Good News for People of All Nations
Good News for People of All Nations
ÈYÍ ni kókó ọ̀rọ̀ inú ìwé kékeré kan tó jáde lédè Gẹ̀ẹ́sì ní Ìpàdé Àgbègbè “Ẹ Bá Ọlọ́run Rìn” táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe lọ́dún 2004 sí 2005. Ọ̀kan lára ẹ̀dà ìwé ọ̀hún tó jẹ́ olójú ìwé 96 ní ọ̀rọ̀ ìhìn rere náà nínú lédè méjì lé ní àádọ́rùn-ún [92], látorí èdè kan tí wọ́n ń pè ní Afrikaans títí dórí èdè Zulu. Ìdí tí wọ́n fi tẹ ìwé kékeré yìí ni láti lè sọ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn. (Mátíù 24:14) Àwọn ohun tó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà táwọn ará bá lo ìwé kékeré náà rèé:
• Lẹ́yìn tí ìdílé Ẹlẹ́rìí kan gba ìwé kékeré náà ní ìpàdé àgbègbè yẹn, wọ́n lọ sáwọn ọ̀gbà ìtura mẹ́ta kan táwọn èèyàn ti máa ń ṣe eré ìnàjú. Wọ́n rí àwọn èèyàn tó wá láti orílẹ̀-èdè Íńdíà, Netherlands, Pakísítánì àti orílẹ̀-èdè Philippines níbẹ̀. Olórí ìdílé náà sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn náà lè sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì díẹ̀, inú wọ́n dùn gan-an nígbà tá a fi ọ̀rọ̀ ìhìn rere náà hàn wọ́n ní èdè wọn, nítorí pé ibi tí wọ́n ń gbé jìnnà gan-an sí ìlú wọn. Wọ́n wá rí i kedere pé iṣẹ́ wa jẹ́ èyí tá a ń ṣe jákèjádò ayé àti pé ìṣọ̀kan wà láàárín wa.”
• Obìnrin kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí fi ìwé kékeré náà han òṣìṣẹ́ ẹlẹ́gbẹ́ rẹ̀ kan tó wá láti orílẹ̀-èdè Íńdíà. Inú rẹ̀ dùn gan-an nígbà tó rí gbogbo èdè tó wà níbẹ̀ tó sì ka ọ̀rọ̀ ìhìn rere náà lédè tirẹ̀. Èyí jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ lè jọ sọ̀rọ̀ sí i nípa Bíbélì. Ẹnu ya òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ mìíràn tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Philippines nígbà tó rí èdè ìbílẹ̀ rẹ̀ nínú ìwé kékeré yìí, ó sì fẹ́ láti túbọ̀ mọ̀ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
• Lórílẹ̀-èdè Kánádà, obìnrin kan láti Nepal gbà kí Ẹlẹ́rìí kan máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lórí tẹlifóònù àmọ́ kò fẹ́ kí obìnrin Ẹlẹ́rìí náà wá sílé òun. Ṣùgbọ́n nígbà tí Ẹlẹ́rìí náà sọ fún obìnrin náà pé ìwé kékeré kan wà tí ọ̀rọ̀ ìhìn rere náà lédè Nepali wà nínú rẹ̀, inú rẹ̀ dùn gan-an, ó sì pe Ẹlẹ́rìí náà wá sílé rẹ̀. Ó ṣáà fẹ́ láti fojú ara rẹ̀ rí ọ̀rọ̀ ìhìn rere náà lédè ìbílẹ̀ rẹ̀! Látìgbà náà wá, inú ilé obìnrin náà ni wọ́n ti ń kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.