Mímọrírì Ìdí Tá A Fi Ń Báni Wí
Mímọrírì Ìdí Tá A Fi Ń Báni Wí
KÍ LÓ máa ń wá sí ọ lọ́kàn nígbà tó o bá gbọ́ ọ̀rọ̀ náà “ìbáwí”? Ìwé kan túmọ̀ ìbáwí sí “mímú káwọn èèyàn ṣègbọràn sí ìlànà ìwà híhù àti fífi ìyà jẹ wọ́n nígbà tí wọ́n bá ṣàìgbọràn.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí kì í ṣe ọ̀nà kan ṣoṣo tá a lè gbà túmọ̀ rẹ̀, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ èèyàn lóde òní ló ní irú èrò òdì yẹn nípa ohunkóhun tó jẹ mọ́ ìbáwí.
Àmọ́, ohun tí Bíbélì sọ nípa ìbáwí yàtọ̀. Sólómọ́nì ọlọ́gbọ́n Ọba kọ̀wé pé: “Ìwọ ọmọ mi, má kọ ìbáwí Jèhófà.” (Òwe 3:11) Ọ̀rọ̀ yìí ò tọ́ka sí ìbáwí lásán, bí kò ṣe “ìbáwí Jèhófà,” ìyẹn ìbáwí tá a gbé karí ìlànà gíga látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Irú ìbáwí bẹ́ẹ̀ ló ń ṣeni láǹfààní nípa tẹ̀mí—kódà á nílò rẹ̀ gan-an. Ní òdìkejì èyí, ìbáwí tá a gbé karí èrò ènìyàn tó tako ìlànà gíga látọ̀dọ̀ Jèhófà sábà máa ń ní àṣejù nínú ó sì máa ń pani lára. Abájọ tí ọ̀pọ̀ èèyàn kì í fojú tó dára wo ìbáwí.
Kí nìdí tá a fi rọ̀ wá láti gba ìbáwí tó wá látọ̀dọ̀ Jèhófà? Ìwé Mímọ́ ṣàpèjúwe ìbáwí látọ̀dọ̀ Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà ń fi ìfẹ́ hàn sí ẹ̀dá ènìyàn. Ìdí nìyẹn tí Sólómọ́nì fi ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Ẹni tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ni ó ń fi ìbáwí tọ́ sọ́nà, àní gẹ́gẹ́ bí baba ti ń tọ́ ọmọ tí ó dunnú sí.”—Òwe 3:12.
Kí Ni Ìyàtọ̀ Tó Wà Láàárín Ìbáwí àti Ìfìyàjẹni?
Ìbáwí pín sí oríṣiríṣi ọ̀nà, gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ ọ́ nínú Bíbélì—ó wà fún amọ̀nà, ìtọ́ni, ìdánilẹ́kọ̀ọ́, ìbáwí àfitọ́nisọ́nà, ìtọ́sọ́nà, kódà o tún wà fún ìfìyàjẹni pàápàá. Àmọ́, ní gbogbo ọ̀nà, ìfẹ́ ló ń mú kí Jèhófà báni wí, ó sì ń ṣe bẹ́ẹ̀ káwọn tó bá fara mọ́ ìbáwí rẹ̀ lè ṣe ara wọn láǹfààní. Kì í ṣe nítorí àtifi ìyà jẹni nìkan ni Jèhófà ṣe ń báni wí.
Bẹ́ẹ̀ náà ni, ìyà tí Ọlọ́run fi jẹ àwọn èèyàn kì í fìgbà gbogbo jẹ́ láti tọ́ni sọ́nà tàbí láti kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́. Bí àpẹẹrẹ, láti ọjọ́ tí Ádámù àti Éfà ti ṣẹ̀ ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí jìyà àwọn àbájáde àìgbọràn tí wọ́n ṣe. Jèhófà lé wọn jáde kúrò nínú ọgbà Édẹ́nì tí í ṣe Párádísè, wọ́n wá di aláìpé, wọ́n ṣàìsàn, wọ́n sì darúgbó. Lẹ́yìn tí wọ́n ti wà nínú ìrora fún àwọn ọgọ́rùn-ún ọdún, wọ́n ṣègbé títí láé. Gbogbo èyí jẹ́ ìyà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, àmọ́ kì í ṣe ìbáwí láti fi tọ́ wọ́n sọ́nà. Ádámù àti Éfà ti ṣe ohun tó kọjá ìtọ́sọ́nà, nítorí pé ńṣe ni wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ ṣàìgbọràn, wọn ò sì ronú pìwà dà.
Àwọn àkọsílẹ̀ mìíràn tó sọ nípa bí Jèhófà ṣe fìyà jẹ àwọn kan ni: Ìkún Omi ọjọ́ Nóà, ìparun Sódómù àti Gòmórà, àti ìparun àwọn ọmọ ogun Íjíbítì nínú Òkun Pupa. Àwọn ohun tí Jèhófà ṣe wọ̀nyí kì í ṣe láti fún àwọn èèyàn náà ní ìtọ́sọ́nà, ìtọ́ni, tàbí ìdálẹ́kọ̀ọ́. Nítorí irú ìjìyà bẹ́ẹ̀ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni àpọ́sítélì Pétérù ṣe kọ̀wé pé: “Kò sì fawọ́ sẹ́yìn ní fífìyàjẹ ayé ìgbàanì, ṣùgbọ́n ó pa Nóà, oníwàásù òdodo mọ́ láìséwu pẹ̀lú àwọn méje mìíràn nígbà tí ó mú àkúnya omi wá sórí ayé àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run; àti nípa sísọ àwọn ìlú ńlá náà Sódómù àti Gòmórà di eérú, ó dá wọn lẹ́bi, ní fífi àpẹẹrẹ kan lélẹ̀ fún àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run nípa àwọn ohun tí ń bọ̀.”—2 Pétérù 2:5, 6.
Ọ̀nà wo ni àwọn ìjìyà wọ̀nyí gbà fi “àpẹẹrẹ kan lélẹ̀ fún àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run nípa àwọn ohun tí ń bọ̀”? Nínú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn 2 Tẹsalóníkà 1:8, 9) Ó hàn gbangba pé irú ìyà bẹ́ẹ̀ kò wà fún kíkọ́ àwọn èèyàn náà lẹ́kọ̀ọ́ tàbí fún yíyọ́ wọn mọ́. Àmọ́ ṣá o, nígbà tí Jèhófà bá rọ àwọn olùjọsìn rẹ̀ láti tẹ́wọ́ gba ìbáwí, kì í ṣe ìyà tó máa fi jẹ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí kò ronú pìwà dà ló ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.
ará Tẹsalóníkà, ó tọ́ka sí àkókò tá a wà yìí gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí Ọlọ́run yóò tipasẹ̀ ọmọ rẹ̀ Jésù Kristi mú “ẹ̀san wá sórí àwọn tí kò mọ Ọlọ́run àti àwọn tí kò ṣègbọràn sí ìhìn rere.” Pọ́ọ̀lù fi kún un pé: “Àwọn wọ̀nyí gan-an yóò fara gba ìyà ìdájọ́ ìparun àìnípẹ̀kun.” (Ó ṣe pàtàkì láti mọ̀ pé Bíbélì kò ṣàpèjúwe Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ẹni tó jẹ́ pé kìkì ìyà ló máa ń fi jẹni. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó sábà máa ń sọ nípa rẹ̀ ni pé ó jẹ́ olùkọ́ tó nífẹ̀ẹ́ àti ẹni tó ń fi sùúrù kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́. (Jóòbù 36:22; Sáàmù 71:17; Aísáyà 54:13) Bẹ́ẹ̀ ni o, ìbáwí látọ̀dọ̀ Ọlọ́run tá a lò láti fi tọ́ni sọ́nà máa ń fìgbà gbogbo ní ìfẹ́ àti sùúrù nínú. Tá a bá lóye ìdí tá a fi ń bá wa wí, kò lè ṣòro rárá fún àwọn Kristẹni láti fi ẹ̀mí rere gba ìbáwí kí àwọn náà sì máa fi ẹ̀mí rere báni wí.
Ìbáwí Látọ̀dọ̀ Àwọn Òbí To Nífẹ̀ẹ́
Ó yẹ kí gbogbo wa pátá lóye ìdí tá a fi ń báni wí nínú ìdílé àti nínú ìjọ Kristẹni. Àwọn tí èyí pọn dandan fún jù lọ ni àwọn tó wà nípò àṣẹ, bí àwọn òbí. Ìwé Òwe 13:24 sọ pé: “Ẹni tí ó fa ọ̀pá rẹ̀ sẹ́yìn kórìíra ọmọ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ ni ẹni tí ó wà lójúfò láti fún un ní ìbáwí.”
Báwo ló ṣe yẹ káwọn òbí máa báni wí? Bíbélì ṣàlàyé pé: “Ẹ̀yin, baba, ẹ má ṣe máa sún àwọn ọmọ yín bínú, ṣùgbọ́n ẹ máa bá a lọ ní títọ́ wọn dàgbà nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.” (Éfésù 6:4) Ó tún ọ̀rọ̀ yìí sọ lọ́nà yìí pé: “Ẹ̀yin baba, ẹ má ṣe máa dá àwọn ọmọ yín lágara, kí wọ́n má bàa soríkodò.”—Kólósè 3:21.
Àwọn Kristẹni òbí tó lóye ìdí tá a fi ń báni wí kò ní máa kanra. Ìlànà tó wà nínú ìwé 2 Tímótì 2:24 ṣeé mú lo nínú ọ̀nà tí àwọn òbí gbà ń báni wí. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Kò yẹ kí ẹrú Olúwa máa jà, ṣùgbọ́n ó yẹ kí ó jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́ sí gbogbo ènìyàn, ẹni tí ó tóótun láti kọ́ni.” Bíbínú sódì, jíjágbe mọ́ni, àti bíbúni tàbí sísọ kòbákùngbé ọ̀rọ̀ síni kì í ṣe ohun tá a lè pè ní ìbáwí onífẹ̀ẹ́, kò sì yẹ kó máa wáyé nínú ìgbésí ayé Kristẹni.—Éfésù 4:31; Kólósè 3:8.
Ìbáwí látọ̀dọ̀ òbí kọjá yíyára fìyà jẹni lọ́nà kan pàtó. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ọmọdé ló fẹ́ ká sọ
ohun kan fún wọn lásọtúnsọ kí wọ́n tó ṣàtúnṣe ìrònú wọn. Nítorí èyí, àwọn òbí gbọ́dọ̀ lo àkókò, kí wọ́n ní sùúrù, kí wọ́n sì máa ronú dáadáa lórí ọ̀nà tí wọ́n lè gbà bá àwọn ọmọ wọn wí. Wọn ò gbọ́dọ̀ gbàgbé pé ńṣe ló yẹ kí wọ́n tọ́ àwọn ọmọ wọn dàgbà nínú “ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.” Èyí túmọ̀ sí dídáni lẹ́kọ̀ọ́ fún ọ̀pọ̀ ọdún.Àwọn Kristẹni Olùṣọ́ Àgùntàn Ń Fi Ìwà Tútù Báni Wí
Ìlànà kan náà tún kan àwọn Kristẹni alàgbà. Gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn onífẹ̀ẹ́, wọ́n ń sapá láti fún agbo níṣìírí nípa fífún wọn ní ìtọ́ni, ìdarí, àti ìbáwí àfitọ́nisọ́nà nígbà tí wọ́n bá nílò rẹ̀. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, wọn ò gbàgbé ìdì pàtàkì tá a fi ń báni wí. (Éfésù 4:11, 12) Tó bá jẹ́ pé ká ṣáà ti jẹni níyà ni wọ́n gbájú mọ́, wọ́n á wulẹ̀ máa dá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lẹ́jọ́ ni, wọn ò ní ṣe ohunkóhun láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Ìbáwí látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ju ìyẹn lọ gan-an. Ìfẹ́ ń mú kí àwọn alàgbà tẹra mọ́ sísapá láti ràn ẹni tó ṣi ẹsẹ̀ gbé náà lọ́wọ́. Nítorí pé wọ́n ń ṣàníyàn gidigidi nípa wọn, wọ́n á bẹ irú ẹni bẹ́ẹ̀ wò lọ́pọ̀ ìgbà kí wọ́n lè fún wọn níṣìírí àti ìdálẹ́kọ̀ọ́.
Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ìṣítí tó wà nínú 2 Tímótì 2:25, 26, kódà nígbà tàwọn alàgbà bá ń bá àwọn tí kò fẹ́ gba ìbáwí sọ̀rọ̀, wọ́n ní láti tọ́ni sọ́nà “pẹ̀lú ìwà tútù.” Ìwé Mímọ́ wá sọ ìdí tá a fi ń báni wí pé: “Bóyá Ọlọ́run lè fún wọn ní ìrònúpìwàdà tí ń ṣamọ̀nà sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́, kí wọ́n sì lè padà wá sí agbára ìmòye wọn tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu kúrò nínú ìdẹkùn Èṣù.”
Nígbà mìíràn, ó máa n pọn dandan láti yọ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí kò bá ronú pìwà dá kúrò nínú ìjọ. (1 Tímótì 1:18-20) Síbẹ̀ ìbáwí ló yẹ kí a ka ohun tí wọ́n ṣe yìí sí, kì í ṣe ìfìyàjẹni. Látìgbàdégbà, àwọn alàgbà máa ń lọ sọ́dọ̀ àwọn tá a ti yọ lẹ́gbẹ́ àmọ́ tí wọ́n ti ń jáwọ́ nínú híhu ìwà àìtọ́. Nírú àkókò bẹ́ẹ̀, àwọn alàgbà máa ń ṣe ohun tó bá ìdí tá a fi ń báni wí gan-an mu, wọ́n á sọ ìgbésẹ̀ tí onítọ̀hún ní láti gbé kó lè padà sínú ìjọ Kristẹni.
Jèhófà Ni Onídàájọ́ Pípé
Àwọn òbí, àwọn Kristẹni olùṣọ́ àgùntàn, àtàwọn mìíràn tí Ìwé Mímọ́ fún láṣẹ láti báni wí gbọ́dọ̀ fọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ náà. Wọn ò gbọ́dọ̀ máa ṣèdájọ́ àwọn ẹlòmíràn bíi pé àwọn onítọ̀hún ò lè yí padà láé. Nítorí náà, ìbáwí tí wọ́n ń fúnni kò gbọ́dọ̀ dà bíi pé wọ́n ń ránró tàbí kó jẹ́ ti ìfìyàjẹni lọ́nà rírorò.
Hébérù 10:31) Àmọ́ kò sí ẹ̀dá ènìyàn kankan tó gbọ́dọ̀ fi ara rẹ̀ wé Jèhófà nínú ọ̀ràn yìí tàbí nínú ohunkóhun mìíràn. Òbí kan tàbí alàgbà kan nínú ìjọ kò gbọ́dọ̀ mú kí ẹnikẹ́ni ronú pé ohun akúnfẹ́rù ni láti ṣubú sí ọwọ́ òun.
Ní tòótọ́, Bíbélì sọ pé Jèhófà ni ẹni tí yóò fìyà ìkẹyìn mímúná jẹni. Kódà, Ìwé Mímọ́ sọ pé, “ó jẹ́ ohun akúnfẹ́rù láti ṣubú sí ọwọ́ Ọlọ́run alààyè.” (Jèhófà mọ ibi tó yẹ kí òun bá ènìyàn wí dé. Èèyàn ò mọ ìyẹn. Ọlọ́run lè rí ọkàn kó sì mọ ìgbà tí ẹnì kan bá ṣe ohun tó ré kọjá ìtọ́sọ́nà tó sì tipa bẹ́ẹ̀ di ẹni tí ìdájọ́ mímúná tọ́ sí. Àmọ́ àwọn èèyàn kò lè ṣe irú ìdájọ́ bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, nígbà tó bá yẹ láti báni wí, àwọn tó wà nípò àṣẹ gbọ́dọ̀ máa ṣe é láti fi tọ́ni sọ́nà.
Títẹ́wọ́ Gba Ìbáwí Látọ̀dọ̀ Jèhófà
Gbogbo wa lá nílò ìbáwí látọ̀dọ̀ Jèhófà. (Òwe 8:33) Kódà ńṣe ló yẹ kó máa wù wá láti gba ìbáwí tó dá lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Bá a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, a lè rí ìbáwí gbà tààràtà látọ̀dọ̀ Jèhófà nípasẹ̀ Ìwé Mímọ́. (2 Tímótì 3:16, 17) Àmọ́ ṣá o, àwọn ìgbà mìíràn wà tá a máa gba ìbáwí látọ̀dọ̀ Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa. Mímọ ìdí tá a fi fúnni ní irú ìbáwí bẹ́ẹ̀ yóò ràn wá lọ́wọ́ láti gbà á tọkàntọkàn.
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ ọ́ ní kedere pé: “Lóòótọ́, kò sí ìbáwí tí ó dà bí ohun ìdùnnú nísinsìnyí, bí kò ṣe akó-ẹ̀dùn-ọkàn-báni.” Ó tún fi kún un pé: “Síbẹ̀ nígbà tí ó bá yá, fún àwọn tí a ti kọ́ nípasẹ̀ rẹ̀, a máa so èso ẹlẹ́mìí àlàáfíà, èyíinì ni, òdodo.” (Hébérù 12:11) Ìbáwí látọ̀dọ̀ Jèhófà jẹ́ ẹ̀rí pé ó nífẹ̀ẹ́ wa dénú. Yálà a ń gbà ìbáwí ni o, tàbí a ń fúnni ní ìbáwí, ẹ má ṣe jẹ́ ká gbàgbé ìdí tá a fi ń gba ìbáwí látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ká sì kọbi ara sí ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì pé: “Di ìbáwí mú; má ṣe jẹ́ kí ó lọ. Fi ìṣọ́ ṣọ́ ọ, nítorí òun ni ìwàláàyè rẹ.”—Òwe 4:13.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Ìyà ìdájọ́ látọ́dọ̀ Ọlọ́run ni àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí kò ronú pìwà da gbà, kì í ṣe ìbáwí àfitọ́nisọ́nà
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
Ìfẹ́ ló ń mú kí àwọn alàgbà máa lo àkókò wọn fún ṣíṣe ìwádìí àti ríran àwọn tó ṣi ẹsẹ̀ gbé lọ́wọ́
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Àwọn òbí ń fi sùúrù àti ìfẹ́ tọ́ni sọ́nà nínú “ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà”