Fi Àṣìṣe Àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì Kọ́gbọ́n
Fi Àṣìṣe Àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì Kọ́gbọ́n
ÀWỌN ọmọ Ísírẹ́lì mọ ohun tí Jèhófà fẹ́ kí wọ́n ṣe bí wọ́n bá ti wọ Ilẹ̀ Ìlérí. Ọlọ́run tipasẹ̀ Mósè pàṣẹ fún wọn pé: “Kí ẹ . . . lé gbogbo àwọn olùgbé ilẹ̀ náà kúrò níwájú yín, kí ẹ sì pa gbogbo àwòrán àfòkútaṣe wọn run, gbogbo àwọn ère wọn tí a fi irin dídà ṣe sì ni kí ẹ pa run, gbogbo àwọn ibi gíga ọlọ́wọ̀ wọn sì ni kí ẹ pa rẹ́ ráúráú.”—Núm. 33:52.
Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò gbọ́dọ̀ bá àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà ṣe àdéhùn àlàáfíà kankan, wọn ò sì gbọ́dọ̀ bá wọn dána. (Diu. 7:2, 3) Àní, Ọlọ́run kìlọ̀ fáwọn èèyàn rẹ̀ tó yàn pé: “Ṣọ́ ara rẹ kí o má ṣe bá àwọn olùgbé ilẹ̀ tí ìwọ ń lọ dá májẹ̀mú, kí ó má bàa di ìdẹkùn ní àárín rẹ.” (Ẹ́kís. 34:12) Pẹ̀lú gbogbo ìkìlọ̀ yẹn náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, èyí sì fà wọ́n sínú ìdẹkùn. Kí tiẹ̀ ló ṣàkóbá fún wọn? Kí la lè fi kọ́gbọ́n nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn?—1 Kọ́r. 10:11.
Ibi Wọléwọ̀de Ni Ìbọ̀rìṣà Ti Bẹ̀rẹ̀
Báwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ṣẹ́gun àwọn tó ń gbé Ilẹ̀ Ìlérí báyìí ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í gba ilẹ̀ wọn. Àmọ́, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò tẹ̀ lé àṣẹ Ọlọ́run délẹ̀délẹ̀. Wọn ò lé àwọn ọ̀tá lọ tán pátápátá. (Oníd. 1:1-2:10) Dípò kí wọ́n ṣohun tí Jèhófà pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n ṣe, ńṣe ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í gbé láàárín “àwọn orílẹ̀-èdè méje” tí wọ́n ń gbé ilẹ̀ náà, bí wọ́n sì ṣe ń rí àwọn ará orílẹ̀-èdè wọ̀nyẹn lemọ́lemọ́ mú kí wọ́n di ọ̀rẹ́ wọn. (Diu. 7:1) Àkóbá wo nìyẹn wá ṣe fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì? Bíbélì sọ pé: “Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí mú àwọn ọmọbìnrin wọn ṣe aya fún ara wọn, àwọn ọmọbìnrin tiwọn ni wọ́n sì fi fún àwọn ọmọkùnrin wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí sin àwọn ọlọ́run wọn. Nítorí náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ohun tí ó burú ní ojú Jèhófà, wọ́n sì gbàgbé Jèhófà Ọlọ́run wọn, wọ́n sì lọ ń sin àwọn Báálì àti àwọn òpó ọlọ́wọ̀.” (Oníd. 3:5-7) Ibi wọléwọ̀de táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń ṣe pẹ̀lú àwọn èèyàn yẹn ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀, nígbà tó yá ó di pé kí wọ́n jọ máa fẹ́ ara wọn, kí wọ́n sì máa bọ̀rìṣà. Nígbà tó ti di pé wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn abọ̀rìṣà yẹn dána báyìí, bóyá ló tún máa ṣeé ṣe láti lé wọn kúrò níbẹ̀ mọ́. Ìjọsìn tòótọ́ di àmúlùmálà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fúnra wọn dẹni tó ń jọ́sìn àwọn ọlọ́run èké.
Nígbà táwọn ará Ilẹ̀ Ìlérí ń bá àwọn ọmọ
Ísírẹ́lì jà, ọ̀tá gidi ni wọ́n jẹ́ síra wọn, àmọ́ nísinsìnyí táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti wá di ọ̀rẹ́ wọn, ọṣẹ́ tí wọ́n á ṣe fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa burú ju ìgbà tí wọ́n jẹ́ ọ̀tá wọn lọ nítorí pé wọ́n á sọ ọkàn wọn dìdàkudà wọ́n á sì ba àjọse wọn pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́. Ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò ọ̀nà míì tí wọ́n lè gbà ba ẹ̀sìn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ́.Bí Iṣẹ́ Àgbẹ̀ Ṣe Mú Kí Wọ́n Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Jọ́sìn Báálì
Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ Ilẹ̀ Ìlérí, wọn ò ṣí kiri mọ́, ọ̀pọ̀ nínú wọn sì di àgbẹ̀. Ó ṣeé ṣe kí ọ̀nà tí wọ́n ń gbà dáko jọ tàwọn ọmọ Kénáánì tó ti ń dáko lórí ilẹ̀ náà ṣáájú wọn. Ẹ̀rí sì wà pé kì í ṣe ọ̀nà táwọn ará Kénáánì ń gbà dáko nìkan ni wọ́n kọ́. Wọléwọ̀de táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń bá àwọn èèyàn yẹn ṣe tún mú kí wọ́n máa bá wọn lọ́wọ́ nínú àwọn àṣà ìbọ̀rìṣà kan táwọn àgbẹ̀ ibẹ̀ máa ń ṣe.
Àwọn ọmọ Kénáánì máa ń jọ́sìn ọ̀pọ̀ òrìṣà Báálì, ìyẹn àwọn òrìṣà oko tí wọ́n gbà pé ó ń mú kí ilẹ̀ lọ́ràá. Nítorí náà, ọ̀rọ̀ yẹn wá kọjá káwọn ọmọ Ísírẹ́lì kàn máa dáko kí wọ́n sì máa kórè, nígbà tó yá, wọ́n bá a débi tí wọ́n ń bá àwọn ọmọ Kénáánì lọ́wọ́ nínú jíjọ́sìn àwọn ọlọ́run tí wọ́n gbà pé ó ń mú káwọn kórè oko jaburata. Bó ṣe di pé ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń ṣe bí ẹní ń jọ́sìn Jèhófà nìyẹn, nígbà tó sì jẹ́ pé wọ́n ti kẹ̀yìn sí i.
Ìkìlọ̀ Pàtàkì Lèyí Jẹ́ fún Wa Lónìí
Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn èèyàn tó wà ní Ilẹ̀ Ìlérí da nǹkan pọ̀, kò dájú pé wọ́n ní in lọ́kàn pé àwọn fẹ́ máa bá wọn lọ́wọ́ nínú ìjọsìn Báálì àtàwọn ohun játijàti tó máa ń bá a rìn. Àmọ́, wọléwọ̀de pẹ̀lú wọn bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì débi jíjọ́sìn Báálì. Àwọn kan náà wà lónìí tí wọ́n lè dà bí ọmọlúwàbí, àmọ́ tí wọn kì í jọ́sìn Ọlọ́run táwa ń jọ́sìn, tí wọn kì í tẹ̀ lé ìlànà táwa ń tẹ̀ lé, tí wọn kò sì ní ìwà Kristẹni. Tá a bá lọ ń ṣe wọléwọ̀de pẹ̀lú àwọn wọ̀nyí, ṣóhun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò ní ṣẹlẹ̀ sáwa náà? A gbà pé ó lè pọn dandan kí nǹkan dà wá pọ̀ pẹ̀lú àwọn tí kì í ṣe Kristẹni bíi tiwa níbi iṣẹ́, níléèwé tàbí nínú ilé pàápàá. Àmọ́, ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì yẹn yẹ kó ṣe kìlọ̀kìlọ̀ fún wa pé tá a bá fẹ́ máa ṣe wọléwọ̀de pẹ̀lú wọn, bí ẹní ń fàjọ̀gbọ̀n lẹ́sẹ̀ ni. Òtítọ́ kan tí Bíbélì sọ tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀ rèé: “Ẹgbẹ́ búburú a máa ba ìwà rere jẹ́.”—1 Kọ́r. 15:33.
Ọ̀pọ̀ àdánwò tó jọ tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì ló dójú kọ àwa náà lónìí. Oríṣiríṣi nǹkan làwọn èèyàn ayé òde òní ti sọ di òrìṣà. Lára wọn ni owó, àwọn gbajúmọ̀ òṣèré, àwọn sàràkí eléré ìdárayá, àwọn ètò ìṣèlú kan, àwọn kan lára àwọn aṣáájú ìsìn àtàwọn ará ilé ẹni pàápàá. Èyíkéyìí nínú nǹkan wọ̀nyí ló lè dohun tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé wa. Tá a bá lọ ń bá àwọn tí kò nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ṣọ̀rẹ́, ó lè ba àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà jẹ́.
Ìbálòpọ̀ tí kò bójú mu jẹ́ ohun kan pàtàkì tí wọ́n máa ń ṣe nínú ìjọsìn Báálì tó fa ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́kàn mọ́ra, tó sì dẹkùn mú wọn. Ohun kan náà ṣì máa ń dẹkùn mú àwọn kan láàárín àwa èèyàn Ọlọ́run lónìí. Bí àpẹẹrẹ, téèyàn ò bá ṣọ́ra, fífi kọ̀ǹpútà wo àwòrán ìṣekúṣe lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì nínú yàrá ẹni kò pẹ́ rárá, èèyàn sì lè tipa bẹ́ẹ̀ ṣàkóbá fún ẹ̀rí ọkàn rere rẹ̀. Ìbànújẹ́ gbáà ló máa jẹ́ fún Kristẹni kan tó bá lọ kó sínú ìdẹkùn wíwo àwòrán ìṣekúṣe lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì!
“Aláyọ̀ Ni Àwọn Tí Ń Pa Àwọn Ìránnilétí Rẹ̀ Mọ́”
Tó bá dọ̀rọ̀ àwọn tá a ó máa bá kẹ́gbẹ́, àwa fúnra wa la máa pinnu bóyá a máa gbọ́ ti Jèhófà àbí a ò ní gbọ́ ọ. (Diu. 30:19, 20) Torí náà, ó yẹ ká bi ara wa pé: ‘Ta ni mò ń bá kẹ́gbẹ́ lásìkò tọ́wọ́ mi bá dilẹ̀ tí mò ń ṣe fàájì? Kí lèrò wọn nípa ìlànà Ọlọ́run lórí ìwà tó yẹ kéèyàn máa hù? Ṣé wọ́n ń jọ́sìn Jèhófà? Ṣé wọléwọ̀de tí mò ń bá wọn ṣe máa mú kí ìwà mi túbọ̀ dára sí i?’
Ọ̀kan lára àwọn tó kọ Sáàmù kọ ọ́ lórin pé: “Aláyọ̀ ni àwọn aláìní-àléébù ní ọ̀nà wọn, àwọn tí ń rìn nínú òfin Jèhófà. Aláyọ̀ ni àwọn tí ń pa àwọn ìránnilétí rẹ̀ mọ́; wọ́n ń fi gbogbo ọkàn-àyà wá a.” (Sm. 119:1, 2) Láìsí àní-àní, “aláyọ̀ ni gbogbo ẹni tí ó bẹ̀rù Jèhófà, tí ó ń rìn ní àwọn ọ̀nà rẹ̀.” (Sm. 128:1) Tó bá dọ̀rọ̀ àwọn tá a ó máa bá rìn, ẹ jẹ́ ká fi àṣìṣe àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kọ́gbọ́n, ká máa ṣègbọràn sí Jèhófà délẹ̀délẹ̀.—Òwe 13:20.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Wọléwọ̀de pẹ̀lú àwọn tí kò nífẹ̀ẹ́ Jèhófà lè sọ wá dẹni tó ń bọ̀rìṣà