Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Ìránṣẹ́ Jèhófà Ní Ìrètí Tòótọ́

Àwọn Ìránṣẹ́ Jèhófà Ní Ìrètí Tòótọ́

Àwọn Ìránṣẹ́ Jèhófà Ní Ìrètí Tòótọ́

“Àwọn tí ó ṣẹ́ kù nínú Jékọ́bù yóò sì dà bí ìrì láti ọ̀dọ̀ Jèhófà ní àárín ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn . . . [ìyẹn ìrì] tí kì í retí ènìyàn.”—MÍKÀ 5:7.

1. Báwo ni Ísírẹ́lì tẹ̀mí ṣe jẹ́ orísun ìtura?

 JÈHÓFÀ ni Ẹni tí ń mú kí òjò rọ̀ kí ìrì sì máa sẹ̀. Asán lórí asán ni ká máa retí òjò àti ìrì látọ̀dọ̀ èèyàn. Wòlíì Míkà kọ̀wé pé: “Àwọn tí ó ṣẹ́ kù nínú Jékọ́bù yóò sì dà bí ìrì láti ọ̀dọ̀ Jèhófà ní àárín ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ yanturu ọ̀wààrà òjò lórí ewéko, tí kì í retí ènìyàn tàbí kí ó dúró de àwọn ọmọ ará ayé.” (Míkà 5:7) Àwọn wo ni “àwọn tí ó ṣẹ́ kù nínú Jékọ́bù” lóde òní? Àwọn ni Ísírẹ́lì tẹ̀mí, ìyẹn àwọn tó ṣẹ́ kù nínú “Ísírẹ́lì Ọlọ́run.” (Gálátíà 6:16) Lójú “ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn” tó wà lórí ilẹ̀ ayé, wọ́n dà bí “ìrì” tó ń tuni lára “láti ọ̀dọ̀ Jèhófà” àti bí “ọ̀pọ̀ yanturu ọ̀wààrà òjò lórí ewéko.” Bẹ́ẹ̀ ni o, orísun ìtura látọ̀dọ̀ Ọlọ́run làwọn Kristẹni ẹni àmì òróró òde òní jẹ́ fún àwọn èèyàn. Gẹ́gẹ́ bí olùpòkìkí Ìjọba náà, Jèhófà ń lò wọ́n láti sọ nípa ìrètí tòótọ́ fún àwọn èèyàn.

2. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú ayé tó kún fún ìṣòro là ń gbé, èé ṣe tá a fi ní ìrètí tòótọ́?

2 Kò yẹ kó yà wá lẹ́nu pé ayé yìí kò ní ìrètí tòótọ́. Ìlú ò tòrò mọ́, ìwà ọmọlúwàbí ti dàwáàrí, ìwà ọ̀daràn gbòde kan, ètò ìṣúnná owó dẹnu kọlẹ̀, àwọn amòòkùn-ṣìkà ń ṣọṣẹ́, ogun níwá, ogun lẹ́yìn—irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ ò ṣàjèjì nínú ayé tí Sátánì Èṣù ń ṣàkóso rẹ̀. (1 Jòhánù 5:19) Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń bẹ̀rù bí ọjọ́ ọ̀la ṣe máa rí. Àmọ́ àwa olùjọ́sìn Jèhófà ò bẹ̀rù rárá, nítorí pé a ní ìrètí tó dájú pé ọjọ́ ọ̀la ń bọ̀ wá dára. Ìrètí tòótọ́ sì ni nítorí pé orí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run la gbé e kà. A ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà àti nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀, nítorí pé gbogbo ìlérí rẹ̀ ló ń mú ṣẹ.

3. (a) Kí nìdí tí Jèhófà fi máa fìyà jẹ Ísírẹ́lì àti Júdà? (b) Kí nìdí tí àwọn ọ̀rọ̀ Míkà fi kàn wá lónìí?

3 Àsọtẹ́lẹ̀ Míkà tí Ọlọ́run mí sí ń fún wa lókun láti rìn ní orúkọ Jèhófà, ó sì jẹ́ ká nírètí tòótọ́. Nígbà tí Míkà sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ ní ọ̀rúndún kẹjọ ṣááju Sànmánì Tiwa, orílẹ̀-èdè méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ la pín àwọn èèyàn tí Ọlọ́run bá dá májẹ̀mú sí nígbà yẹn—ìyẹn Ísírẹ́lì àti Júdà—àwọn méjèèjì ni kò sì ka májẹ̀mú Ọlọ́run sí. Ìdí nìyẹn tí ìjọba méjèèjì fi di èyí tó kún fún ìwà ìbàjẹ́, táwọn èèyàn ibẹ̀ di apẹ̀yìndà, tí wọ́n sì wá nífẹ̀ẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́nì bí nǹkan míì. Ìyẹn ló mú kí Jèhófà sọ pé òun máa fìyà jẹ wọ́n. Lóòótọ́, àwọn èèyàn tó wà nígbà ayé Míkà ni Ọlọ́run darí àwọn ọ̀rọ̀ yìí sí. Àmọ́ àwọn ọ̀rọ̀ Míkà yìí tún kàn wá lóde òní nítorí pé bí ipò nǹkan ṣe rí lákòókò tiwa yìí bá ti àkókò Míkà mu gan-an. Èyí yóò ṣe kedere bá a ṣe ń gbé àwọn kókó pàtàkì bíi mélòó kan yẹ̀ wò látinú orí méje tí ìwé Míkà ní.

Àwọn Ohun Tá A Rí Nínú Ìwé Míkà

4. Àwọn ìsọfúnni pàtàkì wo la rí nínú Míkà orí kìíní sí ìkẹta?

4 Ẹ jẹ́ ká sáré wo àwọn kókó pàtàkì tó wà nínú ìwé Míkà. Ní orí Kìíní, Jèhófà fi ìdìtẹ̀ Ísírẹ́lì àti Júdà hàn kedere. Nítorí àìgbọràn wọn, a ó pa Ísírẹ́lì run, ìyà Júdà yóò sì nasẹ̀ dé ẹnubodè Jerúsálẹ́mù pàápàá. Orí kejì fi hàn pé àwọn ọlọ́rọ̀ àtàwọn alágbára ń fìyà jẹ àwọn ẹni rírẹlẹ̀ àtàwọn tí kò ní olùrànlọ́wọ́. Síbẹ̀, Ọlọ́run ṣe ìlérí kan. A óò kó àwọn èèyàn Ọlọ́run jọpọ̀. Orí kẹta kéde bí Jèhófà ṣe máa dá àwọn aṣáájú orílẹ̀-èdè lẹ́jọ́ àtàwọn àlùfáà tí kò mọṣẹ́ wọn níṣẹ́. Àwọn aṣáájú ń yí ìdájọ́ po, àwọn àlùfáà sì ń parọ́. Láìfi èyí pè, ẹ̀mí mímọ́ fún Míkà lágbára láti kéde ìdájọ́ Jèhófà tó ń bọ̀.

5. Àwọn kókó ọ̀rọ̀ wo ló wà nínú Míkà orí kẹrin àti ìkarùn-ún?

5 Orí kẹrin sọ tẹ́lẹ̀ pé ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́, gbogbo orílẹ̀-èdè yóò wá sí òkè ńlá ilé Jèhófà láti gba ìtọ́ni lọ́dọ̀ rẹ̀. Àmọ́ kíyẹn tó ṣẹlẹ̀, Júdà yóò lọ sí ìgbèkùn ní Bábílónì, ṣùgbọ́n Jèhófà yóò dá a nídè. Orí kárùn-ún fi hàn pé a óò bí Mèsáyà ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ti Júdà. Yóò darí àwọn èèyàn rẹ̀, yóò sì dá wọn nídè kúrò lọ́wọ́ àwọn orílẹ̀-èdè tó ń ni wọ́n lára.

6, 7. Àwọn kókó pàtàkì wo ló wà nínú orí kẹfà àti ìkeje àsọtẹ́lẹ̀ Míkà?

6 Àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí Jèhófà kà sí àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́rùn ló wà nínú Míkà orí kẹfà. Kí ni Jèhófà ṣe tó mú káwọn èèyàn rẹ̀ ṣọ̀tẹ̀? Kò sí. Ká sọ tòótọ́, àwọn ohun tó béèrè kò le rárá. Ó fẹ́ káwọn olùjọ́sìn òun máa ṣe ìdájọ́ òdodo, kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ inú rere, kí wọ́n sì jẹ́ ẹni tó mẹ̀tọ́mọ̀wà bí wọ́n ti ń bá òun rìn. Dípò tí wọn ì bá fi ṣèyẹn, Ísírẹ́lì àti Júdà ṣọ̀tẹ̀, wọ́n sì gbọ́dọ̀ jìyà ohun tí wọ́n ṣe.

7 Ní orí tó kẹ́yìn àsọtẹ́lẹ̀ Míkà Mik 7 , ó bẹnu àtẹ́ lu ìwà ibi táwọn tí wọ́n jọ gbé ayé lákòókò kan náà ń hù. Àmọ́, kò jẹ́ kíyẹn kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá òun, nítorí pé ó ti pinnu láti “fi ẹ̀mí ìdúródeni hàn” sí Jèhófà. (Míkà 7:7) Ohun tó parí ìwé náà ni ọ̀rọ̀ tó fúnni lẹ́rìí ìdánilójú pé Jèhófà yóò fi àánú hàn sí àwọn èèyàn rẹ̀. Ìtàn fi hàn pé ìrètí yìí kò já sásán. Ní ọdún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa, nígbà tí Jèhófà bá àwọn èèyàn rẹ̀ wí tán, ó fi tàánútàánú dá àwọn tó ṣẹ́ kù padà sí ilẹ̀ wọn.

8. Báwo lo ṣe máa ṣàkópọ̀ ohun tó wà nínú ìwé Míkà?

8 Ẹ ò rí i pé ìsọfúnni àtàtà ni Jèhófà tipasẹ̀ Míkà sọ yìí! Ìwé onímìísí yìí jẹ́ ká mọ irú ọwọ́ tí Ọlọ́run fi ń mú àwọn tó bá sọ pé àwọn ń sìn ín àmọ́ tí wọ́n jẹ́ aláìṣòótọ́. Ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń wáyé lóde òní. Ó wá fún wa ní ìmọ̀ràn àtọ̀runwá lórí bá a ó ṣe hùwà láwọn àkókò líle koko yìí, kí ìrètí wa lè fẹsẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in.

Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ Sọ̀rọ̀

9. Gẹ́gẹ́ bí ìwé Míkà 1:2 ti wí, kí ni Jèhófà sọ pé òun máa ṣe?

9 Ẹ jẹ́ ká wá gbé ìwé Míkà yẹ̀ wò kínníkínní báyìí. Míkà 1:2 kà pé: “Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ènìyàn, gbogbo yín; fetí sílẹ̀, ìwọ ilẹ̀ ayé àti ohun tí ó kún inú rẹ, sì jẹ́ kí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí lòdì sí yín, Jèhófà láti inú tẹ́ńpìlì mímọ́ rẹ̀ wá.” Ká sọ pé o wà láyé nígbà ayé Míkà, ó dájú pé àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn ì bá gba àfiyèsí rẹ. Láìṣe àní-àní, ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn gba àfiyèsí rẹ nítorí pé Jèhófà ló ń sọ̀rọ̀ látinú tẹ́ńpìlì mímọ́ rẹ̀. Kò darí ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí Ísírẹ́lì àti Júdà nìkan àmọ́ ó tún darí rẹ̀ sí àwọn èèyàn níbi gbogbo. Àwọn èèyàn ti kọ Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sílẹ̀ fún àkókò gígùn gan-an nígbà ayé Míkà. Ìyẹn yóò yí padà láìpẹ́. Jèhófà ṣe tán láti gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ lórí ọ̀ràn náà.

10. Èé ṣe táwọn ọ̀rọ̀ inú Míkà 1:2 fi ṣe pàtàkì fún wa?

10 Bákan náà lọ̀rọ̀ rí lákòókò tiwa. Ìṣípayá 14:18-20 fi hàn pé Jèhófà tún ń báni sọ̀rọ̀ látinú tẹ́ńpìlì mímọ́ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i. Láìpẹ́, yóò yanjú àwọn ẹni ibi, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mánigbàgbé yóò sì tún mi ayé tìtì. Lọ́tẹ̀ yìí, “àjàrà ilẹ̀ ayé” búburú yìí ni a ó fi sọ̀kò sínú ìfúntí wáìnì ìbínú Jèhófà, kí ó lè pa ètò Sátánì run yán-ányán-án.

11. Kí ni àwọn ọ̀rọ̀ inú Míkà 1:3, 4 túmọ̀ sí?

11 Fetí sí ohun tí Jèhófà máa ṣe. Míkà 1:3, 4 sọ pé: “Wò ó! Jèhófà ń jáde lọ láti ipò rẹ̀, dájúdájú, òun yóò sọ̀ kalẹ̀ wá, yóò sì tẹ àwọn ibi gíga ilẹ̀ ayé mọ́lẹ̀. Àwọn òkè ńlá yóò sì yọ́ lábẹ́ rẹ̀, àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ yóò sì pínyà, bí ìda nítorí iná, bí omi tí a dà sórí ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́.” Ṣé Jèhófà yóò wá fi ibùgbé rẹ̀ ní ọ̀run sílẹ̀ ni, tí yóò sì wá máa tẹ àwọn òkè ńlá àtàwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ilẹ̀ Ìlérí mọ́lẹ̀? Rárá o. Kò ní ṣe bẹ́ẹ̀. Yóò wulẹ̀ darí àfiyèsí rẹ̀ sórí ilẹ̀ ayé ni kí ìfẹ́ rẹ̀ lè di ṣíṣe. Àti pé, kì í ṣe ilẹ̀ ayé gan-an là ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ bí kò ṣe àwọn olùgbé inú rẹ̀ tó máa jìyà àwọn ohun tá a ṣàpèjúwe wọ̀nyẹn. Nígbà tí Jèhófà bá dá sí ọ̀ràn náà, àbájáde rẹ̀ yóò burú jáì fún àwọn aláìṣòótọ́—ńṣe ni yóò dà bíi pé àwọn òkè ńlá ti yọ́ bí ìda, tí ìsẹ̀lẹ̀ sì ti mi àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ tìtì.

12, 13. Ní ìbámu pẹ̀lú 2 Pétérù 3:10-12, kí ló mú kí ìrètí wa dájú?

12 Àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ inú Míkà 1:3, 4 lè rán ọ létí àsọtẹ́lẹ̀ onímìísí mìíràn tó sọ nípa àwọn àjálù lórí ilẹ̀ ayé. Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú 2 Pétérù 3:10, àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé pé: “Ọjọ́ Jèhófà yóò dé gẹ́gẹ́ bí olè, nínú èyí tí àwọn ọ̀run yóò kọjá lọ pẹ̀lú ariwo tí ó dún ṣì-ì-ì, ṣùgbọ́n àwọn ohun ìpìlẹ̀ tí ó ti gbóná janjan yóò di yíyọ́, ilẹ̀ ayé àti àwọn iṣẹ́ tí ń bẹ nínú rẹ̀ ni a ó sì wá rí.” Bíi ti àsọtẹ́lẹ̀ Míkà, ọ̀rọ̀ Pétérù kò tọ́ka sí àjùlé ọ̀run àti ayé ní ti gidi. Ó tọ́ka sí ìpọ́njú ńlá tó ń bọ̀ sórí ayé aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run yìí.

13 Láìfi àjálù tó ń bọ̀ náà pè, àwọn Kristẹni lè ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé ọjọ́ ọ̀la yóò dára, bí Míkà ti ṣe. Lọ́nà wo? Nípa títẹ̀lé ìmọ̀ràn tó wà nínú àwọn ẹsẹ tó tẹ̀ lé ìyẹn nínú lẹ́tà Pétérù. Àpọ́sítélì náà sọ pé: “Irú ènìyàn wo ni ó yẹ kí ẹ jẹ́ nínú ìṣe ìwà mímọ́ àti àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run, ní dídúró de wíwàníhìn-ín ọjọ́ Jèhófà àti fífi í sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí!” (2 Pét. 3:11, 12) Ìrètí wa fún ọjọ́ ọ̀la yóò dájú bí a bá jẹ́ onígbọràn, tí a sì rí i dájú pé ìwà wa jẹ́ mímọ́, tí ìgbésí ayé wa kún fún àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run. Kí ìrètí wa lè dájú, a tún ní láti máa rántí pé ọjọ́ Jèhófà yóò dé dandan.

14. Kí nìdí tó fi yẹ kí Ísírẹ́lì àti Júdà jìyà?

14 Jèhófà ṣàlàyé ìdí táwọn èèyàn òun ìgbàanì fi gbọ́dọ̀ jìyà. Míkà 1:5 sọ pé: “Gbogbo èyí jẹ́ nítorí ìdìtẹ̀ Jékọ́bù, àní nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ilé Ísírẹ́lì. Kí ni ìdìtẹ̀ Jékọ́bù? Kì í ha ṣe Samáríà bí? Kí sì ni àwọn ibi gíga Júdà? Wọn kì í ha ṣe Jerúsálẹ́mù bí?” Jèhófà ló jẹ́ kí Ísírẹ́lì àti Júdà wà. Síbẹ̀, wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí i, ìṣọ̀tẹ̀ wọn sì ti dé inú àwọn olú ìlú wọn, ìyẹn Samáríà àti Jerúsálẹ́mù.

Ìwà Búburú Gbòde Kan

15, 16. Ìwà ibi wo ni àwọn tó gbé ayé ní àkókò Míkà jẹ̀bi rẹ̀?

15 Àpẹẹrẹ ìwà ibi àwọn tó gbé ayé ní àkókò Míkà la ṣàpèjúwe rẹ̀ nínú Míkà 2:1, 2, pé: “Ègbé ni fún àwọn tí ń pète-pèrò ohun apanilára, àti fún àwọn tí ń fi ohun búburú ṣe ìwà hù, lórí ibùsùn wọn! Ìgbà ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ṣe é, nítorí pé ó wà ní agbára ọwọ́ wọn. Ojú wọn sì ti wọ pápá, wọ́n sì ti já wọn gbà; àti àwọn ilé pẹ̀lú, wọ́n sì ti gbà wọ́n; wọ́n sì ti lu abarapá ọkùnrin àti agbo ilé rẹ̀ ní jìbìtì, ènìyàn àti ohun ìní àjogúnbá rẹ̀.”

16 Àwọn oníwọra kì í sùn lóru, ńṣe ni wọ́n ń pète-pèrò báwọn ṣe máa gba oko àti ilé àwọn aládùúgbò wọn. Gbàrà tí ilẹ̀ bá mọ́ ni wọ́n á gbéra láti lọ ṣe ohun tí wọ́n pète-pèrò rẹ̀. Wọn ò ní hu irú ìwà ibi bẹ́ẹ̀ ká ní wọ́n rántí májẹ̀mú Jèhófà ni. Àwọn ìlànà tó ń dáàbò bo àwọn tálákà wà nínú Òfin Mósè. Lábẹ́ Òfin náà, kò sí ìdílé tó gbọ́dọ̀ pàdánù ogún rẹ̀ pátápátá. Àmọ́, àwọn oníwọra ò fìyẹn pè rárá. Wọ́n kọ etí ikún sí ọ̀rọ̀ tó wà nínú Léfítíkù 19:18, tó sọ pé: “Kí ìwọ . . . nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.”

17. Kí ló lè ṣẹlẹ̀ nígbà táwọn tó sọ pé àwọn ń sin Ọlọ́run bá ń sáré àtilà kiri?

17 Èyí fi ohun tó lè ṣẹlẹ̀ hàn nígbà táwọn tó sọ pé àwọn ń sin Ọlọ́run bá pa góńgó tẹ̀mí tì, tó sì wá jẹ́ pé eré àtilà ni wọ́n ń sá kiri. Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ fáwọn Kristẹni ìgbà ayé rẹ̀ pé: “Àwọn tí ó pinnu láti di ọlọ́rọ̀ máa ń ṣubú sínú ìdẹwò àti ìdẹkùn àti ọ̀pọ̀ ìfẹ́-ọkàn tí í ṣe ti òpònú, tí ó sì ń ṣeni lọ́ṣẹ́, èyí tí ń ri ènìyàn sínú ìparun àti ègbé.” (1 Tímótì 6:9) Nígbà téèyàn bá fi owó níní ṣe olórí ohun tó ń lépa nínú ìgbésí ayé, ohun tónítọ̀hún ń ṣe, lẹ́nu kan, ni pé ó ń sin ọlọ́run èké—ìyẹn Ọrọ̀. Ọlọ́run èké yẹn kò lè fúnni ní ìrètí dídájú kankan fún ọjọ́ ọ̀la.—Mátíù 6:24.

18. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sáwọn tó nífẹ̀ẹ́ ọ̀rọ̀ àlùmọ́ọ́nì nígbà ayé Míkà?

18 Ojú ọ̀pọ̀ èèyàn rí màbo nígbà ayé Míkà kí wọ́n tó mọ̀ pé asán lórí asán ni kéèyàn máa gbára lé ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Míkà 2:4 wí, Jèhófà sọ pé: “Ní ọjọ́ yẹn, ẹnì kan yóò gbé ọ̀rọ̀ òwe dìde nípa yín, yóò sì ṣe ìdárò dájúdájú, àní ìdárò. Ẹnì kan yóò sì sọ pé: ‘A ti fi wá ṣe ìjẹ dájúdájú! Àní ìpín àwọn ènìyàn mi ni ó mú ìyípadà bá. Ẹ wo bí ó ti mú un kúrò lọ́dọ̀ mi tó! Ó fi pápá wa fún aláìṣòótọ́.’” Bẹ́ẹ̀ ni o, àwọn tó ń jí ilé àti pápá wọ̀nyẹn yóò pàdánù ogún ìdílé tiwọn pẹ̀lú. A óò kó wọn lọ sí ilẹ̀ àjèjì, àwọn ohun ìní wọn yóò sì di ìjẹ fún àwọn “aláìṣòótọ́,” tàbí èèyàn àwọn orílẹ̀-èdè. Gbogbo ìrètí wọn fún ọjọ́ iwájú aláásìkí yóò sì di asán.

19, 20. Báwo ni nǹkan ṣe rí fún àwọn Júù tó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà?

19 Àmọ́ ṣá o, ìrètí àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà kò ní já sófo. Jèhófà kò ní da àwọn májẹ̀mú tó bá Ábúráhámù àti Dáfídì dá, ó sì fi àánú hàn sí àwọn bíi Míkà tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, tí wọ́n sì ń kẹ́dùn lórí bí àwọn èèyàn ṣe ya ara wọn nípa sí Ọlọ́run. Tìtorí irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ ni ìmúpadàbọ̀sípò ṣe wáyé nígbà tí àkókò tó lójú Ọlọ́run.

20 Ìyẹn wáyé lọ́dún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa, lẹ́yìn tí Bábílónì ṣubú àti nígbà tí àṣẹ́kù àwọn Júù padà bọ̀ wálé. Àkókò yẹn ni ọ̀rọ̀ Míkà 2:12 ní ìmúṣẹ rẹ̀ àkọ́kọ́. Jèhófà sọ pé: “Èmi yóò kó Jékọ́bù jọ dájúdájú, gbogbo yín; láìsí àní-àní, èmi yóò kó àwọn tí ó ṣẹ́ kù nínú Ísírẹ́lì jọpọ̀. Èmi yóò gbé wọn kalẹ̀ ní ìṣọ̀kan, bí agbo ẹran nínú ọgbà ẹran, bí agbo ẹran ọ̀sìn láàárín pápá ìjẹko rẹ̀; ibẹ̀ yóò sì kún fún ariwo àwọn ènìyàn.” Jèhófà mà nífẹ̀ẹ́ o! Lẹ́yìn tó bá àwọn èèyàn rẹ̀ wí tán, ó jẹ́ káwọn tó ṣẹ́ kù padà wá sin òun ní ilẹ̀ tó fún àwọn baba ńlá wọn.

Ìjọra Tó Kàmàmà ní Àkókò Wa

21. Báwo ni ipò nǹkan lóde òní ṣe jọ ti àkókò Míkà?

21 Bá a ṣe ń gbé àwọn ẹsẹ wọ̀nyí yẹ̀ wò látinú orí méjì àkọ́kọ́ nínú ìwé Míkà, ǹjẹ́ o rí i pé àwọn ohun kan náà ń ṣẹlẹ̀ lóde òní? Gẹ́gẹ́ bó ṣe rí nígbà ayé Míkà, ọ̀pọ̀ ló sọ pé àwọn ń sin Ọlọ́run lóde òní. Síbẹ̀, bíi ti Júdà àti Ísírẹ́lì, wọ́n pínyà, wọ́n sì ń bá ara wọn jagun. Ọ̀pọ̀ àwọn tó jẹ́ ọlọ́rọ̀ ní Kirisẹ́ńdọ̀mù ló ń ni àwọn tálákà lára. Ńṣe ni iye àwọn aṣáájú ìsìn tó ń fàyè gba àwọn àṣà tí Bíbélì kà léèwọ̀ túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Abájọ tí Kirisẹ́ńdọ̀mù yóò fi parun láìpẹ́, tòun ti ìyókù “Bábílónì Ńlá,” ìyẹn ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé! (Ìṣípayá 18:1-5) Síbẹ̀síbẹ̀, níbàámu pẹ̀lú ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà ayé Míkà, Jèhófà tún ní àwọn ìránṣẹ́ olóòótọ́ tó ṣẹ́ kù sórí ilẹ̀ ayé.

22. Àwọn ẹgbẹ́ méjì wo ló gbé ìrètí wọn ka Ìjọba Ọlọ́run?

22 Ní ọdún 1919, àwọn Kristẹni olóòótọ́ tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró ya ara wọn sọ́tọ̀ pátápátá kúrò lọ́dọ̀ Kirisẹ́ńdọ̀mù, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí kéde ìhìn rere Ìjọba náà fún gbogbo orílẹ̀-èdè. (Mátíù 24:14) Àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn tó jẹ́ Ísírẹ́lì tẹ̀mí ni wọ́n kọ́kọ́ wá kàn. Ẹ̀yìn ìyẹn ni “àwọn àgùntàn mìíràn” wá dara pọ̀ mọ́ wọn, tí ẹgbẹ́ méjèèjì sì wá di “agbo kan, olùṣọ́ àgùntàn kan.” (Jòhánù 10:16) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti ń sin Ọlọ́run ní igba ó lé mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n [234] ilẹ̀ báyìí, síbẹ̀ gbogbo àwọn olóòótọ́ olùjọ́sìn fún Jèhófà wọ̀nyí ló wà “ní ìṣọ̀kan” ní ti tòótọ́. Àti pé nísinsìnyí, agbo àgùntàn náà ti “kún fún ariwo àwọn ènìyàn,” ìyẹn àwọn ọkùnrin, obìnrin, ọmọdé àti àgbà. Wọn ò gbé ìrètí wọn ka ètò àwọn nǹkan yìí, bí kò ṣe Ìjọba Ọlọ́run, èyí tí yóò mú Párádísè padà bọ̀ sórí ilẹ̀ ayé láìpẹ́.

23. Kí nìdí tó o fi gbà pé ìrètí rẹ dájú?

23 Nígbà tí ẹsẹ tó kẹ́yìn Míkà orí kejì ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn olùjọsìn tòótọ́ fún Jèhófà, ó ní: “Ọba wọn yóò sì kọjá lọ níwájú wọn, Jèhófà yóò sì wà ní ipò orí wọn.” Ǹjẹ́ o rí ara rẹ nínú àwọn tó tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ tí wọ́n ń yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun yìí, tí o sì ń tẹ̀ lé Jésù Kristi Ọba rẹ, pẹ̀lú Jèhófà fúnra rẹ̀ tó jẹ́ aṣáájú? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, mọ̀ pé ìṣẹ́gun ìkẹyìn ti dé tán, ìrètí rẹ sì dájú. Èyí yóò túbọ̀ ṣe kedere sí i bá a ṣe ń ṣàyẹ̀wò àwọn kókó pàtàkì inú àsọtẹ́lẹ̀ Míkà síwájú sí i.

Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?

• Èé ṣe tí Jèhófà fi pinnu láti fìyà jẹ Júdà àti Ísírẹ́lì nígbà ayé Míkà?

• Kí ló lè ṣẹlẹ̀ nígbà táwọn tó sọ pé àwọn ń sin Ọlọ́run bá ń sáré àtilà kiri?

• Lẹ́yìn tá a gbé Míkà orí kìíní àti ìkejì yẹ̀ wò, kí nìdí tó o fi gbà pé ìrètí rẹ dájú?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Àsọtẹ́lẹ̀ Míkà lè fún wa lókun nípa tẹ̀mí

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Bíi tàwọn Júù tó ṣẹ́ kù ní ọdún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa, Ísírẹ́lì tẹ̀mí àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn ń gbé ìjọsìn tòótọ́ lárugẹ