Ẹ̀sìn Kristẹni Gbilẹ̀ Láàárín Àwọn Júù Ọ̀rúndún Kìíní
Ẹ̀sìn Kristẹni Gbilẹ̀ Láàárín Àwọn Júù Ọ̀rúndún Kìíní
ÌPÀDÉ pàtàkì kan wáyé ní Jerúsálẹ́mù ní nǹkan bí ọdún 49 Sànmánì Kristẹni. “Àwọn tí wọ́n dà bí ọwọ̀n” nínú ìjọ Kristẹni ti ọ̀rúndún kìíní, ìyẹn Jòhánù, Pétérù àti Jákọ́bù iyèkan Jésù wà nípàdé yẹn. Àwọn méjì tí Bíbélì tún sọ pé ó wà níbẹ̀ ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àti Bánábà ìkejì rẹ̀. Ohun tí wọ́n ṣèpàdé lé lórí ni bí wọ́n ṣe máa pín ìpínlẹ̀ ńlá tí wọ́n ti ń wàásù. Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé: “[Wọ́n] fún èmi àti Bánábà ní ọwọ́ ọ̀tún ìṣàjọpín, pé kí a lọ sọ́dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè, ṣùgbọ́n kí àwọn lọ sọ́dọ̀ àwọn tí ó dádọ̀dọ́.”—Gálátíà 2:1, 9. a
Báwo ló ṣe yẹ ká lóye ohun tí wọ́n fẹnu kò lé lórí? Ṣé bí wọ́n ṣe pín ìpínlẹ̀ ìwàásù ìhìn rere yìí ni pé kí àwọn kan máa wàásù fáwọn Júù àtàwọn aláwọ̀ṣe Júù kí àwọn mìíràn sì lọ máa wàásù fáwọn Kèfèrí? Àbí wọ́n kàn pín ìpínlẹ̀ ìwàásù yìí ní ẹlẹ́kùnjẹkùn láìfi tàwọn tó wà níbẹ̀ pín in ni? Ká tó mọ èyí tó lè jẹ́, ó yẹ ká kọ́kọ́ mọ̀ díẹ̀ nípa àwọn Júù tó wà lájò, ìyẹn àwọn Júù tí kò gbé nílẹ̀ Palẹ́sìnì.
Àwọn Ibi Táwọn Júù Wà Ní Ọ̀rúndún Kìíní
Àwọn Júù mélòó ló ń gbé láwọn ibi tí kì í ṣe ilẹ̀ Palẹ́sìnì ní ọ̀rúndún kìíní? Ó jọ pé ọ̀pọ̀ ọ̀mọ̀wé fara mọ́ ohun tí ìwé Atlas of the Jewish World sọ lórí kókó yìí. Ìwé náà sọ pé: “Ó ṣòro láti mọ iye gbogbo wọn pátápátá, ṣùgbọ́n wọ́n fojú bù ú pé kété ṣáájú ọdún 70 Sànmánì Kristẹni àwọn Júù tó wà ní Jùdíà tó mílíọ̀nù méjì àtààbọ̀ nígbà táwọn tó ń gbé láwọn ibi yòókù ní ilẹ̀ ọba Róòmùlé ní mílíọ̀nù mẹ́rin dáadáa. . . . Ó dà bíi pé tá a bá rí èèyàn mẹ́wàá nínú gbogbo èèyàn orílẹ̀-èdè tó wà lábẹ́ ilẹ̀ ọba Róòmù, ọ̀kan lára wọn á jẹ́ Júù. Àní láwọn ìlú àwọn ará ìlà oòrùn táwọn Júù pọ̀ sí jù lọ, ó dà bíi pé tá a bá fi máa rí èèyàn mẹ́rin, ọ̀kan lára wọn á jẹ́ Júù.”
Àwọn ilẹ̀ bíi Síríà, Éṣíà Kékeré, Babilónì àti Íjíbítì tí wọ́n wà lápá ìlà oòrùn làwọn Júù pọ̀ sí jù. Àwọn Júù tó wà láwọn ilẹ̀ wọ̀nyí pọ̀ ju àwọn tó wà ní ilẹ̀ Yúróòpù lọ. Ara àwọn Júù tó wà lájò yìí làwọn kan tó jẹ́ Kristẹni tó gbajúmọ̀ ní ọ̀rúndún kìíní, àwọn bíi Bánábà láti Kípírọ́sì, Pírísíkà àti Ákúílà tó jẹ́ ọmọ bíbí Pọ́ńtù tó lọ gbé ní Róòmù, Ápólò láti Alẹkisáńdíríà àti Pọ́ọ̀lù láti ìlú Tásù.—Ìṣe 4:36; 18:2, 24; 22:3.
Àwọn Júù tó wà lájò ń lọ́wọ́ sí ohun tó ń lọ ní ìlú ìbílẹ̀ wọn ní Palẹ́sìnì dáadáa. Ọ̀nà kan tí wọ́n gbà ń ṣe èyí ni owó orí tí wọ́n fi ń ránṣẹ́ sí tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù lọ́dọọdún láti máa fi ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe ní tẹ́ńpìlì àti ìjọsìn tí wọ́n ń ṣe níbẹ̀. Lórí kókó yìí, ọ̀mọ̀wé John Barclay sọ pé: “Ẹ̀rí fi hàn pé àwọn Júù tó wà lájò ò fọwọ́ yẹpẹrẹ mú ọ̀rọ̀ sísan owó orí yìí, kódà àwọn ọlọ́rọ̀ àárín wọn máa ń fi ọrẹ tó jọjú ránṣẹ́ pẹ̀lú.”
Ọ̀nà mìíràn táwọn Júù tún gbà ń lọ́wọ́ sí ọ̀rọ̀ ìlú ìbílẹ̀ wọn ni ìrìn-àjò ẹ̀sìn tí wọ́n ń rìn wá Ìṣe 2:9-11, ìyẹn ìtàn ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni. Nígbà yẹn, àwọn Júù rin ìrìn-àjò ẹ̀sìn wá láti ilẹ̀ Pátíà, Mídíà, Élámù, Mesopotámíà, Kapadókíà, Pọ́ńtù, Éṣíà, Fíríjíà, Panfílíà, Íjíbítì, Líbíà, Róòmù, Kírétè àti Arébíà.
sí Jerúsálẹ́mù lọ́dọọdún láti wá ṣe àjọyọ̀. A rí àpẹẹrẹ èyí látinú ìtàn tó wà nínúÀwọn tó ń ṣe kòkárí ètò inú tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù máa ń kọ̀wé sáwọn Júù tó wà lájò. Ẹ̀rí sì fi hàn pé Gàmálíẹ́lì, olùkọ́ òfin tí ìwé Ìṣe 5:34 sọ̀rọ̀ rẹ̀, kọ lẹ́tà sí àwọn tó ń gbé ilẹ̀ Bábílónì àtàwọn ilẹ̀ mìíràn. Nígbà tí wọ́n mú Pọ́ọ̀lù lóǹdè dé Róòmù lọ́dún 59 Sànmánì Kristẹni, “àwọn tí wọ́n jẹ́ sàràkí-sàràkí . . . lára àwọn Júù” sọ fún un pé “àwa kò gba àwọn lẹ́tà nípa rẹ láti Jùdíà, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni lára àwọn ará tí ó ti dé kò ròyìn tàbí kí wọ́n sọ ohun burúkú kankan nípa rẹ.” Ohun tí èyí fi hàn ni pé wọ́n sábà máa ń fi lẹ́tà àti ìròyìn ránṣẹ́ láti Palẹ́sìnì sí Róòmù déédéé.—Ìṣe 28:17, 21.
Bíbélì Septuagint, ìyẹn Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù tí wọ́n túmọ̀ sí èdè Gíríìkì, làwọn Júù tó wà lájò ń lò. Ìwé kan sọ pé: “A ò jayò pa tá a bá sọ pé Bíbélì Septuagint làwọn Júù tó wà lájò ń kà, pé òun ni wọ́n gbà pé ó jẹ́ Bíbélì, tàbí ‘Ìwé Mímọ́,’ tiwọn.” Àwọn Kristẹni ìjímìjí lo Bíbélì yìí dáadáa nígbà tí wọ́n ń kọ́ni.
Gbogbo èyí làwọn Kristẹni tó wà nínú ìgbìmọ̀ olùdarí ní Jerúsálẹ́mù nígbà náà lọ́hùn-ún mọ̀. Ìhìn rere ṣáà ti dé ọ̀dọ̀ àwọn Júù tó wà lẹ́yìn odi nígbà náà, irú bíi Síríà àtàwọn ibi tó jìnnà jùyẹn lọ, títí kan Damásíkù àti Áńtíókù. (Ìṣe 9:19, 20; 11:19; 15:23, 41; Gálátíà 1:21) Láìsí àní-àní, ètò bí iṣẹ́ ìwàásù yóò ṣe máa lọ lọ́jọ́ iwájú làwọn tó wà nípàdé ọdún 49 Sànmánì Kristẹni yẹn ṣe. Ẹ jẹ́ ká wá wo ohun tí Bíbélì sọ nípa bí iṣẹ́ ìwàásù náà ṣe gbilẹ̀ láàárín àwọn Júù àtàwọn aláwọ̀ṣe Júù.
Bí Pọ́ọ̀lù Ṣe Rìnrìn Àjò Láti Wàásù Ìhìn Rere Fáwọn Júù Tó Wà Lájò
Iṣẹ́ tí Jésù gbé lé Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́ níbẹ̀rẹ̀ ni pé kí ó “gbé orúkọ [Jésù Kristi] lọ sọ́dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn ọba àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.” b (Ìṣe 9:15) Lẹ́yìn ìpàdé tí wọ́n ṣe ní Jerúsálẹ́mù, Pọ́ọ̀lù ń bá a lọ láti wá àwọn Júù tó wà lájò kàn ní gbogbo ibi tó bá dé láti lè wàásù fún wọn. (Wo àpótí tó wà lójú ìwé 14.) Èyí fi hàn pé ńṣe ni wọ́n pín ìpínlẹ̀ wọn ní ẹlẹ́kùnjẹkùn yálà àwọn Júù ló wà níbẹ̀ tàbí àwọn tí kì í ṣe Júù. Pọ́ọ̀lù àti Bánábà ń bá iṣẹ́ míṣọ́nnárì wọn lọ lápá ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ ọba Róòmù, àwọn yòókù sì ń bójú tó àwọn Júù tó wà ní Palẹ́sìnì àti ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn Júù tó ń gbé ní ìlà oòrùn ayé.
Nígbà tí Pọ́ọ̀lù àtàwọn alábàáṣiṣẹ́ rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ìrìn-àjò míṣọ́nnárì ẹlẹ́ẹ̀kejì láti Áńtíókù ti Síríà, ẹ̀mí mímọ́ darí wọn gba apá ìwọ̀ oòrùn lọ sí Éṣíà Kékeré títí lọ dé Tíróásì. Láti ibẹ̀ ni wọ́n ti sọdá sí Makedóníà torí wọ́n gbà pé “Ọlọ́run ti fi ọlá àṣẹ pe [àwọn] láti polongo ìhìn rere fún [àwọn ará Makedóníà].” Ẹ̀yìn ìgbà náà ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí dá ìjọ Kristẹni sílẹ̀ láwọn ìlú ńlá mìíràn ní ilẹ̀ Yúróòpù, títí kan ìlú Áténì àti Kọ́ríńtì.—Ìṣe 15:40, 41; 16:6-10; 17:1–18:18.
Nígbà tí Pọ́ọ̀lù parí ìrìn-àjò míṣọ́nnárì rẹ̀ ẹlẹ́ẹ̀kẹta ní nǹkan bí ọdún 56 Sànmánì Kristẹni, ó fẹ́ mú kí iṣẹ́ ìwàásù náà túbọ̀ débi tó jìnnà sí i lápá ìwọ̀ oòrùn tí wọ́n pín fún un nígbà ìpàdé tí wọ́n ṣe ní Jerúsálẹ́mù. Ó kọ̀wé pé: “Ìháragàgà wà ní ìhà ọ̀dọ̀ mi láti polongo ìhìn rere pẹ̀lú fún ẹ̀yin tí ẹ wà ní Róòmù,” lẹ́yìn náà, ó ní, “èmi yóò gba ọ̀dọ̀ yín lọ sí Sípéènì.” (Róòmù 1:15; 15:24, 28) Àmọ́, báwo ni ìhìn rere ṣe ń lọ sí láàárín ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn Júù tó ń gbé lápá ìlà oòrùn tí kì í ṣe ilẹ̀ Palẹ́sìnì?
Àwọn Júù Tó Ń Gbé ní Apá Ìlà Oòrùn
Ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Kristẹni, ilẹ̀ Íjíbítì làwọn Júù tó wà lájò pọ̀ sí jù, pàápàá ìlú Alẹkisáńdíríà tó jẹ́ olú ìlú rẹ̀ nígbà náà. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Júù ló wà ní ìlú Alẹkisáńdíríà yìí tó jẹ́ ojúkò ìṣòwò àti àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀, wọ́n sì kọ́ sínágọ́gù káàkiri ìlú náà. Júù kan tó ń jẹ́ Philo tó
jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Alẹkisáńdíríà sọ pé, àpapọ̀ àwọn Júù tó wà ní ilẹ̀ Íjíbítì nígbà náà tó mílíọ̀nù kan ó kéré tán. Bákan náà, ọ̀pọ̀ àwọn Júù tún tẹ̀dó sí ìlú Kírénè àti àgbègbè rẹ̀ lórílẹ̀-èdè Líbíà nítòsí Íjíbítì.Àwọn ibi tá a dárúkọ yìí làwọn Júù kan tó di Kristẹni ti wá. Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa “Àpólò, ọmọ ìbílẹ̀ Alẹkisáńdíríà,” “àwọn ará Kípírù àti ará Kírénè kan,” àti “Lúkíọ́sì ará Kírénè” tó kọ́wọ́ ti ìjọ tó wà ní Áńtíókù ti Síríà lẹ́yìn. (Ìṣe 2:10; 11:19, 20; 13:1; 18:24) Yàtọ̀ sí àwọn tí Bíbélì dárúkọ yìí, Bíbélì ò sọ̀rọ̀ nípa bí àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ṣe wàásù ní Íjíbítì àti àgbègbè rẹ̀ rárá, àfi èyí tó sọ nípa bí Fílípì ajíhìnrere ṣe wàásù fún ìwẹ̀fà ará Etiópíà.—Ìṣe 8:26-39.
Ibòmíì táwọn Júù tún pọ̀ sí ni ilẹ̀ Bábílónì, títí lọ dé ilẹ̀ Pátíà, Mídíà àti Élámù. Òpìtàn kan sọ pé: “Kò síbi tá a máa dé ní gbogbo àgbègbè odò Tígírísì àti ti Yúfírétì, láti ilẹ̀ Àméníà títí dé ibi tí òkun ti ya wọ ilẹ̀ Páṣíà, àti láti apá àríwá Òkun Kásípíà títí lọ sí àgbègbè Mídíà lápá ìlà oòrùn, tá ò ní rí àwọn Júù.” Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Judaica sọ pé iye àwọn Júù tó wà níbẹ̀ tó ogójì ọ̀kẹ́ [800, 000] tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Òpìtàn kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Josephus tó gbé ayé ní ọ̀rúndún kìíní sọ pé ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Júù ló máa ń ti Bábílónì lọ sí Jerúsálẹ́mù láti lọ ṣe àwọn àjọyọ̀ ọdọọdún.
Ǹjẹ́ àwọn arìnrìn-àjò ẹ̀sìn kankan láti Bábílónì ṣèrìbọmi ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni? A ò mọ̀, àmọ́ àwọn ará Mesopotámíà wà lára àwọn tó gbọ́ ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pétérù lọ́jọ́ náà. (Ìṣe 2:9) A mọ̀ dájú pé àpọ́sítélì Pétérù wà ní Bábílónì ní nǹkan bí ọdún 62 sí 64 Sànmánì Kristẹni. Ibẹ̀ ló wà nígbà tó kọ lẹ́tà rẹ̀ kìíní, ó sì lè jẹ́ pé ibẹ̀ ló ti kọ lẹ́tà rẹ̀ kejì pẹ̀lú. (1 Pétérù 5:13) Ó dájú pé Bábílónì táwọn Júù pọ̀ sí yìí wà lára ìpínlẹ̀ tí wọ́n pín fún Pétérù, Jòhánù àti Jákọ́bù nígbà ìpàdé tí Pọ́ọ̀lù tọ́ka sí nínú lẹ́tà tó kọ sáwọn ará Gálátíà.
Ìjọ Jerúsálẹ́mù Wàásù Fáwọn Júù Tó Wà Lájò
Jákọ́bù jẹ́ alábòójútó nínú ìjọ tó wà ní Jerúsálẹ́mù, ó sì wà nínú ìpàdé tí wọ́n ti pín ìpínlẹ̀ ìwàásù yẹn. (Ìṣe 12:12, 17; 15:13; Gálátíà 1:18, 19) Ìṣojú rẹ̀ ni ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Júù tó wá sí Jerúsálẹ́mù láti àwọn ibi tí kì í ṣe ilẹ̀ Palẹ́sìnì ṣe gbọ́ ìwàásù ìhìn rere nígbà Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni tí wọ́n sì ṣèrìbọmi.—Ìṣe 1:14; 2:1, 41.
Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn Júù ló wá síbi àjọyọ̀ tí wọ́n ṣe lọ́dún yẹn àtàwọn àjọyọ̀ ẹ̀yìn ìgbà náà. Èrò máa ń pọ̀ gan-an ní Jerúsálẹ́mù débi pé àwọn kan ní láti lọ wáyè sí àwọn àrọko tàbí kí wọ́n wábi pàgọ́ sí. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Judaica sọ pé yàtọ̀ sáwọn ọ̀rẹ́ àti ojúlùmọ̀ táwọn tó rìnrìn àjò ẹ̀sìn wá máa lè rí, wọ́n tún máa ń wọ tẹ́ńpìlì lọ ṣe ìjọsìn, wọ́n máa ń rúbọ wọ́n sì máa ń kẹ́kọ̀ọ́ nínú Tórà, ìyẹn ìwé òfin Mósè.
Ó dájú pé Jákọ́bù àtàwọn ará yòókù nínú ìjọ Jerúsálẹ́mù lo àǹfààní yẹn láti wàásù fáwọn Júù tó wà lájò. Nígbà tí “inúnibíni ńlá dìde sí ìjọ tí ó wà ní Jerúsálẹ́mù” lẹ́yìn ikú Sítéfánù, àwọn àpọ́sítélì ti ní láti ṣọ́ra gan-an tí wọ́n bá ń wàásù. (Ìṣe 8:1) Síbẹ̀, àkọsílẹ̀ fi hàn pé ńṣe ni iye àwọn ọmọ ẹ̀yìn ń pọ̀ sí i ṣáá ṣáájú ìgbà inúnibíni yìí àti lẹ́yìn náà nítorí ìtara táwọn Kristẹni fi ń wàásù.—Ìṣe 5:42; 8:4; 9:31.
Ẹ̀kọ́ Wo Ni Ìtàn Yìí Kọ́ Wa?
Ó hàn gbangba pé àwọn Kristẹni ìjimìjí sa gbogbo ipá wọn láti wàásù dé ọ̀dọ̀ àwọn Júù níbikíbi tí wọ́n bá wà. Bákan náà, Pọ́ọ̀lù àtàwọn míì wàásù fáwọn tí kì í ṣe Júù ní ilẹ̀ Yúróòpù. Wọ́n ṣe ohun tí Jésù pa láṣẹ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nígbà tó fẹ́ kúrò láyé, ìyẹn ni pé kí wọ́n lọ “máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.”—Mátíù 28:19, 20.
Àpẹẹrẹ wọn jẹ́ ká rí bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká ṣe iṣẹ́ ìwàásù wa létòlétò kí ẹ̀mí Jèhófà lè tì wá lẹ́yìn. A tún rí àǹfààní tó wà nínú wíwàásù fáwọn tó mọyì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, pàápàá láwọn ìpínlẹ̀ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò ti fi bẹ́ẹ̀ pọ̀. Ǹjẹ́ àwọn apá ibì kan wà nínú ìpínlẹ̀ ìjọ yín táwọn èèyàn ti ń gbọ́ ìwàásù ju àwọn apá ibòmíì? Á dára kẹ́ ẹ máa wàásù láwọn ibi wọ̀nyẹn lemọ́lemọ́. Ǹjẹ́ àwọn nǹkan kan wà táwọn aráàlú máa ń ṣe ládùúgbò yín tẹ́ ẹ lè lọ síbẹ̀ láti lọ jẹ́rìí lọ́nà àìjẹ́-bí-àṣà tàbí láti wàásù ní òpópónà ibẹ̀?
Ohun tí yóò túbọ̀ ṣe wá láǹfààní ni pé bá a ṣe ń ka ìtàn àwọn Kristẹni ìjímìjí nínú Bíbélì ká tún rí i pé a mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ìtàn náà àtàwọn ìlú tí wọ́n ti ṣẹlẹ̀. Ohun kan tí yóò jẹ́ ká lè mọ èyí ni ìwé pẹlẹbẹ “Wo ‘Ilẹ̀ Dáradára’ Náà,” tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwòrán ilẹ̀ àti fọ́tò wà nínú rẹ̀.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìgbà àpérò tí ìgbìmọ̀ olùdarí ti ọ̀rúndún kìíní ṣe lórí ọ̀ràn ìdádọ̀dọ́ ni wọ́n ṣèpàdé yìí tàbí kó jẹ́ pé àbájáde àpérò náà ló fa ìpàdé yìí.—Ìṣe 15:6-29.
b Bí Pọ́ọ̀lù ṣe wàásù láàárín àwọn Júù ni àpilẹ̀kọ yìí sọ̀rọ̀ lé lórí, kì í ṣe ọ̀nà tó gbà ṣe iṣẹ́ ìwàásù rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “àpọ́sítélì fún àwọn orílẹ̀-èdè.”—Róòmù 11:13.
[Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 14]
Ọ̀RỌ̀ ÀWỌN JÚÙ TÓ WÀ LÁJÒ JẸ PỌ́Ọ̀LÙ LÓGÚN GAN-AN
ṢÁÁJÚ ÌPÀDÉ TÍ WỌ́N ṢE NÍ JERÚSÁLẸ́MÙ LỌ́DÚN 49 SÀNMÁNÌ KRISTẸNI
Ìṣe 9:19, 20 Damásíkù — “ó bẹ̀rẹ̀ sí wàásù . . . nínú àwọn
sínágọ́gù”
Ìṣe 9:29 Jerúsálẹ́mù — “ó . . . ń bá àwọn Júù tí ń sọ èdè
Gíríìkì sọ̀rọ̀”
Ìṣe 13:5 Sálámísì, Kípírù — ó “bẹ̀rẹ̀ sí kéde ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nínú
àwọn sínágọ́gù àwọn Júù”
Ìṣe 13:14 Áńtíókù ní Písídíà — ó “wọ sínágọ́gù”
Ìṣe 14:1 Íkóníónì — ó “wọ sínágọ́gù àwọn Júù”
LẸ́YÌN ÌPÀDÉ TÍ WỌ́N ṢE NÍ JERÚSÁLẸ́MÙ LỌ́DÚN 49 SÀNMÁNÌ KRISTẸNI
Ìṣe 16:14 Fílípì — “Lìdíà, . . . tí ó jẹ́ olùjọsìn Ọlọ́run”
Ìṣe 17:1 Tẹsalóníkà — “sínágọ́gù àwọn Júù”
Ìṣe 17:10 Bèróà — “sínágọ́gù àwọn Júù”
Ìṣe 17:17 Áténì — ó “fèrò-wérò nínú sínágọ́gù pẹ̀lú àwọn Júù”
Ìṣe 18:4 Kọ́ríńtì — ó “sọ àsọyé nínú sínágọ́gù”
Ìṣe 18:19 Éfésù — ó “wọ sínágọ́gù lọ, ó sì fèrò-wérò
pẹ̀lú àwọn Júù”
Ìṣe 19:8 Éfésù — “ní wíwọ sínágọ́gù, ó sọ̀rọ̀ pẹ̀lú àìṣojo
fún oṣù mẹ́ta”
Ìṣe 28:17 Róòmù — “ó pe àwọn . . . sàràkí-sàràkí jọ
lára àwọn Júù”
[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 15]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Ibi púpọ̀ làwọn tó gbọ́ ìhìn rere ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni ti wá
ÍLÍRÍKÓNÌ
ÍTÁLÌ
Róòmù
MAKEDÓNÍÀ
GÍRÍÌSÌ
Áténì
KÍRÉTÈ
Kírénè
LÍBÍÀ
BÍTÍNÍÀ
GÁLÁTÍÀ
ÉṢÍÀ
FÍRÍJÍÀ
PANFÍLÍÀ
KÍPÍRỌ́SÌ
ÍJÍBÍTÌ
ETIÓPÍÀ
PỌ́ŃTÙ
KAPADÓKÍÀ
SÌLÍṢÍÀ
MESOPOTÁMÍÀ
SÍRÍÀ
SAMÁRÍÀ
Jerúsálẹ́mù
JÙDÍÀ
MÍDÍÀ
Bábílónì
ÉLÁMÙ
ÁRÉBÍÀ
PÁTÍÀ
[Àwọn omi ńlá]
Òkun Mẹditaréníà
Òkun Dúdú
Òkun Pupa
Ibi Tí Òkun Ti Ya Wọ Ilẹ̀ Páṣíà