Nígbà kan Rí àti Nísinsìnyí—Bí Bíbélì Ṣe Yí Ọkùnrin Yìí Padà
“Ẹ Sún Mọ́ Ọlọ́run, Yóò Sì Sún Mọ́ Yín”
Nígbà kan Rí àti Nísinsìnyí—Bí Bíbélì Ṣe Yí Ọkùnrin Yìí Padà
ORIN ló ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé Rolf-Michael. Oògùn olóró sì ti di bárakú fún un. Nígbà tó ṣì wà ní ọ̀dọ́ ní Jámánì, ó ń mu ọtí àmuyíràá, bẹ́ẹ̀ náà ló ń mu igbó, ó tún ń mu kokéènì àtàwọn oògùn olóró mìíràn.
Ibi tí Rolf-Michael ti ń wá ọ̀nà láti ṣe fàyàwọ́ oògùn olóró wọ orílẹ̀-èdè kan ní ilẹ̀ Áfíríkà lọwọ́ àwọn agbófinró ti bà á, ó sì ṣẹ̀wọ̀n ọdún kan àti oṣù kan. Àkókò tó lò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n yìí mú kó ronú nípa ohun tí ìgbésí ayé túmọ̀ sí.
Rolf-Michael àti Ursula, aya rẹ̀ sapá gan-an láti mú kí ìgbésí ayé wọn nítumọ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n ń wá òtítọ́ kiri. Bó tilẹ̀ jẹ pé ọ̀pọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì tí wọ́n lọ ni wọ́n ti já wọn kulẹ̀, síbẹ̀ ó ṣì wù wọ́n gan-an láti mọ Ọlọ́run. Àwọn ìbéèrè tó ń gbé wọn lọ́kàn pọ̀ gan-an, wọn ò sì tíì rí ìdáhùn tó tẹ́ wọn lọ́rùn nínú onírúurú ẹ̀sìn tí wọ́n lọ. Kò tán síbẹ̀ o, àwọn ẹ̀sìn yìí kò sún wọn láti yí ìgbésí ayé wọn padà.
Nígbà tó yá, Rolf-Michael àti Ursula bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pàdé. Nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìmọ̀ràn tó wà nínú Bíbélì pé: “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín,” wọ Rolf-Michael lọ́kàn gan-an. (Jákọ́bù 4:8) Ó pinnu pé òun máa ‘bọ́ ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà sílẹ̀, èyí tí ó bá ìwà rẹ̀ àtijọ́ mu, òun á sì gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀, èyí tí a dá ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run nínú òdodo tòótọ́ àti ìdúróṣinṣin.’—Éfésù 4:22-24.
Ọ̀nà wo ni Rolf-Michael lè gbà gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀? Wọ́n fi hàn án nínú Bíbélì pé “nípasẹ̀ ìmọ̀ pípéye,” ìwà ẹnì kan lè “di tuntun . . . ní ìbámu pẹ̀lú àwòrán Ẹni tí ó dá a,” ìyẹn Jèhófà Ọlọ́run.—Kólósè 3:9-11.
Bí Rolf-Michael ṣe ń gba ìmọ̀ pípéye sínú, ó bẹ̀rẹ̀ sí sapá láti mú kí ìgbésí ayé rẹ̀ wà níbàámu pẹ̀lú àwọn ìlànà inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Jòhánù 17:3) Kò rọrùn fún Rolf-Michael láti fi oògùn olóró sílẹ̀, àmọ́ ó rí i pé ó ṣe pàtàkì gan-an kí òun gbàdúrà sí Jèhófà kó lè ran òun lọ́wọ́. (1 Jòhánù 5:14, 15) Ó tún rí ìrànlọ́wọ́ gbà sí i nínú bó ṣe ń bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kẹ́gbẹ́, tí wọ́n ń sapá láti ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́.
Ohun mìíràn tó tún ran Rolf-Michael lọ́wọ́ ni ẹ̀kọ́ tó kọ́ pé ayé yìí ń kọjá lọ àti pé kìkì àwọn tó ń ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ló máa wà lórí ilẹ̀ ayé títí láé. Èyí ló jẹ́ kó yan ìbùkún ayérayé, ìyẹn àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́ náà Jèhófà, tí kò sì yan ìfẹ́ ayé yìí tí kò ní pẹ́ kọjá lọ. (1 Jòhánù 2:15-17) Ọ̀rọ̀ tó wà nínú Òwe 27:11 wọ Rolf-Michael lọ́kàn gan-an, èyí tó sọ pé: “Ọmọ mi, jẹ́ ọlọ́gbọ́n, kí o sì mú ọkàn-àyà mi yọ̀, kí n lè fún ẹni tí ń ṣáátá mi lésì.” Pẹ̀lú ìmọrírì ló fi sọ pé: “Ẹsẹ Bíbélì yìí fi hàn pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ tó jinlẹ̀ gan-an, nítorí pé ó fún ẹdá èèyàn láàyè láti ṣe ohun tó máa mú ọkàn òun yọ̀.”
Ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ló ti jàǹfààní nípa títẹ̀ lé àwọn ìlànà inú Bíbélì bíi ti Rolf-Michael, ìyàwó rẹ̀ àtàwọn ọmọ wọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Irú àwọn èèyàn wọ̀nyí wà nínú ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà káàkiri ayé. Ó bani nínú jẹ́ pé láwọn orílẹ̀-èdè kan, ńṣe làwọn èèyàn ń fi ẹ̀sùn èké kan àwa Ẹlẹ́rìí pé ẹ̀ya ẹ̀sìn eléwu ni wá, pé túlétúlé sì ni wá pẹ̀lú. Ìrírí Rolf-Michael fi hàn pé irọ́ funfun báláú ni irú ẹ̀sùn bẹ́ẹ̀.—Hébérù 4:12.
Rolf-Michael sọ pé ìwé Mátíù 6:33, tó rọ̀ wá pé ká fi àwọn ohun tẹ̀mí sí ipò kìíní ni “atọ́nà” ìdílé òun, èyí tó ń darí wọn sí ọ̀nà tó tọ́. Òun àti ìdílé rẹ̀ ń dúpẹ́ gidigidi lọ́wọ́ Jèhófà fún bí ìgbésí ayé wọn ṣe ń dùn bí oyin nísinsìnyí tí wọ́n ti di Kristẹni. Wọ́n ní irú ẹ̀mí tí onísáàmù náà ní, nígbà tó kọrin pé: “Kí ni èmi yóò san padà fún Jèhófà nítorí gbogbo àǹfààní tí mo rí gbà láti ọ̀dọ̀ rẹ̀?”—Sáàmù 116:12.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 9]
Ọlọ́run fún ẹdá èèyàn ní àyè láti ṣe ohun tó máa mú ọkàn òun yọ̀
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 9]
Àwọn Ìlànà Bíbélì Tó Ṣe É Mú Lò
Díẹ̀ lára àwọn ìlànà Bíbélì tó ti mú ọ̀pọ̀ èèyàn jáwọ́ nínú oògùn olóró tó lè ṣekú pani rèé:
“Ẹ̀yin tí ẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ẹ kórìíra ohun búburú.” (Sáàmù 97:10) Téèyàn bá ti rí i dájú pé àṣà kan tó lè ṣekú pani ò dáa, tó sì kórìíra wọn, ẹni náà yóò rí i pé ó rọrùn láti ṣe ohun tí inú Ọlọ́run dùn sí.
“Ẹni tí ó bá ń bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ní ìbálò pẹ̀lú àwọn arìndìn yóò rí láburú.” (Òwe 13:20) Téèyàn kò bá fẹ́ lọ́wọ́ nínú lílo oògùn olóró àtàwọn nǹkan burúkú mìíràn, onítọ̀hún gbọ́dọ̀ fọgbọ́n yan àwọn tó ń bá ṣọ̀rẹ́. Dídọ́rẹ̀ẹ́ pẹ̀lú àwọn Kristẹni tó máa ranni lọ́wọ́ láti má ṣe lọ́wọ́ nínú àwọn àṣà wọ̀nyí máa ń ṣàǹfààní gan-an.
“Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun, ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run; àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà yín àti agbára èrò orí yín nípasẹ̀ Kristi Jésù.” (Fílípì 4:6, 7) Kò sí ohunkóhun tó lè fúnni nírú àlàáfíà àti ìbàlẹ̀ ọkàn yìí. Gbígbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run nípasẹ̀ àdúrà yóò ranni lọ́wọ́ láti kojú àwọn ìṣòro ìgbésí ayé láìlo àwọn oògùn olóró.