Ìdí Tí Ọ̀pọ̀ Èèyàn Fi Rò Pé Ìsìn Ò Lè Mú Kí Aráyé Wà Níṣọ̀kan
Ìdí Tí Ọ̀pọ̀ Èèyàn Fi Rò Pé Ìsìn Ò Lè Mú Kí Aráyé Wà Níṣọ̀kan
“NÍFẸ̀Ẹ́ aládùúgbò rẹ.” (Mátíù 22:39) Ọ̀pọ̀ ìsìn ló ń sọ pé ìlànà rere ni ìlànà pàtàkì yìí. Bí àwọn ìsìn tó ń sọ bẹ́ẹ̀ bá sì ń kọ́ àwọn ọmọ ìjọ wọn lójú méjèèjì pé kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì wọn, ìṣọ̀kan á wà láàárín wọn. Àmọ́, èwo nínú irú àwọn ìsìn bẹ́ẹ̀ lo ti rí tí ìṣọ̀kan wà láàárín àwọn ọmọ ìjọ rẹ̀? Ǹjẹ́ ìsìn lè mú kí aráyé wà níṣọ̀kan? Nínú ìwádìí kan tí wọ́n ṣe lórílẹ̀-èdè Jámánì lẹ́nu àìpẹ́ yìí, wọ́n béèrè lọ́wọ́ àwọn kan pé: “Ṣé ìsìn tiẹ̀ ń mú káwọn èèyàn wà níṣọ̀kan ni àbí ńṣe ló ń fa ìyapa láàárín wọn?” Ìdá méjìlélógún nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tó dáhùn ìbéèrè yìí ló sọ pé ìsìn ń mú káwọn èèyàn wà níṣọ̀kan. Àmọ́, ìdá méjìléláàádọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún ló sọ pé ńṣe ni ìsìn ń fa ìyapa láàárín àwọn èèyàn. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé èrò táwọn èèyàn ní lórílẹ̀-èdè tìrẹ náà nìyẹn.
Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi rò pé ìsìn ò lè mú kí aráyé wà níṣọ̀kan? Ó lè jẹ́ pé àwọn nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá ló fà á. Kàkà kí ìsìn máa mú káwọn èèyàn wà níṣọ̀kan, ńṣe ló ń fa ìyapa láàárín wọn. Nígbà míì, ìsìn ló máa ń wà lẹ́yìn ìwà ìkà bíbani lẹ́rù tàwọn èèyàn máa ń hù. Gbé àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀ wò lára àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ láàárín ọgọ́rùn-ún ọdún tó kọjá.
Ìsìn Ló Ń Fa Ìyapa
Nígbà ogun àgbáyé kejì, àwọn ọmọ ilẹ̀ Croatia tí wọ́n ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì dojúùjà kọ àwọn ọmọ ilẹ̀ Serbia tí wọ́n ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì. Ọmọlẹ́yìn Jésù sì làwọn tó ń ṣe ẹ̀sìn méjèèjì yìí pera wọn o. Bẹ́ẹ̀ ohun tí Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ni pé kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì wọn. Olùṣèwádìí kan sọ pé, ogun tí wọ́n bára wọn jà yìí “jẹ́ ọ̀kan lára ìpakúpa rẹpẹtẹ tó bààyàn lẹ́rù jù lọ látìgbà táláyé ti dáyé.” Ńṣe ni jìnnìjìnnì bo gbogbo ayé nígbà tí wọ́n rí bí wọ́n ṣe pa àwọn ọkùnrin, àwọn obìnrin àtàwọn ọmọdé nípakúpa. Iye àwọn tí wọ́n pa yìí lé ní ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [500,000].
Ní ọdún 1947, nǹkan bí irínwó mílíọ̀nù èèyàn ló wà ní ilẹ̀ Íńdíà. Iye yẹn jẹ́ ìdá márùn-ún gbogbo èèyàn tó wà láyé nígbà yẹn. Nínú iye yẹn, àwọn ẹlẹ́sìn Híńdù, àwọn Mùsùlùmí àtàwọn ẹlẹ́sìn Sikhs ló pọ̀ jù. Nígbà tí wọ́n wá pín ilẹ̀ Íńdíà, wọ́n yọ orílẹ̀-èdè Pakistan tí wọ́n ti ń ṣe ẹ̀sìn Ìsìláàmù lára rẹ̀. Lákòókò yẹn, wọ́n ja ogun ìsìn tí wọ́n ti pààyàn nípakúpa. Àìmọye àwọn olùwá-ibi-ìsádi tó wá láti orílẹ̀-èdè méjèèjì yìí ni wọ́n dáná sun. Wọ́n lu àwọn kan lára wọn, wọ́n dá àwọn kan lára wọn lóró, wọ́n sì yìnbọn pa àwọn míì.
Àfi bíi pé àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ tá a ti mẹ́nu kàn yìí kò tó, làwọn apániláyà bá bẹ̀rẹ̀ wàhálà tiwọn nígbà tó di ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kọkànlélógún. Lónìí, gbogbo ayé ló ń bẹ̀rù àwọn apániláyà, bẹ́ẹ̀ ọ̀pọ̀ àwọn apániláyà yìí ló sọ pé àwọn ń ṣe ẹ̀sìn. Àwọn èèyàn ò wo ìsìn gẹ́gẹ́ bí ohun tó lè mú kí aráyé wà níṣọ̀kan. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìwà ipá àti ìpínyà ni ohun tí wọ́n mọ̀ tí ìsìn máa ń fà. Abájọ tí ìwé ìròyìn orílẹ̀-èdè Jámánì kan tí wọ́n ń pè ní FOCUS ṣe fi àwọn ìsìn ńlá-ńlá lágbàáyé wé ẹ̀tù ìbọn. Àwọn ìsìn náà ni Búdà, Kirisẹ́ńdọ̀mù, Confucius, Híńdù, Ìsìláàmù, ìsìn àwọn Júù, àti ìsìn Táò.
Àríyànjiyàn Ń Bẹ Lábẹ́lé
Àwọn ìsìn kan ń bá ìsìn mìíràn jagun. Bẹ́ẹ̀ làwọn kan tí wọ́n jọ ń ṣe ẹ̀sìn kan náà ń bara wọn ṣe awuyewuye. Bí àpẹẹrẹ, láti ọdún mélòó kan sẹ́yìn làwọn ìjọ tó wà nínú ìsìn Kirisẹ́ńdọ̀mù ti ń bára wọn jiyàn lórí ẹ̀kọ́ ìsìn, ìyẹn ò sì jẹ́ kí wọ́n ṣọ̀kan. Àtàlùfáà àtọmọ ìjọ ló ń béèrè pé: Ǹjẹ́ ó dára kéèyàn máa fètò sọ́mọ bíbí? Ṣé ó dára kéèyàn máa ṣẹ́yún? Ǹjẹ́ ó yẹ kí wọ́n máa yan obìnrin sí ipò àlùfáà? Ojú wo ló yẹ kí ṣọ́ọ̀ṣì máa fi wo àṣà kí ọkùnrin máa bá ọkùnrin lò pọ̀ àti kí obìnrin máa bá obìnrin lò pọ̀? Ǹjẹ́ ó yẹ kí ìsìn máa lọ́wọ́ sí ogun? Àìsí ìṣọ̀kan láàárín àwọn ìsìn ti mú kí ọ̀pọ̀ máa ṣe kàyéfì pé, ‘Báwo ni ìsìn tí kò lè so àwọn ọmọ ìjọ rẹ̀ pọ̀ ṣe lè mú kí aráyé wà níṣọ̀kan?’
Ó ṣe kedere pé ìsìn ní gbogbo gbòò kò lè mú kí aráyé wà níṣọ̀kan. Àmọ́, ṣé gbogbo ìsìn ni ìyapa wà láàárín àwọn ọmọ ìjọ wọn? Ǹjẹ́ ìsìn kan tiẹ̀ wà tó yàtọ, tó lè mú kí aráyé wà níṣọ̀kan?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]
Àwọn ọlọ́pàá fara ṣèṣe nígbà ìjà tó wáyé láàárín àwọn ẹlẹ́sìn lórílẹ̀-èdè Íńdíà ní ọdún 1947
[Credit Line]
Fọ́tò látọwọ́ Keystone/Getty Images