Inú Mi Dùn Pé Mo Kópa Nínú Iṣẹ́ Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Tó Kárí Ayé
Ìtàn Ìgbésí Ayé
Inú Mi Dùn Pé Mo Kópa Nínú Iṣẹ́ Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Tó Kárí Ayé
GẸ́GẸ́ BÍ ANNA MATHEAKIS TI SỌ Ọ́
Ọkọ̀ ojú omi náà gbiná. Bí ọkọ̀ ojú omi gìrìwò tó gùn ní ẹsẹ̀ bàtà ọgọ́rùn-ún márùn-ún àti mọ́kànlélọ́gọ́ta [561] yìí bá lọ rì, ìsàlẹ̀ òkun ni màá kú sí. Gbogbo agbára ni mo fi lúwẹ̀ẹ́ kí n bàa lè yè bọ́, ìgbì omi òkun náà sì le kú. Ohun kan ṣoṣo tí mo lè ṣe kí n bàa lè léfòó ni pé kí n di ẹ̀wù amúniléfòó tí obìnrin kan wọ̀ mú. Mo gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún mi lókun àti ìgboyà. Gbogbo ohun tí mo lè ṣe kò jùyẹn lọ.
ÌṢẸ̀LẸ̀ yìí wáyé lọ́dún 1971 nígbà tí mò ń padà lọ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ míṣọ́nnárì mi ní ibì kẹta tí wọ́n yàn mí sí, ìyẹn ní orílẹ̀-èdè Ítálì. Gbogbo ohun tí mo ní ló ṣègbè sínú ọkọ̀ tó rì yẹn. Àmọ́ ṣá o, mi ò pàdánù àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ, ìyẹn ẹ̀mí mi, ìfẹ́ àwọn ará àti àǹfààní sísìn Jèhófà. Iṣẹ́ ìsìn yẹn ti gbé mi dé agbègbè mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lágbàáyé, ọkọ̀ tó rì yẹn sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ohun mánigbàgbé tó ṣẹlẹ̀ sí mi.
Ọdún 1922 ni wọ́n bí mi. Ìdílé mi ń gbé ní ìlú Rām Allāh tó jẹ́ nǹkan bíi kìlómítà mẹ́rìndínlógún sí ìlú Jerúsálẹ́mù. Ọmọ erékùṣù Kírétè làwọn òbí mi, àmọ́ Násárétì ni wọ́n ti tọ́ bàbá mi dàgbà. Èmi ni àbíkẹ́yìn nínú àwa ọmọ márùn-ún tí wọ́n bí, ìyẹn ọkùnrin mẹ́ta àti obìnrin méjì. Ìbànújẹ́ tó bá ìdílé wa kì í ṣe kékeré nígbà tí ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin tó tẹ̀ lé èyí tó dàgbà jù kú. Inú Odò Jọ́dánì ló rì sí nígbà tàwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ rẹ̀ lọ ṣèbẹ̀wò síbẹ̀. Lẹ́yìn tí ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú yìí wáyé, Màmá mi sọ pé òun ò gbé ìlú Rām Allāh mọ́, a sì ṣí lọ sí ìlú Áténì, lórílẹ̀-èdè Gíríìsì, ìyẹn nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́ta.
Ìdílé Wa Rí Òtítọ́
Kété lẹ́yìn tá a dé sí ilẹ̀ Gíríìsì, ẹ̀gbọ́n mi àgbà, Nikos, tó jẹ́ ẹni ọdún méjìlélógún nígbà
yẹn, bá àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pàdé. Orúkọ yẹn la mọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sí nígbà yẹn. Ẹ̀kọ́ Bíbélì tó ń kọ́ mú inú rẹ̀ dùn gan-an, ó sì nítara gan-an fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni. Èyí bí bàbá mi nínú gidigidi ó sì lé Nikos kúrò nílé. Àmọ́, nígbà tí bàbá mi bá lọ sí Palẹ́sìnì, èmi, màmá mi àtẹ̀gbọ́n mi obìnrin máa ń tẹ̀ lé Nikos lọ sáwọn ìpàdé Kristẹni. Mo ṣì ń rántí bí ìyá mi ṣe máa ń fìtara sọ àwọn ohun tó ń kọ́ làwọn ìpàdé náà. Àmọ́ kété lẹ́yìn náà, àrùn jẹjẹrẹ kọ lù ú, ó sì kú lẹ́ni ọdún méjìlélógójì. Ní àkókò ìṣòro yẹn, ẹ̀gbọ́n mi obìnrin, Ariadne, fìfẹ́ bójú tó ìdílé wa. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀dọ́ ṣì ni, ọ̀pọ̀ ọdún ló fi ṣe bí ìyá fún mi.Bàbá mi máa ń mú mi lọ sí Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì nígbà tó wà ní Áténì, kódà mo ṣì máa ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì náà lẹ́yìn tí bàbá mi kú, àmọ́ mi ò kì í lọ déédéé. Nígbà tí mi ò rí nǹkan kan tó fi hàn pé àwọn tó ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì náà ń fọkàn sin Ọlọ́run, ni mi ò bá lọ mọ́.
Lẹ́yìn tí bàbá mi kú, mo rí iṣẹ́ kan tó fi mí lọ́kàn balẹ̀ sílé iṣẹ́ ètò ìnáwó ìjọba. Àmọ́ ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin ní tirẹ̀ ti fi gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀ fún iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run, ọ̀pọ̀ ọdún ló sì fi sìn nílẹ̀ Gíríìsì. Lọ́dún 1934, ó ṣí lọ sí ìlú Kípírọ́sì. Lákòókò yẹn, kò sí Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ti ṣèrìbọmi ní erékùṣù náà, ìdí nìyẹn tó fi láǹfààní láti mú kí iṣẹ́ ìwàásù náà tẹ̀ síwájú níbẹ̀. Lẹ́yìn tó gbéyàwó, ìyàwó rẹ̀, Galatia, ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún fún ọ̀pọ̀ ọdún pẹ̀lú rẹ̀. a Ìgbà gbogbo ni Nikos máa ń fi ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ àtàwọn ìwé ìròyìn tó dá lórí Bíbélì ránṣẹ́ sí wa, àmọ́, ekukáká lá fi ń ṣí wọn wò. Kípírọ́sì ló ń gbé títí tó fi kú.
Mo Jẹ́ Kí Òtítọ́ Wọ̀ Mí Lọ́kàn
Lọ́dún 1940, George Douras, Ẹlẹ́rìí kan tó nítara tó ń gbé nílùú Áténì tó tún jẹ́ ọ̀rẹ́ Nikos wá sọ́dọ̀ wa, ó sì ní ká wá dara pọ̀ mọ́ àwùjọ kékeré kan láti máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ilé òun. Tayọ̀tayọ̀ la fi gba láti ṣe bẹ́ẹ̀. Láìpẹ́, a bẹ̀rẹ̀ sí sọ ohun tá à ń kọ́ fún àwọn èèyàn. Ẹ̀kọ́ tá à ń kọ́ látinú Bíbélì mú kí èmi àti ẹ̀gbọ́n mi obìnrin ya ìgbésí ayé wa sí mímọ́ fún Jèhófà. Ariadne ṣèrìbọmi lọ́dún 1942, èmi sì ṣèrìbọmi lọ́dún 1943.
Nígbà tí Ogun Àgbáyé Kejì parí, Nikos ní ká wá sí Kípírọ́sì, nípa bẹ́ẹ̀ a ṣí wá sí ìlú Nicosia lọ́dún 1945. Wọn ò dí iṣẹ́ ìwàásù wa lọ́wọ́ ní orílẹ̀-èdè Kípírọ́sì bí wọ́n ṣe dí i lọ́wọ́ ní ilẹ̀ Gíríìsì. Ìwàásù láti ilé dé ilé nìkan kọ́ la máa ń ṣe, a tún máa ń wàásù ní òpópónà pẹ̀lú.
Ọdún méjì lẹ́yìn ìyẹn, Ariadne ní láti padà sí orílẹ̀-èdè Gíríìsì. Ibẹ̀ ló ti pàdé ọkọ tó fẹ́, olùjọ́sìn Jèhófà lòun náà, bí ẹ̀gbọ́n mi ṣe dẹni tó ń gbé ní Áténì nìyẹn. Láìpẹ́ ọkọ ẹ̀gbọ́n mi àti ẹ̀gbọ́n mi rọ̀ mí láti padà sí orílẹ̀-èdè Gíríìsì kí n sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ní ìlú Áténì. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà ti wà lọ́kàn mi tẹ́lẹ̀, mo padà sí Áténì, níbi tí wọ́n ti nílò oníwàásù púpọ̀ sí i.
Àwọn Àǹfààní Tuntun Yọjú
Ní November 1, ọdún 1947, mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà, tí mò ń fi àádọ́jọ [150] wákàtí wàásù lóṣooṣù. Ìpínlẹ̀ tí ìjọ wa ti ń wàásù gbòòrò gan-an, mo sì máa ń rìn gan-an. Síbẹ̀, mo ti rí ọ̀pọ̀ ìbùkún. Àwọn ọlọ́pàá sábà máa ń mú Ẹlẹ́rìí tí wọ́n bá rí tó ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù tàbí tó ń lọ sáwọn ìpàdé Kristẹni, nítorí ìdí èyí, kò pẹ́ tí wọ́n fi mú mi.
Wọ́n fẹ̀sùn kàn mí pé mo ń yí àwọn èèyàn lọ́kàn padà láti ṣe ẹ̀sìn mi, ẹ̀ṣẹ̀ ńlá sì ni nígbà yẹn lọ́hùn-ún. Wọ́n sọ mí sẹ́wọ̀n oṣù méjì ní Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Averof tó wà fáwọn obìnrin ní ìlú Áténì. Obìnrin Ẹlẹ́rìí kan ti wà níbẹ̀ tẹ́lẹ̀, àwa
méjèèjì sì gbádùn ìbákẹ́gbẹ́ Kristẹni tó ń gbéni ró láìfi ti inú ẹ̀wọ̀n tá a wà pè. Lẹ́yìn tí mo ti ṣẹ̀wọ̀n tí wọ́n dá fún mi tán, mo ń fi ìdùnnú bá iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà mi nìṣó. Ọ̀pọ̀ lára àwọn tí mo bá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà yẹn ló ṣì jẹ́ olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà títí di ìsinsìnyí, ìyẹn sì ń fún mi láyọ̀.Lọ́dún 1949, wọ́n pè mí sí kíláàsì kẹrìndínlógún ti ilé ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ilé ẹ̀kọ́ yìí ni wọ́n ti ń dá àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún lẹ́kọ̀ọ́ láti ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì. Inú èmi àtàwọn mọ̀lẹ́bí mi dùn gan-an. Mo wá pinnu pé máa lọ sí ìpàdé àgbáyé nílùú New York nígbà ẹ̀rùn ọdún 1950, màá sì tibẹ̀ lọ́ sílé ẹ̀kọ́ Gílíádì.
Lẹ́yìn tí mo dé orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, mo láǹfààní láti ṣe iṣẹ́ ìtọ́jú ilé fún oṣù díẹ̀ ní orílé-iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílùú New York. Àyíká ibẹ̀ mọ́ tónítóní, ó dùn ún wò, ó sì wú mi lórí. Àwọn arákùnrin àti arábìnrin tó jẹ́ ọlọ́yàyà ló yí mi ká. Mi ò jẹ́ gbàgbé oṣù mẹ́fà tí mo lò níbẹ̀. Ẹ̀yìn ìyẹn ni àkókò wá tó láti bẹ̀rẹ̀ ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì, kò sì pẹ́ rárá tí oṣù márùn-ún tá a fi kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ níbẹ̀ fi parí. Àwa akẹ́kọ̀ọ́ wá rí i bí ìmọ̀ Ìwé Mímọ́ ti ṣeyebíye tó, tó sì dára gan-an. Èyí mú kí ayọ̀ wa pọ̀ sí i, ó sì mú ká túbọ̀ fẹ́ láti sọ fún àwọn èèyàn nípa ìmọ̀ òtítọ́ tó ń fúnni ní ìyè.
Ibi Tí Wọ́n Kọ́kọ́ Yàn fún Mi Láti Lọ Ṣiṣẹ́ Míṣọ́nnárì
Wọ́n fún wa láǹfààní nílé Ẹ̀kọ́ Gílíádì pé ká yan ẹni tá a máa jọ ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì kó tó di pé wọ́n sọ ibi tá a ti máa lọ ṣe iṣẹ́ ìsìn náà. Ruth Hemmig (tó ń jẹ́ Bosshard nísinsìnyí), lẹnì kejì mi, arábìnrin náà ṣèèyàn gan-an. Inú èmi àti Ruth dùn lọ́pọ̀lọpọ̀ nígbà tí wọ́n yàn wá sí ìlú Istanbul, lórílẹ̀-èdè Turkey, tó wà láàárín ilẹ̀ Éṣíà àti ilẹ̀ Yúróòpù! A mọ̀ pé wọ́n kò gba iṣẹ́ ìwàásù láyè lórílẹ̀-èdè yẹn nígbà yẹn, àmọ́ a ò mikàn rárá pé Jèhófà yóò tì wá lẹ́yìn.
Ìlú Istanbul jẹ́ ìlú tó lẹ́wà, táwọn èèyàn láti onírúurú orílẹ̀-èdè ń gbé. Ṣọ́ọ̀bù pọ̀ níbẹ̀, oríṣiríṣi oúnjẹ ilẹ̀ òkèèrè wà níbẹ̀, àwọn ilé ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí tó gbayì wà níbẹ̀, àwọn àgbègbè tó jẹ́ àrímáleèlọ àtàwọn omi tó fani mọ́ra sì yí ìlú náà ká. Àmọ́ ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ ni pé, a rí àwọn olóòótọ́ ọkàn tí wọ́n fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run. Àwọn ará Áméníà, àwọn Gíríìkì, àtàwọn Júù ló para pọ̀ jẹ́ àwùjọ àwọn Ẹlẹ́rìí kékeré tó wà ní ìlú Istanbul. Bó ti wù kó rí, ọ̀pọ̀ àwọn ará orílẹ̀-èdè mìíràn tún wà níbẹ̀, ó sì dára kéèyàn lè sọ díẹ̀díẹ̀ lára onírúurú èdè táwọn èèyàn náà ń sọ, títí kan èdè Turkey. Ó máa ń dùn mọ́ wa gan-an tá a bá bá àwọn ará orílẹ̀-èdè mìíràn tí òùngbẹ òtítọ́ ń gbẹ pàdé. Ọ̀pọ̀ lára wọn ṣì ń sin Jèhófà tọkàntọkàn di bá a ṣe ń sọ̀rọ̀ yìí.
Ó ṣeni láàánú pé kò ṣeé ṣe fún Ruth láti rí ìwé àṣẹ tuntun tí yóò fi máa gbé ìlú yẹn nìṣó gbà, ó sì di dandan fún un kó kúrò lórílẹ̀-èdè náà. Ó ṣì ń bá iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún rẹ̀ lọ lórílẹ̀-èdè Switzerland. Lẹ́yìn tá a ti fi ara wa sílẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún, àárò rẹ̀ ṣì máa ń sọ mí nítorí adùn-únbárìn ni, ó sì ṣèèyàn gan-an.
Mo Ṣí Lọ sí Apá Ibòmíràn Láyé
Lọ́dún 1963, wọ́n ò fún mi ní ìwé àṣẹ tuntun láti máa gbé orílẹ̀-èdè Turkey nìṣó. Kò rọrùn fún mi rárá láti fi àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ mi sílẹ̀, àwọn tó jẹ́ pé wọ́n ń tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí bí wọ́n ti ń gbìyànjú láti borí ọ̀pọ̀ ìṣòro tí wọ́n ní. Àwọn mọ̀lẹ́bí mi fẹ́ fún mi níṣìírí, ni wọ́n bá sanwó ọkọ̀ mi kí n lè lọ sí ìlú New York kí n lọ ṣe ìpàdé àgbègbè níbẹ̀. Nígbà yẹn, wọn ò tíì yàn ibòmíràn tí mo ti máa ṣiṣẹ́ fún mi.
Lẹ́yìn tí ìpàdé àgbègbè náà parí, wọ́n yàn mí sílùú Lima, lórílẹ̀-èdè Peru. Èmi àti arábìnrin kan tó jẹ́ ọ̀dọ́ tá a jọ fẹ́ máa ṣiṣẹ́ la jọ lọ tààràtà
láti ìlú New York sí ibi tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn fún mi náà. Mo kọ́ èdè Spanish mo sì ń gbé nílé àwọn míṣọ́nnárì tó wà lókè ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà níbẹ̀. Mo gbádùn iṣẹ́ ìwàásù níbẹ̀ gan-an mo sì mọ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó wà ládùúgbò yẹn dáadáa.Wọ́n Yàn Mí sí Ibòmíràn, Mo sì Tún Kọ́ Èdè Mìíràn
Nígbà tó yá, àwọn mọ̀lẹ́bí mi tó wà nílẹ̀ Gíríìsì bẹ̀rẹ̀ sí ní àwọn ìṣòro tí ọjọ́ ogbó máa ń fà, ara wọn ò sì le mọ́. Wọn ò fìgbà kan rí sọ pé kí n kúrò lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún tí mò ń ṣe kí n wá máa ṣiṣẹ́ owó kí n lè máa ran àwọn lọ́wọ́. Àmọ́, lẹ́yìn tí mo ti rò ó dáadáa tí mo sì gbàdúrà, mo rí i pé yóò dára tí mo bá lọ ń sìn níbi tó sún mọ́ ìdílé mi. Àwọn arákùnrin tó ń múpò iwájú fi ìfẹ́ hàn sí mi wọ́n sì gbà láti yàn mí sí orílẹ̀-èdè Ítálì, àwọn mọ̀lẹ́bí mi sì sọ pé àwọn á san owó tí màá fi wọkọ̀ débẹ̀. Kẹ́ ẹ sì wá wò ó, mo wá rí i pé wọ́n nílò àwọn ajíhìnrere gan-an nílẹ̀ Ítálì.
Mo tún ní láti kọ́ èdè tuntun, ìyẹn èdè Italian. Ìlú Foggia ni ibi tí wọ́n kọ́kọ́ yàn fún mi láti ṣiṣẹ́. Lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n gbé mi lọ sí ìlú Naples, níbi tí wọ́n ti nílò oníwàásù lójú méjèèjì. Posilipo tó jẹ́ apá kan lára ibi tó lẹ́wà jù lọ́ nílùú Naples ni ibi tí mo ti ń wàásù. Àgbègbè náà fẹ̀ gan-an, ẹnì kan ṣoṣo ló sì jẹ́ oníwàásù Ìjọba Ọlọ́run níbẹ̀. Mo gbádùn iṣẹ́ náà púpọ̀, Jèhófà sì ràn mí lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà tó yá, ìjọ ńlá kan wá wà ní agbègbè yẹn.
Lára àwọn èèyàn tí mo kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì níbẹ̀ ni ìyá kan àtàwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́rin. Òun àtàwọn ọmọbìnrin rẹ̀ méjì ṣì jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà títí dòní. Mo tún kọ́ tọkọtaya kan tí wọ́n ní ọmọbìnrin kékeré kan lẹ́kọ̀ọ́. Ìdílé yẹn tẹ̀ síwájú nínú òtítọ́ wọ́n sì ṣèrìbọmi láti fẹ̀rí ìyàsímímọ́ wọn hàn. Ní báyìí, ọmọbìnrin yẹn ti fẹ́ olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà kan wọ́n sì ń fi ìtara sin Ọlọ́run pa pọ̀. Nígbà tí mò ń kọ́ ìdílé ńlá kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mo rí i bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe lágbára tó. Bá a ṣe ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ mélòó kan tó fi hàn pé Ọlọ́run kò tẹ́wọ́ gba kéèyàn máa lo ère nínú ìjọsìn, ìyá náà kò tiẹ̀ dúró ká parí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà rárá. Ojú ẹsẹ̀ yẹn ló kó gbogbo ère tó wà nínú ilé rẹ̀ dà nù!
Ewu Lójú Òkun
Ní gbogbo ìgbà tí mo máa ń rìnrìn àjò láti ilẹ̀ Ítálì sí Gíríìsì, ọkọ̀ òkun ni mo máa ń wọ̀. Ìrìn àjò ojú òkun náà sì máa ń gbádùn mọ́ mi gan-an. Àmọ́ ọ̀kan lára àwọn ìrìn àjò yìí ṣàrà ọ̀tọ̀, ìyẹn ìrìn àjò tí mo rìn nígbà ẹ̀rùn ọdún 1971. Mò ń padà bọ̀ wá sí Ítálì nínú ọkọ̀ ojú omi tó ń jẹ́ Heleanna. Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ní August 28, iná ṣàdédé sọ nínú ilé ìgbọ́únjẹ inú ọkọ òkun náà. Iná náà ràn káàkiri, bẹ́ẹ̀ sì ni jìnnìjìnnì bo gbogbo èrò inú ọkọ. Àwọn obìnrin ń dákú, àwọn ọmọ kéékèèké ń ké, àwọn ọkùnrin ń ṣàròyé gan-an wọ́n sì tún ń fárígá. Àwọn èèyàn rọ́ gììrì lọ síbi táwọn ọkọ̀ agbẹ̀mílà tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀tún àti ẹ̀gbẹ́ òsì ọkọ̀ òkun náà wà. Àmọ́ ẹ̀wù amúniléfòó tó wà níbẹ̀ kò tó, ohun tí wọ́n sì fi ń gbé àwọn ọkọ̀ agbẹ̀mílà náà sójú òkun kò ṣiṣẹ́ dáadáa. Èmi ò ní ẹ̀wù amúniléfòó, bẹ́ẹ̀ iná ọ̀hún ń ròkè lálá, ohun kan tó kù tí mo lè ṣe tó bọ́gbọ́n mu kò sì ju pé kí n bẹ́ sínú òkun lọ.
Gbàrà tí mo bára mi nínú òkun, mo rí obìnrin kan tó wọ ẹ̀wù amúniléfòó tó sì léfòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi. Ó jọ pé obìnrin náà ò mọ béèyàn ṣe ń lúwẹ̀ẹ́, bí mo ṣe dì í lápá mú nìyẹn kí n lè Ìṣe, orí 27.
wọ́ ọ kúrò lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọkọ̀ tó ń rì lọ náà. Ìrugùdù òkun náà ń le sí i, àárẹ̀ sì ti mú mi gan-an bí mo ṣe ń sa gbogbo ipá mi kí n má bàa rì lọ sísàlẹ̀. Ó jọ pé ẹ̀pa ò fẹ́ bóró mọ́, àmọ́ mò ń gbàdúrà sí Jèhófà gan-an pé kó fún mi ní ìgboyà, èyí sì fún mi lókun gan-an. Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí mú mi rántí ohun tójú àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rí nígbà tí ọkọ̀ tó wọ̀ rì.—Bí mo ṣe di ẹnì kejì mi mú yìí ni ìgbì òkun ń gbé mi síbí gbé mi sọ́hùn-ún fún odindi wákàtí mẹ́rin, tí mò ń lúwẹ̀ẹ́ nígbà tí agbára mi bá gbé e díẹ̀, mo sì ń gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn mí lọ́wọ́. Níkẹyìn, mo tajú kan rí ọkọ òkun kékeré kan tó ń bọ̀. Wọ́n yọ mí, àmọ́ obìnrin tó ṣèkejì mi yẹn ti kú. Nígbà tá a dé ìlú Bari, ní orílẹ̀-èdè Ítálì, wọ́n gbé mi lọ sílé ìwòsàn, níbi tí mo ti gbàtọ́jú. Mo ní láti dúró sílé ìwòsàn náà fún bí ọjọ́ mélòó kan, ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí sì wá kí mi. Wọ́n pèsè gbogbo ohun tí mo nílò. Ìfẹ́ tí wọ́n fi hàn sí mi wú gbogbo àwọn tó wà ní wọ́ọ̀dù ilé ìwòsàn náà lórí gan-an ni. b
Lẹ́yìn tí ara mi ti yá dáadáa, wọ́n ní kí n lọ máa sìn nílùú Róòmù. Wọ́n ní kí n máa ṣiṣẹ́ ní agbègbè tí ilé ìtajà pọ̀ sí láàárín ìlú náà. Jèhófà ràn mí lọ́wọ́, mo sì ṣíṣẹ́ níbẹ̀ fún ọdún márùn-ún gbáko. Ogún ọdún ni mo fi gbádùn iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà nílẹ̀ Ítálì, mo sì wá fẹ́ràn àwọn ará Ítálì gan-an.
Mo Padà Síbi Tí Mo Ti Bẹ̀rẹ̀
Bọ́jọ́ ti ń gorí ọjọ́, àìlera Ariadne àti ọkọ rẹ̀ ń burú sí i. Mo rí i pé tí mo bá ń gbé nítòsí wọn, yóò lè ṣeé ṣe fún mi láti san díẹ̀ lára oore tí wọ́n ṣe fún mi àti ìfẹ́ tí wọ́n fi hàn sí mi. Kí n sòótọ́, inú mi ò dún láti fi Ítálì sílẹ̀. Àmọ́, àwọn arákùnrin tó ń mú ipò iwájú níbẹ̀ yọ̀ǹda mi láti lọ, mo sì ti ń ṣe aṣáájú ọ̀nà láti ìgbà ẹ̀rùn ọdún 1985 ní ìlú Áténì, níbi tí mo ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún lọ́dún 1947.
Mo ń wàásù ní agbègbè tí wọ́n yàn fún ìjọ mi, mo sì béèrè lọ́wọ́ àwọn arákùnrin tó wà ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ wa bóyá mo lè máa wàásù níbi táwọn ilé ìtajà pọ̀ sí láàárín ìlú. Ọdún mẹ́ta ni mo fi wàásù níbẹ̀ pẹ̀lú ẹnì kejì mi tá a jọ ń ṣe aṣáájú ọ̀nà. Ó ṣeé ṣe fún wa láti wàásù kúnnákúnná fáwọn èèyàn tó ṣòroó bá nílé.
Bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, bẹ́ẹ̀ ló ń wù mí gan-an láti máa sìn nìṣó, àmọ́ agbára mi ò gbé e mọ́. Ní báyìí ọkọ ẹ̀gbọ́n mi ti sùn nínú ikú. Ẹ̀gbọ́n mi, Ariadne, tó ti ń ṣe bí ìyá fún mi kò sì ríran mọ́. Ní tèmi, mi ò ṣàìsàn ní gbogbo àkókò tí mo fi ń ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Àmọ́ lẹ́nu àìpẹ́ yìí, mo ṣubú lórí àtẹ̀gùn, apá ọ̀tún mi sì dá. Lẹ́yìn ìyẹn mo tún ṣubú, ìbàdí mi sì yẹ̀. Wọ́n ní láti ṣeṣẹ́ abẹ́ fún mi, mo sì wà lórí ibùsùn fún ọ̀pọ̀ àkókò. Nísinsìnyí mi ò lè máa rìn kiri bó ṣe wù mí mọ́. Igi ni mo fi ń tilẹ̀ rìn, mi ò sì lè lọ síbikíbi àyàfi tí ẹnì kan bá mú mi lọ. Síbẹ̀, mo ń ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe, mo sì nírètí pé ara mi á ṣì le sí i. Kíkópa nínú iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àní bí kò tiẹ̀ tó nǹkan, ṣì jẹ́ olórí ohun tó ń fún mi láyọ̀, ó sì jẹ́ kí n ní ìbàlẹ̀ ọkàn.
Nígbà tí mo bá rántí àwọn ọdún aláyọ̀ tí mo ti lò nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, ọkàn mi máa ń kún fún ọpẹ́ sí Jèhófà. Jèhófà àti apá tó wà lórí ilẹ̀ ayé lára ètò rẹ̀ ti ń bá a nìṣó láti fún mi ní ìtọ́sọ́nà tó dára gan-an, wọ́n sì ti ràn mí lọ́wọ́ lọ́nà tó kọ yọyọ. Èyí sì ti mú kí n lè lo agbára mi dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ níwọ̀n bí mo ti fi gbogbo ìgbésí ayé mi sìn ín. Ìfẹ́ ọkàn mi ni pé kí Jèhófà fún mi lókun láti máa ṣe iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ nìṣó. Inú mi dùn pé mo lè kó ipa díẹ̀ nínú iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí Jèhófà ń darí kárí ayé.—Málákì 3:10.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo ojú ìwé 73 sí 89 nínú 1995 Yearbook of Jehovah’s Witnesses. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde.
b Tó bá fẹ́ ka ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìtàn yìí, wo Jí! February 8, 1972 (Gẹ̀ẹ́sì), ojú ìwé 12-16.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Èmi pẹ̀lú ẹ̀gbọ́n mi Ariadne àti ọkọ rẹ̀ Michalis nígbà tí mo fẹ́ gbéra lọ sílé ẹ̀kọ́ Gílíádì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Èmi àti Ruth Hemmig nígbà tí wọ́n yàn wá sí ìlú Istanbul, lórílẹ̀-èdè Turkey
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]
Èmi rèé ní orílẹ̀-èdè Ítálì, níbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1970
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Èmi àti ẹ̀gbọ́n mi, Ariadne lónìí