Ojú Wo Ló Yẹ Ká Máa Fi Wo Àwọn Èèyàn Bí Ọjọ́ Jèhófà Ṣe Ń sún Mọ́lé?
Ojú Wo Ló Yẹ Ká Máa Fi Wo Àwọn Èèyàn Bí Ọjọ́ Jèhófà Ṣe Ń sún Mọ́lé?
“Jèhófà kò fi nǹkan falẹ̀ ní ti ìlérí rẹ̀, . . . ṣùgbọ́n ó ń mú sùúrù fún yín nítorí pé kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run ṣùgbọ́n ó fẹ́ kí gbogbo ènìyàn wá sí ìrònúpìwàdà.”—2 PÉTÉRÙ 3:9.
1, 2. (a) Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo àwọn èèyàn lóde òní? (b) Àwọn ìbéèrè wo la lè bi ara wa?
AYAN iṣẹ́ fún àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà láti “sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.” (Mátíù 28:19) Bá a ṣe ń ṣe iṣẹ́ yẹn, tá a sì ń dúró de “ọjọ́ ńlá Jèhófà,” ojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn èèyàn ni a ní láti máa fi wò wọ́n. (Sefanáyà 1:14) Báwo ló sì ṣe ń wò wọ́n? Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé: “Jèhófà kò fi nǹkan falẹ̀ ní ti ìlérí rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn kan ti ka ìfi-nǹkan-falẹ̀ sí, ṣùgbọ́n ó ń mú sùúrù fún yín nítorí pé kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run ṣùgbọ́n ó fẹ́ kí gbogbo ènìyàn wá sí ìrònúpìwàdà.” (2 Pétérù 3:9) Ọlọ́run ń wo àwọn èèyàn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí ẹni tó lè ronú pìwà dà. “Ìfẹ́ rẹ̀ [ni] pé kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.” (1 Tímótì 2:4) Kódà, inú Jèhófà máa ń dùn nígbà tí ‘ẹni burúkú bá yí padà kúrò nínú ọ̀nà rẹ̀, tí ó sì ń wà láàyè nìṣó ní tòótọ́’!—Ìsíkíẹ́lì 33:11.
2 Ǹjẹ́ ojú tí Jèhófà fi ń wò àwọn èèyàn ni àwa fúnra wa fi ń wo wọ́n? Ǹjẹ́ a máa ń ka ẹnì kọ̀ọ̀kan láti inú gbogbo ẹ̀yà àti orílẹ̀-èdè sẹ́ni tó máa di “àgùntàn pápá ìjẹko rẹ̀” lọ́la? (Sáàmù 100:3; Ìṣe 10:34, 35) Ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò àwọn àpẹẹrẹ méjì tó fi hàn bí níní èrò Ọlọ́run ti ṣe pàtàkì tó. Nínú ọ̀ràn méjèèjì, ìparun ló sún mọ́lé, a sì ti fi ọ̀rọ̀ yìí tó àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà létí ṣáájú àkókò náà. Àwọn àpẹẹrẹ wọ̀nyí ṣe pàtàkì gan-an bá a ṣe ń dúró de ọjọ́ ńlá Jèhófà.
Ojú Tí Ábúráhámù Fi Wo Nǹkan Bá Ti Jèhófà Mu
3. Ojú wo ni Jèhófà fi wo àwọn olùgbé Sódómù àti Gòmórà?
3 Àpẹẹrẹ àkọ́kọ́ ni èyí tó kan Ábúráhámù, baba ńlá olóòótọ́ nì àti Sódómù òun Gòmórà tí wọ́n jẹ́ ìlú ńlá tó kún fún ìwà ibi. Nígbà tí Jèhófà gbọ́ “igbe ìráhùn nípa Sódómù àti Gòmórà,” kò pa àwọn ìlú ńlá yẹn àti gbogbo àwọn olùgbé rẹ̀ run lójú ẹsẹ̀. Ó kọ́kọ́ ṣe ìwádìí. (Jẹ́nẹ́sísì 18:20, 21) Ó rán àwọn áńgẹ́lì méjì sí Sódómù, níbi tí wọ́n ti dé sílé Lọ́ọ̀tì ọkùnrin olóòótọ́ nì. Ní alẹ́ ọjọ́ táwọn áńgẹ́lì náà dé, ńṣe ni “àwọn ọkùnrin ìlú ńlá náà . . . yí ilé náà ká, láti orí ọmọdékùnrin dórí àgbà ọkùnrin, gbogbo àwọn ènìyàn náà ní ìwọ́jọpọ̀ kan,” láti bá àwọn áńgẹ́lì náà ṣèṣekúṣe. Láìsí àní-àní, ipò ìdíbàjẹ́ tí àwọn olùgbé ìlú náà wà fi hàn pé ó yẹ fún ìparun. Síbẹ̀, àwọn áńgẹ́lì náà sọ fún Lọ́ọ̀tì pé: “Ǹjẹ́ o ní ẹnikẹ́ni mìíràn níhìn-ín? Ọkọ ọmọ rẹ àti àwọn ọmọkùnrin rẹ àti àwọn ọmọbìnrin rẹ àti gbogbo àwọn tí ó jẹ́ tìrẹ nínú ìlú ńlá yìí, ni kí o mú jáde kúrò ní ibí yìí!” Jèhófà ṣí ọ̀nà sílẹ̀ láti dáàbò bo àwọn kan lára àwọn olùgbé ìlú ńlá náà, àmọ́ kìkì Lọ́ọ̀tì àtàwọn ọmọbìnrin rẹ̀ méjì ló la ìparun náà já.—Jẹ́nẹ́sísì 19:4, 5, 12, 16, 23-26.
4, 5. Kí nìdí tí Ábúráhámù fi rawọ́ ẹ̀bẹ̀ nítorí àwọn olùgbé Sódómù, ǹjẹ́ ojú tó fi ń wo àwọn èèyàn bá ti Jèhófà mu?
4 Wàyí o, ẹ jẹ́ ká padà sí àkókò tí Jèhófà sọ pé òun fẹ́ lọ ṣàyẹ̀wò ìlú ńlá Sódómù àti Gòmórà. Ìgbà yẹn ni Ábúráhámù bẹ̀bẹ̀ pé: “Ká sọ pé àádọ́ta olódodo wà ní àárín ìlú ńlá náà. Nígbà náà, ìwọ yóò ha gbá wọn lọ, tí o kò sì ní dárí ji ibẹ̀ ní tìtorí àádọ́ta olódodo tí wọ́n wà nínú rẹ̀ bí? Kò ṣeé ronú kàn nípa rẹ pé o ń gbé ìgbésẹ̀ ní irú ọ̀nà yìí láti fi ikú pa olódodo pẹ̀lú ẹni burúkú tí ó fi jẹ́ pé ó ní láti ṣẹlẹ̀ sí olódodo bí ó ti ń rí fún ẹni burúkú! Kò ṣeé ronú kàn nípa rẹ. Onídàájọ́ gbogbo ilẹ̀ ayé kì yóò ha ṣe ohun tí ó tọ́ bí?” Ábúráhámù lo gbólóhùn náà, “kò ṣeé ronú kàn nípa rẹ” lẹ́ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Látinú ìrírí tí Ábúráhámù fúnra rẹ̀ ti ní, ó mọ̀ pé Jèhófà kò ní pa olódodo run pẹ̀lú ẹni ibi. Nígbà tí Jèhófà sọ pé òun ò ní pa Sódómù run tó bá jẹ́ pé “àádọ́ta olódodo wà ní àárín ìlú ńlá náà,” Ábúráhámù wá rọra ń dín iye náà kù títí tó fi dórí mẹ́wàá péré.—Jẹ́nẹ́sísì 18:22-33.
5 Ǹjẹ́ Jèhófà ì bá fetí sí ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ Ábúráhámù tí kò bá wà níbàámu pẹ̀lú èrò òun fúnra rẹ̀? Ó dájú pé kò ní ṣe bẹ́ẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí “ọ̀rẹ́ Jèhófà,” ó hàn gbangba pé Ábúráhámù ti ní láti mọ irú ojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn nǹkan. (Jákọ́bù 2:23) Nígbà tí Jèhófà darí àfiyèsí rẹ̀ sórí Sódómù òun Gòmórà, ó múra tán láti gba ti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ Ábúráhámù rò. Kí nìdí? Nítorí pé Baba wa ọ̀run “kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run ṣùgbọ́n ó fẹ́ kí gbogbo ènìyàn wá sí ìrònúpìwàdà.”
Ojú Tí Jónà Fi Wo Àwọn Èèyàn Yàtọ̀ Pátápátá
6. Kí làwọn ará Nínéfè ṣe nígbà tí wọ́n gbọ́ ìpolongo Jónà?
6 Ẹ jẹ́ ká wá gbé àpẹẹrẹ kejì yẹ̀ wò—ìyẹn ni ti Jónà. Lọ́tẹ̀ yìí, ìlú ńlá tá a fẹ́ pa run ni Nínéfè. A sọ fún wòlíì Jónà pé kó lọ polongo pé ìwà búburú ìlú náà ti ‘gòkè wá síwájú Jèhófà.’ (Jónà 1:2) Tá a ba wò ó pẹ̀lú àwọn ìgbèríko rẹ̀, ìlú ńlá ni Nínéfè jẹ́, “tí ó tó ìwọ̀n ìrìn ọjọ́ mẹ́ta.” Nígbà tí Jónà wá ṣègbọràn níkẹyìn, tó wọnú ìlú Nínéfè, ó bẹ̀rẹ̀ sí polongo pé: “Kìkì ogójì ọjọ́ sí i, a ó sì bi Nínéfè ṣubú.” Nítorí bẹ́ẹ̀, “àwọn ènìyàn Nínéfè sì bẹ̀rẹ̀ sí ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, wọ́n sì tẹ̀ síwájú láti pòkìkí ààwẹ̀, wọ́n sì gbé aṣọ àpò ìdọ̀họ wọ̀.” Kódà, ọba ìlú Nínéfè pàápàá ronú pìwà dà.—Jónà 3:1-6.
7. Báwo ni Jèhófà ṣe wo ẹ̀mí ìrònúpìwàdà táwọn ará Nínéfè fi hàn?
7 Ìyẹn yàtọ̀ pátápátá sí ohun táwọn ará Sódómù ṣe! Ojú wo ni Jèhófà fi wo àwọn ará Nínéfè tó ronú pìwà dà yìí? Ìwé Jónà 3:10 sọ pé: “Ọlọ́run tòótọ́ pèrò dà lórí ìyọnu àjálù tí ó ti sọ pé òun yóò mú bá wọn; kò sì mú un wá.” Jèhófà “pèrò dà” ní ti pé ó yí ohun tó fẹ́ ṣe fún àwọn ará Nínéfè padà nítorí pé wọ́n ti yí padà. Àwọn ìlànà Ọlọ́run kò yí padà o, àmọ́ Jèhófà yí ìpinnu rẹ̀ padà nígbà tó rí i pé àwọn ará Nínéfè ronú pìwà dà.—Málákì 3:6.
8. Kí nìdí tí Jónà fi rẹ̀wẹ̀sì?
8 Nígbà tí Jónà rí i pé a ò ní pa Nínéfè run mọ́, ǹjẹ́ ó wo àwọn nǹkan lọ́nà tí Jèhófà gbà wò wọ́n? Rárá o, nítorí a sọ fún wa pé: “Bí ó ti wù kí ó rí, kò dùn mọ́ Jónà nínú rárá, inú rẹ̀ sì ru fún ìbínú.” Kí ni Jónà wá ṣe? Ìtàn náà sọ fún wa pé: “Ó gbàdúrà sí Jèhófà, ó sì wí pé: ‘Áà, nísinsìnyí, Jèhófà, ohun tí mo ń ṣàníyàn nípa rẹ̀ ha kọ́ ni èyí, nígbà tí mo wà lórí ilẹ̀ mi? Ìdí nìyẹn tí mo fi lọ ní ìṣáájú, tí mo sì fẹsẹ̀ fẹ lọ sí Táṣíṣì; nítorí mo mọ̀ pé ìwọ jẹ́ Ọlọ́run olóore ọ̀fẹ́ àti aláàánú, tí ó ń lọ́ra láti bínú, tí ó sì pọ̀ yanturu ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́, tí ń pèrò dà lórí ìyọnu àjálù.’” (Jónà 4:1, 2) Jónà mọ̀ nípa àwọn ànímọ́ Jèhófà. Àmọ́, lákòókò yẹn, wòlíì náà di ẹni tó rẹ̀wẹ̀sì, kò sì ní irú èrò tí Ọlọ́run ní nípa àwọn èèyàn tó ronú pìwà dà ní Nínéfè.
9, 10. (a) Ẹ̀kọ́ wo ni Jèhófà kọ́ Jónà? (b) Kí nìdí tá a fi lè gbà pé ojú tí Jèhófà fi wo àwọn ará Nínéfè ni Jónà wá fi wò wọ́n níkẹyìn?
9 Jónà wá jáde kúrò ní Nínéfè, ó lọ kọ́ àtíbàbà kan, ó sì jókòó sábẹ́ ibòji rẹ̀ “títí yóò fi rí ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí ìlú ńlá náà.” Jèhófà wá jẹ́ kí ewéko akèrègbè kan hù kí ó lè di ibòji fún Jónà. Àmọ́, nígbà tó di ọjọ́ kejì, ewéko náà gbẹ dà nù. Nígbà tí Jónà wá ń bínú sí ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn, Jèhófà sọ pé: “Ìwọ, ní tìrẹ, káàánú fún ewéko akèrègbè náà . . . Ní tèmi, kò ha sì yẹ kí n káàánú fún Nínéfè ìlú ńlá títóbi nì, inú èyí tí àwọn ènìyàn tí ó ju ọ̀kẹ́ mẹ́fà wà, tí wọn kò mọ ìyàtọ̀ rárá láàárín ọwọ́ ọ̀tún wọn àti òsì wọn, yàtọ̀ sí ọ̀pọ̀ àwọn ẹran agbéléjẹ̀?” (Jónà 4:5-11) Ẹ ò rí i pé ẹ̀kọ́ ńlá ni èyí jẹ́ fún Jónà nípa irú ojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn èèyàn!
10 Ohun tí Jónà fi fèsì ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run sọ nípa kíkáàánú àwọn èèyàn ìlú Nínéfè kò sí lákọsílẹ̀. Àmọ́, ó hàn gbangba pé wòlíì náà ti ní láti wá nǹkan ṣe sí ojú tó fi ń wo àwọn èèyàn tó ronú pìwà dà ní Nínéfè. Ìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀ ni pé òun ni Jèhófà lò láti ṣàkọ́sílẹ̀ ìtàn onímìísí yìí.
Kí Ni Ìṣarasíhùwà Rẹ?
11. Irú ojú wo ló ṣeé ṣe kí Ábúráhámù fi wo àwọn èèyàn tó wà láyé lóde òní?
11 Àwa náà dojú kọ iparun mìíràn lóde òní—ìyẹn ni ìparun ètò àwọn nǹkan búburú ìsinsìnyí nígbà ọjọ́ ńlá Jèhófà. (Lúùkù 17:26-30; Gálátíà 1:4; 2 Pétérù 3:10) Ká ní Ábúráhámù ṣì wà ni, ojú wo ni ì bá fi wo àwọn èèyàn tó ń gbé nínú aye tí kò ní pẹ́ pa run yìí? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọ̀ràn àwọn tí kò tíì gbọ́ “ìhìn rere Ìjọba” náà ló máa ká a lára jù. (Mátíù 24:14) Léraléra ni Ábúráhámù ń rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Ọlọ́run nípa àwọn tó ṣeé ṣe kí wọ́n jẹ́ olódodo ní Sódómù. Ǹjẹ́ àwa náà máa ń ṣàníyàn nípa àwọn tó máa kọ àwọn ọ̀nà ayé yìí tó wà lábẹ́ ìṣàkóso Sátánì sílẹ̀ tá a bá fún wọn láǹfààní àtironú pìwà dà kí wọ́n sì sin Ọlọ́run?—1 Jòhánù 5:19; Ìṣípayá 18:2-4.
12. Kí nìdí tó fi rọrùn láti ní irú ẹ̀mí tí Jónà ní nípa àwọn èèyàn tá à ń bá pàdé nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, kí la sì lè ṣe nípa èyí?
12 Kò sóhun tó burú nínú kéèyàn fẹ́ kí ìwà ibi dópin. (Hábákúkù 1:2, 3) Síbẹ̀, ó tún rọrùn láti ní irú ẹ̀mí tí Jónà ní, ìyẹn ni pé kí ire àwọn ẹlòmíràn tó ṣeé ṣe kó ronú pìwà dà máà ká wa lára. Èyí sábà máa ń rí bẹ́ẹ̀ tó bá jẹ́ pé àwọn tí ò ka nǹkan sí, àwọn alátakò, tàbí àwọn aríjàgbá la máa ń bá pàdé nígbà tá a bá lọ wàásù ìhìn Ìjọba náà nílé àwọn èèyàn. A lè máà fẹ́ kọbi ara sáwọn tí Jèhófà ṣì máa kó kúrò nínú ètò nǹkan búburú yìí. (Róòmù 2:4) Tá a bá fara balẹ̀ yẹ ara wa wò dáadáa, tá a sì rí i pé a ní àwọn èrò kan tó fẹ́ dà bí irú èyí tí Jónà kọ́kọ́ ní sí àwọn ará Nínéfè, a lè gbàdúrà pé kí Jèhófà ràn wá lọ́wọ́ kí èrò wa lè bá tirẹ̀ mu.
13. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé Jèhófà ń ṣàníyàn nípa àwọn èèyàn òde òní?
13 Jèhófà máa ń ṣàníyàn nípa àwọn tí ò tíì bẹ̀rẹ̀ sí í sìn ín, ó sì ń tẹ́tí sí ẹ̀bẹ̀ àwọn èèyàn tó ti ya ara wọn sí mímọ́ fún un. (Mátíù 10:11) Bí àpẹẹrẹ, “yóò mú kí a ṣe ìdájọ́ òdodo” láti dáhùn àwọn àdúrà wọn. (Lúùkù 18:7, 8) Ìyẹn nìkan kọ́ o, Jèhófà yóò tún mú gbogbo àwọn ìlérí rẹ̀ àti ète rẹ̀ ṣẹ nígbà tó bá tó àkókò lójú rẹ̀. (Hábákúkù 2:3) Èyí yóò kan mímú gbogbo ibi kúrò lórí ilẹ̀ ayé yìí gẹ́gẹ́ bó ṣe pa Nínéfè run nígbà táwọn olùgbé ibẹ̀ tún padà sídìí ìwà ibi wọn.—Náhúmù 3:5-7.
14. Kí ló yẹ ká máa ṣe bá a ṣe ń dúró de ọjọ́ ńlá Jèhófà?
14 Títí dìgbà tá ó fi mú ètò àwọn nǹkan búburú yìí kúrò nígbà ọjọ́ ńlá Jèhófà, ṣé a ó máa fi sùúrù dúró, ká sì jẹ́ kí ọwọ́ wa dí nínú ṣíṣe ìfẹ́ rẹ̀? A ò mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ibi tó kù kí iṣẹ́ ìwàásù náà dé ṣáájú dídé ọjọ́ Jèhófà, àmọ́ ohun tá a mọ̀ ni pé a óò wàásù ìhìn rere Ìjọba náà ní gbogbo ilẹ̀ ayé táwọn èèyàn ń gbé débi tó tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn kí òpin tóó dé. Ó sì dájú pé a ní láti máa ṣàníyàn nípa “àwọn ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra” tó ṣì máa wọlé wá bí Jèhófà ṣe ń bá a lọ láti fi ògo kún ilé rẹ̀.—Hágáì 2:7.
Ìṣe Wa Ló Ń Fi Irú Ojú Tá A Fi Ń Wo Nǹkan Hàn
15. Kí ló lè jẹ́ ká túbọ̀ mọrírì iṣẹ́ ìwàásù náà?
15 Bóyá àgbègbè táwọn èèyàn ò ti nífẹ̀ẹ́ sí iṣẹ́ ìwàásù náà là ń gbé, tá ò sì láǹfààní àtiṣí lọ sí àgbègbè tí wọ́n ti nílò àwọn olùpòkìkí Ìjọba náà. Ká sọ pé a lè rí ẹni mẹ́wàá ní ìpínlẹ̀ wa kí òpin náà tóó dé. Ǹjẹ́ a rò pé àwọn mẹ́wàá wọ̀nyẹn yẹ lẹ́ni tá à ń wá rí? “Àánú” àwọn ogunlọ́gọ̀ èèyàn ṣe Jésù “nítorí a bó wọn láwọ, a sì fọ́n wọn ká bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ àgùntàn.” (Mátíù 9:36) Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tá a sì ń fara balẹ̀ ka àwọn àpilẹ̀kọ tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ àti Jí!, a lè túbọ̀ ní ìjìnlẹ̀ òye nípa ipò búburú tí ayé yìí wà. Èyí sì lè jẹ́ ká túbọ̀ mọrírì ìdí tó fi yẹ ká wàásù ìhìn rere náà. Láfikún sí i, fífi ìmọrírì lo àwọn ìtẹ̀jáde tá a gbé karí Bíbélì, èyí tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” náà ń pèsè tún lè jẹ́ ká túbọ̀ mọ bí a ó ṣe máa yíni lérò padà láwọn ìpínlẹ̀ tá a ti ń wàásù déédéé.—Mátíù 24:45-47; 2 Tímótì 3:14-17.
16. Báwo la ṣe lè jẹ́ kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa túbọ̀ gbéṣẹ́ sí i?
16 Àníyàn tá a ní fáwọn tó ṣeé ṣe kó tẹ́wọ́ gba ìhìn Bíbélì tí ń fúnni ní ìyè ló ń mú ká máa ronú nípa àkókò tá a lè báwọn èèyàn nílé àti ọ̀nà tá a lè gbà bá àwọn onílé sọ̀rọ̀ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. Ǹjẹ́ a máa ń rí i pé ọ̀pọ̀ èèyàn ni kì í sí nílé nígbà tá a bá délé wọn? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, a lè jẹ́ kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa túbọ̀ gbéṣẹ́ sí i nípa yíyí àwọn àkókò tá à ń jáde òde ẹ̀rí àti àwọn àgbègbè tá a ti ń jẹ́rìí padà lóòrèkóòrè. Àkókò táwọn apẹja mọ̀ pé àwọn lè rí ẹja pa ni wọ́n máa ń lọ sétí odò. Ǹjẹ́ a le ṣe bákan náà nínú iṣẹ́ ìpẹja tẹ̀mí tá à ń ṣe? (Máàkù 1:16-18) O ò ṣe gbìyànjú jíjáde òde ẹ̀rí nírọ̀lẹ́ àti ìjẹ́rìí orí tẹlifóònù, níbi tíyẹn bá ti bófin mu? Àwọn kan tí rí i pé àwọn ibi ìgbọ́kọ̀sí, ilé epo, àti àwọn ibi ìtajà jẹ́ ‘ibi ìpẹja’ tó ń méso jáde. Níní tá a ní irú ẹ̀mí tí Ábúráhámù ní sáwọn èèyàn tún hàn kedere nígbà tá a ba lo àǹfààní tá a ní láti jẹ́rìí láìjẹ́ bí àṣà.
17. Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà fún àwọn míṣọ́nnárì àtàwọn mìíràn tó ń sìn nílẹ̀ òkèèrè níṣìírí?
17 Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ni kò tíì gbọ́ ìhìn Ìjọba náà. Yàtọ̀ sí iṣẹ́ ìwàásù wa, ǹjẹ́ a tún lè fi hàn pé a bìkíta fún irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ kódà látinú ilé wa pàápàá? Tóò, ǹjẹ́ a mọ àwọn míṣọnnárì tàbí àwọn tó wà nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún tí wọ́n ń sìn nílẹ̀ òkèèrè? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, a lè kọ lẹ́tà sí wọn láti fi hàn pé a mọrírì iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe. Báwo nìyẹn ṣe lè fi hàn pé a bìkítà fún gbogbo èèyàn lápapọ̀? Lẹ́tà ìṣírí tá a bá kọ àti bá a ṣe ń gbóríyìn fún wọn lè fún àwọn míṣọ́nnárì náà lókun láti máa bá iṣẹ́ wọn lọ, kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ túbọ̀ ṣèrànwọ́ fún ọ̀pọ̀ èèyàn láti ní ìmọ̀ òtítọ́. (Àwọn Onídàájọ́ 11:40) A tún lè gbàdúrà fún àwọn míṣọ̀nnárì àti fún àwọn tébi òtítọ́ ń pa láwọn orílẹ̀-èdè mìíràn. (Éfésù ) Ọ̀nà mìíràn tá a tún lè gbà fi hàn pé a bìkítà ni pé ká máa dáwó láti ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe kárí ayé.— 6:18-202 Kọ́ríńtì 8:13, 14; 9:6, 7.
Ṣé Wàá Lè Lọ?
18. Kí làwọn Kristẹni kan ti ṣe láti gbé ire Ìjọba náà ga ní orílẹ̀-èdè tí wọ́n ń gbé?
18 Àwọn tó ṣí lọ sáwọn ibi tá a ti nílò àwọn olùpòkìkí Ìjọba ti rí ìbùkún yàbùgà yabuga gbà nítorí ìsapá ìfara-ẹni-rúbọ tí wọ́n ṣe. Àmọ́ o, àwọn mìíràn tó jẹ Ẹlẹ́rìí fún Jèhófà ti kọ́ èdè mìíràn ní orílẹ̀-èdè tiwọn fúnra wọn kí wọ́n lè ṣèrànwọ́ nípa tẹ̀mí fáwọn tó ń ṣí wọ̀lú wọn. Irú àwọn ìsapá bẹ́ẹ̀ sì ti mérè wá gan-an. Bí àpẹẹrẹ, àwọn èèyàn mẹ́rìnléláàádọ́fà [114] ni àwọn Ẹlẹ́rìí méje, tí wọ́n ń ṣèrànwọ́ fún àwọn ará Ṣáínà tó wà ní Texas, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà kí káàbọ̀ síbi ayẹyẹ Oúnjẹ Alẹ́ Oluwa ní ọdún 2001. Àwọn tó ń ṣèrànwọ́ fún irú àwọn àwùjọ bẹ́ẹ̀ tí rí i pé pápá oko wọn tí wà ní sẹpẹ́ fún ìkórè.—Mátíù 9:37, 38.
19. Kí ló bọ́gbọ́n mu láti ṣe nígbà tó o bá ń ronú àtiṣí lọ sí orílẹ̀-èdè mìíràn láti mú kí iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà tẹ̀ síwájú níbẹ̀?
19 Bóyá ìwọ àti ìdílé rẹ̀ ti rí i pé ẹ láǹfààní àtiṣí lọ síbì kan tí wọ́n ti nílò àwọn olùpòkìkí Ìjọba. Ohun tó bọ́gbọ́n mu láti kọ́kọ́ ṣe ni pé kó o “jókòó, kí [o] sì gbéṣirò lé ìnáwó náà.” (Lúùkù 14:28) Èyí ṣe pàtàkì gan-an, àgàgà téèyàn bá ń pinnu àtiṣí lọ sílẹ̀ òkèèrè. Ẹnikẹ́ni tó bá ń ronú àtiṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè bi ara rẹ̀ láwọn ìbéèrè bí ìwọ̀nyí: ‘Ṣé màá lè gbọ́ bùkátà ìdílé mi? Ṣé màá rí ìwé àṣẹ wíwọ orílẹ̀-èdè míì gbà? Ǹjẹ́ mo gbọ́ èdè tí wọ́n ń sọ lórílẹ̀-èdè náà, àbí mo ti múra tán láti kọ́ ọ? Ṣe mo ti gbé bí ipò ojú ọjọ́ ṣe máa ń rí lórílẹ̀-èdè náà àti àṣà ìbílẹ̀ ibẹ̀ yẹ̀ wò? Ṣé mo lè jẹ́ “àrànṣe afúnnilókun” ní ti gidi níbẹ̀ kí n má sì jẹ́ ẹrù ìnira fáwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ mi tó wà lórílẹ̀-èdè náà?’ (Kólósè 4:10, 11) Tó o bá fẹ́ mọ bí wọ́n ṣe nílò àwọn èèyàn tó ní orílẹ̀-èdè tó ò ń ronú àtiṣí lọ, ohun tó sábà máa ń dára jù lọ ni pé kó o kọ̀wé sí ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń bójú tó iṣẹ́ ìwàásù ní àgbègbè náà. a
20. Báwo ni Kristẹni kan tó jẹ́ ọ̀dọ́ ṣe lo ara rẹ̀ fún àǹfààní àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ àti fún àwọn mìíràn tó wà nílẹ̀ òkèèrè?
20 Kristẹni kan tó ti kópa nínú kíkọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba nílẹ̀ Japan gbọ́ pé wọ́n nílò àwọn òṣìṣẹ́ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ láti wá kọ ibi ìjọsìn kan ní Paraguay. Nígbà tó jẹ́ pé àpọ́n ni tó sì tún jẹ́ ọ̀dọ́, bó ṣe forí lé orílẹ̀-èdè náà nìyẹn tó sì ṣiṣẹ́ níbẹ̀ fún odindi oṣù mẹ́jọ̀ gbáko. Òun nìkan ṣoṣo sì ni òṣìṣẹ́ alákòókò kíkún nídìí iṣẹ́ náà. Láàárín àkókò tó fi wà níbẹ̀ yẹn, ó kọ́ èdè Spanish ó sì darí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó rí i pé wọ́n nílò àwọn olùpòkìkí Ìjọba lórílẹ̀-èdè náà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó padà sí Japan, kò pẹ́ tó tún fi padà lọ sí Paraguay tó sì ṣèrànwọ́ láti kó àwọn èèyàn jọ sínú Gbọ̀ngàn Ìjọba kan náà yẹn.
21. Kí ló yẹ kó jẹ́ olórí àníyàn wa àti èrò wa bá a ṣe ń dúró de ọjọ́ ńlá Jèhófà?
21 Ọlọ́run yóò rí sí i pé a ṣe iṣẹ́ ìwàásù náà ní kíkún, níbàámu pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ̀. Ó sì ti ń mú kí àṣekágbá iṣẹ́ ìkórè tẹ̀mí náà yára kánkán lóde òní. (Aísáyà 60:22) Bá a ṣe ń dúró de ọjọ́ Jèhófà, ẹ jẹ́ ká máa fìtara kópa nínú iṣẹ́ ìkórè náà kí ojú tá a fi ń wo àwọn èèyàn sì bá èyí tí Ọlọ́run wa onífẹ̀ẹ́ fi ń wò wọ́n mu.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Kì í ṣe ohun tó dára pé kó o kàn ṣí lọ sí orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ ìwàásù. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ tiẹ̀ lè ṣèpalára fáwọn akéde Ìjọba tó rọra ń fọgbọ́n wàásù lábẹ́ irú ipò yẹn.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Bá a ṣe ń dúró de ọjọ́ Jèhófà, irú ojú wo ló yẹ ká máa fi wo àwọn èèyàn?
• Irú ojú wo ni Ábúráhámù fi wo àwọn olódodo tó ṣeé ṣe kó wà ní Sódómù?
• Ojú wo ni Jónà fi wo àwọn èèyàn tó ronú pìwà dà ní Nínéfè?
• Báwo la ṣe lè fi hàn pé ojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn tí kò tíì gbọ́ ìhìn rere làwa náà fi ń wò wọ́n?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Ojú ti Ábúráhámù fi ń wo àwọn èèyàn bá ti Jèhófà mu
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Ojú tí Jèhófà fi wo àwọn èèyàn tó ronú pìwa dà ní Nínéfè ni Jónà wá fi wò wọ́n níkẹyìn
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Àníyàn tá a ní fún àwọn èèyàn ló ń jẹ́ ká ronú nípa onírúurú àkókò tá a lè wàásù ìhìn rere náà àtàwọn ọ̀nà tá a lè gbà ṣe é