Àwọn Olódodo Yóò Máa Yin Ọlọ́run Títí Láé
Àwọn Olódodo Yóò Máa Yin Ọlọ́run Títí Láé
“Olódodo yóò wà fún ìrántí . . . Òdodo rẹ̀ dúró títí láé.”—SM. 112:6, 9.
1. (a) Báwo ni ọjọ́ iwájú àwọn tí Ọlọ́run kà sí olódodo ṣe máa rí? (b) Ìbéèrè wo ló jẹ yọ?
ỌJỌ́ iwájú àwọn tí Ọlọ́run kà sí olódodo á mà lárinrin o! Títí ayé ni yóò máa wù wọ́n láti mọ̀ sí i nípa àwọn ànímọ́ Jèhófà tó fani mọ́ra. Ńṣe ni ọkàn wọn yóò sì máa kún fún ìyìn bí wọ́n ṣe ń mọ̀ sí i nípa àwọn iṣẹ́ ìṣẹ̀dá Ọlọ́run. Ọ̀kan lára ohun pàtàkì tí wọ́n máa ṣe tí ọjọ́ iwájú wọn á fi lárinrin ni iṣẹ́ “òdodo” tí Sáàmù 112 sọ̀rọ̀ rẹ̀ lásọtúnsọ. Àmọ́, báwo ni Jèhófà, Ọlọ́run mímọ́ àti olódodo ṣe lè ka àwa èèyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ sí olódodo? Kò sáà sí bá a ṣe lè gbìyànjú tó ká má ṣàṣìṣe, nítorí a kì í mọ̀-ọ́n rìn kórí má mì, kódà a máa ń ṣàṣìṣe tó lágbára láwọn ìgbà míì.—Róòmù 3:23; Ják. 3:2.
2. Iṣẹ́ ìyanu méjì wo ni ìfẹ́ mú kí Jèhófà ṣe?
2 Jèhófà ti fìfẹ́ ṣètò ọ̀nà pípé kan táwọn èèyàn tá a bí sínú ẹ̀ṣẹ̀ á fi lè jẹ́ olódodo lójú rẹ̀. Báwo ló ṣe ṣe é? Lákọ̀ọ́kọ́ ná, Jèhófà ṣe iṣẹ́ ìyanu, ó mú ìwàláàyè ààyò Ọmọ rẹ̀ láti ọ̀run, ó fi sínú ilé ọlẹ̀ wúńdíá kan ní ayé, tí wúńdíá náà sì wá bí i léèyàn pípé. (Lúùkù 1:30-35) Nígbà tó sì yá táwọn ọ̀tá pa Jésù Ọmọ rẹ̀ yìí, Jèhófà tún ṣe iṣẹ́ ìyanu míì tó ta yọ. Ó jí Jésù dìde gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹ̀mí kan tó jẹ́ ológo.—1 Pét. 3:18.
3. Kí nìdí tó fi dùn mọ́ Ọlọ́run nínú láti fún Ọmọ rẹ̀ ní ìwàláàyè tọ̀run?
3 Jèhófà wá san Jésù Ọmọ rẹ̀ lẹ́san. Ó fún un ní ìwàláàyè tí kò ṣeé pa run ní ọ̀run, irú èyí tí kò ní ṣáájú kó tó di èèyàn. (Héb. 7:15-17, 28) Ó dùn mọ́ Jèhófà nínú láti fún Jésù nírú ìwàláàyè yìí nítorí pé ó jẹ́ olóòótọ́ pátápátá lójú àwọn ìdánwò tó le koko. Jésù tipa báyìí jẹ́ kí Bàbá rẹ̀ rí ìdáhùn tó dára jù, èyí tí kò ṣeé já ní koro, pé irọ́ gbuu ni Sátánì ń pa bó ṣe sọ pé nítorí ìmọtara-ẹni-nìkan làwọn èèyàn ṣe ń sin Ọlọ́run.—Òwe 27:11.
4. (a) Lẹ́yìn tí Jésù pa dà dé ọ̀run, kí ló ṣe nítorí tiwa, kí sì ni Jèhófà ṣe nípa rẹ̀? (b) Báwo lohun tí Jèhófà àti Jésù ṣe fún ọ ṣe rí lára rẹ?
4 Nígbà tí Jésù dé ọ̀run, ó tún ṣe ohun mìíràn. Ó gbé ìtóye “ẹ̀jẹ̀ òun fúnra rẹ̀,” ó lọ “fara hàn níwájú Ọlọ́run fúnra rẹ̀” nítorí tiwa. Bàbá wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́ sì fi inúure gba ẹbọ iyebíye Jésù gẹ́gẹ́ bí “ìpẹ̀tù fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.” Ìdí rèé tó fi ṣeé ṣe fún wa láti lè máa fi ‘ẹ̀rí ọkàn tó mọ́’ ṣe “iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún Ọlọ́run alààyè.” Ẹ ò rí i pé ìdí pàtàkì nìyẹn jẹ́ fáwa náà láti ṣe ohun tí gbólóhùn àkọ́kọ́ nínú Sáàmù 112 sọ, ìyẹn ni pé: “Ẹ yin Jáà”!—Héb. 9:12-14, 24; 1 Jòh. 2:2.
5. (a) Kí la gbọ́dọ̀ ṣe kí Ọlọ́run tó lè kà wá sí olódodo? (b) Báwo ni wọ́n ṣe to Sáàmù 111 àti Sáàmù 112?
5 Kí Ọlọ́run tó lè kà wá sí olódodo, a gbọ́dọ̀ lo ìgbàgbọ́ nínú ẹ̀jẹ̀ Jésù tó ta sílẹ̀. Ojoojúmọ́ ló yẹ ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún ìfẹ́ ńlá tó ní sí wa yìí. (Jòh. 3:16) Ó tún yẹ ká máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nìṣó ká sì máa sa gbogbo ipá wa láti tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ inú rẹ̀. Sáàmù 112 ní ìmọ̀ràn pàtàkì fún gbogbo ẹni tó bá fẹ́ máa ní ẹ̀rí ọkàn mímọ́ lójú Ọlọ́run. Sáàmù yìí tan mọ́ Sáàmù 111. Gbólóhùn tó bẹ̀rẹ̀ sáàmù méjèèjì ni “Ẹ yin Jáà!” tàbí lédè mìíràn “Halelúyà”! Ìlà orin méjìlélógún ló tẹ̀ lé gbólóhùn yìí nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan Sáàmù náà, gbogbo ìlà náà sì bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀kọ̀ọ̀kan lẹ́tà ABD méjìlélógún ti èdè Hébérù. a
Ohun Tó Ń Múni Láyọ̀
6. Báwo ni “ènìyàn” tó bẹ̀rù Ọlọ́run tí Sáàmù 112 sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ yóò ṣe gba ìbùkún?
6 “Aláyọ̀ ni ènìyàn tí ó bẹ̀rù Jèhófà, tí ó ní inú dídùn gidigidi sí àwọn àṣẹ rẹ̀. Àwọn ọmọ rẹ̀ yóò di alágbára ńlá ní ilẹ̀ ayé. Ní ti ìran àwọn adúróṣánṣán, yóò ní ìbùkún.” (Sm. 112:1, 2) Kíyè sí i pé “ènìyàn” kan ṣoṣo ni onísáàmù yẹn kọ́kọ́ mẹ́nu kàn kó tó wá dẹ́nu lé ọ̀rọ̀ “àwọn adúróṣánṣán” lápá ìparí ẹsẹ kejì. Èyí fi hàn pé Sáàmù 112 yìí lè tọ́ka sí àwùjọ àwọn èèyàn kan. Ẹ̀rí ohun tá a sọ yìí hàn látinú bí Ọlọ́run ṣe mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti lo ọ̀rọ̀ inú Sáàmù 112:9 láti fi ṣàlàyé ọ̀rọ̀ nípa àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní. (Ka 2 Kọ́ríńtì 9:8, 9.) Ẹ ò rí bí sáàmù yìí ṣe jẹ́ ká rí àwọn ohun tó lè mú káwọn ọmọlẹ́yìn Kristi tó wà lórí ilẹ̀ ayé lóde òní láyọ̀!
7. Kí nìdí tó fi yẹ káwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run, irú ọwọ́ wo ló sì yẹ kí ìwọ fi mú àṣẹ rẹ̀?
7 Gẹ́gẹ́ bí Sáàmù 112:1 ṣe sọ, àwọn Kristẹni tòótọ́ yìí ń ní ayọ̀ tó ga lọ́lá bí wọ́n ṣe ń rìn ní ‘ìbẹ̀rù Jèhófà.’ Ìbẹ̀rù Ọlọ́run tí wọ́n ní, tí kì í jẹ́ kí wọ́n fẹ́ ṣe ohun tó máa bí i nínú, ni kò jẹ́ kí wọ́n fàyè gba ẹ̀mí ayé Sátánì. Ńṣe ni wọ́n “ní inú dídùn gidigidi” sí kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti pípa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́. Ara àṣẹ yẹn sì ni pé kí wọ́n máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run káàkiri ayé. Wọ́n ń sapá láti sọ àwọn èèyàn di ọmọlẹ́yìn ní gbogbo orílẹ̀-èdè, wọ́n sì ń kìlọ̀ fáwọn ẹni burúkú pé ọjọ́ ìdájọ́ Ọlọ́run ń bọ̀.—Ìsík. 3:17, 18; Mát. 28:19, 20.
8. (a) Ìbùkún wo làwọn èèyàn Ọlọ́run òde òní ti rí gbà fún ìtara wọn lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀? (b) Àwọn ìbùkún wo ló wà lọ́jọ́ iwájú fún àwọn tó ń retí àtijogún ayé?
8 Nítorí pé à ń pa irú àwọn àṣẹ bẹ́ẹ̀ mọ́, iye àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó wà lórí ilẹ̀ ayé báyìí ti ju mílíọ̀nù méje lọ. Ta ló máa wá sọ pé àwọn èèyàn Jèhófà kò tíì di “alágbára ńlá ní ilẹ̀ ayé”? (Jòh. 10:16; Ìṣí. 7:9, 14) Ẹ sì tún wá wo bí “ìbùkún” wọn á ṣe pọ̀ tó nígbà tí Ọlọ́run bá ṣe ohun tó ti pinnu! Gẹ́gẹ́ bí àwùjọ èèyàn kan, Jèhófà máa mú kí àwọn tó ń retí àtijogún ayé la ìpọ́njú ńlá tó ń bọ̀ já, wọn yóò sì para pọ̀ di “ayé tuntun” nínú èyí tí ‘òdodo yóò máa gbé.’ Tó bá wá yá, àwọn tó la Amágẹ́dọ́nì já yìí “yóò ní ìbùkún” tó tún ju ìyẹn lọ. Àwọn ni yóò máa kí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn tó bá jíǹde káàbọ̀. Ọjọ́ iwájú yẹn á mà láyọ̀ o! Níkẹyìn, àwọn tó “ní inú dídùn gidigidi” sí àwọn àṣẹ Ọlọ́run yóò dẹni pípé, títí láé sì ni wọ́n á máa gbádùn “òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run.”—2 Pét. 3:13; Róòmù 8:21.
Ọ̀nà Tó Bọ́gbọ́n Mu Láti Gbà Lo Ọrọ̀
9, 10. Báwo ni àwọn Kristẹni tòótọ́ ṣe ń lo ọrọ̀ tẹ̀mí wọn, báwo sì ni òdodo wọn yóò ṣe dúró títí láé?
9 “Àwọn ohun tí ó níye lórí àti ọrọ̀ wà nínú ilé rẹ̀; òdodo rẹ̀ sì dúró títí láé. Ó ti kọ mànà nínú òkùnkùn gẹ́gẹ́ bí ìmọ́lẹ̀ fún àwọn adúróṣánṣán. Òun jẹ́ olóore ọ̀fẹ́ àti aláàánú àti olódodo.” (Sm. 112:3, 4) Láyé ìgbà tí wọ́n kọ Bíbélì, àwọn kan lára àwọn èèyàn Ọlọ́run jẹ́ ọlọ́rọ̀. Tá a bá sì tún gba apá ibòmíì wò ó, àwọn tí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà náà jẹ́ ẹni tó ní ojúlówó ọrọ̀, bí wọn ò tiẹ̀ lọ́rọ̀ nípa tara. Lóòótọ́, ọ̀pọ̀ àwọn tó bá rẹ ara wọn sílẹ̀ níwájú Ọlọ́run lè jẹ́ tálákà táwọn èèyàn lè máa fojú pa rẹ́ gẹ́gẹ́ bó ṣe rí nígbà ayé Jésù. (Lúùkù 4:18; 7:22; Jòh. 7:49) Àmọ́ yálà ẹnì kan jẹ́ ọlọ́rọ̀ nípa tara tàbí ó ní ìwọ̀nba nǹkan tara díẹ̀, onítọ̀hún ṣì lè di ọlọ́rọ̀ nípa tẹ̀mí, ìyẹn ni pé kó ní ọgbọ́n àti ìmọ̀ Ọlọ́run.—Mát. 6:20; 1 Tím. 6:18, 19; ka Jákọ́bù 2:5.
10 Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn kò dá nìkan lo ọrọ̀ tẹ̀mí wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni wọ́n ń “kọ mànà” “bí ìmọ́lẹ̀ fún àwọn adúróṣánṣán” nínú ayé Sátánì tó ṣókùnkùn yìí. Bí wọ́n ṣe ń ṣe é ni pé wọ́n ń ṣèrànwọ́ fáwọn èèyàn kí wọ́n lè jàǹfààní ìṣúra tẹ̀mí, ìyẹn ọgbọ́n àti ìmọ̀ Ọlọ́run. Àwọn alátakò ti gbìyànjú láti dá iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run dúró, àmọ́ wọn kò rí i ṣe. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni àṣeyọrí iṣẹ́ òdodo yìí máa “dúró títí láé.” Báwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run bá ń bá iṣẹ́ òdodo yìí lọ láìfi àtakò pè, ó dájú pé àwọn náà máa “dúró títí láé,” ìyẹn ni pé wọ́n á máa wà láàyè títí lọ gbére.
11, 12. Àwọn ọ̀nà wo làwọn èèyàn Ọlọ́run gbà ń lo àwọn ohun ìní wọn?
11 Àwọn èèyàn Ọlọ́run, ìyẹn àwọn ẹni àmì òróró tó jẹ́ ẹgbẹ́ ẹrú náà àtàwọn “ogunlọ́gọ̀ ńlá” ti fi hàn pé ọ̀làwọ́ làwọn nípa tara. Sáàmù 112:9 sọ pé: “Ó ti pín nǹkan fúnni lọ́nà gbígbòòrò; ó ti fún àwọn òtòṣì.” Lóde òní, àwọn Kristẹni tòótọ́ sábà máa ń dá nǹkan jọ fáwọn Kristẹni bíi tiwọn tó bá di aláìní, kódà wọ́n máa ń ṣe irú ẹ̀ fáwọn aládùúgbò wọn míì tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Wọ́n tún máa ń fi àwọn nǹkan ìní tara ṣètìlẹ́yìn fún ètò ìrànwọ́ tí wọ́n máa ń ṣe fáwọn èèyàn lásìkò àjálù. Gẹ́gẹ́ bí Jésù sì ṣe sọ, ohun tí wọ́n ń ṣe yìí ń fún wọn ní ayọ̀ pẹ̀lú.—Ka Ìṣe 20:35; 2 Kọ́ríńtì 9:7.
12 Láfikún sí i, ronú nípa iye owó tí ètò Ọlọ́run ń ná láti máa tẹ ìwé ìròyìn yìí ní èdè méjìléláàádọ́sàn-án [172], tó sì jẹ́ pé àwọn tí nǹkan ò rọ̀ṣọ̀mù fún ló ń sọ púpọ̀ nínú àwọn èdè náà. Ohun tó tún yẹ fún àkíyèsí ni pé ìwé ìròyìn yìí tún wà ní oríṣiríṣi èdè àwọn adití, a sì tún ń ṣe èyí táwọn afọ́jú lè kà.
Olóore Ọ̀fẹ́ àti Onídàájọ́ Òdodo
13. Àwọn wo ló fi àpẹẹrẹ títayọ lélẹ̀ lórí ọ̀ràn fífi oore ọ̀fẹ́ fúnni ní nǹkan, báwo la sì ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn?
13 “Ènìyàn rere ni ẹni tí ń fi oore ọ̀fẹ́ hàn, tí ó sì ń wínni.” (Sm. 112:5) Ó ṣeé ṣe kó o ti kíyè sí i pé kì í ṣe inúure ọ̀pọ̀ àwọn tó ń ta àwọn èèyàn lọ́rẹ náà ló pọ̀ tó bẹ́ẹ̀. Ńṣe làwọn kan máa ń fún àwọn èèyàn ní nǹkan láti lè fi ẹni tí wọ́n fún ní nǹkan gbayì tàbí kí wọ́n máa fúnni ní nǹkan tìkanra-tìkanra. Ó dájú pé kò ní wù ọ́ láti gba nǹkan lọ́wọ́ ẹnì kan tó máa kọ́kọ́ wọ́ ẹ nílẹ̀ kó tó fún ẹ tàbí tó máa fojú ayọnilẹ́nu wò ọ́. Àmọ́, wo bí yóò ṣe dùn mọ́ ẹ tó láti gba ìrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ ẹni tó máa fi oore ọ̀fẹ́ fún ọ ní nǹkan. Jèhófà jẹ́ àpẹẹrẹ títayọ lórí ọ̀ràn fífi ayọ̀ àti oore ọ̀fẹ́ fúnni ní nǹkan. (1 Tím. 1:11; Ják. 1:5, 17) Jésù Kristi náà tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Bàbá rẹ̀ olóore ọ̀fẹ́ láìkù síbì kan. (Máàkù 1:40-42) Torí náà, kí Ọlọ́run tó lè kà wá sí olódodo, a ní láti máa fi oore ọ̀fẹ́ fúnni ní nǹkan tọ̀yàyàtọ̀yàyà, pàápàá nígbà tá a bá wà lóde ẹ̀rí tá à ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti mọ Jèhófà.
14. Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà ‘fi ìdájọ́ òdodo gbé àwọn àlámọ̀rí wa ró’?
14 “Ó ń fi ìdájọ́ òdodo gbé àwọn àlámọ̀rí rẹ̀ ró.” (Sm. 112:5) Gẹ́gẹ́ bí Jésù ti sọ tẹ́lẹ̀, ẹgbẹ́ olóòótọ́ ìríjú ń bójú tó àwọn ohun ìní Ọ̀gá náà lọ́nà tó bá ìdájọ́ òdodo Jèhófà mu. (Ka Lúùkù 12:42-44.) Èyí máa ń hàn nínú àwọn ìtọ́ni láti inú Ìwé Mímọ́ tí ẹgbẹ́ ẹrú náà máa ń fún àwọn alàgbà, tó jẹ́ pé nígbà míì, wọ́n máa ń bójú tó àwọn ọ̀ràn tó jẹ mọ́ ẹ̀ṣẹ̀ nínú ìjọ. Ẹ̀rí míì tó fi hàn pé ọ̀nà tó bá ìdájọ́ òdodo mu ni ẹgbẹ́ ẹrú náà gbà ń ṣe nǹkan ni ìtọ́ni tó dá lórí Bíbélì tí ẹrú yìí máa ń gbé jáde lórí bó ṣe yẹ kí nǹkan máa lọ ní gbogbo ìjọ, ní ilé àwọn míṣọ́nnárì àtàwọn ilé Bẹ́tẹ́lì. Àmọ́ àwọn alàgbà nìkan kọ́ ló yẹ kó máa tẹ̀ lé ìdájọ́ òdodo, ó kan gbogbo àwọn Kristẹni yòókù náà, pàápàá nínú bí wọ́n ṣe ń ṣe sí ara wọn àti sí àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àní títí dórí ọ̀ràn okòwò.—Ka Míkà 6:8, 11.
Àwọn Ìbùkún Tó Wà fún Olódodo
15, 16. (a) Báwo ni àwọn ìròyìn búburú inú ayé ṣe máa ń rí lára àwọn olódodo? (b) Kí làwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run ti pinnu láti máa ṣe?
15 “Nítorí a kì yóò mú kí ó ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n ní àkókò kankan. Olódodo yóò wà fún ìrántí fún àkókò tí ó lọ kánrin. Kì yóò fòyà ìhìn búburú pàápàá. Ọkàn-àyà rẹ̀ fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin, a gbé e lé Jèhófà. Ọkàn-àyà rẹ̀ jẹ́ aláìṣeémì; òun kì yóò fòyà, títí yóò fi máa wo àwọn elénìní rẹ̀.” (Sm. 112:6-8) Ìròyìn búburú kò tíì pọ̀ tó ti ayé ìsinsìnyí rí. Bẹ́ẹ̀ náà ni ogun, ìpániláyà, ìwà ọ̀daràn, ipò òṣì, ìbàyíkájẹ́ àti bí àrùn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń yọjú ṣe pọ̀ lọ jàra, bẹ́ẹ̀ sì rèé, àwọn àrùn tó ti wà tẹ́lẹ̀ kò tíì kásẹ̀ nílẹ̀. Lóòótọ́, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ láabi tá à ń gbọ́ ìròyìn rẹ̀ yìí ń kan àwọn tí Ọlọ́run kà sí olódodo náà, àmọ́ ìyẹn ò kó jìnnìjìnnì bá wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni ọ̀kan wọn “fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin,” tó sì jẹ́ “aláìṣeémì,” nítorí wọ́n nífọ̀kànbalẹ̀ pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa, bí wọ́n ṣe mọ̀ pé ayé tuntun òdodo Ọlọ́run ti sún mọ́lé. Tí àjálù kan bá wá ṣẹlẹ̀ tó sì kàn wọ́n, ó máa ń rọrùn fún wọn láti fara dà á ju àwọn yòókù lọ tórí pé Jèhófà ni wọ́n gbójú lé. Kì í jẹ́ kí àwọn olódodo “ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n,” kàkà bẹ́ẹ̀, ó máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́, ó sì máa ń fún wọn lókun láti fara dà á.—Fílí. 4:13.
16 Ara ohun táwọn èèyàn Ọlọ́run tó jẹ́ olódodo ń fara dà ni ìkórìíra àti irọ́ táwọn alátakò ń pa mọ́ wọn kiri. Àmọ́ gbogbo èyí ò pa àwọn Kristẹni tòótọ́ lẹ́nu mọ́, kò sì ní pa wọ́n lẹ́nu mọ́ láéláé. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe làwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run ń bá a lọ láti fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin láìṣeémì lẹ́nu iṣẹ́ tí Jèhófà gbé lé wa lọ́wọ́, ìyẹn iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run àti sísọ àwọn tó bá tẹ́wọ́ gbà á di ọmọ ẹ̀yìn. Láìsí àní-àní, àwọn olódodo máa fojú winá àtakò púpọ̀ sí i bí òpin ti ń sún mọ́lé. Àtakò yẹn máa dójú ẹ̀ nígbà tí Sátánì Èṣù tó jẹ́ Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù bá dojú ìjà kọ àwọn èèyàn Ọlọ́run kárí ayé. Nígbà náà ni àkókò yóò wá tó fún wa láti “máa wo àwọn elénìní wà” bí Ọlọ́run ṣe ń fọ́ wọn túútúú. Inú wa á mà dùn o láti rí bí Jèhófà yóò ṣe sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́ pátápátá!—Ìsík. 38:18, 22, 23.
‘A Fi Ògo Gbé E Ga’
17. Báwo ni a ó ṣe “fi ògo gbé” olódodo “ga”?
17 Ẹ wo bí yóò ti dùn tó nígbà tí gbogbo wa pátá bá jọ ń yin Jèhófà láìsí àtakò kankan látọ̀dọ̀ Èṣù àti ayé rẹ̀! Títí ayé ni gbogbo àwọn tí Ọlọ́run bá kà sí olódodo yóò sì máa fi irú ìdùnnú bẹ́ẹ̀ yìn ín. Ìtìjú ò ní dorí wọn kodò, àwọn ọ̀tá ò sì ní borí wọn, níwọ̀n bí Jèhófà ti ṣèlérí pé “ìwo” ìránṣẹ́ òun olódodo ni ‘a ó fi ògo gbé ga.’ (Sm. 112:9) Ìránṣẹ́ Jèhófà olódodo yóò yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun nígbà tó bá rí ìparun gbogbo àwọn ọ̀tá Jèhófà Ọba Aláṣẹ.
18. Báwo ni ọ̀rọ̀ tó parí Sáàmù 112 ṣe máa nímùúṣẹ?
18 “Àní ẹni burúkú yóò rí i, yóò sì bínú dájúdájú. Àní yóò wa eyín pọ̀, yóò sì yọ́ dànù ní ti gidi. Ìfẹ́-ọkàn àwọn ẹni burúkú yóò ṣègbé.” (Sm. 112:10) Gbogbo àwọn tí kò bá ṣíwọ́ títako àwọn èèyàn Ọlọ́run ló máa tipa owú àti ìkórìíra wọn “yọ́ dànù.” Nígbà “ìpọ́njú ńlá” tó ń bọ̀, wọ́n á pa run tàwọn ti ìfẹ́ ọkàn wọn láti fòpin sí iṣẹ́ ìwàásù wa.—Mát. 24:21.
19. Ìdánilójú wo la ní?
19 Ṣé wàá wà lára àwọn aláyọ̀ tó máa fojú rí ìṣẹ́gun ńlá yẹn? Tó bá sì ṣẹlẹ̀ pé àìsàn tàbí ọjọ́ ogbó gbẹ̀mí rẹ kí òpin tó dé bá ayé Sátánì yìí, ǹjẹ́ wàá wà lára “àwọn olódodo” tó máa jíǹde? (Ìṣe 24:15) Wàá lè dáhùn pé bẹ́ẹ̀ ni tí o kò bá jẹ́ kí ìgbàgbọ́ rẹ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù yẹ̀, tó o sì ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà, bíi tàwọn tí “ènìyàn” olódodo inú Sáàmù 112 dúró fún. (Ka Éfésù 5:1, 2.) Jèhófà yóò rí sí i pé “ìrántí” irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ kò di ìgbàgbé, kò sì ní gbójú fo iṣẹ́ òdodo tí wọ́n ti ṣe. Jèhófà yóò máa rántí wọn, yóò sì máa nífẹ̀ẹ́ wọn títí láé àti láéláé—Sm. 112:3, 6, 9.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Bí wọ́n ṣe to Sáàmù méjèèjì yìí àti irú àwọn ọ̀rọ̀ tó wà níbẹ̀ fi hàn pé wọ́n tan mọ́ra. Àwọn ànímọ́ Ọlọ́run tí Sáàmù 111 ń gbé ga ni “ènìyàn” tó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí Sáàmù 112 sọ̀rọ̀ rẹ̀, fi ń ṣèwà hù. A lè rí èyí tá a bá fi ohun tó wà nínú Sáàmù 111:3, 4 wé ohun tó wà nínú Sáàmù 112:3, 4.
Ìbéèrè Tí A Ó Fi Ṣàṣàrò
• Àwọn ìdí wo la ní láti máa ké “Halelúyà”?
• Àwọn ohun wo ló ń ṣẹlẹ̀ lóde òní tó ń mú àwa Kristẹni tòótọ́ láyọ̀ gan-an?
• Irú ẹ̀mí wo ni Jèhófà fẹ́ ká máa fi fúnni ní nǹkan?
[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Láti lè máa jẹ́ olódodo nìṣó lójú Ọlọ́run, a ní láti ní ìgbàgbọ́ nínú ẹ̀jẹ̀ Jésù tó ta sílẹ̀
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
À ń lo àwọn ọrẹ tá a fínnúfíndọ̀ ṣe fún ṣíṣe ìrànwọ́ nígbà àjálù, àti fún iṣẹ́ ìpínkiri àwọn ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì