Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Kí nìdí tá a fi pe Sátánì ní “ẹni tí ó ní ọ̀nà àtimú ikú wá” nínú ìwé Hébérù 2:14?
Ní ṣókí, ohun tí Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn ni pé Sátánì lè fúnra rẹ̀ pa èèyàn tàbí kó lo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Abájọ tí Jésù fi pe Sátánì ní “apànìyàn . . . nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀.”—Jòhánù 8:44.
Èèyàn lè ṣi ìwé Hébérù 2:14 lóye nítorí ọ̀nà táwọn ìtumọ̀ Bíbélì kan gbà sọ ọ́ pé Sátánì ní “agbára ikú” tàbí “agbára lórí ikú.” (King James Version; Revised Standard; New International Version; Jerusalem Bible) Irú ìtumọ̀ yẹn lè jẹ́ kó dà bíi pé Sátánì ní agbára tí kò láàlà láti pa ẹnikẹ́ni tó bá wù ú. Àmọ́, ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Tó bá jẹ́ pé bẹ́ẹ̀ ni, ó dájú pé ì bá ti pa gbogbo àwọn olùjọsìn Jèhófà tán kúrò lórí ilẹ̀ ayé tipẹ́tipẹ́.—Jẹ́nẹ́sísì 3:15.
Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a túmọ̀ sí “agbára lórí ikú” nínú àwọn ìtumọ̀ kan àti “ẹni tí ó ní ọ̀nà àtimú ikú wá” nínú Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ni “kraʹtos tou tha·naʹtou.” Tou tha·naʹtou jẹ́ gbólóhùn kan tó túmọ̀ sí “ikú.” Ohun tí Kraʹtos ní tiẹ̀ túmọ̀ sí ni “ipá, okun, agbára.” Gẹ́gẹ́ bí ìwé atúmọ̀ èdè náà, Theological Dictionary of the New Testament, ṣe sọ ọ́, ó ń tọ́ka sí “níní ipá tàbí níní okun, kì í ṣe lílò ó.” Nítorí náà, ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ nínú Hébérù 2:14 kò túmọ̀ sí pé Sátánì ní agbára tí kò láàlà lórí ikú. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló ń sọ nípa bí agbára Sátánì ṣe tó tàbí ibi tí agbára tó ní láti fa ikú lè dé.
Báwo ni Sátánì ṣe ń lo “ọ̀nà àtimú ikú wá” náà? Nínú ìwé Jóòbù, a kà nípa ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó lè dà bí èyí tó jẹ́ àrà ọ̀tọ̀. Ìtàn náà sọ pé Sátánì lo ìjì láti ‘fa ikú’ àwọn ọmọ Jóòbù. Àmọ́ ṣá o, ṣàkíyèsí pé kìkì ohun tó mú kí Sátánì lè ṣe èyí ni pé Ọlọ́run fàyè gbà á nítorí ọ̀ràn pàtàkì kan tó fẹ́ yanjú. (Jóòbù 1:12, 18, 19) Kódà, Sátánì ò lè pa Jóòbù fúnra rẹ̀. Jèhófà ò fún un láyè ìyẹn. (Jóòbù 2:6) Èyí fi hàn pé, bó tiẹ̀ ṣeé ṣe fún Sátánì láti fa ikú àwọn olóòótọ́ èèyàn nígbà mìíràn, a ò ní láti bẹ̀rù pé ó lè pa wá ní ìgbàkugbà tó bá wù ú.
Sátánì tún ti lo àwọn èèyàn láti fa ikú. Nípa bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ Kristẹni ló ti kú nítorí ìgbàgbọ́ wọn, àwọn jàǹdùkú tínú ń bí ti pa àwọn kan, àwọn aláṣẹ ìjọba tàbí àwọn adájọ́ oníwà ìbàjẹ́ náà ti pàṣẹ pé kí wọ́n yẹgi fáwọn kan láìyẹ.—Ìṣípayá 2:13.
Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ìgbà mìíràn wà tí Sátánì máa ń lo ibi téèyàn kù díẹ̀ káàtó sí láti fá ikú. Nígbà ayé Ísírẹ́lì ìgbàanì, wòlíì Báláámù gba àwọn ọmọ Móábù níyànjú láti sún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì “hùwà àìṣòótọ́ sí Jèhófà.” (Númérì 31:16) Ìyẹn yọrí sí ikú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlélógún. (Númérì 25:9; 1 Kọ́ríńtì 10:8) Bákan náà ni Sátánì ń fi “ètekéte” rẹ̀ tan àwọn kan jẹ lóde òní, tó sì ń sún wọn sínú ìwà pálapàla tàbí àwọn ìwà mìíràn tí kò bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu. (Éfésù 6:11) Lóòótọ́, irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ kì í sábàá kú lójú ẹsẹ̀ o. Àmọ́, wọ́n máa ń pàdánù àǹfààní rírí ìyè àìnípẹ̀kun gbà, ọ̀nà tí Sátánì fi ń fa ikú wọn sì nìyẹn.
Bá a tiẹ̀ mọ̀ pé Sátánì lágbára láti fa ìpalára, síbẹ̀ a ò ní láti máa gbọ̀n jìnnìjìnnì nítorí rẹ̀. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù sọ pé Sátánì ní ọ̀nà àtimú ikú wá, ó tún sọ pé Kristi kú kí ó lè “sọ [Sátánì] di asán . . . àti pé kí ó lè dá gbogbo àwọn tí a ti fi sábẹ́ ìsìnrú ní gbogbo ìgbésí ayé wọn nítorí ìbẹ̀rù ikú nídè kúrò lóko ẹrú.” (Hébérù 2:14, 15) Bẹ́ẹ̀ ni o, Jésù san ìràpadà náà, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ dá ìran ènìyàn onígbàgbọ́ nídè kúrò lóko ẹrú sí ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú.—2 Tímótì 1:10.
Ká sọ tòótọ́, ó bani nínú jẹ́ láti mọ̀ pé Sátánì ní ọ̀nà àtimú ikú wá, àmọ́ ọkàn wa balẹ̀ pé Jèhófà lè ṣàtúnṣe gbogbo ìpalára tí Sátánì àtàwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ bá fà. Jèhófà mú un dá wa lójú pé Jésù tá a ti jí dìde yóò “fọ́ àwọn iṣẹ́ Èṣù túútúú.” (1 Jòhánù 3:8) Ní agbára Jèhófà, Jésù yóò jí àwọn òkú dìde, yóò sì mú ikú fúnra rẹ̀ kúrò. (Jòhánù 5:28, 29) Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, Jésù yóò tú àṣírí ibi tí agbára Sátánì mọ lọ́nà gbígbàfiyèsí nípa jíjù ú sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀. Sátánì yóò sì wá pa run pátápátá níkẹyìn.— Ìṣípayá 20:1-10.