Èrè Wà Nínú Kéèyàn Jẹ́ Olóòótọ́
Èrè Wà Nínú Kéèyàn Jẹ́ Olóòótọ́
LÁWỌN orílẹ̀-èdè kan, àwọn ọmọdé fẹ́ràn kí wọ́n máa fi èèmọ́ sára ẹ̀wù olówùú táwọn ẹgbẹ́ wọn wọ̀, eré ni wọ́n sì máa fi ń bá ara wọn ṣe. Àwọn èèmọ́ náà á lẹ̀ mọ́ ẹ̀wù típẹ́típẹ́. Ohun yòówù tí ọmọ tó wọ ẹ̀wù náà ì báà máa ṣe, bóyá ó ń rìn ni o, ó ń sáré ni o, ó ń gbọnra ni o tàbí ó ń fò sókè ni o, àwọn èèmọ́ náà kò ní já bọ́ lára ẹ̀wù rẹ̀. Ọ̀nà kan ṣoṣo téèyàn lè gbà mú àwọn èèmọ́ náà kúrò ni kéèyàn yọ wọ́n kúrò lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan. Eré aládùn làwọn ọmọdé kà á sí.
Ká sòótọ́, kì í ṣe gbogbo èèyàn ló máa fẹ́ kí èèmọ́ lẹ̀ mọ́ àwọn láṣọ, àmọ́ gbogbo èèyàn ni bí èèmọ́ ṣe máa ń lẹ̀ mọ́ ara aṣọ máa ń jọ lójú. Bí èèmọ́ yẹn ṣe rí gan-an lọ̀rọ̀ olóòótọ́ èèyàn rí. Olóòótọ́ èèyàn kì í já ẹni tó bá ń bá ṣọ̀rẹ́ jù sílẹ̀. Ó máa ń ṣe gbogbo nǹkan tó lè mú kí àjọṣe àárín wọn gún régé kódà bí ipò nǹkan bá tiẹ̀ le koko pàápàá. Ọ̀rọ̀ náà “jíjẹ́ olóòótọ́” máa ń mú àwọn ànímọ́ bí òótọ́ inú, àdúrótì àti ìfọkànsìn wa sọ́kàn ẹni. Àmọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé o lè mọyì rẹ̀ gan-an táwọn èèyàn bá jẹ́ olóòótọ́ sí ọ, ǹjẹ́ ìwọ náà múra tán láti jólóòótọ́ sáwọn èèyàn? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ta ló yẹ kó o jólóòótọ́ sí?
Ìṣòtítọ́ Pọn Dandan Láàárín Tọkọtaya
Ọ̀kan lára ibi tí ìṣòtítọ́ ti ṣe pàtàkì ni àárín tọkọtaya, àmọ́ ó ṣeni láàánú pé ọ̀pọ̀ tọkọtaya kì í sábà jólóòótọ́ síra wọn. Bí tọkọtaya kan ò bá fi ara wọn sílẹ̀ tí wọ́n sì jọ máa ń wá ire ara wọn, ìyẹn fi hàn pé wọ́n ń tẹ̀ lé ẹ̀jẹ́ tí wọ́n jẹ́ nígbà ìgbéyàwó wọn. Ohun pàtàkì tó sì máa mú kí wọ́n ní ayọ̀ àti ìbàlẹ̀ ọkàn ni wọ́n ń ṣe yẹn. Kí nìdí? Ìdí ni pé Ọlọ́run dá èèyàn láti jẹ́ olóòótọ́ sí ara wọn. Nígbà tí Ádámù àti Éfà ṣègbéyàwó nínú ọgbà Édẹ́nì, Ọlọ́run sọ pé, ‘Ọkùnrin yóò fi baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, yóò sì fà mọ́ aya rẹ̀.’ Ohun kan náà ni aya ní láti ṣe, ó ní láti fà mọ́ ọkọ rẹ̀. Ọkọ àti aya ní láti jẹ́ olóòótọ́ sí ara wọn kí wọ́n sì máa bá ara wọn fọwọ́ sowọ́ pọ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 2:24; Mátíù 19:3-9.
Lóòótọ́, ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn ni wọ́n ti kọ ọ̀rọ̀ yìí sílẹ̀. Ǹjẹ́ ìyẹn túmọ̀ sí pé ìṣòtítọ́ nínú ìgbéyàwó kò bóde mu mọ́ lákòókò tiwa yìí? Ìdáhùn ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ni pé ó ṣì bóde mu gan-an. Àwọn èèyàn kan tó ṣèwádìí lórílẹ̀-èdè Jámánì rí i pé ìdá ọgọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún èèyàn ló ka ìṣòtítọ́ láàárín ọkọ àti aya sí ohun tó ṣe pàtàkì gan-an. Wọ́n tún ṣe ìwádìí kejì láti mọ àwọn ìwà tó dára jù lọ tó yẹ kí ọkùnrin àti obìnrin máa hù. Wọ́n ní káwọn ọkùnrin kan sọ ànímọ́ márùn-ún tí wọ́n fẹ́ jù lọ lára obìnrin, wọ́n sì tún ní káwọn obìnrin kan sọ ànímọ́ márùn-ún tí wọ́n fẹ́ jù lọ lára ọkùnrin. Ànímọ́ táwọn ọkùnrin àtàwọn obìnrin wọ̀nyí gbà pé ó ṣeyebíye jù lọ ni ìṣòtítọ́.
Bẹ́ẹ̀ ni o, ìṣòtítọ́ jẹ́ ara ìpìlẹ̀ lílágbára tó lè mú kí ìgbéyàwó kan yọrí sí rere. Síbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí a ti rí i nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, ibi gbogbo làwọn èèyàn ti gbà pé ìṣòtítọ́ dára àmọ́ wọn kì í fi ṣèwà hù. Bí àpẹẹrẹ, bí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn tọkọtaya ṣe ń kọra wọn sílẹ̀ ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè jẹ́ ẹ̀rí pé àìṣòótọ́ ti gbòde kan. Kí ni ọkọ
àti aya lè ṣe tí wọn ò fi ni hùwà àìṣòótọ́ tí wọ́n á sì jólóòótọ́ sí ara wọn?Ìṣòtítọ́ Ló Ń Mú Kí Ìgbéyàwó Tọ́jọ́
Tí ọkọ àti aya bá ń wá ọ̀nà láti fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ tó jinlẹ̀ sí ara wọn, ìṣòtítọ́ ni wọ́n ń fi hàn yẹn. Bí àpẹẹrẹ, ohun tó dáa jù ni pé kí ọkọ tàbí aya máa lo ọ̀rọ̀ náà “tiwa,” irú bíi “ọ̀rẹ́ wa,” “ọmọ wa,” “ilé wa,” àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ dípò kí wọ́n máa sọ pé “tèmi.” Nígbà tí tọkọtaya bá ń gbèrò láti ṣe nǹkan kan tàbí tí wọ́n fẹ́ ṣe ìpinnu kan, bóyá nípa ibùgbé, iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́, ọmọ títọ́, eré ìnàjú, lílo àkókò ìsinmi, tàbí nípa ọ̀rọ̀ ìjọsìn, ó yẹ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn gba ti ẹnì kejì rẹ̀ rò.—Òwe 11:14; 15:22.
Bí ọkọ tàbí aya kan bá mú kí ẹnì kejì rẹ̀ mọ̀ pé òun nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ìṣòtítọ́ ló ń fi hàn yẹn. Ọkàn ọkọ tàbí aya kì í balẹ̀ nígbà tí ẹnì kejì rẹ̀ bá ń ṣe kùrùkẹrẹ lọ́dọ̀ obìnrin mìíràn tàbí ọkùnrin mìíràn. Bíbélì gba àwọn ọkùnrin nímọ̀ràn pé kí wọ́n fà mọ́ “aya ìgbà èwe [wọn].” Kò yẹ kí ọkọ kan jẹ́ kí ọkàn òun máa fà sí obìnrin tí kì í ṣe aya rẹ̀. Dájúdájú ó ní láti yẹra fún ṣíṣe gulegule lọ́dọ̀ obìnrin mìíràn. Bíbélì kìlọ̀ pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó bá bá obìnrin ṣe panṣágà jẹ́ ẹni tí ọkàn-àyà kù fún; ẹni tí ó bá ṣe é ń run ọkàn ara rẹ̀.” Bákan náà la retí pé kí aya tẹ̀ lé ìlànà ìṣòtítọ́ tó dára gan-an yìí.—Òwe 5:18; 6:32.
Ǹjẹ́ ìṣòtítọ́ nínú ìgbéyàwó tó ohun tá à ń tìtorí ẹ̀ sapá? Bẹ́ẹ̀ ni, ó tó bẹ́ẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ó ń mú kí ìgbéyàwó túbọ̀ fìdí múlẹ̀ dáadáa kó sì wà títí lọ, àtọkọ àtaya ni yóò sì jàǹfààní rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ọkọ bá ń bójú tó aya rẹ̀ tinútinú, ọkàn aya náà yóò balẹ̀, á sì jẹ́ kí aya náà lè túbọ̀ ṣàgbéyọ àwọn ànímọ́ dáadáa tó ní. Bákan náà ni ìṣòtítọ́ aya yóò mú kí àwọn ànímọ́ tó dára tí ọkọ ní túbọ̀ fara hàn. Ìpinnu ọkọ láti jólóòótọ́ sí aya rẹ̀ yóò ran ọkọ náà lọ́wọ́ láti máa tẹ̀ lé ìlànà òdodo nínú gbogbo ohun tó bá ń ṣe ní ìgbésí ayé rẹ̀.
Bí ọkọ àti aya kan bá wà nínú ìṣòro, jíjẹ́ olóòótọ́ síra wọn yóò mú kí ọkàn àwọn méjèèjì balẹ̀ pé ìṣòro náà á yanjú. Àmọ́ tí tọkọtaya kan kò bá fọkàn tán ara wọn, ohun tí wọ́n á máa rò tí wọ́n bá ti níṣòro ni pé káwọn pínyà tàbí káwọn já ìwé ìkọ̀sílẹ̀ fúnra wọn. Irú èrò bẹ́ẹ̀ kì í yanjú ìṣòro rárá, kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe ló máa ń dá àwọn ìṣòro mìíràn sílẹ̀. Láwọn ọdún 1980, ọkùnrin kan tó jẹ́ ògbógi nínú iṣẹ́ aṣọ rírán tó sì gbajúmọ̀ gan-an fi ìyàwó àtàwọn ọmọ rẹ̀ sílẹ̀. Ǹjẹ́ ó láyọ̀ nígbà tó lọ ń dá gbé? Ogún ọdún lẹ́yìn ìgbà yẹn ló wá sọ pé ńṣe ni fífi tóun fi ìyàwó àtàwọn ọmọ òun sílẹ̀ mú kí ‘àárò wọn máa sọ òun, ìdààmú sì bá òun àti pé òun kì í lè sùn lálẹ́ nítorí ó máa ń wu òun láti sọ fáwọn ọmọ òun pé ó dàárọ̀ o.’
Ìṣòtítọ́ Láàárín Òbí àti Ọmọ
Táwọn òbí bá jólóòótọ́ síra wọn, ànímọ́ yìí lè ran àwọn ọmọ wọn. Nígbà táwọn ọmọ tá a tọ́ nínú ìdílé onífẹ̀ẹ́, tí wọ́n ti ń fi ìṣòtítọ́ bára wọn lò, bá dàgbà, yóò rọrùn fún wọn láti jólóòótọ́ sí ọkọ tàbí aya wọn àti sáwọn òbí wọn nígbà tí 1 Tímótì 5:4, 8.
ọjọ́ ogbó bá sọ àwọn òbí náà di aláìlera.—Àmọ́ ṣá, nígbà mìíràn àwọn òbí kọ́ ló máa ń kọ́kọ́ di aláìlera. Nígbà mìíràn ọmọ lè nílò ìtọ́jú tó ń gba àkókò àti okun. Bí ọ̀rọ̀ Herbert àti Gertrud ìyàwó rẹ̀ ṣe rí nìyẹn. Ó ti lè ní ogójì ọdún tí wọ́n ti jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àìsàn kan tó máa ń ba iṣan ẹsẹ̀ jẹ́ kò jẹ́ kí Dietmar ọmọ wọn gbádùn rárá, gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ ló sì fi ṣàìsàn náà. Lọ́dún méje tí Dietmar lò kẹ́yìn kó tó kú ní oṣù November 2002, tọ̀sántòru ló fi nílò àbójútó. Àwọn òbí rẹ̀ sì fìfẹ́ bójú tó o. Kódà wọ́n ní ẹ̀rọ tí wọ́n fi ń ṣètọ́jú aláìsàn nílé, wọ́n sì gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ lórí bí wọ́n á ṣe máa tọ́jú ọmọ náà. Àpẹẹrẹ gidi lèyí jẹ́ tá a bá ń sọ nípa dídúrótini lọ́jọ́ ìṣòro nínú ìdílé!
Ìṣòtítọ́ Ṣe Pàtàkì Láàárín Àwọn Ọ̀rẹ́
Obìnrin kan tó ń jẹ́ Birgit sọ pé: “Èèyàn lè láyọ̀ láìní ọkọ tàbí aya, àmọ́ ó ṣòro láti láyọ̀ láìní ọ̀rẹ́.” Ó ṣeé ṣe kó o gbà bẹ́ẹ̀. Yálà o ti ṣègbéyàwó tàbí àpọ́n ni ọ́, tó o bá ní ọ̀rẹ́ rere tó jẹ́ olóòótọ́, èyí yóò máa múnú rẹ dùn, ayé rẹ yóò sì lárinrin. Dájúdájú, bó o bá ti ṣègbéyàwó, ọkọ tàbí aya rẹ ló yẹ kó jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ tó sún mọ́ ọ jù lọ.
Ọ̀rẹ́ kì í kàn án ṣe ojúlùmọ̀ lásán. Èèyàn lè ní ọ̀pọ̀ ojúlùmọ̀, irú bí aládùúgbò, àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́, àtàwọn èèyàn tá a máa ń bá pàdé. Kéèyàn tó lè jẹ́ ọ̀rẹ́ tòótọ́, ó ń béèrè pé kéèyàn máa lo àkókò rẹ̀ àti okun rẹ̀ kó sì tún jẹ́ ẹni tó ṣeé fọkàn tán. Ohun àmúyangàn ni kéèyàn lọ́rẹ̀ẹ́. Níní ọ̀rẹ́ máa ń ṣeni láǹfààní, àmọ́ ó tún máa ń mú iṣẹ́ lọ́wọ́.
Ó pọn dandan ká máa bá àwọn ọ̀rẹ́ wa sọ̀rọ̀. Ohun tó jẹ́ ẹ̀dùn ọkàn wa wà lára àwọn ohun tá a lè sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Birgit sọ pé, “Bí èmi tàbí ọ̀rẹ́ mi obìnrin bá níṣòro kan, a máa ń bára wa sọ̀rọ̀ lórí tẹlifóònù lẹ́ẹ̀kan tàbí lẹ́ẹ̀mejì lọ́sẹ̀. Ìtùnú ló jẹ́ pé ó wà fún mi lọ́jọ́kọ́jọ́, ó sì máa ń tẹ́tí sí mi.” Ọ̀nà jíjìn kò dí ọ̀rẹ́ ṣíṣe lọ́wọ́. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún kìlómítà ni ibi tí Gerda ń gbé fi jìnnà síbi tí Helga ń gbé, ṣùgbọ́n wọ́n ti jẹ́ ọ̀rẹ́ ara wọn fún ohun tó lé ní ọdún márùndínlógójì. Gerda ṣàlàyé pé: “A máa ń kọ̀wé síra wa déédéé, a máa ń sọ ìrírí, a sì máa ń sọ ohun tó wà lọ́kàn wa fúnra wa, ì báà jẹ́ èyí tó múnú wa dùn tàbí èyí tó bà wá nínú jẹ́. Lẹ́tà Helga máa ń múnú mi dùn gan-an. Bákan náà la ṣe máa ń ronú.”
Ìṣòtítọ́ ṣe pàtàkì kí àjọṣe àárín àwọn ọ̀rẹ́ tó lè gún régé. Ìwà ọ̀dàlẹ̀ lè ba ọ̀rẹ́ téèyàn ti ń ṣe bọ̀ látọjọ́ pípẹ́ pàápàá jẹ́. Kódà àwọn ọ̀rẹ́ máa ń gba ara wọn nímọ̀ràn nípa ọ̀rọ̀ tó jẹ́ àṣírí. Àwọn ọ̀rẹ́ sì máa ń sọ̀rọ̀ látọkànwá láìbẹ̀rù pé ọ̀rẹ́ àwọn á fojú tẹ́ńbẹ́lú àwọn tàbí pé yóò lọ sọ ọ̀rọ̀ àṣírí àwọn fún ẹlòmíràn. Bíbélì sọ pé: “Alábàákẹ́gbẹ́ tòótọ́ a máa nífẹ̀ẹ́ ẹni ní gbogbo ìgbà, ó sì jẹ́ arákùnrin tí a bí fún ìgbà tí wàhálà bá wà.”—Òwe 17:17.
Níwọ̀n bí èrò, ìṣe àti ìwà àwọn ọ̀rẹ́ wa ti lè ràn wá, ó ṣe pàtàkì pé ká máa bá àwọn èèyàn tí ìgbésí ayé wọn bá tiwa mu ṣọ̀rẹ́. Bí àpẹẹrẹ, rí i dájú pé àwọn tí ìgbàgbọ́ wọn bá tìẹ mu lò ń bá ṣọ̀rẹ́, ìyẹn àwọn tẹ́ ẹ jọ ní èrò kan náà nípa ìwà rere, tí èrò yín sì tún ṣọ̀kan nípa ohun tó tọ́ àtèyí tí kò tọ́. Irú àwọn ọ̀rẹ́ bẹ́ẹ̀ yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti jẹ́ kí ọwọ́ rẹ tẹ ohun tó ò ń lépa. Àbí, kí nìdí tó o fi máa fẹ́ bá ẹnì kan ṣọ̀rẹ́ nígbà tí ìlànà tẹ́ni náà ń tẹ̀ lé àti ìwà tó ń hù kò bá tìrẹ mu? Bíbélì jẹ́ ká mọ bó ti ṣe pàtàkì tó láti yan àwọn ọ̀rẹ́ tó dára nígbà tó sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ní ìbálò pẹ̀lú àwọn arìndìn yóò rí láburú.”—Òwe 13:20.
A Lè Kọ́ Béèyàn Ṣe Ń Jólóòótọ́
Bí ọmọ kan bá ti mọ bá a ṣe ń fi èèmọ́ sára aṣọ ẹlòmíràn, ńṣe ni yóò máa wù ú láti ṣe eré
náà ní gbogbo ìgbà. Bí ọ̀rọ̀ ẹni tó jẹ́ olóòótọ́ ṣe rí nìyẹn. Kí nìdí? Ìdí ni pé bá a bá ṣe ń fi òótọ́ inú bá àwọn èèyàn lò tó ni yóò ṣe túbọ̀ máa rọrùn sí i fún wa láti jólóòótọ́. Tó bá ti mọ́ ẹnì kan lára láti jólóòótọ́ sí ìdílé rẹ̀ láti kékeré, kò ní nira fún irú ẹni bẹ́ẹ̀ láti jólóòótọ́ sí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. Nígbà tó bá yá, jíjẹ́ tí ẹni náà ti jẹ́ olóòótọ́ sáwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ á jẹ́ kó lè jólóòótọ́ sí ọkọ tàbí aya rẹ̀. Á sì tún ràn án lọ́wọ́ láti jẹ́ olóòótọ́ sí ọ̀rẹ́ kan tó ṣe pàtàkì jù lọ.Jésù sọ pé àṣẹ tó tóbi jù lọ ni pé ká nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run wa pẹ̀lú gbogbo ọkàn, èrò, àti okun wa. (Máàkù 12:30) Èyí túmọ̀ sí pé a gbọ́dọ̀ jólóòótọ́ sí Ọlọ́run délẹ̀délẹ̀. Jíjẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà Ọlọ́run máa ń mú èrè rẹpẹtẹ wá. Jèhófà kò ní já wa kulẹ̀ láé, nítorí ó sọ nípa ara rẹ̀ pé: “Adúróṣinṣin ni mi.” (Jeremáyà 3:12) Ní tòótọ́, jíjẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run ń mú èrè tí kò lópin wá.—1 Jòhánù 2:17.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 6]
Tó o bá ní ọ̀rẹ́ rere tó jẹ́ olóòótọ́, èyí yóò máa múnú rẹ dùn
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Nínú Ìdílé tí wọ́n ti jẹ́ olóòótọ́ síra wọn, wọ́n máa ń bójú tó ohun tẹ́nì kọ̀ọ̀kan wọn nílò