kristẹni ayé àtijọ́ àti tòde òní ti dojú kọ? (b) Kí nìdí táwọn tó ń fúnni níṣìírí náà fi lè nílò ìṣírí nígbà mìíràn?

15 Gbogbo àwọn tó ń sin Jèhófà tọkàntọkàn tí wọ́n sì jẹ́ adúróṣinṣin sí i ló máa ń kojú inúnibíni lónírúurú ọ̀nà. (2 Tímótì 3:12) Àmọ́ ṣá, ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni ló ti kojú ìṣòro tó le koko. Lóde òní, ọ̀pọ̀ wọn làwọn agánnigàn ẹ̀dá ti dún mọ̀huru mọ̀huru mọ́ tí wọ́n sì sọ wọ́n sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́, wọ́n tún fi wọ́n sọ́gbà ẹ̀wọ̀n àtàwọn àgọ́ tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ àṣekúdórógbó, tí wọ́n sì ń hàn wọ́n léèmọ̀ níbẹ̀. Àwọn ìjọba ti fúnra wọn ṣe inúnibíni sáwọn èèyàn yìí tàbí kí wọ́n fọwọ́ lẹ́rán nígbà táwọn ẹhànnà ẹ̀dá ń hùwà ìkà sí wọn. Kò tán síbẹ̀ o, àwọn Kristẹni ti kojú ipò àìlera tó burú jáì tàbí ìṣòro ìdílé tó le koko. Kristẹni kan tó dàgbà dénú náà tún lè ní ìṣòro tiẹ̀ pẹ̀lú bó ṣe ń ran ọ̀pọ̀ àwọn onígbàgbọ́ bíi tiẹ̀ lọ́wọ́. Bí ọ̀ràn bá dà báyìí, ẹni tó ń fúnni níṣìírí náà lè nílò ìṣírí.

16. Báwo ni Dáfídì ṣe rí ìrànlọ́wọ́ gbà lákòókò tó wà nínú ìṣòro líle koko?

16 Nígbà tí Sọ́ọ̀lù Ọba ń dọdẹ Dáfídì kiri láti gbẹ̀mí rẹ̀, ńṣe ni Dáfídì yíjú sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí Olùrànlọ́wọ́ rẹ̀, ó bẹ̀bẹ̀ pé: “Ọlọ́run, gbọ́ àdúrà mi. . . . Òjìji ìyẹ́ apá rẹ . . . ni mo sá di.” (Sáàmù 54:2, 4; 57:1) Ǹjẹ́ Dáfídì rí ìrànlọ́wọ́ gbà? Ó kúkú rí i gbà. Láàárín àkókò náà, Jèhófà lo wòlíì Gáàdì àti Ábíátárì àlùfáà láti fún Dáfídì ní ìtọ́sọ́nà, Ó sì tún lo Jónátánì ọmọ Sọ́ọ̀lù láti fún un lókun. (1 Sámúẹ́lì 22:1, 5; 23:9-13, 16-18) Jèhófà tún jẹ́ káwọn Filísínì kógun ja ilẹ̀ náà, èyí sì mú kí Sọ́ọ̀lù dẹ̀yìn lẹ́yìn rẹ̀.—1 Sámúẹ́lì 23:27, 28.

17. Ibo ni Jésù wá ìrànlọ́wọ́ gbà nígbà tí wàhálà dé bá a?

17 Jésù Kristi alára ní ìdààmú ọkàn bí òpin ìwàláàyè rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé ṣe ń sún mọ́. Ó mọ bí irú ìwà èyíkéyìí tóun bá hù á ṣe nípa lórí orúkọ Baba òun lọ́run àtohun tó lè túmọ̀ sí fún ọjọ́ ọ̀la gbogbo ẹ̀dá èèyàn. Ó gbàdúrà taratara, àní débi tí ‘ìrora fi ba á.’ Ọlọ́run rí i dájú pé Jésù rí ìtìlẹ́yìn tó nílò lákòókò líle koko yìí gbà.—Lúùkù 22:41-44.

18. Ìtùnú wo ni Ọlọ́run fún àwọn Kristẹni ìjímìjí tí wọ́n kojú inúnibíni líle koko?

18 Inúnibíni tó dé bá àwọn Kristẹni lẹ́yìn tí wọ́n dá ìjọ Kristẹni ọ̀rúndún kìíní sílẹ̀ le débi pé gbogbo wọn pátá ló sá kúrò ní Jerúsálẹ́mù àyàfi àwọn àpọ́sítélì nìkan tó kù síbẹ̀. Tọkùnrin tobìnrin ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í wọ́ tuuru kúrò nínú ilé wọn. Irú ìtùnú wo ni Ọlọ́run fún wọn? Ó mú un dá wọn lójú nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé wọ́n ní “ohun ìní dídára jù àti èyí tí ó wà lọ títí,” ìyẹn ogún tí mìmì kan ò lè mì tí wọ́n máa jẹ lókè ọ̀run pẹ̀lú Kristi. (Hébérù 10:34; Éfésù 1:18-20) Bí wọ́n ṣe ń bá iṣẹ́ ìwàásù wọn lọ, wọ́n rí ẹ̀rí pé ẹ̀mí Ọlọ́run wà pẹ̀lú wọn, àwọn ohun tójú wọ́n rí sì túbọ̀ fún wọn láyọ̀.—Mátíù 5:11, 12; Ìṣe 8:1-40.

19. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Pọ́ọ̀lù kojú inúnibíni tó gbóná janjan, báwo ni ìtùnú tí Ọlọ́run fún un ṣe rí lára rẹ̀?

19 Nígbà tó yá, Sọ́ọ̀lù (Pọ́ọ̀lù), tóun fúnra rẹ̀ jẹ́ ẹni tó ń ṣe inúnibíni rírorò tẹ́lẹ̀, wá dẹni táwọn èèyàn ń gbógun tì nítorí pé ó ti di Kristẹni. Oníṣẹ́ oṣó kan wà ní erékùṣù Kípírọ́sì, tó ṣèdènà fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ Pọ́ọ̀lù nípa ṣíṣe gbájúẹ̀ àti èrú. Wọ́n sọ Pọ́ọ̀lù lókùúta ní Gálátíà títí tí wọ́n fi rò pé ó ti kú kí wọ́n to fi í sílẹ̀. (Ìṣe 13:8-10; 14:19) Wọ́n fi ọ̀pá nà án bí ẹní máa pa á ní Makedóníà. (Ìṣe 16:22, 23) Lẹ́yìn wàhálà kan táwọn jàǹdùkú fà ní Éfésù, ó kọ̀wé pé: “A wà nínú ìdààmú dé góńgó tí ó ré kọjá okun wa, tó bẹ́ẹ̀ tí a kò ní ìdánilójú rárá nípa ìwàláàyè wa pàápàá. Ní ti tòótọ́, a nímọ̀lára nínú ara wa pé a ti gba ìdájọ́ ikú.” (2 Kọ́ríńtì 1:8, 9) Àmọ́ inú lẹ́tà kan náà yìí ni Pọ́ọ̀lù ti kọ àwọn ọ̀rọ̀ ìtùnú tá a fà yọ nínú ìpínrọ̀ kejì àpilẹ̀kọ yìí.—2 Kọ́ríńtì 1:3, 4.

20. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?

20 Báwo lo ṣe lè lọ́wọ́ nínú fífún àwọn èèyàn nírú ìtùnú yìí? Ọ̀pọ̀ ló wà lákòókò yìí tí wọ́n nílò rẹ̀ nígbà tí ìbànújẹ́ bá dorí wọn kodò, bóyá nítorí àjálù ibi kan tó ṣẹlẹ̀ sí ọ̀pọ̀ èèyàn ni o tàbí nítorí ìpọ́njú tó bá àwọn fúnra wọn. A óò jíròrò bá a ṣe lè fún àwọn èèyàn ní ìtùnú lọ́nà méjèèjì nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.

Ǹjẹ́ O Rántí?

• Kí nìdí tí ò fi sí ìtùnú mìíràn tá a lè fi wé èyí tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run?

• Ìtùnú wo la fún wa nípasẹ̀ Kristi?

• Báwo ni ẹ̀mí mímọ́ ṣe jẹ́ olùtùnú?

• Fúnni làwọn àpẹẹrẹ bí Ọlọ́run ṣe tu àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ nínú nígbà tí wọ́n kojú ìṣòro líle koko.

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà máa ń fúnni ní ìtùnú nípa dídá àwọn èèyàn rẹ̀ nídè

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Jésù pèsè ìtùnú fáwọn èèyàn nípa kíkọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́, nípa mímú wọn lára dá àti nípa jíjí òkú dìde

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Jésù rí ìrànlọ́wọ́ gbà látòkè ọ̀run