Ṣé Wàá Bá Ọlọ́run Rìn?
Ṣé Wàá Bá Ọlọ́run Rìn?
“Jẹ́ ẹni tí ó mẹ̀tọ́mọ̀wà ní bíbá Ọlọ́run rẹ rìn.”—MÍKÀ 6:8.
1, 2. Báwo la ṣe lè fi bí ọ̀rọ̀ wa ṣe rí lára Jèhófà wé ti òbí kan tó ń kọ́ ọmọ rẹ̀ ní ìrìn?
ỌMỌ ìrákòrò kan dá ẹsẹ̀ rẹ̀ tí kò tíì ranlẹ̀ tilẹ̀, ó na ọwọ́ síwájú, ni òbí rẹ̀ bá fà á ní tẹ̀tẹ́. Ìgbà àkọ́kọ́ rèé tó máa ṣísẹ̀ rìn láyé rẹ̀. Ohun tó ṣe yẹn lè má fi bẹ́ẹ̀ jọni lójú o, àmọ́ ohun ńlá ló jẹ́ lójú ìyá àti bàbá ọmọ náà. Ó jẹ́ àkókò kan tó fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ pé ọjọ́ ọ̀la ọmọ náà á dára. Àwọn òbí náà á bẹ̀rẹ̀ sí hára gàgà de ìgbà tí wọ́n á máa di ọmọ náà lọ́wọ́ mú tàwọn pẹ̀lú rẹ̀ á jọ máa rìn káàkiri bọ́jọ́ ti ń gorí ọjọ́, tọ́dún sì ń gorí ọdún. Ọ̀pọ̀ ọ̀nà ni wọ́n á máa gbà wá báwọn ṣe máa tọ́ ọmọ náà sọ́nà, bí wọ́n ṣe máa pèsè ohun tó nílò tí wọ́n á sì jẹ́ alábàárò rẹ̀ títí lọ.
2 Bí ọ̀rọ̀ àwa èèyàn tá a jẹ́ ọmọ Jèhófà Ọlọ́run ṣe rí lára rẹ̀ náà nìyẹn. Ìgbà kan wà tó sọ nípa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tàbí Éfúráímù tó jẹ́ ènìyàn rẹ̀ pé: “Mo kọ́ Éfúráímù ní ìrìn, ní gbígbé wọn sí apá mi . . . Mo ń bá a nìṣó láti fi àwọn ìjàrá ará ayé fà wọ́n, pẹ̀lú àwọn okùn ìfẹ́.” (Hóséà 11:3, 4) Níbí yìí, Jèhófà sọ pé òun dà bíi bàbá onífẹ̀ẹ́ kan tó ń fi sùúrù kọ́ ọmọ rẹ̀ bó ṣe máa rìn, bóyá kó tiẹ̀ gbé e mọ́ra nígbà tó bá ṣubú. Jèhófà tó jẹ́ òbí tó dára jù lọ fẹ́ láti kọ́ wa bí a ó ṣe máa rìn. Inú rẹ̀ tún máa ń dùn láti wà pẹ̀lú wa bá a ṣe ń tẹ̀ síwájú. Gẹ́gẹ́ bí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a gbé àpilẹ̀kọ yìí kà ti sọ, a lè bá Ọlọ́run rìn! (Míkà 6:8) Àmọ́ kí ni bíbá Ọlọ́run rìn túmọ̀ sí? Kí nìdí tó fi yẹ ká máa bá Ọlọ́run rìn? Báwo ló ṣe lè ṣeé ṣe? Àwọn ìbùkún wò léèyàn sì máa rí tó bá ń bá Ọlọ́run rìn? Ẹ jẹ́ ká gbé àwọn ìbéèrè mẹ́rẹ̀ẹ̀rin yìí yẹ̀ wò lọ́kọ̀ọ̀kan.
Kí Ni Bíbá Ọlọ́run Rìn Túmọ̀ Sí?
3, 4. (a) Kí ló mú kí àpèjúwe nípa bíbá Ọlọ́run rìn jẹ́ èyí tó pabanbarì gan-an? (b) Kí ni bíbá Ọlọ́run rìn túmọ̀ sí?
3 Lóòótọ́, èèyàn ẹlẹ́ran ara àti ẹ̀jẹ̀ kò lè máa bá Jèhófà tó jẹ́ ẹni ẹ̀mí kẹ́sẹ̀ rìn. (Ẹ́kísódù 33:20; Jòhánù 4:24) Nítorí náà, èdè ìṣàpẹẹrẹ ni Bíbélì lò nígbà tó sọ pé àwọn èèyàn ń bá Ọlọ́run rìn. Ó lo àpèjúwe pípabanbarì kan tó yé gbogbo èèyàn ní gbogbo orílẹ̀-èdè tó wà láyé, kódà àpèjúwe náà wúlò nígbàkigbà. Ó ṣe tán, ibo làwọn èèyàn ò ti ní lóye rẹ̀ tá a bá sọ pé ẹnì kan ń bá ẹnì kejì rìn tàbí àkókò wo ni àwọn èèyàn ò ní lóye irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀? Àpèjúwe yìí fi àjọṣe tó máa ń wà láàárín ọ̀rẹ́ kòríkòsùn hàn, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Irú àjọṣe bẹ́ẹ̀ jẹ́ ká túbọ̀ lóye ohun tí bíbá Ọlọ́run rìn túmọ̀ sí. Àmọ́, ẹ jẹ́ ká túbọ̀ ṣàlàyé kókó yìí sí i.
4 Rántí àwọn ọkùnrin olóòótọ́ nì, Énọ́kù àti Nóà. Kí nìdí tí Bíbélì fi sọ pé wọ́n bá Ọlọ́run rìn? (Jẹ́nẹ́sísì 5:24; 6:9) Nínú Bíbélì, ọ̀rọ̀ náà “láti rìn” sábà máa ń túmọ̀ sí kéèyàn máa gbé ìgbésí ayé rẹ̀ lọ́nà kan pàtó. Énọ́kù àti Nóà yan ọ̀nà kan tó bá ìfẹ́ Jèhófà Ọlọ́run mu. Dípò kí wọ́n máa ṣe bíi tàwọn èèyàn tó yí wọn ká, ojú Jèhófà ni wọ́n ń wò fún ìtọ́sọ́nà, wọ́n sì tẹ̀lé ọ̀nà tó darí wọn sí. Wọ́n nígbẹ̀ẹ́kẹ̀lé nínú rẹ̀. Ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé Jèhófà ló ń bá wọn ṣe ìpinnu wọn ni? Rárá o. Jèhófà ti fún àwa èèyàn lómìnira láti yan ohun tó bá wù wá, ó sì fẹ́ ká lo òmìnira náà pa pọ̀ pẹ̀lú “agbára ìmọnúúrò” wa. (Róòmù 12:1) Àmọ́, bá a ṣe ń ṣe ìpinnu, ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ń jẹ́ kí èrò Jèhófà tó ga ju tiwa lọ fíìfíì darí bá a ṣe ń ronú. (Òwe 3:5, 6; Aísáyà 55:8, 9) Ìyẹn túmọ̀ sí pé, bá a ṣe ń rìn ìrìn àjò ìgbésí ayé wa là ń bá Jèhófà rìn.
5. Kí nìdí tí Jésù fi sọ̀rọ̀ nípa fífi ìgbọ̀nwọ́ kan kún ọjọ́ ayé ẹni?
5 Bíbélì sábà máa ń fi ìgbésí ayé èèyàn wé ìrìn àjò tàbí ìrìn kan. Nígbà mìíràn, àfiwé yẹn máa ń ṣe tààrà, ìgbà mìíràn sì wà tí kì í ṣe tààrà. Bí àpẹẹrẹ, Jésù sọ pé: “Ta ni nínú yín, nípa ṣíṣàníyàn, tí ó lè fi ìgbọ̀nwọ́ kan kún ìwọ̀n gígùn ìwàláàyè rẹ̀?” (Mátíù 6:27) Ohun kan lè ṣe ọ́ ní kàyéfì nínú ọ̀rọ̀ yẹn. Kí nìdí tí Jésù fi sọ̀rọ̀ nípa fífi “ìgbọ̀nwọ́ kan” kún “gígùn ìwàláàyè” ẹnì kan nígbà tó jẹ́ pé ìrìn ni wọ́n máa ń fi ìgbọ̀nwọ́ díwọ̀n, tí wọ́n sì máa ń fi àkókò díwọ̀n ọjọ́ ayé èèyàn? a Ó dájú pé ńṣe ni Jésù ń fi ìwàláàyè èèyàn wé ìrìn àjò. Lẹ́nu kan, ohun tó fi ń kọ́ni ni pé àníyàn ṣíṣe kò lè mú kó o fi ìṣísẹ̀ kan péré kún ìrìn àjò ìgbésí ayé rẹ. Àmọ́, ṣé ó wá yẹ ká ronú pé kò sóhun tá a lè ṣe nípa bí àkókò tá a máa fi bá Ọlọ́run rìn yóò ṣe gùn tó? Rárá o! Ìyẹn wá sún wa dórí ìbéèrè kejì pé, kí nìdí tó fi yẹ ká máa bá Ọlọ́run rìn?
Kí Nìdí Tá A Fi Ní Láti Máa Bá Ọlọ́run Rìn?
6, 7. Kí ni ẹ̀dá èèyàn aláìpé nílò gidi gan-an, kí sì nìdí tó fi yẹ́ ká yíjú sí Jèhófà láti rí nǹkan náà gbà?
6 Ìdí kan tó fi yẹ ká máa bá Jèhófà Ọlọ́run rìn wà nínú Jeremáyà 10:23 tó sọ pé: “Mo mọ̀ dáadáa, Jèhófà, pé ọ̀nà ará ayé kì í ṣe tirẹ̀. Kì í ṣe ti ènìyàn tí ń rìn àní láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” Nítorí náà, àwa èèyàn ò lágbára tàbí ẹ̀tọ́ láti darí ìgbésí ayé wa fúnra wa. A nílò ìtọ́sọ́nà gidi gan-an. Ńṣe làwọn tó fàáké kọ́rí tí wọn ò tẹ̀lé ìlànà Ọlọ́run ń ṣe àṣìṣe kan náà tí Ádámù àti Éfà ṣe. Àwọn tọkọtaya àkọ́kọ́ náà rò pé àwọn lẹ́tọ̀ọ́ láti fúnra àwọn pinnu ohun tó dára àti ohun tí kò dára. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6) Ẹ̀tọ́ yẹn “kì í ṣe” tiwa rárá.
7 Ǹjẹ́ o mọ̀ pé o nílò ìtọ́sọ́nà nínú ìrìn àjò ìgbésí ayé rẹ? Ojoojúmọ́ la máa ń ní àwọn ìpinnu tá a ní láti ṣe, ì báà jẹ́ èyí tó kéré tàbí èyí tó tóbi. Àwọn kan lára àwọn ìpinnu wọ̀nyí ṣòroó ṣe gan-an, wọ́n sì lè nípa lórí ọjọ́ ọ̀la wa àti tàwọn èèyàn wa. Àmọ́ o, ẹnì kan tó jù wá lọ fíìfíì, tó sì gbọ́n jù wá lọ ti múra tán láti fún wa ní ìtọ́sọ́nà onífẹ̀ẹ́ ká lè ṣe àwọn ìpinnu náà dáadáa! Ó ṣeni láàánú pé ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn lónìí ló rò pé àwọn lè dá ṣèpinnu káwọn sì darí ìṣísẹ̀ ara àwọn. Wọ́n fojú di òótọ́ ọ̀rọ̀ tó wà nínú Òwe 28:26, èyí tó kà pé: “Ẹni tí ó bá gbẹ́kẹ̀ lé ọkàn-àyà ara rẹ̀ jẹ́ arìndìn, ṣùgbọ́n ẹni tí ń fi ọgbọ́n rìn ni ẹni tí yóò sá àsálà.” Jèhófà fẹ́ ká bọ́ lọ́wọ́ àjálù tó máa ń wáyé nígbà téèyàn bá gbẹ́kẹ̀ lé ọkàn-àyà tó ń gbékútà. (Jeremáyà 17:9) Ó fẹ́ ká máa rìn nínú ọgbọ́n, ká gbẹ́kẹ̀ lé òun pé Òun lẹni tí yóò darí wa tí yóò sì máa kọ́ wa. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìrìn àjò ìgbésí ayé wa yóò fi wa lọ́kàn balẹ̀, yóò dùn bí oyin, yóò sì mérè wá.
8. Ibo ni ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé máa ń sin ẹ̀dá lọ, síbẹ̀ kí ni Jèhófà fẹ́ fún wa?
8 Ìdí mìíràn tó tún fi yẹ ká máa bá Ọlọ́run rìn ní í ṣe pẹ̀lú bí ìrìn tá a fẹ́ rìn náà ṣe gùn tó. Bíbélì sọ ohun kan tó bani lọ́kàn jẹ́. Ohun náà ni pé gbogbo èèyàn ló ń lọ síbì kan náà. Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn àdánwò tó ń bá ọjọ́ ogbó rìn, ìwé Oníwàásù 12:5 sọ pé: “Ènìyàn ń rìn lọ sí ilé rẹ̀ pípẹ́ títí, àwọn apohùnréré ẹkún sì ti rìn yí ká ní ojú pópó.” Kí ni “ilé rẹ̀ pípẹ́ títí” yìí? Sàréè ni, níbi tí ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé ń gbé gbogbo wa lọ. (Róòmù 6:23) Àmọ́ ohun tí Jèhófà fẹ́ fún wa ju ìrìn àjò kúkúrú tó kún fún wáhálà tá à ń rìn látìgbà tí wọ́n ti bí wa títí di ọjọ́ ikú wa. (Jóòbù 14:1) Kíkì bíbá Ọlọ́run rìn nìkan la fi lè láǹfààní láti rìn fún àkókò gígùn tó fẹ́ ká fi rìn, ìyẹn títí ayérayé. Àbí kì í ṣe nǹkan tíwọ náà fẹ́ nìyẹn? Nítorí náà, o ní láti máa bá Bàbá rẹ rìn.
Báwo La Ṣe Lè Bá Ọlọ́run Rìn?
9. Kí nìdí tí Jèhófà fi fi ara rẹ̀ pa mọ́ fáwọn èèyàn rẹ̀ láwọn ìgbà kan, síbẹ̀ ìdánilójú wo ló fúnni gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Aísáyà 30:20?
9 Ìkẹta nínú àwọn ìbéèrè tá à ń gbé yẹ̀ wò gbà àfiyèsí gidi. Ìbéèrè náà ni pé, Báwo la ṣe lè bá Ọlọ́run rìn? A rí ìdáhùn rẹ̀ nínú Aísáyà 30:20, 21, tó sọ pé: “Olùkọ́ni rẹ Atóbilọ́lá kì yóò tún fi ara rẹ̀ pa mọ́, ojú rẹ yóò sì di ojú tí ń rí Olùkọ́ni rẹ Atóbilọ́lá. Etí rẹ yóò sì gbọ́ ọ̀rọ̀ kan lẹ́yìn rẹ tí ń sọ pé: ‘Èyí ni ọ̀nà. Ẹ máa rìn nínú rẹ̀,’ bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹ lọ sí apá ọ̀tún tàbí bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹ lọ sí apá òsì.” Nínú àyọkà tó fúnni níṣìírí yìí, ọ̀rọ̀ Jèhófà tó wà ní Aís 30 ẹsẹ ogún ti ní láti rán àwọn èèyàn rẹ̀ létí pé ìgbà táwọn bá ṣọ̀tẹ̀ sí i ló máa ń fi ara rẹ̀ pà mọ́ fún wọn. (Aísáyà 1:15; 59:2) Àmọ́ níbí yìí, wọn ò sọ̀rọ̀ Jèhófà bíi pé ò fi ara rẹ̀ pa mọ́, wọ́n sọ ọ́ bíi pé ó dúró síwájú àwọn èèyàn rẹ̀ tó jẹ́ olóòótọ́. A lè fojú inú wo olùkọ́ kan tó dúró síwájú àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀, tó ń kọ́ wọn ní ohun tó fẹ́ kí wọ́n mọ̀.
10. Ọ̀nà wo lo lè gbà “gbọ́ ọ̀rọ̀ kan lẹ́yìn rẹ” látẹnu Olùkọ́ni rẹ Atóbilọ́lá?
10 Àpèjúwe mìíràn tó yàtọ̀ síyẹn ló wà nínú Aís 30 ẹsẹ kọkànlélógún. Ibẹ̀ ṣàpèjúwe Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ń rìn lẹ́yìn àwọn èèyàn rẹ̀, ó sì ń tibẹ̀ sọ ọ̀nà tó tọ́ tí wọ́n ní láti máa rìn fún wọn. Àwọn ọ̀mọ̀wé tó kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ ti kíyè sí i pé ó ní láti jẹ́ pé ọ̀nà táwọn olùṣọ́ àgùntàn máa ń gbà tẹ̀ lé àwọn àgùntàn wọn lẹ́yìn nígbà mìíràn ni gbólóhùn yìí ń sọ nípa rẹ̀. Ìyẹn bí wọ́n ṣe máa ń tẹ̀ lé àwọn àgùntàn lẹ́yìn, tí wọ́n á máa sọ̀rọ̀ láti darí wọn, kí àwọn àgùntàn náà má bàa kọrí síbi tí kò yẹ. Báwo ni àpèjúwe yìí ṣe kàn wá? Ṣé ẹ rí i, nígbà tá a bá ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ká lè rí ìtọ́sọ́nà, àwọn ọ̀rọ̀ tó ti wà lákọsílẹ̀ láti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn là ń kà yẹn. À ń gbọ́ wọn láti ẹ̀yìn wa nítorí pé wọ́n ti wà lákọsílẹ̀ tipẹ́tipẹ́. Síbẹ̀ wọn ṣe pàtàkì lóde òní bí wọ́n ti ṣe pàtàkì lákòókò tá a kọ wọ́n sílẹ̀. Ìmọ̀ràn Bíbélì lè tọ́ wa sọ́nà nínú àwọn ìpinnu tá à ń ṣe lójoojúmọ́, ó sì tún lè ràn wá lọ́wọ́ láti mọ ọ̀nà tá a máa gbà gbé ìgbésí ayé wa lọ́jọ́ ọ̀la. (Sáàmù 119:105) Ìgbà tá a bá fi gbogbo ọkàn wa wá irú ìmọ̀ràn bẹ́ẹ̀ tá a sì fi wọ́n sílò ni Jèhófà tó lè jẹ́ Olùdarí wa. Ìgbà yẹn la lè sọ pé à ń bá Ọlọ́run rìn.
11. Ní ìbámu pẹ̀lú Jeremáyà 6:16, àpèjúwe afúnnilókun wo ni Jèhófà lò láti fi ké sí àwọn èèyàn rẹ̀, àmọ́ báwo ni wọ́n ṣe fèsì?
11 Ǹjẹ́ a máa ń jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run darí wa dáadáa? Ó dára ká máa sinmẹ̀dọ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan ká sì máa fi òótọ́ inú yẹ ara wa wò dáadáa. Gbé ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀ yẹ̀ wò, ibẹ̀ kà pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí: ‘Ẹ dúró jẹ́ẹ́ ní ọ̀nà, kí ẹ sì rí, ẹ béèrè fún àwọn òpópónà ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn, ibi tí ọ̀nà tí ó dára wà nísinsìnyí; ẹ sì máa rìn ín, kí ẹ sì rí ìdẹ̀rùn fún ọkàn yín.’” (Jeremáyà 6:16) Àwọn ọ̀rọ̀ yìí lè rán wa létí arìnrìn-àjò kan tó dúró ní ìkòríta kan láti béèrè ọ̀nà. Ohun tó jọ èyí nípa tẹ̀mí ló yẹ káwọn èèyàn Jèhófà tí wọ́n jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ ní Ísírẹ́lì ṣe. Ó yẹ kí wọ́n wá ọ̀nà tí wọ́n a fi padà sí “àwọn òpópónà ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn.” “Ọ̀nà tí ó dára” yẹn ni ọ̀nà táwọn baba ńlá wọn tó jẹ́ olóòótọ́ rìn, orílẹ̀-èdè náà sì ti rìn gbéregbère kúrò ní ọ̀nà náà nítorí ìwà òmùgọ̀ wọn. Ó dunni pé ńṣe làwọn ọmọ Ísírẹ́lì tún ń ṣagídí tí wọn ò tẹ̀lé ìránnilétí onífẹ̀ẹ́ tí Jèhófà fún wọn yìí. Ẹsẹ kan náà yẹn tún ń bá a lọ pé: “Ṣùgbọ́n wọ́n ń wí pé: ‘Àwa kì yóò rìn.’” Àmọ́, lóde òní, àwọn èèyàn Ọlọ́run ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn rere yẹn.
12, 13. (a) Ọ̀nà wo làwọn ẹni àmì òróró ọmọlẹ́yìn Kristi ti gbà fi ìmọ̀ràn tó wà nínú Jeremáyà 6:16 sílò? (b) Báwo la ṣe lè yẹ ara wa wò nípa bá a ṣe ń rìn lóde òní?
12 Látìgbà tó ti kù díẹ̀ kí ọ̀rúndún kọkàndínlógún parí làwọn ẹni àmì òróró ọmọlẹ́yìn Kristi ti gbà pé àwọn ni ìmọ̀ràn inú ìwé Jeremáyà 6:16 ń bá wí. Gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ kan, wọ́n ti mú ipò iwájú nínú fífi gbogbo ọkàn wọn padà sí “àwọn òpópónà ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn.” Wọn ò ṣe bíi ti Kirisẹ́ńdọ̀mù apẹ̀yìndà, ńṣe ni wọ́n ń fi ìṣòtítọ́ tẹ̀ lé “àwọn ọ̀rọ̀ afúnni-nílera” tí Jésù Kristi fi lélẹ̀ táwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ò sì fọwọ́ yẹpẹrẹ mú láti ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Kristẹni. (2 Tímótì 1:13) Títí di oní olónìí làwọn ẹni àmì òróró ń ran ara wọn lọ́wọ́, tí wọ́n tún ń ran àwọn “àgùntàn mìíràn” tó jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ wọn lọ́wọ́ láti máa tọ ọ̀nà ìgbésí ayé tó ń fúnni nílera àti ayọ̀, èyí tí Kirisẹ́ńdọ̀mù kùnà láti tọ̀.—Jòhánù 10:16.
13 Nípa pípèsè oúnjẹ tẹ̀mí ní àkókò tó bẹ́tọ̀ọ́ mu, ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ náà ti ran àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn lọ́wọ́ láti rí “àwọn òpópónà ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn,” kí wọ́n lè máa bá Ọlọ́run rìn. (Mátíù 24:45-47) Ǹjẹ́ o wà lára àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn yìí? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, kí lo lè ṣe tó ò fi ní sú lọ láé, ìyẹn ni pé tó ò fi ni dẹni tó ń tọ ọ̀nà ti ara rẹ? Ó bọ́gbọ́n mu kó o máa sinmẹ̀dọ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan kó o máa ṣàyẹ̀wò ọ̀nà tó ò gbà ń rin ìrìn àjò ìgbésí ayé rẹ. Tó o bá ń ka Bíbélì déédéé àtàwọn ìwé tá a gbé karí Bíbélì, tó o tún ń wà níbi gbogbo ìtòlẹ́sẹẹsẹ táwọn ẹni àmì òróró ń ṣe láti fún wa nítọ̀ọ́ni lónìí, a jẹ́ pé o ti ń gba ẹ̀kọ́ láti máa bá Ọlọ́run rìn nìyẹn. Tó o bá sì ń fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tẹ̀ lé àwọn ìmọ̀ràn tí wọ́n ń fún ọ, a jẹ́ pé o ti ń bá Ọlọ́run rìn nìyẹn, o sì ń tọ “àwọn òpópónà ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn.”
Máa Rìn Bí Ẹni Pé Ò “Ń Rí Ẹni Tí A kò Lè Rí”
14. Bó bá dà bíi pé à ń rí Jèhófà lójúkojú, báwo la ṣe lè fi èyí hàn nínú ìpinnu tá a bá ń ṣe?
14 Ká tó lè bá Jèhófà rìn, ó gbọ́dọ̀ dà bíi pé à ń rí i lójúkojú. Rántí pé Jèhófà mú un dá àwọn olóòótọ́ ní Ísírẹ́lì ìgbàanì lójú pé òun ò fi ara òun pa mọ́ fún wọn. Bákan náà ló tún ṣe ń fi ara rẹ̀ han àwọn èèyàn rẹ̀ lóde òní pé Olùkọ́ wọn Atóbilọ́lá lòun jẹ́. Ǹjẹ́ ó dà bíi pé ò ń rí Jèhófà lójúkojú, bíi pé ó dúró síwájú rẹ tó ń kọ́ ẹ? Irú ìgbàgbọ́ tá a gbọ́dọ̀ ní nìyẹn tá a bá fẹ́ bá Ọlọ́run rìn. Irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ ni Mósè ní, “nítorí . . . ó ń bá a lọ ní fífẹsẹ̀múlẹ̀ ṣinṣin bí ẹni tí ń rí Ẹni tí a kò lè rí.” (Hébérù 11:27) Tó bá dà bíi pé à ń rí Jèhófà lójúkojú lóòótọ́, a óò máa ronú nípa ojú tí Jèhófà á fi wo àwọn ìpinnu tá a bá ṣe. Bí àpẹẹrẹ, a ò tiẹ̀ ní ronú débi lílọ́wọ́ nínú ìwàkiwà, ká wá máa fi ẹ̀ṣẹ̀ wa pa mọ́ fáwọn alàgbà tàbí àwọn ara ilé wa. Kàkà bẹ́ẹ̀, a ó gbìyànjú láti máa bá Ọlọ́run rìn kódà nígbà tí èèyàn kankan ò lè rí wa. Àwa náà yóò ṣe bíi ti Dáfídì Ọba ìgbàanì tó pinnu pé: “Èmi yóò máa rìn káàkiri nínú ìwà títọ́ ọkàn-àyà mi nínú ilé mi.”—Sáàmù 101:2.
15. Báwo ni bíbá àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa kẹ́gbẹ́ ṣe lè mú kó dà bíi pé à ń rí Jèhófà lójúkojú?
15 Jèhófà mọ̀ pé aláìpé ẹ̀dá ni wá, ó sì mọ̀ pé àwọn ìgbà kọ̀ọ̀kan wà tó lè má rọrùn fún wa láti gba ohun tá ò lè fojú rí gbọ́. (Sáàmù 103:14) Ó ti ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan láti ràn wá lọ́wọ́ ká lè borí ìkùdíẹ̀ káàtó wa yìí. Bí àpẹẹrẹ, ó ti kó “àwọn ènìyàn kan [jọ] fún orúkọ rẹ̀” látinú gbogbo orílẹ̀-èdè tó wà lórí ilẹ̀ ayé. (Ìṣe 15:14) Bá a ṣe ń jọ́sìn pọ̀ níṣọ̀kan là ń gba okun látọ̀dọ̀ ara wa. Bá a ṣe ń gbọ́ nípa ọ̀nà tí Jèhófà gbà ran arákùnrin kan tàbí arábìnrin kan lọ́wọ́ láti borí àwọn àìlera tàbí àwọn àdánwò líle kan máa ń mú kó túbọ̀ dà bíi pé à ń rí Ọlọ́run wa lójúkojú.—1 Pétérù 5:9.
16. Báwo ni kíkẹ́kọ̀ọ́ nípa Jésù yóò ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti máa bá Ọlọ́run rìn?
16 Lékè gbogbo rẹ̀, Jèhófà ti fún wa ní àpẹẹrẹ ti Ọmọ rẹ̀. Jésù sọ pé: “Èmi ni ọ̀nà àti òtítọ́ àti ìyè. Kò sí ẹni tí ń wá sọ́dọ̀ Baba bí kò ṣe nípasẹ̀ mi.” (Jòhánù 14:6) Kíkẹ́kọ̀ọ́ nípa ọ̀nà tí Jésù gbà lo ìgbésí ayé rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀nà tó dára jù lọ láti jẹ́ kó túbọ̀ dà bíi pé à ń rí Jèhófà lójúkojú. Gbogbo ohun tí Jésù sọ àti ohun tó ṣe ló fi irú ẹni tí Bàbá wa ọ̀run jẹ́ hàn kedere, ó sì tún fi báwọn ọ̀nà rẹ̀ ṣe rí hàn láìkù síbì kan. (Jòhánù 14:9) Bá a ṣe ń ṣe àwọn ìpinnu wa, a gbọ́dọ̀ máa ronú lórí ohun tí Jésù máa ṣe tó bá jẹ́ pé òun ló wà nípò wa. Bí àwọn ìpinnu wa bá ń fi irú ìrònú tó jinlẹ̀ dáadáa bẹ́ẹ̀ hàn tá a sì ń gbàdúrà nípa rẹ̀, a jẹ́ pé à ń tẹ̀ lé àwọn ìṣísẹ̀ Kristi nìyẹn. (1 Pétérù 2:21) Èyí á sì máa fi hàn pé à ń bá Ọlọ́run rìn.
Àwọn Ìbùkún Wo La Óò Rí Gbà?
17. Bí a bá rìn ní ọ̀nà Jèhófà, irú “ìdẹ̀rùn” wo la máa rí fún ọkàn wa?
17 Bíbá Jèhófà Ọlọ́run rìn túmọ̀ sí kéèyàn máa gbé ìgbésí ayé tó lárinrin. Rántí ohun tí Jèhófà ṣèlérí fáwọn èèyàn rẹ̀ nípa wíwá “ọ̀nà tí ó dára” náà. Ó sọ pé: “Ẹ . . . máa rìn ín, kí ẹ sì rí ìdẹ̀rùn fún ọkàn yín.” (Jeremáyà 6:16) Kí ni “ìdẹ̀rùn” yẹn túmọ̀ sí? Ṣé ìgbésí ayé ìdẹ̀rùn tó kún fún fàájì àti afẹ́ ayé ni? Rárá ò. Jèhófà pèsè ohun kan tó dáa gan-an ju ìyẹn lọ, ohun kan tẹ́ni tó lówó jù lọ láyé yìí ò lè ní. Láti rí ìdẹ̀rùn fún ọkàn rẹ túmọ̀ sí kó o ní ìbàlẹ̀ ọkàn, kó o tún ní ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn, kó o sì wá rí i pé ò ń ṣe ohun tó tọ́ nípa tẹ̀mí. Irú ìdẹ̀rùn bẹ́ẹ̀ túmọ̀ sí pé ọkàn rẹ á balẹ̀ dáadáa pé o ti yan ọ̀nà ìgbésí ayé tó dára jù lọ. Irú ìbàlẹ̀ ọkàn bẹ́ẹ̀ jẹ́ ìbùkún tó ṣọ̀wọ́n nínú ayé oníwàhálà yìí!
18. Ìbùkún wo ni Jèhófà fẹ́ fi jíǹkí rẹ, kí sì ni ìpinnu rẹ?
18 Lóòótọ́, ìbùkún ńlá ni ìwàláàyè fúnra rẹ̀ jẹ́. Kódà, kéèyàn wà láàyè fúngbà díẹ̀ sàn ju kéèyàn má sí láàyè rárá. Àmọ́ o, Jèhófà ò fìgbà kan ní i lọ́kàn pé kí ìrìn rẹ wulẹ̀ jẹ́ ìrìn kúkúrú lásán, tí wàá kàn rìn látìgbà èwe tó o ṣì lókun dáadáa di ọjọ́ ogbó tó kún fún ìrora. Rárá o, Jèhófà fẹ́ kó o rí ìbùkún tó ga ju gbogbo ìbùkún lọ. Ó fẹ́ kó o bá òun rìn títí láé! Èyí sì ṣe kedere nínú Míkà 4:5, tó sọ pé: “Gbogbo àwọn ènìyàn, ní tiwọn, yóò máa rìn, olúkúlùkù ní orúkọ ọlọ́run tirẹ̀; ṣùgbọ́n àwa, ní tiwa, yóò máa rìn ní orúkọ Jèhófà Ọlọ́run wa fún àkókò tí ó lọ kánrin, àní títí láé.” Ṣé ìbùkún yẹn wù ẹ́? Ṣé o fẹ́ gbé ìgbésí ayé tí Jèhófà fìfẹ́ pè ní “ìyè tòótọ́”? (1 Tímótì 6:19) Rí i dájú nígbà náà pé o pinnu láti máa bá Jèhófà rìn lónìí, lọ́la, ní gbogbo ọjọ́, àní títí ayérayé!
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwọn Bíbélì kan yí ọ̀rọ̀ náà “ìgbọ̀nwọ́” tó wà nínú ẹsẹ yìí sí ìwọ̀n àkókò, bíi “àkókò kan kíún,” (The Emphatic Diaglott) tàbí “ìṣẹ́jú kan” (A Translation in the Language of the People, látọwọ́ Charles B. Williams). Bó ti wù kó rí, ìgbọ̀nwọ́ kan ni ọ̀rọ̀ tí wọ́n lò nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ti ìpilẹ̀ṣẹ̀ túmọ̀ sí, ìyẹn sì jẹ́ nǹkan bíi ẹsẹ bàtà kan ààbọ̀ ní gígùn.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Kí ni bíbá Ọlọ́run rìn túmọ̀ sí?
• Kí nìdí tó o fi rò pé ó yẹ kó o máa bá Ọlọ́run rìn?
• Kí ló máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti máa bá Ọlọ́run rìn?
• Ìbùkún wo làwọn tó ń bá Ọlọ́run rìn máa ń rí gbà?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
À ń tipasẹ̀ Bíbélì gbọ́ ohùn Jèhófà tó ń dún lẹ́yìn wa pé, “Èyí ni ọ̀nà”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
À ń gba oúnjẹ tẹ̀mí lákòókò tó bẹ́tọ̀ọ́ mu láwọn ìpàdé