Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ronú Lọ́nà Tó Ṣe Tààrà Kó O sì Fi Ọgbọ́n Hùwà

Ronú Lọ́nà Tó Ṣe Tààrà Kó O sì Fi Ọgbọ́n Hùwà

Ronú Lọ́nà Tó Ṣe Tààrà Kó O sì Fi Ọgbọ́n Hùwà

FOJÚ inú yàwòrán ìṣẹ̀lẹ̀ yìí: Jésù Kristi ń ṣàlàyé pé àwọn ọ̀tá tí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́sìn ní Jerúsálẹ́mù máa fìyà ńláǹlà jẹ òun wọ́n á sì pa òun. Àpọ́sítélì Pétérù tó jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ kò gbà pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè ṣẹlẹ̀. Kódà, ńṣe ló pe Jésù sí kọ̀rọ̀ tó sì nà án ní pàṣán ọ̀rọ̀. Kò sí iyèméjì nípa òótọ́ inú tí Pétérù fi sọ̀rọ̀ àti àníyàn tó ní. Àmọ́ ojú wo ni Jésù fi wo ọ̀nà tí Pétérù gbà ronú? Jésù sọ pé: “Dẹ̀yìn lẹ́yìn mi, Sátánì! Ohun ìkọ̀sẹ̀ ni ìwọ jẹ́ fún mi, nítorí kì í ṣe àwọn ìrònú Ọlọ́run ni ìwọ ń rò, bí kò ṣe ti ènìyàn.”—Mátíù 16:21-23.

Kò sí ni kí jẹbẹtẹ máà gbé ọmọ lé Pétérù lọ́wọ́! Dípò tí ì bá fi jẹ́ alátìlẹyìn àti olùrànlọ́wọ́, “ohun ìkọ̀sẹ̀” ló jẹ́ fún Ọ̀gá rẹ̀ ọ̀wọ́n lọ́tẹ̀ yìí. Báwo lèyí ṣe ṣẹlẹ̀? Ó ṣeé ṣe kí kùdìẹ̀-kudiẹ kan tó wọ́pọ̀ nínú èrò àwọn èèyàn ti nípa lórí Pétérù—ìyẹn ni pé kí ó gba kìkì ohun tó bá wù ú gbọ́.

Má Ṣe Dá Ara Rẹ Lójú Ju Bó Ṣe Yẹ Lọ

Ìṣòro kan tó lè máà jẹ́ ká ronú bó ti yẹ ni dídá ara ẹni lójú ju bó ti yẹ lọ. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ fáwọn Kristẹni bíi tirẹ̀ ní Kọ́ríńtì ìgbàanì pé: “Kí ẹni tí ó bá rò pé òun dúró kíyè sára kí ó má bàa ṣubú.” (1 Kọ́ríńtì 10:12) Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi sọ̀rọ̀ yìí? Dájúdájú, ó sọ bẹ́ẹ̀ nítorí ó mọ̀ pé ó rọrùn gan-an kí èrò ẹ̀dá èèyàn dìdàkudà—àní ó tiẹ̀ rọrùn kí ọkàn àwọn Kristẹni pàápàá “di ìbàjẹ́ kúrò nínú òtítọ́ inú àti ìwà mímọ́ tí ó tọ́ sí Kristi.”—2 Kọ́ríńtì 11:3.

Èyí ṣẹlẹ̀ sí odindi ìran kan lára àwọn baba ńlá Pọ́ọ̀lù. Nígbà yẹn, Jèhófà sọ fún wọn pé: “Ìrònú yín kì í ṣe ìrònú mi, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀nà mi kì í ṣe ọ̀nà yín.” (Aísáyà 55:8) Wọ́n ti “gbọ́n ní ojú ara wọn,” èyí kò sì bímọ rere. (Aísáyà 5:21) Nítorí náà, ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé ká ṣàyẹ̀wò bá a ṣe lè ronú lọ́nà tó ṣe tààrà kí ibi tó ṣẹlẹ̀ sí wọn má bàa ṣẹlẹ̀ sí àwa náà.

Ṣọ́ra fún Ríronú Lọ́nà Ti Ara

Èrò ti ara ṣàkóbá lọ́pọ̀lọpọ̀ fún àwọn kan ní Kọ́ríńtì. (1 Kọ́ríńtì 3:1-3) Wọ́n ka ìmọ̀ ọgbọ́n orí ẹ̀dá èèyàn sí ju Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lọ. Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, kò sí iyèméjì pé àwọn èèyàn tó gbọ́n féfé ni àwọn ará Gíríìkì aláròjinlẹ̀. Àmọ́ lójú Ọlọ́run, òmùgọ̀ gbáà ni wọ́n. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Nítorí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: ‘Ṣe ni èmi yóò mú kí ọgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n ṣègbé, làákàyè àwọn amòye ni èmi yóò sì rọ́ tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan.’ Ibo ni ọlọ́gbọ́n ènìyàn náà wà? Ibo ni akọ̀wé òfin náà wà? Ibo ni olùjiyàn ọ̀rọ̀ ètò àwọn nǹkan yìí wà? Ọlọ́run kò ha ti sọ ọgbọ́n ayé di òmùgọ̀?” (1 Kọ́ríńtì 1:19, 20) “Ẹ̀mí ayé” ló ń darí irú àwọn onímọ̀ yẹn kì í ṣe ẹ̀mí Ọlọ́run. (1 Kọ́ríńtì 2:12) Ìmọ̀ ọgbọ́n orí wọn àti èrò wọn ò bá ìrònú Jèhófà mu páàpáà.

Sátánì Èṣù tó lo ejò láti tan Éfà jẹ ni orísun ìrònú lọ́nà ti ara yìí. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6; 2 Kọ́ríńtì 11:3) Ǹjẹ́ ó ṣì lè wu wá léwu? Bẹ́ẹ̀ ni o! Gẹ́gẹ́ bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti wí, Sátánì ‘ti sọ èrò inú àwọn èèyàn dìbàjẹ́’ débi pé ní báyìí òun ló “ń ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà.” (2 Kọ́ríńtì 4:4; Ìṣípayá 12:9) Ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká wà lójúfò nítorí àwọn ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ rẹ̀!—2 Kọ́ríńtì 2:11.

Ṣọ́ra fún “Ìwà Àgálámàṣà Àwọn Ènìyàn”

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tún kìlọ̀ pé ká ṣọ́ra fún “ìwà àgálámàṣà àwọn ènìyàn.” (Éfésù 4:14) Ó bá “àwọn oníṣẹ́ ẹ̀tàn” pàdé, tí wọ́n ń díbọ́n pé òtítọ́ làwọn fi ń kọ́ni àmọ́ tó jẹ́ pé wọ́n ti sọ òtítọ́ dìdàkudà. (2 Kọ́ríńtì 11:12-15) Kí ọwọ́ àwọn èèyàn yìí bàa lè tẹ ohun tí wọ́n fẹ́, wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ sí lo kìkì àwọn ẹ̀rí tó gbe èròkerò wọn lẹ́sẹ̀, kí wọ́n máa sọ àwọn èdè tó ń wọni lákínyẹmí ara, kí wọ́n máa pa dúdú pọ̀ mọ́ funfun, kí wọ́n máa fẹ̀sùn kanni tàbí parọ́ ojúkojú pàápàá.

Àwọn tó máa ń polongo èké yìí sábàá máa ń lo ọ̀rọ̀ náà “ẹ̀ya ìsìn” láti fi kó àbààwọ́n bá àwọn ẹlòmíràn. Nínú ìwé kan tí ẹnì kan kọ ṣọwọ́ sí Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin ti Ìparapọ̀ Orílẹ̀-Èdè Yúróòpù, àbá kan wà níbẹ̀ tó sọ pé káwọn aláṣẹ ìjọba tí wọ́n máa ń ṣèwádìí àwọn ẹ̀sìn tuntun “yé lo èdè yìí.” Nítorí kí ni? Wọ́n sọ pé ìtumọ̀ tí ò bójú mu ni ọ̀rọ̀ náà “ẹ̀ya ìsìn” máa ń gbé wá sọ́kàn àwọn èèyàn. Ó sọ síwájú pé: “Lọ́kàn ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí, ẹ̀ya ìsìn jẹ́ ohun kan tó burú tó sì léwu púpọ̀.” Lọ́nà kan náà, àwọn ọ̀mọ̀ràn Gíríìkì fi àṣìṣe pe àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní “onírèégbè.” Ní ṣáńgílítí, èyí túmọ̀ sí “ẹni tó ń ṣa èso kiri.” Wọ́n pè é bẹ́ẹ̀ kó bà a lè dà bí ẹni pé kò níṣẹ́ méjì ju kó kàn máa sọ̀rọ̀ bórobòro lọ, pé ení-tere èjì-tere ìmọ̀ ló ń sọ lásọtúnsọ. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ńṣe ni Pọ́ọ̀lù “ń polongo ìhìn rere Jésù àti àjíǹde.”—Ìṣe 17:18.

Ṣé ọgbọ́n táwọn tó ń polongo èké kiri yìí ń lò ń ṣiṣẹ́? Ó kúkú ń ṣiṣẹ́. Àwọn gan-an ni ẹni tó dá ìkórìíra ẹ̀yà àti ti ẹ̀sìn sílẹ̀ nípa bí wọ́n ṣe mú káwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí ní èròkerò nípa àwọn ẹ̀yà mìíràn àti ẹ̀sìn mìíràn. Ọ̀pọ̀ ti lò wọ́n láti sọ àwọn àwùjọ kéékèèké tí kò fi bẹ́ẹ̀ gbajúmọ̀ dẹni tí ò lẹ́nu ọ̀rọ̀ mọ́ láwùjọ. Adolf Hitler lo irú àwọn ọ̀nà yìí gan-an nígbà tó pe àwọn Júù àtàwọn àwùjọ kéékèèké mìíràn ní “ẹni yẹ̀yẹ́,” “ẹni ibi,” pé wọ́n jẹ́ “ewu” fún Orílẹ̀-èdè. Má ṣe jẹ́ kí irú ẹ̀tàn yìí sọ ìrònú rẹ dìdàkudà.—Ìṣe 28:19-22.

Má Ṣe Tan Ara Rẹ Jẹ

Ó tún rọrùn púpọ̀ láti bẹ̀rẹ̀ sí tan ara wa jẹ. Ká sòótọ́, ó lè ṣòro fún wa gan-an láti pa àwọn èrò kan tó wà lọ́kàn wa tì tàbí ká tún wọn gbé yẹ̀ wò dáadáa. Kí nìdí? Ìdí ni pé a ti sọ àwọn èrò wa di nǹkan bàbàrà tá ò lè yí padà. A lè wá bẹ̀rẹ̀ sí fi àwọn èrò èké tan ara wa jẹ—ká bẹ̀rẹ̀ sí hùmọ̀ àwọn ohun tí á mú káwọn èrò tí kò tọ̀nà àti ìgbàgbọ́ tí kò tọ̀nà wá dà bí èyí tó bọ́gbọ́n mu.

Èyí ṣẹlẹ̀ sáwọn Kristẹni kan ní ọ̀rúndún kìíní. Wọ́n mọ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àmọ́ wọn ò jẹ́ kó ṣe atọ́nà ìrònú wọn. Bí wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ sí fi “èrò èké tan ara [wọn] jẹ” nìyẹn. (Jákọ́bù 1:22, 26) Ohun kan tó lè jẹ́ ká mọ̀ pé a ti kó sí pańpẹ́ irú ẹ̀tàn bẹ́ẹ̀ ni tó bá ṣẹlẹ̀ pé ńṣe ni inú máa ń bí wa tẹ́nì kan bá ṣe lámèyítọ́ ohun tá a gbà gbọ́. Dípò ká fa ìbínú yọ, ńṣe ló yẹ ká fara balẹ̀ ká sì tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́ sí nǹkan táwọn ẹlòmíràn fẹ́ sọ—bí a tiẹ̀ mọ̀ pé èrò tiwa ló tọ̀nà.—Òwe 18:17.

Wá “Ìmọ̀ Ọlọ́run Gan-an”

Kí la lè ṣe láti máa ronú lọ́nà tó ṣe tààrà? Ẹgbàágbèje ìrànlọ́wọ́ ló ń bẹ lárọ̀ọ́wọ́tó, àmọ́ kò ní wá bá wa níbi tá a jókòó gẹlẹtẹ sí o. Sólómọ́nì Ọlọgbọ́n Ọba sọ pé: “Ọmọ mi, bí ìwọ yóò bá gba àwọn àsọjáde mi, tí ìwọ yóò sì fi àwọn àṣẹ tèmi ṣúra sọ́dọ̀ rẹ, láti lè dẹ etí rẹ sí ọgbọ́n, kí o lè fi ọkàn-àyà rẹ sí ìfòyemọ̀; jù bẹ́ẹ̀ lọ, bí o bá ké pe òye, tí o sì fọ ohùn rẹ jáde sí ìfòyemọ̀, bí o bá ń bá a nìṣó ní wíwá a bí fàdákà, tí o sì ń bá a nìṣó ní wíwá a kiri bí àwọn ìṣúra fífarasin, bí ọ̀ràn bá rí bẹ́ẹ̀, ìwọ yóò lóye ìbẹ̀rù Jèhófà, ìwọ yóò sì rí ìmọ̀ Ọlọ́run gan-an.” (Òwe 2:1-5) Dájúdájú, tá a bá sapá láti jẹ́ kí òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kúnnú ọkàn wa, àá ní ojúlówó ọgbọ́n, ìfòyemọ̀ àti òye. Lẹ́nu kan, ńṣe là ń wá àwọn nkan tó níye lórí fíìfíì ju fàdákà tàbí ohun ìṣura èyíkéyìí mìíràn lọ.—Òwe 3:13-15.

Ó dájú pé ọgbọ́n àti ìmọ̀ ṣe kókó gan-an téèyàn bá fẹ́ máa ronú lọ́nà tó ṣe tààrà. Ọ̀rọ̀ Ọlọrun sọ pé: “Nígbà tí ọgbọ́n bá wọnú ọkàn-àyà rẹ, tí ìmọ̀ sì dùn mọ́ ọkàn rẹ pàápàá, agbára láti ronú yóò máa ṣọ́ ọ, ìfòyemọ̀ yóò máa fi ìṣọ́ ṣọ́ ọ, láti dá ọ nídè kúrò ní ọ̀nà búburú, kúrò lọ́wọ́ ẹni tí ń sọ àwọn ohun àyídáyidà, kúrò lọ́wọ́ àwọn tí ń fi àwọn ipa ọ̀nà ìdúróṣánṣán sílẹ̀ láti rìn ní àwọn ọ̀nà òkùnkùn.”—Òwe 2:10-13.

Ó ṣe pàtàkì ká jẹ́ kí èrò Ọlọ́run ṣamọ̀nà ìrònú wa àgàgà lákòókò ìpọ́njú tàbí lákòókò ìṣòro. Ríronú lọ́nà tó ṣe tààrà lè má rọrùn fún ẹni tí ara rẹ̀ ò rọlẹ̀, bí ẹni tínú ń bí tàbí tí ẹ̀rù ń bà. Sólómọ́nì sọ pé: “Ìnilára pàápàá lè mú kí ọlọ́gbọ́n ṣe bí ayírí.” (Oníwàásù 7:7) Ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kéèyàn “kún fún ìhónú sí Jèhófà” pàápàá. (Òwe 19:3) Lọ́nà wo? Nípa dídi ẹ̀bi àwọn ìṣòro wa ru Ọlọ́run, ká wá máa fi èyí ṣe àwíjàre fún àwọn ohun tá à ń ṣe tí kò bá òfin àti ìlànà rẹ̀ mu. Dípò ká máa ronú pé àwa la gbọ́n tán tá a mọ̀ tán, ńṣe ló yẹ ká fi ìrẹ̀lẹ̀ tẹ́tí sáwọn olùgbani-nímọ̀ràn tí wọ́n fẹ́ fi Ìwé Mímọ́ ràn wá lọ́wọ́. Tó bá sì di pé ó pọn dandan, ẹ jẹ́ ká múra tán láti jáwọ́ nínú àwọn èrò tá a kà sí bàbàrà tẹ́lẹ̀ àmọ́ to wá hàn báyìí pé kò tọ̀nà.—Òwe 1:1-5; 15:22.

“Máa Bá A Nìṣó ní Bíbéèrè Lọ́wọ́ Ọlọ́run”

Àkókò tí gbogbo nǹkan ń dojú rú tó sì léwu là ń gbé yìí. Ó ṣe pàtàkì láti máa gbàdúrà sí Jèhófà nígbà gbogbo ká bàa lè ṣe ìpinnu tó tọ́ ká sì fọgbọ́n hùwà. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun, ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run; àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà yín àti agbára èrò orí yín nípasẹ̀ Kristi Jésù.” (Fílípì 4:6, 7) Tó bá ṣẹlẹ̀ pé a ò ní ọgbọ́n tá a nílò láti yanjú àwọn ìṣòro tó lọ́jú pọ̀ tàbí àdánwò, ńṣe ni ká “máa bá a nìṣó ní bíbéèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, nítorí òun a máa fi fún gbogbo ènìyàn pẹ̀lú ìwà ọ̀làwọ́ àti láìsí gíganni.”—Jákọ́bù 1:5-8.

Nítorí pé àpọ́sítélì Pétérù mọ̀ pé ó yẹ kí àwọn Kristẹni bíi tirẹ̀ máa lo ọgbọ́n, ó sapá láti ‘ru agbára ìrònú wọn ṣíṣe kedere sókè.’ Ó fẹ́ kí wọ́n “rántí àwọn àsọjáde tí àwọn wòlíì mímọ́ ti sọ ní ìṣáájú àti àṣẹ Olúwa àti Olùgbàlà,” ìyẹn Jésù Kristi. (2 Pétérù 3:1, 2) Táwa náà bá ṣe bẹ́ẹ̀ tá a sì jẹ́ kí ìrònú wa wà níbàámu pẹ̀lú Ọ̀rọ̀ Jèhófà, àá máa ronú lọ́nà tó ṣe tààrà àá sì máa fọgbọ́n hùwà.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Ọgbọ́n Ọlọ́run làwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ jẹ́ kó darí ọ̀nà tí wọ́n gbà ń ronú, kì í ṣe ìmọ̀ ọgbọ́n orí

[Àwọn Credit Line]

Àwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí, láti apá òsì sí apá ọ̀tún: Epicurus: Fọ́tò tá a yà nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda British Museum; Cicero: A tún un gbé jáde látinú ìwé The Lives of the Twelve Caesars; Plato: Roma, Musei Capitolini

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Àdúrà àti ìkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe pàtàkì