Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jèhófà Máa Ń Fa Àwọn Onírẹ̀lẹ̀ Wá Sínú Òtítọ́

Jèhófà Máa Ń Fa Àwọn Onírẹ̀lẹ̀ Wá Sínú Òtítọ́

Ìtàn Ìgbésí Ayé

Jèhófà Máa Ń Fa Àwọn Onírẹ̀lẹ̀ Wá Sínú Òtítọ́

GẸ́GẸ́ BÍ ASANO KOSHINO ṢE SỌ Ọ́

Ní ọdún 1949, ìyẹn ọdún díẹ̀ lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì, ọkùnrin gíga kan, tó jẹ́ àjèjì, tó sì lọ́yàyà, wá sọ́dọ̀ ìdílé tí mo ń bá ṣiṣẹ́ ní Ìlú Kobe. Òun gan-an ni míṣọ́nnárì tó kọ́kọ́ wá sí Japan lára àwọn míṣọ́nnárì ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Wíwá tó wá yìí fún mi láǹfààní láti gbọ́ nípa òtítọ́ Bíbélì. Àmọ́, ẹ jẹ́ kí n kọ́kọ́ sọ ìtàn ìgbésí ayé mi fún yín.

ỌDÚN 1926 ni wọ́n bí mi sí abúlé kékeré kan tó wà ní ìhà àríwá Àgbègbè Okayama. Èmi lẹnì kárùn-ún nínú àwa ọmọ mẹ́jọ táwọn òbí wa bí. Baba ní ìgbàgbọ́ tó ga nínú òrìṣà Shinto tí wọ́n ń bọ ládùúgbò wa. Nítorí náà, àwa ọmọ máa ń gbádùn àwọn àṣeyẹ àti ìkórajọ gbogbo ẹbí nígbà tí wọ́n bá ń ṣe àwọn ọdún òrìṣà.

Bí mo ṣe ń dàgbà ni ọ̀pọ̀ ìbéèrè nípa ìgbésí ayé ń kọ́ mi lóminú, àmọ́ ikú ni mo máa ń ronú nípa rẹ̀ jù lọ. Àṣà ìbílẹ̀ wa ni pé èèyàn gbọ́dọ̀ kú sílé, àwọn ọmọdé sì gbọ́dọ̀ wà nítòsí ẹni tó bá fẹ́ kú nínú ìdílé náà. Ọkàn mi gbọgbẹ́ gan-an nígbà tí ìyá baba mi kú àti nígbà tí àbúrò mi ọkùnrin kú kí ó tó pé ọmọ ọdún kan. Inú mi máa ń bà jẹ́ ṣáá ni ti mo bá ti ń ronú pé àwọn òbí mi náà lè kú. ‘Ṣé ikú wá ni òpin gbogbo rẹ̀ ni? Ṣé ìgbésí ayé kò nítumọ̀ ju báyìí lọ ni?’ Ó wu mi kí n tètè rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè wọ̀nyí.

Ọdún 1937, nígbà tí mo wà ní kíláàsì kẹfà nílé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ni Ogun àárín Ṣáínà àti Japan bẹ̀rẹ̀. Wọ́n ń fagbára mú àwọn ọkùnrin lọ sójú ogun ní Ṣáínà. Bí àwọn ọmọ ilé ìwé ṣe ń kí àwọn baba wọn àtàwọn ẹ̀gbọ́n wọn ọkùnrin pé ó dìgbóṣe ni wọ́n ń lọgun pé “banzai!” ìyẹn ni pé kí olú ọba (kí ó pẹ́ láyé). Ó dá àwọn èèyàn lójú pé Japan ló máa ṣẹ́gun, nítorí pé ó jẹ́ orílẹ̀-èdè táwọn ọlọ́run ń ṣàkóso, tí olú ọba rẹ̀ pàápàá jẹ́ ọlọ́run kan tó wà láàyè.

Kò pẹ́ táwọn ìdílé bẹ̀rẹ̀ sí gba lẹ́tà pé àwọn èèyàn wọn ti ń kú lójú ogun. Àwọn táwọn èèyàn wọn kú ò ṣeé tù nínú. Ìkórìíra gba gbogbo ọkàn wọn, inú wọn sì máa ń dùn nígbà tí wọ́n bá gbọ́ pé ọ̀pọ̀ ọ̀tá ti kú. Àmọ́ lákòókò kan náà yẹn ni mo tún ń ronú pé, ‘Bi inú wa ṣe ń bà jẹ́ nítorí ikú àwọn èèyàn wa náà ni inú àwọn ọ̀tá wa yóò máa bà jẹ́ nígbà tí wọ́n bá ń gbọ́ pé àwọn èèyàn tiwọn náà kú sójú ogun.’ Nígbà tí mo fi máa parí ilé ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀, ogun náà ti wọnú Ṣáínà gan-an.

Mo Bá Àjèjì Kan Pàdé Láìròtẹ́lẹ̀

Nítorí pé àgbẹ̀ ni wá, ìdílé wà kó fi bẹ́ẹ̀ rí jájẹ, àmọ́ baba mi fún mi láyè láti kàwé tí kò bá ti ní ná wa lówó. Nítorí náà, ní ọdún 1941, mo wọ ilé ẹ̀kọ́ gíga tó wà fún àwọn obìnrin ní Ìlú Okayama, tó wà ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún kìlómítà sí abúlé wa. Ilé ẹ̀kọ́ náà wà fún dídá àwọn ọmọbìnrin lẹ́kọ̀ọ́ láti di aya àti ìyá rere, ó sì máa ń yan àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti lọ gbé lọ́dọ̀ àwọn tó jẹ́ ọlọ́rọ̀ láàárín ìlú, kí wọ́n lè kọ béèyàn ṣe ń tọ́jú ilé níbẹ̀. Ní àràárọ̀, àwọn ọmọbìnrin wọ̀nyí á kẹ́kọ̀ọ́ nípa ṣíṣe iṣẹ́ nínú àwọn ilé wọ̀nyí, nígbà tó bá sì di ọ̀sán wọ́n á lọ sílé ìwé.

Lẹ́yìn tí ayẹyẹ ìkíni káàbọ̀ sílé ìwé parí, olùkọ́ mi wọ aṣọ kan tí wọ́n ń pè ní kimono, ó sì mú mi lọ sí ilé ńlá kan báyìí. Àmọ́ fún ìdí kan tí a ò mọ̀, obìnrin tó ní ilé náà kọ̀ kò gbà mí. Olùkọ́ mi wá bi ara rẹ̀ pé, “Ṣé ká wá lọ sílé Ìyá Ààfin Koda ni?” Ó wá mú mi lọ sí ilé kan tí wọ́n kọ́ bíi ti àwọn ará Ìwọ̀ Oòrùn ayé, ó sì tẹ aago ẹnu ọ̀nà wọn. Nígbà tó yá, obìnrin kan tó ga, tí irun rẹ̀ ní àwọ̀ eérú tó ń dán yọ̀yọ̀, jáde sí wa. Ńṣe làyà mi là gàrà! Obìnrin yìí kì í ṣe ara Japan, mi ò sì tíì rí ará Ìwọ̀ Oòrùn ayé rí ní ìgbésí ayé mi. Olùkọ́ mi fi mi hàn Ìyá Ààfin Maud Koda, ó sì kúrò níbẹ̀ lójú ẹsẹ̀. Mo ń wọ́ àpò mi tẹ̀ lé e, bí mo ṣe ń fi ìbẹ̀rùbojo wọnú ilé náà lọ. Ìgbẹ̀yìngbẹ́yín ni mo ṣẹ̀ṣẹ̀ wá gbọ́ pé ara Amẹ́ríkà ni Ìyá Ààfin Maud Koda, àmọ́ ọmọ ilẹ̀ Japan tó lọ kàwé ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni ọkọ rẹ̀. Iṣẹ́ olùkọ́ tí ń kọ́ni ní èdè Gẹ̀ẹ́sì ní obìnrin yìí ń ṣe láwọn ilé ìwé tí wọ́n ti ń kọ́ ẹ̀kọ́ ìṣòwò.

Àárọ̀ ọjọ́ kejì gan-an ni iṣẹ́ bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹu. Ọ̀gbẹ́ni Koda ní àrùn wárápá, mo sì ní láti tọ́jú rẹ̀. Nítorí pé mi ò gbọ́ èdè òyìnbó rárá, àyà mi bẹ̀rẹ̀ sí já. Àmọ́ ọkàn mi wá balẹ̀ nígbà tí Ìyá Ààfin Koda sọ èdè Japan sí mi. Ojoojúmọ́ mi mo máa ń gbọ́ tí wọ́n ń sọ èdè òyìnbó síra wọn, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ èmi náà bẹ̀rẹ̀ sí gbọ́ èdè náà. Mo fẹ́ràn bí ilé náà ṣe tòrò minimini.

Bí Maud ṣe fi gbogbo ọkàn fẹ́ràn ọkọ rẹ̀ tó jẹ́ aláìsàn yìí wú mi lórí gan-an. Ọkùnrin yìí máa ń ka Bíbélì gan-an. Mo gbọ́ lẹ́yìn ìgbà yẹn pé tọkọtaya yìí ti ra ẹ̀dà ìwé The Divine Plan of the Ages tó jẹ ti èdè Japan ní ilé ìtajà kan tí wọ́n ti ń ta àwọn àlòkù ìwé àti pé wọ́n ti san àsansílẹ̀ owó ọdún bíi mélòó kan tí wọ́n á fi máa gba ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ ní èdè Gẹ̀ẹ́sì.

Ní ọjọ́ kan, ẹni kan fi Bíbélì ta mi lọ́rẹ. Inú mi dùn gan-an, nítorí pé ìgbà tí mo kọ́kọ́ ní Bíbélì tó jẹ tèmi fúnra mi nìyẹn. Mo máa ń kà á nígbà tí mò bá ń lọ sílé ìwé mo sì tún máa ń kà á nígbà tí mò bá ń bọ̀, àmọ́ kò fi bẹ́ẹ̀ yé mi. Nítorí pé inú ẹ̀sìn Shinto ti ilẹ̀ Japan ni wọ́n ti tọ́ mi dàgbà, Jésù Kristi kò fi bẹ́ẹ̀ jẹ́ ẹni gidi kan lójú mi. Mi ò mọ̀ rárá pé ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yìí ni ìbẹ̀rẹ̀ ohun tó máa jẹ́ kí n rí òtítọ́ Bíbélì níkẹyìn, tó sì máa dáhùn àwọn ìbéèrè tí mo ní nípa ìgbésí ayé àti nípa ikú pẹ̀lú.

Ìṣẹ̀lẹ̀ Mẹ́ta Tó Bà Mi Nínú Jẹ́

Kò pẹ́ tí ọdún méjì tí mo fi kọ́ṣẹ́ níbẹ̀ parí, mo sì ní láti kí ìdílé náà pé ó dìgbóṣe. Nígbà tí mo ṣe tán nílé ìwé, mo dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ àwọn ọ̀dọ́bìnrin tó ń ṣèrànwọ́, mo sì kópa nínú rírán aṣọ àwọn ológun ojú omi. Láìpẹ́ sí àkókò yẹn ni ọkọ̀ òfuurufú tí wọ́n ń pè ní B-29 ti ilẹ̀ Amẹ́ríkà bẹ̀rẹ̀ sí ju bọ́ǹbù, nígbà tó sì di August 6, 1945, wọ́n ju bọ́ǹbù kan sí Hiroshima. Ọjọ́ díẹ̀ lẹ́yìn ìyẹn ni mo rí wáyà kan gbà, tó sọ pé Màmá wà lórí àìsàn líle koko. Kíá ni mo wọ ọkọ ojú irin lọ sábúlé wa. Bí mo ṣe ń sọ kalẹ̀ báyìí ni mọ̀lẹ́bí wa kan sọ fún mi pé Màmá ti kú. Ó kú ní August 11. Ohun tó ti ń bà mi lẹ́rù tipẹ́ ti wá ṣẹlẹ̀ báyìí! Èrò mi nígbà yẹn ni pé Màmá ò ní lè bá mi sọ̀rọ̀ mọ́, kò sì ní rẹ́rìn-ín sí mi mọ́ láé.

August 15 ló wá hàn gbangba pé wọ́n ti ṣẹ́gun Japan. Mo ní láti kojú ìṣẹ̀lẹ̀ mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó bà mí nínú jẹ́ gan-an, gbogbo rẹ̀ sì ṣẹlẹ̀ láàárín ọjọ́ mẹ́wàá péré: èkíní, bọ́ǹbù tó bú gbàù, èkejì, ikú Màmá, ẹ̀kẹta, ṣíṣẹ́gun tí wọ́n ṣẹ́gun Japan tó jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ mánigbàgbé nínú ìtàn. Àmọ́, ó jẹ́ ìtùnú fún wa láti mọ̀ pé àwọn èèyàn ó ní kú lójú ogun mọ́ báyìí. Pẹ̀lú ìbànújẹ́ tó dorí mi kodò, mo kúrò níbi tí mo ti ń ṣiṣẹ́ mo sì padà sí abúlé wa.

Òtítọ́ Fà Mí Mọ́ra

Lọ́jọ́ kan, mo gba lẹ́tà ti mi ò retí látọ̀dọ̀ Maud Koda ní Okayama. Ó béèrè bóyá mo lè wá ran òun lọ́wọ́ láti ṣe àwọn iṣẹ́ ilé, nítorí pé ó fẹ́ dá ilé ìwé tí wọ́n tí ń kọ́ni ní èdè Gẹ̀ẹ́sì sílẹ̀. Mo ronú nípa ohun tó yẹ kí n ṣe, àmọ́ mo fara mọ́ ohun tó ní kí n wá ṣe. Ọdún díẹ̀ lẹ́yìn ìyẹn ni mo tẹ̀ lé ìdílé Koda lọ sí Kobe.

Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ọdún 1949, ọ̀gbẹ́ni gíga kan tó lọ́yàyà wá sílé àwọn Koda. Donald Haslett ni orúkọ rẹ̀, Tokyo ló sì ti wá sí Kobe láti wá ilé fún àwọn míṣọ́nnárì ní Kobe. Òun ni míṣọ́nnárì tó kọ́kọ́ dé sí Japan lára àwọn míṣọ́nnárì ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó rí ilé kan gbà, nígbà tó sì di November 1949, àwọn míṣọ́nnárì bíi mélòó kan ti dé sí Kobe. Àwọn márùn-ún lára wọn wá kí àwọn Koda lọ́jọ́ kan. Méjì lára wọn, ìyẹn Lloyd Barry àti Percy Iszlaub fi ìṣẹ́jú mẹ́wàá mẹ́wàá bá àwọn tó pé jọ sínú ilé náà sọ̀rọ̀ ní èdè Gẹ̀ẹ́sì. Kristẹni arábìnrin ni àwọn míṣọ́nnárì náà ń pe Maud, bí wọ́n sì ṣe ń bá a ṣe nǹkan pọ̀ fún un níṣìírí gan-an. Ìgbà yẹn gan-an ló wá wu mi kí n kọ èdè Gẹ̀ẹ́sì.

Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn míṣọ́nnárì tí wọ́n jẹ́ onítara wọ̀nyí, mo wá ń lóye ìpìlẹ̀ òtítọ́ Bíbélì díẹ̀díẹ̀. Mo sì ń rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè tó ti ń kọ mi lóminú láti kékeré. Dájúdájú, Bíbélì fúnni ní ìrètí wíwà láàyè títí láé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé àti ìlérí àjíǹde fún “gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí.” (Jòhánù 5:28, 29; Ìṣípayá 21:1, 4) Mo dúpẹ́ púpọ̀ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó jẹ́ kí irú ìrètí bẹ́ẹ̀ ṣeé ṣe nípasẹ̀ ẹbọ ìràpadà Ọmọ rẹ̀, Jésù Kristi.

Àwọn Iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run Tó Ń Fúnni Láyọ̀

Àpéjọ àkọ́kọ́ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ní Japan wáyé ní December 30, 1949, sí January 1, 1950, wọ́n sì ṣe é ní ilé míṣọ́nnárì tó wà ní Kobe. Mo bá Maud lọ síbẹ̀. Ìjọba Násì ló ni ilé ńlá náà tẹ́lẹ̀, ó rí rèǹtèrente bí àwọn ilé tó wà ní Òkun Inland àti Erékùṣù Awaji. Nítorí pé ìmọ̀ Bíbélì tí mo ní ò tó nǹkan, díẹ̀ ló yé mi nínú ohun tí wọ́n sọ níbẹ̀. Síbẹ̀, báwọn míṣọ́nnárì wọ̀nyẹn ṣe ń bá àwọn ara Japan ṣe wọléwọ̀de níbẹ̀ wú mi lórí gan-an. Àwa mọ́kànlélọ́gọ́rùn-ún ló pésẹ̀ síbi àsọyé fún gbogbo ènìyàn ní àpéjọ náà.

Kété lẹ́yìn ìgbà yẹn ni mo bẹ̀rẹ̀ sí kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù. Mo nílò ìgboyà gan-an kí n lè wàásù láti ilé dé ilé, nítorí pé onítìjú èèyàn ni mi. Ní àárọ̀ ọjọ́ kan, Arákùnrin Barry wá sílé wa láti mú mi jáde òde ẹ̀rí. Ilé tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ilé Arábìnrin Koda gan-an ló ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́. Ńṣe ni mo sá pa mọ́ sẹ́yìn rẹ̀ ti mo ń fetí sí ohun tó ń sọ. Nígbà tí mo lọ sóde ẹ̀rí lẹ́ẹ̀kejì, èmi àtàwọn míṣọ́nnárì méjì mìíràn la jọ ṣiṣẹ́. Ìyá àgbà kan tó jẹ́ ará Japan ni ká wọlé, ó fetí sílẹ̀, ó sì fún ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ní ife wàrà kọ̀ọ̀kan mu. Ó gbà pé ká wá máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀ ó di Kristẹni tó ṣe batisí. Bó ṣe tètè tẹ́wọ́ gba òtítọ́ yẹn múnú wa dù gan-an ni.

Ni April 1951, Arákùnrin Nathan H. Knorr, láti orílé-iṣẹ́ ní Brooklyn wà sí ilẹ̀ Japan fún ìgbà àkọ́kọ́. Nǹkan bí ọgọ́rùn-ún méje èèyàn ló wá síbi ọ̀rọ̀ àwíyé fún gbogbo ènìyàn tó sọ ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ ti ìlú Kyoritsu ní Kanda, Tokyo. Gbogbo àwọn tó wà níbi ìpàdé àkànṣe yìí ni inú wọ́n dùn gan-an nígbà tí olùbánisọ̀rọ̀ kéde ìtẹ̀jáde ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ ní èdè Japan tó sì fi hàn wọ́n. Arákùnrin Knorr tún ṣèbẹ̀wò sí Kobe ni oṣù tó tẹ̀ lé ìyẹn, ibi ìpàdé àkànṣe tá a ṣe níbẹ̀ ni mo sì ti ṣèrìbọmi gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí pé mo ti ya ara mi sí mímọ́ fún Jèhófà.

Nǹkan bí ọdún kan lẹ́yìn ìyẹn ni wọ́n gbà mí níyànjú pé kí n wọnú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún, ìyẹn iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà. Àwọn aṣáájú ọ̀nà tó wa ní Japan lákòókò yẹn kò pọ̀ rárá, mo sì ń ronú nípa bí mo ṣe máa gbọ́ bùkátà ara mi. Mo tún ń ronú nípa bí mo ṣe máa rọ́kọ fẹ́. Àmọ́ mo wá rántí pé sísin Jèhófà ló yẹ ká fi sí ipò kìíní nínú ìgbésí ayé wa, bí mo ṣe di aṣáájú ọ̀nà lọ́dún 1952 nìyẹn. Inú mi dùn pé bí mo ṣe ń bá iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà mi lọ, ó tún ṣeé ṣe fún mi láti máa fi ààbọ̀ àkókò ṣiṣẹ́ lọ́dọ̀ Arábìnrin Koda.

Àárín àkókò yẹn ni ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin, tí mo rò pé ó ti kú sógun, padà wálé láti Taiwan, tòun ti ìdílé rẹ̀. Ìdílé mi ò nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀sìn Kristẹni rí, àmọ́ ìtara aṣáájú ọ̀nà tí mo ní ló mú kí n bẹ̀rẹ̀ sí fi àwọn ìwé ìròyìn àti ìwé kékeré ránṣẹ́ sí wọn. Nígbà tó yá ẹ̀gbọ́n mi àti ìdílé rẹ̀ kó wá sí Kobe nítorí iṣẹ́ rẹ̀. Mo bi ìyàwó ẹ̀gbọ́n mi pé: “Ǹjẹ́ ẹ ti ka àwọn ìwé ìròyìn wọ̀nyẹn?” Ìyàlẹ́nu ńlá ló jẹ́ fún mi nígbà tó fèsì pé, “Àwọn ìwé ìròyìn yẹn dùn gan-an o.” Bó ṣe bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ míṣọ́nnárì kan nìyẹn, àbúrò mi obìnrin tó ń gbé lọ́dọ̀ wọn náà tún bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́. Nígbà tó yá, àwọn méjèèjì di Kristẹni tó ṣèrìbọmi.

Ẹgbẹ́ Àwọn Ará Kárí Ayé Mú Orí Mi Yá Gágá

Láìpẹ́ sí àkókò yẹn, ó jẹ́ ìyàlẹ́nu ńláǹlà fún mi láti gba lẹ́tà tí wọ́n fi pè mí sí kíláàsì kejìlélógún ti ilé ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead. Èmi àti Arákùnrin Tsutomu Fukase ló kọ́kọ́ lọ sí ilé ìwé yẹn láti ilẹ̀ Japan. Ní 1953, kí kíláàsì wá tó bẹ̀rẹ̀, ó ṣeé ṣe fún wa láti lọ sí Àpéjọ Ẹgbẹ́ Ayé Tuntun tá a ṣe ní Pápá Ìṣeré Yankee ní New York. Ẹgbẹ́ àwọn ará kárí ayé ti àwọn èèyàn Jèhófà mórí mi yá gágá gan-an.

Aṣọ kimono ni àwa tó wá láti Japan máa wọ̀ ní ọjọ́ kárùn-ún àpéjọ yìí, àwọn míṣọ́nnárì ló sì pọ̀ jù lára wa. Nítorí pé kimono tí mo gbé sínú ọkọ̀ òkun ṣáájú àkókò yẹn ò tètè dé, mo lọ tọrọ ti Arábìnrin Knorr. Bí ìtòlẹ́sẹẹsẹ ṣe ń lọ lọ́wọ́ ni òjò bẹ̀rẹ̀ sí rọ̀, mo wá ń bẹ̀rù pé kí òjò má lọ pa kimono náà. Àkókò yẹn gan-an ni ẹnì kan rọra fi ẹ̀wù òjò kan bò mí látẹ̀yìn. Arábìnrin kan tó dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ mi bí mi pé: “Ǹjẹ́ o mọ ẹni yẹn?” Mo wá gbọ́ níkẹyìn pé Arákùnrin Frederick W. Franz ni, tó jẹ́ ọkàn lára Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso. Ìyẹn mà jẹ́ kí n mọ̀ bí ètò àjọ Jèhófà ṣe rí o!

Kíláàsì kejìlélógún ti ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì jẹ́ ti ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ní ti tòótọ́, ó ní àwọn ọgọ́fà akẹ́kọ̀ọ́ láti orílẹ̀-èdè mẹ́tàdínlógójì nínú. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ní ìṣòro èdè, síbẹ̀ a gbádùn ẹgbẹ́ àwọn ará tá a wá láti ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè náà. Ọjọ́ tí yìnyín pọ̀ gan-an ní February 1954 la ṣe ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege, tí wọ́n sì yàn mí padà sí Japan. Arábìnrin kan tá a jọ wà ní kíláàsì kan náà, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Inger Brandt tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Sweden, la jọ máa lọ sí Ìlú Nagoya. Ibẹ̀ la ti wá dara pọ̀ mọ́ àwọn míṣọ́nnárì tí wọ́n kó kúrò ní Korea nítorí ogun. Ọdún díẹ̀ tí mo lò nínú iṣẹ́ ìsìn míṣọ́nnárì yẹn ṣeyebíye lójú mi gan-an ni.

Mò Ń Ṣe Iṣẹ́ Ìsìn Aláyọ̀ Pẹ̀lú Ọkọ Mi

Ní September 1957, wọ́n pè mi pé kí n wá ṣiṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Tokyo. Ilé alájà méjì kan tí wọ́n fi igi kọ́ la ń lò fún ẹ̀ka ilé iṣẹ́ wa ní Japan. Ní ẹ̀ka ilé iṣẹ́ náà, àwọn mẹ́rin péré ló jẹ́ ìdílé Bẹ́tẹ́lì níbẹ̀, lára wọn ni Arákùnrin Barry, tó jẹ́ alábòójútó ẹ̀ka náà. Míṣọ́nnárì ni gbogbo àwa tó kù. Wọ́n yàn mí láti ṣe iṣẹ́ ìtumọ̀ àti ṣíṣàyẹ̀wò ohun táwọn mìíràn túmọ̀, wọ́n tún ní kí n máa ṣe iṣẹ́ ìmọ́tótó, aṣọ fífọ̀, oúnjẹ síse, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Iṣẹ́ wa ní Japan túbọ̀ ń gbòòrò sí i, wọ́n sì ń pé àwọn arákùnrin púpọ̀ sí i wá sí Bẹ́tẹ́lì. Ọ̀kan nínú wọn di alábòójútó nínú ìjọ tí mò ń dara pọ̀ mọ́. Èmi àti arákùnrin náà, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Junji Koshino, ṣègbéyàwó ní ọdún 1966. Ẹ̀yìn tá a ṣègbéyàwó ni wọ́n yan Junji sí iṣẹ́ alábòójútó àyíká. Inú wá dùn gan-an pé a mọ ọ̀pọ̀ arákùnrin àti arábìnrin bá a ṣe ń bẹ àwọn onírúurú ìjọ wò. Níwọ̀n bí wọ́n ti ní kí n máa ṣe àwọn iṣẹ́ títúmọ̀ ìwé, mo máa ń ṣe é láwọn ilé tá a bá dé sí lọ́sẹ̀ náà. Bá a ṣe ń rìnrìn àjò là ń gbé àwọn ìwé atúmọ̀ èdè bàǹtì-bàǹtì dání, pẹ̀lú àpótí aṣọ wa àti àwọn àpò mìíràn.

A gbádùn iṣẹ́ àyíká náà fún ohun tó lé ní ọdún mẹ́rin, a sì rí i bí ètò àjọ náà ṣe ń gbòòrò. Wọ́n kó ẹ̀ka ilé iṣẹ́ wa lọ sí Numazu, ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn ìyẹn ni wọ́n wá kó o lọ sí Ebina, níbi tó wà títí di oní olónìí. Ó ti pẹ́ tí èmi àti Junji ti ń gbádùn iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì, nǹkan bí ẹgbẹ̀ta èèyàn ni àwa tá a jẹ́ ìdílé Bẹ́tẹ́lì tó ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀ báyìí. Ní May 2002, àwọn ọ̀rẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì ṣe ayẹyẹ àjọ̀dún àádọ́ta ọdún tí mo ti wà nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún fún mi.

Mo Láyọ̀ Láti Rí Bí Iṣẹ́ Wa Ṣe Ń Gbòòrò Sí I

Nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í sin Jèhófà nígbà yẹn lọ́hùn-ún ní ọdún 1950, ìwọ̀nba díẹ̀ làwọn akéde tó wà ní Japan nígbà yẹn. Ẹgbàá márùnlélọ́gọ́rùn-ún [210,000] ni iye akéde Ìjọba tó wà níbẹ̀ báyìí. Láìsí àní-àní, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ẹni-bí-àgùntàn la ti fà sí ọ̀dọ̀ Jèhófà, gẹ́gẹ́ bíi tèmi.

Àwọn arákùnrin míṣọ́nnárì mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àti arábìnrin kan tó wá kí wa nílé Arábìnrin Koda nígbà yẹn lọ́hùn-ún ní 1949, títí kan Arábìnrin Maud Koda fúnra rẹ̀, gbogbo wọn pátá ló ṣòtítọ́ títí tí wọ́n fi kú. Bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ̀gbọ́n mi tí òun náà jẹ́ ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ nígbà yẹn, àti ìyàwó rẹ̀, tó ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà fún nǹkan bí ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún. Ìrètí wo ló wá wà fún àwọn òbí mi tí mo ti máa ń bẹ̀rù ikú wọn látìgbà tí mo ti wà lọ́mọdé? Ìlérí àjíǹde tí Bíbélì ṣe ló fún mi ní ìrètí àti ìtùnú.—Ìṣe 24:15

Bí mo ṣe ń ronú nípa ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn, mo rí i pé bíbá tí mo bá Maud pàdé ní ọdún 1941 jẹ́ ìyípadà ńlá nínú ìgbésí ayé mi. Ká ní mi ò bá a pàdé lákòókò yẹn, ká sì ní mi ò padà lọ bá a ṣiṣẹ́ lẹ́yìn ogun ni, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé oko wa lábúlé lọ́hùn-ún ni ǹ bá fìdí kalẹ̀ sí tí ǹ bá má sì rí àwọn míṣọ́nnárì tó kọ́kọ́ wá yẹn. Mo mà dúpẹ́ o, pé Jèhófà fà mí sínú òtítọ́ nípasẹ̀ Maud àtàwọn míṣọ́nnárì tó wá nígbà yẹn lọ́hùn-ún!

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Èmi àti Maud Koda àti ọkọ rẹ̀. Èmi nìyẹn níwájú lápá òsì

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

Èmi àtàwọn míṣọ́nnárì láti Japan ní Pápá Ìṣeré Yankee ní 1953. Èmi ni mo wà lápá òsì pátápátá

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

Èmi àti Junji ọkọ mi rèé ní Bẹ́tẹ́lì