Jẹ́ Kí Jèhófà Máa Wà Níwájú Rẹ Nígbà Gbogbo
Jẹ́ Kí Jèhófà Máa Wà Níwájú Rẹ Nígbà Gbogbo
“Mo ti gbé Jèhófà sí iwájú mi nígbà gbogbo.”—SM. 16:8.
1. Báwo làwọn ìtàn inú Bíbélì ṣe lè ràn wá lọ́wọ́?
Ọ̀RỌ̀ Jèhófà tó wà lákọọ́lẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ìtàn alárinrin nínú, ìyẹn àwọn ìtàn nípa bí Jèhófà ṣe bá àwọn èèyàn lò. Àkọsílẹ̀ náà sọ nípa ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n kópa nínú ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà ń mú ohun tó ní lọkàn ṣẹ. Àmọ́ ṣá o, àwọn ohun tí wọ́n sọ àtohun tí wọ́n ṣe, èyí tó wà lákọọ́lẹ̀ nínú Bíbélì kì í wulẹ̀ ṣe ìtàn àkàgbádùn lásán. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn ìtàn náà lè ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run.—Ják. 4:8.
2, 3. Kí ni ìtumọ̀ ohun tó wà nínú Sáàmù 16:8?
2 Gbogbo wa lè kẹ́kọ̀ọ́ látinú ìrírí àwọn èèyàn tá a mọ ìtàn wọn dáadáa nínú Bíbélì. Lára irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni Ábúráhámù, Sárà, Mósè, Rúùtù, Dáfídì, Ẹ́sítérì, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àtàwọn mìíràn. Àmọ́, a tún lè jàǹfààní látinú ìtàn àwọn èèyàn tá ò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ dáadáa. Tá a bá ń ṣàṣàrò lórí àwọn ìtàn inú Bíbélì yóò ràn wá lọ́wọ́ láti máa ṣe ohun tí onísáàmù kan ṣe, ó sọ pé: “Mo ti gbé Jèhófà sí iwájú mi nígbà gbogbo. Nítorí pé ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún mi, a kì yóò mú kí n ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n.” (Sm. 16:8) Kí ni ìtumọ̀ ohun tó sọ yìí?
3 Ọwọ́ ọ̀tún ní ọmọ ogun sábà máa ń fi idà tó ń lò sí, ìyẹn ni kì í jẹ́ kí apata tó wà lọ́wọ́ òsì rẹ̀ bo apá ọ̀tún rẹ̀. Àmọ́ bí jagunjagun ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ kan bá wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀tún rẹ̀, ó máa dáàbò bò ó. Tá a bá ń fi Jèhófà sọ́kàn tá a sì ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀, yóò dáàbò bò wá. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò báwọn ìtàn inú Bíbélì ṣe lè mú kí ìgbàgbọ́ wa lágbára sí i, ká lè ‘jẹ́ kí Jèhófà máa wà níwájú wa nígbà gbogbo.’
Jèhófà Máa Ń Dáhùn Àdúrà Wa
4. Sọ àpẹẹrẹ kan látinú Ìwé Mímọ́ tó fi hàn pé Ọlọ́run máa ń dáhùn àdúrà.
4 Tá a bá jẹ́ kí Jèhófà máa wà níwájú wa, a nígbọ́kànlé pé yóò máa dáhùn àdúrà wa. (Sm. 65:2; 66:19) A rí ẹ̀rí èyí nínú ọ̀ràn ìránṣẹ́ Ábúráhámù tó dàgbà jù lọ, tó ṣeé ṣe kó jẹ́ Élíésérì. Ábúráhámù rán an lọ sí Mesopotámíà láti lọ wá ìyàwó tó bẹ̀rù Ọlọ́run fún Ísákì. Élíésérì gbàdúrà pé kí Ọlọ́run tọ́ òun sọ́nà, ó sì gbà pé Jèhófà dáhùn àdúrà òun nígbà tí Rèbékà fún àwọn ràkúnmí rẹ̀ lómi. Nítorí pé Élíésérì gbàdúrà tọkàntọkàn, ó rí obìnrin tó wá di aya rere fún Ísákì. (Jẹ́n. 24:12-14, 67) A gbà pé iṣẹ́ pàtàkì kan ni ìránṣẹ́ Ábúráhámù lọ jẹ́, àmọ́, ṣé kò yẹ káwa náà ní ìgbọ́kànlé bíi tirẹ̀ pé Jèhófà á dáhùn àdúrà wa?
5. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé àdúrà ṣókí téèyàn gbà ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́ sí Jèhófà lè gbà?
5 Nígbà míì, ó máa gba pé ká sáré gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ràn wá lọ́wọ́. Nígbà kan, Atasásítà Ọba Páṣíà kíyè sí i pé ojú Nehemáyà tó jẹ́ agbọ́tí òun fà ro. Ni ọba bá bi í léèrè pé, “Kí ni ohun náà tí ìwọ ń wá?” “Lójú-ẹsẹ̀, [Nehemáyà] gbàdúrà sí Ọlọ́run ọ̀run.” Ó ní láti jẹ́ pé àdúrà ṣókí ni Nehemáyà gbà, ó sì hàn gbangba pé àdúrà ìdákẹ́jẹ́ẹ́ ni. Síbẹ̀, Ọlọ́run dáhùn àdúrà náà, nítorí ọba ran Nehemáyà lọ́wọ́ láti kọ́ ògiri Jerúsálẹ́mù. (Ka Nehemáyà 2:1-8.) Ó dájú pé àdúrà ṣókí téèyàn gbà ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́ pàápàá lè gbà.
6, 7. (a) Tá a bá ń sọ nípa àdúrà gbígbà, kí ni àpẹẹrẹ Epafírásì kọ́ wa? (b) Kí nìdí tó fi yẹ ká máa fọ̀rọ̀ àwọn ẹlòmíì sínú àdúrà wa?
6 Bíbélì gbà wá níyànjú láti “máa gbàdúrà fún ara [wa] lẹ́nì kìíní-kejì,” àní bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìgbà gbogbo kọ́ la máa ń rí ẹ̀rí lójú ẹsẹ̀ pé Ọlọ́run ti dáhùn irú àdúrà bẹ́ẹ̀. (Ják. 5:16) Epafírásì tó jẹ́ “olùṣòtítọ́ òjíṣẹ́ fún Kristi” gbàdúrà tọkàntọkàn fún àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń kọ̀wé láti Róòmù, ó ní: “Epafírásì, ẹni tí ó ti àárín yín [ìyẹn àwọn ará Kólósè] wá, ẹrú Kristi Jésù, kí yín, nígbà gbogbo ni ó ń tiraka nítorí yín nínú àwọn àdúrà rẹ̀, pé kí ẹ lè dúró lọ́nà tí ó pé níkẹyìn àti pẹ̀lú ìdálójú ìgbàgbọ́ tí ó fìdí múlẹ̀ gbọn-in nínú gbogbo ìfẹ́ Ọlọ́run. Ní tòótọ́, mo jẹ́rìí rẹ̀ pé ó ṣe ìsapá ńláǹlà nítorí yín àti nítorí àwọn tí ń bẹ ní Laodíkíà àti nítorí àwọn tí ń bẹ ní Hirapólísì.”—Kól. 1:7; 4:12, 13.
7 Ìlú Kólósè, Laodíkíà, àti Hirapólísì wà ní àgbègbè kan náà ní Éṣíà Kékeré. Àwọn Kristẹni tó wà ní Hirapólísì ń gbé láàárín àwọn tó ń jọ́sìn abo ọlọ́run tó ń jẹ́ Síbílì. Àwọn Kristẹni tó ń gbé ní Laodíkíà wà láàárín àwọn èèyàn tó nífẹ̀ẹ́ ọrọ̀ àtohun ìní. Ẹ̀kọ́ ọgbọ́n orí ló sì jẹ́ ewu fáwọn Kristẹni ti ìlú Kólósè. (Kól. 2:8) Abájọ tí Epafírásì, tó wá láti Kólósè, fi ń ‘gbàdúrà kíkankíkan’ nítorí àwọn Kristẹni tó wà nílùú yẹn! Bíbélì kò ṣàlàyé bí Ọlọ́run ṣe dáhùn àdúrà Epafírásì ṣùgbọ́n kò sinmi àdúrà gbígbà fún àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́. Bẹ́ẹ̀ ni àwa náà ò gbọ́dọ̀ dákẹ́ àdúrà gbígbà fún àwọn ará wa. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò ní máa ‘tojú bọ ọ̀rọ̀ ọlọ́rọ̀,’ síbẹ̀ ó ṣeé ṣe ká mọ̀ pé ẹnì kan nínú ìdílé wa tàbí ọ̀rẹ́ wa kan wà nínú ìṣòro tó ń dán ìgbàgbọ́ rẹ̀ wò. (1 Pét. 4:15) Ẹ ò rí i pé ó dára láti máa fọ̀rọ̀ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ sínú àdúrà wa! Ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ táwọn ẹlòmíì ṣe nítorí Pọ́ọ̀lù ràn án lọ́wọ́ gan-an, àdúrà táwa náà bá gbà fáwọn ẹlòmíì lè ṣe bẹbẹ.—2 Kọ́r. 1:10, 11.
8. (a) Báwo la ṣe mọ̀ pé àwọn alàgbà tó wá láti Éfésù mọyì àdúrà? (b) Ojú wo ló yẹ káwa náà fi máa wo àdúrà gbígbà?
8 Ǹjẹ́ àwọn ẹlòmíràn mọ̀ wá sẹ́ni tó mọyì àdúrà tó sì máa ń gbàdúrà déédéé? Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù pàdé pọ̀ pẹ̀lú àwọn alàgbà láti Éfésù, “ó kúnlẹ̀ pẹ̀lú gbogbo wọn, ó sì gbàdúrà.” Lẹ́yìn náà, “ẹkún sísun tí kò mọ níwọ̀n bẹ́ sílẹ̀ láàárín gbogbo wọn, wọ́n sì rọ̀ mọ́ ọrùn Pọ́ọ̀lù, wọ́n sì fi ẹnu kò ó lẹ́nu lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́, nítorí pé ọ̀rọ̀ tí ó sọ, pé wọn kì yóò tún rí ojú òun mọ́, dùn wọ́n ní pàtàkì.” (Ìṣe 20:36-38) A ò mọ orúkọ àwọn alàgbà tó wá pàdé Pọ́ọ̀lù yẹn, ṣùgbọ́n ó hàn gbangba pé wọ́n mọyì àdúrà. Dájúdájú ó yẹ káwa náà mọyì àǹfààní tá a ní láti máa gbàdúrà sí Ọlọ́run ká sì “máa gbé ọwọ́ ìdúróṣinṣin sókè,” pẹ̀lú ìgbàgbọ́ pé Bàbá wa ọ̀run yóò dáhùn àdúrà wa.—1 Tím. 2:8.
Ṣègbọràn sí Ọlọ́run ní Kíkún
9, 10. (a) Àpẹẹrẹ wo làwọn ọmọbìnrin Sélóféhádì fi lélẹ̀? (b) Tó bá dọ̀rọ̀ ìgbéyàwó, ẹ̀kọ́ wo làwọn Kristẹni tí kò tíì ṣègbéyàwó lè rí kọ́ látinú ìgbọràn àwọn ọmọbìnrin Sélóféhádì?
9 Fífi Jèhófà sọ́kàn nígbà gbogbo yóò ràn wá lọ́wọ́ láti máa ṣègbọràn sí i, èyí á sì jẹ́ ká rí ìbùkún gbà lọ́dọ̀ rẹ̀. (Diu. 28:13; 1 Sám. 15:22) Èyí fi hàn pé a ní láti jẹ́ onígbọràn. Gbé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọbìnrin márùn-ún tí Sélóféhádì bí yẹ̀ wò. Wọ́n gbé láyé nígbà ayé Mósè. Ó jẹ́ àṣà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé àwọn ọmọkùnrin nìkan ló máa ń jogún ilẹ̀ àtohun ìní látọ̀dọ̀ bàbá wọn. Sélóféhádì kú láìní ọmọkùnrin kankan. Jèhófà ní káwọn ọmọbìnrin márùn-ún yìí gba gbogbo ogún tó jẹ́ tiwọn, kìkì tí wọ́n bá gbà láti ṣe ohun kan. Wọ́n ní láti fẹ́ àwọn ọmọkùnrin Mánásè kí ogún wọn, ìyẹn ilẹ̀ àtohun ìní má bàa kúrò nínú ẹ̀yà kan náà yẹn.—Núm. 27:1-8; 36:6-8.
10 Àwọn ọmọbìnrin Sélóféhádì nígbàgbọ́ pé ọ̀rọ̀ náà yóò yọrí sí rere báwọn bá ṣègbọràn sí Ọlọ́run. Bíbélì sọ pé: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti pàṣẹ fún Mósè, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọbìnrin Sélóféhádì ṣe. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Málà, Tírísà àti Hógílà àti Mílíkà àti Nóà, àwọn ọmọbìnrin Sélóféhádì, di aya àwọn ọmọkùnrin tí ó jẹ́ arákùnrin baba wọn. Wọ́n di aya fún àwọn kan lára àwọn ìdílé ọmọ Mánásè ọmọkùnrin Jósẹ́fù, kí ogún wọn lè máa wà nìṣó pa pọ̀ pẹ̀lú ẹ̀yà ìdílé baba wọn.” (Núm. 36:10-12) Àwọn obìnrin onígbọràn yìí ṣe ohun tí Jèhófà pa láṣẹ. (Jóṣ. 17:3, 4) Bí àwọn ọ̀dọ́ Kristẹni tí kò tíì ṣègbéyàwó tí òtítọ́ jinlẹ̀ lọ́kàn wọn bá ní ìgbàgbọ́ bíi tàwọn ọmọbìnrin Sélóféhádì, wọ́n á ṣègbọràn sí Ọlọ́run nípa ṣíṣègbéyàwó “kìkì nínú Olúwa.”—1 Kọ́r. 7:39.
11, 12. Báwo ni Kálébù ṣe fi hàn pé òun gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run?
11 A ní láti ṣègbọràn sí Jèhófà délẹ̀délẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Kálébù tó jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì ti ṣe. (Diu. 1:36) Lẹ́yìn tí Jèhófà ti dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nídè kúrò ní Íjíbítì lọ́dún 1513 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Mósè rán àwọn ọkùnrin méjìlá lọ ṣe amí ilẹ̀ Kénáánì, àmọ́ méjì péré lára wọn, ìyẹn Kálébù àti Jóṣúà ló gba àwọn èèyàn náà níyànjú láti nígbẹ̀ẹ́kẹ̀lé kíkún nínú Ọlọ́run kí wọ́n bàa lè wọ ilẹ̀ náà. (Núm. 14:6-9) Ní nǹkan bí ogójì ọdún lẹ́yìn náà, Jóṣúà àti Kálébù ṣì wà láàyè tí wọ́n ń tẹ̀ lé Jèhófà ní kíkún, Ọlọ́run sì lo Jóṣúà láti mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ Ilẹ̀ Ìlérí. Àmọ́, ó ṣe kedere pé àwọn amí mẹ́wàá tí wọn ò nígbàgbọ́ yẹn ti kú láàárín ogójì ọdún táwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi rìn kiri nínú aginjù.—Núm. 14:31-34.
12 Kálébù tó ti di àgbàlagbà kò kú nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń rìn kiri nínú aginjù yẹn, ìdí nìyẹn tó fi ṣeé ṣe fún un láti dúró níwájú Jóṣúà tó sì sọ pé: “Mo tọ Jèhófà Ọlọ́run mi lẹ́yìn ní kíkún.” (Ka Jóṣúà 14:6-9.) Kálébù ẹni ọdún márùnlélọ́gọ́rin sọ pé kí wọ́n fún òun ní ìpínlẹ̀ tó ní àwọn òkè ńlá tí Ọlọ́run ti ṣèlérí fún un, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọ̀tá tó ń gbé nínú àwọn ìlú olódi ló wà níbẹ̀.—Jóṣ. 14:10-15.
13. Láìka àwọn àdánwò tó lè dé bá wa sí, kí la lè ṣe tá a ó fi rí ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run gbà?
13 Bá a bá ń ‘tẹ̀ lé Jèhófà ní kíkún,’ Jèhófà yóò ràn wá lọ́wọ́ bíi ti Kálébù tó nígbàgbọ́ tó sì ṣègbọràn. Yóò ràn wá lọ́wọ́ tí ìṣòro ńlá bá dojú kọ wá. Àmọ́ títẹ̀lé Jèhófà ní gbogbo ọjọ́ ayé wa bíi ti Kálébù lè má rọrùn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Sólómọ́nì Ọba tẹ̀ lé Jèhófà nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí í jọba, ṣùgbọ́n àwọn ìyàwó rẹ̀ mú ọkàn rẹ̀ fà sí sísin àwọn ọlọ́run èké ní ọjọ́ ogbó rẹ̀, “kò sì tọ Jèhófà lẹ́yìn ní kíkún gẹ́gẹ́ bí Dáfídì baba rẹ̀.” (1 Ọba 11:4-6) Láìka àdánwò èyíkéyìí tó lè dé bá wa sí, a lè ṣègbọràn sí Ọlọ́run ní kíkún ká sì jẹ́ kó máa wà níwájú wa nígbà gbogbo.
Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà Nígbà Gbogbo
14, 15. Látinú ìtàn ìgbésí ayé Náómì, kí lo rí kọ́ nípa ìdí tó fi yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run?
14 A ní láti gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run, pàápàá jù lọ tí ìdààmú ọkàn bá bá wa tó sì dà bíi pé kò sírètí fún wa. Gbé ọ̀rọ̀ obìnrin àgbàlagbà kan tó ń jẹ́ Náómì yẹ̀ wò. Ikú pa ọkọ rẹ̀ àtàwọn ọmọkùnrin rẹ̀ méjèèjì mọ́ ọn lójú. Nígbà tó kúrò nílẹ̀ Móábù tó sì padà sí Júdà, ó kédàárò pé: “Ẹ má pè mí ní Náómì [tó túmọ̀ sí adùn]. Márà [tó túmọ̀ sí ìkorò] ni kí ẹ máa pè mí, nítorí Olódùmarè ti mú kí ó korò gan-an fún mi. Mo kún nígbà tí mo lọ, ní ọwọ́ òfo sì ni Jèhófà mú kí n padà. Èé ṣe tí ẹ̀yin yóò fi máa pè mí ní Náómì, nígbà tí ó jẹ́ pé Jèhófà ni ó tẹ́ mi lógo, Olódùmarè ni ó sì mú ìyọnu àjálù bá mi?”—Rúùtù 1:20, 21.
15 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìdààmú ọkàn bá Náómì, tá a bá fara balẹ̀ ka ìwé Rúùtù a óò rí i pé Náómì ń bá a lọ láti máa gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà nígbà gbogbo. Ẹ sì wá wo bí ìbànújẹ́ rẹ̀ ṣe dayọ̀! Rúùtù tó jẹ́ ìyàwó ọ̀kan lára àwọn ọmọ Náómì tó kú wá di ìyàwó Bóásì, ó sì bí ọmọkùnrin kan fún un. Náómì ló tọ́jú ọmọ náà, àkọsílẹ̀ náà sọ pé: “Àwọn obìnrin àdúgbò fún un ní orúkọ, wọ́n wí pé: ‘A ti bí ọmọkùnrin kan fún Náómì.’ Wọ́n sì pe orúkọ rẹ̀ ní Óbédì. Òun ni baba Jésè, baba Dáfídì.” (Rúùtù 4: 14-17) Nígbà tí Náómì bá jíǹde sórí ilẹ̀ ayé, yóò wá mọ̀ pé, Rúùtù tóun náà máa wà lórí ilẹ̀ ayé, ló di ìyá ńlá Jésù tó jẹ́ Mèsáyà. (Mát. 1:5, 6, 16) Bíi Náómì, àwa náà ò lè mọ ìgbà tóhun tó le ń bọ̀ wá dẹ̀rọ̀. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká máa gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run nígbà gbogbo, gẹ́gẹ́ bí Òwe 3:5, 6 ti gbà wá níyànjú pé: “Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ. Ṣàkíyèsí rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà rẹ, òun fúnra rẹ̀ yóò sì mú àwọn ipa ọ̀nà rẹ tọ́.”
Gbára Lé Ẹ̀mí Mímọ́
16. Báwo ni ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ṣe ran àwọn àgbà ọkùnrin kan lọ́wọ́ ní Ísírẹ́lì ìgbà àtijọ́?
16 Bá a bá jẹ́ kí Jèhófà máa wà níwájú wa nígbà gbogbo, yóò máa fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ darí wa. (Gál. 5:16-18) Ẹ̀mí Ọlọ́run wà lára àwọn àádọ́rin àgbà ọkùnrin tí Mósè yàn láti máa bá a ‘gbé ẹrù àwọn ènìyàn’ Ísírẹ́lì. Orúkọ Ẹ́lídádì àti Médádì nìkan ni Bíbélì mẹ́nu kàn, àmọ́ ẹ̀mí mímọ́ mú kí gbogbo wọn ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé wọn lọ́wọ́. (Núm. 11:13-29) Láìsí àní-àní, wọ́n kúnjú ìwọ̀n, wọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run, wọ́n sì ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé, wọ́n sì jólóòótọ́ bíi táwọn tí Mósè yàn ṣáájú wọn. (Ẹ́kís. 18:21) Àwọn alàgbà inú ìjọ Kristẹni òde òní máa ń fi irú àwọn ànímọ́ yìí hàn.
17. Ipa wo ni ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà kó nínú kíkọ́ àgọ́ ìjọsìn?
17 Ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà ló mú kí kíkọ́ àgọ́ ìjọsìn ṣeé ṣe ní aginjù. Bẹ́sálẹ́lì ni Jèhófà gbé iṣẹ́ kíkọ́ àgọ́ ìjọsìn náà lé lọ́wọ́, ó sì ṣèlérí pé òun á “fi ẹ̀mí Ọlọ́run kún inú rẹ̀ ní ti ọgbọ́n àti ní ti òye àti ní ti ìmọ̀ àti ní ti gbogbo onírúurú ọgbọ́n iṣẹ́ ọnà.” (Ẹ́kís. 31:3-5) Àwọn ọkùnrin tó “gbọ́n ní ọkàn-àyà” sì ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Bẹ́sálẹ́lì àti olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ Òhólíábù láti ṣe gbogbo iṣẹ́ àgbàyanu náà láṣeyanjú. Ìyẹn nìkan kọ́, ẹ̀mí Jèhófà tún mú kí àwọn tí ọkàn wọn ti múra tán láti ṣètọrẹ tó pọ̀ rẹpẹtẹ ṣe é. (Ẹ́kís. 31:6; 35:5, 30-34) Ẹ̀mí Ọlọ́run kan náà yẹn ló ń mú káwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lóde òní máa sapá láti wá Ìjọba Ọlọ́run lákọ̀ọ́kọ́. (Mát. 6:33) A lè ní àwọn ẹ̀bùn kan, àmọ́ ó yẹ ká máa gbàdúrà fún ẹ̀mí mímọ́ ká sì jẹ́ kó máa darí wa tá a bá fẹ́ ṣe àṣeyọrí nínú iṣẹ́ tí Jèhófà gbé lé àwa èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́ lóde òní.—Lúùkù 11:13.
Máa Jọ́sìn Jèhófà Ẹgbẹ́ Ọmọ Ogun Tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀
18, 19. (a) Kí ni ẹ̀mí Ọlọ́run ń mú ká ní? (b) Kí lo kọ́ látinú àpẹẹrẹ Síméónì àti Ánà?
18 Ẹ̀mí mímọ́ máa ń mú ká ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún Jèhófà, èyí táá jẹ́ kí Jèhófà lè máa wà níwájú wa nígbà gbogbo. Ọlọ́run sọ fún àwọn èèyàn rẹ̀ nígbà àtijọ́ pé: “Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun—òun ni Ẹni tí ó yẹ kí ẹ kà sí mímọ́.” (Aísá. 8:13) Àgbàlagbà ni Síméónì àti Ánà, àwọn méjèèjì ń sin Ọlọ́run tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ní Jerúsálẹ́mù lọ́gọ́rùn-ún ọdún kìíní. (Ka Lúùkù 2:25-38.) Síméónì nígbàgbọ́ nínú àsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà, ó sì “ń dúró de ìtùnú Ísírẹ́lì.” Ọlọ́run tú ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ sórí Síméónì, ó sì mú un dá a lójú pé Mèsáyà máa dé lójú ẹ̀mí ẹ̀. Ohun tó ṣẹlẹ̀ gẹ́lẹ́ nìyẹn. Lọ́jọ́ kan lọ́dún 2 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Màríà tó jẹ́ ìyá Jésù àti Jósẹ́fù tó jẹ́ bàbá alágbàtọ́ fún Jésù gbé Jésù wá sí tẹ́ńpìlì. Ẹ̀mí mímọ́ darí Síméónì láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà, ó sọ pé ìbànújẹ́ máa bá Màríà nítorí ó máa ṣọ̀fọ̀ nígbà tí wọ́n bá kan Jésù mọ́ igi oró. Àmọ́ wo bí ayọ̀ Síméónì ṣe máa pọ̀ tó nígbà tó gbé “Kristi ti Jèhófà” sọ́wọ́! Ẹ wo àpẹẹrẹ tí Síméónì fi lélẹ̀ fún àwọn èèyàn Ọlọ́run lónìí lórí sísin Ọlọ́run tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀!
19 Ánà ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́rin tó ń sin Ọlọ́run tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ “kì í pa wíwà ní tẹ́ńpìlì jẹ.” Ó ń ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ sí Jèhófà tọ̀sántòru “pẹ̀lú ààwẹ̀ àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀.” Ánà pẹ̀lú wà níbẹ̀ nígbà tí wọ́n gbé Jésù, ọmọ ọwọ́ wá sí tẹ́ńpìlì. Ẹ wo bí Ánà ti kún fún ọpẹ́ tó pé òun rẹ́ni tó máa di Mèsáyà lọ́jọ́ iwájú! Kódà, ńṣe ló “bẹ̀rẹ̀ sí dá ọpẹ́ padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run, ó sì ń sọ̀rọ̀ nípa ọmọ náà fún gbogbo àwọn tí ń dúró de ìdáǹdè Jerúsálẹ́mù.” Ánà wò ó pé dandan ni kóun sọ ìhìn rere yìí fún àwọn ẹlòmíràn! Bíi ti Síméónì àti Ánà, inú àwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ àgbàlagbà lónìí máa ń dùn pé kò sí béèyàn ti lè dàgbà tó tí kò lè sin Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí rẹ̀.
20. Láìfi ọjọ́ orí wa pè, kí ló yẹ ká máa ṣe, kí sì nìdí?
20 Láìfi ti ọjọ́ orí wa pè, a ní láti jẹ́ kí Jèhófà máa wà níwájú wa nígbà gbogbo. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà yóò bù kún ìsapá wa bá a ti ń sọ nípa Ìjọba Ọlọ́run àtàwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀ fáwọn èèyàn. (Sm. 71:17, 18; 145:10-13) Àmọ́ o, tá a bá fẹ́ máa bọ̀wọ̀ fún Jèhófà nígbà gbogbo, a gbọ́dọ̀ ní àwọn ànímọ́ tí yóò máa múnú Ọlọ́run dùn. Kí lá lè rí kọ́ nípa àwọn ànímọ́ wọ̀nyẹn bá a ti ń gbé àwọn àkọsílẹ̀ Bíbélì yẹ̀ wò síwájú sí i?
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Báwo la ṣe mọ̀ pé Jèhófà ń gbọ́ àdúrà?
• Kí nìdí tó fi yẹ ká ṣègbọràn sí Ọlọ́run délẹ̀délẹ̀?
• Bí ìdààmú ọkàn bá tiẹ̀ bá wa, kí nìdí tó fi yẹ ká máa gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà nígbà gbogbo?
• Báwo ni ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ṣe ń ran àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́?
[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
Jèhófà gbọ́ àdúrà Nehemáyà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Tá a bá ń rántí bí àyípadà rere ṣe bá Náómì, èyí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà