Ìhìn Rere Túbọ̀ Dé Ọ̀dọ̀ Àwọn Èèyàn Ní Makedóníà
Ìhìn Rere Túbọ̀ Dé Ọ̀dọ̀ Àwọn Èèyàn Ní Makedóníà
Lọ́jọ́ kan, ọkùnrin kan yọ sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lójú ìran, ó sì sọ fún un pé: “Rékọjá wá sí Makedóníà, kí o sì ràn wá lọ́wọ́.” (Ìṣe 16:9) Ọ̀rọ̀ ọkùnrin yìí fi hàn pé ìpínlẹ̀ tuntun kan wà tó yẹ káwọn oníwàásù ti lọ wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, ìyẹn ìpínlẹ̀ tí ń bẹ láwọn ìlú tó ti di ara orílẹ̀-èdè Gíríìsì lóde òní.
Lórílẹ̀-èdè Makedóníà òde òní, èèyàn á kà tó ẹgbẹ̀rún àti òjìlélẹ́gbẹ̀rin [1,840] èèyàn kó tó lè rí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn lórílẹ̀-èdè náà ni ò tíì gbọ́ nípa Jèhófà Ọlọ́run rí láyé wọn. A lè wá rí i pé ó ṣe pàtàkì pé káwọn Ẹlẹ́rìí tètè wá bí wọ́n ṣe máa wàásù ìhìn rere fáwọn tó wà lórílẹ̀-èdè yìí.—Mátíù 24:14.
Ọlọ́run ṣínà fáwọn ará Makedóníà kí wọ́n lè gbọ́ ìhìn rere. Ó ṣẹlẹ̀ pé lọ́jọ́ kan, ní oṣù November ọdún 2003, Àjọ Tó Ń Rí sí Ètò Afẹ́nifẹ́re ní Makedóníà ṣàdédé fi tẹlifóònù pe ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nílùú Skopje ní orílẹ̀-èdè Makedóníà. Wọ́n ní káwọn Ẹlẹ́rìí wá síbi ìpàtẹ ọlọ́jọ́ mẹ́ta kan tí yóò bẹ̀rẹ̀ ní ogúnjọ́ oṣù November, kí wọ́n wá ṣe ibi kékeré kan síbẹ̀ tí wọ́n ti lè máa sọ ìgbàgbọ́ wọn fáwọn èèyàn. Àǹfààní ńlá gbáà lèyí jẹ́ fún wọn láti wàásù fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn tí wọn ò tíì gbọ́ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run rí!
Àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n yọ̀ǹda ara wọn ṣiṣẹ́ kárakára láti ṣe ibì kan tí wọ́n lè to oríṣiríṣi ìwé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní èdè Makedóníà sí. Wọ́n fi ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìwé náà síbi táwọn tó bá wá síbi ìpàtẹ náà ti lè rí i kí wọ́n sì mú èyí tó bá wù wọ́n. Àwọn ìwé yìí jẹ́ kí ọ̀pọ̀ èèyàn lè gba omi ìyè tó ń tuni lára lọ́fẹ̀ẹ́.—Ìṣípayá 22:17.
Àwọn tó wá síbi ìpàtẹ náà ń fojú wá àwọn ìwé tó máa wúlò fún wọn, irú bí ìwé Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè-Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, àti Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé. a Àwọn méjìdínlọ́gọ́rùn-ún ló fún wọn ní àdírẹ́sì wọn pé àwọn ń fẹ́ káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá sọ́dọ̀ àwọn. Púpọ̀ lára wọn ló sọ pé iṣẹ́ rere làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe, wọ́n sì tún sọ pé ìwé gidi là ń tẹ̀ jáde.
Ọkùnrin kan wá sí ọ̀dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí tòun ti ọmọ rẹ̀ ọkùnrin kékeré tó fà lọ́wọ́. Ọkùnrin yìí béèrè bóyá òun lè rí ìwé tó wà fáwọn ọmọdé. Ni wọ́n bá fi Iwe Itan Bibeli Mi b hàn án. Bó ṣe yẹ ìwé náà wò, inú rẹ̀ dùn gan-an, ó wá béèrè iye tí wọ́n ń ta ìwé náà. Nígbà tí wọ́n sọ fún un pé ọrẹ àtinúwá ni wọ́n fi ń bójú tó iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe, èyí túbọ̀ mórí ẹ̀ wú. (Mátíù 10:8) Ó fi ìwé náà han ọmọ rẹ̀, ó ní: “O ò ri pé ìwé yìí dáa gan-an ni! Màá máa ka ìtàn kọ̀ọ̀kan fún ọ lójoojúmọ́!”
Ọ̀jọ̀gbọ́n kan wá sí ibi táwọn Ẹlẹ́rìí wà. Gbogbo ìsìn ni ọ̀jọ̀gbọ́n yìí fẹ́ mọ̀ nípa rẹ̀, àmọ́ ní pàtàkì ó fẹ́ mọ̀ nípa ìgbàgbọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Bí ọ̀jọ̀gbọ́n náà ṣe ń yẹ ìwé Mankind’s Search for God c wò, ó ní: “Bí mo ṣe fẹ́ kéèyàn máa to ọ̀rọ̀ gan-an ni wọ́n ṣe tò ó sínú ìwé yìí! Bí mo ṣe ronú pé ó yẹ kéèyàn gbà gbé ọ̀rọ̀ kalẹ̀ gẹ́lẹ́ ni wọ́n ṣe gbé e kalẹ̀.” Nígbà tó yá, àwọn ọmọ ilé ìwé tí ọ̀jọ̀gbọ́n yìí ti ń ṣiṣẹ́ olùkọ́ wá síbi ìpàtẹ náà, wọ́n béèrè bóyá àwọn lè gba ẹ̀dà tiwọn lára ìwé tí olùkọ́ yẹn gbà káwọn náà lè máa ka ìwé náà. Wọ́n ti gbà pé olùkọ́ náà máa fi àwọn ohun tó wà nínú ìwé náà kọ́ wọn ní kíláàsì.
Ìpàtẹ náà ló jẹ́ káwọn kan láǹfààní láti gbọ́ ọ̀rọ̀ òtítọ́ Bíbélì fún ìgbà àkọ́kọ́. Àwọn ọ̀dọ́ mélòó kan tó jẹ́ adití wá síbi ìpàtẹ náà bóyá àwọn náà máa rí ohun tó wù wọ́n. Ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí náà bá àwọn adití náà sọ̀rọ̀ ní ráńpẹ́, ọmọbìnrin kan ló sì bá a túmọ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí èdè àwọn adití. Ẹlẹ́rìí náà fi àwòrán inú ìwé Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí d han àwọn adití náà, ó sì ṣàlàyé fún wọn pé Jésù wo àwọn èèyàn sàn, títí kan àwọn adití. Inú wọn dùn láti mọ ìlérí tí Bíbélì ṣe pé láìpẹ́ Jésù yóò ṣe ìwòsàn fáwọn tó ń gbé lórí ilẹ̀ ayé nísinsìnyí. Tayọ̀tayọ̀ ni àwọn mélòó kan lára àwọn adití náà gba ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àwọn Ẹlẹ́rìí sì ṣètò pé kí Ẹlẹ́rìí kan tó gbọ́ èdè àwọn adití máa lọ sọ́dọ̀ wọn.
Yàtọ̀ sí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ní èdè Makedóníà, wọ́n tún kó àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tó wà ní èdè Albania, èdè Gẹ̀ẹ́sì, àti èdè Turkey lọ síbẹ̀. Ọkùnrin kan tí ò gbọ́ èdè Makedóníà sọ pé kí wọ́n fóun níwèé tó wà lédè Gẹ̀ẹ́sì. Nígbà tí wọ́n fún ọkùnrin náà ní Ilé Ìṣọ́ àti Jí! lédè Gẹ̀ẹ́sì, ó sọ pé òun gbọ́ èdè Turkey. Nígbà tí wọ́n wá fi àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tó wà ní èdè rẹ̀ hàn án, ẹnu yà á! Ó wá rí i pé gbogbo èèyàn làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fẹ́ láti ràn lọ́wọ́.
Ìwàásù ńlá ló wáyé lákòókò ìpàtẹ yẹn o, inú wa sì dùn gan-an láti rí i pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì! Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí fi hàn pé Jèhófà ti ṣí ọ̀nà lóríṣiríṣi kí ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run lè túbọ̀ dé ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn ní orílẹ̀-èdè Makedóníà.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe gbogbo ìwé wọ̀nyẹn.
b Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe gbogbo ìwé wọ̀nyẹn.
c Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe gbogbo ìwé wọ̀nyẹn.
d Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe gbogbo ìwé wọ̀nyẹn.
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
ÌTẸ̀SÍWÁJÚ ŃLÁ!
Ní May 17, 2003, ohun kan wáyé tó mú ìtẹ̀síwájú bá akitiyan tá à ń ṣe láti máa sọ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fáwọn èèyàn ní Makedóníà. Ọjọ́ yẹn gan-an ni wọ́n ṣe ìyàsímímọ́ ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nílùú Skopje. Ọdún méjì ni wọ́n fi kọ́ àwọn ilé tuntun tí wọ́n kọ́ láfikún sí ti tẹ́lẹ̀. Ibẹ̀ sì ti wá fi ìlọ́po mẹ́rin ju bó ṣe wà tẹ́lẹ̀ báyìí.
Ilé mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló wà tí wọ́n ń lò fún ọ́fíìsì àbójútó, ọ́fíìsì àwọn atúmọ̀ èdè, ibùgbé, ilé ìdáná, àti ilé ìfọṣọ. Arákùnrin Guy Pierce, tó jẹ́ ọkàn lára Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló lọ sọ ọ̀rọ̀ ìyàsímímọ́ níbẹ̀. Láti orílẹ̀-èdè mẹ́wàá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ làwọn èèyàn sì ti wá síbi ìyàsímímọ́ náà. Inú gbogbo wọn dùn jọjọ láti rí àwọn ilé tuntun tó jojú ní gbèsè wọ̀nyẹn.
[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 8, 9]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
BULGARIA
MAKEDÓNÍÀ
Skopje
ALBANIA
GÍRÍÌSÌ
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Ìlú Skopje, lórílẹ̀-èdè Makedóníà