Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Tẹsalóníkà Kìíní àti Ìkejì, àti Ìwé Tímótì Kìíní àti Ìkejì
Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Tẹsalóníkà Kìíní àti Ìkejì, àti Ìwé Tímótì Kìíní àti Ìkejì
ÀTÌGBÀ tí wọ́n ti dá ìjọ Tẹsalóníkà sílẹ̀ nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lọ síbẹ̀ ni ìjọ náà ti ń fojú winá inúnibíni. Bí Tímótì, tó ṣeé ṣe kó ti lé lógún ọdún nígbà yẹn, ṣe wá padà dé láti ibẹ̀, tó sì mú ìròyìn rere wá, inú Pọ́ọ̀lù dùn débi pé ó kọ̀wé láti fi yin àwọn ará Tẹsalóníkà àti láti fi gbà wọ́n níyànjú. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ apá ìparí ọdún 50 Sànmánì Kristẹni ni Pọ́ọ̀lù kọ ìwé yìí, òun sì làkọ́kọ́ nínú àwọn ìwé tí Ọlọ́run mí sí i láti kọ. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà ló tún kọ̀wé kejì sáwọn Kristẹni tó wà nílùú Tẹsalóníkà. Lọ́tẹ̀ yìí, ńṣe ló tọ́ wọn sọ́nà lórí èrò òdì táwọn kan ní, tó sì tún gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n dúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́.
Nǹkan bí ọdún mẹ́wàá lẹ́yìn náà, Pọ́ọ̀lù wà ní Makedóníà, Tímótì sì wà ní Éfésù. Pọ́ọ̀lù wá kọ̀wé sí Tímótì láti fi gbà á níyànjú pé kó dúró sílùú Éfésù láti ran àwọn ará tó wà níbẹ̀ lọ́wọ́ kí àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ èké tó wà nínú ìjọ yẹn má bàa paná ìgbàgbọ́ wọn. Pọ́ọ̀lù tún kọ̀wé kejì sí Tímótì nígbà tí wọ́n dojú inúnibíni kọ àwọn Kristẹni lẹ́yìn tí jàǹbá iná ńlá kan wáyé nílùú Róòmù lọ́dún 64 Sànmánì Kristẹni. Ìwé yẹn sì ni Pọ́ọ̀lù kọ gbẹ̀yìn nínú àwọn ìwé tí Ọlọ́run mí sí i láti kọ. Lóde òní, àwa náà lè jàǹfààní nínú ìwé mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí Pọ́ọ̀lù kọ yìí.—Héb. 4:12.
Ẹ “WÀ LÓJÚFÒ”
Pọ́ọ̀lù yin àwọn ará Tẹsalóníkà fún ‘iṣẹ́ ìṣòtítọ́ wọn, òpò onífẹ̀ẹ́ wọn àti ìfaradà wọn.’ Ó sọ pé ‘ìrètí àti ìdùnnú àti adé ayọ̀ ńláǹlà’ ni wọ́n jẹ́ fóun.—1 Tẹs. 1:3; 2:19.
Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù rọ àwọn Kristẹni tó wà ní Tẹsalóníkà pé kí wọ́n máa fi ìrètí àjíǹde tu ara wọn nínú, ó sọ pé: “Ọjọ́ Jèhófà ń bọ̀ gẹ́gẹ́ bí olè ní òru.” Ó wá rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n “wà lójúfò” kí wọ́n sì pa agbára ìmòye wọn mọ́.—1 Tẹs. 4:16-18; 5:2, 6.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
4:15-17—Àwọn wo ni ‘a ó gbà lọ nínú àwọsánmà láti pàdé Olúwa nínú afẹ́fẹ́,’ báwo ló sì ṣe máa ṣẹlẹ̀? Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó wà láàyè nígbà wíwà níhìn-ín Kristi gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba Ọlọ́run ni. Inú ọ̀run níbi tí ojú èèyàn kò lè rí ni wọn yóò ti “pàdé Olúwa” wa Jésù. Àmọ́ kí èyí tó lè ṣeé ṣe, wọ́n ní láti kú kí wọ́n sì jíǹde gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹ̀mí. (Róòmù 6:3-5; 1 Kọ́r. 15:35, 44) A ti wà nígbà wíwà níhìn-ín Kristi báyìí, nítorí náà, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó bá kú lóde òní, kò ní wà nípò òkú títí lọ. Ńṣe ni ‘a ó gbà wọ́n lọ,’ ìyẹn ni pé, a ó jí wọn dìde lọ́gán.—1 Kọ́r. 15:51, 52.
5:23—Kí ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó gbàdúrà pé “kí a pa ẹ̀mí àti ọkàn àti ara ẹ̀yin ará mọ́”? Ẹ̀mí, ọkàn àti ara ìjọ Kristẹni tó láwọn ará tó pọ̀, títí kan àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó wà ní Tẹsalóníkà, ni Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Dípò táá kàn fi gbàdúrà pé kí Ọlọ́run pa ìjọ yẹn mọ́, ó gbàdúrà pé kí Jèhófà pa “ẹ̀mí” ìjọ, ìyẹn ọ̀nà táwọn ará gbà ń ronú, mọ́. Ó tún gbàdúrà fún “ọkàn” ìjọ náà, ìyẹn wíwà tó wà, ó sì tún gbàdúrà fún “ara” rẹ̀, ìyẹn gbogbo àwọn ẹni àmì òróró tó para pọ̀ di ìjọ yẹn. (1 Kọ́r. 12:12, 13) Àdúrà tí Pọ́ọ̀lù gbà yìí fi hàn pé ìṣọ̀kan ìjọ jẹ ẹ́ lógún gidigidi.
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
1:3, 7; 2:13; 4:1-12; 5:15. Ọ̀nà téèyàn lè gbà fúnni nímọ̀ràn tó múná dóko ni pé kó kọ́kọ́ yin onítọ̀hún lórí ibi tó ti ṣe dáadáa, kó sì wá rọ̀ ọ́ pé kó túbọ̀ ṣe dáadáa níbi tó kù sí.
4:1, 9, 10. Àwọn olùjọsìn Jèhófà gbọ́dọ̀ rí i dájú pé àwọn ń tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn àwọn.
5:1-3, 8, 20, 21. Bí ọjọ́ Jèhófà ṣe ń sún mọ́lé, a gbọ́dọ̀ “pa agbára ìmòye wa mọ́, kí a sì gbé àwo ìgbàyà ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ wọ̀ àti ìrètí ìgbàlà gẹ́gẹ́ bí àṣíborí.” Yàtọ̀ síyẹn, a gbọ́dọ̀ fọkàn sí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
“Ẹ DÚRÓ GBỌN-IN GBỌN-IN”
Ó jọ pé àwọn kan nínú ìjọ yẹn ń túmọ̀ ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ nínú ìwé rẹ̀ kìíní sọ́nà òdì, tí wọ́n ń sọ pé àkókò “wíwàníhìn-ín Olúwa” ti dé. Láti jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ohun tí wọ́n rò yẹn kò rí bẹ́ẹ̀, Pọ́ọ̀lù sọ ohun tó máa ‘kọ́kọ́ dé’ ṣáájú ìyẹn.—2 Tẹs. 2:1-3.
Pọ́ọ̀lù rọ̀ wọ́n pé: “Ẹ dúró gbọn-in gbọn-in, kí ẹ sì di àwọn àṣà àfilénilọ́wọ́ tí a kọ́ yín mú láìjáwọ́.” Ó wá páṣẹ fún wọn pé kí wọ́n “fà sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ olúkúlùkù arákùnrin tí ń rìn ségesège.”—2 Tẹs. 2:15; 3:6.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
2:3, 8—Ta ni “ọkùnrin oníwà àìlófin” yẹn, báwo ni Jésù yóò sì ṣe pa á? “Ọkùnrin” yẹn dúró fún àwùjọ àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì. Jésù Kristi, ẹni tí í ṣe “Ọ̀rọ̀,” ìyẹn Olórí Agbọ̀rọ̀sọ Ọlọ́run ni Ọlọ́run fún láṣẹ láti kéde ìdájọ́ rẹ̀ sórí àwọn ẹni ibi, kó sì pàṣẹ pé kí wọ́n pa wọ́n run. (Jòh. 1:1) Nítorí náà, a lè sọ pé Jésù yóò “fi ẹ̀mí ẹnu rẹ̀,” ìyẹn agbára ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀, pa ọkùnrin oníwà àìlófin náà.
2:13, 14—Báwo ló ṣe jẹ́ pé “láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀” ni ‘Ọlọ́run ti yan àwọn ẹni àmì òróró fún ìgbàlà’? Jèhófà ti yan àwọn ẹni àmì òróró gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ kan látìgbà tó ti pinnu pé irú ọmọ obìnrin náà máa fọ́ Sátánì lórí. (Jẹ́n. 3:15) Jèhófà sì tún sọ àwọn nǹkan tí wọ́n gbọ́dọ̀ máa ṣe kí wọ́n tó lè kúnjú òṣùwọ̀n àti iṣẹ́ tí wọ́n máa ṣe àti àdánwò tí wọ́n máa fojú winá. Nípa bẹ́ẹ̀, ńṣe ló pè wọ́n sí “ìpín yìí.”
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
1:6-9. Jèhófà kì í fi ìdájọ́ rẹ̀ pa àwọn ẹni rere run pọ̀ mọ́ àwọn ẹni burúkú.
3:8-12. A ò gbọ́dọ̀ torí pé ọjọ́ Jèhófà ti sún mọ́lé ká má ṣiṣẹ́ láti fi gbọ́ bùkátà ara wa, pàápàá lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wa. Jíjókòó gẹlẹtẹ máa ń sọni dọ̀lẹ, ó sì lè jẹ́ ká di “olùyọjúràn sí ọ̀ràn àwọn ẹlòmíràn.”—1 Pét. 4:15.
“MÁA ṢỌ́ OHUN TÍ A TÒ JỌ NÍ ÌTỌ́JÚPAMỌ́ SỌ́DỌ̀ RẸ”
Pọ́ọ̀lù sọ fún Tímótì pé kó “máa bá a lọ ní jíja ogun àtàtà; ní dídi ìgbàgbọ́ àti ẹ̀rí-ọkàn rere mú.” Ó mẹ́nu ba àwọn ohun tí a ó máa wò ká tó yan ẹnì kan sípò iṣẹ́ ìsìn nínú ìjọ. Pọ́ọ̀lù tún sọ fún Tímótì pé kó “kọ̀ láti gba àwọn ìtàn èké tí ó máa ń fi àìmọ́ ba ohun mímọ́ jẹ́.”—1 Tím. 1:18, 19; 3:1-10, 12, 13; 4:7.
Pọ́ọ̀lù ní: “Má ṣe fi àṣìṣe àgbà ọkùnrin hàn lọ́nà mímúná janjan.” Ó rọ Tímótì pé: “Máa ṣọ́ ohun tí a tò jọ ní ìtọ́júpamọ́ sọ́dọ̀ rẹ, yẹra fún àwọn òfìfo ọ̀rọ̀ tí ó máa ń fi àìmọ́ ba ohun mímọ́ jẹ́ àti fún àwọn ìtakora ohun tí a fi èké pè ní ‘ìmọ̀.’”—1 Tím. 5:1; 6:20.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
1:18; 4:14—Kí ni “ìsọtẹ́lẹ̀” tí wọ́n sọ nípa Tímótì? Ó lè jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ tí ẹ̀mí Ọlọ́run mú kí a sọ nígbà tí Pọ́ọ̀lù wá sí Lísírà nígbà ìrìn àjò míṣọ́nnárì rẹ̀ ẹlẹ́ẹ̀kejì, ìyẹn àsọtẹ́lẹ̀ nípa ipa tí Tímótì máa kó nínú ìjọ Kristẹni lọ́jọ́ iwájú. (Ìṣe 16:1, 2) “Ìsọtẹ́lẹ̀” yìí ló mú káwọn àgbà ìjọ “gbé ọwọ́ lé” Tímótì tó jẹ́ ọ̀dọ́ nígbà yẹn, tí wọ́n sì fa iṣẹ́ pàtàkì kan lé e lọ́wọ́.
2:15—Ọ̀nà wo la ó gbà “pa [obìnrin] mọ́ láìséwu nípasẹ̀ ọmọ bíbí”? Ọmọ bíbí, títọ́jú ọmọ àti mímójú tó agbo ilé lè ‘pa obìnrin mọ́ láìséwu’ kó má di aláìníṣẹ́, ‘olófòófó àti alátojúbọ àlámọ̀rí àwọn ẹlòmíràn.’—1 Tím. 5:11-15.
3:16—Kí ni àṣírí ọlọ́wọ̀ yìí ti fífọkànsin Ọlọ́run? Fún ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún, kò ṣeé ṣe fúnni láti mọ̀ bóyá ẹ̀dá èèyàn lè ṣègbọràn sí Jèhófà délẹ̀délẹ̀ láìkù síbì kankan tàbí wọn ò lè ṣe é. Ohun àṣírí ló jẹ́. Jésù ló wá pèsè ìdáhùn nípa jíjẹ́ tó jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run láìyingin títí dójú ikú.
6:15, 16—Ṣé Jèhófà Ọlọ́run lọ̀rọ̀ yìí ń tọ́ka sí ni tàbí Jésù Kristi? Jésù Kristi, tí ẹsẹ yẹn ń sọ̀rọ̀ nípa ìfarahàn rẹ̀ ló ń tọ́ka sí. (1 Tím. 6:14) Tá a bá fi ipò Jésù wé tàwọn tó jẹ́ ọba àti olúwa láàárín àwa èèyàn, Jésù ni “Ọba Alágbára Gíga kan ṣoṣo náà,” òun nìkan ṣoṣo ló sì ní àìkú. (Dán. 7:14; Róòmù 6:9) Látìgbà tó ti gòkè re ọ̀run, kò sí ẹ̀dá èèyàn kankan lórí ilẹ̀ ayé tó “lè” fi ojúyòójú “rí i.”
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
4:15. Yálà a ṣẹ̀ṣẹ̀ di Kristẹni ni o tàbí ó pẹ́ tá a ti di Kristẹni, a gbọ́dọ̀ máa rí i pé à ń tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn wa, ká sì jẹ́ kí àjọṣe àwa àti Jèhófà túbọ̀ máa dára sí i.
6:2. Tí Ẹlẹ́rìí bíi tiwa bá gbà wá síṣẹ́, dípò tá a ó fi gùn lé ìyẹn, ká wá máa ṣe bó ṣe wù wá, ńṣe ló yẹ ká múra tán láti ṣiṣẹ́ yẹn dáadáa ju bí a ṣe máa ṣe lọ́dọ̀ ẹni tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí bíi tiwa.
“WÀÁSÙ Ọ̀RỌ̀ NÁÀ, WÀ LẸ́NU RẸ̀ NÍ KÁNJÚKÁNJÚ”
Láti lè mú kí Tímótì gbára dì de àwọn ìṣòro tó máa ní, Pọ́ọ̀lù sọ fún un pé: “Kì í ṣe ẹ̀mí ojo ni Ọlọ́run fún wa bí kò ṣe ti agbára àti ti ìfẹ́ àti ti ìyèkooro èrò inú.” Ó wá fún un nímọ̀ràn pé: “Kò yẹ kí ẹrú Olúwa máa jà, ṣùgbọ́n ó yẹ kí ó jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́ sí gbogbo ènìyàn, ẹni tí ó tóótun láti kọ́ni.”—2 Tím. 1:7; 2:24.
Pọ́ọ̀lù gba Tímótì níyànjú pé: “Máa bá a lọ nínú àwọn ohun tí o ti kọ́.” Ẹ̀kọ́ àwọn àpẹ̀yìndà ń tàn kálẹ̀ láyé ìgbà yẹn, nítorí náà Pọ́ọ̀lù sọ fún Tímótì pé: “Wàásù ọ̀rọ̀ náà, wà lẹ́nu rẹ̀ ní kánjúkánjú . . . fi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, báni wí kíkankíkan, gbani níyànjú.”—2 Tím. 3:14; 4:2.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
1:13—Kí ni “àpẹẹrẹ àwọn ọ̀rọ̀ afúnni-nílera”? Ọ̀rọ̀ “tí ó jẹ́ ti Olúwa wa Jésù Kristi” ni “àwọn ọ̀rọ̀ afúnni-nílera” yìí, ìyẹn àwọn ẹ̀kọ́ Kristẹni tóòtọ́. (1 Tím. 6:3) Ohun tí Jésù kọ́ni àtohun tó ṣe bá Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mu pátápátá, nípa báyìí, gbólóhùn náà, “àwọn ọ̀rọ̀ afúnni-nílera,” kó gbogbo ẹ̀kọ́ inú Bíbélì mọ́ra. Àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì yìí ló ń jẹ́ ká mọ ohun tí Jèhófà fẹ́ ká máa ṣe. Fífi tá a bá ń fi àwọn ohun tá a kọ́ nínú Bíbélì ṣèwà hù ló ń fi hàn pé a di àpẹẹrẹ àwọn ọ̀rọ̀ afúnni-nílera mú.
4:13—Kí ni “àwọn ìwé awọ” wọ̀nyẹn? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ara àwọn àkájọ ìwé inú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, èyí tí Pọ́ọ̀lù ń sọ pé kí wọ́n fi ránṣẹ́ sóun kóun lè máa kà wọ́n nígbà tó wà lẹ́wọ̀n nílùú Róòmù. Ó lè jẹ́ òrépèté ni wọ́n fi ṣe àwọn kan lára àkájọ ìwé yìí, kí àwọn míì sì jẹ́ awọ.
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
1:5; 3:15. Ìdí pàtàkì tí Tímótì fi gba Kristi Jésù gbọ́, ìyẹn ìgbàgbọ́ tó mú kí Tímótì lè ṣe gbogbo ohun tó ṣe nínú ìjọsìn, ni pé wọ́n fi Ìwé Mímọ́ kọ́ ọ nílé láti kékeré. Ó ṣe pàtàkì gan-an pé kí olúkúlùkù nínú ìdílé ronú ara rẹ̀ wò bóyá òun ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bí Ọlọ́run ṣe fẹ́, kí òbí sì wò ó bóyá òun ń kọ́ ọmọ òun lọ́nà bẹ́ẹ̀!
1:16-18. Táwọn ará wa bá wà nínú ìṣòro tàbí wọ́n ń ṣenúnibíni sí wọn tàbí wọ́n jù wọ́n sẹ́wọ̀n, ẹ jẹ́ ká máa gbàdúrà fún wọn, ká sì ṣe gbogbo ìrànlọ́wọ́ tá a bá lè ṣe fún wọn.—Òwe 3:27; 1 Tẹs. 5:25.
2:22. Kò yẹ kí àwa Kristẹni, pàápàá ọ̀dọ́, jẹ́ kí ṣíṣe eré ìmárale tó ń mú kí iṣu ẹran ara ki pọ́pọ́, eré ìdárayá, orin, eré ìnàjú, eré ìgbà-ọwọ́-dilẹ̀, rírin ìrìn àjò, ìtàkúrọ̀sọ, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ gba àkókò wọn débi pé wọn kò ní fi bẹ́ẹ̀ ráyè fún àwọn ìgbòkègbodò ìjọsìn wa.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Èwo ni Pọ́ọ̀lù kọ gbẹ̀yìn nínú àwọn ìwé tí Ọlọ́run mí sí i láti kọ?