Ẹ̀kọ́ Táwọn Ẹyẹ Lè Kọ́ Wa
Ẹ̀kọ́ Táwọn Ẹyẹ Lè Kọ́ Wa
“ẸFI tọkàntara ṣàkíyèsí àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run, nítorí wọn kì í fún irúgbìn tàbí ká irúgbìn tàbí kó jọ sínú ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́; síbẹ̀ Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run ń bọ́ wọn. Ẹ kò ha níye lórí jù wọ́n lọ bí?” (Mátíù 6:26) Inú ìwàásù olókìkí kan tí Jésù Kristi ṣe lórí òkè kan nítòsí Òkun Gálílì ló ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nìkan kọ́ ló gbọ́ ìwàásù náà o. Ogunlọ́gọ̀ àwọn èèyàn tí wọ́n lè di ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ náà ló wà níbẹ̀. Ọ̀pọ̀ lára wọn ni ò rí já jẹ tí wọ́n gbé àwọn èèyàn tó ń ṣàìsàn wá sọ́dọ̀ Jésù láti gba ìwòsàn.—Mátíù 4:23–5:2; Lúùkù 6:17-20.
Lẹ́yìn tí Jésù ti mú àwọn tó ń ṣàìsàn lára dá, ó wá bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ nípa nǹkan tẹ̀mí èyí tó ṣe pàtàkì jù lọ. Lára àwọn ẹ̀kọ́ tó kọ́ wọn ni èyí tá a mẹ́nu bà lókè yìí.
Ọjọ́ ti pẹ́ táwọn ẹyẹ ojú ọ̀run ti ń bẹ láyé. Kòkòrò làwọn kan lára wọn ń jẹ, àwọn mìíràn sì ń jẹ èso àti irúgbìn. Bí Ọlọ́run bá lè pèsè oúnjẹ púpọ̀ rẹpẹtẹ bẹ́ẹ̀ fáwọn ẹyẹ, ó dájú pé ó lágbára láti pèsè oúnjẹ òòjọ́ fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ẹ̀dá èèyàn. Ó lè ṣe èyí nípa ríràn wọ́n lọ́wọ́ láti ríṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ tó máa mówó wọlé tí wọ́n á lè fi ra oúnjẹ. Tàbí kó fìbùkún sí iṣẹ́ ọ̀gbìn tí wọ́n ń ṣe. Lákòókò tí nǹkan ò bá rọgbọ, Ọlọ́run lè mú káwọn aládùúgbò rere àtàwọn ọ̀rẹ́ ṣàjọpín oúnjẹ èyíkéyìí tí wọ́n bá ní pẹ̀lú àwọn tó bá ṣaláìní.
Ọ̀pọ̀ nǹkan la tún lè rí kọ́ tá a bá fara balẹ̀ kíyè sí ìgbésí ayé ẹyẹ. Ọlọ́run ṣẹ̀dá wọn pẹ̀lú ànímọ́ àgbàyanu kan tó máa ń mú wọn kọ́ ìtẹ́ níbi tí wọ́n á ti lè tọ́jú àwọn ọmọ wọn. Wo oríṣi ìtẹ́ méjì tó wà níhìn-ín. Ìtẹ́ ẹyẹ alápàńdẹ̀dẹ̀ ló wà lápá òsì yìí. Orí òkúta tàbí ara ògiri ilé ló máa ń kọ́ ìtẹ́ rẹ̀ sí. Òkúta tó yọrí síta ni wọ́n máa fi ń ṣe òrùlé ìtẹ́ wọn, tàbí ìgbátí òrùlé gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú àwòrán yìí. Àwọn ègé amọ̀ kéékèèké ni wọ́n á jàn pa pọ̀ tí wọ́n á fi tẹ́ ìsàlẹ̀ rẹ̀ tá á fi jinnú bí ife. Akọ àti abo wọn ló jọ máa ń ṣiṣẹ́ àṣekára láti ṣa èbúbù amọ̀ jọ ó sì lè gbà wọ́n ní àkókò tó lé ní oṣù kan láti kọ́ ìtẹ́ náà parí. Ẹ̀yìn èyí ni wọ́n á wá fi koríko àti ìyẹ́ tẹ́ inú rẹ̀. Àwọn méjèèjì ló jọ máa ń fún àwọn ọmọ wọn lóúnjẹ. Ìtẹ́ ẹyẹ ẹ̀gà lèyí tó wà nísàlẹ̀ yìí. Koríko tàbí àwọn ewéko mìíràn ni ẹyẹ ilẹ̀ Áfíríkà tó máa ń ṣiṣẹ́ kára yìí máa ń fi kọ́ ìtẹ́ rẹ̀. Ó lè kọ́ ìtẹ́ kan parí lójúmọ́, ó sì lè kọ́ iye tó lé ní ọgbọ̀n ní sáà kan!
Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́? Ẹ̀kọ́ ibẹ̀ ni pé bí Ọlọ́run bá fún àwọn ẹyẹ ní irú ọgbọ́n báyìí àtàwọn ohun èlò tó pọ̀ rẹpẹtẹ bẹ́ẹ̀ láti kọ́ ìtẹ́ wọn, ó dájú pé ó lè ran àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ láti rí ibùgbé tí wọ́n nílò. Àmọ́ ṣá, Jésù jẹ́ ká mọ̀ pé ohun pàtàkì kan wà tá a gbọ́dọ̀ ṣe tá a bá fẹ́ kí Jèhófà Ọlọ́run ràn wá lọ́wọ́ láti ní àwọn ohun ìní ti ara tó ṣe kókó. Jésù ṣèlérí pé: “Ẹ máa bá a nìṣó, nígbà náà, ní wíwá ìjọba náà àti òdodo rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́, gbogbo nǹkan mìíràn wọ̀nyí ni a ó sì fi kún un fún yín.” (Mátíù 6:33) O lè bẹ̀rẹ̀ sí béèrè pé, ‘Kí ni wíwá Ìjọba Ọlọ́run lákọ̀ọ́kọ́ ní nínú?’ Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n ń pín ìwé ìròyìn yìí, á dùn láti dáhùn ìbéèrè yẹn.