Ayé Tí Nǹkan Ò Ti Dọ́gba La Wà Yìí
Ayé Tí Nǹkan Ò Ti Dọ́gba La Wà Yìí
ǸJẸ́ o gbà pé inú ayé tí nǹkan ò ti dọ́gba là ń gbé yìí? Ó dájú pé o gbà bẹ́ẹ̀. Ká sòótọ́, kò sírú ẹ̀bùn tá a lè ní tàbí bó ti wù ká fọgbọ́n wéwèé ìgbésí ayé wa tó, tó máa ní ká dolówó tàbí ká ṣàṣeyọrí nínú ohun tá a dáwọ́ lé tàbí pé ká tiẹ̀ rí oúnjẹ jẹ pàápàá. Bí Sólómọ́nì Ọba ìgbàanì ṣe sọ ọ́ lọ̀rọ̀ náà sábà máa ń rí, ó ní: “Oúnjẹ kì í ṣe ti àwọn ọlọ́gbọ́n pẹ̀lú, bẹ́ẹ̀ ni ọrọ̀ kì í ṣe ti àwọn olóye pẹ̀lú, bẹ́ẹ̀ ni ojú rere kì í ṣe ti àwọn tí ó ní ìmọ̀ pàápàá.” Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? Sólómọ́nì sọ síwájú sí i pé, nítorí “ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀ ni ó ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wọn.”—Oníwàásù 9:11.
‘Nígbà Tí Àjálù Bá Ṣẹlẹ̀ Lójijì’
Dájúdájú, “ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀,” èyí tó túmọ̀ sí kéèyàn kàgbákò láìròtẹ́lẹ̀, sábà máa ń dabarú gbogbo ohun tá a ti fara balẹ̀ wéwèé, ó sì máa ń sọ ìrètí ẹni dòfo. Gẹ́gẹ́ bí Sólómọ́nì ti sọ, ńṣe la dà ‘bí àwọn ẹja tí a ń fi àwọ̀n búburú mú, àti bí àwọn ẹyẹ tí a ń fi pańpẹ́ mú, ní ìgbà oníyọnu àjálù, nígbà tí ó bá já lù wá lójijì.’ (Oníwàásù 9:12) Bí àpẹẹrẹ, ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn lóde òní máa ń ṣiṣẹ́ oko láṣekára kí wọ́n lè rí oúnjẹ bọ́ ìdílé wọn, àmọ́ lójijì, wọ́n lè bára wọn nínú “ìgbà oníyọnu,” tí òjò kò ní rọ̀, tí ọ̀dá á sì ba irè oko wọn jẹ́.
Àwọn kan máa ń gbìyànjú láti ṣèrànwọ́, àmọ́ ọ̀pọ̀ ìgbà ló tiẹ̀ jẹ́ pé ńṣe ni ìrànwọ́ táwọn orílẹ̀-èdè yòókù láyé ń ṣe fáwọn tí wọ́n bára wọn nínú “ìgbà oníyọnu” máa ń dà bíi pé kò dára tó. Bí àpẹẹrẹ, ní ọdún kan láìpẹ́ yìí nígbà tí wọ́n ń gbógun ti ìyàn, àjọ kan tó jẹ́ òléwájú nínú àwọn àjọ tó ń ṣèrànwọ́ fáwọn tí àjálù bá sọ pé, “owó tí wọ́n fi ṣèrànwọ́ fún ilẹ̀ [Áfíríkà] lápapọ̀ kò ju ìdá kan nínú ìdá márùn-ún owó tí wọ́n ná sí ogun Gulf.” Ṣó dáa bó ṣe jẹ́ pé ìlọ́po márùn-ún owó táwọn orílẹ̀-èdè tó lọ́rọ̀ ná láti gbógun ti ìnira àti ìyà tí ìyàn fà nílẹ̀ Áfíríkà ni wọ́n ná sórí ogun lórílẹ̀-èdè kan ṣoṣo péré? Ṣó sì dáa bí ẹnì kan nínú ẹni mẹ́rin tó ń gbé láyé ṣe wà nínú ipò òṣì paraku lákòókò yìí tọ́pọ̀ èèyàn wà nínú ọrọ̀? Àní sẹ́, ṣó dáa bí àrùn tó ṣeé dènà ṣe ń pa ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ lọ́dọọdún? Kò dáa rárá!
Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe “ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀” nìkan ló ń fa ‘àjálù òjijì.’ Àwọn nǹkan mìíràn tápá wa ò ká rárá tún máa ń nípa lórí ìgbésí ayé
wa àtàwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí wa. Ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an nìyí nílùú Beslan lórílẹ̀-èdè Alania, nígbà ìrúwé 2004, tí ọgọ́rọ̀ọ̀rún èèyàn kú sínú ìjà kan tó wáyé láàárín àwọn akópayàbáni àtàwọn aláàbò ìlú. Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó kú náà ló sì jẹ́ àwọn ọmọdé tó jẹ́ pé ọjọ́ yẹn ni wọ́n kọ́kọ́ wọlé sílé ẹ̀kọ́. Lóòótọ́ o, ọ̀rọ̀ èèṣì ni pé àwọn èèyàn kan kú, àwọn èèyàn kan sì yè nínú jàǹbá náà, àmọ́ olórí ohun tó fa ‘àjálù òjijì’ yìí gan-an ni ìjà táwọn èèyàn ń bára wọn jà.Ṣé Bí Ayé Á Ṣe Máa Rí Lọ Rèé?
Ohun táwọn kan máa ń sọ nípa ìrẹ́jẹ tó wà nínú ayé ni pé: “Báyé ṣe rí nìyẹn. Ó ti wà bẹ́ẹ̀ látọjọ́ táláyé ti dáyé, bó sì ṣe máa máa rí lọ nìyẹn.” Lójú tiwọn, ńṣe làwọn alágbára á máa fìyà jẹ àwọn tí kò lágbára, àwọn olówó á sì máa rẹ́ àwọn tálákà jẹ. Wọ́n sọ pé gbogbo ìwọ̀nyí, pa pọ̀ pẹ̀lú “ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀” yóò máa nípa lórí wa níwọ̀n ìgbà táráyé bá ṣì wà lókè eèpẹ̀.
Ṣé bó ṣe yẹ kó rí nìyẹn? Ǹjẹ́ á ṣeé ṣe fún àwọn èèyàn tó ń fi ọpọlọ pípé àti ọgbọ́n lo ẹ̀bùn wọn láti jèrè gbogbo iṣẹ́ àṣekára wọn bó ti tọ́ àti bó ti yẹ? Ǹjẹ́ ẹnì kan tiẹ̀ lè ṣe ohunkóhun láti tún ayé tí nǹkan ò ti dọ́gba yìí ṣe láìkù síbi kan? Gbé ohun tí àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí máa sọ nípa koko yìí yẹ̀ wò.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 2]
Ẹ̀YÌN ÌWÉ: Ọkùnrin tó gbé ọmọ dání: UN PHOTO 148426/McCurry/Stockbower
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]
MAXIM MARMUR/AFP/Àwòrán Getty