Ǹjẹ́ O Rántí?
Ǹjẹ́ O Rántí?
Ǹjẹ́ o gbádùn kíka àwọn Ilé Ìṣọ́ tó jáde lẹ́nu àìpẹ́ yìí? Tóò, wò ó bóyá wàá lè dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e wọ̀nyí:
• Àwọn ọ̀nà díẹ̀ wo ni Rúùtù gbà jẹ́ àpẹẹrẹ rere fún wa?
Ó ta yọ nínú ìfẹ́ tó ní fún Jèhófà, nínú ìfẹ́ ìdúróṣinṣin tó ní fún Náómì, àti bó ṣe jẹ́ òṣìṣẹ́ aláápọn àti onírẹ̀lẹ̀. Ìdí rèé táwọn èèyàn fi kà á sí “obìnrin títayọ lọ́lá.” (Rúùtù 3:11)—4/15, ojú ìwé 23-26.
• Báwo la ṣe mọ̀ pé Jèhófà ń bójú tó àwọn mẹ̀kúnnù?
Ó sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì táwọn èèyàn ti hàn léèmọ̀ ní Íjíbítì, pé wọn ò gbọ́dọ̀ ṣàìdáa sáwọn mẹ̀kúnnù. (Ẹ́kísódù 22:21-24) Jésù, tó fara wé Baba rẹ̀, fi ìfẹ́ tòótọ́ hàn sáwọn gbáàtúù èèyàn. Àwọn èèyàn “tí kò mọ̀wé àti gbáàtúù” ló sì yàn láti jẹ́ àpọ́sítélì rẹ̀. (Ìṣe 4:13; Mátíù 9:36) A lè ṣàfarawé Ọlọ́run nípa ṣíṣe aájò àwọn ẹlòmíràn irú bíi àwọn ọmọdé.—4/15, ojú ìwé 28-30.
• Báwo ló ṣe dá wa lójú pé Jèhófà ń kíyè sí ohun tá a ń ṣe?
Àwọn àkọsílẹ̀ inú Bíbélì fi hàn pé Jèhófà kíyè sáwọn àṣeyọrí táwọn èèyàn ṣe. Ó kíyè sí ẹbọ tí Ébẹ́lì rú, ó sì tún ń kíyè sí ‘ẹbọ ìyìn tá a ń rú, ìyẹn èso ètè.’ (Hébérù 13:15) Jèhófà mọ̀ pé ìsapá ńláǹlà ni Énọ́kù ṣe láti múnú rẹ̀ dùn nípa gbígbé ìgbésí ayé tó mọ́ tó sì hùwà rere. Bákan náà ni Ọlọ́run tún kíyè sí bí opó kan tí kì i ṣe ọmọ Ísírẹ́lì, tó ń gbé ìlú Sáréfátì ṣe fún wòlíì Èlíjà nínú ìwọ̀nba oúnjẹ tó ní. Bákan náà ni Jèhófà ṣe ń kíyè sí àwọn ohun tá a ń fi ìgbàgbọ́ ṣe.—5/1, ojú ìwé 28-31.
• Kí nìdí tá a fi lè sọ pé àwọn Júù tí wọ́n di Kristẹni lẹ́yìn Pẹ́ńtíkọ́sì 33 Sànmánì Tiwa, gbọ́dọ̀ ya ara wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run?
Lọ́dún 1513, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì di ẹni tá a yà sí mímọ́ fún Jèhófà. (Ẹ́kísódù 19:3-8) Inú orílẹ̀-èdè tó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ lábẹ́ májẹ̀mú Òfin yìí la sì bí àwọn ìrandíran àwọn Júù sí. Àmọ́ Jèhófà mú májẹ̀mú Òfin náà kúrò nípasẹ̀ ikú Kristi ní ọdún 33 Sànmánì Tiwa. (Kólósè 2:14) Látìgbà náà, àwọn Júù tí wọ́n bá fẹ́ kí Ọlọ́run gba ìjọsìn àwọn gbọ́dọ̀ ya ara wọn sí mímọ́ fún un kí wọ́n sì ṣèrìbọmi lórúkọ Jésù Kristi.—5/15, ojú ìwé 30-31.
• Ǹjẹ́ ó lóhun tí tùràrí sísun ń ṣe nínú ìjọsìn tòótọ́ lónìí?
Tùràrí sísun jẹ́ apá kan ìjọsìn tòótọ́ ní Ísírẹ́lì ìgbàanì. (Ẹ́kísódù 30:37, 38; Léfítíkù 16:12, 13) Ṣùgbọ́n májẹ̀mú Òfin, tó fi dórí tùràrí sísun, dópin nígbà tí Kristi kú. Àwọn Kristẹni lè fúnra wọn yàn yálà láti lo tùràrí láyè ara wọn láìlò ó fún ohun tó jẹ mọ́ ti ẹlẹ́sìn dé, àmọ́ tùràrí kò ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú ìjọsìn mímọ́ lónìí. Ó tún yẹ láti gba tàwọn ẹlòmíràn rò ká má bàa mú wọn kọsẹ̀.—6/1, ojú ìwé 28-30.
• Kí lohun náà tí òkìkí rẹ̀ kàn nínú ìròyìn láìpẹ́ yìí tó mú kí ọ̀pọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí tún inú rò pé lóòótọ́ ni Jésù wá sáyé?
Láìpẹ́ yìí, òkìkí kàn nípa àpótí kan tí wọ́n kó eegun òkú sí. Wọ́n rí àpótí náà ní Ísírẹ́lì. Ó dà bí ẹni pé ọ̀rúndún kìíní ló ti wà, wọ́n sì kọ ọ̀rọ̀ sára rẹ̀ pé: “Jákọ́bù, ọmọ Jósẹ́fù, arákùnrin Jésù.” Àwọn kan sọ pé èyí ló máa jẹ́ “ẹ̀rí tó yàtọ̀ sí tinú Bíbélì tó sì lọ́jọ́ lórí jù lọ” tó fi hàn pé Jésù wá sáyé.—6/15, ojú ìwé 3-4.
• Báwo Lèèyàn Ṣe Lè Kọ́ Bá A Ṣe Ń Nífẹ̀ẹ́?
Ibi táwọn èèyàn ti kọ́kọ́ máa ń kọ́ bá a ṣe ń nífẹ̀ẹ́ ni ìgbà tí wọ́n bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àti ẹ̀kọ́ àwọn òbí wọn. Àwọn ọmọ yóò kọ́ béèyàn ṣe ń nífẹ̀ẹ́ bí ọkọ àti aya bá ń fìfẹ́ hàn síra wọn tí wọ́n sì ń bọ̀wọ̀ fúnra wọn. (Éfésù 5:28; Títù 2:4) ) Kódà, ẹni tá a tọ́ dàgbà níbi tí kò ti sí ìfẹ́ pàápàá lè kẹ́kọ̀ọ́ láti ní ìfẹ́ nípa títẹ̀lé ìlànà Jèhófà, nípa wíwá ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí mímọ́ àti nípa jíjàǹfààní látinú ìtìlẹ́yìn ẹgbẹ́ ará tí wọ́n jẹ́ Kristẹni kárí ayé.—7/1, ojú ìwé 4-7.
• Ta ni Yùsíbíọ̀sì, ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ nínú ìtàn ìgbésí ayé rẹ̀?
Yùsíbíọ̀sì jẹ́ òpìtàn ìgbà láéláé, ní ọdún 324 ṣáájú Sànmánì Tiwa, ó parí ìwé alápá mẹ́wàá tó pe àkọlé rẹ̀ ní History of the Christian Church. Òótọ́ ni Yùsíbíọ̀sì gbà gbọ́ pé Baba ti wà ṣáájú Ọmọ, àmọ́ ọ̀tọ̀ ni èrò tó fara mọ́ níbi àpérò kan tó wáyé ní Nicaea. Ó hàn gbangba pé kò ka ohun tí Jésù sọ sí pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn Rẹ̀ kì í “ṣe apá kan ayé.” (Jòhánù 17:16)—7/15, ojú ìwé 29-31.
• Ṣé ojú tí Jèhófà fi ń wo ìkóbìnrinjọ ti yí padà ni?
Rárá o, ojú tí Jèhófà fi ń wo ìkóbìnrinjọ kò tíì yí padà. (Málákì 3:6) Ètò tí Ọlọ́run ṣe fún ọkùnrin àkọ́kọ́ ni pé kó “fà mọ́ aya rẹ̀” káwọn méjèèjì sì di ara kan. (Jẹ́nẹ́sísì 2:24) Jésù sọ pé kíkọ ọkọ tàbí aya ẹni sílẹ̀ láìṣe nítorí ìwà pálapàla, ká sì wá fẹ́ ẹlòmíràn ń sọ èèyàn di panṣágà. (Mátíù 19:4-6, 9) Àyè tí Jèhófà fi gba ìkóbìnrinjọ dópin nígbà tá a dá ìjọ Kristẹni sílẹ̀.—8/1, ojú ìwé 28.