Máa Jẹ́ Kí Ìgbéyàwó Rẹ Jẹ́ “Okùn Onífọ́nrán Mẹ́ta”
Máa Jẹ́ Kí Ìgbéyàwó Rẹ Jẹ́ “Okùn Onífọ́nrán Mẹ́ta”
“Okùn onífọ́nrán mẹ́ta ni a kò sì lè tètè fà já sí méjì.”—ONÍW. 4:12.
1. Ta ló so ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́ pọ̀ gẹ́gẹ́ bíi tọkọtaya?
LẸ́YÌN tí Jèhófà Ọlọ́run ti dá oríṣiríṣi ewéko àti ẹranko tán, ó dá ọkùnrin àkọ́kọ́ tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ádámù. Ẹ̀yìn ìgbà yẹn ni Ọlọ́run wá fi oorun àsùnwọra kun Ádámù, ó sì yọ ọ̀kan lára egungun ìhà Ádámù láti fi ṣe olùrànlọ́wọ́ tó jẹ́ ẹni pípé fún un. Bí Ádámù ṣe fojú kan obìnrin tí Jèhófà dá fún un, ó sọ pé: “Èyí ni egungun nínú àwọn egungun mi àti ẹran ara nínú ẹran ara mi.” (Jẹ́n. 1:27; 2:18, 21-23) Jèhófà fi hàn pé inú òun dùn bí òun ṣe dá ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́ yìí, ó wá so wọ́n pọ̀ bíi tọkọtaya, ó sì súre fún wọn.—Jẹ́n. 1:28; 2:24.
2. Báwo ni Sátánì ṣe fi orí Ádámù àti Éfà gbára?
2 Àmọ́, ó dunni pé kò pẹ́ kò jìnnà tí ìgbéyàwó tí Ọlọ́run dá sílẹ̀ yìí fi kó sí ìṣòro. Báwo ló ṣe ṣẹlẹ̀? Ẹ̀dá ẹ̀mí búburú kan tó dẹni tá a wá mọ̀ sí Sátánì tan Éfà débi tó fi jẹ nínú igi kan ṣoṣo tí Ọlọ́run kà léèwọ̀ fún tọkọtaya náà. Lẹ́yìn náà ni Ádámù ọkọ rẹ̀ bá a lọ́wọ́ sí àìgbọràn yìí tí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ di aṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run tó lẹ́tọ̀ọ́ láti máa ṣàkóso lọ́nà tó dáa. (Jẹ́n. 3:1-7) Nígbà tí Jèhófà bi wọ́n léèrè nípa ohun tí wọ́n ṣe, ó hàn gbangba pé ìṣòro ti wà láàárín tọkọtaya yìí. Ádámù dẹ́bi ru ìyàwó ẹ̀, ó ní: “Obìnrin tí ìwọ fi fún mi láti wà pẹ̀lú mi, òun ni ó fún mi ní èso láti ara igi náà, nítorí náà, mo sì jẹ.”—Jẹ́n. 3:11-13.
3. Èrò tí kò tọ̀nà wo làwọn Júù kan ní?
3 Láti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún tó ti kọjá lẹ́yìn ìgbà náà wá, Sátánì ti ń fi onírúurú ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ da àárín ọkọ àtìyàwó rú. Bí àpẹẹrẹ, láwọn ìgbà kan ó máa ń lo àwọn olórí ẹ̀sìn láti máa tan ohun tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu kálẹ̀ lórí ọ̀ràn ìgbéyàwó. Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù kan fọwọ́ rọ́ àwọn ìlànà Ọlọ́run tì sẹ́gbẹ̀ẹ́, wọ́n gbà pé ọkọ lè kọ ìyàwó rẹ̀ lórí àwọn ọ̀ràn tí ò tó nǹkan, bíi kíyàwó fi iyọ̀ já oúnjẹ. Àmọ́ Jésù sọ ọ́ kedere pé: “Ẹnì yòówù tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, bí kò ṣe lórí ìpìlẹ̀ àgbèrè, tí ó sì gbé òmíràn níyàwó, ṣe panṣágà.”—Mát. 19:9.
4. Àwọn nǹkan wo ló ń sọ ìdè ìgbéyàwó di aláìlágbára lóde òní?
4 Sátánì ò tíì jáwọ́ nínú sísọ ìdè ìgbéyàwó di nǹkan yẹpẹrẹ. Ara ohun tó fi hàn pé ìgbéyàwó ti di nǹkan yẹ̀yẹ́ ni pé ọkùnrin àti ọkùnrin ń fẹ́ ara wọn sílé, bẹ́ẹ̀ náà sì la rí àwọn obìnrin méjì tó ń ṣerú ẹ̀, a tún rí àwọn ọkùnrin àtobìnrin tí wọ́n ń gbé pọ̀ láìṣègbéyàwó, kódà ìkọ̀sílẹ̀ ti di mẹ́ta kọ́bọ̀. (Ka Hébérù 13:4.) Kí làwa gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni lè ṣe tá ò fi ní nírú èrò òdì táráyé ní nípa ìgbéyàwó? Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò àwọn nǹkan kan tó máa ń ṣẹlẹ̀ nínú ìdílé aláyọ̀.
Jẹ́ Kí Jèhófà Wà Nínú Ìgbéyàwó Rẹ
5. Kí nìtumọ̀ gbólóhùn náà, “okùn onífọ́nrán mẹ́ta” tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ìgbéyàwó?
5 Tí tọkọtaya kan bá fẹ́ kí àárín àwọn máa dùn yùngbà, àyàfi kí wọ́n jẹ́ kí Jèhófà bá wọn lọ́wọ́ sọ́rọ̀ àwọn. Ọ̀rọ̀ Jèhófà sọ pé: “Okùn onífọ́nrán mẹ́ta ni a kò sì lè tètè fà já sí méjì.” (Oníw. 4:12) Àpèjúwe ni gbólóhùn náà, “okùn onífọ́nrán mẹ́ta.” Tá a bá fi àpèjúwe yìí ṣàlàyé ọ̀rọ̀ àárín tọkọtaya, bó ṣe jẹ́ ni pé ọkọ àti aya jẹ́ okùn méjì, okùn kẹta tí wọ́n jọ lọ́ mọ́ra ni Jèhófà Ọlọ́run. Bí tọkọtaya bá wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Ọlọ́run, wọ́n á ní okun tí wọ́n á fi lè máa borí àwọn ìṣòro tó bá ń yọjú, ìyẹn sì lohun tó ṣe pàtàkì jù tó ń mú kí ayọ̀ wà nínú ìdílé.
6, 7. (a) Kí làwọn tọkọtaya Kristẹni lè ṣe láti rí i pé Ọlọ́run wà láàárín àwọn? (b) Kí ni arábìnrin kan sọ pé ọkọ òun fi ń wu òun jù?
6 Àmọ́ kí ni tọkọtaya kan lè ṣe láti rí i dájú pé ìgbéyàwó tiwọn dà bí okùn onífọ́nrán mẹ́ta? Dáfídì kọ ọ́ lórin nínú Sáàmù pé: “Láti ṣe ìfẹ́ rẹ, ìwọ Ọlọ́run mi, ni mo ní inú dídùn sí, òfin rẹ sì ń bẹ ní ìhà inú mi.” (Sm. 40:8) Ìfẹ́ táwa náà ní fún Ọlọ́run ló máa ń mú ká sìn ín pẹ̀lú ọkàn pípé. Ìdí nìyẹn tó fi yẹ kí ọkọ àti aya lẹ́nì kọ̀ọ̀kan wọn ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà, kí wọ́n sì máa ní inú dídùn sí ṣíṣe ìfẹ́ rẹ̀. Àwọn tọkọtaya tún gbọ́dọ̀ sápá láti máa ran ara wọn lọ́wọ́ kí ìfẹ́ tí olúkúlùkù wọn ní sí Ọlọ́run lè máa lágbára sí i.—Òwe 27:17.
7 Tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ ni òfin Ọlọ́run wà ní ìhà inú wa, àwọn ànímọ́ bí ìgbàgbọ́, ìrètí àti ìfẹ́ á máa hàn nínú ìwà wa, èyí á sì máa fún ìdè ìgbéyàwó wa lókun. (1 Kọ́r. 13:13) Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Sandra tó ti wọlé ọkọ láti àádọ́ta ọdún sẹ́yìn sọ pé: “Ohun tí ọkọ mi fi máa ń wù mí jù ni bó ṣe máa ń fún mi ní ìtọ́ni àti ìmọ̀ràn látinú Bíbélì àti ìfẹ́ tó ní fún Jèhófà, tó lágbára ju ìfẹ́ tó ní sí mi lọ.” Ẹ̀yin ọkọ, ṣé ìyàwó yín náà lè sọ irú ẹ̀ nípa yín?
8. Kí tọkọtaya kan tó lè gba “ẹ̀san rere” nínú ìgbéyàwó wọn, kí ni wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe?
8 Ṣé àjọṣe yín pẹ̀lú Jèhófà àti ọ̀ràn tó jẹ mọ́ Ìjọba Ọlọ́run ló ṣe pàtàkì jù ní ìgbésí ayé yín gẹ́gẹ́ bíi tọkọtaya? Síwájú sí i, ṣé ojú alábàáṣiṣẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà lẹ̀yin méjèèjì fi ń wo ara yín? (Jẹ́n. 2:24) Ọlọgbọ́n Ọba Sólómọ́nì kọ̀wé pé: “Ẹni méjì sàn ju ẹnì kan, nítorí pé wọ́n ní ẹ̀san rere fún iṣẹ́ àṣekára wọn.” (Oníw. 4:9) “Ẹ̀san rere” tí tọkọtaya kan á ní ni ìdílé tí ìfẹ́ àti ìbùkún Ọlọ́run gbilẹ̀ níbẹ̀. Ká sòótọ́, ọkọ àti aya gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ kára kí wọ́n tó lè rí èyí gbà.
9. (a) Kí ni ojúṣe àwọn ọkọ? (b) Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà ní Kólósè 3:19, báwo ló ṣe yẹ kí ọkọ máa ṣe sí ìyàwó rẹ̀?
9 Ohun kan tó lè fi hàn bóyá Ọlọ́run wà nínú ìdílé kan ni bí tọkọtaya ṣe ń sapá tó láti máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Ọlọ́run. Ara ojúṣe àwọn ọkọ ni pé kí wọ́n máa pèsè ohun tí ìdílé nílò kí wọ́n sì máa rí i pé ìdílé wọn ń jọ́sìn Ọlọ́run déédéé. (1 Tím. 5:8) Ìwé Mímọ́ tún rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n máa ro ti ẹ̀dùn ọkàn àwọn ìyàwó wọn. Ní Kólósè 3:19, a kà pé: “Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa bá a nìṣó ní nínífẹ̀ẹ́ àwọn aya yín, ẹ má sì bínú sí wọn lọ́nà kíkorò.” Ọ̀gbẹ́ni kan tó ń ṣèwádìí nípa Bíbélì ṣàlàyé pé gbólóhùn náà “bínú sí wọn lọ́nà kíkorò” túmọ̀ sí “sísọ kòbákùngbé ọ̀rọ̀ sí wọn, lílù wọ́n, ṣíṣàì fìfẹ́ bá wọn lò, ṣíṣàì tọ́jú wọn, ṣíṣàì ràn wọ́n lọ́wọ́, ṣíṣàì dáàbò bò wọ́n àti ṣíṣàì pèsè fún wọn.” Ó ṣe kedere pé irú ìwà bẹ́ẹ̀ ò bójú mu nínú ìdílé Kristẹni. Tí ọkọ kan bá ń lo ipò orí rẹ̀ tìfẹ́tìfẹ́, á mú kó máa wu ìyàwó rẹ̀ láti tẹrí ba fún un gẹ́gẹ́ bí orí.
10. Irú ẹ̀mí wo ló yẹ káwọn aya Kristẹni máa ní?
10 Táwọn ìyàwó Kristẹni náà bá fẹ́ kí Jèhófà wà nínú ìdílé àwọn, wọ́n gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Ọlọ́run. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Kí àwọn aya wà ní ìtẹríba fún àwọn ọkọ wọn gẹ́gẹ́ bí fún Olúwa, nítorí pé ọkọ ni orí aya rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti jẹ́ orí ìjọ.” (Éfé. 5:22, 23) Sátánì tan Éfà jẹ nípa jíjẹ́ kó gbà pé èèyàn á ní ayọ̀ tí kò nípẹ̀kun tó bá wà lómìnira kúrò lábẹ́ àṣẹ Ọlọ́run. Kedere báyìí la sì ń rí ẹ̀mí tinú-mi-ni-màá-ṣe láàárín ọ̀pọ̀ tọkọtaya. Àmọ́, títẹríba fún ọkọ tí Ọlọ́run yàn ṣe orí ẹni kì í ṣohun ìríra fáwọn obìnrin tó fara mọ́ ohun tí Ọlọ́run sọ. Wọ́n máa ń rántí pé “àṣekún” ni Jèhófà fi Éfà ṣe fún ọkọ rẹ̀, ó sì ṣe kedere pé ipò ọ̀wọ̀ ni ipò yẹn lójú Ọlọ́run. (Jẹ́n. 2:18) Ká sòótọ́, “adé” orí ọkọ ni ìyàwó Kristẹni tó bá ń fi tinútinú fara mọ́ ipò tí Ọlọ́run gbé e sí yìí.—Òwe 12:4.
11. Kí ni arákùnrin kan sọ pé ó ti ran ìdílé òun lọ́wọ́?
11 Ohun míì tó tún lè jẹ́ kí Ọlọ́run wà nínú ìgbéyàwó ni pé kí tọkọtaya máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pa pọ̀. Arákùnrin Gerald tó ti ń gbádùn ìgbéyàwó tó ṣe lọ́dún márùnléláàádọ́ta sẹ́yìn sọ pé, “Kọ́kọ́rọ́ pàtàkì tó ń ṣílẹ̀kùn àṣeyọrí ìgbéyàwó ni pé kí tọkọtaya máa ka Bíbélì kí wọ́n sì máa kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ pa pọ̀.” Ó fi kún un pé, “Ṣíṣe nǹkan pa pọ̀, pàápàá àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ìjọsìn wa, máa ń jẹ́ kí tọkọtaya túbọ̀ sún mọ́ ara wọn, kí wọ́n sì sún mọ́ Jèhófà.” Kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pa pọ̀ máa ń jẹ́ kí ìdílé túbọ̀ máa fi àwọn ìlànà Jèhófà sọ́kàn, ó sì máa ń mú kí wọ́n túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run, kí wọ́n sì lè máa tẹ̀ síwájú.
12, 13. (a) Kí nìdí tí gbígbàdúrà pa pọ̀ fi ṣe pàtàkì púpọ̀ fún tọkọtaya? (b) Àwọn ìgbòkègbodò Kristẹni míì wo ló tún lè fún ìgbéyàwó lókun?
12 Àwọn tọkọtaya tó láyọ̀ tún máa ń gbàdúrà pa pọ̀. Nígbà tí ọkọ bá ń ‘tú ọkàn rẹ̀ jáde’ láti béèrè àwọn ohun tó kan ìdílé wọn gbọ̀ngbọ̀n, kò sí àní-àní pé ó máa mú kí tọkọtaya náà túbọ̀ sún mọ́ra. (Sm. 62:8) Bí àpẹẹrẹ, wo bó ṣe máa rọrùn tó láti gbé èdèkòyédè yín jù sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan lẹ́yìn tẹ́yin méjèèjì bá ti ké sí Olódùmarè pé kó tọ́ yín sọ́nà! (Mát. 6:14, 15) Níbàámu pẹ̀lú àdúrà yẹn, wo bó ṣe máa ṣàǹfààní tó tí olúkúlùkù yín bá fi ṣe ìpinnu rẹ̀ pé ẹ ó máa ran ara yín lọ́wọ́ àti pé ẹ ò tún “máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà lẹ́nì kìíní-kejì.” (Kól. 3:13) Má gbàgbé pé ńṣe ni àdúrà ń fi hàn pé èèyàn gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run. Dáfídì Ọba sọ pé: “Ìwọ ni ojú gbogbo gbòò ń wò tìrètí-tìrètí.” (Sm. 145:15) Tá a bá ń wojú Ọlọ́run pẹ̀lú ìrètí àti àdúrà, àníyàn wa kò ní pọ̀ torí a óò rí i pé ‘ó bìkítà fún wa.’—1 Pét. 5:7.
13 Ọ̀nà míì tá a lè gbà jẹ́ kí Jèhófà wà nínú ìgbéyàwó wa ni pé ká máa lọ sípàdé déédéé ká sì máa lọ sóde ẹ̀rí pa pọ̀. Inú ìpàdé Kristẹni làwọn tọkọtaya ti máa ń kọ́ bí wọ́n á ṣe borí “ètekéte,” ìyẹn ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí tí Sátánì ń lò láti tú ìgbéyàwó. (Éfé. 6:11) Àwọn ọkọ àtaya tó bá sì jọ ń lọ sóde ẹ̀rí pa pọ̀ máa ń mọ bí wọ́n á ṣe “fẹsẹ̀ múlẹ̀” tí wọ́n á sì di “aláìṣeéṣínípò.”—1 Kọ́r. 15:58.
Ohun Tẹ́ Ẹ Lè Ṣe Tí Ìṣòro Bá Dé
14. Àwọn nǹkan wo ló lè fa ìnira fún tọkọtaya?
14 Lóòótọ́, àwọn àbá tá a ti dá sókè yìí lè má tuntun létí, àmọ́ o ò ṣe bá ọkọ tàbí ìyàwó rẹ jíròrò rẹ̀ láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ? Ẹ wò ó bóyá àwọn apá ibì kan wà tó yẹ kẹ́ ẹ ti ṣàtúnṣe díẹ̀ sí i nínú ìdílé yín. Àmọ́ ṣá o, Bíbélì sọ ọ́ pé àwọn tí Ọlọ́run wà nínú ìgbéyàwó wọn pàápàá “yóò ní ìpọ́njú nínú ẹran ara wọn.” (1 Kọ́r. 7:28) Ìdí ni pé nítorí àìpé ẹ̀dá, ipa búburú ayé aláìlófin yìí àti ìdẹkùn Èṣù, àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run pàápàá lè rí ìnira tó ga nínú ìgbéyàwó wọn. (2 Kọ́r. 2:11) Àmọ́ Jèhófà ń ràn wá lọ́wọ́ láti lè borí rẹ̀. Àní sẹ́, a lè borí ìṣòro náà. Ṣebí Jóòbù tó jẹ́ adúróṣinṣin ìránṣẹ́ Ọlọ́run pàdánù àwọn ẹran ọ̀sìn rẹ̀, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àtàwọn ọmọ rẹ̀. Síbẹ̀ náà, Bíbélì sọ pé: “Nínú gbogbo èyí, Jóòbù kò dẹ́ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò ka ohunkóhun tí kò bẹ́tọ̀ọ́ mu sí Ọlọ́run lọ́rùn.”—Jóòbù 1:13-22.
15. Kí ni ìnira lè mú kéèyàn ṣe, kí sì làwọn lọ́kọláya lè ṣe tí ọ̀kan nínú wọn bá ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀?
15 Ohun tí ìyàwó Jóòbù sọ ní tiẹ̀ ni pé: “Ìwọ ha ṣì di ìwà títọ́ rẹ mú ṣinṣin? Bú Ọlọ́run, kí o sì kú!” (Jóòbù 2:9) Ká sòótọ́, nígbà tí àjálù tàbí àwọn ìṣòro míì bá dé sí wa, àníyàn tó máa ń tìdí ẹ̀ wá lè mú kéèyàn hùwà láìronú jinlẹ̀. Ọkùnrin ọlọ́gbọ́n yẹn sọ pé: “Ìnilára pàápàá lè mú kí ọlọ́gbọ́n ṣe bí ayírí.” (Oníw. 7:7) Tí ọkọ tàbí aya rẹ bá fìbínú sọ̀rọ̀ torí “ìnilára” tàbí ìṣòro kan, ìwọ gbìyànjú láti ṣe sùúrù. Tíwọ náà bá fìbínú sọ̀rọ̀ padà, ó lè mú kẹ́nì kan nínú yín tàbí ẹ̀yin méjèèjì sọ ohun kan tó máa fọ́ ọ̀rọ̀ yẹn lójú pọ̀. (Ka Sáàmù 37:8.) Torí náà, fi gbígbọ́ ṣaláìgbọ́ tí ọkọ tàbí aya rẹ bá sọ “ọ̀rọ̀ ẹhànnà” torí pé nǹkan tojú sú u tàbí nítorí ìrẹ̀wẹ̀sì.—Jóòbù 6:3.
16. (a) Báwo ni tọkọtaya ṣe lè fi ọ̀rọ̀ Jésù tó wà nínú Mátíù 7:1-5 sílò? (b) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí tọkọtaya máa fòye bá ara wọn lò?
16 Kò yẹ káwọn méjì tí wọ́n fẹ́ ara wọn máa retí pé gbogbo nǹkan á rí báwọn ṣe fẹ́. Ọkùnrin tàbí obìnrin kan lè rí àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ kan lára ẹnì kejì rẹ̀ àmọ́ kó máa sọ fún ara rẹ̀ pé ‘Màá gbà á lọ́wọ́ ẹ̀.’ Pẹ̀lú ìfẹ́ àti sùúrù, o lè ran ọkọ tàbí aya rẹ lọ́wọ́ láti máa yí padà díẹ̀díẹ̀ lóòótọ́ o. Àmọ́ má gbàgbé ṣá o, Jésù sọ pé ẹni tó sábà máa ń rí ìkùdíẹ̀-káàtó kéékèèké lára ẹnì kejì rẹ̀ dà bí ẹni tó ń wo “èérún pòròpórò” tó wà lójú arákùnrin rẹ̀ àmọ́ tí kò rí “igi ìrólé” tó wà lójú ara rẹ̀. Jésù rọ̀ wá pé: “Ẹ dẹ́kun dídánilẹ́jọ́ kí a má bàa dá yín lẹ́jọ́.” (Ka Mátíù 7:1-5.) Èyí ò wá sọ pé ká sọ àléébù tó lágbára di àríìgbọ́dọ̀wí o. Arákùnrin Robert, tó ti gbéyàwó láti bí ogójì ọdún sẹ́yìn sọ pé: “Kí tọkọtaya tó lè máa bá ara wọn sọ̀rọ̀ láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ, táwọn méjèèjì á sì máa gba àṣìṣe tí wọ́n ṣe, ó lè gba pé kí wọ́n yí ìwà wọn padà.” Torí náà, òye ni kẹ́ ẹ máa fi bá ara yín lò. Dípò tí wàá fi máa dààmú ara rẹ lórí àwọn ànímọ́ tó wù ọ́ àmọ́ tí ọkọ tàbí ìyàwó rẹ ò ní, gbìyànjú láti mọrírì àwọn ànímọ́ rere tó ní báyìí kó o sì jẹ́ kí wọ́n máa dá ẹ lọ́rùn.—Oníw. 9:9.
17, 18. Nígbà tí ìdààmú bá ga bí òkè níwájú wa, ibo la lè wá ìrànlọ́wọ́ lọ?
17 Ìdánwò lè dé nígbà tí ipò ìgbésí ayé yín bá yí padà. Táwọn tọkọtaya kan bá ti ń bímọ, àwọn nǹkan lè má fi bẹ́ẹ̀ rọrùn. Àìsàn tó lágbára lè kọ lu ọ̀kan nínú àwọn méjèèjì tàbí kó kọ lu ọmọ wọn. Àwọn òbí tó ń darúgbó lè nílò àbójútó àrà ọ̀tọ̀. Àwọn ọmọ lè bẹ̀rẹ̀ sí í filé sílẹ̀ lọ sọ́nà jíjìn bí wọ́n ṣe ń dàgbà. Àwọn iṣẹ́ téèyàn ń bójú tó nínú ètò Ọlọ́run lè mú ìyípadà míì wá. Gbogbo èyí lè fa ìnira àti àníyàn sáàárín tọkọtaya kan.
18 Tí ìnira tó wà nínú ìgbéyàwó yín bá ti le débi pé ó fẹ́ kọjá agbára yín, kí lo lè ṣe? (Òwe 24:10) Má juwọ́ sílẹ̀! Ńṣe ni inú Sátánì á máa dùn ṣìnkìn tí ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run bá lè pa ìjọsìn tòótọ́ tì, àgàgà tó bá tún lọ jẹ́ pé tọkọtaya ló ṣe bẹ́ẹ̀. Torí náà, ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti rí i pé ìgbéyàwó rẹ jẹ́ okùn onífọ́nrán mẹ́ta. Ìtàn ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn tó dúró bí olóòótọ́ lójú ìṣòro kún inú Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, ìgbà kan wà tí Dáfídì bá Jèhófà sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀, ó ní: “Fi ojú rere hàn sí mi, Ọlọ́run, nítorí pé ẹni kíkú . . . ń ni mí lára ṣáá.” (Sm. 56:1) Ǹjẹ́ “ẹni kíkú” ń ṣe nǹkan tó ń ni ọ́ lára? Ì báà jẹ́ ọ̀dọ̀ ẹnì kan tó jìnnà sí ọ lohun tó ń ni ọ́ lára náà ti ń wá tàbí kó jẹ́ ọ̀dọ̀ ẹnì kan tó sún mọ́ ọ, rántí ohun kan: Dáfídì rí okun tó mú kó lè fara dà á, ìwọ náà sì lè rí i. Dáfídì sọ pé: “Mo wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà, ó sì dá mi lóhùn, ó sì dá mi nídè nínú gbogbo jìnnìjìnnì mi.”—Sm. 34:4.
Àwọn Àǹfààní Míì Tá A Lè Rí
19. Kí la lè ṣe tí Sátánì ò fi ní rí wa gbé ṣe?
19 Lákòókò òpin yìí, ó yẹ káwọn tọkọtaya máa ‘tu ara wọn nínú lẹ́nì kìíní-kejì, kí wọ́n sì máa gbé ara wọn ró.’ (1 Tẹs. 5:11) Má gbàgbé pé ńṣe ni Sátánì ń sọ pé torí ìmọtara-ẹni-nìkan la ṣe jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà. Gbogbo agbára tó bá wà níkàáwọ́ Sátánì ló máa sà láti lè rí i pé òun mú ká jáwọ́ nínú ìṣòtítọ́ sí Ọlọ́run. Kódà tó bá gba pé kó da ìdílé wa rú, á fẹ́ dà á rú. Ohun tá a lè ṣe tí Sátánì ò fi ní rí wa gbé ṣe ni pé ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá. (Òwe 3:5, 6) Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Mo ní okun fún ohun gbogbo nípasẹ̀ agbára ìtóye ẹni tí ń fi agbára fún mi.”—Fílí. 4:13.
20. Àwọn àǹfààní wo la máa rí tá a bá jẹ́ kí Ọlọ́run wà nínú ìgbéyàwó wa?
20 Àǹfààní tó wà nínú jíjẹ́ kí Ọlọ́run wà nínú ìgbéyàwó wa pọ̀. Ó dájú pé Arákùnrin Joel àti ìyàwó rẹ̀ tí wọ́n ti fẹ́ ara wọn láti ọdún mọ́kànléláàádọ́ta sẹ́yìn ń jàǹfààní yẹn. Ó ní: “Ìgbà gbogbo ni mo máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà nítorí ìyàwó tó fún mi àti bá a ṣe mọwọ́ ara wa. Òun gan-an ni ìyàwó tó yẹ mí.” Ọgbọ́n wo ni wọ́n ń dá tí ìdè ìgbéyàwó wọn fi ń lágbára? Ó sọ pé: “A máa ń gbìyànjú láti máa ṣe ara wa pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́, à ń ní sùúrù àti ìfẹ́ fún ara wa.” Lóòótọ́, kò sí ẹnikẹ́ni nínú wa tó máa lè ṣe ìyẹn láṣepé nínú ètò nǹkan ìsinsìnyí. Síbẹ̀, ẹ jẹ́ ká sakun láti máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì kí Jèhófà bàa lè wà nínú ìgbéyàwó wa. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ìgbéyàwó wa á jẹ́ “okùn onífọ́nrán mẹ́ta [tí kò lè tètè] já sí méjì.”—Oníw. 4:12.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Kí ló túmọ̀ sí láti jẹ́ kí Jèhófà wà nínú ìgbéyàwó kan?
• Kí làwọn tọkọtaya ní láti ṣe nígbà tíṣòro bá dé?
• Báwo la ṣe máa mọ̀ tí Ọlọ́run bá wà nínú ìgbéyàwó kan?
[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Tí tọkọtaya bá ń gbàdúrà pa pọ̀, á ràn wọ́n lọ́wọ́ nígbà tí nǹkan bá le